Awọn Kristian ati Ẹgbẹ́ Awujọ Eniyan Lonii
“A o sì koriira yin lọdọ gbogbo orilẹ-ede nitori orukọ mi.”—MATTEU 24:9.
1. Ki ni ohun ti o yẹ ki o jẹ́ àmì ṣiṣekedere kan nipa isin Kristian?
IYASỌTỌ kuro ninu ayé jẹ àmì ṣiṣekedere kan nipa awọn Kristian igbaani. Ninu adura si Baba rẹ̀ ọrun, Jehofa, Kristi sọ nipa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Emi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fun wọn; ayé sì ti koriira wọn, nitori ti wọn kìí ṣe ti ayé, gẹgẹ bi emi kìí tií ṣe ti ayé.” (Johannu 17:14) Nigba ti a pè é siwaju Pontiu Pilatu, Jesu sọ pe: “Ijọba mi kìí ṣe ti ayé yii.” (Johannu 18:36) Iyasọtọ isin Kristian akọkọbẹrẹ kuro lara ayé ni Iwe Mimọ Kristian Lede Griki ati awọn opitan jẹrii si.
2. (a) O ha yẹ ki iyatọ eyikeyii wà ninu ipo-ibatan laaarin awọn ọmọlẹhin Jesu ati ayé bi akoko ti ń lọ bi? (b) Ijọba Jesu yoo ha dé nipasẹ iyipada awọn orilẹ-ede bi?
2 Jesu lẹhin-ọ-rẹhin ha ṣí i payá pe iyipada yoo wà ninu ibatan ti ó wà laaarin awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ati ayé ati pe Ijọba rẹ̀ yoo de nipasẹ yiyi araye pada si isin Kristian bi? Bẹẹkọ. Kò si ohunkohun ti a misi awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati kọ lẹhin iku Jesu ti ó tilẹ mẹnuba iru nǹkan bẹẹ paapaa. (Jakọbu 4:4 [ti a kọ ni ìgbà kukuru ṣaaju 62 C.E.]; 1 Johannu 2:15-17; 5:19 [ti a kọ ni nǹkan bi 98 C.E.]) Ni odikeji, Bibeli so “wíwàníhìn-ín” ati “dídé” Jesu ti o tẹlee ninu agbara Ijọba pọ mọ́ “opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi,” eyi ti yoo dé ogogoro pẹlu “opin,” tabi iparun rẹ̀. (Matteu 24:3, 14, 29, 30, NW; Danieli 2:44; 7:13, 14) Ninu ami ti Jesu fifunni nipa pa·rou·siʹa, tabi wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ pe: “Nigba naa ni wọn ó fi yin funni lati jẹ niya, wọn ó sì pa yin: a o sì koriira yin lọdọ gbogbo orilẹ-ede nitori orukọ mi.”—Matteu 24:9.
Awọn Kristian Tootọ Lonii
3, 4. (a) Bawo ni iwe gbédègbéyọ̀ Katoliki kan ṣe ṣapejuwe awọn Kristian ijimiji? (b) Ni ọ̀nà ti o jọra wo ni a gbà ṣapejuwe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati awọn Kristian ijimiji?
3 Awujọ isin wo lonii ni o ti jèrè orukọ rere fun araarẹ fun iduroṣinṣin si awọn ọpa-idiwọn Kristian ati iyasọtọ kuro ninu ayé yii, ti a koriira awọn mẹmba rẹ̀ ti a sì ń ṣe inunibini si wọn? Ó dara eto-ajọ Kristian wo kaakiri agbaye ni o baramu ni gbogbo ọ̀nà pẹlu apejuwe onitan ti awọn Kristian igbaani? Nipa awọn wọnyi, New Catholic Encyclopedia sọ pe: “Awọn ẹgbẹ́ awujọ Kristian akọkọbẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe a kọkọ kà wọn si ẹ̀ya isin miiran kan lati inu sakaani awọn Ju wá, jẹ eyi ti o fẹ̀rí jíjẹ́ alailẹgbẹ hàn ninu ẹkọ-isin rẹ̀, paapaa julọ ninu itara awọn mẹmba rẹ̀, awọn ti wọn sìn gẹgẹ bi ẹlẹ́rìí fun Kristi ‘ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ̀-ayé.’ (Iṣe 1.8).”—Idipọ 3, oju-iwe 694.
4 Ṣakiyesi awọn ọ̀rọ̀ naa “kà . . . si ẹ̀ya isin miiran kan,” “jẹ eyi ti o fẹ̀rí jíjẹ́ alailẹgbẹ hàn ninu ẹkọ-isin rẹ̀,” “itara . . . gẹgẹ bi ẹlẹ́rìí.” Ki o sì wá wo bi iwe gbedegbẹyọ yẹn kan-naa ṣe ṣapejuwe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa: “Ẹ̀ya isin kan . . . awọn Ẹlẹ́rìí ni wọn gbagbọ jinlẹ pe opin ayé yoo dé laaarin awọn ọdun diẹ kan. Igbagbọ mimuna yii dabi eyi ti o jẹ agbara isunniṣe ti o wà lẹhin itara aláìṣàárẹ̀ wọn. . . . Lajori iṣẹ-aigbọdọmaṣe mẹmba kọọkan ẹ̀ya isin yii ni lati jẹrii fun Jehofa nipa kikede Ijọba Rẹ̀ ti ń bọ̀. . . . Wọn ka Bibeli si orisun igbagbọ ati ilana ihuwa wọn kanṣoṣo . . . Lati jẹ Ẹlẹ́rìí tootọ ẹnikan gbọdọ waasu lọna ti o gbeṣẹ ni ọ̀nà kan tabi omiran.”—Idipọ 7, oju-iwe 864 si 865.
5. (a) Ni awọn ọ̀nà wo ni ẹkọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi jẹ́ alailẹgbẹ? (b) Funni ni awọn apẹẹrẹ ti ń fihàn pe igbagbọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà ni ìṣọ̀kan pẹlu Iwe Mimọ.
5 Ni awọn ọ̀nà wo ni ẹkọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà jẹ aláìlẹ́gbẹ́? Iwe New Catholic Encyclopedia mẹnukan diẹ pe: “Wọn [awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] dẹbi fun ẹkọ Mẹtalọkan gẹgẹ bi ibọriṣa keferi . . . Wọn ka Jesu si Ẹlẹ́rìí Jehofa titobi julọ, ‘ọlọrun kan’ (bẹẹ ni wọn ṣe tumọ Johannu 1.1), ti kò kere si ẹnikẹni ayafi Jehofa. . . . Ó kú gẹgẹ bi ọkunrin kan a sì jí i dide gẹgẹ bi Ọmọkunrin tẹmi kan ti o jẹ́ alaileeku. Ijiya ati iku rẹ̀ ni iye ti o san lati jere ẹ̀tọ́ lati maa gbe titi ayeraye lori ilẹ̀-ayé pada fun iran eniyan. Nitootọ, ‘ogunlọgọ eniyan’ (Iṣi. 7.9) ti awọn Ẹlẹ́rìí oloootọ ní ireti ninu Paradise ilẹ̀-ayé kan; kiki 144,000 awọn oluṣotitọ (Iṣi. 7.4; 14.1, 4) lè gbadun ògo ti ọ̀run pẹlu Kristi. Awọn ẹni buburu yoo niriiri iparun yán-án-yán-án. . . . Iribọmi—tí awọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe nipa ìtẹ̀bọnú-omi . . . [jẹ́] àmì iṣapẹẹrẹ òde nipa iyasimimọ wọn fun iṣẹ-isin Jehofa Ọlọrun. . . . Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti gba afiyesi itagbangba nipa kíkọ ifajẹsinilara . . . Iwarere wọn nipa ti igbeyawo ati ibalopọ takọtabo duro ṣánṣán.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè jẹ́ alailẹgbẹ ni awọn ọ̀nà wọnyi, ṣugbọn ipo wọn lori gbogbo awọn kókó wọnyi ni a gbekari Bibeli lọna fifidimulẹ gbọnyin.—Orin Dafidi 37:29; Matteu 3:16; 6:10; Iṣe 15:28, 29; Romu 6:23; 1 Korinti 6:9, 10; 8:6; Ìfihàn 1:5.
6. Iduro wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dimu? Eeṣe?
6 Iwe Roman Katoliki yii fikun un pe ní 1965 (ọdun ti o hàn gbangba pe a kọ ọrọ-ẹkọ naa) “awọn Ẹlẹ́rìí naa kò kà á sí sibẹ pe wọn jẹ́ apakan ẹgbẹ́ awujọ ayé ninu eyi ti wọn ń gbé.” Ó jọ bii pe onṣewe naa ti ronu pe bí akoko ti ń lọ tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì ń di pupọ sii ti wọn sì bẹrẹ sii ní “irisi ṣọọṣi kan ni iyatọ si ti ẹ̀ya kan,” wọn yoo di apakan ayé yii. Ṣugbọn iru iyẹn kò tii ṣẹlẹ rí. Lonii, pẹlu eyi ti o fi ilọpo mẹrin rekọja iye awọn Ẹlẹ́rìí ti o wà ni 1965 lọ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti di iduro wọn mú laiyẹsẹ niti ọ̀ràn ayé yii. “Wọn kìí ṣe ti ayé,” gẹgẹ bi Jesu “kìí tií ṣe ti ayé.”—Johannu 17:16.
Wọn Yàtọ̀ Ṣugbọn Wọn Kìí Ṣe Akóguntini
7, 8. Bi o ti jẹ́ otitọ nipa ti awọn Kristian ijimiji, ki ni o jẹ́ otitọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii?
7 Ní titọka si ìgbèjà awọn Kristian ijimiji lati ẹnu agbèjà ìgbàgbọ́ ti ọrundun keji naa Justin Martyr, Robert M. Grant kọ ninu iwe rẹ̀ Early Christianity and Society pe: “Bi awọn Kristian bá jẹ́ olùyí-ìpìlẹ̀-padà wọn kìí fipá ṣe é. . . . Wọn jẹ́ oluranlọwọ didara julọ fun olu-ọba ninu ọ̀ràn ti pipa alaafia ati eto rere mọ́.” Bakan naa, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ni a mọ̀ jakejado ayé pe wọn jẹ olufẹ alaafia ati ọmọ orilẹ-ede rere. Awọn ijọba, iru eyikeyii, mọ̀ pe wọn kò ni ohunkohun lati bẹru lati ọ̀dọ̀ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
8 Oluyẹwoṣatunṣe iwe-irohin Ariwa America kan kọwe pe: “Ironuwoye ti a fi oríkunkun ati aifọkantanni dìmú ni yoo mú ki a gbagbọ pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń halẹ iru ewu eyikeyii kan mọ́ ijọba oṣelu eyikeyii; wọn kìí ṣe adojú-ìjọba-dé wọ́n sì jẹ́ olufẹ alaafia gẹgẹ bi ẹgbẹ́ isin kan ti lè jẹ́.” Ninu iwe rẹ̀ L’objection de conscience (Ikọjalẹ Àfẹ̀rí-Ọkàn Ṣe), Jean-Pierre Cattelain kọwe pe: “Awọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ olutẹriba si awọn alaṣẹ lọna pipe ati lakoopọ wọn ń pa awọn ofin mọ́; wọn ń san owó-orí wọn, wọn kò si wá ọ̀nà lati beere, pààrọ̀, tabi ba awọn ijọba jẹ́, nitori pe wọn kò daamu araawọn pẹlu awọn alaamọri ayé yii.” Cattelain ń baa lọ lati fikun un pe kiki bi Ijọba bá beere iwalaaye wọn, eyi ti wọn ti yasimimọ fun Ọlọrun, ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa maa ń kọ̀ jalẹ lati ṣegbọran. Ninu eyi wọn jọra pẹkipẹki pẹlu awọn Kristian ijimiji.—Marku 12:17; Iṣe 5:29.
Agbo Awọn Alakooso Ṣì Wọn Lóye
9. Nipa ti iyasọtọ kuro ninu ayé, ki ni iyatọ titayọ kan ti o wà laaarin awọn Kristian ijimiji ati awọn Katoliki ode-oni?
9 Pupọ julọ lara awọn olu-ọba Romu ṣi awọn Kristian ijimiji lóye wọn sì ṣe inunibini si wọn. Ní fifi idi ti o fi rí bẹẹ hàn, The Epistle to Diognetus, tí awọn kan lero pe o ti wà lati ọrundun keji C.E., polongo pe: “Awọn Kristian ń gbé ninu ayé, ṣugbọn wọn kìí ṣe apakan ayé.” Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, Igbimọ Vatican Keji, ninu Ofin Igbagbọ Alaifẹsẹmulẹ rẹ̀ Lori Ṣọọṣi, sọ pe awọn Katoliki gbọdọ “wá ijọba Ọlọrun nipa lilọwọ ninu awọn alaamọri ti kìí ṣe ti isin” ki wọn sì “ṣiṣẹ fun iyasimimọ ayé lati inu wá.”
10. (a) Oju wo ni agbo awọn alakooso fi wo awọn Kristian ijimiji? (b) Oju wo ni a sábà fi ń wo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ki si ni ihuwapada wọn?
10 Opitan E. G. Hardy sọ pe awọn olu-ọba Romu ka awọn Kristian ijimiji sí “awọn onitara alainilaari lọna kan.” Opitan ọmọ ilẹ France naa Étienne Trocmé sọ nipa “bi awọn ọ̀làjú Griki ati oṣiṣẹ ará Romu ti fojú tín-ín-rín ohun ti wọn kà sí ẹ̀ya isin Gabasi ti o ṣajeji gidigidi [awọn Kristian].” Ikọwe ranṣẹ laaarin Pliny eyi Àbúrò, gomina Romu ti Bithynia, ati Olu-ọba Trajan fihàn pe agbo awọn alakooso lapapọ kò mọ iru ohun ti isin Kristian jẹ́ niti gidi. Bakan naa lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a sábà maa ń ṣì loye ti agbo awọn alakooso ayé tilẹ maa ń kẹgan. Bi o ti wu ki o ri, eyi ko yà awọn Ẹlẹ́rìí lẹnu kò si dáyàfò wọn.—Iṣe 4:13; 1 Peteru 4:12, 13.
“Nibi Gbogbo Ni A Ń Sọrọ Lodi Sí I”
11. (a) Awọn ohun wo ni a sọ nipa awọn Kristian ijimiji, ki sì ni a ti sọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? (b) Eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò fi kopa ninu oṣelu?
11 A sọ nipa awọn Kristian ijimiji pe: “Bi o ṣe ti isin ìyapa yii ni awa mọ̀ pe nibi gbogbo ni a ń sọrọ lodi si i.” (Iṣe 28:22) Ni ọrundun keji C.E., Celsus abọriṣa fi idaniloju sọ pe kìkì awọn ẹ̀dá ti kò wulo julọ laaarin awujọ eniyan ni isin Kristian ń fà mọra. Bakan naa a ti sọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pe “fun apa ti o pọ julọ, a kó wọn jọ lati inu awọn aláìníláárí ninu awujọ wa.” Opitan nipa ṣọọṣi Augustus Neander rohin pe “awọn Kristian ni a fihàn gẹgẹ bi oku eniyan si ayé, ti wọn kò sì wulo fun gbogbo alaamọri igbesi-aye; . . . a si beere pe, ki ni yoo ṣẹlẹ sí iṣẹ amuṣe igbesi-aye, bi eniyan gbogbo bá dabi wọn?” Nitori pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yẹra kuro ninu lilọwọ ninu oṣelu, a sábà maa ń fẹsun jíjẹ́ aláìwúlò ninu ẹgbẹ́ awujọ araye kàn wọn. ṣugbọn bawo ni wọn ṣe lè jẹ́ alákitiyan ninu iṣẹ́ oṣelu ati lakooko kan-naa ki wọn sì jẹ́ alagbawi Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye? Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ọ̀rọ̀ aposteli Paulu naa sọkan pe: “Ṣajọpin ninu ijiya gẹgẹ bi ọmọ-ogun rere ti Kristi Jesu. Kò si ọmọ-ogun kan lẹnu iṣẹ-isin ti ń kowọnu awọn ilepa ara ilu, niwọn bi o ti jẹ́ pe gongo ilepa rẹ̀ ni lati tẹ́ ẹni ti o gbà á si iṣẹ ológun lọrun.”—2 Timoteu 2:3, 4, Revised Standard Version, Ẹ̀dà Ìwáṣọ̀kan Awọn Ṣọọṣi Agbaye.
12. Ní apa pataki iyasọtọ wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi jọ awọn Kristian ijimiji?
12 Ninu iwe rẹ̀ A History of Christianity, Ọjọgbọn K. S. Latourette kọwe pe: “Ọ̀kan ninu awọn ọ̀ràn lori eyi ti awọn Kristian ijimiji kò fi wà ni iṣọkan pẹlu ayé Griki-oun-Romu ni ikopa ninu ogun. Fun ọrundun mẹta akọkọ kò si akọsilẹ Kristian kan ti o tíì laaja dé akoko wa ti o gbọ̀jẹ̀gẹ́ fun ikopa awọn Kristian ninu ogun.” Iwe Edward Gibbon The History of the Decline and Fall of the Roman Empire sọ pe: “Laiṣe pe wọn kọ ìṣe kan ti o tubọ jẹ́ mímọ́ silẹ, kò ṣeeṣe pe ki awọn Kristian gba ipo jagunjagun, adajọ, tabi awọn ọmọ-aládé.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bakan naa gba ipo aidasitọtuntosi alaijuwọsilẹ, wọn sì tẹle awọn ilana Bibeli ti a là silẹ ninu Isaiah 2:2-4 ati Matteu 26:52.
13. Ẹ̀sùn wo ni a fikan awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣugbọn ki ni awọn otitọ fihàn?
13 A fẹsun kan awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lati ọ̀dọ̀ awọn ọ̀tá wọn fun títú awọn idile ká. Loootọ, awọn ọ̀ràn nipa awọn idile ti wọn di eyi ti o pinya nigba ti mẹmba rẹ̀ kan tabi ju bẹẹ lọ bá di Ẹlẹ́rìí Jehofa wà. Jesu sọtẹlẹ pe eyi yoo ṣẹlẹ. (Luku 12:51-53) Bi o ti wu ki o ri, iṣiro fihàn pe awọn igbeyawo ti ó tuka nitori idi yii jẹ́ àyàfi. Laaarin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni France, fun apẹẹrẹ, ọ̀kan ninu awọn tọkọtaya mẹta ní olùbáṣègbéyàwó kan ti kìí ṣe Ẹlẹ́rìí ninu. Sibẹ, ìwọ̀n ikọsilẹ laaarin awọn igbeyawo Ẹlẹ́rìí pẹlu ẹni ti kìí ṣe Ẹlẹ́rìí wọnyi kò ga tó ipindọgba ikọsilẹ ni orilẹ-ede naa. Eeṣe? Aposteli Paulu ati Peteru fun awọn Kristian ti wọn ṣegbeyawo pẹlu awọn alaigbagbọ ni imọran ọlọgbọn ti a misi, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì ń saakun lati tẹle ọ̀rọ̀ wọn. (1 Korinti 7:12-16; 1 Peteru 3:1-4) Bi igbeyawo pẹlu alaigbagbọ kan bá tuka, igbesẹ naa fẹrẹẹ sábà maa ń wá lati ọ̀dọ̀ ẹnikeji ti kìí ṣe Ẹlẹ́rìí naa. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ọpọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn igbeyawo ni a ti gbàlà nitori pe awọn alabaaṣegbeyawo naa di Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn sì bẹrẹ sii fi awọn ilana Bibeli silo ninu igbesi-aye wọn.
Kristian Ni Wọ́n, Wọn Kìí Ṣe Onigbagbọ Mẹtalọkan
14. Ẹ̀sùn wo ni a fikan awọn Kristian ijimiji, eesitiṣe ti eyi fi jẹ́ ẹ̀dà-ọ̀rọ̀?
14 Ẹ̀dà-ọ̀rọ̀ ni pe ní Ilẹ-ọba Romu, ọ̀kan ninu awọn ẹ̀sùn ti a fikan awọn Kristian ijimiji ni pe wọn jẹ́ alaigbagbọ ninu wíwà Ọlọrun. Dokita Augustus Neander kọwe pe: “Awọn ti wọn sẹ́ awọn ọlọrun oriṣa, awọn alaigbagbọ ninu wíwà Ọlọrun, . . . ni orukọ ti o wọ́pọ̀ ti a fi sami si awọn Kristian laaarin awọn eniyan.” Ẹ wo bi o ti ṣajeji tó pe awọn Kristian, ti wọn ń jọsin Ẹlẹdaa alààyè ni awọn abọriṣa ti wọn kò jọsin ọlọrun eyikeyii, “ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ eniyan . . . igi ati okuta” nilati pe ni alaigbagbọ ninu wíwà Ọlọrun.—Isaiah 37:19.
15, 16. (a) Ki ni awọn onisin kan ti sọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣugbọn ibeere wo ni eyi gbé dide? (b) Ki ni fihàn pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ Kristian nitootọ?
15 Bakan naa ni otitọ naa pe lonii awọn alaṣẹ kan ninu Kristẹndọm kò gbà pé awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ Kristian jẹ́ ẹ̀dà-ọ̀rọ̀. Eeṣe? Nitori pe awọn Ẹlẹ́rìí kọ̀ Mẹtalọkan. Gẹgẹ bi itumọ Kristẹndọm ti ó gbè sápákan, “awọn Kristian ni awọn wọnni ti wọn gba Kristi gẹgẹ bi Ọlọrun.” Ni itakora si eyi, iwe atumọ-ede igbalode kan tumọ ọ̀rọ̀ orukọ naa “Kristian” sí “ẹnikan ti o gbagbọ ninu Jesu Kristi ti o si ń tẹle awọn ẹkọ rẹ̀” ati “isin Kristian” gẹgẹ bi “isin kan ti a gbekari awọn ẹkọ Jesu Kristi ati igbagbọ naa pe oun ni ọmọkunrin Ọlọrun.” Awujọ wo ni o bá itumọ yii mu lọna ṣiṣe timọtimọ ju?
16 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹwọgba ẹ̀rí Jesu funraarẹ nipa ẹni ti oun jẹ́. Ó sọ pe: “Ọmọ Ọlọrun ni emi í ṣe,” kìí ṣe “Ọlọrun Ọmọ ni emi í ṣe.” (Johannu 10:36, ẹ̀dà ti 1969; fiwe Johannu 20:31.) Wọn gba ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ti a misi naa nipa Kristi pe: “Ẹni ti, bi o ti jẹ́ aworan Ọlọrun, kò ka ibaradọgba pẹlu Ọlọrun si ohun ti ó nilati gbámú.”a (Filippi 2:6, The New Jerusalem Bible) Iwe naa The Paganism in Our Christianity sọ pe: “Jesu Kristi kò mẹnukan iru ohun àrà bẹẹ rí [Mẹtalọkan abáradọ́gba kan], kò sì sí ibi kankan ninu Majẹmu Titun ti ọ̀rọ̀ naa ‘Mẹtalọkan’ ti farahan. Ero naa ni Ṣọọṣi wulẹ gbà ni ọgọrun-un ọdun mẹta lẹhin iku Oluwa wa; ati pe ipilẹṣẹ ironu naa jẹ́ ti ibọriṣa patapata.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹwọgba ẹkọ Bibeli nipa Kristi. Kristian ni wọn, awọn kìí ṣe onigbagbọ Mẹtalọkan.
Kò Sí Wíwá Ìṣọ̀kan Pẹlu Awọn Ṣọọṣi Agbaye
17. Eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò fi fọwọsowọpọ pẹlu igbokegbodo wíwá ìṣọ̀kan ṣọọṣi agbaye, tabi amulumala igbagbọ?
17 Awọn awawi meji miiran ti a ṣe lodisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni pe wọn kọ̀ jalẹ lati kopa ninu igbokegbodo wíwá ìṣọ̀kan awọn ṣọọṣi agbaye ati pe wọn lọwọ ninu ohun ti a fun lorukọ naa “fífi jàgídíjàgan sọni di aláwọ̀ṣe.” Awọn ẹ̀gàn mejeeji wọnyi ni a fi ipá bù lu awọn Kristian ijimiji pẹlu. Kristẹndọm, pẹlu awọn Katoliki, Orthodox, ati Protẹstanti ti o parapọ wà ninu rẹ̀, lọna ti kò ṣee sẹ́ jẹ́ apakan ayé yii. Bii ti Jesu, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa “kìí ṣe ti ayé.” (Johannu 17:14) Bawo ni wọn ṣe lè tipasẹ awọn àjọ igbokegbodo alámùúlùmálà igbagbọ so araawọn pọ̀ mọ́ awọn eto-ajọ isin ti wọn ń gbé iwa ati igbagbọ ti kìí ṣe ti Kristian lárugẹ?
18. (a) Eeṣe ti a kò fi lè ṣe lámèyítọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun títànmọ́-òn pe awọn nikan ni wọn ń ṣe isin tootọ? (b) Nigba ti wọn gbagbọ pe awọn ní isin tootọ, ki ni awọn Roman Katoliki kò ní?
18 Ta ni o lè fi pẹlu idalare ṣe lámèyítọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun gbigbagbọ, bí awọn Kristian akọkọbẹrẹ ti ṣe, pe awọn nikan ni wọn ń ṣe isin tootọ kanṣoṣo naa? Àní Ṣọọṣi Katoliki paapaa, nigba ti o ń fi agabagebe jẹwọ pe oun ń fọwọsowọpọ pẹlu igbokegbodo wíwá ìṣọ̀kan awọn ṣọọṣi, polongo pe: “Awa gbagbọ pe isin tootọ kanṣoṣo yii ń baa lọ lati maa wà ninu Ṣọọṣi Katoliki ati Apostoliki, eyi ti Oluwa Jesu fa iṣẹ títàn án kálẹ̀ laaarin gbogbo eniyan lé lọwọ nigba ti o sọ fun awọn aposteli pe: ‘Nitori naa ẹ lọ ki ẹ maa sọ awọn orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin.’” (Igbimọ Vatican II, “Ipolongo Lori Ominira Isin”) Bi o ti wu ki o ri, lọna ti o hàn gbangba iru igbagbọ bẹẹ kò tó lati fi itara aláìsàárẹ̀ sinu awọn Katoliki fun titẹsiwaju lati sọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin.
19. (a) Ki ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti pinnu lati ṣe, pẹlu isunniṣe wo si ni? (b) Ki ni a o gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee?
19 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní iru itara bẹẹ. Wọn muratan lati maa baa lọ ni wiwaasu bi Ọlọrun bá ti fẹ́ ki wọn ṣe bẹẹ tó. (Matteu 24:14) Iwaasu wọn jẹ́ onitara ṣugbọn kìí ṣe oníjàgídíjàgan. O jẹ́ eyi ti a sún ṣiṣẹ nipasẹ ifẹ aladuugbo, kìí ṣe nipasẹ ikoriira araye. Wọn nireti pe ọpọ bi o bá ti lè ṣeeṣe tó ni a o gbala ninu araye. (1 Timoteu 4:16) Bii ti awọn Kristian ijimiji, wọn ń sakun lati “wà ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan.” (Romu 12:18) Ọ̀nà ti wọn ń gbé eyi gbà ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹlee.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun ijiroro ẹsẹ yii ni isopọ pẹlu ẹ̀kọ́ gbà-á-bẹ́ẹ̀ ti Mẹtalọkan, wo Ile-Iṣọ Na, March 15, 1973, oju-iwe 163 si 164.
Ní Ọ̀nà Atunyẹwo
◻ Ki ni a fi dá awọn Kristian ijimiji mọ̀ yatọ, bawo sì ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe jọ wọn?
◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbà fihàn pe wọn jẹ́ ọmọ orilẹ-ede rere?
◻ Oju wo ni agbo awọn alakooso fi wo awọn Kristian akọkọbẹrẹ, o ha ní iyatọ kankan lonii bi?
◻ Ki ni idaniloju awọn Ẹlẹ́rìí naa pe wọn ní otitọ sun wọn lati ṣe?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti pinnu lati maa bá wiwaasu lọ niwọn bi Ọlọrun bá ti fẹ́ ki wọn ṣe bẹẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Pilatu sọ pe: “Ẹ wò Ọkunrin naa!”—Ẹni naa ti kìí ṣe apakan ayé—Johannu 19:5
[Credit Line]
“Ecce Homo” lati ọwọ́ A. Ciseri: Florence, Galleria d’Arte Moderna / Alinari/Art Resource, N.Y.