Ki Ni Ó Buru Ninu Ife Owó?
PAUL ati Mary ń bojuto ilé ìtajà mú-un-fúnraàrẹ kan ni adugbo ti o tòṣì kan ni Africa.a Nipa ṣiṣiṣẹ kára tọ̀sán tòru, wọn ń rí owó ti ó pọ̀. Bi akoko ti ń lọ Mary lè fi ile titun titobi kan ti awọn ohun ìtolé gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ kún inu rẹ̀ fọ́fọ́ yangàn. Niti Paul, ó ṣeeṣe fun un lati maa gun ọkọ̀ ayọkẹlẹ bọ̀gìnnì kan kiri.
Ni ọjọ kan awujọ kan ti o lodisi ijọba tọ Paul wa. Wọn fi dandan beere pe: “A fẹ́ ki ile-iṣẹ rẹ maa dá [$100] loṣooṣu lati ti ipa-ọna wa lẹhin.” Bi wọn kò ti fẹ lati ṣe itilẹhin ninu ìjàgùdù ti oṣelu, Paul ati Mary fi igboya kọ̀. Nitori iduro alaidasi tọtun-tosi wọn, a fura sí wọn pe wọn ń gba itilẹhin owó lati ọwọ́ ijọba. Ni opin ọsẹ kan, nigba ti Paul ati Mary ti jade lọ sinu igboro, ile-itaja wọn ni a kó lọ, ti a sì dáná sun ọkọ̀ ayọkẹlẹ ati ile wọn mèremère.
Irohin ti ń banininujẹ ni, niti tootọ, ṣugbọn ǹjẹ́ a ha lè kẹkọọ ninu rẹ̀ bi? Ọpọ awọn ti wọn ti ṣiṣẹ kára lati di ọlọ́rọ̀ ni ó ṣeeṣe ki ajalu-ibi kan ti ó jà wọn lólè ọrọ̀ wọn má tíì ya lù, sibẹ ki ni nipa ọjọ-iwaju? Eeṣe ti Bibeli fi sọ pe “awọn ti ń fẹ di ọlọ́rọ̀ a maa bọ sinu idanwo ati idẹkun, ati sinu were ifẹkufẹẹ pipọ tii panilara, iru eyi tii maa ri eniyan sinu iparun ati ègbé”?—1 Timoteu 6:9.
Oju-iwoye Gígúnrégé Nipa Owó
Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, Kristian tootọ kan gbọdọ pese fun awọn aini ti ara ti awọn mẹmba idile rẹ̀ ti wọn gbarale e lọkunrin tabi lobinrin. Awọn ipo ayika, iru bii ainiṣẹlọwọ tabi iṣoro ilera, lè mú ki eyi ṣoro nigba miiran. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Kristian kan ti ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣainaani lati pese fun idile rẹ̀ “ti sẹ́ igbagbọ, ó buru ju alaigbagbọ lọ.”—1 Timoteu 5:8.
Ni awọn adugbo igberiko kan, awọn eniyan daradé iṣẹ àgbẹ̀ lati gbọ́ bukata nipa gbígbin ounjẹ tiwọn funraawọn ati sisin ẹran ọ̀sìn. Awọn kan kò fi bẹẹ nilo owó, bi wọn ti ń ri awọn kòṣeémánìí igbesi-aye gbà nipa ṣiṣe pàṣípààrọ̀ fun ọjà ati iṣẹ ipese. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀nà ti ó wọ́pọ̀ julọ ti awọn ti ń mówówọlé ń gbà pese fun idile wọn ni nipa lilọwọ ninu iru ìgbanisíṣẹ́ kan ni ìsanpadà fun owó-ọ̀yá. Wọn ń lo owó ti ń wọle lati ra ounjẹ ati awọn ohun eelo miiran ti ń fikun ire-alaafia idile wọn. Ni afikun, owó ti a fi ọgbọn tọjupamọ lè pese iwọn aabo kan ni awọn akoko inira tabi ajalu-ibi. Fun apẹẹrẹ, a lè lò ó lati kárí awọn inawo iṣegun tabi lati ṣe awọn atunṣe tí wọn ṣe kókó lara ile ẹni. Idi niyẹn ti Bibeli fi sọ ni gidi tootọ pe: ‘owó jẹ́ ààbò’ ati pe oun “ni idahun ohun gbogbo.”—Oniwasu 7:12; 10:19.
Nitori pe owó ń ṣaṣepari ohun ti o pọ̀ tobẹẹ, ewu ti mímú oju-iwoye ti kìí ṣe otitọ dagba nipa agbara rẹ̀ wà. Kristian kan nilati wà lojufo nipa awọn ààlà rẹ̀ ni ifiwera pẹlu awọn ohun ti o tubọ ṣe pataki miiran. Fun apẹẹrẹ, Bibeli fi iniyelori owó wé ọgbọn oniwa-bi-Ọlọrun, ni sisọ pe: “Ààbò ni ọgbọn, àní bi owó ti jẹ́ ààbò: ṣugbọn èrè ìmọ̀ ni pe, ọgbọn fi ìyè fun awọn ti ó ní i.” (Oniwasu 7:12) Ni ọ̀nà wo ni ọgbọn oniwa-bi-Ọlọrun gbà ni anfaani yii lori owó?
Ẹkọ kan Lati Ìgbà ti Ó Ti Kọja
Awọn iṣẹlẹ ti o wáyé ni Jerusalemu ni ọdun 66 C.E. ṣakawe anfaani ọgbọn oniwa-bi-Ọlọrun lori owó. Lẹhin lílé awọn ọmọ-ogun Romu ti wọn gbógun tì wọn pada sẹhin, awọn Ju ni Jerusalemu lọna ti ó hàn gbangba gbagbọ pe ọjọ-iwaju iṣẹ́-ajé dara nisinsinyi. Nitootọ, wọn bẹrẹ sii ṣe owó tiwọn funraawọn ni ṣiṣajọyọ ominira wọn titun ti wọn ṣẹṣẹ rí. A lẹ òǹtẹ̀ ti ó ni awọn ọ̀rọ̀ èdè Heberu, bii “Fun ominira Sioni” ati “Jerusalemu Mimọ” mọ́ ẹyọ-owó wọn lara. Ni ọdun titun kọọkan, wọn ń ṣe ẹyọ-owó titun ti ó ni ikọwe ti o fi wọn hàn gẹgẹ bii ti “ọdun keji,” “ọdun kẹta,” ati “ọdun kẹrin.” Awọn awalẹpitan tilẹ hú awọn ẹyọ-owó diẹ ti kò fi bẹẹ wọpọ ti o ni ikọwe naa “ọdun karun-un,” eyi ti o dọgba pẹlu ọdun 70 C.E. jade paapaa. Ǹjẹ́ awọn Ju ti wọn jẹ́ Kristian ha ka owó awọn Ju si àmì ominira pipẹtiti kan ti o lẹsẹ nilẹ bi?
Bẹẹkọ. Nitori pe wọn fi awọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọn Ọ̀gá wọn sọkan. Jesu ti sọ asọtẹlẹ ìgbóguntì Romu eyi ti ó wáyé ni 66 C.E. Ó ti fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nimọran pe nigba ti ó ba ṣẹlẹ, wọn nilati ‘fà sẹhin kuro laaarin Jerusalemu.’ (Luku 21:20-22) Ìtàn jẹrii si i pe awọn Ju ti wọn jẹ Kristian ṣe bẹẹ gẹgẹ. Dajudaju wọn muratan lati faragbá àdánù ẹrù, awọn ohun-ìní, ati awọn anfaani iṣẹ-aje nitori fifi Jerusalemu silẹ. Ni ọdun mẹrin lẹhin naa, awọn ọmọ-ogun Romu pada wá wọn sì ṣàga ti ilu naa.
“Ọpọ rẹpẹtẹ goolu wà ninu Ilu-nla naa,” gẹgẹ bi ẹni ti ọ̀ràn ṣoju rẹ̀ kan, opitan Josephus ṣe sọ. Ṣugbọn ọpọ yanturu owó kò lè gba Jerusalemu là kuro lọwọ ìyàn, eyi ti o “tubọ di buburu” ti ó sì “jẹ odindi ile ati idile run” laidawọduro. Awọn olugbe kan gbé ẹyọ-owó goolu mì wọn sì gbiyanju lati sá jade kuro ninu ilu naa. Ṣugbọn a pa wọn lati ọwọ́ awọn ọ̀tá wọn ti wọn fa ikùn wọn ya ki wọn baa lè fa owó naa yọ. “Fun awọn ọlọ́rọ̀,” ni Josephus ṣalaye, “bi ó ṣe léwu tó lati wà ninu Ilu-nla naa ni ó ṣe léwu tó lati fi i silẹ; nitori pe lori àwáwí naa pe wọn jẹ ẹni ti ó sá loju ogun, ọpọ awọn ọkunrin ni a pa nitori owó wọn.”
Ni ohun ti ó dín si oṣu mẹfa lati ibẹrẹ ìṣàgatì naa, Jerusalemu ni a parun, ti iye ti ó ju aadọta-ọkẹ kan ninu awọn olugbe rẹ̀ sì kú nipasẹ ìyàn, ajakalẹ-arun, ati idà. Ifẹ owó ti fọ́ ọpọlọpọ loju, ní rírì wọn sinu iparun ati ègbé, nigba ti ó jẹ́ pe fifi awọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọn silo ti mú ki ó ṣeeṣe fun awọn Ju ti wọn jẹ Kristian lati sá asala.
Iyẹn kìí ṣe ọ̀ràn kanṣoṣo ninu ìtàn nigba ti owó kùnà lati gba awọn eniyan là ni akoko yanpọnyanrin. Ẹ wo ọ̀gá buburu kan ti ifẹ owó lè jẹ́! (Matteu 6:24) Ju bẹẹ lọ, ó tun lè fi ayọ ti isinsinyi dù ọ́.
Awọn Igbadun Ti Owó Kò Lè Rà
Èrò agbanilọ́kàn lati di ọlọ́rọ̀ lè fọ́ ẹnikan loju si ọpọlọpọ igbadun ti kò beere owó gọbọi. Fun apẹẹrẹ, ṣe ayẹwo ayọ ipo-ibatan idile, awọn ọ̀rẹ́ tootọ, awọn iyanu adanida, wíwọ̀ oorun apàfiyèsí kan, ìjì-àrá wíwọnilọ́kàn, oju ọrun ti ó kun fun awọn irawọ, iwa yiyanilẹnu ti awọn ẹranko, tabi awọn òdòdó ati igi ninu awọn igbó-ẹgàn ti a kò tii bajẹ.
Loootọ, awọn eniyan diẹ ti wọn lọ́rọ̀ tubọ ni akoko ti ó pọ lati jẹ awọn igbadun ti a mẹnukan loke yii, ṣugbọn ọpọ julọ ninu wọn ni ọwọ́ wọn dí gan-an ni gbigbiyanju lati pa ọrọ̀ wọn mọ́ tabi mú un gbooro sii. Ó lè yanilẹnu, ṣugbọn, ayọ sábà maa ń fo awọn wọnni ti wọn ni akoko fàájì paapaa ru. Eyi ya awọn oluṣewadii ode-oni lẹnu. “Bawo ni a o ṣe ṣalaye otitọ naa pe ohun kan ti ọpọlọpọ eniyan tobẹẹ ń fẹ́, ti a sì nigbagbọ ninu rẹ̀ gẹgẹ bi iru gbogbo-nì-ṣe kan, nigba ti ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́ nilati ni awọn ipa ti ó yatọsira lati ori jijanikulẹ si didanilaamu?” ni Thomas Wiseman beere ninu iwe rẹ̀ The Money Motive—A Study of an Obsession.
Ohun kan ti ó lè fi ayọ du ọlọ́rọ̀ kan ni iṣoro ti ó wà ninu mímọ awọn ti wọn jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ gidi. Ọlọ́rọ̀ Ọba Solomoni niriiri iyẹn “nigba ti ẹrù bá ń pọ̀ sii, awọn ti o sì ń jẹ ẹ́ a maa pọ̀ sii.” (Oniwasu 5:11) Ọpọ awọn ọlọ́rọ̀ tun ń jiya àníyàn nipa gbigbiyanju lati pa ọrọ̀ wọn mọ́ tabi mú iniyelori rẹ̀ pọ̀ sii. Eyi sábà maa ń fi oorun ti ó gbadunmọni dù wọn. Bibeli ṣalaye pe: “Didun ni oorun oniṣẹ, ìbáà jẹ́ ounjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọ́rọ̀ kìí jẹ́, ki ó sùn.”—Oniwasu 5:12.
Ifẹ owó lè ba ipo-ibatan laaarin idile ati ọ̀rẹ́ jẹ nitori pe ó lè dẹ ẹnikan sinu iwa àbòsí ati iwa-ọdaran. Awọn olufẹ owó sábà maa ń yiju si tẹ́tẹ́ títa. Lọna ti ó banininujẹ, òòfà-ọkàn fun iriri tẹ́tẹ́ títa kanṣoṣo sii maa ń sin ọpọlọpọ wọnú oko gbèsè. “Nigba ti wọn bá fi maa wá sọdọ mi,” ni dokita ọpọlọ ara South Africa kan sọ, “[awọn atatẹ́tẹ́ lápàpàǹdodo] ti sábà maa ń kọja ẹni ti a ń ràn lọwọ mọ, wọn ti padanu awọn iṣẹ, iṣẹ-aje, ile, tí awọn idile wọn sì ti sábà maa ń fi wọn silẹ.” Ikilọ Bibeli ti jẹ́ otitọ tó pe: “Oloootọ eniyan yoo pọ̀ fun ibukun: ṣugbọn ẹni ti o kanju ati là ki yoo ṣe alaijiya.”—Owe 28:20.
‘Ó Hu Ìyẹ́-apá . . . Ó Sì Fò Ni Oju Ọrun’
Idi miiran ti ifẹ owó fi léwu tobẹẹ ni pe awọn ijọba eniyan kò tíì lè fọwọsowọpọ ni kikun tabi rí i daju pe owó ní iniyelori rẹ̀ ti ó wà lojukan jakejado awọn orilẹ-ede; bẹẹ ni kò tíì ṣeeṣe fun wọn lati dá ìfẹ́ri igbokegbodo orọ̀-ajé, ilọsilẹ-iṣẹ-aje, ati ìforíṣọ́npọ́n ọja-iṣura-okowo. Jibiti, olè jíjà, ati ilọsoke owó-ọjà tun nú-ẹnu-mọ́ otitọ awọn ọ̀rọ̀ ti a mísí naa pe: “Maṣe làálàá ati lọ́rọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ. Iwọ o ha fi oju rẹ wò ó? ki yoo sì sí mọ́, nitori ti ọrọ̀ hu ìyẹ́-apá fun ara rẹ̀ bi idì ti ń fò ni oju ọrun.”—Owe 23:4, 5.
Ilọsoke owó-ọjà. Iṣoro yẹn kò mọ si awọn orilẹ-ede otoṣi nikan. Ni ibẹrẹ ọrundun yii, ilọsoke owó-ọjà alaidawọduro kọlu awọn orilẹ-ede ti iṣẹ àfẹ̀rọṣe ti pọ ni aarin gbungbun Europe. Fun apẹẹrẹ, ṣaaju Ogun Agbaye I, ẹyo-owó mark ti Germany jẹ́ nǹkan ti ó dọgba pẹlu ṣílè kan ti ilu Britain, eyọ-owó franc ti awọn Faranse, tabi ẹyọ-owó lira. Ọdun mẹwaa lẹhin naa, ẹyọ-owó ṣílè, franc, tabi lira ti Italy jẹ́ 1,000,000,000,000 ẹyọ-owó mark ni ibara-dọgba lọna kan ṣáá. Ipa wo ni ilọsoke owó-ọjà tí ń ga fíofío ní lori awọn eniyan ti wọn wà ninu awujọ ọlọ́rọ̀? “Bi ohun ti ó ṣẹlẹ si awọn Ilẹ-ọba ti Aarin Gbungbun ti a bori ni ibẹrẹ awọn ọdun 1920 bá nilati jẹ ohun ti a o fi ṣedajọ,” ni Adam Fergusson sọ ninu iwe rẹ̀ When Money Dies, “nigba naa [iwolulẹ owó] tú iru iwọra, iwa-ipa, ailayọ, ati ikoriira bẹẹ silẹ, eyi ti a mú jade ni pataki lati inu ibẹru, bi awujọ kankan kò tilè là á já laifarapa tabi laiyipada.”
Ni 1923, Germany tun iye bù lé owó rẹ̀ nipa gígé awọn òdo 12 kuro debi pe 1,000,000,000,000 ẹyọ-owó mark atijọ wá baradọgba pẹlu ẹyọ-owó mark titun kan. Igbesẹ yii fopin si ilọsoke owó-ọjà ṣugbọn ó ni awọn iyọrisi onijamba miiran. Fergusson ṣalaye pe: “Wíwà deedee owó ti a tun idi rẹ̀ fi mulẹ, eyi ti ó sọ ẹgbẹẹgbẹrun di ajigbèsè, ti o du araadọta-ọkẹ ni ọ̀nà atijẹ wọn, ti ó sì fopin sí ireti araadọta-ọkẹ sii, lọna ti kò ṣe taarata beere fun iye ti ó gadabú ti gbogbo ayé nilati san.” Ó jọbi pe, “iye ti ó gadabú” ti onkọwe naa ní lọ́kàn ni idide eto ijọba Nazi ati Ogun Agbaye II.
Pe akọsilẹ-owo ńláǹlà ní banki ti já ọpọlọpọ kulẹ ni ìgbà atijọ nilati jẹ́ ikilọ amúnigbéjẹ́ẹ́ ni awọn akoko iṣunna-owo alaidaniloju kari-aye wọnyi. Ọmọkunrin Ọlọrun funraarẹ kilọ pe owó yoo kùnà, eyi ti ó ti ri bẹẹ dajudaju ni ọpọ ìgbà. (Luku 16:9) Ṣugbọn ijakulẹ owó ti o ga julọ ti ó sì tankalẹ julọ yoo dé nigba ti Jehofa Ọlọrun bá mú idajọ rẹ̀ ṣẹ lori ayé buburu yii. “Ọrọ̀ kìí ní anfaani ni ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo nii gbani lọwọ iku.”—Owe 11:4.
Ó ti ṣe pataki tó, nigba naa, pe ki ẹnikọọkan wa lakaka lati pa iduro ododo mọ pẹlu awọn Ọ̀rẹ́ wa tootọ, Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi!
Orisun Ayọ Pipẹtiti
Paul ati Mary, ti a mẹnukan ni ibẹrẹ, jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Fun ọpọ ọdun wọn ṣajọpin ninu iṣẹ ajihinrere alakooko kikun. Bi o ti wu ki o ri, ifẹ-ọkan wọn fun ọrọ̀ mú ki wọn dawọ lilọ si awọn ipade ijọ Kristian duro, wọn sì dawọ ṣiṣajọpin igbagbọ wọn ninu iṣẹ-ojiṣẹ gbangba duro. Ṣugbọn wọn tají. “Nisinsinyi mo lè rí i bi o ti jẹ́ alailọgbọn tó lati lo gbogbo akoko ati okun mi lori ohun kan ti ó lè deérú ni iwọnba iṣẹju diẹ,” ni Mary sọ lẹhin ti a ti fipa jà á lólè ti a sì ba ile rẹ̀ jẹ́. Lọna ti ó muni layọ, awọn tọkọtaya yii kọ́ ẹkọ kan ki ó tó di pe ó pẹ́ jù. Bẹẹni, ewu ti ó tobi julọ tí ifẹ owó lè ṣokunfa ni ti fifi ipo-ibatan ṣiṣetẹwọgba pẹlu Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi du ẹnikan. Laisi awọn Ọ̀rẹ́ wọnyi, ireti wo ni a lè ní lati la opin ayé buburu yii já sinu ayé titun ododo ti a ṣeleri?—Matteu 6:19-21, 31-34; 2 Peteru 3:13.
Nitori naa laika yala o ka araarẹ si ọlọ́rọ̀ tabi otoṣi si, ṣọra fun mimu ifẹ owó dagba. Ṣiṣẹ lori rírí ati didi iṣura titobi julọ mú—iduro onitẹẹwọgba pẹlu Jehofa Ọlọrun. Eyi ni iwọ lè ṣe nipa fifi iyè gidigidi si ikesini kanjukanju naa pe: “Ati Ẹmi ati iyawo wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti ó ń gbọ́ ki o wi pe, Maa bọ̀. Ati ẹni ti ongbẹ ń gbẹ ki ó wá. Ẹnikẹni ti ó bá sì fẹ́, ki ó gba omi ìyè naa lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìfihàn 22:17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A kò lo orukọ wọn gidi.
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ẹ̀gbẹ́ mejeeji ẹyọ-owó ti a dà nigba iṣọtẹ awọn Ju ti o ni ikọwe naa “ọdun keji” lara
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.