Ojú-ìwòye Bibeli
Ìdí Tí Ìyọlẹ́gbẹ́ Fi Jẹ́ Ìṣètò Onífẹ̀ẹ́
ÌYỌNÍJỌ—èrò náà ń ru ìmọ̀lára tibi tire sókè láàárín ọ̀pọ̀ àwọn ònísìn.a Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà pé àwọn ìsìn nílò àwọn ìbáwí kan. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ń wo ìyọníjọ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí ohun tó ti kọjá—ìlànà ìbáwí rírorò bóofẹ́bóokọ̀, tí ń rán wọn létí ìwà fífi ìkà dọdẹ ẹni àti ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀.
Ohun tí ó tún ń pa kún ìṣòro náà ni ipa òdì tí ayé aláìṣe ti ìsìn tí ó gbalẹ̀ kan ń ní. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìsin Kirisẹ́ńdọ̀mù ti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye tí ó túbọ̀ gbọ̀jẹ̀gẹ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà, abájọ tí òjíṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Episcopal kan ṣe sọ pé: “Ìyọníjọ jẹ́ apá kan àṣa wa, ṣùgbọ́n n kò lérò pé a ń ṣàmúlo rẹ̀ ní ọ̀rúndún yìí.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ó lè ya ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́nu láti mọ̀ pé láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì fi ọwọ́ pàtàkì mú ìyọlẹ́gbẹ́ (tí ó jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú ìyọníjọ). Lótìítọ́, kì í ṣe ìgbésẹ̀ tó rọrùn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìṣètò onífẹ̀ẹ́. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Ó Ń Gbé Orúkọ Ọlọ́run Lárugẹ
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run mímọ́. Kì í gba ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá láyè fún àwọn tí wọ́n bá jẹ́wọ́ pé àwọ́n ń jọ́sìn rẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni pé: “Kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí tí èmí jẹ́ mímọ́.’” (Pétérù Kìíní 1:15, 16) Nítorí náà, yíyọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ ń gbé orúkọ mímọ́ Ọlọ́run lárugẹ; ó ń fi ìfẹ́ fún orúkọ yẹn hàn.—Fi wé Hébérù 6:10.
Èyí ha túmọ̀ sí pé bí Kristẹni kan bá jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àìlera tàbí tí ó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, a óò wulẹ̀ lé e jáde nínú ìjọ ni bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Jèhófà kì í ṣe apàṣẹwàá tí kò lójú àánú. Ó kún fún àánú àti ìgbatẹnirò. Ó máa ń rántí pé aláìpé ni wá. (Orin Dáfídì 103:14) Jèhófà mọ̀ pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀ wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Ọlọ́run ti ṣètò fún ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí láàárín ìjọ kí ó lè jẹ́ pé bí Kristẹni kan bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé” tàbí tí ó tilẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan, a lè fìfẹ́ ‘tọ́ ọ sọ́nà padà’ ní ẹ̀mí ìwà tútù. (Gálátíà 6:1) Nípa gbígba ìbáwí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti fífi ìbànújẹ́ àti ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn, ẹni tí ó ṣìnà kúrò ní ipa ọ̀nà òdodo lè “gba ìmúláradá” nípa tẹ̀mí.—Jákọ́bù 5:13-16.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí Kristẹni kan tí ó ti ṣe batisí bá dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, tí gbogbo ìsapá láti mú un padà sì já sí pàbó ńkọ́? Ní ọ̀rọ̀ míràn, bí ó bá fi oríkunkun kọ̀ láti ṣàtúnṣe ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ńkọ́?
Ó Ń Mú Kí Ìjọ Wà Láìséwu
Bíbélì pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jáwọ́ dídara pọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra ènìyàn tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.”—Kọ́ríńtì Kìíní 5:11.
Òfin Bíbélì yìí ha rorò, tí ó sì ń buni kù bí? Ronú ná nípa èyí: Bí a bá fi ọ̀daràn paraku kan sẹ́wọ̀n nítorí pé ó tẹ òfin lójú, a óò ha wo ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwà òǹrorò tàbí àìláàánú bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé àwọn aráàlú ní ẹ̀tọ́ láti dáàbò bo àlàáfíà àti àìléwu ládùúgbò. Ó túmọ̀ sí pé a yọ ọ̀daràn náà lẹ́gbẹ́ kúrò láwùjọ àwọn olùpa òfin mọ́ lákòókò ìgbà tí ó ń ṣẹ̀wọ̀n.
Bákan náà, ìjọ Kristẹni lẹ́tọ̀ọ́ láti lé ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà jáde kúrò láàárín wọn. Èé ṣe? Nítorí pé ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ àwọn oníwà pálapàla àti àwọn mìíràn tí ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀.
Ní mímọ̀ pé ‘ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lè ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́,’ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.” (Oníwàásù 9:18; Kọ́ríńtì Kìíní 5:13) Ìgbésẹ̀ yìí kò ní jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà tan ìwà ìbàjẹ́ kálẹ̀ nínú ìjọ, ó sì ń dáàbò bo orúkọ rere ìjọ náà.—Fi wé Tímótì Kìíní 3:15.
Ààbò fún Olúkúlùkù
Bákan náà, ìyọlẹ́gbẹ́ ń dáàbò bo olúkúlùkù mẹ́ḿbà ìjọ. Ẹ jẹ́ kí a ṣàpèjúwe: Finú wòye pé ìro fèrè ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí agogo ìdágìrì kán jí ọ láti ojú oorun. Ó ṣòro láti kọtí ikún sí ìró híhan gooro náà; ní ti gidi, ó mú kí o ta gìrì! Bákan náà, nígbà tí a bá lé ẹnì kan jáde kúrò nínú ìjọ, a retí pé kí ìgbésẹ̀ náà gba àfiyèsí olúkúlùkù mẹ́ḿbà agbo náà gidigidi. O máa ń kó ìdààmú bá ọpọlọ wọn. A kò lè ṣàìkọbi ara sí i. Báwo ni èyí ṣe lè jẹ́ ààbò?
Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba pé a ti yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ńṣe ni mo kọ́kọ́ gbọ̀n rìrì. Lẹ́yìn náà, ó rẹ̀ mí sílẹ̀. Ó mú kí n mọ̀ pé èmi pẹ̀lú lè ṣi ẹsẹ̀ gbé.” Bí ọ̀rọ rẹ̀ ṣe fi hàn, ìyọlẹ́gbẹ́ lè mú kí àwọn yòó kù ṣe ìdíyelé ìwà wọn.—Kọ́ríńtì Kìíní 10:12.
Nípa bíbi ara wa ní àwọn ìbéèrè bí ‘Apá kan ha wà nínú ìgbésí ayé mi tí mo ti ṣípayá sí ewu nípa tẹ̀mí bí?’ a lè ràn ara wa lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wo ìdúró àwa tìkára wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Lọ́nà yìí, a lè máa bá a lọ láti ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà àwa tìkára wa yọrí pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.’—Fílípì 2:12.
Padà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run
Kristẹni kan tí a lé jáde fún àkókò kan sọ pé: “Bí ó ti ṣòro tó nígbà náà, ìbáwí náà pọn dandan, mo sì nílò rẹ̀ gan-an, ó sì yọrí sí ìgbẹ̀mílà.” Èyí tẹnu mọ́ apá pàtàkì míràn nípa ìyọlẹ́gbẹ́. Ó lè sún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà tẹ́lẹ̀ rí láti gbé ìgbésẹ̀ wọn àkọ́kọ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.” (Hébérù 12:6) Nígbà tí ó sì jẹ́ òtítọ́ pé “kò sí ìbáwí tí ó dà bí onídùnnú-ayọ̀ nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá fún àwọn wọnnì tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀ a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.”—Hébérù 12:11.
Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Richard nìyẹn. Lẹ́yìn tí a ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì, ó ronú pìwà dà, ó ṣàtúnṣe ìwà rẹ̀ tí ń tàbùkù sí Ọlọ́run, a sì gbà á padà sínú ìjọ Kristẹni. Ní ríronú ìgbà tó ti kọjá, ó sọ nípa ìrírí náà pé: “Mo mọ̀ pé wọ́n ní láti yọ mí lẹ́gbẹ́ àti pé ohun tí wọ́n ṣe fún mi tọ́ sí mi gan-an. Ó pọn dandan ní ti gidi, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti rí bí ipa ọ̀nà mi ṣe wúwo tó àti àìní náà láti wá ìdáríjì Jèhófà.”
Ó lè má rọrùn láti forí ti ìbáwí. Ó ń béèrè ìrẹ̀lẹ̀ láti tẹ́wọ́ gbà á, àmọ́ àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti inú rẹ̀ ń jèrè lọ́pọ̀ yanturu.
Nítorí náà, ìyọlẹ́gbẹ́ jẹ́ ìṣètò onífẹ̀ẹ́ nítorí pé ó ń gbé orúkọ mímọ́ Ọlọ́run lárugẹ, ó sì ń dáàbò bo ìjọ kúrò lọ́wọ́ ipa ìsọdìbàjẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ní. Bákan náà, ó ń fi ìfẹ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà hàn nípa fífún un níṣìírí láti ronú pìwà dà, kí ó sì “yí padà kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [rẹ̀] rẹ́, kí àwọn àsìkò títuni lára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.”—Ìṣe 3:19.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìyọníjọ jẹ́ ìgbésẹ̀ ìbáwí tí ń yọrí sí yíyọni kúrò nínú ìjọ ìsìn kan.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
The New Testament: A Pictorial Archive from Nineteenth-Century Sources, tí Don Rice/Dover Publications, Inc., ṣe