Ìyọlẹ́gbẹ́—Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ Ha Ni Bí?
“MÍMỌ́, mímọ́, mímọ́ ni Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè.” (Ìṣípayá 4:8) Ní ìbámu pẹ̀lú àpèjúwe yẹn, Jehofa ni Orísun àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n mímọ́. Àwọn wọ̀nyí ni a là sílẹ̀ nínú “àwọn àkọsílẹ̀ mímọ́,” ó sì jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún àwọn Kristian láti tẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí. Nítòótọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ ní ojú Jehofa.—2 Timoteu 3:15; Isaiah 52:11.
Bibeli pàṣẹ ní kedere pé: “Ní ìbámu pẹlu Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹlu di mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín, nitori a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nitori tí emi jẹ́ mímọ́.’” (1 Peteru 1:15, 16) Láti ìgbà tí a ti dá ìjọ Kristian sílẹ̀ ní ọ̀rúndún 19 sẹ́yìn, àwọn Kristian tòótọ́ ti ja ìjà líle láti dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ àìmọ́ tẹ̀mí àti ti ìwàhíhù.—Juda 3.
Ìdí Tí Ìdáàbòbò Fi Pọndandan
Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ni ó dojúkọ ìpèníjà náà láti wà ní mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí àti ti ìwàhíhù. Nítorí ète yẹn, àwọn ọ̀tá mẹ́ta tí ó lágbára ni a gbọ́dọ̀ dènà—Satani, ayé rẹ̀, àti ìtẹ̀sí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ wa. (Romu 5:12; 2 Korinti 2:11; 1 Johannu 5:19) Ayé Satani yóò dán ọ wò láti jẹ́ oníwà pálapàla, yóò pè ọ́ níjà láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà rẹ̀, yóò sì fi ọrọ̀ nípa ti ara, òkìkí, ipò, ìyọrí-ọlá, àti agbára lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n bá pinnu láti lépa ìjọsìn tòótọ́ ń dènà ohun tí Satani ń fi lọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń wà “láìní èérí kúrò ninu ayé.” Èéṣe? Nítorí pé wọ́n fẹ́ láti dúró sábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ àti aláàbò ti ètò-àjọ mímọ́ tónítóní ti Jehofa.—Jakọbu 1:27; 1 Johannu 2:15-17.
Jehofa ti pèsè ìrànwọ́ fún mẹ́ḿbà èyíkéyìí ti ìjọ Kristian tí ó bá ṣubú sínú àwọn ìdánwò Satani nítorí àìlera ẹ̀dá ènìyàn. Ó ti yan àwọn alàgbà tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí sípò láti dáàbò bo ìjọ kí wọ́n sì fi tìfẹ́tìfẹ́ ran àwọn tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí wọ́n sì ṣe àtúnṣebọ̀sípò tí ó bá yẹ láti lè kọ́fẹpadà. Kristian èyíkéyìí tí ó bá lọ́wọ́ nínú ìwà-àìtọ́ ni a níláti fi sùúrù ràn lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà kí ó sì yí àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà.—Galatia 6:1, 2; Jakọbu 5:13-16.
Bí Ìyọlẹ́gbẹ́ Ṣe Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí wọ́n ti ṣèrìbọmi tí wọ́n bá mọ̀ọ́mọ̀ tẹ̀lé ipa-ọ̀nà burúkú tí wọ́n sì kọ̀ láti yípadà ni a gbọ́dọ̀ wò gẹ́gẹ́ bí aláìronúpìwàdà tí wọn kò sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian. (Fiwé 1 Johannu 2:19.) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a kò lè yọ̀ǹda fún láti wà nínú ìjọ Kristian mímọ́ tónítóní kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kó èérí bá a. A gbọ́dọ̀ lé wọn jáde.
Bí lílé àwọn wọnnì tí wọ́n bá sọ àwọn ìṣe burúkú dàṣà ṣe tọ̀nà tó ni a lè fi àyíká ipò tí ó tẹ̀lé e yìí ṣàpèjúwe: Nítorí ìkọluni àti ìwà-ọ̀daràn oníwà-ipá sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ kan ti lo ìlànà ètò tí ó “béèrè pé kí a lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá lo ohun-ìjà tàbí tí ó fi halẹ̀ mọ́ni dànù pátápátá,” ni ìwé agbéròyìnjáde kan ní Toronto, Canada, The Globe and Mail ròyìn. A ń lé wọn jáde láti lè dáàbò bo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ́ láti jàǹfààní láti inú ètò ẹ̀kọ́ náà láìjẹ́ pé wọ́n kówọnú àwọn ìwà-ipá.
Èéṣe tí ó fi jẹ́ ohun tí ó fi ìfẹ́ hàn láti lé oníwà-àìtọ́ kan tí kò ronúpìwàdà kúrò nínú ìjọ? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ fífi ìfẹ́ hàn fún Jehofa àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Orin Dafidi 97:10) Ìgbésẹ̀ yìí fi ìfẹ́ hàn fún àwọn wọnnì tí ń lépa ipa-ọ̀nà òdodo nítorí pé ó mú ẹnì kan tí ó lè lo agbára ìdarí búburú lórí wọn kúrò láàárín wọn. Ó tún ń dáàbò bo ìjẹ́mímọ́ ìjọ náà. (1 Korinti 5:1-13) Bí a bá fàyègba ìwà-pálapàla wíwúwo tàbí àìmọ́ nípa tẹ̀mí láti wà nínú ìjọ, a óò kó èérí bá a kì yóò sì ṣeé lò fún iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún Jehofa mọ́, ẹni tí ó jẹ́ ẹni mímọ́. Síwájú síi, lílé oníwà-àìtọ́ náà kúrò lè ràn án lọ́wọ́ láti rí bí ipa-ọ̀nà ìwà-wíwọ́ rẹ̀ ti burú lékenkà tó, kí ó ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe àwọn ìyípadà tí ó yẹ kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà á padà sínú ìjọ.
Ipa Tí Ó Ń Ní Lórí Àwọn Ẹlòmíràn
Nígbà tí mẹ́ḿbà ìjọ kan bá dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, irú bí panṣágà, òun kò mú inú Jehofa dùn. (Owe 27:11) Kristian èyíkéyìí tí ó bá juwọ́sílẹ̀ fún ìwà pálapàla takọtabo dájúdájú kò ronú bí Josefu ti ṣe nígbà tí aya Potifari gbìyànjú láti mú kí ó ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú òun. Ìhùwàpadà Josefu ni pé: “Ǹjẹ́ èmi ó ha ti ṣe hu ìwà búburú ńlá yìí, kí èmi sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?” (Genesisi 39:6-12) Josefu bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n mímọ́ ti Jehofa ó sì sá kúrò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, onípanṣágà kan dàbí ẹni tí kò ní ìfẹ́ tó fún Ọlọrun láti yẹra fún títẹ́ ìfẹ́ àìníjàánu ti ẹran-ara rẹ̀ lọ́rùn.—Galatia 5:19-21.
Ẹnì kan tí ó ti ṣèrìbọmi tí ó bá ré àṣẹ Ọlọrun kọjá kò bìkítà nípa ìpalára àti ìrora tí èyí yóò fà fún àwọn ìbátan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́. Ipa tí ń ní lórí ìmọ̀lára ju ohun tí àwọn kan lè faradà lọ. Lẹ́yìn rírí i pé ọmọkùnrin òun jẹ́ oníwà pálapàla, Kristian obìnrin kan kédàárò pé: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó lóye bí inú wa ṣe bàjẹ́ tó tí ọkàn wa sì pòrúrùu tó kò tó nǹkan, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá. . . . Ọkàn wa bàjẹ́.” A lè gbé ìbéèrè dìde sí orúkọ rere ìdílé kan látòkèdélẹ̀. Ìsoríkọ́ àti ẹ̀bi díẹ̀ lè fìyà jẹ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́. Ipa-ọ̀nà burúkú oníwà-àìtọ́ náà ń tipa báyìí mú ìrora ọkàn wá fún ìdílé náà.
Ìrànlọ́wọ́ Onífẹ̀ẹ́ fún Àwọn Mẹ́ḿbà Ìdílé
Àwọn Kristian olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé ẹnì kan tí a yọ lẹ́gbẹ́ yẹ kí wọ́n rántí pé ìyọlẹ́gbẹ́ jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti adáàbòboni. Gbogbo ipá tí ó bá ṣeé ṣe ni a sà láti ran oníwà-àìtọ́ náà lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ó bá fi hàn pé òun jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọrun tí ó sì jẹ́ olóríkunkun aláìronúpìwàdà, a níláti dáàbò bo ìjọ náà kò sì sí ohun mìíràn láti ṣe ju láti gbé ìgbésẹ̀ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti fúnni ní ìtọ́ni pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú naa kúrò láàárín ara yín.” (1 Korinti 5:13) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí kan ti sọ, “ìyọlẹ́gbẹ́ jẹ́ ọ̀ràn ìṣòtítọ́ sí Jehofa.”
Nígbà tí a bá yọ mẹ́ḿbà ìdílé kan lẹ́gbẹ́, àwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ Kristian máa ń ní ìrírí ìrora. Nítorí náà àwọn alàgbà tí a yànsípò gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti tù wọ́n lára nípa tẹ̀mí. (1 Tessalonika 5:14) Àwọn alàgbà lè gbàdúrà fún wọn àti pẹ̀lú wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ó máa ń ṣeé ṣe láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn Kristian olùṣòtítọ́ wọ̀nyí láti jíròrò àwọn ìrònú tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu tí ó sì ń gbéniró. Àwọn olùṣọ́ àgùtàn agbo àgùtàn gbọ́dọ̀ lo gbogbo àǹfààní láti fún àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí lókun ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ìpàdé Kristian. Àfikún ìṣírí ni a lè fifúnni nípa bíbá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá wọn. (Romu 1:11, 12) Ó yẹ kí àwọn olùṣọ́ àgùtàn nípa tẹ̀mí fi ìfẹ́ hàn sí àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa wọ̀nyí kí wọ́n sì fún wọn ní àfiyèsí tí ó yẹ wọn.—1 Tessalonika 2:7, 8.
Ipa-ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ ti ẹnì kan kì í ṣe ìdí láti ṣá ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ̀ tí ó bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Jehofa tì. Ọlọrun kọ Saulu ọba burúkú ti Israeli sílẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi kò yọ̀ǹda fún èyí láti dabarú ìfẹ́ni tí òun ní fún Jonatani ọmọkùnrin Saulu. Ní tòótọ́, ìdè tí ó wà láàárín Dafidi àti Jonatani wá di èyí tí ó lágbára gan-an. (1 Samueli 15:22, 23; 18:1-3; 20:41) Nítorí náà gbogbo àwọn tí ó bá wà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ ṣe ìtìlẹ́yìn kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristian tí àwọn ìbátan wọn dẹ́ṣẹ̀ sí Jehofa.
Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà àìnífẹ̀ẹ́ tó láti ṣá wọn tì tàbí láti hùwà aláìnínúrere sí irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀! Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n bá jẹ́ adúróṣinṣin ní àìní àkànṣe fún ìṣírí. Wọ́n lè nímọ̀lára ìdánìkanwà wọ́n sì lè rí i pé ipò wọn nira gidigidi. Bóyá o lè ṣàjọpín àwọn ìsọfúnni tẹ̀mí tàbí ìrírí tí ń gbéniró pẹ̀lú wọn nípasẹ̀ tẹlifóònù. Bí ẹni tí a ti lé jùnù náà bá gbé tẹlifóònù náà, ṣáà sọ fún un pé o fẹ́ bá ìbátan tí ó jẹ́ Kristian sọ̀rọ̀. O lè késí àwọn mẹ́ḿbà olùṣòtítọ́ nínú agbo ìdílé bẹ́ẹ̀ wá sí ìkójọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tàbí kí o pè wọ́n fún oúnjẹ nínú ilé rẹ. Bí o bá bá wọn pàdé nígbà tí wọ́n ń rajà, o lè lo àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà fún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ń gbéniró. Rántí pé, àwọn Kristian adúróṣinṣin tí wọ́n ní àwọn ìbátan tí a ti yọlẹ́gbẹ́ ṣì jẹ́ apákan ètò-àjọ mímọ́ tónítóní ti Jehofa. Wọ́n lè tètè nímọ̀lára ìdánìkanwà kí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì. Nítorí náà, wà lójúfò láti fi inúrere àti ìfẹ́ hàn sí wọn. Máa bá a nìṣó láti máa ṣe ohun rere ‘sí awọn wọnnì tí wọ́n bá ọ tan ninu ìgbàgbọ́.’—Galatia 6:10.
Mọrírì Ìpèsè Jehofa
Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé Jehofa Ọlọrun fi àníyàn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nínú ìdílé àgbáyé ti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. Nípasẹ̀ ètò-àjọ rẹ̀ ó ti fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ètò kan láti ràn wá lọ́wọ́ nínú rírìn níwájú rẹ̀ ní ọ̀nà òdodo. Àní bí mẹ́ḿbà ìdílé kan bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà tí a sì gbọ́dọ̀ lé e kúrò nínú ìjọ, ọ̀nà wà fún un láti padà bí ó bá ronúpìwàdà níti tòótọ́. Èyí ni a fi àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀lé e yìí ṣàkàwé:
Àwọn alàgbà ti gbìyànjú láti ran ẹnì kan tí a óò pè ní Anna lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó yíjú sí sìgá mímu, ọtí mímu, àti oògùn ìlòkulò. Kò ronúpìwàdà kò sì dúró nínú ìjọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ kò jìnnà, Anna bẹ̀rẹ̀ sí pàdánù ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ onífẹ̀ẹ́ ti ìjọ mímọ́ tónítóní ti Jehofa ó sì gbàdúrà sí i fún ìrànlọ́wọ́. Ó gbà pé òun kò tí ì ní ìmọrírì lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ tó fún bí àwọn alàgbà ṣe ń bìkítà nípa àwọn tí wọ́n ṣáko lọ. Anna bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé lẹ́ẹ̀kan síi, èyí sì yọrí sí ìrònúpìwàdà. Lẹ́yìn náà, a gbà á padà sínú ìjọ onífẹ̀ẹ́ àti adáàbòboni. Lẹ́ẹ̀kan síi, Anna di ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti Jehofa lórí ìwàhíhù mú. Ó mọrírì ìfẹ́ tí àwọn alàgbà fi hàn ó sì tún sọ pé: “Ẹ kò lè finúmòye bí àwọn ìtẹ̀jáde Kristian ti ràn mí lọ́wọ́ tó. Dájúdájú Jehofa máa ń bójútó àwọn àìní wa dáradára.”
Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun ti pèsè ọ̀nà kan láti padà fún àwọn wọnnì tí a ti lé kúrò nínú ìjọ ṣùgbọ́n tí wọ́n ronúpìwàdà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. A ti rí i pé ìyọlẹ́gbẹ́ fúnra rẹ̀ jẹ́ ìpèsè onífẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti sàn jù tó láti yẹra fún ìrírí bíbaninínújẹ́ yìí nípa rírọ̀mọ́ àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọrun wa mímọ́ nígbà gbogbo! Ǹjẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní fífi ìmọrírì hàn fún àǹfààní yíyin Jehofa gẹ́gẹ́ bí apákan ètò-àjọ mímọ́ tónítóní, onífẹ̀ẹ́, àti adáàbòboni rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
O ha ń fi ìfẹ́ hàn fún àwọn olùṣòtítọ́ ìbátan ti àwọn wọnnì tí a lé kúrò nínú ìjọ bí?