Ìtùnú àti Ìṣírí—Àwọn Ohun Iyebíye Alápá Púpọ̀
PÚPỌ̀ jù lọ nínú wa ti la àwọn àkókò kan kọjá, nígbà tí a nímọ̀lára jíjẹ́ òtòṣì gidigidi—kì í ṣe òtòṣì nípa ti ara, ṣùgbọ́n otòṣì nípa tẹ̀mí. Ìrẹ̀wẹ̀sì ńláǹlà bá wa, a tilẹ̀ sorí kọ́. Síbẹ̀, ní irú àwọn àkókò yẹn, a ti lè ní ohun iyebíye kan níkàáwọ́ wa, tí ó lè ṣe wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore. “Ohun iyebíye” yẹn ni ìṣírí.
Nínú Bibeli, ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà ni a lò fún “fún ní ìṣírí” àti “tù nínú.” Àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì gbé ìtumọ̀ fífúnni ní ìgboyà, okun tàbí ìrètí jáde. Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, nígbà tí ó bá rẹ̀ wá tàbí tí a bá rẹ̀wẹ̀sì, ìtùnú àti ìṣírí gan-an ni a nílò. Níbo ni a ti lè rí wọn?
Bibeli fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé, Jehofa ni “Ọlọrun ìtùnú gbogbo.” (2 Korinti 1:3) Ó tún sọ fún wa pé “kò jìnnà sí ẹni kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Nítorí náà, ìtùnú àti ìṣírí wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Jẹ́ kí a gbé àwọn ọ̀nà mẹ́rin pàtàkì nípasẹ̀ èyí tí Jehofa gbà ń fúnni ní ìṣírí yẹ̀ wò.
Nípasẹ̀ Ipò Ìbátan Tí Ẹnì Kan Ní Pẹ̀lú Ọlọrun
Ipò ìbátan tí ẹnì kan ní pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun ni orísun ìtùnú títóbi jù lọ. Ìṣírí ni ó jẹ́ pé, irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe pàápàá. Ó ṣe tán, alákòóso ayé wo ni yóò gbà, kí a máa tẹ òun láago, tàbí tí yóò fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ hàn nínú àwọn ìṣòro wa? Jehofa lágbára fíìfíì ju irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ. Síbẹ̀, òún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀—ó múra tán pátápátá láti bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, tí ó rẹlẹ̀ lò. (Orin Dafidi 18:35) Jehofa tilẹ̀ ti lo àtinúdá náà ní fífi ìfẹ́ hàn sí wa. Johannu Kíní 4:10 sọ pé: “Ìfẹ́ naa jẹ́ lọ́nà yii, kì í ṣe pé awa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun, bíkòṣe pé oun nífẹ̀ẹ́ wa ó sì rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Síwájú sí i, Jehofa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ fà wá sún mọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀.—Johannu 6:44.
O ha ti dáhùn padà, tí o sì ti wá ìtùnú nínú bíbá Ọlọrun dọ́rẹ̀ẹ́ bí? (Fi wé Jakọbu 2:23.) Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn kan, tí ó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí ọ, kì yóò ha jẹ́ ohun tí ó gbádùn mọ́ni láti lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ìwọ nìkan, kí o sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa àwọn àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn rẹ, àwọn ìrètí àti ayọ̀ rẹ bí? Jehofa ń ké sí ọ láti ṣe ohun kan náà pẹ̀lú òun. Kò fi òté lé iye àkókò tí o lè bá òun sọ̀rọ̀ nínú àdúrà—ó sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ ní tòótọ́. (Orin Dafidi 65:2; 1 Tessalonika 5:17) Jesu gbàdúrà déédéé àti pẹ̀lú ìtara ọkàn. Ní tòótọ́, ṣáájú yíyan àwọn aposteli rẹ̀ 12, ó fi gbogbo òru gbàdúrà.—Luku 6:12-16; Heberu 5:7.
Láti ìgbà dé ìgbà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gbìyànjú láti dá wà pẹ̀lú Jehofa. Wíwulẹ̀ jókòó jẹ́ẹ́ lójú fèrèsé tàbí dídọ́gbẹ̀ẹ́rẹ́ lè pèsè àǹfààní dídára láti ṣí ọkàn wa payá fún Jehofa nínú àdúrà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ orísun ìtura àlàáfíà àti ìtùnú kíkọyọyọ. Bí a bá ní àwọn ìṣẹ̀dá Jehofa kan tí a fẹ́ wò bí a ṣe ń ṣàṣàrò—bí ó tilẹ̀ jẹ́ apá kan àwọsánmà, àwọn igi tàbí ẹyẹ—a lè rí àwọn ìránnilétí atunilára ti ìfẹ́ Jehofa àti ìdàníyàn rẹ̀ fún wa, nínú wọn.—Romu 1:20.
Nípasẹ̀ Dídá Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nípasẹ̀ dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a fi ń ṣí àwọn ànímọ́ Jehofa payá fún wa. Léraléra ni Bibeli fi Jehofa hàn pé ó jẹ́ “Ọlọrun aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, onípamọ́ra, àti ẹni tí ó pọ̀ ní oore.” (Eksodu 34:6; Nehemiah 9:17; Orin Dafidi 86:15) Ìfẹ́ ọkàn láti tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé nínú jẹ́ apá pàtàkì kan nínú àkópọ̀ ìwà Jehofa.
Fún àpẹẹrẹ, ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa nínú Isaiah 66:13 tí ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi óò tù yín nínú.” Jehofa pète ìfẹ́ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ onífara-ẹni-rúbọ àti adúróṣinṣin. Bí o bá ti rí ìyá onífẹ̀ẹ́ tí ń tu ọmọ rẹ̀ tí ó fara pa nínú rí, ìwọ yóò mọ ohun tí Jehofa ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé, òun yóò tu àwọn ènìyàn òun nínú.
Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ Bibeli fi bí irú ìtùnú bẹ́ẹ̀ ṣe ṣiṣẹ́ hàn. Nígbà tí Ayaba Jesebeli búburú fi ikú halẹ̀ mọ́ wòlíì Elija, ẹ̀rú bà á, ó sì sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. Ó sorí kọ́ débi pé, ó fi odindi ọjọ́ kan rìn lọ sínú aginjù, ó sì dájú pé, kò gbé omi tàbí oúnjẹ kankan lọ́wọ́. Nínú làásìgbò, Elija sọ fún Jehofa pé, òún fẹ́ kú. (1 Awọn Ọba 19:1-4) Kí ni Jehofa ṣe láti tu wòlíì náà nínú, kí ó sì fún un níṣìírí?
Jehofa kò bá Elija wí fún nínímọ̀lára ìdánìkanwà, àìjámọ́ nǹkan kan, àti fún bíbẹ̀rù. Ní òdì kejì, wòlíì náà gbọ́ “ohùn kẹ́lẹ́, kékeré.” (1 Awọn Ọba 19:12) Bí o bá ka 1 Awọn Ọba orí 19, ìwọ yóò rí i bí Jehofa ṣe tu Elija nínú, tí ó tù ú lára, tí ó sì gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ró. Ìtùnú yìí kì í ṣe oréfèé. Ó wọnú ọkàn Elija tí ìdààmú ti bá gan-an lọ, ní fífún wòlíì náà níṣìírí láti máa bá a lọ. (Fi wé Isaiah 40:1, 2.) Láìpẹ́, ó padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Bákan náà, Jesu Kristi ń tu àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ adúróṣinṣin nínú, ó sì ń fún wọn níṣìírí. Ní tòótọ́, Isaiah sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Messia náà pé: “Oluwa Jehofa . . . ti rán mi láti ṣe àwòtán àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn, . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń gbààwẹ̀ nínú.” (Isaiah 61:1-3) Nígbà ayé rẹ̀, Jesu mú un ṣe kedere pé, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ sí òun lára. (Luku 4:17-21) Bí o bá rí i pé, o nílò ìtùnú, ṣàṣàrò lórí ìwà pẹ̀lẹ́ Jesu, ìbálò onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí a bà lọ́kàn jẹ́, tí wọ́n sì wà ní ipò àìní. Ní tòótọ́, fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jẹ́ orísun ìtùnú àti ìṣírí ńláǹlà.
Nípasẹ̀ Ìjọ
Nínú ìjọ Kristian, àwọn ohun iyebíye ti ìtùnú àti ìṣírí ń tàn yinrin ní apá púpọ̀ wọn. A mí sí aposteli Paulu láti kọ̀wé pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nìkínní kejì.” (1 Tessalonika 5:11) Báwo ni a ṣe lè rí ìtùnú àti ìṣírí gbà ní àwọn ìpàdé ìjọ?
Dájúdájú, lákọ̀ọ́kọ́, a ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristian kí ‘Jehofa baà lè kọ́ wa.’ kí a lè rí ìsọfúnni gbà nípa rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Johannu 6:45) A pète irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ láti fúnni níṣìírí àti ìtùnú. Ní Ìṣe 15:32, a kà pé: “Judasi ati Sila fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún awọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.”
Ìwọ ha ti fìgbà kan nírìírí rẹ̀ rí pé, o lọ sí ìpàdé Kristian nígbà tí o sorí kọ́, tí o sì padà wá sílé pẹ̀lú ara yíyá gágá bí? Bóyá ohun kan tí a sọ nínú àsọyé, nínú ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí, tàbí nínú àdúrà gbún ọkàn rẹ ní kẹ́ṣẹ́, tí ó sì pèsè ìtùnú àti ìṣírí tí o nílò. Nítorí náà, má ṣe máa pa àwọn ìpàdé Kristian jẹ.—Heberu 10:24, 25.
Dídara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ní àwọn ìgbà míràn lè ní ipa kan náà. Nínú èdè Heberu, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe mélòó kan tí ó túmọ̀ sí “láti so pa pọ̀” tún túmọ̀ sí “okun” tàbí “láti fún lókun”—èrò tí ó ṣe kedere náà ni pé, nǹkan túbọ̀ ń lágbára sí i, nígbà tí a bá so ó pọ̀. Ìlànà yìí já sí òtítọ́ nínú ìjọ. Wíwà pa pọ̀ ń tù wá nínú, ó ń fún wa níṣìírí, àní, ó ń fún wa lókun. Ìfẹ́, ìdè lílágbára jù lọ, ni ó so wá pọ̀.—Kolosse 3:14.
Nígbà míràn, ìṣòtítọ́ àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa nípa tẹ̀mí ní ń fún wa níṣìírí. (1 Tessalonika 3:7, 8) Nígbà míràn, ó máa ń jẹ́ ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn. (Filemoni 7) Nígbà míràn, ó sì máa ń jẹ́ wíwulẹ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, nígbà tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun. Bí ó bá rẹ̀ ọ́, tí o sì nílò ìṣírí nígbà tí ó bá di ọ̀ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́, èé ṣe tí o kò fi ṣètò láti bá akéde Ìjọba mìíràn tí ó dàgbà jù ọ́ lọ tàbí tí ó nírìírí jù ọ́ lọ ṣiṣẹ́? Ó ṣeé ṣe kí o rí ìtùnú púpọ̀ sí i nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—Oniwasu 4:9-12; Filippi 1:27.
Nípasẹ̀ “Olùṣòtítọ́ ati Ọlọ́gbọ́n-Inú Ẹrú”
Ta ni ń ṣètò àwọn apá ìjọsìn wa tí ń tuni nínú? Jesu yan ẹgbẹ́ kan sípò, ẹni tí ó pè ní “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí yóò máa pín “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.” (Matteu 24:45) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ àwọn Kristian ẹni àmì òróró yìí wà lẹ́nu iṣẹ́. Ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti àwọn alàgbà ní Jerusalemu kọ lẹ́tà afúnninítọ̀ọ́ni àti atọ́nisọ́nà sí àwọn ìjọ. Kí ni ó yọrí sí? Bibeli kọ bí àwọn ìjọ ṣe hùwà padà sí irú lẹ́tà kan bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, wọ́n yọ̀ nitori ìṣírí naa.”—Ìṣe 15:23-31.
Bákan náà, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko wọ̀nyí, olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà ń pín oúnjẹ tẹ̀mí tí ń pèsè ìtùnú àti ìṣírí ńláǹlà fún àwọn ènìyàn Jehofa. Ìwọ ha ń jẹ nínú oúnjẹ náà bí? Ó wà ní sẹpẹ́ nínú àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú náà mú wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní gbogbo ayé. Àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tí Watch Tower Society ń tẹ̀ jáde ti mú ìtùnú wá fún àìmọye àwọn òǹkàwé.
Alábòójútó arìnrìn àjò kan kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n wọ́n sábà máa ń bá ìjákulẹ̀, ìbẹ̀rù àti ìmọ̀lára pé wọn kò lágbára láti ran ara wọn lọ́wọ́ jìjàkadì. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé àtìgbàdégbà wa ń ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti jèrè ìṣàkóso ìgbésí ayé àti ìmọ̀lára wọn padà. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà tún ń fún àwọn alàgbà ní àwọn ohun púpọ̀ sí i tí wọ́n lè fúnni, tí ó ju ìṣírí oréfèé lọ.”
Lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ẹrú náà dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Àwọn ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí ó bá ìgbà mu, lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtùnú, nígbà tí sànmánì bá lọ́ tín-ín-rín. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí o bá wà ní ipò láti fún ẹnì kan tí ó rẹ̀wẹ̀sì ní ìṣírí, lo ìsọfúnni tí a gbé karí Ìwé Mímọ́, tí ó wà nínú àwọn ìwé àtìgbàdégbà yìí. A kọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú ìṣọ́ra gidigidi, lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn ìwádìí àfìṣọ́raṣe, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà, fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù. A gbé ìmọ̀ràn náà karí Bibeli, a ti yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì jẹ́ òtítọ́. Àwọn kan ti rí i pé, ó ń ṣèrànwọ́ púpọ̀ láti ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan tàbí méjì tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ẹni kan tí ó rẹ̀wẹ̀sì. Èyí lè yọrí sí ìtùnú àti ìṣírí púpọ̀.
Bí o bá rí ohun iyebíye, ìwọ yóò ha kó o pa mọ́, tàbí ìwọ yóò ṣàjọpín díẹ̀ lára ọrọ̀ náà fàlàlà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bí? Fi í ṣe góńgó láti jẹ́ orísun ìtùnú àti ìṣírí fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ nínú ìjọ. Bí o bá ń gbéni ró dípò bíbani jẹ́, tí o ń gbóríyìn fúnni dípò ṣíṣe lámèyítọ́, tí o ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “ahọ́n ẹni tí a kọ́” dípò sísọ̀rọ̀ “lásán bí ìgúnni idà,” o lè mú ìyípadà wá nínú ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn. (Isaiah 50:4; Owe 12:18) Ní tòótọ́, ó ṣeé ṣe kí a wo ìwọ fúnra rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun iyebíye—orísun ojúlówó ìtùnú àti ìṣírí!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìtùnú fún Àwọn Aláìní
Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ti sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! kan ṣe túbọ̀ mú kí ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jehofa jinlẹ̀ sí i. Ẹnì kan sọ pé: “Lẹ́yìn kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, mo nímọ̀lára pé, Jehofa, pẹ̀lú gbogbo agbára àti ọlá ńlá rẹ̀ wà níbẹ̀ gan-an pẹ̀lú mi. Mo nímọ̀lára pé, ó jẹ́ ẹni gidi.” Lẹ́tà míràn sọ pé: “A yí ọkàn àti èrò inú wa padà ní ti ojú ìwòye wa nípa Jehofa lọ́nà tí ó múni jí gìrì débi pé, a yàtọ̀. Ṣe ni ó dà bíi pé, ẹnì kan bá wa nu awò ojú wa mọ́ tónítóní, nísinsìnyí, ohun gbogbo ṣe rekete.”
Àwọn kan kọ̀wé nípa bí àwọn ìwé ìròyìn náà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro àti ìpèníjà kan pàtó, tí ó sì tipa báyìí fi wọn lọ́kàn balẹ̀ nípa ọkàn ìfẹ́ ara ẹni tí Jehofa ní nínú wọn. Òǹkàwé kan sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ẹ ṣeun púpọ̀ fún jíjẹ́ kí a tún rí i bí Jehofa ṣe bìkítà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ àti bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó.” Obìnrin kan ní Japan, tí ó pàdánù ọmọ rẹ̀ nínú ikú, sọ èyí nípa àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà nínú Jí!: “A tú bí àánú Ọlọrun ti jinlẹ̀ tó jáde ní àwọn ojú iwé náà, mo sọkún, sọkún, sọkún. Mo ti fi àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí si ibì kan tí mo ti lè tètè rí wọn kà nígbàkigbà tí inú mi bá bà jẹ́, ti mo sì nímọ̀lára ìdánìkanwà.” Obìnrin mìíràn tí ń ṣọ̀fọ̀ kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí! àti ti ìwé pẹlẹbẹ náà, “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú,” ti fún mi ní okun tí mo nílò láti fara da àwọn àkókò ìbànújẹ́ mi.”
Ìwé Mímọ́ ni pàtàkì orísun ìtùnú. (Romu 15:4) Ilé-Ìṣọ́nà ń rọ̀ mọ́ Bibeli gẹ́gẹ́ bí ọlá àṣẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwé ìròyìn kejì rẹ̀, Jí! Nítorí èyí, àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ti já sí èyí tí ń pèsè ìtùnú àti ìṣírí fún àwọn tí ń kà wọ́n.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọlọrun ìtùnú gbogbo náà tún ni Olùgbọ́ àdúrà