Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Dènà Ẹ̀mí Ayé
“Wàyí o, kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 2:12.
1, 2. (a) Ìyàtọ̀ wo la lè rí láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí ń bẹ nínú ayé àti àwọn èwe tó wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (b) Oríyìn wo la lè gbé fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí?
“AYÉ ti sú àwọn ọmọ ìwòyí, wọn ò lálábàárò, wọ́n sì ti di ọlọ̀tẹ̀.” Ohun tí ìwé ìròyìn The Sun-Herald nílẹ̀ Ọsirélíà sọ nìyẹn. Ó tún fi kún un pé: “Àkọsílẹ̀ ilé ẹjọ́ fi hàn pé iye àwọn ọmọ tí kò tí ì tójú bọ́ tó ń jẹ́jọ́ ìwà ọ̀daràn tó lékenkà ti fi ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún lé sí ti [àwọn ọdún tó ti kọjá] . . . Bẹ̀rẹ̀ láti àárín àwọn ọdún 1960 ni iye àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tí ń fọwọ́ ara wọn pa ara wọn ti lé ní ìlọ́po mẹ́ta sí tàtẹ̀yìnwá . . . Ẹ̀mí kóńkó jabele táwọn ọmọ ìwòyí ní sí àwọn àgbààgbà ti wá gbilẹ̀ débi pé, ó ti di ọ̀gbun táwọn ọ̀dọ́ ń ré sínú rẹ̀ ṣáá, a ń rí èyí bí àwọn tí ń di ajoògùnyó, ọ̀mùtí àti afọwọ́ ara ẹni para ẹni ṣe ń pọ̀ sí i.” Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ilẹ̀ kan ṣoṣo ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ń ṣẹlẹ̀. Jákèjádò ayé làwọn òbí, olùkọ́, àti àwọn ògbógi nínú ìṣègùn ọpọlọ ti ń dárò nípa ipò tí àwọn ọmọ òde ìwòyí wà.
2 Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí àti àwọn ọ̀dọ́ tó gbayì, tó gbẹ̀yẹ, tí wọ́n wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà ga o! Àwọn ọ̀dọ́ wa wọ̀nyí kì í ṣe ẹni pípé. Àwọn pẹ̀lú ń bá “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” jìjàkadì. (2 Tímótì 2:22) Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ti mú ìdúró wọn gẹ́gẹ́ bí onígboyà, wọ́n ti múra tán láti ṣe ohun tó tọ́, wọ́n sì ń sọ pé, rárá o, àwọn ò ní jẹ́ káyé sọ àwọn dà bó ṣe dà. Gbogbo ẹ̀yin ọ̀dọ́ tí ẹ ń jàjàyè nínú ogun tí ẹ ń bá “àrékérekè” Sátánì jà, la fi tọkàntọkàn ṣe sàdáńkátà fún, ẹ káre láé! (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Jòhánù, a sún wa láti sọ pé: “Mo kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin [àti ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin], nítorí ẹ jẹ́ alágbára àti pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú yín, ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 2:14.
3. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” lè túmọ̀ sí?
3 Síbẹ̀síbẹ̀, láti lè máa bá a nìṣó láti jàjàyè nínú ogun tí ẹ̀ ń bá ẹni burúkú yìí jà, ẹ gbọ́dọ̀ lo gbogbo agbára yín láti dènà ohun tí Bíbélì pè ní “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan nípa èdè Gíríìkì ti sọ, “ẹ̀mí” lè túmọ̀ sí “ìrònú tàbí agbára kan tó gba inú ọkàn ẹni, tí ó sì lè darí ẹni.” Fún àpẹẹrẹ, bóo bá ṣàkíyèsí pé ẹnì kan jẹ́ oníkanra, o lè sọ pé onítọ̀hún ní “ẹ̀mí” burúkú. “Ẹ̀mí” rẹ, ìrònú rẹ, tàbí èrò-ọkàn rẹ ń nípa lórí àwọn ohun tí o yàn láti ṣe; òun ló ń darí ìgbésẹ̀ àti ọ̀rọ̀ rẹ. Lọ́nà tó dùn mọ́ni, ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan àti gbogbo àwùjọ ló lè fi “ẹ̀mí” kan hàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwùjọ àwọn Kristẹni kan pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.” (Fílémónì 25) Nígbà náà, irú ẹ̀mí wo ni ayé yìí ń fi hàn? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ìyẹn ni Sátánì Èṣù, kò sọ́nà tí ẹ̀mí ayé lè gbà dáa, àbó lè dáa?—1 Jòhánù 5:19.
Mímọ Ẹ̀mí Ayé
4, 5. (a) Ẹ̀mí wo ló ti nípa lórí àwọn tó wà ní ìjọ Éfésù kí wọ́n tó di Kristẹni? (b) Ta ni “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” kí sì ni “afẹ́fẹ́” náà?
4 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ni Ọlọ́run sọ di ààyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, nínú èyí tí ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn. Bẹ́ẹ̀ ni, ní àkókò kan, gbogbo wa hùwà láàárín wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa, ní ṣíṣe àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́ àti ti àwọn ìrònú, a sì jẹ́ ọmọ ìrunú lọ́nà ti ẹ̀dá àní bí àwọn yòókù.”—Éfésù 2:1-3.
5 Kí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀sìn Kristẹni, wọ́n ti ń tẹ̀ lé “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” ìyẹn ni Sátánì Èṣù, láìmọ̀ọ́mọ̀. “Afẹ́fẹ́” táà ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kì í ṣe àgbègbè kan pàtó tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbé o. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sátánì Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ṣì láǹfààní láti máa lọ sọ́run. (Fi wé Jóòbù 1:6; Ìṣípayá 12:7-12.) Ọ̀rọ̀ náà “afẹ́fẹ́” túmọ̀ sí ẹ̀mí, tàbí ìrònú, tó gba ayé Sátánì kan. (Fi wé Ìṣípayá 16:17-21.) Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ tó wà láyìíká wa, ẹ̀mí yìí wà níbi gbogbo.
6. Kí ni “ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” báwo ló sì ṣe ń lo agbára lórí ọ̀pọ̀ àwọn èwe?
6 Ṣùgbọ́n kí ni “ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́” yìí? Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí táa rí, èyí ń tọ́ka sí agbára ńlá tí “afẹ́fẹ́” yìí ń ní lórí àwọn ènìyàn. Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹ̀mí yìí ń “ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọràn.” Nítorí náà, ẹ̀mí ayé yìí ló bí ẹ̀mí àìgbọràn àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe sì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí afẹ́fẹ́ yìí gbà ń lo ọlá àṣẹ rẹ̀. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Nígbà tóo bá wà nílé ẹ̀kọ́, gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹ ni wọ́n a máa ṣe nǹkan tí yóò mú kí o fẹ́ lẹ́mìí ọ̀tẹ̀ díẹ̀. Àwọn ojúgbà ẹ á túbọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ tìẹ wọ̀ ẹ́, tóo bá ṣe nǹkan tó fi hàn pé o lẹ́mìí ọ̀tẹ̀.”
Fífi Ẹ̀mí Ayé Hàn
7-9. (a) Mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí àwọn ọ̀dọ́ gbà ń fi ẹ̀mí ayé hàn lóde òní. (b) Ǹjẹ́ o ti fúnra rẹ ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí lágbègbè rẹ?
7 Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí àwọn ọ̀dọ́ gbà ń fi ẹ̀mí ayé hàn lóde òní? Ìwà àìṣòótọ́ àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ ni. Ìwé ìròyìn kan sọ pé iye tó lé ní ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàá ló wí pé àwọn ti ṣòjóró rí nígbà ìdánwò. Ọ̀rọ̀ àfojúdi, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, àti ìsọkúsọ tún gbalégbòde. Lóòótọ́, nígbà kan, Jóòbù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ táwọn kan lè kà sí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, àmọ́ ṣáá o, ọ̀rọ̀ táwọn sọ, ìbínú òdodo ni wọ́n fi sọ ọ́. (Jóòbù 12:2; 2 Kọ́ríńtì 12:13) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àgbọ́dití tó kún ẹnu ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló sábà máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ èébú.
8 Àṣejù eré ìnàjú tún jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń fi ẹ̀mí ayé hàn. Lílọ sí ilé ìgbafàájì alaalẹ́ tó jẹ́ tàwọn èwe, lílọ sí ilé ijó tàkasúfèé,a àti onírúurú àwọn òde àríyá aláriwo bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́. Bákan náà sì ni ṣíṣàṣerégèé nínú ìmúra àti ìwọṣọ tún gbòde kan. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìwòyí ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ọ̀tẹ̀, ẹ̀mí tó jẹ́ ti ayé yìí, nípa wíwọ àwọn ẹ̀wù gbàgìẹ̀-gbàgìẹ̀, títí dórí wíwọ àwọn aṣọ ìgbàlódé, tí ń múni kọ háà, lára wọn ni àwọn kan tí ń gbẹ mọ́ni lára típẹ́típẹ́. (Fi wé Róòmù 6:16.) Jíjẹ́ kí kíkó ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ gbani lọ́kàn tún jẹ́ ohun mìíràn tó ń fi hàn pé ẹnì kan lẹ́mìí ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan tí a pète láti dáni lẹ́kọ̀ọ́ ti sọ, “onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bíbanilẹ́rù àti àìlóǹkà ọjà [rẹpẹtẹ] tí àwọn oníṣòwò wọ̀nyí ń kó jáde ni wọ́n fi ń da àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn rú.” Nígbà tí àwọn èwe tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà bá fi jáde ilé ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàá, wọ́n á ti wo ọ̀kẹ́ méjìdínlógún [360,000] ìpolówó ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn ojúgbà rẹ pẹ̀lú lè sún ọ láti ra nǹkan. Ọmọdébìnrin, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan wí pé: “Gbogbo èèyàn ni yóò má béèrè pé, ‘Irú súẹ́tà wo ni tìẹ yìí, ta ló rán jákẹ́ẹ̀tì ẹ, tàbí jín-ǹ-sì ẹ?’”
9 Láti ìgbà kíkọ Bíbélì ni orin burúkú ti jẹ́ irin iṣẹ́ tí Sátánì ń lò láti ru ìwà àìmọ́ sókè. (Fi wé Ẹ́kísódù 32:17-19; Sáàmù 69:12; Aísáyà 23:16.) Abájọ tó fi jẹ́ pé àwọn orin tí ń ru ìfẹ́ fún ìṣekúṣe sókè, àwọn orin ọlọ́rọ̀ játijàti, èyí tó kún fún èdè àwọn ọmọọ̀ta, tí wọ́n sì n lo ìlú tàbí orin náà láti ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè ló gbajúmọ̀ lónìí. Síbẹ̀, ohun mìíràn tó tún ń fi ẹ̀mí àìmọ́ ti ayé yìí hàn ni ìṣekúṣe. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba, ìbálòpọ̀ jẹ́ ohun tí a fi ń tẹ́wọ́ gbani láwùjọ . . . Ó lé ní ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jáde ìwé mẹ́wàá tí wọ́n ti ní ìbálòpọ̀ rí.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Wall Street Journal fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ọmọdé tó wà láàárín ọdún mẹ́jọ sí méjìlá “túbọ̀ ń kúndùn ìbálòpọ̀.” Olùgbani-nímọ̀ràn nílé ẹ̀kọ́, ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀yìn tì láìpẹ́ yìí sọ pé: “A ti bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn kan lára àwọn ọmọ oníwèé mẹ́fà táwọn náà ti gboyún.”b
Kíkọ Ẹ̀mí Ayé Sílẹ̀
10. Báwo làwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n wá láti ìdílé Kristẹni ti ṣe fàyè gba ẹ̀mí ayé?
10 Ó ṣeni láàánú pé, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ti fàyè gba ẹ̀mí ayé. Ọ̀dọ́mọbìnrin ara Japan kan sọ pé: “Tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn òbí mi àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi, mo máa ń hùwà rere. Ṣùgbọ́n mo tún máa ń hu àwọn ìwà mìíràn o.” Ọ̀dọ́ kan láti Kẹ́ńyà sọ pé: “Fún ìgbà kan mo gbé ìgbésí ayé méjì, lára rẹ̀ ni lílọ sílé ijó, gbígbọ́ orin rọ́ọ̀kì, àti kíkó àwọn ọ̀rẹ́ burúkú. Mo mọ̀ péyìí ò dáa, ṣùgbọ́n mo gbìyànjú láti mọ́kàn kúrò níbẹ̀, pẹ̀lú èrò pé nígbà tó bá yá màá kiwọ́ rẹ̀ bọlẹ̀. Àmọ́ n kò jáwọ́ ńbẹ̀. Kàkà kéwé àgbọn mi ó dẹ̀, líle ló ń le sí i.” Ọ̀dọ́ mìíràn láti Jámánì wí pé: “Orí kíkó àwọn ọ̀rẹ́ búburú ni gbogbo rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá. Àwọn òbí mi ni mo fẹ́ kó ìbànújẹ́ bá, àmọ́ ṣáá o, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ara mi ni mo bà nínú jẹ́.”
11. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún Kálébù láti ṣẹ́pá títẹ̀ síbi ayé tẹ̀ sí nígbà tí àwọn amí mẹ́wàá mú ìròyìn búburú wá?
11 Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe láti dènà ẹ̀mí ayé, àní ó ṣeé ṣe láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ ayé àtijọ́ kan yẹ̀ wò, ìyẹn ni ti Kálébù. Nígbà tí àwọn amí mẹ́wàá tí wọ́n ń ṣojo mú ìròyìn búburú wá nípa Ilẹ̀ Ìlérí, òun, pẹ̀lú Jóṣúà, kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n mú wọn láyà pami, kí wọ́n sì wá tẹ̀ síbi ayé tẹ̀ sí. Wọ́n fi ìgboyà kéde pé: “Ilẹ̀ náà tí a là kọjá láti ṣe amí rẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára gidigidi. Bí Jèhófà bá ní inú dídùn sí wa, dájúdájú, nígbà náà òun yóò mú wa wá sínú ilẹ̀ yìí, yóò sì fi í fún wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” (Númérì 14:7, 8) Kí ló ran Kálébù lọ́wọ́ láti dènà gbogbo pákáǹleke yìí? Jèhófà sọ nípa Kálébù pé: “Ẹ̀mí tí ó yàtọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.”—Númérì 14:24.
Fífi “Ẹ̀mí Tí Ó Yàtọ̀” Hàn
12. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fi “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” hàn nípa ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ lẹ́nu?
12 Lónìí, ó gba ìgboyà àti agbára láti fi “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” hàn tàbí láti fi ẹ̀mí ìrònú tí ó yàtọ̀ sí ti ayé hàn. Ọ̀nà kan tóo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni nípa yíyẹra fún ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, ọ̀rọ̀ àfojúdi. Ó dùn mọ́ni pé, ní ṣáńgílítí, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “sarcasm” tí a tú sí “ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì náà tí ó túmọ̀ sí “láti fa ẹran ya bí ìgbà tí ajá bá fà á ya.” (Fi wé Gálátíà 5:15.) Gẹ́gẹ́ bí eyín ajá ṣe lè fa ẹran já kúrò lára egungun, bẹ́ẹ̀ gan-an ni “àwàdà” tó kún fún ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn lè gbọn iyì ara àwọn èèyàn ya mọ́ wọn lára. Ṣùgbọ́n Kólósè 3:8 rọ̀ yín láti “mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” Òwe 10:19 náà sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” Bẹ́nì kan bá bú ọ, kóra rẹ níjàánu nípa ‘yíyí ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì sí i,’ bóyá kóo pè é sí kọ̀rọ̀, kóo sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀, kóo sì yanjú rẹ̀ ní ìtùnbí-ìnùbí.—Mátíù 5:39; Òwe 15:1.
13. Báwo làwọn èwe ṣe lè fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn nínú ojú tí wọ́n fi ń wo ohun ìní ti ara?
13 Ọ̀nà mìíràn táa lè gbà fi “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” hàn ni láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ní ti ojú táa fi ń wo ohun ìní ti ara. Àmọ́ ṣáá o, ìwà ẹ̀dá ni pé ká fẹ́ ní nǹkan tó dáa. Ó hàn gbangba pé ó kéré pin, Jésù Kristi pàápàá ní ẹ̀wù kan tó jojú ní gbèsè. (Jòhánù 19:23, 24) Ṣùgbọ́n, nígbà tí ẹ̀mí níní nǹkan bá wá di àforí-àfọrùn, tó sì wá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lo máa ń fúngun mọ́ àwọn òbí rẹ láti ra nǹkan tí apá wọn ò ká fún ọ, tàbí tí ò ń fipá mú wọn torí pé ìwọ náà fẹ́ dà bí àwọn ọ̀dọ́ yòókù, nígbà náà àfàìmọ̀ ni ẹ̀mí ayé ò ti ń ní agbára lórí rẹ, tí oò sì mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì ayé yìí ní agbára lórí rẹ! Kọ́ láti jẹ́ kí ohun tí o ní tẹ́ ọ lọ́rùn.—1 Jòhánù 2:16; 1 Tímótì 6:8-10.
14. (a) Báwo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọjọ́ Aísáyà ṣe fi hàn pé wọn kì í ṣe oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ní ti ọ̀ràn eré ìnàjú? (b) Ewu wo ni àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ti bá pàdé níbi ilé ìgbafàájì alaalẹ́ àti àwọn àríyá aláriwo?
14 Fífi eré ìnàjú sí àyè rẹ̀ tún ṣe pàtàkì. Wòlíì Aísáyà kéde pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná! Háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì àti fèrè, àti wáìnì sì ní láti wà níbi àsè wọn; ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì ni wọn kò rí.” (Aísáyà 5:11, 12) Ó ṣeni láàánú pé, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan ti lọ sírú àríyá aláriwo bẹ́ẹ̀. Nígbà táa ní kí àwùjọ àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kan ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ìgbafàájì alaalẹ́ tó jẹ́ tàwọn ọ̀dọ́, arábìnrin ọ̀dọ́ kan ròyìn pé: “Wọn ò lè ṣe kí wọ́n má jà níbẹ̀. Mo ti bára mi láàárín ibi tí wọ́n ti ń ja gídígbò rí.” Ọ̀dọ́ arákùnrin kan fi kún un pé: “Ọtí mímu, fífa sìgá, àti irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló gbabẹ̀ kan.” Arákùnrin mìíràn tí òun pẹ̀lú jẹ́ ọ̀dọ́ sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń mutí yó níbẹ̀. Wọ́n á wá máa ṣe bí akídanidání! Oògùn olóró tún máa ń wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan burúkú ló ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ o. Bóo bá lọ síbẹ̀, tóo rò pé oò ní bá wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀, irọ́ lo pa.” Abájọ tí Bíbélì fi to àwọn àríyá aláriwo, tàbí “àríyá oníwà ẹhànnà,” mọ ara “àwọn iṣẹ́ ti ara.”—Gálátíà 5:19-21; Byington; Róòmù 13:13.
15. Ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì wo ni Bíbélì fúnni nípa eré ìnàjú?
15 Bóo bá yẹra fún eré ìnàjú tó lè pa ọ́ lára, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé oò ní láyọ̀. “Ọlọ́run aláyọ̀” tó fẹ́ kí o gbádùn ìgbà èwe rẹ là ń jọ́sìn! (1 Tímótì 1:11; Oníwàásù 11:9) Ṣùgbọ́n Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ àríyá [“eré ìnàjú,” Lamsa] yóò wà nínú àìní.” (Òwe 21:17) Bẹ́ẹ̀ ni, bóo ba sọ eré ìnàjú di ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ, oò ní ní nǹkan tẹ̀mí. Nítorí náà, tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nígbà tóo bá ń yan eré ìnàjú rẹ. Ọ̀nà tóo lè fi gbádùn ara rẹ, tí yóò gbé ọ ró, tí kò sì ní sọ ọ́ di ẹni yẹpẹrẹ, pọ̀ lọ jàra.c—Oníwàásù 11:10.
16. Báwo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ṣe lè fi hàn pé àwọn yàtọ̀?
16 Jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwọṣọ àti ìmúra rẹ, yíyẹra pátápátá fún àwọn àṣà ayé, yóò fi ọ́ hàn pé o yàtọ̀. (Róòmù 12:2; 1 Tímótì 2:9) Bákan náà ni yóò ṣe rí bóo bá jẹ́ ẹni tó ń ṣàṣàyàn orin tí ò ń gbọ́. (Fílípì 4:8, 9) Kristẹni ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo láwọn orin kan tó yẹ kí n kó sọ nù, àmọ́ wọ́n dùn púpọ̀!” Ọ̀dọ́mọkùnrin mìíràn tún sọ pé: “Ọ̀fìn ni orin jẹ́ fún mi nítorí pé mo fẹ́ràn orin gan-an. Bí mo bá rí i pé nǹkan kan wà nínú orin kan tí kò dáa, tàbí tí àwọn òbí mi bá pe àfiyèsí mi sí i, mo ní láti fagbára mú ara mi kí n tó lè pa orin náà tì, nítorí lọ́kàn mi mo fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀.” Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ má ṣe “aláìmọ àwọn ète-ọkàn [Sátánì]”! (2 Kọ́ríńtì 2:11) Ó ń sapá láti fi orin yí ọkàn àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà! Àwọn àpilẹ̀kọ ti jáde nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society tó jíròrò nípa orin ọlọ́rọ̀ wótowòto, onílù dídún kíkankíkan, àti àwọn orin rọ́ọ̀kì mìíràn.d Ṣùgbọ́n, àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society kò lè sọ̀rọ̀ lórí gbogbo orin tí yóò máa jáde. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ lo “agbára láti ronú” àti “ìfòyemọ̀” láti yan orin tóo fẹ́ gbọ́.—Òwe 2:11.
17. (a) Kí ni por·neiʹa, àwọn ìwà wo ló sì wé mọ́ ọn? (b) Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run tó bá dọ̀ràn ìwà rere?
17 Lákòótán, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó mọ́ níwà. Bíbélì rọni pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún àgbèrè ni, por·neiʹa, ó sì túmọ̀ sí gbogbo ìṣekúṣe tí wọ́n ń fi àwọn ẹ̀yà ìbímọ ṣe lẹ́yìn òde ìgbéyàwó. Lára rẹ̀ ni ìbálòpọ̀ àtẹnuṣe àti mímọ̀ọ́mọ̀ fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ àwọn ẹlòmí-ìn. Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni mélòó kan ti lọ́wọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì lérò pé àwọn ò tí ì ṣàgbèrè. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là á mọ́lẹ̀ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.”—1 Tẹsalóníkà 4:3, 4.
18. (a) Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí ẹ̀mí ayé kéèràn ràn? (b) Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí?
18 Bẹ́ẹ̀ ni, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o lè yẹra fún dídi ẹni tí ẹ̀mí ayé kéèràn ràn! (1 Pétérù 5:10) Àmọ́ ṣáá o, Sátánì sábà máa ń ṣawúrúju sí àwọn ẹ̀bìtì aṣekúpani tó ń dẹ kiri, nígbà mí-ìn ó sì ń béèrè ìfòyemọ̀ gidi láti lè fura sí ewu náà. A ṣètò àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé èyí láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti mú agbára ìwòye wọn dàgbà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àríyá alaalẹ́ sábà máa ń jẹ́ àṣemọ́jú. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ijó Rave Ha Jẹ́ Amóríyá Aláìléwu Bí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti December 22, 1997.
b Àwọn ọmọ bí ọlọ́dún mọ́kànlá.
c Láti lè rí ìmọ̀ràn lórí èyí, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 296 sí 303 ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.
d Wo ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1993.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ni “ẹ̀mí ayé,” báwo ló sì ṣe ń ní “ọlá àṣẹ” lórí ènìyàn?
◻ Kí làwọn nǹkan díẹ̀ tó fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ òde òní ní ẹ̀mí ayé?
◻ Báwo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ṣe lè fi “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe?
◻ Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè fi “ẹ̀mí tí ó yàtọ̀” hàn ní ti ìwà híhù àti orin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń fi hàn pé àwọn wà lábẹ́ “ọlá àṣẹ” ẹ̀mí ayé yìí nípa ìwà tí wọ́n ń hù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣàṣàyàn orin tí ò ń gbọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ó gba ìgboyà láti lè dènà ẹ̀mí ayé