Sí Àwọn Ará Róòmù
14 Ẹ tẹ́wọ́ gba ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára,+ àmọ́ ẹ má ṣe dá a lẹ́jọ́ nítorí èrò rẹ̀.* 2 Ìgbàgbọ́ ẹnì kan lè fàyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo, àmọ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára máa ń jẹ àwọn nǹkan ọ̀gbìn nìkan. 3 Kí ẹni tó ń jẹ má fojú àbùkù wo ẹni tí kò jẹ, kí ẹni tí kò jẹ má sì dá ẹni tó ń jẹ lẹ́jọ́,+ nítorí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba onítọ̀hún. 4 Ta ni ọ́, tí o fi ń ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ẹlòmíì?+ Ọ̀gá rẹ̀ ló máa pinnu bóyá ó máa ṣubú tàbí ó máa wà ní ìdúró.+ Ní tòótọ́, a máa mú un dúró, nítorí Jèhófà* lè mú un dúró.
5 Ẹnì kan gbà pé ọjọ́ kan ṣe pàtàkì ju òmíràn lọ;+ ẹlòmíì gbà pé ọjọ́ kan kò yàtọ̀ sí gbogbo ọjọ́ yòókù;+ kí èrò kálukú dá a lójú hán-ún hán-ún. 6 Ẹni tó ń pa ọjọ́ kan mọ́ ń pa á mọ́ fún Jèhófà.* Bákan náà, ẹni tó ń jẹun, ń jẹun fún Jèhófà,* nítorí ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run;+ ẹni tí kò sì jẹun kò jẹun fún Jèhófà,* síbẹ̀, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.+ 7 Kò sí ìkankan nínú wa, ní ti gidi, tó wà láàyè nítorí ara rẹ̀,+ kò sì sí ẹni tó kú nítorí ara rẹ̀. 8 Nítorí pé tí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà,*+ tí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà.* Torí náà, tí a bá wà láàyè tàbí tí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.*+ 9 Torí èyí ni Kristi fi kú, tí ó sì pa dà wà láàyè, kí ó lè jẹ́ Olúwa lórí àwọn òkú àti àwọn alààyè.+
10 Àmọ́ kí ló dé tí o fi ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́?+ Tàbí kí ló dé tí ò ń fojú àbùkù wo arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa la máa dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.+ 11 Nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “‘Bí mo ti wà láàyè,’+ ni Jèhófà* wí, ‘gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé èmi ni Ọlọ́run.’”+ 12 Nítorí náà, kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.+
13 Torí náà, kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́,+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ pinnu pé ẹ ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí ohun ìdènà síwájú arákùnrin yín.+ 14 Mo mọ̀, ó sì dá mi lójú nínú Jésù Olúwa pé kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ aláìmọ́ fúnra rẹ̀;+ àmọ́ tí ẹnì kan bá ka ohun kan sí aláìmọ́, ó máa jẹ́ aláìmọ́ lójú rẹ̀. 15 Nítorí bí o bá ṣẹ arákùnrin rẹ torí oúnjẹ, o ò rìn lọ́nà tó bá ìfẹ́ mu mọ́.+ Má fi oúnjẹ rẹ pa ẹni tí Kristi kú fún run.*+ 16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tí ẹ̀ ń ṣe pé ibi ni. 17 Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú jíjẹ àti mímu,+ àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú òdodo àti àlàáfíà àti ayọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. 18 Nítorí ẹni tó bá ń ṣẹrú fún Kristi lọ́nà yìí ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn.
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà+ àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.+ 20 Ẹ má ṣe máa ya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ nítorí oúnjẹ.+ Lóòótọ́, ohun gbogbo ni ó mọ́, àmọ́ nǹkan burúkú ni* fún ẹni tó ń jẹ oúnjẹ tó máa fa ìkọ̀sẹ̀.+ 21 Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.+ 22 Ìgbàgbọ́ tí o ní, jẹ́ kó wà láàárín ìwọ àti Ọlọ́run. Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í dá ara rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ohun tó tẹ́wọ́ gbà. 23 Àmọ́ tó bá ń ṣiyèméjì, a ti dá a lẹ́bi tó bá jẹ ẹ́, nítorí kò jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, gbogbo ohun tí kò bá ti bá ìgbàgbọ́ mu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.