Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
“Ẹni ti ó bá tọ̀ mí lẹhin . . . yoo ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”—JOHANNU 8:12.
1. Bawo ni ìmọ́lẹ̀ ti ṣe pataki tó?
KI NI awa yoo ṣe laisi ìmọ́lẹ̀? Ronuwoye jíjí ni gbogbo ọjọ ti ó wà ninu ọdun kan si wakati 24 okunkun. Ronuwoye ayé kan laisi àwọ̀, nitori pe laisi ìmọ́lẹ̀ kò sí àwọ̀. Niti gidi, bi kò bá sí ìmọ́lẹ̀, àwa pẹlu kò ní wà! Eeṣe ti a kò fi ni wà? Nitori pe, ninu ọ̀nà-ìgbàṣiṣẹ photosynthesis, awọn ọgbin aláwọ̀-ewé ń lo ìmọ́lẹ̀ lati ṣe ounjẹ ti a ń jẹ—hóró ọkà, ẹ̀fọ́, ati eso. Loootọ, nigba miiran a ń jẹ ẹran awọn ẹranko. Ṣugbọn awọn ẹranko wọnyẹn ń jẹ eweko tabi awọn ẹranko miiran ti wọn ń jẹ eweko. Nipa bayii, igbesi-aye wa nipa ti ara sinmi lori ìmọ́lẹ̀ patapata.
2. Awọn orisun ìmọ́lẹ̀ lilagbara wo ni o wà, ki ni eyi sì sọ fun wa nipa Jehofa?
2 Ìmọ́lẹ̀ wa ń wá lati ara oorun, eyi ti ó jẹ́ irawọ kan. Nigba ti oorun wa ń tan ìwọ̀n ìmọ́lẹ̀ ti o pegede kan, kìkì ìwọ̀n irawọ alabọọde kan ni o jẹ́ sibẹ. Ọpọlọpọ tobi ju bẹẹ lọ fíìfíì. Awujọ awọn irawọ ti a sì ń gbé ninu rẹ̀, iṣupọ irawọ Milky Way, ní ninu ohun ti o ju ọgọrun-un billion irawọ lọ. Ni afikun, ailonka billion iṣupọ irawọ ní ń bẹ ninu gbalasa ofuurufu. Ẹ wo iru itolọwọọwọ irawọ pipegede ti o jẹ́! Ẹ wo iru ìwọ̀n ìmọ́lẹ̀ gigalọla ti ń jade lati inu wọn wá! Ẹ wo iru orisun ìmọ́lẹ̀ lilagbara ti Jehofa, ẹni ti o da gbogbo iyẹn jẹ́! Isaiah 40:26 kede pe: “Ẹ gbe oju yin soke sibi giga, ki ẹ sì wò, ta ni ó dá nǹkan wọnyi, ti ń mu ogun wọn jade wa ni iye: ó ń pe gbogbo wọn ni orukọ nipa titobi ipá rẹ, nitori pe oun le ni ipá; kò sí ọ̀kan ti ó kù.”
Iru Ìmọ́lẹ̀ Miiran
3. Bawo ni ìmọ́lẹ̀ nipa tẹmi lati ọ̀dọ̀ Jehofa ti ṣe pataki tó?
3 Jehofa tún ni Orisun iru ìmọ́lẹ̀ miiran, ọ̀kan ti o mu ki o ṣeeṣe fun wa lati ní iran tẹmi, ìlàlóye tẹmi. Iwe atumọ-ọrọ kan tumọ “làlóye” ni ọ̀nà yii: “Lati pese ìmọ̀ fún: tọsọna; lati fi ìjìnlẹ̀-òye nipa tẹmi fún.” Ó tumọ “ti a làlóye” gẹgẹ bi: “bọ́ lọwọ aimọkan ati ìsọfúnni-òdì.” Ìlàlóye tẹmi lati ọ̀dọ̀ Jehofa ni a ń pese nipasẹ ìmọ̀ pipeye Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Eyi ni ohun ti ó mú ki o ṣeeṣe fun wa lati mọ iru ẹni ti Ọlọrun jẹ́ ati ohun ti awọn ète rẹ̀ jẹ́. “Nitori Ọlọrun, ẹni ti o wi pe ki ìmọ́lẹ̀ ki o mọ́lẹ̀ lati inu okunkun jade, oun ni ó ti ń mọ́lẹ̀ ni ọkàn wa, lati fun wa ni ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun ni oju Jesu Kristi.” (2 Korinti 4:6) Nipa bayii, awọn otitọ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dá wa silẹ lominira kuro ninu aimọkan ati ìsọfúnni-òdì. Jesu sọ pe: “Ẹ ó sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di ominira.”—Johannu 8:32.
4, 5. Bawo ni ìmọ̀ nipa Jehofa ṣe ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ninu igbesi-aye wa?
4 Jehofa, Orisun ìlàlóye tẹmi tootọ, “pé ní ìmọ̀.” (Jobu 37:16) Bakan naa, Orin Dafidi 119:105 kede nipa Ọlọrun pe: “Ọ̀rọ̀ rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi, ati ìmọ́lẹ̀ si ipa-ọna mi.” Nitori naa kìí ṣe kìkì pe ó lè tanmọlẹ nipa tẹmi si igbesẹ ti o kàn ninu igbesi-aye wa nikan ni ṣugbọn ọ̀nà ti o wà niwaju pẹlu. Laisi iyẹn, igbesi-aye yoo dabi wíwa ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan gba ọ̀nà oke-nla kọ́lọkọ̀lọ kan ni alẹ́ ṣiṣokunkun dudu kan laisi iná lara ọkọ̀ ayọkẹlẹ naa tabi nibomiran. Ìmọ́lẹ̀ nipa tẹmi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a lè fiwe ìmọ́lẹ̀ ti iná iwaju ọkọ̀ ayọkẹlẹ ń pese. Ìmọ́lẹ̀ naa ń tàn si gbogbo oju-ọna ki a baa lè ríran ri ibi ti a ń lọ ni taarata gan-an.
5 Asọtẹlẹ ti o wa ninu Isaiah 2:2-5 fihàn pe ni akoko wa Ọlọrun ń ṣakojọ awọn eniyan ti wọn fẹ́ ìlàlóye tẹmi lati inu gbogbo orilẹ-ede ki wọn baa lè kẹkọọ ki wọn sì ṣe ijọsin tootọ. Ẹsẹ 3 sọ pe: “Oun ó sì kọ́ wa ni ọ̀nà rẹ̀, awa ó sì maa rìn ni ipa rẹ̀.” Ẹsẹ 5 kesi awọn olùwá otitọ pe: “Ẹ wá, ẹ jẹ ki a rìn ninu ìmọ́lẹ̀ Oluwa.”
6. Nibo ni ìmọ́lẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Jehofa yoo ṣamọna wa si nigbẹhin-gbẹhin?
6 Nipa bayii, Jehofa ni orisun iru ìmọ́lẹ̀ ṣiṣekoko meji fun iwalaaye: ti ara ati ti ẹmi. Ìmọ́lẹ̀ nipa ti ara ń ran ara ìyára wa lọwọ lati walaaye nisinsinyi, boya fun nǹkan bii 70 tabi 80 ọdun tabi ti ó sunmọ ọn. Ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ nipa tẹmi ń ṣamọna si ìyè ayeraye ninu paradise ilẹ̀-ayé. Ó ri gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ ninu adura si Ọlọrun pe: “Ìyè ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.”—Johannu 17:3.
Ayé Ninu Okunkun Tẹmi
7. Eeṣe ti a fi nilo ìlàlóye nipa tẹmi nisinsinyi ju ti igbakigba ri lọ?
7 Lonii a nilo ìmọ́lẹ̀ tẹmi ju ti igbakigba ri lọ. Awọn asọtẹlẹ bi iru ti Matteu ori 24 ati 2 Timoteu ori 3 fihàn pe a sunmọ opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii. Iwọnyi ati awọn asọtẹlẹ miiran sọ asọtẹlẹ awọn nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti o ti ṣẹlẹ ni akoko wa, ni mímú ki a mọ̀ pe a wà ni “ikẹhin ọjọ.” Ni ibamu pẹlu iru awọn asọtẹlẹ bẹẹ, ọrundun yii ti niriiri ìjábà lori ìjábá. Iwa-ọdaran ati iwa-ipa ti roke dé iwọn ti ń dẹrubani. Ogun ti gba iwalaaye ti o ju ọgọrun-un million lọ. Àrùn, iru bi AIDS ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, ń dọdẹ pa araadọta-ọkẹ, awọn 160,000 melookan sì ti kú ná nipasẹ àrùn AIDS ni United States nikan. Igbesi-aye idile ti foriṣanpọn ti a sì ń foju wo iwarere ibalopọ takọtabo gẹgẹ bi alaibagbamu.
8. Ipo wo ni ó dojukọ iran eniyan nisinsinyi, eesitiṣe?
8 Akọwe gbogbogboo ti Iparapọ Orilẹ-ede tẹlẹri Javier Pérez de Cuéllar sọ pe: “Ipo ayé nawọ ẹ̀rí tí ń bonimọlẹ jade pe òṣì [ń jin] iparapọṣọkan ẹgbẹ́ awujọ eniyan [lẹsẹ].” Ó sọ ọ́ di mímọ̀ pe “iye ti o ju billion kan awọn eniyan ń gbé nisinsinyi ninu ipo òṣì lilekenka” ati pe “eyi sì ti mu ki awọn okunfa gbọ́nmi-si-omi-òtó oniwa-ipa lọ soke sii.” Awọn “ipọnloju gígogò” wọnyi, ni ó sọ, “kò gbojúbọ̀rọ̀ fun awọn òògùn atunṣe ti ijọba lè lò.” Aṣaaju eto-ajọ kan ti ń kó ipa pataki kan sì tẹnumọ ọn pe: “Lajori iṣoro ti ń dojukọ ẹgbẹ́ awujọ eniyan ni pe ó ti di alaiṣeeṣakoso.” Bawo ni ọ̀rọ̀ inu Orin Dafidi 146:3 ti jẹ́ otitọ tó pe: “Ẹ maṣe gbẹkẹ yin lé awọn ọmọ alade, àní lé ọmọ eniyan, lọwọ ẹni ti kò sí iranlọwọ.”
9. Awọn wo ni wọn ni ẹrù-iṣẹ́ fun okunkun ti o bo ìran eniyan mọ́lẹ̀, ta ni ó sì lè gbà wá lọwọ ipá yii?
9 Ipo ọ̀ràn lonii rí gẹgẹ bi Isaiah 60:2 ṣe ṣasọtẹlẹ pe: “Nitori kiyesi i, okunkun bo ayé mọ́lẹ̀, ati okunkun biribiri bo awọn eniyan.” Okunkun yii ti o bo ọpọ jaburata ninu awọn olugbe ilẹ̀-ayé jẹ́ nitori fifi ti wọn kò fi ara fun ìmọ́lẹ̀ tẹmi lati ọ̀dọ̀ Jehofa. Gbongbo okunfa okunkun tẹmi naa sì ni Satani Eṣu ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀, awọn olu-olori ọ̀tá Ọlọrun ìmọ́lẹ̀. Awọn ni “alaṣẹ ibi okunkun ayé yii.” (Efesu 6:12) Gẹgẹ bi 2 Korinti 4:4 ṣe sọ, Eṣu ni “ọlọrun ayé yii,” ẹni ti o “ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ di afọju, ki ìmọ́lẹ̀ ihinrere Kristi ti o lógo, ẹni tii ṣe aworan Ọlọrun, ki o maṣe mọ́lẹ̀ ninu wọn.” Kò si ofin ẹda-eniyan kan ti o lè gba ayé kuro lọwọ agbara-idari Satani. Ọlọrun nikan ni ó lè ṣe bẹẹ.
“Ìmọ́lẹ̀ Ńlá”
10. Bawo ni Isaiah ṣe sọtẹlẹ pe ni ọjọ wa ìmọ́lẹ̀ ni a o tàn sara awọn eniyan?
10 Sibẹ, nigba ti okunkun kíkàmàmà bo ọpọ julọ ninu iran eniyan, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tun sọ atọtẹlẹ ninu Isaiah 60:2, 3 pe: “Ṣugbọn Oluwa yoo yọ lara rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lara rẹ. Awọn Keferi yoo wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ.” Eyi wà ni ibamu pẹlu Isaiah ori 2, eyi ti o ṣeleri pe ijọsin tootọ ti Jehofa, ti o kun fun ìjìnlẹ̀-òye ni a o gbekalẹ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi ati, gẹgẹ bi ẹsẹ 2 ati 3 ṣe sọ, “gbogbo orilẹ-ede ni yoo sì wọ́ si inu rẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo sì lọ, wọn ó sì wi pe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si oke Oluwa” iyẹn ni pe, si ijọsin tootọ rẹ̀ ti a gbega. Nitori naa bi o tilẹ jẹ pe ayé ni a ń dari lati ọwọ Satani, ìmọ́lẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ń tàn ti ó sì ń sọ ogunlọgọ dominira kuro ninu okunkun.
11. Ta ni yoo jẹ́ ogunna gbongbo julọ ninu fifi ìmọ́lẹ̀ Jehofa hàn, bawo sì ni Simoni ṣe fi í hàn yatọ?
11 Asọtẹlẹ inu Isaiah 9:2 sọtẹlẹ pe Ọlọrun yoo rán ẹnikan sinu ayé lati fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn. Ó sọ pe: “Awọn eniyan tí ń rìn ni okunkun rí ìmọ́lẹ̀ ńlá: awọn tí ń gbé ilẹ ojiji iku, lara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ si.” “Ìmọ́lẹ̀ ńlá” yii jẹ́ Agbẹnusọ Jehofa, Jesu Kristi. Jesu sọ pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé; ẹni ti ó bá tọ̀ mi lẹhin kì yoo rìn ninu okunkun, ṣugbọn yoo ni ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Johannu 8:12) Eyi ni awọn diẹ mọ̀ àní nigba ti Jesu wà ni ọmọde kekere paapaa. Luku 2:25 sọ pe ọkunrin kan ti a ń pe orukọ rẹ̀ ni Simoni “ṣe oloootọ ati olufọkansin” ati pe “ẹmi mimọ sì bà lé e.” Nigba ti Simoni rí ọmọde kekere naa Jesu, ó sọ ninu adura si Ọlọrun pe: “Nitori ti oju mi ti rí igbala rẹ ná, ti iwọ ti pese silẹ niwaju eniyan gbogbo; ìmọ́lẹ̀ lati mọ́ si awọn Keferi.”—Luku 2:30-32.
12. Nigba wo ati bawo ni Jesu ṣe bẹrẹ sii mú ìbòjú okunkun ti o boju awọn eniyan kuro?
12 Jesu bẹrẹ sii mú ìbòjú okunkun kuro loju ìran eniyan gẹ́rẹ́ lẹhin iribọmi rẹ̀. Matteu 4:12-16 sọ fun wa pe eyi mú Isaiah 9:1, 2 ṣẹ, eyi ti ó sọ nipa “ìmọ́lẹ̀ ńlá” eyi ti yoo bẹrẹ sii mọ́lẹ̀ sara awọn eniyan ti wọn ń rìn ninu okunkun nipa tẹmi. Matteu 4:17 sọ pe: “Lati ìgbà naa ni Jesu bẹrẹ sii waasu wi pe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.” Nipa wiwaasu nipa ihinrere Ijọba Ọlọrun, Jesu la awọn eniyan lóye nipa awọn ète Ọlọrun. Ó “mú ìyè ati aidibajẹ wá si ìmọ́lẹ̀ nipasẹ ihinrere.”—2 Timoteu 1:10.
13. Bawo ni Jesu ṣe ṣapejuwe araarẹ, eesitiṣe ti oun fi lè ṣe bẹẹ pẹlu iru idaniloju bẹẹ?
13 Jesu fi iduroṣinṣin fi ìmọ́lẹ̀ Ọlọrun hàn. Ó sọ pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ti o wá si ayé, ki ẹnikẹni ti ó bá gbà mi gbọ́ ki ó maṣe wà ni okunkun. . . . Nitori emi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fun araami, ṣugbọn Baba ti ó rán mi, oun ni ó ti fun mi ni àṣẹ, ohun ti emi ó sọ, ati eyi ti emi ó wi. Emi sì mọ̀ pe ìyè ainipẹkun ni ofin rẹ̀.”—Johannu 12:44-50.
“Ninu Rẹ̀ Ni Ìyè Wà”
14. Bawo ni a ṣe dá Jesu mọ̀ ni Johannu 1:1, 2?
14 Bẹẹni, Jehofa rán Ọmọkunrin rẹ̀ si ilẹ̀-ayé lati jẹ́ ìmọ́lẹ̀ lati fi ọ̀nà si ìyè ainipẹkun han awọn eniyan. Ṣakiyesi bi a ṣe ṣagbeyọ eyi ninu Johannu 1:1-16. Ẹsẹ 1 ati 2 kà pe: “Ni atetekọṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹlu Ọlọrun, [Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ ọlọrun kan, NW]. Oun naa ni ó wà ni atetekọṣe pẹlu Ọlọrun.” Nihin-in Johannu ń pe Jesu ti ó ti walaaye ṣaaju ki o tó di eniyan ni orukọ oyè naa “Ọ̀rọ̀.” Eyi ń fi ipa ti ó kó gẹgẹ bi Agbẹnusọ Jehofa Ọlọrun hàn yatọ. Nigba ti Johannu sì sọ pe “ni atetekọṣe ni Ọ̀rọ̀ wà,” ó tumọ si pe Ọ̀rọ̀ naa jẹ́ ibẹrẹ iṣẹ iṣẹda Jehofa, “olupilẹṣẹ ẹ̀dá Ọlọrun.” (Ìfihàn 3:14) Ipo ìwàṣaájú rẹ̀ laaarin awọn ẹ̀dá Ọlọrun fun wa ni idi gidi fun pípè ti a pè é ni “ọlọrun kan,” ẹni alagbara. Isaiah 9:6 pè é ni “Ọlọrun Alagbara,” bi o tilẹ jẹ pe kìí ṣe Ọlọrun Alagbara Julọ.
15. Afikun isọfunni wo ni Johannu 1:3-5 fun wa nipa Jesu?
15 Johannu 1:3 sọ pe: “Nipasẹ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a kò sì dá ohun kan ninu ohun ti a dá.” Kolosse 1:16 sọ pe “nitori ninu rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, ohun ti ń bẹ ni ọrun, ati ohun ti ń bẹ ni ayé.” Johannu 1:4 sọ pe “ninu rẹ̀ ni ìyè wà; ìyè naa sì ni ìmọ́lẹ̀ araye.” Nitori naa nipasẹ Ọ̀rọ̀ naa, gbogbo iru iwalaaye yooku ni a dá; bakan naa nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀, Ọlọrun mú ki o ṣeeṣe fun ìran eniyan ẹlẹṣẹ ti ń kú lati jere ìyè ainipẹkun. Dajudaju, Jesu ni ẹni alagbara ti Isaiah 9:2 pe ni “ìmọ́lẹ̀ ńlá.” Johannu 1:5 sì sọ pe: “Ìmọ́lẹ̀ naa sì ń mọ́lẹ̀ ninu okunkun; okunkun naa kò sì bori rẹ̀.” Ìmọ́lẹ̀ duro fun otitọ ati òdodo, ni ifiwera pẹlu okunkun, eyi ti o duro fun aṣiṣe tabi aiṣododo. Nipa bayii Johannu fihàn pe okunkun kì yoo bori ìmọ́lẹ̀ naa.
16. Bawo ni Johannu Arinibọmi ṣe tọka si igbooro iṣẹ Jesu?
16 Nisinsinyi Johannu ṣalaye ni ẹsẹ 6 si 9 pe: “Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wa, orukọ ẹni ti ń jẹ́ Johannu [Arinibọmi]. Oun naa ni a sì rán fun ẹ̀rí, ki ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fun ìmọ́lẹ̀ naa, ki gbogbo eniyan ki o lè gbagbọ nipasẹ rẹ̀. Oun [Johannu] kìí ṣe Ìmọ́lẹ̀ naa, ṣugbọn a rán an wá lati ṣe ẹlẹ́rìí fun Ìmọ́lẹ̀ naa [Jesu] ni. Ìmọ́lẹ̀ otitọ ń bẹ ti ń tànmọ́lẹ̀ fun olukuluku eniyan ti o wá si ayé.” Johannu tọka si dídé Messia ó sì yi awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pada si I. Bi akoko ti ń lọ, gbogbo oniruuru eniyan ni a fun ni anfaani lati tẹwọgba ìmọ́lẹ̀. Nitori naa Jesu kò wá kìkì fun anfaani awọn Ju ṣugbọn fun anfaani gbogbo ìran eniyan—òtòṣì tabi ọlọ́rọ̀, laika ẹ̀yà-ìran si.
17. Ki ni Johannu 1:10, 11 sọ fun wa nipa ipo tẹmi awọn Ju ni ọjọ Jesu?
17 Ẹsẹ 10 ati 11 ń baa lọ pe: “Oun sì wà ni ayé, nipasẹ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ayé kò sì mọ̀ ọ́n. Ó tọ awọn tirẹ̀ wa, awọn ará tirẹ̀ kò sì gbà á.” Jesu, ninu iwalaaye rẹ̀ ṣaaju ki ó tó di eniyan, ti jẹ́ ẹni ti a dá ayé iran eniyan nipasẹ rẹ̀. Nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ ninu awọn eniyan rẹ̀, awọn Ju, kọ̀ ọ́ silẹ. Wọn kò fẹ́ ki a tú iwa buburu ati arekereke wọn fó. Wọn yan okunkun dipo ìmọ́lẹ̀.
18. Bawo ni Johannu 1:12, 13 ṣe fihàn pe awọn kan lè di ọmọ Ọlọrun pẹlu ogún akanṣe?
18 Johannu sọ ninu ẹsẹ 12 ati 13 pe: “Ṣugbọn iye awọn ti ó gbà á, awọn ni o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, àní awọn naa ti o gba orukọ rẹ̀ gbọ: awọn ẹni ti a bí, kìí ṣe nipa ti ẹ̀jẹ̀, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹẹ ni kìí ṣe nipa ifẹ ti eniyan, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun.” Awọn ẹsẹ wọnyi fihàn pe lakọọkọ ná, awọn ọmọlẹhin Jesu kìí ṣe ọmọkunrin Ọlọrun. Ṣaaju ki Kristi tó wá si ori ilẹ̀-ayé, iru ipo jíjẹ́ ọmọkunrin tabi ireti ti ọrun kan bẹẹ ni kò tii ṣí silẹ fun awọn eniyan. Ṣugbọn nipasẹ itoye ẹbọ irapada Kristi ninu eyi ti wọn ti lo igbagbọ, awọn eniyan kan ni a tẹwọgba fun jíjẹ́ ọmọkunrin ti ó sì ṣeeṣe fun wọn lati ni ireti iwalaaye gẹgẹ bi ọba pẹlu Kristi ninu Ijọba ọrun ti Ọlọrun.
19. Eeṣe ti Jesu fi wà ni ipo ti o dara julọ lati fi ìmọ́lẹ̀ Ọlọrun hàn, gẹgẹ bi a ṣe fihàn ni Johannu 1:14?
19 Ẹsẹ 14 ṣalaye pe: “Ọ̀rọ̀ naa sì di ara, oun sì ń bá wa gbé, (awa sì ń wo ògo rẹ̀, ògo bii ti ọmọ bíbí-kanṣoṣo lati ọ̀dọ̀ Baba wá).” Lori ilẹ̀-ayé, Jesu fi ògo Ọlọrun hàn gẹgẹ bi akọbi Ọmọkunrin kanṣoṣo Ọlọrun ṣe lè ṣe. Nitori idi eyi, ni ọ̀nà kan ti ó tayọ, oun ni ó tootun daradara julọ lati fi Ọlọrun ati awọn ète Rẹ̀ hàn fun awọn eniyan.
20. Gẹgẹ bi a ti ṣe akọsilẹ rẹ̀ ni Johannu 1:15, ki ni Johannu Arinibọmi sọ fun wa nipa Jesu?
20 Tẹle e, aposteli Johannu kọwe ni ẹsẹ 15 pe: “Johannu [Arinibọmi] sì jẹrii rẹ̀ ó sì kigbe, wi pe, eyi ni ẹni ti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹni ti ń bọ̀ lẹhin mi, ó pọ̀ ju mi lọ: nitori ó wà ṣiwaju mi.” Johannu Arinibọmi ni a bí ni nǹkan bi oṣu mẹfa ṣaaju ìbí Jesu gẹgẹ bi ẹ̀dá eniyan. Ṣugbọn Jesu ṣe iṣẹ ti ó pọ̀ fíìfíì ju Johannu lọ, ti o fi jẹ pe ó tẹsiwaju niwaju Johannu ni gbogbo ọ̀nà. Johannu sì jẹwọ pe Jesu walaaye ṣiwaju oun, niwọn bi Jesu ti ní iwalaaye kan ṣaaju ki o tó di eniyan.
Awọn Ẹbun Lati Ọ̀dọ̀ Jehofa
21. Eeṣe ti Johannu 1:16 fi sọ pe a ti gba “ore-ọfẹ kun ore-ọfẹ”?
21 Johannu 1:16 ṣalaye pe: “Nitori ninu ẹ̀kún rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gbà, ati ore-ọfẹ kun ore-ọfẹ.” Bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan ni a bí ninu ẹṣẹ nitori jijogun rẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Adamu, Jehofa pète iparun eto-igbekalẹ buburu yii, lilaaja araadọta-ọkẹ sinu ayé titun, ajinde awọn oku, ati imukuro ẹṣẹ ati iku, ni yiyọrisi ìyè ainipẹkun ninu paradise ilẹ̀-ayé. Gbogbo awọn ibukun wọnyi jẹ eyi ti a kò lẹtọọsi, ti awọn eniyan ẹlẹṣẹ kò lẹtọọsi. Wọn jẹ ibukun lati ọ̀dọ̀ Jehofa nipasẹ Kristi.
22. (a) Ki ni ẹbun Ọlọrun ti o tobi julọ mu ki o ṣeeṣe? (b) Ikesini wo ni a nawọ́ rẹ̀ jade si wa ninu iwe ti o gbẹhin Bibeli?
22 Ki ni ẹbun titobi julọ ti ó mu ki gbogbo eyi ṣeeṣe? “Nitori Ọlọrun fẹ́ araye tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ má baa ṣegbe, ṣugbọn ki o lè ni ìyè ainipẹkun.” (Johannu 3:16) Nipa bayii, ìmọ̀ ti o peye nipa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀, “olupilẹṣẹ ìyè,” ṣe pataki fun awọn wọnni ti wọn fẹ́ ìmọ́lẹ̀ nipa tẹmi ati ìyè ainipẹkun. (Iṣe 3:15) Idi niyẹn ti iwe ti o gbẹhin ninu Bibeli ṣe nawọ ikesini ti o tẹle e si gbogbo awọn ti wọn fẹ́ otitọ ti wọn sì fẹ́ ìyè pe: “Maa bọ. Ati ẹni ti ó ń gbọ́ ki o wi pe, Maa bọ. Ati ẹni ti oungbẹ ń gbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o bá sì fẹ́, ki o gba omi ìyè naa lọfẹẹ.”—Ìfihàn 22:17.
23. Ki ni awọn ẹni-bi-agutan yoo ṣe nigba ti wọn bá wá si ọ̀dọ̀ ìmọ́lẹ̀?
23 Awọn eniyan onirẹlẹ, ẹni bi agutan kò ni wá sọdọ ìmọ́lẹ̀ ayé naa nikan ṣugbọn wọn yoo tẹle ìmọ́lẹ̀ yẹn: “Awọn agutan sì ń tọ̀ ọ́ lẹhin: nitori ti wọn mọ [ìdúnjáde otitọ ninu] ohùn rẹ̀.” (Johannu 10:4) Niti gidi, wọn ni idunnu lati “tọ ipasẹ rẹ̀” nitori wọn mọ pe ṣiṣe bẹẹ yoo tumọsi ìyè ainipẹkun fun wọn.—1 Peteru 2:21.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Iru ìmọ́lẹ̀ meji wo ni ó ń wá lati ọ̀dọ̀ Jehofa?
◻ Eeṣe ti ìlàlóye nipa tẹmi fi ṣe pataki tobẹẹ lonii?
◻ Ni ọ̀nà wo ni Jesu gbà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ńlá”?
◻ Ki ni Johannu ori 1 sọ fun wa nipa Jesu?
◻ Awọn ẹbun wo ni o ṣàn wá sọdọ awọn wọnni ti wọn tẹle ìmọ́lẹ̀ ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Simoni pe Jesu ni “ìmọ́lẹ̀ lati mọ́ si awọn Keferi”