Awọn Kristian Ijimiji ati Ayé
NI NǸKAN bi ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, iṣẹlẹ agbayanu julọ kan ṣẹlẹ ni Aarin Gbungbun Ila-oorun. Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo ti Ọlọrun ni a rán lati ibugbe rẹ̀ ni ọ̀run wá lati gbé fun ìgbà kukuru kan ninu ayé araye. Bawo ni ọpọ julọ ninu araye ṣe dahunpada? Aposteli Johannu fèsì pe: “Oun [Jesu] sì wà ni ayé, nipasẹ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ayé kò sì mọ̀ ọ́n. Ó tọ awọn tirẹ̀ [Israeli] wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà á.”—Johannu 1:10, 11.
Ayé kò wulẹ gba Jesu, Ọmọkunrin Ọlọrun gbọ́. Eeṣe ti wọn kò fi ṣe bẹẹ? Jesu ṣalaye idi kan nigba ti o sọ pe: ‘Ayé koriira mi, nitori ti mo jẹrii gbè é pe, iṣẹ́ rẹ̀ buru.’ (Johannu 7:7) Asẹhinwa-asẹhinbọ, ayé yii kan-naa—ti awọn olori isin Ju diẹ, ọba Edomu kan, ati oṣelu ara Romu kan jẹ́ apẹẹrẹ fun—mú ki a pa Jesu. (Luku 22:66–23:25; Iṣe 3:14, 15; 4:24-28) Awọn ọmọlẹhin Jesu ńkọ́? Ayé yoo ha tubọ ṣetan lati tẹwọgba wọn bi? Bẹẹkọ. Kété ṣaaju iku rẹ̀, Jesu kilọ fun wọn pe: “Ìbáṣepé ẹyin iṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitori ti ẹyin kìí ṣe ti ayé, ṣugbọn emi ti yàn yin kuro ninu ayé, nitori eyi ni ayé ṣe koriira yin.”—Johannu 15:19.
Ní Akoko Awọn Aposteli
Awọn ọ̀rọ̀ Jesu jasi otitọ. Niwọnba ọsẹ diẹ péré lẹhin iku rẹ̀, awọn aposteli rẹ̀ ni a fi àṣẹ ọba mú, ni a dẹ́rùbà, ti a sì lù. (Iṣe 4:1-3; 5:17, 18, 40) Laipẹ lẹhin naa, Stefanu onitara ni a wọ́ lọ siwaju Ajọ-Igbimọ awọn Ju ti a sì sọ ọ́ ni okuta pa lẹhin naa. (Iṣe 6:8-12; 7:54, 57, 58) Lẹhin naa, aposteli Jakọbu ni Ọba Herodu Agripa I pa. (Iṣe 12:1, 2) Nigba irin-ajo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun rẹ̀ ni ilẹ ajeji, Paulu ni a ṣe inunibini sí nigba ti awọn Ju Diaspora dẹ awọn eniyan si i.—Iṣe 13:50; 14:2, 19.
Bawo ni awọn Kristian ijimiji ṣe huwapada si iru atako bẹẹ? Ní awọn ìgbà ijimiji, nigba ti awọn alaṣẹ isin kà á leewọ fun awọn aposteli lati maṣe waasu ni orukọ Jesu mọ́, awọn aposteli naa wi pe: “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.” (Iṣe 4:19, 20; 5:29) Eyi ń baa lọ lati jẹ́ iṣarasihuwa wọn nigbakigba ti atako bá dide. Bi o tilẹ ri bẹẹ, aposteli Paulu gba awọn Kristian ni Romu nimọran lati “foribalẹ fun awọn alaṣẹ [ti ijọba] ti o wà ni ipo giga.” Ó tun gbà wọn nimọran pe: “Bi ó lè ṣe, bi o ti wà ni ipa ti yin, ẹ maa wà ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan.” (Romu 12:18; 13:1) Nipa bayii, awọn Kristian ijimiji nilati dori wíwà deedee ti o ṣoro. Wọn ṣegbọran si Ọlọrun gẹgẹ bi Alaṣẹ wọn akọkọ. Ni akoko kan-naa, wọn wà ni itẹriba fun awọn alasẹ orilẹ-ede wọ́n sì gbiyanju lati gbé ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan.
Awọn Kristian Ninu Ayé Romu
Lọhun-un nigba ayé ọrundun kìn-ín-ní ti Ilẹ-ọba Romu, kò si iyemeji pe awọn Kristian janfaani lati inu Pax Romana, tabi Alaafia Romu, eyi ti awọn ẹgbẹ-ogun Romu ń ṣabojuto. Ilana ofin ati àṣẹ ti o fẹsẹmulẹ, awọn ọ̀nà ti o dara, ati irin-ajo oju-omi ti o dara dé ìwọ̀n aaye kan mú ki ipo-ayika ti o dara fun imugbooro isin Kristian di eyi ti o wà. Lọna ti o daniloju, awọn Kristian ijimiji mọ ohun ti wọn jẹ awujọ wọn ní gbèsè rẹ̀ wọn sì kọbiara si ìyànjú Jesu lati “fi ohun ti Kesari fun Kesari.” (Marku 12:17) Nigba ti o ń kọwe si Antoninus Pius olu-ọba Romu (138 si 161 C.E.), Justin Martyr tẹnumọ ọn pe awọn Kristian san owo-ori wọn, “pẹlu imuratan ju eniyan gbogbo lọ.” (First Apology, ori 17) Ní 197 C.E., Tertullian sọ fun awọn alakooso Romu pe awọn ti ń gba owo-ori fun wọn “jẹ awọn Kristian ni gbèsè idupẹ” fun ọ̀nà ti wọn gbà ń fi tọkantọkan san owo-ori wọn. (Apology, ori 42) Eyi jẹ́ ọ̀nà kan ti wọn gbà tẹle imọran Paulu pe wọn gbọdọ tẹriba fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga.
Siwaju sii, niwọn bi awọn ilana Kristian wọn bá ti gbà á láàyè tó, awọn Kristian ijimiji gbiyanju lati gbé ni alaafia pẹlu awọn aladuugbo wọn. Ṣugbọn eyi kò rọrùn. Ayé ti o yí wọn ká jẹ́ oniwa palapala ni ọ̀nà gbigbooro o sì ti yí araarẹ kítíkítí mọ́ ibọriṣa Griki-oun-Romu, eyi ti a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ijọsin olu-ọba kún. Ijọsin ibọriṣa Romu niti gidi jẹ́ isin Ijọba Orilẹ-ede, nitori naa kíkọ̀ eyikeyii lati ṣe é ni a wò gẹgẹ bi ìṣòdì si Ijọba Orilẹ-ede. Nibo ni eyi fi awọn Kristian sí?
Ọjọgbọn ile-ẹkọ giga Oxford naa E. G. Hardy kọwe pe: “Tertullian ka ohun pupọ ti kò ṣeeṣe fun Kristian kan ti o fi ẹ̀rí-ọkàn bikita lẹsẹẹsẹ, gẹgẹ bi eyi ti o ní ibọriṣa ninu: fun apẹẹrẹ, ibura ti o sábà maa ń wà nibi adehun iṣẹ́; títanná sí ara ilẹkun nigba awọn ajọdun, ati bẹẹ bẹẹ lọ; gbogbo awọn ajọdun Ibọriṣa; awọn eré idaraya ati ibi iṣere; iṣẹ akọmọọṣe ti kikọni ní ọ̀nà ikọwe ayé [ti awọn abọgibọpẹ igbaani]; iṣẹ-isin ologun; awọn ipo ilu.”—Christianity and the Roman Government.
Bẹẹni, ó ṣoro lati gbé ninu ayé Romu láìdalẹ̀ igbagbọ Kristian. Onkọwe Katoliki ọmọ ilẹ France naa A. Hamman kọwe pe: “Kò ṣeeṣe lati ṣe ohunkohun laikoju oriṣa kan. Ipo iduro Kristian ń mú awọn iṣoro ojoojumọ wá fun un; oun kò tẹ̀ sí ibi ti gbogbo eniyan tẹ̀ sí . . . Ó dojukọ awọn iṣoro ti ń yọju leralera ninu agbo ile, ni awọn opopona, ni ọjà . . . Ni opopona, yala ó jẹ́ ọmọ ibilẹ Romu tabi bẹẹkọ, Kristian kan gbọdọ ṣí fìlà ti o bá ń kọja niwaju tẹmpili tabi ère kan. Bawo ni oun ṣe lè yẹra fun ṣiṣe bẹẹ laipe afiyesi, sibẹ bawo ni oun ṣe lè juwọsilẹ lai dẹṣẹ ijọsin ọba? Bi oun bá ni iṣẹ ti aini sì wà fun un lati yá owó, oun nilati búra fun ayanilowo naa ni orukọ awọn ọlọrun. . . . Bi oun bá tẹwọgba ipo kan lẹnu iṣẹ, a reti pe ki o ṣe irubọ kan. Bi a bá fi ṣe ọmọ-ogun, bawo ni oun ṣe lè yẹra fun bibura ati lilọwọ ninu awọn ààtò iṣẹ-isin ológun?”—La vie quotidienne des premiers chrétiens (95-197) (Igbesi-aye Ojoojumọ Laaarin Awọn Kristian Akọkọbẹrẹ, 95 si 197 C.E.).
Awọn Ọlọ̀tọ̀ Rere, Sibẹ A Ṣe Kèéta Wọn
Ni nǹkan bii 60 tabi 61 C.E., nigba ti Paulu wà ni Romu ti o ń duro de igbẹjọ lọdọ Olu-ọba Nero, awọn saraki Ju sọ nipa awọn Kristian ijimiji pe: “Nitori bi o ṣe ti isin iyapa yii ni, awa mọ̀ pe, nibi gbogbo ni a ń sọrọ lodi si i.” (Iṣe 28:22) Akọsilẹ isin jẹrii sii pe awọn Kristian ni a sọrọ lodi si—ṣugbọn o jẹ lọna ti kò bá ẹ̀tọ́ mu. Ninu iwe rẹ̀ The Rise of Christianity, E. W. Barnes rohin pe: “Ninu awọn iwe rẹ̀ ijimiji ti o ní ọla-aṣẹ ajọ Kristian ni a sọrọ rẹ̀ gẹgẹ bi eyi ti o dara ni iwarere ti o sì jẹ́ olupa ofin mọ́. Awọn mẹmba rẹ̀ daniyan lati jẹ́ ọlọ̀tọ̀ rere ati aduroṣinṣin ọmọ-abẹ. Wọn kẹhin sí awọn ikuna ati aleebu ibọriṣa. Ninu igbesi-aye wọn ni ikọkọ wọn ń wá ọ̀nà lati jẹ aladuugbo ti kìí fa ìjọ̀ngbọ̀n ati ọ̀rẹ́ ti o ṣeé gbẹkẹle. A kọ́ wọn lati jẹ́ onironu ati oniwọntunwọnsi, oṣiṣẹ alaapọn ti o sì ń gbe igbesi-aye mimọ tonitoni. Laaarin iwa ibajẹ ati iwa ailakooso ti o wọ́pọ̀, bí wọn bá jẹ́ aduroṣinṣin si awọn ilana wọn, wọ́n jẹ alailaboosi ati oloootọ. Ọpa-idiwọn wọn niti ibalopọ takọtabo ga: ìdè igbeyawo ni a bọ̀wọ̀ fun ti igbesi-aye idile sì jẹ́ mímọ́. Pẹlu iru awọn iwarere bẹẹ, ni ẹnikan lè ti ronu, wọn kò lè ti jẹ́ ọlọ̀tọ̀ ti ń yọnilẹnu. Sibẹ fun ìgbà pípẹ́ ni a fi kẹ́gàn, ṣe kèéta ti a si koriira wọn.”
Gan-an gẹgẹ bi ayé igbaani kò ti loye Jesu, kò loye awọn Kristian ó sì titori bẹẹ koriira wọn. Niwọn bi wọn ti kọ̀ jalẹ lati jọsin olu-ọba ati awọn ọlọrun oriṣa, a fẹsun aigbagbọ ninu Ọlọrun kàn wọn. Bi ijamba kan bá ṣẹlẹ, awọn ni a ń di ẹ̀bi rù fun mímú inu bí awọn ọlọrun. Nitori pe wọn kò lọ sibi awọn eré iwapalapala tabi awọn afihan eléré ìjà iku ti o ní itajẹsilẹ ninu, a kà wọn si aláìtúraká, àní ‘olukoriira iran eniyan.’ Awọn ọ̀tá wọn sọ pe “ẹ̀ya” isin Kristian ń tú awọn idile ká ó sì titori naa jẹ́ ewu si ifẹsẹmulẹ ẹgbẹ-oun-ọgba. Tertullian sọ nipa awọn ọkọ abọriṣa ti wọn yàn pe ki awọn aya wọn dẹṣẹ panṣaga ju pe ki wọn di Kristian lọ.
A ṣe lámèyítọ́ awọn Kristian nitori pe wọn lodisi iṣẹyun, eyi ti a ń ṣe lọna wiwọpọ ni akoko naa. Sibẹ, awọn ọ̀tá wọn fẹsun ṣiṣekupa awọn ọmọde kàn wọn. A sọ laisi ẹ̀rí pe ni awọn ipade wọn wọ́n mu ẹ̀jẹ̀ awọn ọmọde ti a fi rubọ. Ní akoko kan-naa, awọn ọ̀tá wọn gbiyanju lati fipá mú wọn lati jẹ sọ́sééjì ẹlẹ́jẹ̀, ní mímọ̀ pe eyi lodisi ẹ̀rí-ọkàn wọn. Nipa bayii awọn alatako wọnyi tako ẹ̀sùn tiwọn funrawọn.—Tertullian, Apology, ori 9.
A Kẹ́gàn Wọn Gẹgẹ bi Ẹ̀ya Titun Kan
Opitan Kenneth Scott Latourette kọwe pe: “Sibẹ awọn ẹ̀sùn miiran fi isin Kristian sabẹ ẹ̀sín nitori ipilẹṣẹ rẹ̀ ti kò pẹ́ ti a sì fiwera pẹlu ìlọ́jọ́lórí awọn alábàádíje rẹ̀ [Isin awọn Ju ati isin ibọriṣa Griki-oun-Romu].” (A History of the Expansion of Christianity, Idipọ 1, oju-iwe 131) Ní ibẹrẹ ọrundun keji C.E., opitan Romu naa Suetonius pe isin Kristian ni “igbagbọ asán titun ti o sì níkà ninu.” Tertullian jẹrii sí i pe orukọ naa gan-an Kristian ni a koriira ati pe awọn Kristian jẹ́ ẹ̀ya kan ti a kò nifẹẹ si. Ní sisọrọ nipa ọ̀nà ti awọn oṣiṣẹ Ilẹ-ọba Romu gbà wo awọn Kristian ni ọrundun keji, Robert M. Grant kọwe pe: “Oju-iwoye ipilẹṣẹ ni pe isin Kristian wulẹ jẹ́ isin kan ti kò pọndandan, ti o sì ṣeeṣe ki o jẹ́ apanilara.”—Early Christianity and Society.
A Fẹ̀sùn Fífi Jàgídíjàgan Sọni Di Aláwọ̀ṣe Kàn Wọn
Ninu iwe rẹ̀ Les premiers siècles de l’Eglise (Awọn Ọrundun Iṣaaju ti Ṣọọṣi), ọjọgbọn ile-ẹkọ yunifasiti Sorbonne, Jean Bernardi kọwe pe: “[Awọn Kristian] nilati jade lọ ki wọn sì sọrọ nibi gbogbo ati si ẹni gbogbo. Ni awọn gbangba oju-ọna ati ni awọn ilu-nla, ni awọn gbangba gbalasa ati ni awọn ile. Bi a bá gbà wọn wọle tabi bi a kò bá gbà wọn wọle. Si awọn talaka, ati si awọn ọlọ́rọ̀ ti awọn ohun-ìní wọn ń dí lọwọ. Si ẹni kekere ati si awọn gomina awọn ẹkun ilẹ Romu . . . Wọn nilati rinrin-ajo loju ọ̀nà, wọ ọkọ̀, ki wọn sì lọ si awọn ipẹkun ayé.”
Wọn ha ṣe eyi bi? Dajudaju wọn ṣe bẹẹ. Ọjọgbọn Léon Homo sọ pe èrò awọn ará ilu tako awọn Kristian ijimiji nitori “itara aláwọ̀ṣe” wọn. Ọjọgbọn Latourette sọ pe awọn Ju nigba ti wọn sọ itara wọn fun sisọni di aláwọ̀ṣe nù, “awọn Kristian, ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lọna jàgídíjàgan ti wọn sì tipa bẹẹ gbé ibinu dide.”
Ni ọrundun keji C.E., ọlọgbọn-imọ-ọran ará Romu naa Celsus ṣe lámèyítọ́ nipa ọ̀nà ti awọn Kristian ń gbà waasu. Ó sọ pe isin Kristian wà fun awọn ti wọn kò kàwé ati pe yoo ‘yí kiki awọn omugọ, ẹrú, obinrin, ati awọn ọmọ keekeeke lọkan pada.’ Ó fẹ̀sùn kan awọn Kristian fun kíkọ́ “awọn ti o rọrun lati yí lọkan pada” lẹkọọ, ni mimu ki wọn “gbagbọ laisi ironu jinlẹ.” Ó jẹwọ pe wọn sọ fun awọn ọmọlẹhin wọn titun pe: “Ẹ maṣe beere ibeere; ẹ wulẹ gbagbọ ni.” Sibẹ, gẹgẹ bi Origen ti sọ, Celsus fúnraarẹ̀ gbà pe “kìí ṣe awọn ti wọn kò kawe ati awọn ti ipo wọn rẹlẹ̀ nikan ni ẹkọ Jesu dari lati gba isin Rẹ̀.”
Kò Sí Wíwá Ìṣọkan Awọn Ṣọọṣi Agbaye
Awọn Kristian ijimiji ni a ṣe lámèyítọ́ wọn nitori pe wọn sọ pe awọn ní otitọ Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa. Wọn kò tẹwọgba wíwá ìṣọ̀kan awọn ṣọọṣi agbaye, tabi amulumala igbagbọ. Latourette kọwe pe: “Laidabi ọpọ awọn igbagbọ akoko naa, wọn [awọn Kristian] lodisi awọn isin miiran. . . . Yatọ si ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ ti o gbooro dé ìwọ̀n aaye kan ti o jẹ́ ìwà awọn olujọsin miiran, wọn polongo pe wọn ní otitọ ti kò ṣee sẹ́.”
Ní 202 C.E., Olu-ọba Septimius Severus gbé ofin kan jade ti ń dá awọn Kristian lẹ́kun lati maṣe yí awọn eniyan lọ́kàn pada. Bi o ti wu ki o ri, eyi kò dá wọn duro lati má waasu nipa igbagbọ wọn. Latourette ṣapejuwe abajade rẹ̀: “Ninu ìkọ̀jálẹ̀ rẹ̀ lati fohunṣọkan pẹlu ibọriṣa ti o gbode ati pẹlu ọpọ awọn àṣà ẹgbẹ-oun-ọgba ati awọn àṣà iwahihu ti akoko naa [isin Kristian ijimiji] ṣe igbekalẹ ifaramọra ati eto-ajọ kan ti o fi í sinu ìfagagbága lodi si awujọ. Iyapakuro naa gan-an ti o beere fun lati darapọ mọ́ ọn fun awọn onigbagbọ rẹ̀ ní idaniloju ti o parapọ jẹ́ orisun okun lodisi inunibini ati ti itara ni jijere awọn ti a yí lọ́kàn pada.”
Akọsilẹ ìtàn, nigba naa, ṣe kedere. Ni apá ti o pọ julọ, niwọn bi awọn Kristian ijimiji, ti ń sapa lati jẹ́ ọlọ̀tọ̀ rere ati lati gbé ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan, wọn kọ̀ jalẹ lati di ‘apakan ayé.’ (Johannu 15:19) Wọn ní ọ̀wọ̀ fun awọn alaṣẹ. Ṣugbọn nigba ti Kesari kà á leewọ fun wọn lati waasu, wọn kò ni ohun meji lati ṣe ju lati maa baa lọ ni wiwaasu. Wọn gbiyanju lati maa gbé ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan ṣugbọn wọn kọ̀ jalẹ lati fohunṣọkan lori awọn ilana iwarere ati iwa ibọriṣa awọn oloriṣa. Fun gbogbo eyi, a kẹ́gàn, ṣe kèéta, koriira, a sì ṣe inunibini si wọn, àní gẹgẹ bi Kristi ti sọtẹlẹ pe a óò ṣe si wọn.—Johannu 16:33.
Ǹjẹ́ iyasọtọ wọn kuro ninu ayé ha ń baa lọ bi? Tabi bi akoko ti ń lọ, ǹjẹ́ awọn wọnni ti wọn jẹwọ ṣiṣe isin Kristian ha yí ihuwasi wọn pada ninu eyi bi?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Ipo iduro Kristian mú awọn iṣoro ojoojumọ wá fun un; oun kò tẹ̀ sí ibi ti gbogbo eniyan tẹ̀ sí”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Isin Kristian [ni a ń fi] ṣẹ̀sín nitori ipilẹṣẹ rẹ̀ ti kò pẹ́ ti a sì fiwera . . . pẹlu ìlọ́jọ́lórí awọn alábàádíje rẹ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Nitori pe awọn Kristian kọ jalẹ lati jọsin olu-ọba Romu ati awọn ọlọrun oriṣa, a fẹ̀sùn aigbagbọ ninu wíwà Ọlọrun kàn wọn
[Credit Line]
Museo della Civiltà Romana, Roma
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní ni a mọ̀ gẹgẹ bi olufitara waasu ihin-iṣẹ Ijọba naa
[Picture Credit Line on page 2]
Cover: Alinari/Art Resource, N.Y.