Iwọ Ha Nilati Gba Iribọmi Bi?
IYE ti o sunmọ million kan awọn eniyan ni a baptisi lati ọwọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ọdun mẹta ti o kọja. Eyi wá jẹ́ ipindọgba 824 lọjọ kọọkan, tabi ẹni 4 ti a ń baptisi ni gbogbo iṣẹju 7. Eyi ha jẹ́ kìkì awoṣe igbonara onisin ti awọn ọrundun kẹẹ̀ẹ́dógún ati ikẹrindinlogun bi?
Bẹẹkọ, awọn eniyan lẹnikọọkan wọnyi ni a kò fi tipatipa baptisi, gẹgẹ bi apakan iyilọkanpada gbogbogboo kan, tabi gẹgẹ bi abajade ifọranlọ ero-imọlara lati ọ̀dọ̀ awọn eniyan onisin ti wọn jẹ́ ẹni pataki kan. A baptisi wọn nitori pe Jesu Kristi, Ọ̀gá ati Aṣaaju awọn Kristian, paṣẹ pe ki a ṣe eyi. Wọn ti tẹle igbesẹ ati ilana ti Jesu lapa ti awọn aposteli ti oun funraarẹ yàn ti ó sì dalẹkọọ fi lélẹ̀.
Lẹhin ajinde Jesu ati ṣiwaju igoke re ọrun rẹ̀, o fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni àṣẹ idagbere yii pe: “Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ sì maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mimọ: ki ẹ maa kọ́ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa ni àṣẹ fun yin: ẹ sì kiyesi i, emi wà pẹlu yin nigba gbogbo, titi ó fi dé opin ayé.” (Matteu 28:19, 20) Lati ìgbà naa wá, eyi ni kìkì iribọmi inu omi ti o ni itẹwọgba Ọlọrun.
Ni ibamu pẹlu eyi, Bibeli sọ fun wa pe awọn ọmọlẹhin Kristi akọkọbẹrẹ wọnni di “ẹlẹrii [Jesu] ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ̀-ayé.” (Iṣe 1:8) Gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ, iṣẹ wiwaasu ati kikọni wọn yoo yọrisi iribọmi awọn onigbagbọ ti awọn pẹlu yoo jẹ́ ọmọlẹhin Kristi.
Apẹẹrẹ akọkọ ti a kọsilẹ nipa eyi wáyé ni Jerusalemu ni ọjọ Pentikosti 33 C.E. Ni akoko yẹn aposteli Peteru “dide duro pẹlu awọn mọkanla iyoku” ó sì sọrọ nipa Messia naa Jesu fun ọpọ awọn eniyan ti wọn pejọ. Akọsilẹ naa sọ fun wa pe ọ̀rọ̀ rẹ̀ ‘mu ki ọkàn wọn gbọgbẹ́,’ wọn sì beere ki ni ohun ti wọn nilati ṣe. “Ẹ ronupiwada, ki a sì baptisi olukuluku yin ni orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹṣẹ yin,” ni Peteru sọ. Abajade naa ni pe “awọn ti ó sì fi ayọ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a baptisi wọn: ni ọjọ naa a sì ka ìwọ̀n ẹgbẹẹdogun ọkàn kun wọn.” (Iṣe 2:14-41) Awọn akọsilẹ ti o tẹle e jẹrii sii pe iribọmi awọn ọmọ-ẹhin ni gbigbọ ihin-iṣẹ Kristian, gbigbagbọ ninu ihinrere naa, ati rironupiwada ṣaaju rẹ̀.—Iṣe 8:12, 13, 34-38; 10:34-48; 16:30-34; 18:5, 8; 19:1-5.
Ni Ọ̀nà Wo?
Ṣugbọn bawo ni a ṣe nilati baptisi awọn ọmọ-ẹhin titun wọnyi ninu omi? O ha nilati jẹ́ nipasẹ ìbomijù (wíwọ́n-omi), ìdomilé (dída omi sori), tabi ìtẹ̀bọmi (rírì bọ inu omi patapata) bi? Ki ni ohun ti akọsilẹ Bibeli fihàn? Niwọn bi Jesu ti fi apẹẹrẹ kan lelẹ fun wa ‘ki awa ki o lè maa tọ ipasẹ rẹ̀,’ ni ọ̀nà wo ni a gbà baptisi rẹ̀?—1 Peteru 2:21.
Bibeli fihàn pe Jesu ni a baptisi ninu Jordani, odò titobi kan. Lẹhin ti a baptisi rẹ̀, ó “goke lati inu omi wá.” (Marku 1:10; Matteu 3:13, 16) Nitori naa Jesu niti gidi ni a ti rì bọ inu Odò Jordani. A baptisi rẹ̀ lati ọwọ Johannu, ẹni ti, ní wíwò kaakiri fun ibi kan ti o yẹ lati ṣe iribọmi, yan ibi pàtó kan ni Afonifoji Jordani lẹba Salimu “nitori ti omi pupọ wà nibẹ.” (Johannu 3:23) Otitọ naa pe rírì bọ inu omi patapata ni ọpa-idiwọn aṣa iribọmi laaarin awọn ọmọlẹhin Jesu ni a rí nipa ọ̀rọ̀ iwẹfa ara Etiopia naa. Ni didahun pada si ikọnilẹkọọ Filippi, ó sọ jade pe: “Wò ó, omi niyii; ki ni ó dá mi duro lati baptisi?” Nigba naa a ṣakiyesi pe “awọn mejeeji sì sọkalẹ lọ sinu omi” ati lẹhin naa “wọn sì jade kuro ninu omi.”—Iṣe 8:36-39.
Ǹjẹ́ ìtàn ayé pẹlu tọka si aṣa iribọmi nipasẹ rírini bọ inu omi laaarin awọn Kristian bi? Nitootọ ó ṣe bẹẹ. Ó sì fanilọkan mọra lati mọ̀ pe ọpọlọpọ odò ńlá ti o yẹ fun iribọmi ṣì wà sibẹ ni awọn ilẹ kan. “Ẹ̀rí iwalẹpitan jẹrii si ìtẹ̀bọmi gẹgẹ bi aṣa iribọmi wiwọpọ nigba ọrundun mẹwaa tabi mẹrinla akọkọ lọna ti ó pọ̀ jaburata,” ni iwe agberohinjade naa Ministry sọ. Ó fikun un pe: “Lara awọn awoku ile Kristian akọkọbẹrẹ, ati pẹlu ni awọn ṣọọṣi igbaani ti a ṣì ń lò sibẹ, ìtàn iribọmi Kristian ni a lè tọpasẹ rẹ̀. Awọn aworan ninu awọn ibojì ńlá ati ṣọọṣi, awọn aworan alátòpọ̀ lori ilẹ, lara ogiri, ati lara àjà-ilé, aworan gbígbẹ́, ati awọn aworan yíyà ninu iwe afọwọkọ Majẹmu Titun igbaani fi kulẹkulẹ isọfunni kún ìtàn yii . . . Eyi jẹ́ ni afikun si ẹ̀rí ti a rí ninu iwe awọn baba ṣọọṣi latokedelẹ pe ìtẹ̀bọmi jẹ́ aṣa iribọmi ti ó wọpọ ti ṣọọṣi akọkọbẹrẹ.”
New Catholic Encyclopedia gbà pe: “Ó ṣe kedere pe Iribọmi ní Ṣọọṣi akọkọbẹrẹ jẹ́ nipasẹ ìtẹ̀bọmi.” Kò yanilẹnu, nigba naa, pe a ń rí awọn akọle iwe-irohin gẹgẹ bi iwọnyi: “Awọn Katoliki Mu Iribọmi Onítẹ̀bọmi Pada” (The Edmonton Journal, Canada, September 24, 1983), “Iribọmi Nipasẹ Ìtẹ̀bọmi Di Olokiki Pẹlu Awọn Katoliki Nihin-in” (St. Louis Post-Dispatch, April 7, 1985), “Ọpọ Awọn Katoliki Ń Yan Iribọmi nipasẹ Ìtẹ̀bọmi” (The New York Times, March 25, 1989), ati “Awọn Iribọmi Onítẹ̀bọmi Ń Gbadun Imusọji” (The Houston Chronicle, August 24, 1991).
Fun Ète Wo?
Eeṣe ti Jesu fi beere pe ki a baptisi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O dara, ó jẹ́ apẹẹrẹ ti o bamu wẹ́kú nipa iyasimimọ wọn tọkantọkan si Ọlọrun. “Ihinrere” naa ni o yẹ ki a waasu kaakiri ayé, a sì gbọdọ sọ “gbogbo orilẹ-ede” di ọmọ-ẹhin. (Matteu 24:14; 28:19) Eyi tumọsi pe Ọlọrun kò tun maa baa lọ lati maa bá orilẹ-ede Ju lò lọna ọ̀tọ̀ gédégbé kan, eyi ti o ní ninu awọn eniyan ti wọn ti ya araawọn si mimọ fun un lati ìgbà ìbí. Korneliu ati idile rẹ̀ ni Keferi akọkọ, tabi awọn ti kìí ṣe Ju lati tẹwọgba otitọ nipa Jesu Kristi ti a sì baptisi wọn.
Rírini bọ abẹ́ omi fihàn pe awọn wọnni ti a baptisi ti kú si ipa-ọna igbesi-aye ti ó ti kó afiyesi jọ sori awọn funraawọn. Gbigbe ti a gbé wọn dide jade kuro ninu omi ṣapẹẹrẹ pe wọn walaaye nisinsinyi fun ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun ti wọn sì ń fi si ipo akọkọ ninu igbesi-aye wọn, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe. (Matteu 16:24) Didi ẹni ti a baptisi “ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mimọ” fihàn pe wọn ti kẹkọọ ti wọn sì ti tẹwọgba otitọ nipa ọkọọkan ninu awọn wọnyi ti wọn sì mọ̀ wọn fun ohun ti wọn jẹ́. (Matteu 28:19; fiwe Iṣe 13:48.) Iribọmi wulẹ jẹ́ igbesẹ akọkọ kan ti igbọran si Ọlọrun ati itẹriba fun ifẹ-inu rẹ̀.
Iwe Mimọ kò faramọ oju-iwoye isin ti ó gbodekan pe iribọmi jẹ́ sakramẹnti kan, iyẹn ni, ayẹyẹ isin ti ń funni ni èrè—ojurere, ijẹmimọ, tabi anfaani tẹmi—fun ẹni ti a baptisi naa. Fun apẹẹrẹ, lẹta pope ti Pope Eugenius IV ti a ṣayọlo rẹ̀ ninu ọrọ-ẹkọ ti o ṣaaju ń baa lọ lati sọ nipa iribọmi pe: “Iyọrisi sakramẹnti yii ni idariji gbogbo ẹṣẹ, ti ipilẹṣẹ ati eyi ti o jẹ gidi; bakan naa sì ni ti gbogbo ijiya eyi ti o yẹ fun ẹṣẹ. Gẹgẹ bi abajade kan, kò sí itẹlọrun fun awọn ẹṣẹ ti o ti kọja ti a ń gbekari awọn wọnni ti a baptisi; bi wọn bá sì kú ki wọn tó dá ẹṣẹ eyikeyii, wọn jere ijọba ọrun ati iran Ọlọrun lẹsẹkẹsẹ.”
Bi o ti wu ki o ri, Jesu ni a baptisi bi o tilẹ jẹ pe oun “kò dẹṣẹ.” (1 Peteru 2:22) Siwaju sii, gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi, idariji ẹṣẹ ń wá kìkì nipasẹ ẹbọ irapada Jesu Kristi. Anania rọ Saulu ti Tarsu pe: “Dide, gba iribọmi ki o sì wẹ awọn ẹṣẹ rẹ nù kuro ni pípè ti iwọ pe orukọ [Jesu].” (Iṣe 22:12-16, NW) Bẹẹni, igbala ṣeeṣe kìkì nipa ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ ati nipa ‘pípe orukọ rẹ̀’ ni igbagbọ.—Heberu 9:22; 1 Johannu 1:7.
Nigba naa, ki ni nipa ọ̀rọ̀ Peteru ninu 1 Peteru 3:21? Nibẹ ó sọ pe: “Apẹẹrẹ eyi ti ń gba yin là nisinsinyi pẹlu, àní baptism [iribọmi], kìí ṣe ìwẹ èérí ti ara nù, bikoṣe idahun ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi.” Peteru ṣefiwera iribọmi pẹlu iriri tí Noa ní niti lila omi Ikun-omi já. (Ẹsẹ 20) Noa, ní fifi igbagbọ kikun hàn ninu Ọlọrun, kan arki fun idaabobo idile rẹ̀. (Heberu 11:7) Bakan naa, nipa lilo igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun ati ipese rẹ̀ fun igbala nipasẹ Kristi Jesu, awọn eniyan lonii ni a lè gbala kuro ninu eto-igbekalẹ buburu ayé yii. Wọn gbọdọ gbegbeesẹ lori igbagbọ yẹn. Nipa rironupiwada kuro ninu ẹṣẹ, yiyipada kuro ninu ipa-ọna aitọ, ati ṣiṣe iyasimimọ patapata si Jehofa Ọlọrun ninu adura, a fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ beere lọwọ Ọlọrun fun ẹ̀rí-ọkàn rere. Ṣugbọn ó jẹ́ lori ipilẹ ẹbọ Jesu, ati ajinde rẹ̀ nipasẹ eyi ti o gbé itoye ẹbọ yẹn kalẹ fun Ọlọrun ni ọrun, ni a fi ń dari ẹṣẹ jì ti igbala fi lè ṣeeṣe.—1 Peteru 3:22.
Ki ni Iwọ Yoo Ṣe?
Iwọ ha jẹ ẹnikan ti o ti ń darapọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun akoko kan bi? Boya o ti ṣe awọn iyipada ti o pọndandan ninu igbesi-aye rẹ ni ibamu pẹlu awọn ilana Bibeli ṣugbọn ti o kò tii gbé igbesẹ iyasimimọ ati iribọmi. Iwọ lè fẹ lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, sibẹ o lè bẹru pe iribọmi yoo gbé ẹrù kà ọ. Gẹgẹ bi iyọrisi, iwọ lè yàn lati yẹ iru ẹrù-iṣẹ́ ati ipo ijihin bẹẹ silẹ fun akoko kan. Ohun ti o fẹrẹẹ tó million 11.5 awọn eniyan ni wọn pesẹ si ajọdun Ounjẹ Alẹ Oluwa ni ọdun ti o kọja. Bi o ti wu ki o ri, gongo iye awọn ti wọn ṣajọpin ninu iṣẹ́ wiwaasu ihinrere jalẹ ọdun naa dín si million 4.5. Eyi tumọsi pe nǹkan bi million meje awọn eniyan ni wọn fi iru imọriri kan hàn fun otitọ Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe wọn kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a baptisi. Nitootọ, diẹ ninu awọn wọnyi jẹ́ awọn ọdọmọde ati awọn olufifẹhan titun. Ṣugbọn diẹ ninu awọn ti wọn ṣajọpin ninu iṣẹ́ wiwaasu ni a kò tii baptisi sibẹ. Nitori naa ọpọlọpọ eniyan ni wọn wà ti wọn ti gba ìmọ̀ pipeye Bibeli sinu ṣugbọn sibẹ ti wọn kò tii fi ipese Ọlọrun silo fun araawọn ni kikun fun igbala nipa didi ẹni ti a baptisi.
Koko pataki kan ti a nilati ranti ni pe ìmọ̀ nipa ohun ti Ọlọrun beere lọwọ rẹ ni o mu ipo ijihin wá. “Nitori naa ẹni ti o bá mọ rere iṣe ti kò sì ṣe e, ẹṣẹ ni fun un,” ni Jakọbu 4:17 sọ. Esekieli 33:7-9 fihàn pe ẹnikan ti a sọ awọn ofin ati ilana Ọlọrun fun ni ó ni ẹrù-iṣẹ́ lati ṣe wọn. Nitori naa ibeere naa ni boya ẹnikan ni ifẹ atọkanwa fun Ọlọrun ati ìfẹ́-ọkàn gidi lati tẹ́ ẹ lọrun. Ẹnikan ti o ni iru ifẹ bẹẹ nitootọ ti o sì fẹ́ ipo-ibatan ara-ọtọ pẹlu Jehofa Ọlọrun kò ni fà sẹhin ninu yíya igbesi-aye rẹ̀ si mimọ fun un lọfẹẹ. Iribọmi jẹ apẹẹrẹ ti a fihàn sita nipa iyasimimọ yẹn. Ó jẹ́ igbesẹ ti o ṣe pataki fun igbala. Awọn onigbagbọ ti wọn pójú-owó ń di ẹni ti a baptisi.—Iṣe 8:12.
Ifojusọna titobilọla ti Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ jade fun awọn eniyan oluṣotitọ, ti wọn ti ṣe iyasimimọ lẹnikọọkan ninu ayé titun ti ń bọ̀wá fi pupọpupọ wuwo ju anfaani onigba kukuru eyikeyii ti eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu ti o ti gbó yii lè dabi eyi ti ó nawọ́ rẹ̀ jade. Ibẹru awọn eniyan ẹlẹgbẹ-ẹni ń poora nigba ti a bá ṣagbeyẹwo ọwọ́ alagbara ti Ọlọrun. (1 Korinti 10:22; 1 Peteru 5:6, 7) Loootọ, isinsinyi ni akoko naa lati beere lọwọ araarẹ, gẹgẹ bi iwẹfa ara Etiopia ṣe beere lọwọ Filippi pe: “Ki ni o dá mi duro lati baptisi?”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gẹgẹ bi iwẹfa ara Etiopia, iwọ ha ń beere lọwọ araarẹ pe: “Ki ni o dá mi duro lati baptisi?”