Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Fẹjọ́ Ẹni Tí Ó Hùwà Ibi Sùn?
À ṢÀYÀN ọ̀rọ̀ kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Ẹni bá tàṣìírí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ní gbangba sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá aráyé.” Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Olú nìyẹn nígbà tí ó fẹ̀sùn kan ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin pé, ó bá àbúrò wọn obìnrin lò pọ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ké rara pé: “Òpùrọ́ ni ọ́!” Ó lu Olú bí ẹni lu bàrà, ó lé e kúrò ní agboolé wọn, ó sì dáná sun gbogbo ẹ̀wù Olú. Àwọn ará abúlé wà lẹ́yìn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Nítorí tí wọn kò fẹ́ ẹ ní abúlé mọ́, Olú ní láti wábi gbà. Ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n wá ṣàkíyèsí pé ọmọbìnrin náà ti fẹ́ra kù ni àwọn ènìyàn náà tó gbà pé òótọ́ ni Olú sọ. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́wọ́, a sì pa dà fojú rere hàn sí Olú. Nǹkan ì bá ti yàtọ̀ pátápátá. Wọ́n ì bá ti pa Olú.
Ó ṣe kedere pé, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kò lè mọrírì pé a tú àṣìṣe wọn fó. Ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀dá ènìyàn ní ni láti kọ ìbáwí àti láti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá fúnni ní ìbáwí náà. (Fi wé Jòhánù 7:7.) Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi ń panu mọ́ fẹ́rẹ́ nígbà tí ó bá di ọ̀ràn títú ìwà àìtọ́ àwọn ẹlòmíràn fó fún àwọn tí wọ́n ní ọlá àṣẹ láti mú kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣàtúnṣe.
Mímọrírì Ìníyelórí Ìbáwí
Ṣùgbọ́n, láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà, ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn sí ìbáwí yàtọ̀ pátápátá. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run mọrírì ètò tí Jèhófà ṣe láti ran àwọn tí wọ́n bá ṣàṣìṣe nínú ìjọ Kristẹni lọ́wọ́. Wọn ka irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ sí ọ̀nà kan tí ó gbà ń fi ìfẹ́ inú rere rẹ̀ hàn.—Hébérù 12:6-11.
A lè fi ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí ayé Ọba Dáfídì ṣàkàwé èyí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ olódodo láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ìgbà kan wà nígbà tí ó ṣubú sínú ìwà àìtọ́ búburú jáì. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣe panṣágà. Lẹ́yìn náà, nínú ìgbìdánwò láti bo ìwà àìtọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó ṣètò pé kí a pa ọkọ obìnrin náà. Ṣùgbọ́n Jèhófà táṣìírí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fún wòlíì Nátánì, ẹni tí ó fi ìgboyà ko Dáfídì lójú nípa ọ̀ràn náà. Ní lílo àkàwé kan tí ó lágbára, Nátánì bi Dáfídì ní ohun tí ó yẹ kí a ṣe si ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà tí ó ní ọ̀pọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó mú ẹyọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ṣoṣo tí ọkùnrin òtòṣì kan ní, tí ó ń ṣìkẹ́, tí ọlọ́rọ̀ náà sì pa á láti fi ṣe ọ̀rẹ́ rẹ lálejò. Ìkannú àti ìbínú Dáfídì, tí ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tẹ́lẹ̀, ru. Ó wí pé: “Ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú.” Nígbà náà ni Nátánì lo àkàwé náà fún Dáfídì, ní sísọ pé: “Ìwọ ni ọkùnrin náà.”—Sámúẹ́lì Kejì 12:1-7.
Dáfídì kò bínú sí Nátánì; bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbìyànjú láti gbèjà ara rẹ̀ tàbí kí ó yíjú sí fífẹ̀sùn kàn án pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbáwí Nátánì sún ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ṣiṣẹ́ lọ́nà tí ó jinlẹ̀. Nítorí tí ó dun Dáfídì dé ọkàn àyà, ó jẹ́wọ́ pé: “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa.”—Sámúẹ́lì Kejì 12:13.
Títú tí Nátánì tú ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fó, tí ìbáwí oníwà-bí-Ọlọ́run sì tẹ̀ lé e, yọrí sí rere. Bí a kò tilẹ̀ dènà àwọn àbájáde ìwà àìtọ́ Dáfídì, ó ronú pìwà dà, ó sì pa dà bá Jèhófà rẹ́. Kí ni ìmọ̀lára Dáfídì nípa irú ìbáwí bẹ́ẹ̀? Ó kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí olódodo kí ó lù mí; ìṣeun ni yóò já sí: jẹ́ kí ó sì bá mi wí; òróró dáradára ni yóò já sí, tí kì yóò fọ́ mi lórí.”—Orin Dáfídì 141:5.
Ní ọjọ́ wa lónìí pẹ̀lú, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè kówọ inú ìwà àìtọ́ búburú jáì, àní àwọn tí wọ́n ti jẹ́ olùṣòtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá. Ní mímọ̀ pé àwọn alàgbà lè ṣèrànwọ́, ọ̀pọ̀ ń lo àtinúdá láti tọ̀ wọ́n lọ fún ìrànwọ́. (Jákọ́bù 5:13-16) Ṣùgbọ́n nígbà míràn oníwà àìtọ́ kan lè gbìyànjú láti bo ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, bí Ọba Dáfídì ti ṣe. Kí ni ó yẹ kí a ṣe bí a bá wá mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ búburú jáì nínú ìjọ?
Ẹrù Iṣẹ́ Ta Ni?
Nígbà tí àwọn alàgbà bá gbọ́ nípa ìwà àìtọ́ búburú jáì, wọn yóò tọ ẹni tí ọ̀ràn náà kàn lọ láti fún un ní ìrànlọ́wọ́ àti àtúnṣe. Ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà ni láti ṣèdájọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Ní wíwà lójúfò gidigidi sí ipò tẹ̀mí ìjọ náà, wọ́n ń ran ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ìgbésẹ̀ tí kò bọ́gbọ́n mu tàbí ìgbésẹ̀ òdì lọ́wọ́, wọ́n sì ń ṣí wọn létí.—Kọ́ríńtì Kíní 5:12, 13; Tímótì Kejì 4:2; Pétérù Kíní 5:1, 2.
Ṣùgbọ́n bí ìwọ kì í bá ṣe alàgbà ńkọ́, tí o sì wá mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ búburú jáì kan tí Kristẹni kan hù? A rí àwọn ìlànà nínú Òfin tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Òfin náà sọ pé bí ẹnì kan bá mọ̀ nípa ìwà ìpẹ̀yìndà, tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, ìṣìkàpànìyàn, tàbí àwọn ìwà ọ̀daràn búburú jáì míràn, ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ ni láti fi ẹjọ́ ẹni náà sùn, kí ó sì jẹ́rìí sí ohun tí ó mọ̀. Léfítíkù 5:1 sọ pé: “Bí ẹnì kan bá sì ṣẹ̀, tí ó sì gbọ́ ohùn ìbúra, tí ó sì ṣe ẹlẹ́rìí, bí òun bá rí tàbí bí òun bá mọ̀, tí kò bá wí, ǹjẹ́ kí ó ru àìṣedéédéé rẹ̀.”—Fi wé Diutarónómì 13:6-8; Ẹ́sítérì 6:2; Òwe 29:24.
Bí àwọn Kristẹni kò tilẹ̀ sí lábẹ́ Òfin Mósè lónìí, àwọn ìlànà tí ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀ lè tọ́ wọn sọ́nà. (Orin Dáfídì 19:7, 8) Nítorí náà, bí o bá mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ búburú jáì tí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ kan hù, kí ni ó yẹ kí o ṣe?
Bíbójútó Ọ̀ràn Náà
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ṣe pàtàkì pé kí a ní ẹ̀rí tí ó múná dóko láti gbà gbọ́ pé ìwà àìtọ́ búburú jáì náà wáyé ní tòótọ́. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà wí pé: “Má ṣe ẹlẹ́rìí sí ẹnì kejì rẹ láìnídìí: kí ìwọ kí ó má sì ṣe fi ètè rẹ ṣẹ̀tàn.”—Òwe 24:28.
O lè pinnu láti tọ àwọn alàgbà lọ ní tààràtà. Kò burú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ipa ọ̀nà tí ó fi ìfẹ́ hàn jù lọ ni láti tọ ẹni tí ọ̀ràn kàn náà lọ. Ó lè jẹ́ pé àwọn ẹ̀rí náà kò rí bí wọ́n ṣe jọ. Tàbí kí àwọn alàgbà ti máa bójú tó ọ̀ràn náà. Fi pẹ̀lẹ́tù jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú ẹni náà. Bí ìdí bá ṣì wà láti gbà gbọ́ pé ẹni náà ti hùwà àìtọ́ búburú jáì, rọ̀ ọ́ láti tọ àwọn alàgbà lọ fún ìrànlọ́wọ́, kí o sì ṣàlàyé ọgbọ́n tí ń bẹ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ìyẹn yóò jẹ́ òfófó.
Bí ẹni náà kò bá sọ fún àwọn alàgbà láàárín àkókò díẹ̀, nígbà náà ìwọ ní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà alàgbà kan tàbí méjì yóò jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú ẹni tí a fẹ̀sùn kàn. Àwọn alàgbà ní láti ‘tọsẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò, kí wọ́n sì wádìí kínníkínní’ láti mọ̀ bóyá ẹni náà hùwà àìtọ́ náà. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò bójú tó ọ̀ràn náà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́.—Diutarónómì 13:12-14, NW.
Ó kéré tán, a béèrè pé kí ẹlẹ́rìí méjì fìdí ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ náà múlẹ̀. (Jòhánù 8:17; Hébérù 10:28) Bí ẹni náà bá sẹ́ ẹ̀sùn náà, tí ó sì jẹ́ ẹ̀rí tìrẹ nìkan ṣoṣo ni ó wà, a óò fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́. (Tímótì Kíní 5:19, 24, 25) A ṣe èyí ní mímọ̀ pé ohun gbogbo “wà ní ìṣísílẹ̀ gbayawu” sí Jèhófà àti pé bí ẹni náà bá jẹ̀bi, ó pẹ́ ó yá, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóò ‘lé e bá’.—Hébérù 4:13; Númérì 32:23.
Ṣùgbọ́n ká ní ẹni náà sẹ́ ẹ̀sùn náà ní ti gidi, tí ó sì jẹ́ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni ẹlẹ́rìí tí ó kojú rẹ̀. A ha lè fi ẹ̀sùn ìbanijẹ́ kàn ọ́ bí? Rárá o, àyàfi bí o bá ti sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn tí ọ̀ràn kò kàn. Kì í ṣe ìwà ìbanijẹ́ rárá láti mú ọ̀ràn tí ń nípa lórí ìjọ lọ sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ọlá àṣẹ láti bójú tó ọ̀ràn náà, kí wọ́n sì yanjú rẹ̀, tí ó sì jẹ́ ẹrù iṣẹ́ wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn wa láti ṣe ohun tí ó tọ́ ní gbogbo ìgbà tí ó sì fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin.—Fi wé Lúùkù 1:74, 75.
Pípa Ìjẹ́mímọ́ Mọ́ Nínú Ìjọ
Ọ̀kan lára ìdí tí a fi ń fẹjọ́ ẹnì kan tí ó hu ìwà àìtọ́ sùn ni pé ó ń pa ìjẹ́mímọ́ ìjọ mọ́. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí kò lábààwọ́n, Ọlọ́run mímọ́. Ó ń fẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń jọ́sìn òun jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa ti ìwà híhù. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí ṣí wa létí pé: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí tí èmi jẹ́ mímọ́.’” (Pétérù Kíní 1:14-16) Àwọn tí wọ́n bá hùwà àìmọ́ tàbí ìwà àìtọ́ lè kó ẹ̀gbin bá ìjọ látòkè délẹ̀, wọ́n sì lè mú àìrójúrere Jèhófà wá, àyàfi bí a bá gbé ìgbésẹ̀ láti mú kí wọ́n ṣàtúnṣe tàbí láti yọ wọ́n.—Fi wé Jóṣúà, orí 7.
Lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì fi hàn bí fífi ẹjọ́ oníwà àìtọ́ kan sùn ṣe mú kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí ń bẹ níbẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní. Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní ti gàsíkíá àgbèrè ni a ròyìn láàárín yín, irúfẹ́ àgbèrè tí kò tilẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan báyìí ní aya kan tí ó jẹ́ ti baba rẹ̀.”—Kọ́ríńtì Kíní 5:1.
Bíbélì kò sọ ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ yí tó àpọ́sítélì náà létí fún wa. Ó lè jẹ́ pé ẹnu Sítéfánásì, Fọ́túnátù, àti Ákáíkọ́sì, tí wọ́n rìnrìn àjò láti Kọ́ríńtì wá sí Éfésù níbi tí Pọ́ọ̀lù ń gbé ni Pọ́ọ̀lù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yí. Pọ́ọ̀lù tún rí lẹ́tà ìṣèwádìí kan gbà láti ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì. Ibi yòó wù kí ó ti gbọ́ ọ, gbàrà tí àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbára lé ti fi ọ̀rọ̀ náà tó Pọ́ọ̀lù létí, ó ṣeé ṣe fún un lẹ́yìn náà láti fúnni ní ìtọ́sọ́nà lórí ọ̀ràn náà. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.” Wọ́n yọ ọkùnrin náà kúrò nínú ìjọ.—Kọ́ríńtì Kíní 5:13; 16:17, 18.
Ìtọ́ni Pọ́ọ̀lù ha mú èso rere jáde bí? Bẹ́ẹ̀ ní! Ó hàn gbangba pé, orí oníwà àìtọ́ náà wálé. Nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù rọ ìjọ náà láti ‘fi inú rere dárí jì í, kí wọ́n sì tu ọkùnrin tí ó ronú pìwà dà náà nínú.’ (Kọ́ríńtì Kejì 2:6-8) Nípa báyìí, fífi ẹjọ́ ẹnì kan tí ó hùwà àìtọ́ sùn yọrí sí ìgbésẹ̀ tí ó jálẹ̀ sí mímú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní àti mímú kí ẹni tí ó ti bá ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ pa dà rí ojú rere Ọlọ́run.
A rí àpẹẹrẹ mìíràn nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì. Lọ́tẹ̀ yí, àpọ́sítélì náà dárúkọ àwọn ẹlẹ́rìí tí ó fi ọ̀rọ̀ náà tó o létí. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ará ilé Kílóè sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé àwọn ìjà ìyapa wà láàárín yín.” (Kọ́ríńtì Kíní 1:11) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìjà ìyapa yìí, pẹ̀lú bíbọlá tí kò yẹ fún àwọn ènìyàn, ti dá ẹ̀mí ìyapa sílẹ̀ tí ó fẹ́ ba ìsọ̀kan ìjọ náà jẹ́. Nítorí náà, láti inú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní fún ire tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó wà níbẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbégbèésẹ̀ kíá, ó si kọ lẹ́tà ìmọ̀ràn àtúnṣe sí ijọ náà.
Lónìí, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ jákèjádò ilẹ̀ ayé ń ṣiṣẹ́ kára láti pa ìjẹ́mímọ́ tẹ̀mí ti ìjọ mọ́, nípa dídi ìdúró tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà mú níwájú Ọlọ́run lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àwọn kan ń jìyà láti ṣe bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn tilẹ̀ ti kú láti baà lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Ó dájú pé, gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìwà àìtọ́ tàbí bíbò ó mọ́lẹ̀ yóò fi àìmọrírì àwọn ìsapá wọ̀nyí hàn.
Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Oníláìfí
Èé ṣe tí àwọn kan tí wọ́n ti ṣubú sínú ìwà búburú jáì fi ń lọ́ tìkọ̀ láti tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ? Lọ́pọ̀ ìgbà, ó jẹ́ nítorí pé wọn kò mọ àǹfààní títọ àwọn alàgbà lọ. Lọ́nà tí ó lòdì, àwọn kan gbà gbọ́ pé bí àwọn bá jẹ́wọ́, a óò tú ẹ̀ṣẹ̀ wọn fó fún gbogbo ìjọ. Àwọn mìíràn mọ̀ọ́mọ̀ fojú kéré ipa ọ̀nà wọn. Síbẹ̀ àwọn mìíràn rò pé àwọn lè tún ọ̀nà ara àwọn ṣe láìsí ìrànwọ́ àwọn alàgbà.
Ṣùgbọ́n irú àwọn oníwà àìtọ́ bẹ́ẹ̀ nílò ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:14, 15.
Ẹ wo irú ìpèsè àgbàyanu tí ó jẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn oníláìfí láti mú ipò tẹ̀mí wọn pa dà bọ̀ sípò! Nípa lílo ìmọ̀ràn atunilára láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípa gbígbàdúrà fún wọn, àwọn alàgbà lè ran àwọn tí ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ láti kọ́fẹ pa dà láti inú ìṣìnà wọn. Nípa báyìí, kàkà tí wọn yóò fi rò pé àwọn kò wúlò mọ́, àwọn tí ó ronú pìwà dà lọ́pọ̀ ìgbà máa ń nímọ̀lára ìtura àti ìtùnú nígbà tí wọ́n bá jókòó pẹ̀lú àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó jẹ́ ará Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ṣàgbèrè, ó sì bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ fún oṣù mélòó kan. Lẹ́yìn tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ di mímọ̀, ó sọ fún àwọn alàgbà pé: “Ì bá ti dára ká ní ẹnì kan ti béèrè lọ́wọ́ mi nípa àjọṣe mi pẹ̀lú ọmọbìnrin yẹn! Ìtura ńlá ni ó jẹ́ láti mú ọ̀ràn náà wá sí ojútáyé.”—Fi wé Orin Dáfídì 32:3-5.
Ìṣe Ìfẹ́ Tí A Gbé Karí Ìlànà
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ti ṣe batisí ti “ré kọjá láti inú ikú sí ìyè.” (Jòhánù Kíní 3:14) Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ búburú jáì, wọ́n ti yí pa dà sí ọ̀nà ikú. Bí a kò bá ràn wọ́n lọ́wọ́, ọkàn wọn lè yigbì sínú híhùwà àìtọ́, kí wọ́n má fẹ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì pa dà sí ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.—Hébérù 10:26-29.
Fífi ẹjọ́ ẹni tí ó hùwà àìtọ́ sùn jẹ́ ìwà àníyàn àtọkànwá fún oníwà àìtọ́ náà. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará mi, bí a bá ṣi ẹnikẹ́ni láàárín yín lọ́nà kúrò nínú òtítọ́ tí ẹlòmíràn sì yí i pa dà, mọ̀ pé ẹni tí ó yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan pa dà kúrò nínú ìṣìnà ọ̀nà rẹ̀ yóò gba ọkàn rẹ̀ là kúrò lọ́wọ́ ikú yóò sì bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—Jákọ́bù 5:19, 20.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fẹjọ́ ẹni tí ó hùwà ibi sùn? Nítorí ó ń mú èso rere jáde. Ní tòótọ́, láti fẹjọ́ ẹnì kan tí ó hùwà àìtọ́ sùn jẹ́ ìwà ìfẹ́ Kristẹni tí a gbé karí ìlànà, tí a fi hàn sí Ọlọ́run, tí a fi hàn sí ìjọ, àti sí oníwà àìtọ́ náà. Bí mẹ́ńbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ti ń fi ìdúróṣinṣin di ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run mú, Jèhófà yóò bù kún ìjọ náà lódindi ní jìngbìnnì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òun [Jèhófà] yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in pẹ̀lú títí dé òpin, kí ẹ̀yin má baà fi àyè sílẹ̀ fún ẹ̀sùn kankan ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kristi.”—Kọ́ríńtì Kíní 1:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ó ń fi ìfẹ́ hàn láti fún oníláìfí kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí níṣìírí láti sọ fún àwọn alàgbà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn alàgbà ń ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn oníláìfí pa dà rí ojú rere Ọlọ́run