Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
Heberu 9:16 (NW) sọ pe olùdámájẹ̀mú kan gbọdọ kú ki a tó lè fẹsẹ majẹmu kan mulẹ. Ṣugbọn Ọlọrun dá majẹmu titun, kò sì kú. Nitori naa bawo ni a ṣe lè loye ẹsẹ iwe mímọ́ yii?
A kà ni Heberu 9:15-17 (NW) pe: “Nitori naa iyẹn ni idi ti ó [Kristi] fi jẹ́ alárinà majẹmu titun kan, pe, nitori iku kan ti ṣẹlẹ fun itusilẹ wọn nipa irapada kuro ninu awọn irekọja labẹ majẹmu atijọ, ki awọn ti a ti pè lè rí ileri ogún ainipẹkun naa gbà. Nitori nibi ti majẹmu bá wà, ó yẹ ki a pese ikú [eniyan] olùdámájẹ̀mú naa. Nitori majẹmu fẹsẹmulẹ lori oku ohun ẹbọ, niwọn bi kò ti lagbara ni akoko eyikeyii nigba ti [eniyan] adámájẹ̀mú naa walaaye.”a
Jehofa ni ẹni naa gan-an ti o Dá majẹmu titun naa. Ni Jeremaya 31:31-34, Ọlọrun sọtẹlẹ ni pàtó pe oun funra oun yoo dá majẹmu titun naa pẹlu awọn eniyan oun. Apọsiteli Pọọlu ṣayọlo iwe mímọ́ ni Heberu 8:8-13, eyi ti o fihan pe Pọọlu mọriri rẹ̀ pe, ni sisọ ọ ni pọ́ńbélé, Ọlọrun ni o pilẹ majẹmu atọrunwa yii.
Bi o ti wu ki o ri, ni Heberu ori 9, Pọọlu ń baa lọ lati sọrọ lori oniruuru ipa ti Jesu ti kó nipa majẹmu titun naa. Kristi wá gẹgẹ bi Olori Alufaa majẹmu titun yii. Lati inu oju-iwoye miiran, Jesu ni ẹbọ fun majẹmu titun naa; kiki “ẹ̀jẹ̀ Kristi” ni o lè “wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ kuro ninu awọn oku iṣẹ.” Kristi tun ni Alárinà majẹmu yii, ani bi Mose ti jẹ́ alárinà majẹmu Ofin.—Heberu 9:11-15, NW.
Pọọlu mẹnukan an pe iku kan ni a nilo lati fẹsẹ awọn majẹmu mulẹ laaarin Ọlọrun ati eniyan. Majẹmu Ofin jẹ́ apẹẹrẹ kan. Mose ni alárinà rẹ̀, ẹni naa ti yoo mu iṣọkan yii wá laaarin Ọlọrun ati Isirẹli nipa ti ara. Mose tipa bayii kó ipa pataki kan oun sì ni eniyan naa ti o ba awọn ọmọ Isirẹli lò nigba ti wọn ń wá sinu majẹmu naa. Mose ni a lè tipa bayii wò gẹgẹ bi olùdámájẹ̀mú eniyan ti majẹmu Ofin ti o pilẹṣẹ lọdọ Jehofa. Ṣugbọn Mose ha nilati ta ẹ̀jẹ̀ iwalaaye rẹ̀ silẹ fun majẹmu Ofin naa ki o tó wà lẹnu iṣẹ bi? Bẹẹkọ. Kaka bẹẹ awọn ẹran ni a fi rubọ, ẹ̀jẹ̀ wọn dipo ẹ̀jẹ̀ Mose.—Heberu 9:18-22.
Ki ni nipa majẹmu titun laaarin Jehofa ati orilẹ-ede Isirẹli tẹmi? Jesu Kristi ní ipa ologo ti olùṣalárinà, Alárinà naa laaarin Jehofa ati Isirẹli tẹmi. Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa pilẹ majẹmu yii, ó sinmi lori Jesu Kristi. Yatọ si jíjẹ́ Alárinà rẹ̀, Jesu ní awọn ibalo taarata ninu ẹran ara pẹlu awọn wọnni ti a o kọkọ gbà wọnu majẹmu yii. (Luuku 22:20, 28, 29) Ju bẹẹ lọ, ó tootun lati pese ẹbọ ti a nilo lati fẹsẹ majẹmu naa mulẹ. Ẹbọ yii kii wulẹ ṣe ti awọn ẹran ṣugbọn ti iwalaaye eniyan pípé kan. Nitori naa Pọọlu lè tọka si Kristi gẹgẹ bi olùdámájẹ̀mú eniyan ti majẹmu titun. Lẹhin ti “Kristi wọle lọ . . . si ọrun funraarẹ, lati farahan nisinsinyi niwaju Ọlọrun funraarẹ alara fun wa,” majẹmu titun naa di eyi ti o fẹsẹmulẹ.—Heberu 9:12-14, 24.
Ni sisọrọ nipa Mose ati Jesu gẹgẹ bi awọn eniyan olùdámájẹ̀mú, kii ṣe pe Pọọlu ń damọran pe eyikeyii ninu wọn ti pilẹ awọn majẹmu ọtọọtọ naa, eyi ti a dá nipasẹ Ọlọrun nitootọ. Kaka bẹẹ, awọn eniyan mejeeji wọnni lọwọ jinlẹjinlẹ ninu mimu awọn majẹmu kọọkan ṣẹ gẹgẹ bi alárinà. Ati ninu ọran kọọkan, iku kan ni a nilo—awọn ẹran dipo Mose, ti Jesu sì fi ẹ̀jẹ̀ iwalaaye tirẹ̀ rubọ fun awọn wọnni ti wọn wà ninu majẹmu titun.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Awọn ọrọ Giriiki mejeeji ti a lò níhìn-ín fun “olùdámájẹ̀mú naa” ni a tumọ lóréfèé sí “nipa (ẹni) naa ti o ti dá majẹmu fun araarẹ” tabi “nipa (ẹni) naa ti ń dá majẹmu.”—The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ati The Interlinear Greek-English New Testament, lati ọwọ Dokita Alfred Marshall.