Ki Ni Iwe Mímọ́ Sọ Nipa “Ipo Jíjẹ́ Ọlọrun Kristi”?
JESU KRISTI ti ní ipa jijinlẹ onisin lori araye. Eyi jẹ́ bẹẹ nitori pe araadọta-ọkẹ jẹwọ jijẹ ọmọlẹhin rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, kii ṣe gbogbo wọn ni wọn fohunṣọkan lori ohun ti o jẹ́.
Awọn kan tí wọn sọ pe awọn tẹwọgba awọn ikọnilẹkọọ Jesu kà á si Ọmọkunrin Ọlọrun, kii ṣe gẹgẹ bi Ẹlẹdaa funraarẹ. Awọn miiran gbagbọ ninu “ipo jíjẹ́ ọlọrun Kristi” wọn sì ronu pe oun ni Ọlọrun niti gidi. Wọn gbagbọ pe Jesu ti fi igba gbogbo wà ó sì ju eniyan lasan lọ nigba ti ó wà nihin-in lori ilẹ-aye. Wọn ha tọna nipa eyi bi? Ki ni Iwe Mímọ́ sọ?
Wíwà Jesu Ṣaaju Dídi Eniyan
Jesu jẹrii sii pe oun ní iwalaaye ṣaaju dídi eniyan. Ó wi pe: “Kò sì sí ẹni ti o goke re ọrun, bikoṣe ẹni ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ eniyan ti ń bẹ ni ọrun.” (Johanu 3:13) Jesu tun sọ pe: “Emi ni ounjẹ ìyè nì tí ó ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu ounjẹ yii, yoo yè titi laelae: ounjẹ naa ti emi o sì fifunni ni araami, fun ìyè araye.”—Johanu 6:51.
Pe Jesu wà laaye ṣaaju wíwá sí ilẹ-aye ni o ṣe kedere lati inu awọn ọrọ rẹ̀: “Ki Aburahamu to wà, emi niyii.” (Johanu 8:58) Aburahamu gbé lati 2018 si 1843 B.C.E., nigba ti ó jẹ́ pe iwalaaye eniyan Jesu bẹrẹ lati 2 B.C.E. si 33 C.E. Kété ṣaaju iku rẹ̀, Jesu gbadura pe: “Baba, ṣe mi logo pẹlu araarẹ, ogo ti mo ti ni pẹlu rẹ ki ayé ki o to wà.”—Johanu 17:5.
Awọn ọmọlẹhin Jesu funni ni ẹ̀rí ti o farajọ ọ. Apọsiteli Johanu kọwe pe: “Ni atetekọṣe Ọrọ wà, Ọrọ naa sì wà pẹlu Ọlọrun, Ọrọ naa sì jẹ́ ọlọrun kan. Nipasẹ rẹ̀ ni ohun gbogbo wà, ani laisi i kò si ohun kan ti ó wà. . . . Bẹẹ ni Ọrọ naa di ara ó sì ba wa gbé, a sì rí ogo rẹ̀, ogo ti ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo lati ọdọ baba kan wá; ó sì kun fun inurere ailẹtọọsi ati otitọ.” (Johanu 1:1, 3, 14, NW) Bẹẹni, “Ọrọ naa di ara” gẹgẹ bi ọkunrin naa Jesu Kristi.
Ni sisọrọ bá iwalaaye Jesu ṣaaju dídi eniyan, apọsiteli Pọọlu kọwe pe: “Ẹ pa ironu ero-inu yii mọ́ ninu yin eyi ti ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu, ẹni ti, bi o tilẹ wà ni aworan Ọlọrun, kò fi ìṣàrò kankan fun ìjá-nǹkan-gbà, eyiini ni, pe oun nilati bá Ọlọrun dọgba. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó sọ araarẹ dòfo ó sì mú irisi ẹrú, ó sì wá wà ní jíjọ awọn eniyan.” (Filipi 2:5-7, NW) Pọọlu pe Jesu ni “àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá: nitori ninu rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo.”—Kolose 1:13-16.
Kii ṣe Ọlọrun Lori Ilẹ-Aye
Iwe Mímọ́ mu un ṣe kedere pe Jesu jẹ́ eniyan patapata lati ìgbà ìbí rẹ̀ titi di ìgbà iku rẹ̀. Johanu kò sọ pe Ọrọ naa ni a fi ẹran ara eniyan bò. Ó “di ara” kii sìí ṣe apakan ẹran ara ati apakan Ọlọrun. Bi Jesu bá ti jẹ́ eniyan ati ọlọrun nigba kan naa, a kò bá tí sọ pe a ti ‘dá a rẹlẹ diẹ ju awọn angẹli lọ.—Heberu 2:9; Saamu 8:4, 5.
Bi Jesu bá ti jẹ́ Ọlọrun ati eniyan lapapọ nigba ti ó wà lori ilẹ-aye, eeṣe ti o fi gbadura si Jehofa leralera? Pọọlu kọwe pe: “Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹbẹ lọdọ ẹni ti ó lè gbà á silẹ lọwọ ikú, a sì gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ̀ rẹ̀.”—Heberu 5:7.
Pe Jesu kii ṣe ẹmi lapakan nigba ti ó wà lori ilẹ-aye ni a fi ẹ̀rí hàn nipa gbolohun ọrọ Peteru pe Kristi ni ‘a pa ninu ara, ṣugbọn . . . a sọ ọ́ di aaye ninu ẹmi.’ (1 Peteru 3:18) Kiki nitori pe Jesu jẹ eniyan patapata ni ó fi lè niriiri ohun ti awọn eniyan alaipe ń niriiri ti ó sì tipa bayii di olori alufaa abanikẹdun. Pọọlu kọwe pe: “A kò ni olori alufaa ti kò lè ṣai bani kẹdun ninu ailera wa, ṣugbọn ẹni ti a ti danwo ni ọna gbogbo gẹgẹ bi awa, ṣugbọn ó yege.”—Heberu 4:15.
Gẹgẹ bi “Ọdọ-Agutan Ọlọrun, ẹni ti ó kó ẹṣẹ ayé lọ,” Jesu “ṣe irapada fun gbogbo eniyan.” (Johanu 1:29; 1 Timoti 2:6) Ni ọna yẹn, Jesu ra ohun naa gan-an ti Adamu ti sọnu pada—iwalaaye eniyan pípé, ti ó jẹ́ ayeraye. Niwọn bi idajọ-ododo Ọlọrun ti beere fun ‘ẹmi fun ẹmi,’ Jesu nipa bayii nilati jẹ́ ohun ti Adamu jẹ́ ni ipilẹṣẹ—ẹ̀dá eniyan pípé, kii ṣe Ọlọrun-oun-eniyan.—Deutaronomi 19:21; 1 Kọrinti 15:22.
Maṣe Fa Itumọ Ti A Kò Nilọkan Yọ Ninu Awọn Ọrọ-Ẹsẹ Bibeli
Awọn wọnni ti wọn ń sọ pe Jesu jẹ́ Ọlọrun-oun-eniyan ń lo oniruuru ẹsẹ iwe mímọ́ ninu isapa lati fihan pe ó jẹ́ mẹmba kan ti Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu, ti ó baradọgba ninu irisi, agbara, ogo, ati ní pípe. Ṣugbọn nigba ti a ba ṣayẹwo awọn ọrọ ẹsẹ iwe mímọ́ wọnyi tiṣọratiṣọra, a ri pe awọn wọnni ti wọn ń jiyan fun “ipo jíjẹ́ ọlọrun Kristi” ka awọn ẹsẹ wọnyi gẹgẹ bi eyi ti ń sọ ju bi wọn ti sọ lọ.
Awọn kan sọ pe awọn ọrọ ẹsẹ Bibeli ninu eyi ti Ọlọrun ti lo ọrọ arọpo orukọ naa “wa” sọ wíwà ṣaaju dídi eniyan Jesu (Ọrọ naa) di ọgba pẹlu Jehofa. Ṣugbọn ìlò ọrọ arọpo orukọ yii kò tumọ si pe Ọlọrun ń ba ojúgbà kan sọrọ. Pátápinrá ó tumọsi pe laaarin awọn ẹ̀dá Ọlọrun, ọ̀kan wà ni ipo ti a yànláàyò ju ni ibatan si Ọlọrun. Niti gidi, Jesu ti ó ti wà ṣaaju ki ó to di eniyan jẹ́ alabaakẹgbẹ timọtimọ Ọlọrun, Ọga Oṣiṣẹ, ati Agbọrọsọ.—Jẹnẹsisi 1:26; 11:7; Owe 8:30, 31, NW; Johanu 1:3.
Awọn ipo ti ó yi iribọmi Jesu ká kò damọran pe Ọlọrun, Kristi, ati ẹmi mímọ́ jẹ́ ọgba papọ. Gẹgẹ bi eniyan kan, Jesu ṣe iribọmi ni iṣapẹẹrẹ ti mimu araarẹ wá siwaju fun Baba rẹ̀ ọrun. Ni akoko yẹn “ọrun ṣí silẹ,” ẹmi Ọlọrun sì sọkalẹ, ni wíwá sori Jesu bi àdàbà kan. Pẹlupẹlu, “lati ọrun,” ohùn Jehofa ni a gbọ ti ó sọ pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni ti mo ti tẹwọgba.”—Matiu 3:13-17, NW.
Wayi o, nigba naa, ki ni Jesu ni lọkan nigba ti o sọ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati ṣe iribọmi fun awọn ọmọ-ẹhin “ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mímọ́”? (Matiu 28:19, 20) Jesu kò nii lọkan tabi sọ pe oun, Baba oun, ati ẹmi mímọ́ jẹ́ ọgba papọ. Kaka bẹẹ, awọn wọnni ti a bamtisi mọ Jehofa gẹgẹ bi Olùfúnni-ní-Ìyè ati Ọlọrun Olodumare, ẹni ti wọn ya igbesi-aye wọn si mímọ́ fun. Wọn gba Jesu gẹgẹ bii Mesaya ati ẹni naa nipasẹ ẹni ti Ọlọrun pese irapada fun araye onigbagbọ. Wọn sì mọ pe ẹmi mímọ́ jẹ́ ipá agbekankanṣiṣẹ Ọlọrun, eyi ti wọn gbọdọ juwọsilẹ fun. Bi o ti wu ki o ri, iru awọn olùnàgà fun anfaani iribọmi bẹẹ ni kò nilati wo Jehofa, Jesu, ati ẹmi mímọ́ gẹgẹ bi ọlọrun àjọ́sìnfún ti Mẹtalọkan.
Ṣugbọn ǹjẹ́ awọn iṣẹ iyanu Jesu kò ha fihan pe oun jẹ́ Ọlọrun-oun-eniyan bi? Bẹẹkọ, nitori Mose, Elija, Eliṣa, awọn apọsiteli Peteru ati Pọọlu, ati awọn miiran ṣe iṣẹ iyanu lai jẹ Ọlọrun-oun-eniyan. (Ẹkisodu 14:15-31; 1 Ọba 18:18-40; 2 Ọba 4:17-37; Iṣe 9:36-42; 19:11, 12) Bíi tiwọn, Jesu jẹ́ eniyan kan ti ó ṣe awọn iṣẹ iyanu pẹlu agbara ti Ọlọrun fifun un.—Luuku 11:14-19.
Aisaya tọka si Jesu Mesaya naa lọna alasọtẹlẹ gẹgẹ bi “Ọlọrun Alagbara.” (Aisaya 9:6) Ni Aisaya 10:21, wolii kan naa sọrọ nipa Jehofa gẹgẹ bi “Ọlọrun alagbara.” Awọn kan gbiyanju lati lo ifarajọra awọn ọrọ yii lati fihan pe Jesu ni Ọlọrun. Ṣugbọn a nilati ṣọra nipa fifa itumọ ti Bibeli kò ni lọkan yọ ninu awọn ẹsẹ iwe wọnyi. Ọrọ Heberu naa ti a tumọsi “Ọlọrun Alagbara” ni a kò fimọ sọdọ Jehofa nikan gẹgẹ bi ọrọ naa “Ọlọrun Olodumare.” (Jẹnẹsisi 17:1) Ki a gbà bẹẹ, iyatọ wa laaarin jíjẹ́ alagbara ati jíjẹ́ olodumare, ti kò ni ajulọ.
Gẹgẹ bi Aisaya 43:10 ti wi, Jehofa wi pe: “A kò mọ Ọlọrun kan ṣaaju mi, bẹẹ ni ọ̀kan ki yoo sì hù lẹhin mi.” Ṣugbọn awọn ọrọ wọnni kò fihan pe Jesu jẹ́ Ọlọrun. Koko naa ni pe Jehofa kò ni aṣaaju, pe ọlọrun kankan kò wà ṣaaju rẹ̀, nitori oun jẹ́ ayeraye. Kò ni sí ọlọrun kankan lẹhin Jehofa nitori pe oun yoo maa wà nigba gbogbo kò sì ni ní awọn agbapò kankan gẹgẹ bi Ọba-Alaṣẹ Gigajulọ. Sibẹ, Jehofa mu awọn miiran ti oun funraarẹ pe ni ọlọrun jade, gẹgẹ bi Iwe Mímọ́ ti fihan nipa sisọ nipa awọn eniyan kan pe: “Emi ti wi pe, ọlọrun ni ẹyin; awọn ọmọ Ọga-ogo sì ni gbogbo yin. Ṣugbọn ẹyin ó kú bi eniyan, ẹyin ó sì ṣubu bi ọ̀kan ninu awọn ọmọ-alade.” (Saamu 82:6, 7) Lọna ti ó farajọra, Ọrọ naa jẹ́ ọlọrun kan ti Jehofa dá, ṣugbọn iyẹn kò sọ Jesu di ọgba pẹlu Ọlọrun Olodumare ni ìgbà kankan.
Ipo Tootọ Ti Jesu
Awọn wọnni ti wọn sọ pe Ọlọrun gbé iwalaaye eniyan wọ̀ gẹgẹ bi Ọlọrun-oun-eniyan nilati kiyesi pe Bibeli kò tilẹ fi tonileti pe Jesu foju wo araarẹ ni ọna yẹn. Kaka bẹẹ, ó fi iṣọkandelẹ fihan pe Jesu ti jẹ́ ẹni tí ó kere si Baba rẹ̀ nigba gbogbo. Nigba ti ó wà lori ilẹ-aye, Jesu kò sọ ju pe oun jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun. Ju bẹẹ lọ, Kristi wi pe: “Baba mi tobi ju mi lọ.”—Johanu 14:28.
Pọọlu fi iyatọ ti ó wà laaarin Jehofa ati Jesu han ni wiwi pe: “Fun awa Ọlọrun kan ni ń bẹ, Baba, lọwọ ẹni ti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹni ti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹni ti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.” (1 Kọrinti 8:6) Pọọlu tun sọ pe: “Ẹyin sì ni ti Kristi; Kristi sì ni ti Ọlọrun.” (1 Kọrinti 3:23) Nitootọ, ani bi awọn Kristẹni ti jẹ́ ti Jesu Kristi, Ọga wọn, bẹẹ ni oun jẹ́ ti Ori rẹ̀, Jehofa Ọlọrun.
Ni sisọ koko ti ó farajọ eyi, Pọọlu kọwe pe: “Kristi ni ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin sì ni ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi sì ni Ọlọrun.” (1 Kọrinti 11:3) Ipo ibatan yii laaarin Ọlọrun ati Kristi yoo maa baa lọ, nitori pe lẹhin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun Jesu, ‘oun yoo fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba’ “a o fi Ọmọ tikaraarẹ pẹlu sabẹ ẹni ti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o lè jasi ohun gbogbo ni ohun gbogbo.”—1 Kọrinti 15:24, 28; Iṣipaya 20:6.
Wíwo Awọn Ẹsẹ Iwe Mimọ Miiran
Nipa ìbí Jesu, Matiu kọwe pe: “Gbogbo eyi sì ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá ni ẹnu wolii [ni Aisaya 7:14] ki o lè ṣẹ, pe, kiyesi i, wundia kan yoo loyun, yoo sì bí ọmọkunrin kan, wọn ó maa pe orukọ rẹ̀ ni Imanuẹli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.” (Matiu 1:22, 23) Jesu ni a kò fun ni orukọ ara-ẹni naa Imanuẹli, ṣugbọn ipa ti ó kó gẹgẹ bi eniyan mu itumọ rẹ̀ ṣẹ. Wíwàníhìn-ín Jesu lori ilẹ-aye gẹgẹ bi Iru-Ọmọ ti Mesaya naa ati Ajogun fun ìtẹ́ Dafidi fihan fun awọn olujọsin Jehofa pe Ọlọrun wà pẹlu wọn, lẹgbẹẹ ọdọ wọn, ni títì wọn lẹhin ninu ìdáwọ́lé wọn.—Jẹnẹsisi 28:15; Ẹkisodu 3:11, 12; Joṣua 1:5, 9; Saamu 46:5-7; Jeremaya 1:19.
Ni bíba Jesu ti a ti jí dide naa sọrọ, apọsiteli Tọmasi polongo pe: “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!” (Johanu 20:28) Eyi ati awọn akọsilẹ iṣẹlẹ miiran ni a “kọ, ki [awa] ki o lè gbagbọ pe, Jesu ni iṣe Kristi naa, Ọmọ [Ọmọkunrin,” NW] Ọlọrun.” Kìí sìí ṣe pe Tọmasi ń tako Jesu, ẹni ti ó ti rán awọn ọmọ-ẹhin Rẹ̀ ni ìhìn-iṣẹ́ naa pe: “Emi ń goke lọ sọdọ . . . Ọlọrun mi, ati Ọlọrun yin.” (Johanu 20:17, 30, 31) Nitori naa Tomasi kò ronu pe Jesu ni Ọlọrun Olodumare. Tomasi lè ti pe Jesu ni “Ọlọrun mi” ni itumọ jíjẹ́ ti Kristi jẹ́ “ọlọrun kan,” bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe “Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa.” (Johanu 1:1; 17:1-3, NW) Tabi nipa sisọ pe “Ọlọrun mi,” Tomasi lè ti maa jẹwọ Jesu gẹgẹ bi Agbẹnusọ ati Aṣoju Ọlọrun, ani bi awọn miiran ti pe angẹli ajíṣẹ́ kan gẹgẹ bi ẹni pe oun ni Jehofa.—Fiwe Jẹnẹsisi 18:1-5, 22-33; 31:11-13; 32:24-30; Onidaajọ 2:1-5; 6:11-15; 13:20-22.
Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, nigba naa, Jesu ní iwalaaye ṣaaju ki o to di eniyan gẹgẹ bi Ọrọ naa. Nigba ti ó wà lori ilẹ-aye, oun kii ṣe Ọlọrun-oun-eniyan atọrunwa. Oun jẹ́ eniyan patapata, bi o tilẹ jẹ́ pe ó pé, gẹgẹ bi Adamu ti jẹ́ ni ipilẹṣẹ. Lati ìgbà ajinde Jesu, oun ti jẹ́ ẹmi ti kò lè kú ti a gbéga ti o wà labẹ Ọlọrun nigba gbogbo. Nitori naa, ni kedere, Iwe Mímọ́ kò ti ero “ipo jíjẹ́ Ọlọrun Kristi” lẹhin.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn Angẹli Ha Jọsin Jesu Bi?
AWỌN itumọ Heberu 1:6 kan sọ pe: “Jẹ ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun un [Jesu].” (King James Version; The Jerusalem Bible [Gẹẹsi]) Apọsiteli Pọọlu jọ bi pe ó ṣayọlo Bibeli Septuagint, eyi ti ó sọ ni Saamu 97:7 pe: “Ẹ jọsin Rẹ̀ [Ọlọrun] gbogbo ẹyin angẹli rẹ̀.”—C. Thomson.
Ọrọ Giriiki naa pro·sky·neʹo ti a tumọsi “jọsin” ni Heberu 1:6 ni a lò ni Saamu 97:7 ninu Bibeli Septuagint fun ede isọrọ Heberu kan, sha·chahʹ ti o tumọ si “lati foribalẹ.” Eyi lè jẹ ọ̀nà ibọwọ fun awọn eniyan ti a tẹwọgba. (Jẹnẹsisi 23:7; 1 Samuẹli 24:8; 2 Ọba 2:15) Tabi o lè jẹmọ́ ijọsin Ọlọrun otitọ tabi ọ̀kan ti a fi aitọna dari sọdọ awọn ọlọrun èké.—Ẹkisodu 23:24; 24:1; 34:14; Deutaronomi 8:19.
Nigba gbogbo pro·sky·neʹo ti a fifun Jesu baradọgba pẹlu itẹriba fun awọn ọba ati awọn miiran. (Fiwe Matiu 2:2, 8; 8:2; 9:18; 15:25; 20:20 pẹlu 1 Samuẹli 25:23, 24; 2 Samuẹli 14:4-7; 1 Ọba 1:16; 2 Ọba 4:36, 37.) Niye igba ó ṣe kedere pe itẹriba ni a fifun Jesu kii ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ṣugbọn gẹgẹ bi “Ọmọkunrin Ọlọrun” tabi “Ọmọkunrin eniyan” ti Mesaya naa.—Matiu 14:32, 33; Luuku 24:50-52; Johanu 9:35, 38.
Heberu 1:6 tanmọ́ ipo Jesu labẹ Ọlọrun. (Filipi 2:9-11) Nihin-in awọn ẹ̀dà itumọ kan tumọ pro·sky·neʹo si “ṣe . . . ìjúbà” (The New English Bible [Gẹẹsi]), “ṣe itẹriba fun” (New World Translation [Gẹẹsi]), tabi “foribalẹ niwaju” (An American Translation [Gẹẹsi]). Bi ẹnikan bá faramọ itumọ naa “jọsin,” iru ijọsin bẹẹ láàlà, nitori Jesu sọ fun Satani pe: “Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọdọ jọsin [iru pro·sky·neʹo], oun nikanṣoṣo ni iwọ gbọdọ ṣe iṣẹ-isin mímọ́ fun.”—Matiu 4:8-10, NW.
Bi o tilẹ jẹ pe Saamu 97:7, eyi ti o sọrọ nipa jijọsin Ọlọrun, ni a fisilo fun Kristi ni Heberu 1:6, Pọọlu ti fihan pe Jesu ti a jí dide ni “itanṣan ogo [Ọlọrun], ati aworan oun tikaraarẹ.” (Heberu 1:1-3) Nitori naa “ijọsin” eyikeyii ti awọn angẹli fifun Ọmọkunrin Ọlọrun jẹ́ aláàlà a si dari rẹ̀ nipasẹ rẹ̀ si Jehofa.