“Fi Àwọn Ohun Ìní Rẹ Tí Ó Níye Lórí Bọlá fún Jèhófà”—Lọ́nà Wo?
“FI ÀWỌN ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà àti àkọ́so gbogbo èso rẹ.” Àṣírí nínímọ̀lára ìbùkún Jèhófà ní yanturu ń bẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n, tí a mí sí yìí, tí a kọ sílẹ̀ ní nǹkan bí 2,600 ọdún sẹ́yìn, nítorí òǹkọ̀wé náà ń bá a lọ láti ṣàlàyé pé: “Nígbà náà, àwọn ilé ìtọ́jú ẹrù rẹ yóò kún fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ; wáìnì tuntun yóò sì kún àwọn ẹkù ìfúntí rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀.”—Òwe 3:9, 10, NW.
Ṣùgbọ́n, kí ni ó túmọ̀ sí láti bọlá fún Ọlọ́run? Kí ni àwọn ohun ìní tí ó níye lórí tí ó yẹ kí a fi bọlá fún Jèhófà? Ọ̀nà wo sì ni a lè gbà ṣe èyí?
“Bọlá fún Jèhófà”
Nínú Ìwé Mímọ́, pàtàkì ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún bọlá fún, ka·vohdhʹ, túmọ̀ sí “ìwúwo,” ní ṣangiliti. Nítorí náà, láti bọlá fún ẹnì kan túmọ̀ sí láti kà á sí ẹni pàtàkì, tí ó ní láárí, tàbí tí ó jámọ́ nǹkan. A tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù míràn tí a ń lò fún bọlá fún, yeqarʹ, sí “ṣeyebíye” àti “ohun iyebíye.” Lọ́nà kan náà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ti·meʹ, tí a tú sí “bọlá fún” nínú Bíbélì, gbé ìtumọ̀ gbé gẹ̀gẹ̀, mọyì, ìṣeyebíye, síni lọ́kàn. Nípa báyìí, ẹnì kan ń bọlá fún ẹnì kejì nípa bíbọ̀wọ̀ ńlá fún un àti gbígbé e gẹ̀gẹ̀.
Bíbọlá fúnni tún ní apá mìíràn. Ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ nípa Júù olùṣòtítọ́ náà, Módékáì, tí ó tú ìdìmọ̀lù tí a ṣe láti gba ẹ̀mí Ọba Ahasuwérúsì ti Páṣíà ìgbàanì fó, nígbà kan. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọba gbọ́ pé a kò ṣe ohunkóhun láti fi bọlá fún Módékáì fún ìgbésẹ̀ yẹn, ó bi olórí ìjọba rẹ̀, Hámánì, láti sọ ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbà bọlá fún ẹni náà tí inú ọba yọ́ sí. Hámánì ronú pé tòun ni irú ọlá bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́, ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ó ṣe ṣìnà tó! Kí a má fọ̀rọ̀ gùn, Hámánì sọ pé kí a fi “aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba” wọ irú ẹni bẹ́ẹ̀, kí ó sì gun “ẹṣin tí ọba máa ń gùn.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí pé: “Kí wọ́n . . . mú kí ó gun ẹṣin náà ní ojúde ìlú ńlá, kí wọ́n sì máa ké jáde níwájú rẹ̀ pé, ‘Bí a ti ń ṣe nìyí sí ọkùnrin tí ọba tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí láti bọlá fún.’” (Ẹ́sítérì 6:1-9, NW) Nínú ọ̀ràn yí, bíbọlá fún ẹnì kan wémọ́ gbígbé e ga ní gbangba, kí gbogbo ènìyàn baà lè gbé e gẹ̀gẹ̀.
Lọ́nà kan náà, bíbọlá fún Jèhófà pín sí apá méjì: fífi ọ̀wọ̀ hàn fún un gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan àti gbígbé e ga ní gbangba nípa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ pípolongo orúkọ rẹ̀ ní gbangba àti títi iṣẹ́ náà lẹ́yìn.
“Àwọn Ohun Ìní Rẹ Tí Ó Níye Lórí”—Kí Ni Wọ́n?
Dájúdájú, àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí ní ìgbésí ayé wa, àkókò wa, ẹ̀bùn wa, àti okun wa, nínú. Àwọn ohun ìní wa ti ara ńkọ́? Gbé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nígbà tí ó rí opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an sínú àpótí ìṣúra tẹ́ńpìlì, yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí [àwọn olùṣètọrẹ yòó kù] sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀ sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.” (Lúùkù 21:1-4) Jésù yin opó yìí fún lílo àwọn ohun ìní rẹ̀ ti ara láti ti ìjọsìn Jèhófà lẹ́yìn.
Nígbà náà, ó ṣe kedere pé àwọn ohun ìní tí ó níye lórí tí Sólómọ́nì mẹ́nu kàn tún ní ohun ìní ti ara èyíkéyìí tí a lè ní nínú. Gbólóhùn náà, “àkọ́so gbogbo èso rẹ,” ní ìtumọ̀ fífún Jèhófà ní èyí tí ó dára jù lọ nínú àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí.
Ṣùgbọ́n, báwo ni fífún Ọlọ́run ní ohun ìní ti ara ṣe lè bọlá fún un? Tirẹ̀ ha kọ́ ni ohun gbogbo bí? (Orin Dáfídì 50:10; 95:3-5) Ọba Dáfídì jẹ́wọ́ nínú àdúrà àtọkànwá rẹ̀ sí Jèhófà pé: “Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá.” Ní ti ìtọrẹ ńlá tí òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣe fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì, Dáfídì sọ pé: “Láti ọwọ́ rẹ wá . . . ni a ti fi fún ọ.” (Kíróníkà Kíní 29:14) Nítorí náà, nígbà tí a bá ń ta Jèhófà lọ́rẹ, a wulẹ̀ ń dá lára ohun tí ó ti fún wa, láti inú ire ọkàn àyà rẹ̀, pa dà ni. (Kọ́ríńtì Kíní 4:7) Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìṣáájú, bíbọlá fún Jèhófà ní gbígbé e ga níwájú àwọn ẹlòmíràn nínú. Àwọn ẹ̀bùn ti ara tí a sì ń lò fún ìlọsíwájú ìjọsìn tòótọ́ ń bọlá fún Ọlọ́run. Àwọn àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá ti bíbọlá fún Jèhófà lọ́nà yí kún inú Bíbélì.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìgbà Àtijọ́
Ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí àkókò tó fún Jèhófà láti pèsè àgọ́ àjọ nínú aginjù gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àìní dìde fún onírúurú àwọn ohun iyebíye tí àwòrán ilé tí a fúnni láti ọ̀run ń béèrè fún. Jèhófà pàṣẹ fún Mósè láti jẹ́ kí ‘ẹnikẹ́ni tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ mú ọrẹ wá fún OLÚWA.’ (Ẹ́kísódù 35:5) Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ láti ròyìn pé: “Wọ́n . . . wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ ru nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ mú un fẹ́, wọ́n sì mú ọrẹ OLÚWA wá fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà, àti fún ìsìn rẹ̀ gbogbo, àti fún aṣọ mímọ́ wọnnì.” (Ẹ́kísódù 35:21) Ní tòótọ́, ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wọn pọ̀ púpọ̀ ju ohun tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ náà lọ débi pé wọ́n ní láti “dá àwọn ènìyàn lẹ́kùn àti máa mú wá”!—Ẹ́kísódù 36:5, 6.
Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Lẹ́yìn tí àgọ́ àjọ ti parí iṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń múra fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì, Dáfídì ṣe ìtọrẹ ńlá fún tẹ́ńpìlì tí ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì yóò kọ́. Ó tún ké sí àwọn ẹlòmíràn láti dara pọ̀ mọ́ ọn, àwọn ènìyàn náà sì dáhùn pa dà nípa fífún Jèhófà ní ẹ̀bùn àwọn ohun ìní tí ó níye lórí. Fàdákà àti wúrà nìkan yóò tó 50 bílíọ̀nù dọ́là lónìí. “Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ lórí ṣíṣe tí wọ́n ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe.”—Kíróníkà Kíní 29:3-9, NW; Kíróníkà Kejì 5:1.
“Àwọn Ìtọrẹ Àfínnúfíndọ̀ṣe” ní Ọjọ́ Wa
Báwo ni a ṣe lè ṣàjọpín nínú ayọ̀ ṣíṣe ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ní ọjọ́ wa? Iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ń lọ lọ́wọ́ nínú ayé ní àkókò yí ni ti ìwàásù Ìjọba àti sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Jèhófà sì ti rí i pé ó tọ́ láti fi àwọn ire rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ti Ìjọba sábẹ́ àbójútó Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀.—Aísáyà 43:10.
Ó ṣe kedere pé a nílò owó láti bójú tó iṣẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lónìí. Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ̀ka ọ́fíìsì, ilé ìtẹ̀wé, àti ilé Bẹ́tẹ́lì, àti bíbójú tó wọn, ń béèrè owó. Títẹ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì ní onírúurú èdè àti pípín wọn kiri pẹ̀lú ń béèrè ìnáwó. Báwo ni a ṣe ń kájú ìnáwó irú ìṣètò bẹ́ẹ̀? Nípa ọrẹ tí ó jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe pátápátá!
Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ọrẹ náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ—bí opó tí Jésù kíyè sí. Nítorí tí wọn kò fẹ́ pàdánù àǹfààní bíbọlá fún Jèhófà yí, wọ́n ń fi ọrẹ táṣẹ́rẹ́ tọrẹ “ní ìbámu pẹ̀lú [agbára] wọn gan-an,” àti nígbà míràn, àní “ré kọjá [agbára] wọn gan-an” pàápàá.—Kọ́ríńtì Kejì 8:3, 4.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti [pinnu] nínú ọkàn àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (Kọ́ríńtì Kejì 9:7) Fífúnni tọ̀yàyàtọ̀yàyà ń béèrè fún níní ìwéwèé tí ó dára. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: “Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀ kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gédégbé ní ìtọ́júpamọ́ gẹ́gẹ́ bí òun ti lè máa láásìkí, kí ó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé àkójọ kì yóò ṣẹlẹ̀ nígbà náà.” (Kọ́ríńtì Kíní 16:2) Lọ́nà kan náà, ní ìdákọ́ńkọ́ àti ní àfínnúfíndọ̀ṣe, àwọn tí wọ́n ń fẹ́ láti ṣe ìtọrẹ fún ìlọsíwájú iṣẹ́ Ìjọba lónìí lè ya díẹ̀ lára owó tí ń wọlé fún wọn sọ́tọ̀ fún ète yẹn.
Jèhófà Ń Bùkún Àwọn Tí Ń Bọlá fún Un
Bí aásìkí ti ara kì í tilẹ̀ ṣamọ̀nà sí aásìkí tẹ̀mí, lílo àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí—àkókò wa, okun wa, àti àwọn ohun ìní wa ti ara—lọ́nà ọ̀làwọ́ láti fi bọlá fún Jèhófà ń mú ìbùkún jìngbìnnì wá. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Ọlọ́run, ẹni tí ó ní ohun gbogbo níkàáwọ́, mú un dá wa lójú pé: “Ọkàn ìṣore ni a óò mú sanra; ẹni tí ó ń bomi rinni, òun tìkára rẹ̀ ni a ó sì bomi rin pẹ̀lú.”—Òwe 11:25.
Lẹ́yìn ikú Ọba Dáfídì, ọmọ rẹ̀ Sólómọ́nì lo ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe tí bàbá rẹ̀ ti kó jọ láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì ológo kan, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti lànà rẹ̀ sílẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí Sólómọ́nì fi jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ìjọsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run, “Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé ní àlàáfíà . . . láti Dánì títí dé Bíáṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.” (Àwọn Ọba Kìíní 4:25) Ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ kún bámúbámú, ẹkù wáìnì kún àkúnwọ́sílẹ̀—ní gbogbo ìgbà tí Ísírẹ́lì ‘fi àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’
Lẹ́yìn náà, nípasẹ̀ wòlíì Málákì, Jèhófà sọ pé: “Ẹ . . . fi èyí dán mi wò nísinsìnyí, bí èmi kì yóò bá ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yín, kí n sì tú ìbùkún jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sí àyè tó láti gbà á.” (Málákì 3:10) Aásìkí tẹ̀mí tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbádùn lónìí jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
Kò sí iyè méjì pé ó máa ń dùn mọ́ Jèhófà nínú nígbà tí a bá ṣe ipa tiwa nínú mímú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. (Hébérù 13:15, 16) Ó sì ṣèlérí láti pèsè fún wa bí a bá ‘ń bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Pẹ̀lú ayọ̀ ńláǹlà, ǹjẹ́ kí a ‘fi àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Ọ̀nà tí Àwọn kan Yàn Láti Gbà Ṣètọrẹ fún Iṣẹ́ Yíká Ayé
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a lẹ ìsọfúnni náà: “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Yíká Ayé—Mátíù 24:14” mọ́ lára. Lóṣooṣù ni àwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́, yálà sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, tàbí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti àdúgbò.
A tún lè fi ìtọrẹ owó tí a fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. A tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì míràn ṣètọrẹ. Lẹ́tà ṣókí kan tí ń fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn pátápátá ní láti bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.
Ìṣètò Ìtọrẹ Onípò Àfilélẹ̀ A lè fún Watch Tower Society ní owó lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé olùtọrẹ náà nílò owó náà, a óò dá a pa dà fún un. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí ó wà lókè yìí.
Fífúnni tí A Wéwèé
Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ìtọrẹ onípò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà míràn wà tí a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba kárí ayé. Èyí ní nínú:
Owó Ìbánigbófò: A lè dárúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìlànà ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí ìwéwèé owó àsanfúnni fún ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́. A ní láti fi irú ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
Àkáǹtì Owó ní Báǹkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báǹkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ẹnì kan sí ìkáwọ́ tàbí mú kí ó ṣeé san nígbà ikú, fún Watch Tower Society, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báǹkì àdúgbò bá béèrè fún. A ní láti fi irú àwọn ìṣètò èyíkéyìí bẹ́ẹ̀ tó Society létí.
Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Lórí Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti lórí ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pátápátá, tàbí lábẹ́ ìṣètò kan, níbi tí a óò ti máa bá a nìṣó láti san owó tí ń wọlé wá lórí èyí fún olùtọrẹ náà.
Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tí ó ṣeé tà, ta Watch Tower Society lọ́rẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn pátápátá, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní olùtọrẹ náà, nígbà tí ó bá ṣì wà láàyè, ẹni tí ó ṣì lè máa gbé inú rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Ẹnì kan ní láti kàn sí Society ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ti Society.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Ìfisíkàáwọ́-Ẹni: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, a sì lè dárúkọ Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ìwé àdéhùn fífi ohun sí ìkáwọ́ ẹni. Àwọn ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni tí ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí. A ní láti fi ẹ̀dà kan nínú ìwé ìhágún tàbí ìwé àdéhùn ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni ránṣẹ́ sí Society.
Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ tí gbólóhùn náà “fífúnni tí a wéwèé” gbé rù, irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé díẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó ń ṣètọrẹ. Láti ran àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ń fẹ́ láti ṣe Society láǹfààní nípasẹ̀ irú ọ̀nà ìfúnni tí a wéwèé kan, a ti mú ìwé pẹlẹbẹ kan jáde, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Planned Giving to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà ní ìdáhùnpadà sí ọ̀pọ̀ ìwádìí tí Society ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní ìfisíkàáwọ́-ẹni. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni ṣíṣàǹfààní nípa ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú, a sì pète rẹ̀ láti fi ran àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ní United States tí ń fẹ́ láti ṣàǹfààní fún ire Ìjọba kárí ayé lọ́wọ́ láti yan ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní, tí ó sì gbéṣẹ́ jù lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbígbé àyíká ipò ìdílé àti ti ara wọn yẹ̀ wò. Nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ náà àti fífọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní Planned Giving Desk, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún Society àti lọ́wọ́ kan náà láti mú kí àǹfààní owó orí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí i. Ìwé pẹlẹbẹ náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí a bá béèrè fún un, yálà nípa kíkọ̀wé tàbí títẹ̀ wá láago.
Àwọn tí ó bá nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú ìṣètò fífúnni tí a wéwèé wọ̀nyí lè kàn sí Planned Giving Desk, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 100 Watchtower Drive, Patterson, New York 12563-9204, telephone (914) 878-7000, tàbí kí wọ́n kàn sí ọ́fíìsì Society tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè wọn.