“Jèhófà, Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́”
“Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 34:6.
1. (a) Ìtùnú wo ni Bíbélì pèsè fún àwọn tí ó ṣẹlẹ̀ sí pé ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ gaara? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tí ó ṣìnà?
BABA kan tí ó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Ọmọbìnrin mi sọ fún mi pé òun kò fẹ́ jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni mọ́. Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀, àní ọ̀pọ̀ oṣù tí ó tẹ̀ lé e pàápàá, ìbànújẹ́ ńláǹlà bá mi. Ikú yá jù ú lọ.” Lóòótọ́, ó ń bani lọ́kàn jẹ́ láti rí i pé ẹnì kan tí a nífẹ̀ẹ́ ṣáko lọ́ kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Ǹjẹ́ irú rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí? Bí ó bá ti ṣẹlẹ̀, mímọ̀ pé Jèhófà ń gba tìrẹ rò yóò tù ọ́ nínú. (Ẹ́kísódù 3:7; Aísáyà 63:9) Ṣùgbọ́n, ojú wo ni òun fi ń wo irú àwọn tí ó ti ṣìnà bẹ́ẹ̀? Bíbélì fi hàn pé Jèhófà fi tàánútàánú ké sí wọn láti padà wá rí ojú rere òun. Ó rọ àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n gbé ní ọjọ́ Málákì pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.”—Málákì 3:7.
2. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé àánú jẹ́ apá pàtàkì nínú àkópọ̀ ìwà Jèhófà?
2 Àánú Ọlọ́run hàn sí Mósè lọ́nà tí ó ṣe kedere lórí Òkè Sínáì. Níbẹ̀, Jèhófà fi ara rẹ̀ hàn ní “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, [tí] ó ń lọ́ra láti bínú, [tí] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Ìkéde yìí túbọ̀ fi hàn pé àánú jẹ́ apá pàtàkì nínú àkópọ̀ ìwà Jèhófà. Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù, kọ̀wé pé ó “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Àmọ́ ṣá o, àánú Ọlọ́run kì í ṣe èyí tí kò ní ààlà. A sọ fún Mósè pé: “lọ́nàkọnà kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:7; 2 Pétérù 2:9) Síbẹ̀síbẹ̀, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” àánú sì kó apá púpọ̀ nínú ànímọ́ yẹn. (1 Jòhánù 4:8; Jákọ́bù 3:17) Jèhófà kò ní “máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé,” òun sì “ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Míkà 7:18, 19.
3. Báwo ni èrò Jésù nípa àánú ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí?
3 Jésù mú ìwà Baba rẹ̀ ọ̀run lọ́nà pípé. (Jòhánù 5:19) Fífi tí ó fi àánú bá àwọn oníwà àìtọ́ lò kò túmọ̀ sí pé ó gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ fífi irú ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ kan náà hàn sí wọn, èyí tí ó fi hàn sí àwọn tí ara wọn kò dá. (Fi wé Máàkù 1:40, 41.) Àní, Jésù ka àánú sí ọ̀kan lára “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ” ti Òfin Ọlọ́run. (Mátíù 23:23) Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, gbé àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí yẹ̀ wò, àwọn tí rírin tí wọ́n ń rinkinkin mọ́ ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo kò fàyè gba fífi àánú hàn rárá. Nígbà tí wọ́n rí ìbálò Jésù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, wọ́n ṣàròyé pé: “Ọkùnrin yìí fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” (Lúùkù 15:1, 2) Jésù fi àpèjúwe mẹ́ta, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ fi ìjẹ́pàtàkì àánú Ọlọ́run hàn, dá àwọn tí ó fẹ̀sùn kàn án lóhùn.
4. Àpèjúwe méjì wo ni Jésù sọ, kí sì ni kókó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn?
4 Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù sọ nípa ọkùnrin kan tí ó fi àgùntàn 99 sílẹ̀ láti lọ máa wá ẹyọ kan tí ó ti sọnù. Kókó wo ló fẹ́ fà yọ? “Ìdùnnú púpọ̀ yóò . . . wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn olódodo tí wọn kò nílò ìrònúpìwàdà.” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ nípa obìnrin kan tí ó ń wá ẹyọ owó dírákímà kan tí ó ti sọnù, tí inú rẹ̀ sì dùn nígbà tí ó rí i. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? “Ìdùnnú . . . ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.” Àkàwé ni Jésù fi àpèjúwe kẹta tí ó sọ ṣe.a Ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá kà á sí ìtàn ṣókí tí ó lárinrin jù lọ tí a tíì gbọ́ rí. Àgbéyẹ̀wò àkàwé yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì àánú Ọlọ́run, kí a sì fara wé e.—Lúùkù 15:3-10.
Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ Filé Sílẹ̀
5, 6. Báwo ni ọmọkùnrin tí ó jẹ́ àbúrò nínú àkàwé kẹta tí Jésù ṣe ṣe fi àìnímọrírì gbáà hàn?
5 “Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì. Èyí àbúrò nínú wọn sì wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ipa dúkìá tí ó jẹ́ ìpín tèmi.’ Nígbà náà ni ó pín àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé rẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, ọmọkùnrin tí ó jẹ́ àbúrò kó gbogbo nǹkan jọpọ̀, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀ sí ilẹ̀ jíjìnnàréré, ibẹ̀ ni ó sì ti lo dúkìá rẹ̀ ní ìlò àpà nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà.”—Lúùkù 15:11-13.b
6 Níhìn-ín, èyí àbúrò fi àìmọrírì gbáà hàn. Lákọ̀ọ́kọ́, ó béèrè fún ogún tirẹ̀, lẹ́yìn náà ó ṣe é báṣubàṣu “nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà.” A tú gbólóhùn náà, “ìgbésí ayé oníwà wọ̀bìà,” láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ó túmọ̀ sí “ìgbésí ayé amùṣùà.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ náà “fi àìníwà ọmọlúwàbí rárá hàn.” Pẹ̀lú ìdí tí ó múná dóko, a sábà máa ń pe ọ̀dọ́mọkùnrin inú àkàwé Jésù ni onínàákúnàá, ọ̀rọ̀ kan tí ó ṣàpèjúwe ẹnì kan tí ó jẹ́ àpà àti arugún.
7. Àwọn wo lónìí ni wọ́n dà bí ọmọ onínàákúnàá, èé sì ti ṣe tí ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi ń wá òmìnira lọ sí “orílẹ̀-èdè jíjìnnàréré”?
7 Ǹjẹ́ àwọn èèyàn kan wà lónìí tí wọ́n dà bí ọmọ onínàákúnàá yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó ṣeni láàánú pé, àwọn kéréje kan ti fi “ilé” aláàbò ti Baba wa ọ̀run, Jèhófà, sílẹ̀. (1 Tímótì 3:15) Àwọn kan lára wọn rò pé àyíká agbo ilé Ọlọ́run kò jẹ́ kí àwọn ṣe bí àwọn ti fẹ́, wọ́n rò pé ìdíwọ́ ni ojú Jèhófà tí ń wò wá jẹ́ kì í ṣe ààbò. (Fi wé Sáàmù 32:8.) Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn obìnrin Kristẹni kan tí a fi ìlànà Bíbélì tọ́ dàgbà, ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí ó di ọ̀mùtí àti ajoògùnyó. Nígbà tí ó ronú nípa àkókò tí ó fi gbé ìgbésí ayé ráuràu yẹn, ó sọ pé: “Mo fẹ́ fi hàn pé mo lè fúnra mi gbé ìgbésí ayé tí ó sàn jù. Mo fẹ́ máa ṣe gbogbo ohun tí ó bá wù mí, n kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá mi sọ ohun tí ó bá yàtọ̀ sí ohun tí mo fẹ́.” Bí ti ọmọ onínàákúnàá, obìnrin yìí wá òmìnira. Ó mà ṣe o, a ní láti yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni, nítorí àwọn ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí ó hù.—1 Kọ́ríńtì 5:11-13.
8. (a) Ìrànwọ́ wo ni a lè fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gbé ìgbésí ayé tí ó lòdì sí ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ẹnì kan ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí yíyàn tí ó bá ṣe nípa ọ̀ràn ìjọsìn?
8 Lóòótọ́, ó máa ń jẹ́ ìbànújẹ́ ńláǹlà nígbà tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni bá fi hàn pé òun fẹ́ gbé ìgbésí ayé tí ó lòdì sí ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run. (Fílípì 3:18) Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí ní láti sapá láti tọ́ ẹni tí ó ṣìnà náà sọ́nà. (Gálátíà 6:1) Síbẹ̀síbẹ̀, a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti gba àjàgà dídi Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 11:28-30; 16:24) Àní àwọn èwe pàápàá nígbà tí wọ́n bá dàgbà, ní láti ṣe ìpinnu fúnra wọn nípa ọ̀ràn ìjọsìn. Lékè gbogbo rẹ̀, olúkúlùkù wa jẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù tí yóò jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run. (Róòmù 14:12) Ó sì dájú pé, ‘ohun yòówù tí a bá fúnrúgbìn ni a óò ká’—ẹ̀kọ́ tí ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù yóò kọ́ láìpẹ́.—Gálátíà 6:7, 8.
Àìnírètí ní Orílẹ̀-Èdè Jíjìnnàréré
9, 10. (a) Irú àyípadà wo ni ó dé bá ọmọ onínàákúnàá, báwo sì ni ó ṣe gbà á? (b) Ṣàpèjúwe bí àwọn kan lónìí tí wọ́n fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ ṣe ní irú ìṣòro tí ó jọ ti ọmọ onínàákúnàá?
9 “Nígbà tí ó ti ná ohun gbogbo tán, ìyàn wá mú gan-an jákèjádò ilẹ̀ yẹn, ó sì wá wà nínú àìní. Ó tilẹ̀ lọ so ara rẹ̀ mọ́ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú ilẹ̀ yẹn, ó sì rán an sínú àwọn pápá rẹ̀ láti máa ṣe olùṣọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Òun a sì máa fẹ́ láti jẹ àwọn pódi èso kárọ́ọ̀bù ní àjẹyó, èyí tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, kò sì sí ẹni tí yóò fún un ní ohunkóhun.”—Lúùkù 15:14-16.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣì ti ta á, ọmọ onínàákúnàá yìí kò ronú àtipadà sílé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lọ ba ẹnì kan tí ó jẹ́ aráàlú náà, ìyẹn sì gbà á síṣẹ́ ṣíṣọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Níwọ̀n bí Òfin Mósè ti sọ pàtó pé ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ ẹran aláìmọ́, kò sí Júù tí yóò fẹ́ gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. (Léfítíkù 11:7, 8) Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rí-ọkàn ọmọ onínàákúnàá náà bá tilẹ̀ ń dà á láàmú, ṣeni yóò wulẹ̀ pa ẹ̀rí-ọkàn náà lẹ́nu mọ́. Ó ṣe tán, kò lè retí kí ẹni tó gbà á síṣẹ́, tí ó jẹ́ aráàlú ibẹ̀, máa wá ṣàníyàn nípa àjèjì lásánlàsàn kan tí kò-rí-bá-ti-ṣé. Ipò burúkú tí ọmọ onínàákúnàá náà wà jọ ti ọ̀pọ̀ lónìí tí wọ́n fi ọ̀nà gbọnrangandan ti ìjọsìn mímọ́ gaara sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí wọ́n ti kà sí èyí tí ń rẹni nípò wálẹ̀ tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan jẹ́ ọmọ ọdún 17, ó tako ọ̀nà tí a gbà tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Ó jẹ́wọ́ pé: “Ìṣekúṣe àti ìjoògùnyó pa àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbé karí Bíbélì tí mo ti kọ́ rẹ́ mọ́ mi nínú.” Kò pẹ́ púpọ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí bá ara rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìdigunjalè àti ìpànìyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó padà sípò nípa tẹ̀mí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹ wo ohun tí ojú rẹ̀ rí nítorí “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀”!—Fi wé Hébérù 11:24-26.
11. Kí ni ó mú kí ìṣòro ọmọ onínàákúnàá peléke sí i, báwo sì ni àwọn kan lónìí ṣe wá rí i pé “ẹ̀tàn òfifo” gbáà ni gbogbo nǹkan yòyòòyò ti ayé?
11 Ìṣòro ọmọ onínàákúnàá náà tún wá peléke sí i nítorí pé “kò . . . sí ẹni tí yóò fún un ní ohunkóhun.” Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tuntun tó ń kó kiri ńkọ́? Nísinsìnyí tí kò ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́ mọ́, ó wá dà bí “ẹni ìkórìíra” sí wọn. (Òwe 14:20) Bákan náà, ọ̀pọ̀ lónìí tí wọ́n ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ́ wá rí i pé “ẹ̀tàn òfìfo” gbáà ni gbogbo nǹkan yòyòòyò ti ayé yìí àti ojú ìwòye rẹ̀. (Kólósè 2:8) Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí ó ti fi ètò àjọ Ọlọ́run sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ sọ pé: “Mo jẹ baba ńlá ìyà, ìrora ọkàn sì bá mi nítorí àìní ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Mo gbìyànjú láti ṣe bí ayé ti ń ṣe, ṣùgbọ́n nítorí pé ìwà mi kò jọ tiwọn délẹ̀délẹ̀, wọ́n kọ̀ mí. Mo wá dà bí ọmọ tí ó sọnù tí ó nílò baba rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà. Ìgbà yẹn ni mo tó wá mọ̀ pé mo nílò Jèhófà. N kò tún fẹ́ máa gbé ayé mọ́ láìgbára lé e.” Ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù pẹ̀lú wá mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Orí Ọmọ Onínàákúnàá Wálé
12, 13. Kí ni àwọn nǹkan tí ó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ lónìí láti pe orí ara wọn wálé? (Wo àpótí.)
12 “Nígbà tí orí rẹ̀ wálé, ó wí pé, ‘Mélòómélòó ni àwọn ọkùnrin tí baba mi háyà, tí wọ́n ní oúnjẹ púpọ̀ gidigidi, nígbà tí èmi ń ṣègbé lọ níhìn-ín lọ́wọ́ ìyàn! Ṣe ni èmi yóò dìde, n ó sì rin ìrìn àjò lọ sọ́dọ̀ baba mi, n ó sì wí fún un pé: “Baba, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ. Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.”’ Nítorí náà, ó dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ baba rẹ̀.”—Lúùkù 15:17-20.
13 “Orí” ọmọ onínàákúnàá náà “wálé.” Tẹ́lẹ̀ rí, fàájì ni ọmọ onínàákúnàá náà ń ṣe kiri, bí ẹni pé ayé kan tí ó ti ń lálàá rẹ̀ tipẹ́ ló wà. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó wá mọ ipò rẹ̀ gan-an nípa tẹ̀mí. Bẹ́ẹ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣubú, ìrètí ṣì wà fún ọ̀dọ́mọkùnrin yìí. A ṣì lè rí nǹkan rere díẹ̀ wò mọ́ ọn lára. (Òwe 24:16; fi wé 2 Kíróníkà 19:2, 3.) Àwọn tí wọ́n fi agbo Ọlọ́run sílẹ̀ lónìí ńkọ́? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kò sí àtúnṣe fún wọn mọ́, pé ní gbogbo ọ̀nà, ìwà ọ̀tẹ̀ wọn ti fi hàn pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bí? (Mátíù 12:31, 32) Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Àwọn kan nínú wọn ni ìwà jágbajàgba tí wọ́n hù ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá, lọ́pọ̀ ìgbà sì ni orí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti wálé. Arábìnrin kan nígbà tí ó ń rántí àkókò tí ó lò lẹ́yìn òde ètò àjọ Ọlọ́run sọ pé: “N kò gbàgbé Jèhófà rí, àní n kò tilẹ̀ gbàgbé rẹ̀ fún ọjọ́ kan péré. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbàdúrà pé, lọ́nà kan ṣá, lọ́jọ́ kan, òun yóò gbà mí padà sínú òtítọ́.”—Sáàmù 119:176.
14. Ìpinnu wo ni ọmọ onínàákúnàá náà ṣe, báwo sì ni ó ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
14 Ṣùgbọ́n kí ni àwọn tí wọ́n ti ṣáko lọ lè ṣe nípa ipò wọn? Nínú àkàwé Jésù, ọmọ onínàákúnàá náà pinnu láti rìnrìn àjò padà sílé, kí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì baba rẹ̀. Ọmọ onínàákúnàá náà pinnu láti sọ pé: “Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.” Iṣẹ́ òòjọ́ ni a ń gba ìránṣẹ́ kan tí a háyà fún, ìsọfúnni ọjọ́ kan péré sì ti tó láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ipò rẹ̀ tilẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju ti ẹrú lọ, ẹni tí ó jẹ́ pé, lọ́nà kan, ojú mẹ́ńbà ìdílé lá fi ń wò ó. Nítorí náà, ọmọ onínàákúnàá náà kò ní in lọ́kàn pé kí a padà fi òun sí ipò ọmọ tí òun wà tẹ́lẹ̀. Kíá ni yóò gbà láti wà ní ipò rírẹlẹ̀ jù lọ yìí, kí ó lè fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ tí ó sọ dọ̀tun hàn fún baba rẹ̀ lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n, ẹnu yóò ya ọmọ onínàákúnàá náà.
Ìgbàwọlé Amọ́kànyọ̀
15-17. (a) Kí ni baba náà ṣe nígbà tí ó rí ọmọ rẹ̀? (b) Ki ni aṣọ, òrùka, àti sálúbàtà tí baba pèsè fún ọmọ rẹ̀ túmọ̀ sí? (d) Kí ni ètò tí baba ṣe fún àsè fi hàn?
15 “Nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn, baba rẹ̀ tajú kán rí i, àánú sì ṣe é, ó sì sáré, ó sì rọ̀ mọ́ ọrùn rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Nígbà náà ni ọmọkùnrin náà wí fún un pé, ‘Baba, èmi ti ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí ọ. Èmi kò yẹ mọ́ ní ẹni tí a ń pè ní ọmọkùnrin rẹ. Fi mí ṣe bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí o háyà.’ Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Kíá! ẹ mú aṣọ jáde wá, èyí tí ó dára jù lọ, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́, kí ẹ sì fi òrùka sí ọwọ́ rẹ̀ àti sálúbàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀. Kí ẹ sì mú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí a jẹun, kí a sì gbádùn ara wa, nítorí pé ọmọkùnrin mi yìí kú, ó sì wá sí ìyè; ó sọnù, a sì rí i.’ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ara wọn.”—Lúùkù 15:20-24.
16 Gbogbo òbí onífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń yán hànhàn pé kí ọmọ òun padà sípò nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, a lè finú wòye bí baba ọmọ onínàákúnàá náà ti ń wojú ọ̀nà totooto níwájú ìta ilé rẹ̀ lójoojúmọ́, tí ó ń fi ìháragàgà retí pé kí ọmọ òun padà wálé. Wàyí o, ó tajú kán rí ọmọ rẹ̀ tí ń bọ̀ wálé! A ò ṣẹ̀ṣẹ̀ lè máa sọ ọ́, ìrísí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti yàtọ̀ pátápátá. Síbẹ̀, baba náà ṣì dá a mọ̀ “nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn.” Ti pé àkísà ló wọ̀ àti pé ìbànújẹ́ bá a kọ́ ni pàtàkì báyìí; lájorí ibẹ̀ ni pé ó rí ọmọ rẹ̀, ó sì sáré lọ pàdé rẹ̀!
17 Nígbà tí baba náà pàdé ọmọ rẹ̀, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún àwọn ẹrú rẹ̀ láti mú aṣọ, òrùka, àti sálúbàtà wá fún ọmọ òun. Aṣọ yìí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀wù kan lásán, ṣùgbọ́n “èyí tí ó dára jù”—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tí a kóṣẹ́ sí, irú èyí tí a fi ń ta àlejò pàtàkì lọ́rẹ. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹrú kì í sábà fi òrùka sọ́wọ́ tàbí wọ sálúbàtà, baba náà ń mú kí ó ṣe kedere pé òun ń gba ọmọkùnrin òun padà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó mẹ́ńbà ìdílé. Ṣùgbọ́n ohun tí baba náà ṣe ṣì kù. Ó pàṣẹ pé kí a ṣayẹyẹ pé ọmọ òun padà wálé. Ó ṣe kedere pé, ọkùnrin yìí kò fi ìlọ́ra dárí ji ọmọ rẹ̀ tàbí pé ó wulẹ̀ pọndandan láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí wíwá tí ọmọ rẹ̀ wálé; ó fẹ́ nawọ́ ìdáríjì sí i. Ó mú inú rẹ̀ dùn.
18, 19. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni ó rí kọ́ nípa Jèhófà nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá? (b) Gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú ìbálò Jèhófà pẹ̀lú Júdà àti Jerúsálẹ́mù, báwo ni Jèhófà ṣe ń “bá a lọ ní fífojúsọ́nà” pé kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà wálé?
18 Níbi tí a dé yìí, kí ni àkàwé ọmọ onínàákúnàá kọ́ wa nípa Ọlọ́run tí a láǹfààní láti jọ́sìn? Lákọ̀ọ́kọ́, ó kọ́ wa pé Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Ní tòótọ́, àánú jẹ́ ànímọ́ títayọ tí Ọlọ́run ní. Ọ̀nà tí ó sábà fi ń bá àwọn tí ó nílò ìrànwọ́ lò nìyẹn. Lẹ́yìn náà, àkàwé Jésù kọ́ wa pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Lọ́nà àpèjúwe, ó wà lójúfò láti lè rí ìyípadà èyíkéyìí nínú ọkàn-àyà àwa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, èyí tí yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ fún un láti nawọ́ àánú sí wa.—2 Kíróníkà 12:12; 16:9.
19 Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú Ísírẹ́lì. Jèhófà mí sí wòlíì Aísáyà láti ṣàpèjúwe Júdà àti Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ‘ìlú tí ń ṣàìsàn láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀.’ Síbẹ̀, ó tún wí pé: “Jèhófà yóò máa bá a lọ ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò sì dìde láti fi àánú hàn sí yín.” (Aísáyà 1:5, 6; 30:18; 55:7; Ìsíkíẹ̀lì 33:11) Bí baba inú àkàwé Jésù, Jèhófà ‘ń wọ̀nà,’ kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó ń fi ìháragàgà retí pé kí ẹnikẹ́ni tí ó ti fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ padà wá. Kì í ha ṣe ohun tí a retí pé kí baba onífẹ̀ẹ́ kan ṣe nìyí bí?—Sáàmù 103:13.
20, 21. (a) Ọ̀nà wo ni àánú Ọlọ́run ti gbà fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ra lónìí? (b) Kí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
20 Lọ́dọọdún, àánú Jèhófà ń mú kí orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wálé, kí wọ́n sì padà wá sínú ìjọsìn tòótọ́. Ẹ wo bí èyí ti ń mú inú àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ wọn dùn tó! Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn baba tí ó jẹ́ Kristẹni tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ yẹn yẹ̀ wò. Ó dùn mọ́ni pé, ọmọbìnrin rẹ̀ padà sípò nípa tẹ̀mí, ó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nísinsìnyí. Baba náà wí pé: “Mo láyọ̀ dé ìwọ̀n tí ẹnì kan lè láyọ̀ dé nínú ètò ògbólógbòó yìí. A ti sọ ìbànújẹ́ mi dayọ̀.” Dájúdájú, inú Jèhófà dùn pẹ̀lú!—Òwe 27:11.
21 Àmọ́, ó ṣì ku ohun púpọ̀ tí a ó mọ̀ nípa àkàwé ọmọ onínàákúnàá. Jésù ń bá ìtàn rẹ̀ lọ kí ó bàa lè fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àánú Jèhófà àti ìwà àìgbatẹnirò àti ìṣelámèyítọ́ tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn akọ̀wé òfin àti Farisí. Bí ó ṣe ṣe é—àti ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa—ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àkàwé àti àpèjúwe mìíràn tí Bíbélì sọ kò ṣẹlẹ̀ ní gidi. Síwájú sí i, níwọ̀n bí ète sísọ àwọn ìtàn yìí ti jẹ́ láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan, kò sí ìdí láti wá ìtumọ̀ ìṣàpẹẹrẹ fún gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀.
b A jíròrò ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ àkàwé yìí nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1989, ojú ìwé 16, 17.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Ìyàtọ̀ wo ni ó wà nínú ìwà Jésù àti ti àwọn Farisí ní ti fífi àánú hàn?
◻ Àwọn wo ló dà bí ọmọ onínàákúnàá lónìí, báwo sì ni?
◻ Ipò wo ni ó pe orí ọmọ onínàákúnàá náà wálé?
◻ Báwo ni baba náà ṣe fi àánú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ó ronú pìwà dà?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
WỌ́N PE ORÍ ARA WỌN WÁLÉ
Kí ni ó ti ran àwọn kan tí a ti yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni nígbà kan lọ́wọ́ láti pe orí ara wọn wálé? Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí jẹ́ kí a mọ̀ ọ́n.
“Lọ́kàn mi mo ṣì mọ ibi tí òtítọ́ wà. Àwọn ọdún tí mo fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí mo sì fi lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni ti ní ipa pàtàkì lórí mi. Báwo ni mo ṣe lè wá kẹ̀yìn sí Jèhófà? Kò fi mí sílẹ̀; èmi ni mo fi í sílẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo wá rí i bí mo ti ṣìnà tí mo sì jẹ́ olóríkunkun tó, mo wá gbà pé Ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ̀nà nígbà gbogbo—‘ohun yòówù tí ènìyàn bá fúnrúgbìn ni yóò ká.’”—C.W.
“Ọmọbìnrin tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ìyẹn gún ọkàn mi ní kẹ́ṣẹ́ níwọ̀n bí mo ti fẹ́ kọ́ ọ ní irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti bí ó ṣe lè gbàdúrà sí i. N kì í lè sùn, lóru ọjọ́ kan mo wakọ̀ lọ sí ọgbà ìtura kan, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Mo sọkún títí, lẹ́yìn náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà, fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Gbogbo ohun tí mo ṣáà mọ̀ ni pé mo nílò Jèhófà padà nínú ìgbésí ayé mi, mo sì retí pé yóò dárí jì mí.”—G.H.
“Nígbà tí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn bá ṣẹlẹ̀, mo máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé bí n óò bá yan ẹ̀sìn tí ń fi òtítọ́ kọ́ni, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni màá jẹ́. Lẹ́yìn náà, màá wá sọ pé ọ̀kan lára wọn lèmi náà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìgbà tí n kò lè ṣe é, ni mo bá kúrò. Nígbà tí mo bá ronú kan èyí, ẹ̀rí-ọkàn mi máa ń dá mi lẹ́bi, inú mi sì máa ń bà jẹ́. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo gbà pé, ‘ń kò láyọ̀ rárá. Mo ní láti ṣe ìyípadà gírímọ́káì.’”—C.N.
“Ní ọdún 35 sẹ́yìn, a yọ èmi àti ọkọ mi lẹ́gbẹ́. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1991, ìyàlẹ́nu gbáà ni ó jẹ́ fún wa láti rí àwọn alàgbà méjì tí wọ́n bẹ̀ wá wò, tí wọ́n sì sọ fún wa pé ó ṣeé ṣe kí a padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, inú wa dùn gidigidi pé a gbà wá padà. Ẹni ọdún 79 ni ọkọ mi, mo sì jẹ́ ẹni ọdún 63.”—C.A.