Ìwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?
“Àwa ti gbà, kìí ṣe ẹ̀mí ti ayé, bíkòṣe Ẹ̀mí tíí ṣe ti Ọlọrun.”—1 KORINTI 2:12.
1, 2. Ìṣẹ̀lẹ̀ abaninínújẹ́ tí ó nííṣe pẹ̀lú gáàsì olóró wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bhopal, India, ṣùgbọ́n “gáàsì” aṣekúpani jù bẹ́ẹ̀ lọ́ wo ni a ń mí sínú kárí ayé?
NÍ ALẸ́ píparọ́rọ́ kan ní December 1984, ohun amúnigbọ̀nrìrì kan ṣẹlẹ̀ ní Bhopal, India. Ilé-iṣẹ́ kẹ́míkà kan wà ní ìlú-ńlá yẹn, fáàbù kan sì ṣiṣẹ́gbòdì nínú ọ̀kan lára àwọn táńkà tí wọ́n ń tọ́jú gáàsì sí, ní alẹ́ oṣù December yẹn. Lójijì, ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù gáàsì methyl isocyanate bẹ̀rẹ̀ síí tú sínú afẹ́fẹ́. Bí atẹ́gùn ti gbé e, gáàsì aṣekúpani yìí jà rànyìn wọ inú ilé lọ bá àwọn ìdílé tí ń sùn. Àwọn tí wọn kú wọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí púpọ̀ síi sì di aláàbọ̀ ara. Òun ni ìjábá ilé-iṣẹ́ tí o tíì burú jùlọ títí di àkókò yẹn.
2 Àwọn ènìyàn banújẹ́ nígbà tí wọn gbọ́ nípa Bhopal. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe jẹ́ aṣekúpani tó, gáàsì tí ó tú jáde níbẹ̀ pa ènìyàn kíkéré jọjọ ju iye tí ń kú nípa tẹ̀mí nítorí “gáàsì” kan tí àwọn ènìyàn kárí ayé ń mí sínú lójoojúmọ. Bibeli pè é ní “ẹ̀mí ti ayé.” Afẹ́fẹ́ aṣekúpani yẹn ni aposteli Paulu fi ìyàtọ̀ rẹ̀ wéra pẹ̀lú ẹ̀mí tí ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá nígbà tí ó wí pé: “Ṣùgbọ́n àwa ti gbà, kìí ṣe ẹ̀mí ti ayé, bíkòṣe Ẹ̀mí tíí ṣe ti Ọlọrun; kí àwa kí ó lè mọ ohun tí a fifún wa ní ọ̀fẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.”—1 Korinti 2:12.
3. Kí ni “ẹ̀mí ti ayé”?
3 Kí ni “ẹ̀mí ti ayé” náà gan-an? Bí ìwé The New Thayer’s Greek English Lexicon of the New Testament ti sọ, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” (Griki, pneuʹma) ní gbogbogbòò ni “ìtẹ̀sí tàbí agbára ìdarí tí ó kún inú ọkàn ẹnìkan tí ó sì ń ṣàkóso rẹ̀.” Ẹnìkan lè ní ẹ̀mí, tàbí ìtẹ̀sí rere tàbí búburú. (Orin Dafidi 51:10; 2 Timoteu 4:22) Ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan lè ní ẹ̀mí, tàbí ìtẹ̀sí lílágbára kan. Aposteli Paulu kọ̀wé sí Filemoni ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa wa kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.” (Filemoni 25) Lọ́nà jíjọra—ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n tí ó túbọ̀ gbòòrò—ayé ní gbogbogbòò ní ìtẹ̀sí lílágbára kan, èyí sì ni “ẹ̀mí ti ayé” tí Paulu mẹ́nukàn. Bí ìwé Word Studies in the New Testament ti Vincent ti sọ, “ẹ̀là-ọ̀rọ̀ naa túmọ̀sí ìlànà búburú tí ń sún ayé aláìfẹ́ẹ́ṣàtúnṣe ṣiṣẹ́.” Ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ náà ni ó gba ìrònú ayé kan tí ó sì fi tagbáratagbára nípalórí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà hùwà.
4. Ta ni orísun ẹ̀mí ti ayé, kí sì ni ìyọrísí tí ẹ̀mí yìí ní lórí ẹ̀dá ènìyàn?
4 Ẹ̀mí yìí jẹ́ onímájèlé. Èéṣe? Nítorí ó wá láti ọ̀dọ̀ “aládé ayé yìí,” Satani. Níti gidi, òun ni a pè ní “olùṣàkóso ọlá-àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú awọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Johannu 12:31; Efesu 2:2, NW) Ó nira láti bọ́ lọ́wọ́ “afẹ́fẹ́” tàbí “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Ó wà níbi gbogbo nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Bí a bá mí in sínú, a óò bẹ̀rẹ̀ síí ṣàmúlò àwọn ìṣarasíhùwà, àti góńgó rẹ̀. Ẹ̀mí ayé ń fúnni níṣìírí láti ‘gbé nípa ti ara,’ ìyẹn ni, ní ìbámu pẹ̀lú àìpé ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó jẹ́ aṣekúpani, “nítorí bí ẹ̀yin bá wà níti ara, ẹ̀yin óò kú.”—Romu 8:13.
Yíyẹra fún Ẹ̀mí Ayé Yìí
5. Báwo ni Ẹlẹ́rìí kan ṣe hùwà pẹ̀lú ọgbọ́n lákòókò ìjábá Bhopal náà?
5 Nígbà ìjábá ti Bhopal, Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ni agogo ìdágìrì àti òórùn akóninírìíra ti gáàsì onímájèlé náà jí lójú oorun. Láìfọ̀ràn falẹ̀ ó jí ìdílé rẹ̀ ó sì sáré kó wọn síta bọ́ sí ojú pópó. Ní dídúró díẹ̀ láti mọ ìhà ibi tí atẹ́gùn ti ń fẹ́ wá, ó foríla àárín àwọn èrò tí ìdààmú ti bá tí ó sì kó ìdílé rẹ̀ lọ sórí òkè kan lẹ́yìn odi ìlú náà. Níbẹ̀ ni wọ́n ti lè mí afẹ́fẹ́ tútù, mímọ́gaara tí ń fẹ́ wá láti inú adágún kan nítòsí sínú ẹ̀dọ̀fóró wọn.
6. Níbo ni a lè lọ láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí ti ayé?
6 Ibi gígasókè kan ha wà tí a lè lọ fún ìsádi kúrò lọ́wọ́ “afẹ́fẹ́” onímájèlé ayé yìí bí? Bibeli sọ pé ó wà. Ní wíwo iwájú sí ọjọ́ wa, wòlíì Isaiah kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, a óò fi òkè ilé Oluwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a óò sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò sì wọ́ sí inú rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò sì lọ, wọn ó sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, sí ilé Ọlọrun Jakọbu; Òun óò sì kọ́ wa ni ọ̀nà rẹ̀, àwa óò sì máa rìn ní ipa rẹ̀; nítorí láti Sioni ni òfin yóò ti jáde lọ, àti ọ̀rọ̀ Oluwa láti Jerusalemu.” (Isaiah 2:2, 3) Ibi gígasókè ti ìjọsìn mímọ́gaara, “òkè ilé Oluwa” tí a gbéga, ni ibi kanṣoṣo lórí plánẹ́ẹ̀tì yìí tí ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí onímájèlé, aséniléèémí ti ayé yìí. Níbẹ̀ ni ẹ̀mí Jehofa ti ń fẹ́ káàkiri fàlàlà láàárín àwọn Kristian olùṣòtítọ́.
7. Báwo ni a ti ṣe gba ọ̀pọ̀ là kúró lọ́wọ́ ẹ̀mí ti ayé?
7 Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti mí ẹ̀mí ayé yìí sínú tẹ́lẹ̀ ti gbádùn ìtùra tí ó jọra pẹ̀lú èyí tí Ẹlẹ́rìí ní Bhopal yẹn nírìírí rẹ̀. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọmọ àìgbọ́ràn” tí wọn mí afẹ́fẹ́, tàbí ẹ̀mí ayé yìí sínú, aposteli Paulu sọ pé: “Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ; àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Ọlọrun, ẹni tíí ṣe ọlọ́rọ̀ ní àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa . . . sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi.” (Efesu 2:3-5) Àwọn tí ó jẹ́ kìkì afẹ́fẹ́ onímájèlé ti ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí nìkan ni wọ́n ń mí sínú ti kú nípa tẹ̀mí. Bí ó ti wù kí ó rí, ọpẹ́ ni fún Jehofa, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lónìí ni wọ́n ń sá wá sí ibi gíga tẹ̀mí tí wọ́n sì ń yèbọ́ lọ́wọ́ ipò aṣekúpani yẹn.
Ìfarahàn Àwọn “Ẹ̀mí ti Ayé”
8, 9. (a) Kí ni fihàn pé a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra nígbà gbogbo fún ẹ̀mí ti ayé? (b) Báwo ni ẹ̀mí Satani ṣe lè sọ wa dìbàjẹ́?
8 Afẹ́fẹ́ aṣekúpani ti Satani ṣì ń jà rànyìn yí wa ká. A níláti ṣọ́ra kí a má baà yọ̀ wálẹ̀, padà sínú ayé, bóyá kí a fún wa pa nípa tẹ̀mí. Èyí ń béèrè fún ìwàlójúfò nígbà gbogbo. (Luku 21:36; 1 Korinti 16:13) Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa òtítọ́ yìí. Gbogbo àwọn Kristian ni wọ́n mọ àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Jehofa lórí ìwàhíhù dunjú tí wọn kò sì jẹ́ gbà pé àwọn àṣà aláìmọ́ bíi panṣágà, àgbèrè, àti ìbẹ́yà-kannáà lòpọ̀ ní ìtẹ́wọ́gbà. Síbẹ̀, lọ́dọọdún nǹkan bí 40,000 ènìyàn ni a ń yọlẹ́gbẹ́ kúrò nínú ètò-àjọ Jehofa. Èéṣe? Nínú ọ̀ràn púpọ̀ nítorí àwọn àṣà aláìmọ́ yìí kan-náà ni. Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀?
9 Nítorí tí gbogbo wa jẹ́ aláìpé. Ẹran ara jẹ́ aláìlera, tí a sì níláti fìgbà gbogbo bá àwọn ìtẹ̀sí èrò òdì tí ń wà sí ọkàn-àyà wa jà. (Oniwasu 7:20; Jeremiah 17:9) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìtẹ̀sí èrò òdì wọnnì ni ẹ̀mí ayé ń súnnásí. Ọ̀pọ̀ nínú ayé yìí kò rí ohun tí ó burú rárá nínú ìwàpálapàla, èrò náà pé ohun gbogbo ni ó bójúmu ti di apákan ìtẹ̀sí èrò-orí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Satani. Bí a bá ṣí ara wa sílẹ̀ sí irú ìrònú bẹ́ẹ̀, họ́wù, ṣíṣeéṣe lílágbára náà wà pé àwa yóò bẹ̀rẹ̀ síí ronú bíi ti ayé. Láìpẹ́ láìjìnnà, irú àwọn èrò àìmọ́ bẹ́ẹ̀ lè fa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó lè yọrísí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. (Jakọbu 1:14, 15) Àwa ìbá ti ṣáko kúrò ní òkè ìjọsìn mímọ́gaara Jehofa bọ́ sí àfonífojì ẹlẹ́gbin ti ayé Satani. Kò sí ẹnikẹ́ni tí o mọ̀ọ́mọ̀ dúró síbẹ̀ tí yóò jogún ìyè àìnípẹ̀kun.—Efesu 5:3-5, 7.
10. Kí ni ọ̀nà kan tí afẹ́fẹ́ Satani ń gbà farahàn, èésìtiṣe ti àwọn Kristian fi nílàti yẹra fún èyí?
10 Ẹ̀mí ayé hàn kedere níbi gbogbo ní àyíká wa. Fún àpẹẹrẹ, a tún rí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbé ìgbésí-ayé wọn pẹ̀lú ìṣarasíhùwà aláìlọ́wọ̀, ọlọ́rọ̀-ẹ̀gàn. Bí ìbànújẹ́ kíkorò ti bá wọn nítorí àwọn olóṣèlú oníwà ìbàjẹ́ tàbí aláìlóye kankan àti àwọn aṣáájú ìsìn oníwọra, oníwà pálapàla, wọ́n ń fi àfojúdi sọ̀rọ̀ àní nípa àwọn nǹkan ṣíṣe pàtàkì pàápàá. Àwọn Kristian ń gbéjàko irú ìtẹ̀sí yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ní agbára ìdẹ́rìn-ín-pani gbígbéniró, àwa ń yẹra fún mímú ẹ̀mí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn búburú wá sínú ìjọ. Ọ̀rọ̀ Kristian kan ń ṣàgbéyọ ìbẹ̀rù Jehofa àti ọkàn-àyà mímọ́gaara. (Jakọbu 3:10, 11; fiwé Owe 6:14.) Yálà a jẹ́ àgbà tàbí èwe, ọ̀rọ̀ wa níláti “dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí [àwa] kí ó lè mọ bí [a] óò ti máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.”—Kolosse 4:6.
11. (a) Kí ni apá kejì ẹ̀mí ti ayé? (b) Èéṣe tí àwọn Kristian fi yàtọ̀ sí àwọn tí wọn ṣàgbéyọ apá yìí?
11 Ìtẹ̀sí èrò wíwọ́pọ̀ mìíràn tí ń ṣàgbéyọ ẹ̀mí ayé yìí ni ìkórìíra. Ayé ni ìkórìíra àti ìjà ọlọ́jọ́ gbọọrọ tí ó jẹ́ nítorí ẹ̀yà-ìran, ẹ̀yà-èdè, ti orílẹ̀-èdè, àti aáwọ̀ láàárín ara-ẹni pàápàá ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ẹ wo bí nǹkan ti sàn jù níbi tí ẹ̀mí Ọlọrun ti ń ṣiṣẹ́! Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ máa pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. Bí ó lè ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ máa wà ni àlááfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Olùfẹ́, ẹ máṣe gbẹ̀san ara yin, ṣùgbọ́n ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìbínú; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Oluwa wí pé, Tèmi ni ẹ̀san, èmi óò gbẹ̀san. Ṣùgbọ́n bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu: ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ óò kó ẹyin iná lé e ní orí. Máṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.”—Romu 12:17-21.
12. Èéṣe tí àwọn Kristian fi yẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì?
12 Ẹ̀mí ayé yìí tún ń súnni sí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Bí ètò ìṣòwò ayé ti fún wọn níṣìírí, ọ̀pọ̀ ni àwọn ẹ̀rọ titun, aṣọ ìgbàlódé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ti gbà lọ́kàn. “Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” ti mú wọn nígbèkùn. (1 Johannu 2:16) Ọ̀pọ̀ ń díwọ̀n àṣeyọrísírere wọn nínú ìgbésí-ayé pẹ̀lú bí ilé wọn ti tóbi tó tàbí bí owó wọn ní báǹkì ti pọ̀ tó. Àwọn Kristian, tí ń mí afẹ́fẹ́ tẹ̀mí mímọ́gaara sínú ní òkè ìjọsìn Jehofa tí a gbéga sókè, ń gbéjàko ìtẹ̀sí èrò yìí. Wọ́n mọ̀ pé fífi ìpinnu lílágbára lépa àwọn nǹkan ti ara lè panirun. (1 Timoteu 6:9, 10) Jesu rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ létí pé: “Ìgbésí-ayé ènìyàn kìí dúró nípa ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”—Luku 12:15.
13. Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ ní àfikún tí ẹ̀mí ti ayé yìí ń gbà farahàn?
13 Àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí “afẹ́fẹ́” ayé yìí tí kò gbéniró ń gbà farahàn. Ọ̀kan ni ẹ̀mí ọ̀tẹ̀. (2 Timoteu 3:1-3) Ìwọ ha ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kìí fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ mọ́? Ìwọ ha ti ṣàkíyèsí àṣà àìfẹ́ṣẹ́ṣe tí ó tàn kálẹ̀ níbi iṣẹ́ ounjẹ òòjọ́ rẹ àyàfi bí ẹnìkan bá ń ṣọ́ni níti gidi? Àwọn ènìyàn mélòó ni o mọ̀ tí wọn ti rú òfin—bóyá kí wọn rẹ́nijẹ lórí ìwé owó-orí tàbí kí wọ́n jalè níbi iṣẹ́? Bí ìwọ bá ṣì ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́, a ha ti fìgbàkanrí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ láti ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe nítorí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ń kẹ́gàn àwọn tí wọn ń ṣàṣeyọrí níti ẹ̀kọ́-ìwé bí? Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ìfarahàn ẹ̀mí ayé tí àwọn Kristian gbọ́dọ̀ gbéjàkò.
Bí A Ṣe Lè Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé
14. Ní ọ̀nà wo ni àwọn Kristian fi yàtọ̀ sí àwọn tí kìí ṣe Kristian?
14 Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni àwa ṣe lè gbéjàko ẹ̀mí ayé nígbà tí àwa gan-an ń gbé nínú ayé? Àwa níláti rántí pé láìka ibi tí a lè wà nípa ti ara sí, àwa kìí ṣe apákan ayé nípa tẹ̀mí. (Johannu 17:15, 16) Góńgó wa kìí ṣe góńgó ti ayé yìí. Ojú-ìwòye wa nípa àwọn nǹkan yàtọ̀. Àwa jẹ́ ènìyàn tẹ̀mí, tí ń sọ̀rọ̀ tí ó sì ń ronú “kìí ṣe nínú ọ̀rọ̀ tí ọgbọ́n ènìyàn ń kọ́ni, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ́ni; èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí.”—1 Korinti 2:13.
15. Báwo ni a ṣe lè gbéjàko ẹ̀mí ti ayé?
15 Kí ni ẹnìkan lè ṣe bí ó bá bá araarẹ̀ ní àgbègbè kan tí gáàsì onímájèlé ti sọ dèérí? Yálà kí ó wọ ìbòjú gáàsì tí a dè mọ́ ìpèsè afẹ́fẹ́ mímọ́gaara kan, tàbí kí ó kúrò ní agbègbè náà pátápátá. Ọ̀nà láti gbà yẹra fún afẹ́fẹ́ Satani jẹ́ àpapọ̀ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí. Bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó, àwa ń gbìyànjú láti mú araawa kúrò nínú ohunkóhun tí yóò mú kí ẹ̀mí ayé nípa lórí ìrònú wa. Nípa báyìí, àwa ń yẹra fún ẹgbẹ́ búburú, tí a kò sì ṣí araawa sílẹ̀ sí irú eré-ìnàjú èyíkéyìí tí ń gbé ìwà-ipá, ìwàpálapàla, ìbẹ́mìílò, ọ̀tẹ̀, tàbí iṣẹ́ ti ara èyíkéyìí mìíràn lárugẹ. (Galatia 5:19-21) Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú ayé, ṣíṣírasílẹ̀ sí àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀ pátápátá. Nítorí náà àwa ń hùwà bí ọlọgbọ́n bí a ba so mọ́ ìpèsè afẹ́fẹ́ mímọ́ tẹ̀mí. Àwa ń fi nǹkan kún inú ẹ̀dọ̀fóró wa nípa tẹ̀mí, kí á sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú wíwá sí ìpàdé déédéé, ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìgbòkègbodò àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian, àti àdúrà. Ní ọ̀nà yìí, bí èyíkéyìí nínú afẹ́fẹ́ Satani bá fẹ́ sínú ẹ̀dọ́fóró wa tẹ̀mí, ẹ̀mí Ọlọrun ń fún wa lágbára láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.—Orin Dafidi 17:1-3; Owe 9:9; 13:20; 19:20; 22:17.
16. Báwo ni a ṣe fi ẹ̀rí hàn pé a ní ẹ̀mí Ọlọrun?
16 Ẹ̀mí Ọlọrun ń sọ Kristian kan di ẹni tí ó dá yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí wọ́n jẹ́ apákan ayé yìí. (Romu 12:1, 2) Paulu sọ pé: “Èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlááfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwàtútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu: òfin kan kò lòdìsí irú wọnnì.” (Galatia 5:22, 23) Ẹ̀mí Ọlọrun tún ń fún Kristian kan ní òye jíjinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan. Paulu sọ pé: “Kò sí ẹnìkan tí ó mọ ohun Ọlọrun, bíkòṣe Ẹ̀mí Ọlọrun.” (1 Korinti 2:11) Ní gbogbogbòò, “ohun Ọlọrun” ní nínú àwọn nǹkan bí òtítọ́ nípa ẹbọ ìràpadà, Ìjọba Ọlọrun lábẹ́ Jesu Kristi, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, àti ìmúkúrò ayé búburú yìí tí ó ti rọ̀dẹ̀dẹ̀. Pẹ̀lú ìrànwọ́ ẹ̀mí Ọlọrun, àwọn Kristian mọ̀ wọ́n sì tẹ́wọ́gba àwọn nǹkan wọ̀nyí bí òtítọ́, èyí sì ti mú kí ojú-ìwòye wọn nípa ìgbésí-ayé yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn ayé. Wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn láti rí ayọ̀ nínú sísin Jehofa nísinsìnyí, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún sísìn ín títí ayérayé tí ń bọ̀.
17. Ta ni fi àpẹẹrẹ dídára jùlọ lélẹ̀ ní gbígbéjàko ẹ̀mí ti ayé, báwo sì ni?
17 Jesu jẹ́ ẹni àwòkọ́ṣe dídára jùlọ fún àwọn tí wọ́n gbéjàko ẹ̀mí ayé yìí. Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ìrìbọmi Jesu, Satani gbìyànjú láti darí rẹ̀ kúrò nínú sísin Jehofa nípa gbígbé àdánwò mẹ́ta kalẹ̀. (Matteu 4:1-11) Èyí tí ó gbẹ̀yìn jẹ́ lórí ṣíṣeéṣe náà pé Jesu lè jèrè ìṣàkóso gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí èrè fún kìkì ìṣe ìjọsìn kanṣoṣo fún Satani. Jesu ti lè ronú pé: ‘Ó dára, èmi yóò ṣe ìṣe ìjọsìn náà, lẹ́yìn tí mo bá sì ti gba ìṣàkóso ayé, èmi yóò ronúpìwàdà ń ó sì padà sí jíjọ́sìn Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí alákòóso ayé, èmi yóò wà ní ipò sísunwọ̀n jù láti ṣàǹfààní fún aráyé ju bí mo ti lè ṣe nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bíi gbẹ́nàgbẹ́nà ara Nasareti kan.’ Jesu kò ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀. Òun múratán láti dúró títí di ìgbà tí Jehofa bá fún un ní ìṣàkóso ayé. (Orin Dafidi 2:8) Ní àkókò yẹn, àti ní gbogbo àkókò mìíràn nínú ìgbésí-ayé rẹ̀, òun gbéjàko agbára ìdarí onímájèlé ti afẹ́fẹ́ Satani. Nípa báyìí, òun ṣẹ́gun ayé tí ó ti di eléèérí nípa tẹ̀mí yìí.—Johannu 16:33.
18. Ọ̀nà wo ni a gbà mú ìyìn wá fún Ọlọrun nípa gbígbéjàko ẹ̀mí ti ayé?
18 Aposteli Peteru sọ pé a níláti tẹ̀lé ipasẹ̀ Jesu tímọ́tímọ́. (1 Peteru 2:21) Àwòkọ́ṣe sísunwọ̀n jù wo ni a tún lè ní? Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, bí ẹ̀mí ayé ti nípa lórí wọn, àwọn ènìyàn túbọ̀ ń rì wọlẹ̀ síi sínú ìwà ìbàjẹ́. Ẹ wo ohun àgbàyanu tí ó jẹ́ pé láàárín irú ayé bẹ́ẹ̀, ibi ìjọsìn Jehofa tí a gbégasókè dádúró gedegbe ní mímọ́gaara àti mímọ́ tónítóní! (Mika 4:1, 2) Dájúdájú, agbára ẹ̀mí Ọlọrun ni a ṣàkíyèsí níti pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń dàgììrì wá síbi ìjọsìn Ọlọrun, ní gbígbéjàko ẹ̀mí ayé tí ó gbalẹ̀ káàkiri tí wọ́n sì ń mú ọlá àti ìyìn wá fún Jehofa! (1 Peteru 2:11, 12) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti dúró sí ibi gígasókè náà títí tí Ọba àfòróróyàn Jehofa yóò fi mú ayé búburú yìí kúrò tí yóò sì sọ Satani Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìfihàn 19:19-20:3) Nígbà náà, ẹ̀mí ti ayé yìí kì yóò tún sí mọ́. Ẹ wo àkókò oníbùkún tí ìyẹn yóò jẹ́!
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni ẹ̀mí ti ayé?
◻ Kí ni ipa tí ẹ̀mí ti ayé yìí ní lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí ẹ̀mí ti ayé ń gbà farahàn, báwo sì ni a ṣe lè yẹra fún un?
◻ Báwo ni a ṣe lè fihàn pé a ní ẹ̀mí Ọlọrun?
◻ Kí ni àwọn ìbùkún tí ń wá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n gbéjàko ẹ̀mí ti ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ẹ̀mí ti ayé wá láti ọ̀dọ̀ Satani
Láti yẹra fún ẹ̀mí ti ayé, sá lọ sí ibi ìjọsìn Jehofa tí a gbégasókè