Òfin Tí Ó Wà Ṣáájú Kristi
“Èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Ìṣàrò mi ni ní ọjọ́ gbogbo.”—ORIN DÁFÍDÌ 119:97.
1. Kí ní ń darí ìsúnkẹẹrẹ àwọn ẹ̀dá ọ̀run?
LÁTI ìgbà ọmọdé, ó ṣeé ṣe kí Jóòbù ti máa tẹjú mọ́ àwọn ìràwọ̀ tìyanutìyanu. Bóyá àwọn òbí rẹ̀ ti kọ́ ọ ní orúkọ àwọn arabaríbí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, àti ohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwọn òfin tí ń darí bí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ṣe ń sún kẹẹrẹ lójú ọ̀run. Ó ṣe tán, àwọn ará ìgbàanì máa ń lo ọ̀nà tí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ràgàjì-ragaji ẹlẹ́wà gíga lọ́lá yìí gbà ń sún kẹẹrẹ lọ́nà tí kì í tàsé, láti sàmì sí ìyípadà sáà kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n fún gbogbo àkókò tí Jóòbù fi tẹjú mọ́ wọn pẹ̀lú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, kò mọ agbára ńlá tí ó so ìgbékalẹ̀ ìràwọ̀ wọ̀nyí pọ̀. Nípa báyìí, ẹnu rẹ̀ wọhò nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ́ ha ti lóye àwọn òfin ti ọ̀run?” (Jóòbù 38:31-33, The New Jerusalem Bible) Bẹ́ẹ̀ ni, òfin ń darí àwọn ìràwọ̀—àwọn òfin tí ó ṣe rẹ́gí, tí ó sì díjú débi pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní kò lóye wọn ní kíkún.
2. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé òfin ń darí gbogbo ìṣẹ̀dá?
2 Jèhófà ni Olùfúnnilófin Gíga Lọ́lá Jù Lọ lágbàáyé. Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni òfin ń darí. Ọmọkùnrin rẹ̀, ààyò olùfẹ́, “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” ń fi ìṣòtítọ́ ṣègbọ́ràn sí òfin Bàbá rẹ̀ ṣáájú kí àgbáyé tí a lè fojú rí tó wà! (Kólósè 1:15) Òfin tún ń darí àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú. (Orin Dáfídì 103:20) Òfin ń ṣàkóso àwọn ẹranko pàápàá níwọ̀n bí wọ́n ti ń ṣègbọ́ràn sí àwọn àṣẹ àdánidá tí Ẹlẹ́dàá wọ́n ti dá mọ́ wọn.—Òwe 30:24-28; Jeremáyà 8:7.
3. (a) Èé ṣe tí aráyé fi nílò òfin? (b) Kí ni Jèhófà fi darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
3 Aráyé ńkọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi àwọn ẹ̀bùn bí òye, ìwà híhù, àti ipò tẹ̀mí jíǹkí wa, síbẹ̀, a ṣì nílò òfin àtọ̀runwá díẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà nínú lílo àwọn agbára wọ̀nyí. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, jẹ́ ẹni pípé, tí ó fi jẹ́ pé kìkì ìwọ̀ǹba òfin díẹ̀ ni wọ́n nílò láti tọ́ wọn sọ́nà. Ìfẹ́ fún Bàbá wọn ọ̀run yẹ kí ó ti fún wọn ní ọ̀pọ̀ ìdí jaburata láti ṣègbọràn tayọ̀tayọ̀. Ṣùgbọ́n, wọ́n ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:15-17; 3:6-19) Ní àbájáde rẹ̀, àwọn ọmọ wọ́n di ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó nílò ọ̀pọ̀ òfin sí i láti darí wọn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ kúnjú àìní yìí. Ó fún Nóà ní àwọn òfin pàtó tí ó ní láti sọ fún ìdílé rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1-7) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nípasẹ̀ Mósè, Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè tuntun ti Ísírẹ́lì ní àkọsílẹ̀ àkójọ Òfin, tí ó kún rẹ́rẹ́. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhófà fi òfin àtọ̀runwá ṣàkóso odindi orílẹ̀-èdè kan. Ṣíṣàyẹ̀wò Òfin yẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ipa pàtàkì tí òfin àtọ̀runwá ń kó nínú ìgbésí ayé Kristẹni lónìí.
Òfin Mósè—Ète Rẹ̀
4. Èé ṣe tí yóò fi jẹ́ ìpènijà fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù tí a yàn láti mú Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà jáde?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Òfin, béèrè pé: “Ti Òfin ti wá jẹ́?” (Gálátíà 3:19) Láti dáhùn, a ní láti rántí pé Jèhófà ṣèlérí fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ábúráhámù pé, ìlà ìdílé rẹ̀ yóò pèsè Irú-Ọmọ kan, tí yóò mú ìbùkún ńláǹlà wá bá gbogbo orílẹ̀-èdè. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ṣùgbọ́n ìpèníjà tí ó wà níhìn-ín ni pé: Kì í ṣe gbogbo àwọn àyànfẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ni ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ ya awarùnkì, ọlọ̀tẹ̀—àwọn kan fẹ́rẹ̀ẹ́ di aláìṣeéṣàkóso! (Ẹ́kísódù 32:9; Diutarónómì 9:7) Fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wíwà lára àwọn ènìyàn Ọlọ́run wulẹ̀ jẹ́ nítorí pé a bí wọn síbẹ̀, kì í ṣe nítorí pé wọ́n yàn bẹ́ẹ̀.
5. (a) Kí ni Jèhófà fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Òfin Mósè? (b) Báwo ní a ṣe pète pé kí Òfin náà nípa lórí ìwà àwọn tí ó bá ń tẹ̀ lé e?
5 Báwo ni irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ṣe lè mú Irú-Ọmọ ìlérí náà jáde, kí wọ́n sì jàǹfààní rẹ̀? Dípò dídarí wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì, Jèhófà kọ́ wọn nípasẹ̀ òfin. (Orin Dáfídì 119:33-35; Aísáyà 48:17) Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún “òfin,” toh·rahʹ, túmọ̀ sí “ìtọ́ni.” Kí ni ó kọ́ni? Ní pàtàkì, ó kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìjẹ́pàtàkì Mèsáyà náà, tí yóò rà wọ́n padà kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Gálátíà 3:24) Òfin náà tún kọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìgbọràn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí tí a ṣe fún Ábúráhámù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún Jèhófà fún gbogbo orílẹ̀-èdè yòó kù. Nítorí náà, Òfin náà ní láti kọ́ wọn ní òfin ìwà híhù gíga lọ́lá, tí ó sì tayọ lọ́lá, tí yóò gbé Jèhófà yọ lọ́nà rere; yóò ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn àṣà dídíbàjẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká.—Léfítíkù 18:24, 25; Aísáyà 43:10-12.
6. (a) Nǹkan bíi ìlànà mélòó ni Òfin Mósè ní, èé sì ti ṣe tí kò fi yẹ kí a rò pé ìyẹn ti pọ̀ jù? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.) (b) Òye inú wo ni a lè jèrè nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Òfin Mósè?
6 Abájọ nígbà náà, tí Òfin Mósè fi ní ọ̀pọ̀ ìlànà nínú—wọ́n ju 600 lọ.a Àkọsílẹ̀ àkójọ òfin yìí ni ó ń darí ọ̀ràn ìjọsìn, ìjọba, ìwà híhù, ìdájọ́ òdodo, àní oúnjẹ àti ìmọ́tótó pàápàá. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ha túmọ̀ sí pé Òfin náà wulẹ̀ jẹ́ àkójọ àwọn ìlànà tí kò gba tẹni rò àti àwọn àṣẹ ṣókí bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Kíkẹ́kọ̀ọ́ àkójọ Òfin yìí ń fúnni ní òye inú púpọ̀ nípa àkópọ̀ ìwà onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Òfin Tí Ó Fi Àánú àti Ìyọ́nú Hàn Kedere
7, 8. (a) Báwo ni Òfin náà ṣe tẹnu mọ́ àánú àti ìyọ́nú? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi àánú lo Òfin náà nínú ọ̀ràn Dáfídì?
7 Òfin náà tẹnu mọ́ àánú àti ìyọ́nú, ní pàtàkì fún àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tàbí fún àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́. A dá àwọn opó àti ọmọ òrukàn yà sọ́tọ̀ fún ààbò. (Ẹ́kísódù 22:22-24) A dáàbò bo àwọn ẹranko tí ń ṣiṣẹ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà òǹrorò. A bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ pàtàkì lórí ohun ìní. (Diutarónómì 24:10; 25:4) Nígbà tí Òfin náà béèrè pé kí a fìyà ikú jẹni fún ìṣìkàpànìyàn, ó pèsè àánú nínú ọ̀ràn ṣíṣèèṣì pànìyàn. (Númérì 35:11) Dájúdájú, àwọn onídàájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òmìnira láti pinnu ìyà tí a óò fi jẹni fún àwọn láìfí kan, ní sísinmi lórí ìṣarasíhùwà oníwà àìtọ́ náà.—Fi wé Ẹ́kísódù 22:7 àti Léfítíkù 6:1-7.
8 Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn onídàájọ́ nípa fífi ìdúró ṣinṣin lo Òfin náà níbi tí ó bá ti pọn dandan, ṣùgbọ́n ní fífi àánú lò ó níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe. A fi àánú hàn sí Ọba Dáfídì, ẹni tí ó ti dẹ́ṣẹ̀ panṣágà àti ìṣìkàpànìyàn. Kì í ṣe pé ó lọ láìjìyà, nítorí pé Jèhófà kò dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ èrè bíbanilẹ́rù tí ó ń jẹ yọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, nítorí májẹ̀mú Ìjọba àti nítorí pé Dáfídì jẹ́ aláàánú ní ti ẹ̀dá, tí ó sì ní ìṣarasíhùwà ọkàn onírònúpìwàdà jíjinlẹ̀, a kò pa á.—Sámúẹ́lì Kìíní 24:4-7; Sámúẹ́lì Kejì 7:16; Orin Dáfídì 51:1-4; Jákọ́bù 2:13.
9. Ipa wo ni ìfẹ́ kó nínú Òfin Mósè?
9 Ní àfikún, Òfin Mósè tẹnu mọ́ ìfẹ́. Finú rò ó pé kí ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè òde òní ní àkójọ òfin tí ń béèrè fún ìfẹ́! Nípa báyìí, kì í ṣe pé Òfin Mósè ka ìṣìkàpànìyàn léèwọ̀ nìkan ni; ó pàṣẹ pé: “Kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnì kejì rẹ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Kì í ṣe pé ó ka bíbá àlejò lò lọ́nà àìtọ́ léèwọ̀ nìkan ni; ó pàṣẹ pé: “Kí ìwọ kí ó sì fẹ́ ẹ bí ara rẹ; nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àlejò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Léfítíkù 19:34) Kì í ṣe pé ó fagi lé panṣágà nìkan ni; ó pàṣẹ fún ọkọ láti mú inú ìyàwó rẹ̀ dùn! (Diutarónómì 24:5) Nínú ìwé Diutarónómì níkan, a lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tí ń tọ́ka sí ànímọ́ ìfẹ́ ní nǹkan bí ìgbà 20. Jèhófà mú ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá wọn lójú—nígbà tí ó ti kọjá, nísinsìnyí, àti ní ọjọ́ iwájú. (Diutarónómì 4:37; 7:12-14) Ní tòótọ́, àṣẹ tí ó tóbi jù lọ nínú Òfin Mósè ni: “Kí ìwọ kí ó sì fi gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Jésù sọ pé Òfin náà lódindi sinmi lórí àṣẹ yìí, àti àṣẹ náà láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò ẹni. (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:37-40) Abájọ tí onísáàmù náà fi kọ̀wé pé: “Èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! ìṣàrò mi ni ní ọjọ́ gbogbo.”—Orin Dáfídì 119:97.
Àṣìlò Òfin Náà
10. Nínú apá tí ó pọ̀ jù lọ, ọwọ́ wo ni àwọn Júù fi mú Òfin Mósè?
10 Nígbà náà, ẹ wo bí ó ti bani nínú jẹ́ tó, pé Ísírẹ́lì kò ní ìmọrírì fún Òfin Mósè! Àwọn ènìyàn náà ṣàìgbọràn sí Òfin náà, wọ́n kò náání rẹ̀, wọ́n sì gbàgbé nípa rẹ̀. Wọ́n fi àwọn àṣà ìsìn kíkóni nírìíra, ti àwọn orílẹ̀-èdè míràn sọ ìjọsìn mímọ́ gaara di ẹlẹ́gbin. (Àwọn Ọba Kejì 17:16, 17; Orin Dáfídì 106:13, 35-38) Wọ́n sì rú Òfin náà ní àwọn ọ̀nà míràn pẹ̀lú.
11, 12. (a) Báwo ni àwùjọ àwọn aṣáájú ìsìn ṣe ba nǹkan jẹ́ lẹ́yìn ọjọ́ Ẹ́sírà? (Wo àpótí.) (b) Èé ṣe tí àwọn rábì ìgbàanì fi rò pé ó pọn dandan láti “fi ògiri yí Òfin náà ká”?
11 Àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n ń kọ́ni ní Òfin náà gan-an, tí wọ́n sì ń sọ pé wọ́n ń pa á mọ́, ni wọ́n ba àwọn kan nínú òfin náà jẹ́ lọ́nà búburú jù lọ. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àkókò olùṣòtítọ́ akọ̀wé náà, Ẹ́sírà, ti ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Ẹ́sírà jà fitafita lòdì sí agbára ìdarí tí ń sọni dìbàjẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ó sì tẹnu mọ́ kíka Òfin náà, àti fífi í kọ́ni. (Ẹ́sírà 7:10; Nehemáyà 8:5-8) Àwọn kan lára àwọn olùkọ́ Òfin náà sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Ẹ́sírà, wọ́n sì dá ohun tí a pè ní “Sínágọ́gù Ńlá,” sílẹ̀. Lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ìtọ́ni náà pé: “Fi ògiri yí Òfin náà ká.” Àwọn olùkọ́ wọ̀nyí ṣàlàyé pé Òfin náà dà bí ọgbà kan tí ó ṣeyebíye. Kí ẹnikẹ́ni má baà wọnú ọgbà yìí nípasẹ̀ rírú àwọn òfin rẹ̀, wọ́n ṣe àwọn òfin púpọ̀ sí i, “Òfin Àtẹnudẹ́nu,” láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn sún mọ́ irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀.
12 Àwọn kán lè jiyàn pé ó tọ́ kí àwọn aṣáájú Júù ronú lọ́nà yìí. Lẹ́yìn àkókò Ẹ́sírà, ilẹ̀ òkèèrè, ní pàtàkì ilẹ̀ Gíríìsì, jẹ gàba lórí àwọn Júù. Láti gbéjà ko agbára ìdarí ọgbọ́n èrò orí àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì, àwùjọ àwọn aṣáájú ìsìn dìde láàárín àwọn Júù. (Wo àpótí, ojú ìwé 10.) Nígbà tí ó yá, díẹ̀ nínú àwọn àwùjọ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí i bá ẹgbẹ́ àlùfáà Léfì figẹ̀ wọngẹ̀, wọ́n tilẹ̀ ta wọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ Òfin pàápàá. (Fi wé Málákì 2:7.) Nígbà tí yóò fi di ọdún 200 ṣááju Sànmánì Tiwa, òfin àtẹnudẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sí i lo agbára ìdarí lórí ìgbésí ayé àwọn Júù. Ní ìbẹ̀rẹ̀, a kò gbọdọ̀ kọ òfin wọ̀nyí sílẹ̀, kí á má baà kà wọ́n sí ohun kan náà pẹ̀lú Òfin alákọsílẹ̀. Ṣùgbọ́n ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a fi èrò ènìyàn ṣáájú èrò Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ tí “ògiri” yìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn fi ba “ọgbà” náà gan-an tí ó yẹ kí ó dáàbò bò jẹ́ ní ti gidi.
Ìsọdìbàjẹ́ Tí Ẹ̀kọ́ Àwọn Farisí Mú Wá
13. Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn Júù kán ṣe dá ṣíṣe ọ̀pọ̀ ìlànà láre?
13 Àwọn rábì ṣàlàyé pé níwọ̀n bí Tórà, tàbí Òfin Mósè ti pé pérépéré, ó gbọ́dọ̀ ní ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè tí ó lè dìde. Èrò yìí kò ṣeé fọkàn tẹ̀ ní ti gidi. Ní tòótọ́, ó fún àwọn rábì ní òmìnira láti lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ti ènìyàn, ní mímú kí ó dà bí ẹni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìpìlẹ̀ fún àwọn ìlànà lórí gbogbo onírúurú ọ̀ràn—àwọn kán jẹ́ ti ara ẹni, àwọn mìíràn jẹ́ ọ̀ràn tí kò tó nǹkan.
14. (a) Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe fẹ ìlànà Ìwé Mímọ́ ti yíyà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè lójú ju bí ó ti ṣe yẹ lọ lọ́nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? (b) Kí ni ó fi hàn pé òfin rábì kùnà láti dáàbò bo àwọn Júù kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí ìbọ̀rìṣà?
14 Léraléra, àwọn aṣáájú ìsìn mú àwọn àṣẹ Ìwé Mímọ́, wọ́n sì fẹ̀ wọ́n lójú ju bí ó ṣe yẹ lọ. Fún àpẹẹrẹ, Òfin Mósè gbé ìyàsọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè lárugẹ, ṣùgbọ́n àwọn rábì rọni láti ní ìkórìíra tí kò bọ́gbọ́n mu fún gbogbo ohun tí kì í bá ti í ṣe ti Júù. Wọ́n kọ́ni pé Júù kan kò gbọ́dọ̀ fi màlúù rẹ̀ sílẹ̀ ní ilé èrò tí ó jẹ́ ti Kèfèrí, nítorí pé àwọn Kèfèrí “ni a fura sí pé wọ́n ń bá ẹranko lò pọ̀.” A kò gba obìnrin Júù láyè láti ṣèrànwọ́ fún obìnrin Kèfèrí tí ń rọbí nítorí pé yóò máa tipa bẹ́ẹ̀ “ṣèrànwọ́ láti mú ọmọ wáyé fún ìbọ̀rìṣà.” Níwọ̀n bí wọ́n ti fura, lọ́nà yíyẹ, sí yàrá ńlá fún eré ìdárayá ti Gíríìkì, àwọn rábì ka gbogbo eré ìdárayá léèwọ̀. Ìtàn fi hàn pé díẹ̀ ni gbogbo èyí ṣe láti dáàbò bo àwọn Júù kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ Kèfèrí. Ní tòótọ́, àwọn Farisí fúnra wọn bẹ̀rẹ̀ sí i kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ Gíríìkì ti àìleèkú ọkàn!—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4.
15. Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe lọ́ òfin ìwẹ̀nùmọ́ àti ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan po?
15 Àwọn Farisí tún lọ́ àwọn òfin ìwẹ̀nùmọ́ po. A gbọ́ pé àwọn Farisí yóò wẹ oòrùn pàápàá mọ́ bí a bá fún wọn láyè. Òfin wọ́n sọ pé jíjáfara “láti lọ gbọnsẹ̀” yóò sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin! Wíwẹ ọwọ́ wá di ààtò dídíjú, pẹ̀lú àwọn ìlànà nípa ọwọ́ tí a ní láti kọ́kọ́ wẹ̀ àti bí a ṣe ní láti wẹ̀ ẹ́. A ka àwọn obìnrin ní pàtàkì sí aláìmọ́. Lórí ìpìlẹ̀ àṣẹ Ìwé Mímọ́ láti má ṣe “sún mọ́” ìbátan èyíkéyìí nípa ti ara (ní ti gidi, òfin kan tí ó lòdì sí ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan), àwọn rábì ṣòfin pé ọkọ kan kò gbọdọ̀ rìn tẹ̀ lé ìyàwó rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọdọ̀ bá a sọ̀rọ̀ nínú ọjà.—Léfítíkù 18:6.
16, 17. Báwo ni òfin àtẹnudẹ́nu ṣe gbòòrò sí i ní ti àṣẹ náà láti pa Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
16 Èyí tí ó burú bàlùmọ̀ jù lọ ni ẹ̀sín tẹ̀mí tí òfin àtẹnudẹ́nu fi òfin Sábáàtì ṣe. Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ní òfin rírọrùn náà pé: Má ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ keje ọ̀sẹ̀. (Ẹ́kísódù 20:8-11) Ṣùgbọ́n, òfin àtẹnudẹ́nu tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe àfikún oríṣi iṣẹ́ 39 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a kà léèwọ̀, títí kan títa kókó tàbí títú u, gígán aṣọ, kíkọ lẹ́tà Hébérù méjì sílẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyí tún nílò àwọn ìlànà jáǹtírẹrẹ mìíràn. Irú kókó wo ni a kà léèwọ̀, èwo ni a sì fàyè gbà? Òfin àtẹnudẹ́nu dáhùn pẹ̀lú àwọn ìlànà èrò ara ẹni. Wọ́n ka ìmúláradá sí iṣẹ́ tí a kà léèwọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní ọjọ́ Sábáàtì, èèwọ̀ ni láti to itan tí ó bá dá. Ẹni tí akokoro ń yọ lẹ́nu lè bu ọtí kíkan sí oúnjẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fi ọtí kíkan náà yọnu. Ìyẹn lè wo eyín rẹ̀ sàn!
17 Nípa fífi ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òfin àtọwọ́dá bo òfin Sábáàtì mọ́lẹ̀, ìtumọ̀ tẹ̀mí rẹ̀ sọnù lójú ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù. Nígbà tí Jésù Kristi, “Olúwa sábáàtì,” ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu agbàfiyèsí, tí ń mọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ní ọjọ́ Sábáàtì, kò jọ àwọn akọ̀wé àti Farisí lójú. Kìkì ohun tí ó dùn wọ́n ni pé, ó dà bíi pé kò ka ìlànà wọn sí.—Mátíù 12:8, 10-14.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Ìwà Ẹ̀gọ̀ Àwọn Farisí
18. Kí ni ìyọrísí fífi àwọn òfin àtẹnudẹ́nu àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kún Òfin Mósè? Ṣàkàwé.
18 Ní ṣókí, a lè sọ pé àwọn àfikún òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ Òfin Mósè bí aláńkọ́rọ́ ṣe ń lẹ̀ mọ́ ara ọkọ̀ òkun. Ọlọ́kọ̀ òkun máa ń ṣe wàhálà púpọ̀ láti ṣí àwọn ẹ̀dá ayọnilẹ́nu wọ̀nyí kúrò lára ọkọ̀ òkun rẹ̀ nítorí pé wọn kì í jẹ́ kí ọkọ̀ òkun lè sáré, wọ́n sì ń ba ọ̀dà rẹ̀ tí kì í jẹ́ kí ó dógùn-ún jẹ́. Bákan náà, àwọn òfin àtẹnudẹ́nu àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ dẹrù pa Òfin náà, ó sì mú kí a ṣì í lò lọ́nà tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣe àwùjọ lọ́ṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, dípò ṣíṣí irú àwọn òfin tí kò wúlò bẹ́ẹ̀ kúrò, àwọn rábì túbọ̀ ń fi kún un. Nígbà tí Mèsáyà yóò fi dé láti mú Òfin náà ṣẹ, “aláńkọ́rọ́” ti bo “ọkọ̀ òkun” náà débi pé agbára káká ni ó fi léfòó! (Fi wé Òwe 16:25.) Dípò dídáàbò bo májẹ̀mú Òfin, àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí hùwà ẹ̀gọ̀ ní rírú u. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí “ògiri” àwọn ìlànà wọn fi kùnà?
19. (a) Èé ṣe tí ‘ògiri tí a ṣe yí Òfin náà ká’ fi kùnà? (b) Kí ni ó fi hàn pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù kò ní ojúlówó ìgbàgbọ́?
19 Àwọn aṣáájú Ìsìn Júù kùnà láti lóye pé inú ọkàn-àyà ni a ti ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́, kì í sì í ṣe nínú àwọn ojú ewé àwọn ìwé òfin. (Jeremáyà 4:14) Ìfẹ́ ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣẹ́gun—ìfẹ́ fún Jèhófà, fún òfin àti àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ń pèsè ìkórìíra yíyẹ wẹ́kú fún ohun tí Jèhófà kórìíra. (Orin Dáfídì 97:10; 119:104) Àwọn tí ọkàn-àyà wọ́n tipa báyìí kún fún ìfẹ́ ń dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí àwọn òfin Jèhófà nínú ayé tí ó ti díbàjẹ́ yìí. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní àǹfààní ńlá láti kọ́ àwọn ènìyàn kí wọ́n lè gbé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lárugẹ, kí wọ́n sì mú u gbilẹ̀. Èé ṣe tí wọ́n fi kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀? Dájúdájú, wọ́n kò ní ìgbàgbọ́. (Mátíù 23:23, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Ká ní wọ́n ti ní ìgbàgbọ́ nínú agbára ẹ̀mí Jèhófà láti ṣiṣẹ́ nínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn olùṣòtítọ́ ni, wọn kì bá ti ní ìdí láti fi agbára darí ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn. (Aísáyà 59:1; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:4) Nítorí àìní ìgbàgbọ́, wọ́n kò gbin ìgbàgbọ́ síni lọ́kàn; wọ́n fi àwọn àṣẹ àtọwọ́dá dẹrù pa àwọn ènìyàn.—Mátíù 15: 3, 9; 23:4.
20, 21. (a) Kí ni àpapọ̀ ìyọrísí tí èrò inú tí a gbé karí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní lórí Ìsìn Àwọn Júù? (b) Kí ni ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Ìsìn Àwọn Júù?
20 Àwọn aṣáájú Júù wọ̀nyẹn kò gbé ìfẹ́ lárugẹ. Àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn pèsè ìsìn tí ohun ti òde gbà lọ́kàn, pẹ̀lú ìgbọ́ràn ojú ayé, tí wọ́n ń ṣe nítorí kí a lè rí wọn—ọ̀nà kan láti jẹ́ kí ìwà àgàbàgebè rí àyè láti máa gogò sí i. (Mátíù 23:25-28) Àwọn ìlànà wọn pèsè ìdí tí kò lóǹkà fún dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Nípa báyìí, àwọn Farisí agbéraga, aláṣẹ bóo fẹ́ bóo kọ̀, rò pé àwọn tọ̀nà ní ṣíṣe lámèyítọ́ Jésù Kristi alára. Wọ́n pàdánù ète pàtàkì Òfin náà, wọ́n sì kọ Mèsáyà tòótọ́ kan ṣoṣo náà sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, òun ní láti sọ fún orílẹ̀-èdè Júù pé: “Wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.”—Mátíù 23:38; Gálátíà 3:23, 24.
21 Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́? Ní kedere, èrò inú tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, tí a gbé karí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, kì í gbé ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà lárugẹ! Ṣùgbọ́n, èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn olùjọsìn Jèhófà lónìí kò gbọdọ̀ ní ìlànà èyíkéyìí rárá àyàfi bí a bá kọ wọ́n lẹ́sẹẹsẹ sínú Ìwé Mímọ́? Rárá o. Fún ìdáhùn kíkún rẹ́rẹ́, tẹ̀ lé èyí, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí Jésù Kristi ṣe fi òfin tuntun, tí ó tún jẹ́ òfin tí ó sàn jù rọ́pò Òfin Mósè.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmọ́ ṣáá o, ìyẹn ṣì kéré níye ní ìfiwéra pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ òfin ti àwọn orílẹ̀-èdè òde òní. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, òfin ìjọba àpapọ̀ ti United States gbà ju ojú ìwé 125,000, tí a sì ń fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún òfin tuntun kún un lọ́dọọdún.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni òfin àtọ̀runwá ṣe ń darí gbogbo ìṣẹ̀dá?
◻ Kí ni ète pàtàkì tí Òfin Mósè ní?
◻ Kí ni ó fi hàn pé Òfin Mósè tẹnu mọ́ àánú àti ìyọ́nú?
◻ Èé ṣe tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù fi fi àwọn ìlànà tí kò lóǹkà kún Òfin Mósè, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Aṣáájú Ìsìn Júù
Àwọn Akọ̀wé: Wọ́n ka ara wọn sí agbapò Ẹ́sírà àti alálàyé Òfin. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, A History of the Jews, ṣe sọ, “àwọn akọ̀wé kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ olóye títayọ, ìgbìdánwò wọn láti mú ìtúmọ̀ tí ó fara sin jáde láti inú òfin sì sábà máa ń yọrí sí àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀, àti àwọn ìkálọ́wọ́kò tí kò bọ́gbọ́n mu. Àwọn ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyí wá ń le koko sí i títí wọ́n fi di àṣà, láìpẹ́, tí ó sì wá di ìwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ tí kò dáwọ́ dúró.”
Àwọn Hásídì: Orúkọ náà túmọ̀ sí “ẹni ọ̀wọ̀” tàbí “ẹni mímọ́.” A mẹ́nu kàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan fún ìgbà àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún 200 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n jẹ́ alágbára ní ti ìṣèlú, wọ́n ń fi ìwà agbawèrèmẹ́sìn gbèjà ìjẹ́mímọ́ Òfin náà lòdìsí agbára ìdarí oníwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ti Gírí ìkì. Àwọn Hásídì pín sí àwùjọ mẹ́ta: àwọn Farisí, àwọn Sadusí, àti àwọn Essene.
Àwọn Farisí: Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kán gbà gbọ́ pé a rí orúkọ náà láti inú àwọn ọ̀rọ̀ náà “Àwọn Ẹni Ìyàsọ́tọ̀,” tàbí “Àwọn Àṣo.” Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn nínú ìsapá wọn láti yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn Kèfèrí, ṣùgbọ́n wọ́n tún rí ẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yà sọ́tọ̀ kúrò lára—tí ó sì lọ́lá ju—àwọn ènìyàn Júù lásán lọ, tí wọn kò mọ ọ̀rínkinniwín òfin àtẹnudẹ́nu. Òpìtàn kan sọ nípa àwọn Farisí pé: “Ní gbogbogbòò, wọ́n ń bá àwọn ènìyàn lò bí ọmọdé, wọ́n ń gbé àwọn ìlànà kalẹ̀, wọ́n sì ń ṣàlàyé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó kéré jù lọ nípa ààtò ṣíṣe.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míràn sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Farisí pèsè àkójọ àwọn ìlànà tí ó jẹ mọ́ òfin tí ó kárí gbogbo ipò ọ̀ràn, pẹ̀lú àbájáde tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, ní ti pé, wọ́n fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀, wọ́n ń pa làpálàpá (Mat. 23:23).”
Àwọn Sadusí: Àwùjọ kan tí ó ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti ẹgbẹ́ àlùfáà. Wọ́n fi tagbáratagbára ta ko àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí, ní sísọ pé òfin àtẹnudẹ́nu kò ní ọlá àṣẹ tí Òfin alákọsílẹ̀ ní. Mishnah fúnra rẹ̀ fi hàn pé wọ́n f ìdí rẹmi nínú àríyànjiyàn yìí ní sísọ pé: “A kan [kíkíyè sí] ọ̀rọ̀ àwọn Akọ̀wé nípá jú [kíkíyè sí] ọ̀rọ̀ Òfin [alákọsílẹ̀] lọ.” Talmud, tí o ní ọ̀pọ̀ àlàyé lórí òfin àtẹnudẹ́nu nínú, lẹ́yìn náà lọ jìnnà ní sísọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn akọ̀wé . . . ṣeyebíye ju ọ̀rọ̀ Torah lọ.”
Àwọn Essene: Àwùjọ àwọn olùsẹ́ra-ẹni tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ ní àwọn agbègbè àdádó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Interpreter’s Dictionary of the Bible ṣe sọ, agbára àwọn Essene pọ̀ ju ti àwọn Farisí lọ, àti “nígbà míràn, ìwà àgàbàgebè tiwọn gan-an máa ń le ju ti àwọn Farisí alára lọ.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn òbí Jóòbù lè ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn òfin tí ń darí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀