Bawo ni Jesu Kristi Ṣe Jẹ́ Wolii kan bii Mose?
JEHOFA ỌLỌRUN kii ṣeke. (Titu 1:2; Heberu 6:18) Nitori naa, awọn asọtẹlẹ Ọrọ rẹ̀, Bibeli, ṣee gbẹkẹle wọn sì jẹ́ otitọ. Wọn yoo ni imuṣẹ dajudaju.
Lara awọn asọtẹlẹ ti ó ni imisi atọrunwa wọnyi ni ọ̀kan tí wolii Heberu naa Mose ṣakọsilẹ rẹ̀ nipa Mesaya naa. Ni ṣiṣatunwi ọrọ Jehofa, Mose wi pe: “Emi yoo gbé wolii kan dide fun wọn [awọn ọmọ Isirẹli] laaarin awọn arakunrin wọn, bi iwọ [Mose]; emi yoo sì fi ọrọ mi si i ni ẹnu, oun yoo sì sọ fun wọn gbogbo eyi ti mo palaṣẹ.”—Deutaronomi 18:17, 18.
Apọsiteli naa Peteru fi akọsilẹ yii silo fun Jesu Kristi nigba ti oun kọwe pe: “Mose wi pe, ‘Jehofa Ọlọrun yoo gbé wolii kan ti ó dabii emi dide laaarin awọn arakunrin yin. Ẹ gbọdọ fetisilẹ sii ni ibamu pẹlu gbogbo nǹkan ti ó ba sọ fun yin.’” (Iṣe 3:22, NW) Niti tootọ Jesu tikaraarẹ ti sọtẹlẹ pe: “Bi ẹ ba gba Mose gbọ ẹyin yoo gbà mi gbọ́, nitori pe iyẹn kọwe nipa mi.” (Johanu 5:46, NW) Ni awọn ọna wo ni Jesu ati Mose fi jọra?
Wọn Jọra Ni Ibẹrẹ Iṣẹ Igbesi-aye Wọn
Awọn mejeeji Mose ati Jesu ni wọn yèbọ́ lọwọ ipakupa ti awọn ọmọdekunrin keekeeke. Ọmọ-ọwọ naa Mose ni a gbé pamọ saaarin awọn esusu ni bebe Odo Naili ti ó sì tipa bẹẹ bọ lọwọ ipakupa awọn ọmọ-ọwọ ti ó jẹ ọkunrin ọmọ Isirẹli gẹgẹ bi a ti paṣẹ lati ọwọ Farao ti Ijibiti. Gẹgẹ bi ọmọde kekere kan, Jesu pẹlu bọ́ lọwọ ipakupa awọn ọmọkunrin ti wọn dagba tó ọdun meji ni Betilẹhẹmu ati ni awọn agbegbe rẹ̀. Ipakupa yii ni a paṣẹ rẹ̀ lati ọdọ Ọba Hẹrọdu Nla naa, ẹni ti, gẹgẹ bii Farao, ó jẹ ọta Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ̀.—Ẹkisodu 1:22–2:10; Matiu 2:13-18.
Ẹmi ọkantutu, tabi iwatutu, ni Mose ati Jesu fihan. Bi o tilẹ jẹ pe a tọ ọ dagba gẹgẹ bi ọmọkunrin kan ni agbo ile ọba Ijibiti alagbara kan, Mose wa di ẹni ti “ó jẹ́ oniwatutu julọ ninu gbogbo eniyan ti nbẹ lori ilẹ.” (Numeri 12:3, NW) Ni ọna afiwera, Jesu ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi Maikẹli ọmọ alade alagbara ni ọrun ṣugbọn oun fi irẹlẹ wa si ilẹ-aye. (Daniẹli 10:13; Filipi 2:5-8) Siwaju sii, Jesu ni ibakẹdun fun awọn eniyan oun sì lè wi pe: “Ẹ gba ajaga mi si ọrun yin ki ẹ sì kọ ẹkọ lọdọ mi, nitori ọlọkantutu ati ẹni rirẹlẹ ni ọkan-aya ni emi, ẹyin yoo sì ri itura fun ọkan yin.”—Matiu 11:29, NW; 14:14.
Nititori iṣẹ-isin Jehofa, Mose ati Jesu fi awọn ipo olokiki ati ọrọ̀ nla silẹ. Lati sin Jehofa ati awọn eniyan Rẹ̀, Mose fi ọrọ̀ ati ibi onipo iyì kan ni Ijibiti silẹ. (Heberu 11:24-26) Lọna kan naa, Jesu fi ipo olojurere lọna titobi ati ọrọ̀ ni ọrun silẹ ki ó baa lè sin Ọlọrun ati awọn eniyan Rẹ̀ lori ilẹ-aye.—2 Kọrinti 8:9.
Mose ati Jesu di ẹni ami ororo ti Ọlọrun. Wolii naa Mose sin gẹgẹ bi ẹni ami ororo ti Jehofa fun orilẹ-ede Isirẹli. Gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti sọ, Mose “ka ẹgan [jijẹ] Kristi [ẹni ami ororo] si ọrọ̀ titobi ju awọn iṣura Ijibiti lọ.” (Heberu 11:26, NW; Ẹkisodu 3:1–4:17) Igba wo ni Jesu di Kristi, tabi Ẹni ami ororo? Eyi ṣẹlẹ nigba ti a yan an pẹlu ẹmi mimọ tabi ipa agbekankanṣiṣẹ Ọlọrun, nigba ti a bamtisi rẹ̀ tan. Sí obinrin ara Samaria ni idi kanga Jakọbu ni Sikari ati niwaju olori alufaa Isirẹli nigba iwadii ẹjọ rẹ̀, Jesu jẹrii sii pe oun ni Mesaya naa, tabi Kristi.—Maaku 14:61, 62; Johanu 4:25, 26.
Awọn mejeeji Mose ati Jesu gbaawẹ fun 40 ọjọ. Ni ibẹrẹ igbesi-aye rẹ̀ gẹgẹ bi agbẹnusọ fun Ọlọrun, Mose gbaawẹ fun 40 ọjọ nigba ti ó wà lori oke nla Sinai. (Ẹkisodu 34:28) Jesu gbaawẹ fun 40 ọjọ ni aginju ati lẹhin naa ó dena idanwo Satani ni ibẹrẹ iṣẹ igbesi-aye rẹ̀ gẹgẹ bii Mesaya ti a ṣeleri naa.—Matiu 4:1-11.
Awọn Ọkunrin Mejeeji Ṣe Jehofa Logo
Jehofa lo awọn mejeeji Mose ati Jesu lati gbe orukọ mimọ Rẹ̀ ga. Ọlọrun wi fun Mose pe ki ó lọ si ọdọ awọn ọmọ Isirẹli ni orukọ ‘Jehofa Ọlọrun awọn babanla wọn.’ (Ẹkisodu 3:13-16) Mose ṣoju fun Ọlọrun niwaju Farao, ẹni ti a jẹ ki ó walaaye ki agbara Jehofa ba lè di eyi ti a fihan ki a sì polongo orukọ Rẹ̀ ni gbogbo aye. (Ẹkisodu 9:16) Jesu bakan naa wá ni orukọ Jehofa. Fun apẹẹrẹ, Kristi wi pe: “Emi ti wa ni orukọ Baba mi, ṣugbọn ẹyin kò gbà mi.” (Johanu 5:43, NW) Jesu ṣe Baba rẹ̀ logo, ó fi orukọ Jehofa han fun awọn eniyan ti Ọlọrun fifun un, ó sì mu ki ó di mímọ̀ daradara ni ori ilẹ-aye.—Johanu 17:4, 6, 26.
Nipa agbara atọrunwa, awọn mejeeji Mose ati Jesu ṣe awọn iṣẹ iyanu ti o ṣe Ọlọrun logo. Mose ṣe awọn iṣẹ iyanu lati fihan wi pe Jehofa Ọlọrun ni ó ran oun níṣẹ́. (Ẹkisodu 4:1-31) Jalẹ iṣẹ igbesi-aye rẹ̀, Mose, ẹni ti Ọlọrun lo lati pin Okun Pupa si meji, tẹsiwaju lati ṣe awọn iṣẹ iyanu ti o ṣe Jehofa logo. (Ẹkisodu 5:1-12:36; 14:21-31; 16:11-18; 17:5-7; Saamu 78:12-54) Lọna ti ó jọra, Jesu mu ogo wa fun Ọlọrun nipa ṣiṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu. Ọrọ naa ri bẹẹ pupọ ti Jesu fi lè wi pe: “Ẹ gba mi gbọ pe emi wà ni irẹpọ pẹlu Baba ati pe Baba naa wa ni irẹpọ pẹlu mi; bi bẹẹ kọ, ẹ gbagbọ nititori awọn iṣẹ naa tikaraawọn.” (Johanu 14:11, NW) Lara awọn iṣẹ iyanu rẹ̀ ni ti mimu ki ìjì lile kan rọlẹ̀, ti Okun Galili fi di eyi ti ó parọrọ.—Maaku 4:35-41; Luuku 7:18-23.
Awọn Ifarajọra Pataki Miiran
Awọn mejeeji Mose ati Jesu ni a sopọ mọ ipese ounjẹ lọna iyanu. Mose ni ó jẹ́ wolii Jehofa nigba ti a pese ounjẹ lọna iyanu fun awọn ọmọ Isirẹli. (Ẹkisodu 16:11-36) Lọna ti ó jọra, ni ìgbà meji ninu akọsilẹ Bibeli, Jesu bọ́ ọgọọrọ awọn eniyan lọna iyanu pẹlu ounjẹ ti ara.—Matiu 14:14-21; 15:32-38.
Mana lati ọrun wá ni a sopọ pẹlu iṣẹ-isin awọn mejeeji Mose ati Jesu. Mose ni ó ndari awọn ọmọ Isirẹli nigba ti a pese Mana fun wọn lati ọrun wá, ki a sọọ lọna bẹẹ. (Ẹkisodu 16:11-27; Numeri 11:4-9; Saamu 78:25) Ni ọna ti ó ṣee fiwera, ṣugbọn ti ó ṣe pataki gidigidi kan, Jesu pese araarẹ gẹgẹ bi mana lati ọrun wá fun iwalaaye awọn eniyan onigbọran.—Johanu 6:48-51.
Awọn mejeeji Mose ati Jesu ṣe amọna awọn eniyan kuro ni igbekun sinu ominira. Mose ni Ọlọrun lo lati ṣe amọna awọn ọmọ Isirẹli kuro ni igbekun lọwọ awọn ọmọ Ijibiti ati sinu ominira gẹgẹ bi awọn eniyan Rẹ̀. (Ẹkisodu 12:37-42) Lọna ti o jọra, Jesu Kristi ni o ti nṣamọna awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sinu ominira. Kristi yoo ṣamọna awọn eniyan onigbọran lẹẹkansii sinu ominira kuro ninu igbekun fun eto Satani Eṣu, ati bakan naa kuro ninu ẹṣẹ ati iku.—1 Kọrinti 15:24-26; Kolose 1:13; 1 Johanu 5:19.
Awọn mejeeji Mose ati Jesu ṣalarina awọn majẹmu. Mose ni alarina majẹmu Ofin, laaarin Jehofa Ọlọrun ati awọn ọmọ Isirẹli. (Ẹkisodu 19:3-9) Jesu ni Alarina fun majẹmu titun naa, laaarin Ọlọrun ati Isirẹli ti ẹmi.—Jeremaya 31:31-34; Luuku 22:20; Heberu 8:6-13.
Didajọ ni a fà le awọn mejeeji Mose ati Jesu Kristi lọwọ. Mose ṣiṣẹsin gẹgẹ bi onidaajọ ati olufunni ni ofin fun awọn Isirẹli nipa ti ara. (Ẹkisodu 18:13; Malaki 4:4) Jesu sìn gẹgẹ bi Onidaajọ oun sì ti fun “Isirẹli Ọlọrun” ti ẹmi ni awọn ofin ati aṣẹ rẹ̀. (Galatia 6:16; Johanu 15:10) Kristi funraarẹ wi pe: “Baba kò ṣedajọ ẹnikẹni rara, ṣugbọn o ti fi gbogbo ṣiṣe idajọ lé Ọmọkunrin lọwọ, ki gbogbo eniyan lè maa bọla fun Ọmọkunrin gan-an bi wọn ṣe nbọla fun Baba. Ẹni ti kò ba bọla fun Ọmọkunrin ko bọla fun Baba ti ó ran an.”—Johanu 5:22, 23, NW.
Awọn mejeeji Mose ati Jesu ni a fa ipo jijẹ olori ile Ọlọrun lé lọwọ. Mose jẹ oloootọ gẹgẹ bi olori ile Ọlọrun ni Isirẹli igbaani. (Numeri 12:7) Lọna ti o ṣee fiwera, Jesu ni a fi ṣe Olori ile ẹmi awọn ọmọkunrin Jehofa ti oun sì ti jẹ́ oluṣotitọ lori rẹ̀. Niti tootọ, Jesu “jẹ oloootọ si Ẹni naa ti ó yàn án bẹẹ, bi Mose pẹlu ti jẹ ninu gbogbo ile Ẹni yẹn. Nitori ti a ka eyi ekeji ti ó kẹhin yii ni yiyẹ fun ogo pupọ ju Mose lọ, niwọn bi ẹni ti ó kọle ti ni ọla pupọ ju ile naa lọ. . . . Mose gẹgẹ bi iranṣẹ onitọọju jẹ́ oloootọ ninu gbogbo ile Ẹni yẹn bi ẹ̀rí awọn ohun ti a o sọ lẹhin naa, ṣugbọn Kristi jẹ́ oloootọ gẹgẹ bi Ọmọkunrin lori ile Ẹni yẹn. Awa jẹ́ ile Ẹni yẹn, bi a bá di ominira ọrọ sisọ wa ati iṣogo wa lori ireti naa mu ṣinṣin titi de opin.”—Heberu 3:2-6, NW.
Ani niti iku, Mose ati Jesu ri bakan naa. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? O dara, Jehofa gbe oku Mose kuro, ni titipa bayii ṣediwọ fun awọn eniyan yala lati maṣe le sọ ọ dibajẹ tabi sọ ọ di oriṣa. (Deutaronomi 34:5, 6; Juuda 9) Ni ọna ti ó jọra, Ọlọrun palẹ oku Jesu mọ, oun kò si gba a laaye lati ri idibajẹ ti o sì tipa bayii ṣediwọ fun jijẹ ki o di okuta idigbolu si igbagbọ.—Saamu 16:10; Iṣe 2:29-31; 1 Kọrinti 15:50.
Fiyesi Isọtẹlẹ
Iwọnyi wà lara awọn ọna ti Jesu Kristi gba fi ẹ̀rí han pe oun jẹ́ wolii kan bii Mose. Bawo ni awọn ọrọ Ọlọrun si Mose niti wíwá wolii yẹn ti ni imuṣẹ lọna agbayanu tó!
Ko si ibeere kankan nipa pe Jehofa mu ileri alasọtẹlẹ rẹ̀ ṣẹ lati gbe wolii kan bii Mose dide. Awọn ọrọ Deutaronomi 18:18 ni a muṣẹ ninu igbesi-aye ati awọn iriri Jesu Kristi. Iru awọn imuṣẹ bẹẹ sì fun wa ni idi lati ni igbẹkẹle ninu awọn apa alasọtẹlẹ miiran ti Ọrọ Ọlọrun. Nitori naa, ẹ jẹ ki a maa fi iyè si asọtẹlẹ Bibeli ni gbogbo ìgbà.