Ifọkansin Fun Awọn Ohun Iranti Ha Wu Ọlọrun Bi?
Ẹ̀JẸ̀ “San Gennaro,” ti a sọ pe ó saba maa ndomi lẹẹmẹta lọdun kan, jẹ́ ọkan lara ọpọlọpọ awọn ohun iranti isin. Bẹẹ ni Aṣọ-isinku Turin [Shroud of Turin], ninu eyi ti wọn sọ pe a wé ara Jesu Kristi mọ́. Lara awọn ohun iranti ti ó ni isokọra pẹlu Jesu ni ohun ti wọn rò pe ó jẹ bẹẹdi rẹ̀ nigba ọmọde wà (ninu basilika nla kan ni Roomu), iwe ti o fi ńkọ́ bi a ti nsipẹli ọrọ, ati ohun ti o ju ẹgbẹrun kan ìṣó ti wọn sọ pe wọn lò nibi ti a ti fiya iku jẹ ẹ́! Awọn ohun iranti isin tun ni ninu awọn ori Johanu Arinibọmi melookan ati ara oku mẹrin ti wọn sọ pe ó jẹ ti “Santa Lucia,” ni oniruuru ibi ni Europe.
Lara awọn ilu ti wọn lokiki ni pataki fun awọn ohun iranti ni Trier, Germany, nibi ti a tọju ọ̀kan lara ọpọlọpọ “awọn aṣọ awọtẹlẹ mímọ́”—aṣọ awọtẹlẹ ti kò ni oju rírán tí Jesu Kristi wọ̀—pamọ sí. Ni Vatican City funraarẹ awọn ohun iranti ti wọn ju ẹgbẹrun kan lọ ni wọn wà ninu ile akanṣe kan ti a nko nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé pamọ́ sí. Niti gidi, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ohun iranti isin ni a fipamọ sinu ṣọọṣi “Ursula Mímọ́” ni Cologne, Germany. Akọsilẹ naa lè gun lọ jàn-ànràn-jan-anran. Họwu, ni Italy nikan, 2,468 awọn ibi ti a fẹnu lasan pe ni mímọ́ ti o ni awọn ohun iranti isin ni wọn wà!
Ọ̀wọ̀ fun awọn ohun iranti ni a gbagbọ pe ọjọ rẹ̀ ti pẹ sẹhin lati ọgọrun-un ọdun kẹrin ninu Sanmani Tiwa, gẹgẹ bi ikunlẹbọ “awọn ẹni mímọ́” ti ṣe pẹ́ tó pẹlu. Fun awọn idi ti ó jẹ́ ti isin, ọrọ̀ ajé, ati ti oṣelu paapaa, iye awọn ohun iranti ti pọ jaburata ni kẹrẹkẹrẹ la awọn ọrundun já, ti ẹgbẹẹgbẹrun fi wà lonii. Igbimọ Vatican Keji tun tẹnumọ ọn pe “ni ibamu pẹlu ẹkọ atọwọdọwọ, Ṣọọṣi nkunlẹbọ awọn ẹni mímọ́ wọn si nbọla fun awọn ohun iranti ati aworan wọn ti o lẹsẹ nilẹ.” (Constitution “Sacrosanctum Concilium” sulla sacra Liturgia, ni I Documenti del Concilio Vaticano II, 1980, Edizioni Paoline) “Awọn ohun iranti olokiki ati awọn wọnni ti ọpọ jantirẹrẹ awọn eniyan nbọla fun bakan naa,” ni a mẹnukan ninu Codex Iuris Canonici (Akojọ Iwe Ofin Onimiisi) ti John Paul Keji polongo ni 1983. (Canon 1190) Awọn ara ṣọọṣi Anglica ati awọn mẹmba ṣọọṣi Orthodox nbọla fun awọn ohun iranti pẹlu.
Pẹlu ọpọlọpọ ohun ti wọn sọ pe ó jẹ́ awọn ìṣó ti a fi kan Kristi ati awọn ori Johanu Arinibọmi ti ó wà tobẹẹ, ó farahan pe awọn ohun iranti isin jẹ́ itanjẹ niye igba. Fun apẹẹrẹ, pipinnu ìlọ́jọ́ lórí radiocarbon fẹrii Aṣọ-Isinku Turin han pe ó jẹ́ ayédèrú. Lọna ti ó dùnmọ́ni, lakooko ariyanjiyan ti ó gbona lori rẹ̀ ni 1988, Marco Tosatti oluṣakiyesi Vatican ti ó gbajumọ naa beere pe: “Bi a bá lo iṣayẹwo kínníkínní ti imọ ijinlẹ ti a lo lori Aṣọ-isinku naa fun awọn ohun ifọkansin ti ó lokiki miiran, ki ni ipinnu ikẹhin naa yoo jẹ́?”
Ni kedere, kò sí eniyan ọlọgbọn kankan ti yoo fẹ́ lati kunlẹbọ ohun iranti èké kan. Ṣugbọn iyẹn ha ni kiki koko ti a nilati gbeyẹwo bi?
Ki Ni Ohun Ti Bibeli Sọ?
Bibeli kò sọ pe awọn eniyan ti Ọlọrun ṣojurere si naa, awọn ọmọ Isirẹli igbaani, kunlẹbọ awọn ohun iranti isin nigba ti wọn wà ni oko ẹrú awọn ara Ijibiti. Loootọ, Jakọbu babanla naa kú ni Ijibiti ara oku rẹ̀ ni a sì gbe lọ si ilẹ Kenani fun isinku ‘ninu ihò ti ó wà ni papa Machpelah.’ Ọmọkunrin rẹ̀ Josẹfu kú sí Ijibiti pẹlu, awọn egungun rẹ̀ ni a sì gbe lọ si Kenani fun isinku lẹhin-ọ-rẹhin. (Jẹnẹsisi 49:29-33; 50:1-14, 22-26; Ẹkisodu 13:19) Bi o ti wu ki o ri, Iwe mimọ ko funni ni itọka kankan pe awọn ọmọ Isirẹli kunlẹbọ ara oku Jakọbu ati ti Josẹfu gẹgẹ bi awọn ohun iranti isin kan lae.
Tun ṣagbeyẹwo ohun ti o ṣẹlẹ ninu ọran ti wolii Mose. Labẹ idari Ọlọrun, ó ṣe aṣaaju awọn ọmọ Isirẹli fun 40 ọdun. Lẹhin naa, ni ẹni 120 ọdun, o goke lọ sori Oke Nebo, ó wo Ilẹ Ileri naa, ó sì kú. Maikẹli olu angẹli naa ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu Eṣu nipa ara Mose, Satani ni a sì dí lọwọ ninu igbidanwo eyikeyii ti ó ṣeeṣe lati lò ó lati kẹ́dẹ mu awọn ọmọ Isirẹli ninu ijọsin awọn ohun iranti. (Juuda 9) Bi o tilẹ jẹ pe a loye rẹ̀ pe wọn ṣọfọ iku Mose, wọn kò kunlẹbọ ara oku rẹ̀. Nitootọ, Ọlọrun mu iru nǹkan bẹẹ di eyi ti kò ṣeeṣe nipa sísin Mose si iboji kan ti a kò sami sí ni ibikan ti awọn eniyan kò mọ̀.—Deutaronomi 34:1-8.
Awọn agbẹnusọ kan fun ikunlẹbọ awọn ohun iranti tọka si 2 Ọba 13:21, ti o wi pe: “O sì ṣe, bi wọn ti ńsìnkú ọkunrin kan, sì kiyesi i, wọn ri ẹgbẹ́ kan; wọn sì ju ọkunrin naa sinu isa-oku [wolii] Eliṣa; nigba ti a sì sọ ọ́ silẹ, ti ọkunrin naa fi ara kan egungun Eliṣa, o sì sọji, ó si dide duro ni ẹsẹ rẹ̀.” Eyi jẹ́ iṣẹ iyanu kan ti ó wémọ́ awọn egungun gbígbẹ ti ọ̀kan lara awọn wolii Ọlọrun. Ṣugbọn Eliṣa ti kú ‘ko si mọ ohun kan’ ni akoko iṣẹ iyanu naa. (Oniwaasu 9:5, 10) Fun idi eyi, ajinde yii ni a gbọdọ kà sí agbara ti nṣiṣẹ iyanu ti Jehofa Ọlọrun, ẹni ti ó mu ki ó ṣẹlẹ nipasẹ ẹmi mímọ́, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀. Ó tun yẹ fun afiyesi pe Iwe mimọ kò sọ pe a kunlẹbọ egungun Eliṣa lae.
Awọn kan ninu Kristẹndọmu ti ifọkansin fun awọn ohun iranti lẹhin nitori ohun ti a sọ ni Iṣe 19:11, 12, nibi ti a ti kà pe: “Ọlọrun sì ti ọwọ [apọsiteli] Pọọlu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, tó bẹẹ ti a fi ńmú ìdikù ati ìbàǹtẹ́ ara rẹ̀ tọ awọn olokunrun lọ, arun sì fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu sì jade kuro lara wọn.” Jọwọ ṣakiyesi pe Ọlọrun ni ó ṣe awọn iṣẹ àrà-ọ̀tọ̀ wọnni nipasẹ Pọọlu. Apọsiteli naa funraarẹ kò danikan ṣe iru awọn iṣẹ bẹẹ, oun kò sì faramọ ìkúnlẹ̀bọni lati ọdọ eniyan eyikeyii lae.—Iṣe 14:8-18.
Ó Tako Awọn Ẹkọ Bibeli
Niti gidi, ifọkansin fun awọn ohun iranti isin tako ọpọ iye awọn ẹkọ Bibeli. Fun apẹẹrẹ, koko kan ti ó jẹ́ koṣeemani ninu iru ifọkansin bẹẹ ni igbagbọ ninu aileku ọkàn eniyan. Araadọta ọkẹ awọn mẹmba ṣọọṣi olufọkansin gbagbọ pe ọkàn gbogbo awọn wọnni ti a polongo ni ẹni mímọ́ lẹhin iku ti a sì kunlẹbọ gẹgẹ bi “awọn ẹni mímọ́” wà laaye ninu ọrun. Awọn eniyan oloootọ ọkàn wọnyi gbadura si iru “awọn ẹni mímọ́” bẹẹ, ni wiwa idaabobo wọn ati bibeere pe ki wọn ṣipẹ lọdọ Ọlọrun nititori ẹni ti ntọrọ naa. Nitootọ, gẹgẹ bi iwe kan tii ṣe ti ijọ ti wi, awọn Katoliki ka “agbara ẹ̀bẹ̀ Ẹni mímọ́ lọdọ Ọlọrun” si ti awọn ohun iranti.
Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi Bibeli ti wi, ọkàn eniyan kii ṣe alaileku. Awọn eniyan kò ni ọkàn ti kii ku ti o sì lagbara wíwà laisi ara lẹhin iku ninu wọn. Kaka bẹẹ, Iwe mimọ wi pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun sì fi erupẹ ilẹ mọ eniyan; ó sì mi ẹmi ìyè si iho imu rẹ̀; eniyan sì di alaaye ọkàn.” (Jẹnẹsisi 2:7) Dipo kikọni pe awọn eniyan ni ọkàn ti kii kú, Bibeli wi pe: “Ọkàn ti ó bá ṣẹ̀, oun ó ku.” (Esikiẹli 18:4) Eyi ṣee fisilo fun gbogbo eniyan—papọ pẹlu awọn wọnni ti a kà si “awọn ẹni mímọ́” lẹhin-ọ-rẹhin—nitori gbogbo wa ni a ti jogun ẹṣẹ ati iku lati ọdọ ọkunrin akọkọ, Adamu.—Roomu 5:12.
Ifọkansin fun “awọn ẹni mímọ́” ni a gbọdọ yẹra fun nitori pe a kò fun wọn laṣẹ rí lae lati ṣìpẹ̀ lọdọ Ọlọrun fun ẹnikẹni. Jehofa Ọlọrun ti paṣẹ pe kiki Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ni ó lè ṣe eyi. Apọsiteli Pọọlu sọ pe Jesu “kò kú fun wa nikan—ó ji dide kuro ninu oku, ati nibẹ ni ọwọ́ ọtun Ọlọrun ó duro ó sì nbẹbẹ fun wa.”—Roomu 8:34, The Jerusalem Bible; fiwe Johanu 14:6, 14.
Idi miiran ti a fi nilati yẹra fun ifọkansin fun “awọn ẹni mímọ́” ati awọn ohun iranti isin ti ó sopọ mọ wọn sinmi lori ohun ti Bibeli sọ nipa ibọriṣa. Ọ̀kan lara awọn Ofin Mẹwaa ti a fifun awọn ọmọ Isirẹli sọ pe: “Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti nbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti nbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti nbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ. Iwọ kò gbọdọ tẹ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹẹ ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú [“ti nbeere ifọkansin ayasọtọgedegbe,” NW] ni mi.” (Ẹkisodu 20:4, 5) Ni ọpọ ọrundun lẹhin naa, apọsiteli Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ pe: “Ẹyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa.” (1 Kọrinti 10:14) Bakan naa, apọsiteli Johanu kọwe pe: “Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa ara yin mọ kuro ninu oriṣa.”—1 Johanu 5:21.
Nitori naa, ọ̀wọ̀ fun awọn olóògbé ti a polongo lọna aṣẹ pe wọn jẹ́ “ẹni mímọ́” ati awọn ohun iranti isin kò ni itilẹhin kankan ninu Bibeli. Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan kan fẹ́ wiwa nibẹ ohun kan ti a kà si mímọ́ ti wọn lè ri ki wọn sì fọwọkan ti wọn sì tànmọ́-ọ̀n pe ó ni agbara igbala. Nitootọ, ọpọlọpọ ka awọn ohun iranti isin si isokọra ti ó ṣee fojuri ninu ẹwọn kan laaarin ọrun ati ilẹ-aye. Jọwọ ronu siwa sẹhin lori koko yii fun iṣẹju diẹ.
Kii ṣe nipa rírí ati fifọwọkan awọn ohun iranti isin ni ẹnikan fi lè huwa ni ibamu pẹlu awọn ọrọ Jesu nipa ijọsin ti Ọlọrun fẹ́. Jesu wi pe: “Ṣugbọn wakati nbọ, ó sì dé tan nisinsinyi, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ: nitori iru wọn ni Baba nwa ki ó maa sin oun. Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti nsin in kò le ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:23, 24) Jehofa Ọlọrun jẹ́ “Ẹmi,” ti oju eniyan kò lè rí. Lati sìn ín “ni ẹmi” tumọsi pe iṣẹ-isin mimọ ọlọ́wọ̀ wa si Ọlọrun ni a sun wa ṣe nipasẹ ọkan-aya ti ó kun fun ifẹ ati igbagbọ. (Matiu 22:37-40; Galatia 2:16) Awa kò le sin Ọlọrun “ni otitọ” nipa kikunlẹbọ awọn ohun iranti ṣugbọn kiki nipa ṣíṣá awọn èké isin tì, ni kikẹkọọ ifẹ-inu rẹ̀ gẹgẹ bi a ti ṣipaya rẹ̀ ninu Bibeli, ati ṣiṣe e.
Nitori naa, kò yà wá lẹnu pe ọmọwe James Bentley gbà pe ‘awọn Heberu igbaani kò ṣe ikunlẹbọ awọn ohun iranti.’ Ó tun wi pe lakooko awọn ọrundun mẹrin laaarin ìgbà iku Sitefanu ati ìgbà ti Lucian wú ara oku rẹ̀ jade, iṣarasihuwa awọn Kristẹni si awọn ohun iranti yipada patapata. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti o fi di ọrundun karun-un Sanmani Tiwa, Kristẹndọmu apẹhinda ti dawọ rírọ̀ mọ́ awọn ẹkọ Bibeli ti ó ṣe kedere nipa ibọriṣa, ipo awọn oku, ati ipa Jesu Kristi gẹgẹ bi ẹni naa ti o “nbẹbẹ fun wa” duro.—Roomu 8:34; Oniwaasu 9:5; Johanu 11:11-14.
Bi awa ba fẹ́ ki ijọsin wa wu Ọlọrun, a gbọdọ rí i daju pe a kò so ó pọ pẹlu iru ibọriṣa eyikeyii. Lati di eyi ti ó jasi itẹwọgba, ijọsin wa gbọdọ lọ sọdọ Ẹlẹdaa naa, Jehofa Ọlọrun, kii ṣe sọdọ ohun iranti tabi iṣẹda eyikeyii. (Roomu 1:24, 25; Iṣipaya 19:10) A tun gbọdọ gba imọ pipe ti Bibeli ki a sì gbé igbagbọ ti ó lagbara ró. (Roomu 10:17; Heberu 11:6) Bi a ba sì rìn ni ọna ti ijọsin tootọ, awa yoo huwa ni ibamu pẹlu ọpọ jaburata ẹ̀rí Iwe mimọ pe ifọkansin awọn ohun iranti kò wu Ọlọrun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Egungun Eliṣa ni a kò kunlẹbọ bi o tilẹ jẹ pe wọn wémọ́ ajinde kan