Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Fún Ipò Ọba-aláṣẹ Àtọ̀runwá
“‘Kí ẹ̀yin lè polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè yín jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 PETERU 2:9.
1. Ẹ̀rí gbígbéṣẹ́ wo nípa Jehofa ni a pèsè ní àwọn àkókò tí ó ṣáájú sànmánì àwọn Kristian?
NÍ ÀWỌN àkókò tí ó ṣáájú sànmánì Kristian, ìtògẹ̀ẹ̀rẹ̀ ti àwọn ẹlẹ́rìí jẹ́rìí sí i lọ́nà tí ó ṣe kedere pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà. (Heberu 11:4–12:1) Nítorí ìgbàgbọ́ wọn tí ó lágbára, wọ́n ṣègbọràn sí àwọn òfin Jehofa láìbẹ̀rù wọ́n sì kọ̀ láti fi ọ̀ràn ìjọsìn báni dọ́rẹ̀ẹ́. Wọ́n pèsè ẹ̀rí lílágbára sí ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé ti Jehofa.—Orin Dafidi 18:21-23; 47:1, 2.
2. (a) Ta ni Ẹlẹ́rìí títóbi lọ́lá jù lọ ti Jehofa? (b) Ta ní rọ́pò orílẹ̀-èdè Israeli gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí Jehofa? Báwo ni a ṣe mọ̀?
2 Ẹni tí ó kẹ́yìn tí ó sì tóbi lọ́lá jù lọ nínú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó wà ṣáájú sànmánì Kristian ni Johannu Oníbatisí. (Matteu 11:11) Ó ní àǹfààní láti kéde bíbọ̀ Àyànfẹ́ náà, ó sì tọ́ka sí Jesu gẹ́gẹ́ bí Messia tí a ṣèlérí náà. (Johannu 1:29-34) Jesu ni Ẹlẹ́rìí títóbi lọ́lá jù lọ tí Jehofa ní, “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ati olóòótọ́.” (Ìṣípayá 3:14) Nítorí pé Israeli àbínibí kọ Jesu sílẹ̀, Jehofa kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ó sì yan orílẹ̀-èdè tuntun, Israeli tẹ̀mí ti Ọlọrun, láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Isaiah 42:8-12; Johannu 1:11, 12; Galatia 6:16) Peteru ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Israeli ó sì fi hàn pé ó bá “Israeli Ọlọrun,” ìjọ Kristian mu, nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà-ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, awọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ̀yin lè polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè yín jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 Peteru 2:9; Eksodu 19:5, 6; Isaiah 43:21; 60:2.
3. Kí ni ẹrù iṣẹ́ onípò kìíní ti Israeli Ọlọrun àti ti “ogunlọ́gọ̀ ńlá”?
3 Àwọn ọ̀rọ̀ Peteru fi hàn pé ẹrù iṣẹ́ onípò kìíní ti Israeli Ọlọrun ni láti pèsè ìjẹ́rìí ní gbangba nípa ògo Jehofa. Ní ọjọ́ wa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn ẹlẹ́rìí ti darapọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí, tí àwọn pẹ̀lú ń yin Ọlọrun lógo ní gbangba. Wọ́n ké pẹ̀lú ohùn rara fún gbogbo mùtúmùwà láti gbọ́ pé: “Ọlọrun wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa ni awa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà.” (Ìṣípayá 7:9, 10; Isaiah 60:8-10) Báwo ni Israeli Ọlọrun àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ ṣe lè ṣàṣeparí ìjẹ́rìí wọn? Nípa ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn wọn ni.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Èké
4. Èé ṣe tí àwọn Júù ọjọ́ Jesu fi jẹ́ ẹlẹ́rìí èké?
4 Ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn wé mọ́ gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọrun. Ìjẹ́pàtàkì èyí ni a rí nínú ohun tí Jesu sọ nípa àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní ọjọ́ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí “mú ara wọn jókòó ní ìjókòó Mose” gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ Òfin. Wọ́n tilẹ̀ rán àwọn míṣọ́nnárì láti yí àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kàn padà. Síbẹ̀, Jesu wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin a máa la òkun ati ilẹ̀ gbígbẹ kọjá lati sọ ẹni kan di aláwọ̀ṣe, nígbà tí ó bá sì di ọ̀kan ẹ̀yin a sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu Gẹ̀hẹ́nà ní ìlọ́po méjì ju ara yín lọ.” Àwọn onísìn wọ̀nyí jẹ́ ẹlẹ́rìí èké—ọ̀fẹgẹ̀, alágàbàgebè, àti aláìnífẹ̀ẹ́. (Matteu 23:1-12, 15) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan Jesu wí fún àwọn Júù kan pé: “Lati ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ lati ṣe awọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.” Èé ṣe tí ó fi níláti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí àwọn mẹ́ḿbà orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọrun? Nítorí pé wọn kì yóò kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́rìí títóbi lọ́lá jù lọ ti Jehofa.—Johannu 8:41, 44, 47.
5. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Kristẹndọm ti pèsè ẹ̀rí èké nípa Ọlọrun?
5 Lọ́nà jíjọra, ní àwọn ọ̀rúndún láti àkókò Jesu, ọ̀gọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ní Kristẹndọm ti jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò tí ì ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, nípa bẹ́ẹ̀ Jesu kò mọ̀ wọ́n. (Matteu 7:21-23; 1 Korinti 13:1-3) Kristẹndọm ti rán àwọn míṣọ́nnárì jáde, láìsí iyè méjì ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ olóòótọ́ ọkàn. Síbẹ̀, wọ́n kọ́ àwọn ènìyàn láti jọ́sìn ọlọrun Mẹ́talọ́kan tí ń dáná sun àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú hẹ́ẹ̀lì oníná, ẹ̀rí tí ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn tí wọ́n ti yí lọ́kàn padà ní láti fi hàn pé àwọn jẹ́ Kristian kò tó nǹkan. Fún àpẹẹrẹ, ilẹ̀ Rwanda ní Africa ti jẹ́ pápá ọlọ́ràá fún àwọn míṣọ́nnárì Roman Katoliki. Síbẹ̀, àwọn Katoliki ní Rwanda fi tọkàntọkàn lọ́wọ́ nínú ogun ẹ̀yà tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ní ilẹ̀ náà. Èso inú pápá míṣọ́nnárì náà fi hàn pé kó rí ojúlówó ìjẹ́rìí Kristian gbà láti ọ̀dọ̀ Kristẹndọm.—Matteu 7:15-20.
Gbígbé ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Ọlọrun
6. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìwà títọ́ gbà jẹ́ apá tí ó ṣe pàtàkì ní ti pípèsè ẹ̀rí?
6 Ìwà àìtọ́ àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian ń mú ẹ̀gàn wa sórí “ọ̀nà òtítọ́.” (2 Peteru 2:2) Ojúlówó Kristian kan ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọrun. Kì í jalè, parọ́, rẹ́ni jẹ, tàbí hu ìwà pálapàla. (Romu 2:22) Ó dájú pé kì í pa aládùúgbò rẹ̀. Àwọn Kristian ọkọ ń ṣàbójútó onífẹ̀ẹ́ lórí ìdílé wọn. Àwọn aya ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ti àbójútó náà lẹ́yìn. Àwọn òbí ń kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń tipa báyìí wà ní ìmúrasílẹ̀ láti di Kristian àgbàlagbà tí ó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́. (Efesu 5:21–6:4) Òtítọ́ ni pé, gbogbo wa jẹ́ aláìpé tí a sì ń ṣe àṣìṣe. Ṣùgbọ́n Kristian gidi ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli ó sì ń ṣe ojúlówó ìsapá láti fi wọ́n sílò. Àwọn mìíràn ń ṣàkíyèsí èyí ó sì ń fún wọn ní ẹ̀rí àtàtà. Nígbà mìíràn, àwọn tí wọ́n ti ń tako òtítọ́ tẹ́lẹ̀ ṣàkíyèsí ìwà títọ́ ti Kristian kan, a sì jèrè wọn.—1 Peteru 2:12, 15; 3:1.
7. Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn Kristian nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì?
7 Jesu fi apá tí ó ṣe pàtàkì nínú ìwà Kristian hàn nígbà tí ó wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:35) A dá ayé Satani mọ̀ yàtọ̀ pẹ̀lú “àìṣòdodo, ìwà burúkú, ojúkòkòrò, ìwà búburú, wọ́n kún fún ìlara, ìṣìkàpànìyàn, gbọ́nmisi-omi-ò-to, ẹ̀tàn, inú burúkú, wọn jẹ́ asọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́, awọn asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, olùkórìíra Ọlọrun, aláfojúdi, onírera, ajọra-ẹni-lójú, olùhùmọ̀ ohun aṣeniléṣe, aṣàìgbọràn sí òbí.” (Romu 1:29, 30) Nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀, ètò-àjọ kárí-ayé kan tí a fi ìfẹ́ dá mọ̀ yàtọ̀ yóò jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé ẹ̀mí Ọlọrun wà lẹ́nu iṣẹ́—ẹ̀rí gbígbéṣẹ́ kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa para pọ̀ jẹ́ irú ètò-àjọ bẹ́ẹ̀.—1 Peteru 2:17.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli
8, 9. (a) Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Òfin Ọlọrun àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀ ṣe fún onipsalmu lókun? (b) Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àṣàrò ṣe ń fún wa lókun láti máa bá nìṣó ní jíjẹ́rìí?
8 Láti ṣàṣeyọrí nínú jíjẹ́rìí àtàtà, Kristian kan níláti mọ àwọn ìlànà òdodo Jehofa kí ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn kí ó sì kórìíra ìwà ìbàjẹ́ ayé nítòótọ́. (Orin Dafidi 97:10) Ayé jẹ́ ayíniléròpadà nínú gbígbé ìrònú tirẹ̀ lárugẹ, ó sì lè nira láti dènà ẹ̀mí rẹ̀. (Efesu 2:1-3; 1 Johannu 2:15, 16) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti di ìṣarasíhùwà èrò-orí tí ó tọ́ mú? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé tí ó sì ní ìtumọ̀ ni. Òǹkọ̀wé Orin Dafidi 119 sọ ìfẹ́ rẹ̀ fún Òfin Jehofa jáde léraléra ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ó kà á ó sì ṣàṣàrò lé e lórí nígbà gbogbo, “ní ọjọ́ gbogbo.” (Orin Dafidi 119:92, 93, 97-105) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ó lè kọ̀wé pé: “Èmi kórìíra mo sì ṣe họ́ọ̀ sí èké ṣíṣe: ṣùgbọ́n òfin rẹ ni mo fẹ́.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ rẹ̀ sún un láti gbé ìgbésẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà méje ní òòjọ́ ni èmi ń yìn ọ́ nítorí òdodo ìdájọ́ rẹ.”—Orin Dafidi 119:163, 164.
9 Lọ́nà jíjọra, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀ yóò gbún ọkàn-àyà wa ní kẹ́ṣẹ́ yóò sì sún wa láti ‘yìn ín’—jẹ́rìí nípa Jehofa—nígbà gbogbo, àní “nígbà méje ní òòjọ́.” (Romu 10:10) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, òǹkọ̀wé psalmu kìíní sọ pé ẹnì kan tí ó bá ń ṣàṣàrò déédéé lórí àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa “yóò . . . dàbí igi tí a gbìn sí etí ipa odò, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀; ewé rẹ̀ kì yóò sì rẹ̀; àti ohunkóhun tí ó ṣe ni yóò máa ṣe déédéé.” (Orin Dafidi 1:3) Aposteli Paulu pẹ̀lú fi àgbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní hàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo, kí ènìyàn Ọlọrun lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Timoteu 3:16, 17.
10. Kí ni ó ṣe kedere nípa àwọn ènìyàn Jehofa ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
10 Ìbísí yíyá kánkán nínú iye àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní ọ̀rúndún ogun yìí fi ìbùkún Jehofa hàn. Láìsí iyè méjì kankan, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan, àwọn ẹlẹ́rìí òde-òní wọ̀nyí fún ipò ọba-aláṣẹ ti Ọlọrun ti mú ìfẹ́ fún òfin Jehofa dàgbà ní ọkàn-àyà wọn. Gẹ́gẹ́ bí onipsalmu náà, a ti sún wọn láti ṣègbọràn sí òfin Rẹ̀ kí wọ́n sì jẹ́rìí lọ́nà tí ó ṣeé gbára lé “tọ̀sán tòru” nípa ògo Jehofa.—Ìṣípayá 7:15.
Àwọn Iṣẹ́ Agbára-Ńlá ti Jehofa
11, 12. Kí ni a ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́-ìyanu tí Jesu àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe?
11 Ní ọ̀rúndún kìíní, ẹ̀mí mímọ́ fi agbára fún àwọn Kristian ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́-ìyanu, èyí tí ó fi ẹ̀rí lílágbára hàn pé òtítọ́ ni ẹ̀rí wọn. Nígbà tí Johannu Oníbatisí wà nínú túbú, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti béèrè lọ́wọ́ Jesu pé: “Ṣe iwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀ naa, tabi kí a máa fojúsọ́nà fún ẹni kan tí ó yàtọ̀?” Jesu kò dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó wí pé: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ kí ẹ sì ròyìn fún Johannu ohun tí ẹ ń gbọ́ tí ẹ sì ń rí: Awọn afọ́jú tún ń ríran, awọn arọ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ awọn adẹ́tẹ̀ mọ́ awọn adití sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé awọn òkú dìde, a sì ń polongo ìhìnrere fún awọn òtòṣì; aláyọ̀ sì ni ẹni naa tí kò rí okùnfà kankan fún ìkọ̀sẹ̀ ninu mi.” (Matteu 11:3-6) Àwọn iṣẹ́ agbára wọ̀nyí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún Johannu pé ní tòótọ́ Jesu ni “Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà.”—Ìṣe 2:22.
12 Lọ́nà jíjọra, àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu mú aláìsàn lára dá wọ́n tilẹ̀ jí òkú dìde. (Ìṣe 5:15, 16; 20:9-12) Àwọn iṣẹ́-ìyanu wọ̀nyí dàbí ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun fúnra rẹ̀ nítorí wọn. (Heberu 2:4) Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sì fi agbára ńlá ti Jehofa hàn. Fún àpẹẹrẹ, òtítọ́ ni pé Satani, “olùṣàkóso ayé,” ní agbára láti ṣokùnfà ikú. (Johannu 14:30; Heberu 2:14) Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru jí Dorka obìnrin olùṣòtítọ́ náà dìde láti inú òkú, kìkì nípasẹ̀ agbára Jehofa ni ó fi lè ṣe é, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Òun nìkan ni ó lè dá ìwàláàyè padà.—Orin Dafidi 16:10; 36:9; Ìṣe 2:25-27; 9:6-43.
13, (a) Ní ọ̀nà wo ni àwọn iṣẹ́-ìyanu inú Bibeli ṣì gbà ń jẹ́rìí sí agbára Jehofa? (b) Báwo ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ṣe kó ipa pàtàkì nínú jíjẹ́rìí sí jíjẹ́ tí Jehofa jẹ́ Ọlọrun?
13 Lónìí, àwọn iṣẹ́-ìyanu wọ̀nyẹn kì í ṣẹlẹ̀ mọ́. Wọ́n ti mú ète wọn ṣẹ. (1 Korinti 13:8) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ṣì ní àkọsílẹ̀ wọn nínú Bibeli, tí ọ̀pọ̀ àwọn òǹwòran jẹ́rìí sí. Nígbà tí àwọn Kristian lónìí bá darí àfiyèsí sí àwọn àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn wọ̀nyí, àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn ṣì ń fúnni ní ẹ̀rí gbígbéṣẹ́ sí agbára Jehofa. (1 Korinti 15:3-6) Ní àfikún sí i, ní ọjọ́ Isaiah lọ́hùn-ún, Jehofa tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ pípéye gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títayọ lọ́lá pé Òun ni Ọlọrun tòótọ́. (Isaiah 46:8-11) Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tí ó ní ìmísí Ọlọrun ni a ti ń múṣẹ lónìí—púpọ̀ lára wọn jẹ́ lórí ìjọ Kristian. (Isaiah 60:8-10; Danieli 12:6-12; Malaki 3:17, 18; Matteu 24:9; Ìṣípayá 11:1-13) Papọ̀ pẹ̀lú títọ́ka sí i ní pàtó pé a ń gbé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí dá Jehofa láre gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—2 Timoteu 3:1.
14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀-ìtàn òde-òní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé Jehofa ni Oluwa Ọba-Aláṣẹ?
14 Lákòótán, Jehofa ṣì ń ṣe àwọn nǹkan ńláǹlà, nǹkan àgbàyanu, fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ̀mí Jehofa ní ń darí ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ sí i lórí òtítọ́ Bibeli. (Orin Dafidi 86:10; Ìṣípayá 4:5, 6) Ìbísí títayọ lọ́lá tí a ròyìn rẹ̀ yíká ayé jẹ́ ẹ̀rí pé Jehofa ‘ń ṣe é kánkán ní àkókò rẹ̀.’ (Isaiah 60:22) Nígbà tí ó jẹ́ pé inúnibíni kíkorò ti bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan tẹ̀ lé òmíràn jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìfaradà onígboyà ti àwọn ènìyàn Jehofa ti ṣeé ṣe nítorí ìtìlẹ́yìn afúnnilókun tí ẹ̀mí mímọ́ ń fún wọn. (Orin Dafidi 18:1, 2, 17, 18; 2 Korinti 1:8-10) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀-ìtàn òde-òní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé Jehofa ni Oluwa Ọba-Aláṣẹ.—Sekariah 4:6.
Ìhìnrere náà tí A Níláti Wàásù
15. Ìjẹ́rìí gbígbòòrò wo ni ìjọ Kristian níláti pèsè?
15 Jehofa yan Israeli gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè. (Isaiah 43:10) Bí ó ti wù kí ó rí, kìkì díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israeli ni a pàṣẹ fún látọ̀runwá láti lọ kí wọ́n sì wàásù fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israeli, èyí sì máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígba gbogbo láti baà lè kéde ìdájọ́ Jehofa. (Jeremiah 1:5; Jona 1:1, 2) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu fi hàn pé ní ọjọ́ kan Jehofa yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà gbígbòòrò, èyí ni ó sì ti ṣe nípasẹ̀ Israeli tẹ̀mí ti Ọlọrun. (Isaiah 2:2-4; 62:2) Ṣáájú kí ó tó gòkè lọ sí ọ̀run, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn.” (Matteu 28:19) Níwọ̀n bí Jesu ti darí gbogbo àfiyèsí sí “awọn àgùtàn ilé Israeli tí wọ́n sọnù,” a rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sí “gbogbo orílẹ̀-èdè,” àní “títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” (Matteu 15:24; Ìṣe 1:8) Gbogbo aráyé níláti gbúròó àwọn Kristian ẹlẹ́rìí náà.
16. Iṣẹ́-àṣẹ wo ni ìjọ Kristian ọ̀rúndún kìíní múṣẹ, dé ayé wo sì ni?
16 Paulu fi hàn pé òun lóye èyí dáradára. Ní ọdún 61 C.E., ó lè sọ pé ìhìnrere náà ti “ń so èso tí ó sì ń bí sí i ní gbogbo ayé.” A kò fi ìhìnrere náà mọ sí kìkì orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹ̀ya-ìsìn kan, irú èyí tí ń lọ́wọ́ nínú “ìjọsìn awọn áńgẹ́lì.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a “wàásù” rẹ̀ ní gbangba “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kolosse 1:6, 23; 2:13, 14, 16-18) Nípa bẹ́ẹ̀, Israeli Ọlọrun ní ọ̀rúndún kìíní mú iṣẹ́-àṣẹ rẹ̀ ṣẹ láti “‘polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá’ ẹni naa tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”
17. Báwo ni Matteu 24:14 ṣe ń bá a lọ láti ní ìmúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò?
17 Síbẹ̀síbẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ti ọ̀rúndún kìíní náà wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò ṣáájú nípa ohun tí a óò ṣàṣeparí rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni. Ní fífojúsọ́nà ní pàtàkì fún ọjọ́ wa, Jesu wí pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” (Matteu 24:14; Marku 13:10) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ha ti ní ìmúṣẹ bí? Ní tòótọ́, ó ti ní ìmúṣẹ. Láti orí ìbẹ̀rẹ̀ kékeré ní 1919, ìwàásù ìhìnrere náà ti nasẹ̀ nísinsìnyí dé orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 230. A ń gbúròó ẹ̀rí náà ní àwọn ibi títutù bíi yìnyín ní ìhà Àríwá Ayé àti ní àwọn orílẹ̀-èdè olóoru. A ti kárí àwọn kọ́ńtínẹ̀ǹtì ńlá, a sì ti wá àwọn erékùṣù jíjìnnà réré rí kí àwọn olùgbé wọn baà lè rí ẹ̀rí gbà. Àní láàárín rúkèrúdò ńláǹlà pàápàá, irú bí ogun ní Bosnia àti Herzegovina, ìwàásù ìhìnrere náà ṣì ń bá a nìṣó. Gẹ́gẹ́ bí o tí rí ní ọ̀rúndún kìíní, ẹ̀rí náà ń so èso “ní gbogbo ayé.” A ń kéde ìhìnrere náà ní gbangba “ninu gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àkọ́kọ́ ni pé, a ti ṣe ìkójọpọ̀ àwọn àṣẹ́kù Israeli Ọlọrun “lati inú gbogbo ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n ati awọn orílẹ̀-èdè.” Èkejì ni pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ni a bẹ̀rẹ̀ sí mú wọlé láti inú “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” (Ìṣípayá 5:9; 7:9) Matteu 24:14 ń bá a nìṣó láti ní ìmúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò.
18. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí a ti ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ ìwàásù ìhìnrere náà kárí-ayé?
18 Ìwàásù ìhìnrere náà kárí-ayé ń ràn wá lọ́wọ́ láti fẹ̀rí hàn pé wíwàníhìn-ín ọlọ́ba ti Jesu ti bẹ̀rẹ̀. (Matteu 24:3) Síwájú sí i, òun ni ọ̀nà pàtàkì náà nípasẹ̀ èyí tí a ń ṣe “ìkórè ilẹ̀-ayé,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń darí àwọn ènìyàn sí kìkì ìrètí tòótọ́ fún aráyé, Ìjọba Jehofa. (Ìṣípayá 14:15, 16) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì àwọn ojúlówó Kristian ní ń lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìnrere náà, iṣẹ́ pàtàkì yìí ń ṣèrànwọ́ láti dá àwọn Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ti èké. (Malaki 3:18) Lọ́nà yìí, ó ń ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà àwọn tí ń wàásù, bákan náà sì ni fún àwọn tí ń dáhùn padà. (1 Timoteu 4:16) Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, wíwàásù ìhìnrere náà ń mú ìyìn àti ọlá wá fún Jehofa Ọlọrun, ẹni náà tí ó pàṣẹ pé kí a ṣe é, tí ń ti àwọn tí ń ṣe é lẹ́yìn, tí ó sì ń mu kí ó so èso.—2 Korinti 4:7.
19. Ìpinnu wo ni a fún gbogbo Kristian ní ìṣírí láti ní bí wọ́n ṣe ń wọnú ọdún iṣẹ́-ìsìn tuntun?
19 Abájọ nígbà náà tí a fi sún aposteli Paulu láti sọ pé: “Ègbé ni fún mi bí emi kò bá polongo ìhìnrere!” (1 Korinti 9:16) Irú ìmọ̀lára kan náà ni àwọn Kristian ní lónìí. Àǹfààní kíkọyọyọ àti ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà ni ó jẹ́ láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun,” ní títan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ nínú ayé tí òkùnkùn ti bò mọ́lẹ̀ yìí. (1 Korinti 3:9; Isaiah 60:2, 3) Iṣẹ́ tí ó ní ìbẹ̀rẹ̀ kékeré ní 1919 ti dé ìwọ̀n tí ń mú háà ṣeni nísinsìnyí. Àwọn Kristian tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù márùn-ún ni ń jẹ́rìí fún ipò-ọba-aláṣẹ àtọ̀runwá bí wọn ṣe ń lo wákàtí tí ó lé ní bílíọ̀nù kan lọ́dún láti mú ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà náà tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ láti ní ìpín nínú iṣẹ́ ti sísọ orúkọ Jehofa di mímọ́ yìí! Bí a ti ń wọnú ọdún iṣẹ́-ìsìn 1996, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti má ṣe dẹ̀rìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a óò kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sí Timoteu pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ naa, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” (2 Timoteu 4:2) Bí a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, a gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa pé Jehofa yóò máa bá a nìṣó láti bùkún ìsapá wa.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ta ní rọ́pò Israeli gẹ́gẹ́ bí “ẹlẹ́rìí” Jehofa fún àwọn orílẹ̀-èdè?
◻ Báwo ni ìwà Kristian ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú pípèsè ẹ̀rí?
◻ Èé ṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àṣàrò lórí rẹ̀ fi ṣe kókó fún Kristian Ẹlẹ́rìí?
◻ Ní ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀-ìtàn òde-òní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi jẹ́ ẹ̀rí pé Jehofa ni Ọlọrun tòótọ́?
◻ Kí ni a ṣàṣeparí rẹ̀ nípa wíwàásù ìhìnrere náà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Dípò dídí i lọ́wọ́, ìhìnrere náà ni a ń polongo nísinsìnyí “ninu gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run”