Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Kọ́ Agbára Ìwòye Yín!
“Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—HÉBÉRÙ 5:14.
1, 2. (a) Báwo ni ipò wa lóde òní ṣe bá ti àwọn Kristẹni ìjímìjí tó wà ní Éfésù mu? (b) Àwọn ẹ̀bùn wo ló lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ ewu, báwo lo sì ṣe lè mú wọn dàgbà?
“ẸMÁA ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) Láti ẹgbàá ọdún sẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ‘àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ti tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’ A ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ mìíràn ṣe gbé e kalẹ̀, àkókò “eléwu.”—2 Tímótì 3:1-5, 13; Phillips.
2 Ṣùgbọ́n, o lè yẹra fún ewu tó lè wà níwájú rẹ, nípa mímú “ìfọgbọ́nhùwà, . . . ìmọ̀ àti agbára láti ronú” dàgbà. (Òwe 1:4) Òwe 2:10-12 sọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà.” Àmọ́, báwo gan-an lo ṣe lè mú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn dàgbà? Hébérù 5:14 sọ pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí pẹ̀lú òye èyíkéyìí, dídi ẹni tó mọ agbára ìwòye ẹni lò dáadáa ń béèrè ẹ̀kọ́ tó péye. Ní ṣáńgílítí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí ‘dídi ẹni táa ti dá lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bi eléré ìdárayá.’ Báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í gba irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀?
Kọ́ Agbára Ìwòye Rẹ
3. Báwo lo ṣe lè lo agbára ìwòye rẹ nígbà tọ́ràn bá di pé kí o ṣèpinnu?
3 Ṣàkíyèsí pé a ń kọ́ agbára ìwòye rẹ—agbára tóo ní láti mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́—‘nípasẹ̀ lílò ó.’ Nígbà tó bá yẹ kóo ṣèpinnu, míméfò, ṣíṣe ohunkóhun tó bá wá sí ọ lọ́kàn, tàbí wíwulẹ̀ tẹ̀ síbi tí ayé tẹ̀ sí, kò ní yọrí sí híhùwà ọlọgbọ́n rárá. Láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, o gbọ́dọ̀ lo agbára ìwòye rẹ. Lọ́nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wàá kọ́kọ́ yẹ ipò náà wò fínnífínní, wàá sì rí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Béèrè ìbéèrè bó bá pọndandan. Mọ àwọn ohun tóo lè ṣe. Òwe 13:16 sọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà.” Lẹ́yìn ìyẹn, gbìyànjú láti pinnu òfin tàbí ìlànà Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú kókó náà. (Òwe 3:5) Àmọ́ ṣá o, láti ṣe èyí, o gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi rọ̀ wá láti jẹ “oúnjẹ líle”—láti mọ “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́.—Éfésù 3:18.
4. Èé ṣe tí ìmọ̀ nípa ìlànà Ọlọ́run fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì?
4 Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, nítorí tí a jẹ́ aláìpé, tí ó lè dẹ́ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 5:12) Jeremáyà 17:9 sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” Tí kò bá sí ìlànà Ọlọ́run láti tọ́ wa sọ́nà, a lè máa tanra wa jẹ́ nípa ríronú pé ohun kan tó burú kò fi bẹ́ẹ̀ burú—kìkì nítorí pé ẹran ara wa ń fẹ́ ẹ. (Fi wé Aísáyà 5:20.) Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ. Nítorí àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ, mo ń fi òye hùwà. Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà èké.”—Sáàmù 119:9, 104.
5. (a) Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi ń tọ ọ̀nà tí kò tọ́? (b) Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe sọ òtítọ́ di tirẹ̀?
5 Èé ṣe tí àwọn ọ̀dọ́ kan tí a tọ́ dàgbà ní agboolé Kristẹni fi tẹ̀ lé ipa ọ̀nà àìtọ́? Ṣé pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò fìgbà kankan ‘ṣàwárí fúnra wọn ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” ni? (Róòmù 12:2) Àwọn kan ti lè máa bá àwọn òbí wọn wá sípàdé, kí wọ́n sì mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì díẹ̀ sórí. Ṣùgbọ́n, táa bá wá sọ pé kí wọ́n fi ẹ̀rí ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lẹ́yìn tàbí kí wọ́n ṣàlàyé àwọn ìjìnlẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń tini lójú pé ìmọ̀ wọn ò jinlẹ̀ tó. Ó rọrùn púpọ̀ láti tètè ṣi irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́nà. (Éfésù 4:14) Bó bá jẹ́ bí ọ̀ràn rẹ ṣe rí nìyí, èé ṣe tí o kò fi pinnu láti yí padà? Arábìnrin ọ̀dọ́ kan rántí pé: “Mo máa ń ṣèwádìí àwọn kókó kan. Mo máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé, ‘Báwo ló ṣe dá mi lójú pé ẹ̀sìn tòótọ́ nìyí? Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kan ń bẹ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà?’”a Fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ fínnífínní ló jẹ́ kó gbà gbọ́ pé gbogbo ohun tí àwọn òbí òun fi kọ́ òun ló jẹ́ òótọ́!—Fi wé Ìṣe 17:11.
6. Báwo ni o ṣe lè “wádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún [Jèhófà] Olúwa dájú”?
6 Tóo bá ti ní ìmọ̀ nípa àwọn ìlànà Jèhófà dáadáa, yóò lè rọrùn fún ọ láti “wádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” (Éfésù 5:10) Ṣùgbọ́n, bí o kò bá mọ ìwà tó bọ́gbọ́n mu tó yẹ kóo hù nínú ipò kan pàtó ńkọ́? Gbàdúrà sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. (Sáàmù 119:144) Gbìyànjú láti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ tàbí Kristẹni kan tó dàgbà dénú. (Òwe 15:22; 27:17) O tún lè rí àwọn ìtọ́sọ́nà tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́, bóo bá lè ṣèwádìí nínú Bíbélì àti inú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. (Òwe 2:3-5) Bóo ba ṣe ń lo agbára ìwòye rẹ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe di èyí tó múná tó.
Lílo Ìfòyemọ̀ Bó Bá Dọ̀ràn Eré Ìnàjú
7, 8. (a) Báwo lo ṣe lè lo agbára ìwòye rẹ láti pinnu bóyá ó yẹ kóo lọ sí àpèjẹ kan tàbí kò yẹ? (b) Kí ni ojú ìwòye Bíbélì nípa eré ìnàjú?
7 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká wá wo bóo ṣe lè lo agbára ìwòye rẹ nínú àwọn ipò kan pàtó. Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé a pè ọ́ sí àpèjẹ kan. Ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé o ti ri ìwé gbà tí wọ́n fi kéde àpèjẹ náà. O gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ táwọn náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n wàá dá lára owó tí wọ́n máa ná sórí àpèjẹ náà o. Ṣó yẹ kóo lọ?
8 Tóò, lo agbára ìwòye rẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ibẹ̀. Báwo ni àpèjẹ yìí yóò ti rí? Àwọn wo ló máa wà ńbẹ̀? Ìgbà wo ló máa bẹ̀rẹ̀? Ìgbà wo ló máa parí? Kí làwọn nǹkan tó máa wáyé níbẹ̀? Báwo ni wọn yóò ṣe darí rẹ̀? Lẹ́yìn èyí, wá ṣèwádìí, nípa yíyẹ “Àpèjẹ Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà,” àti “Eré Ìnàjú” wò nínú ìwé Watch Tower Publications Index.b Kí ni ìwádìí rẹ lè fi hàn? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, yóò fi hàn pé Jèhófà kò fojú búburú wo pípéjọ láti ṣe fàájì. Oníwàásù 8:15 ṣáà sọ pé, “aráyé kò ní nǹkan kan tí ó sàn lábẹ́ oòrùn ju pé kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n sì máa mu, kí wọ́n sì máa yọ̀,” lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ti ṣe. Ṣe bí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ lọ síbi àwọn àkànṣe àpèjẹ, ó kéré tán, ó bá wọn lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan. (Lúùkù 5:27-29; Jòhánù 2:1-10) Tí a kò bá ṣàṣejù, afẹ́ ṣíṣe lè ṣeni láǹfààní.
9, 10. (a) Ewu wo ni àpèjẹ lè mú wá? (b) Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara rẹ kóo tó pinnu bóyá wàá lọ sí àpèjẹ kan tàbí oò ní lọ?
9 Àmọ́ ṣáá o, àwọn àpèjẹ tí gbogbo nǹkan ti rí wúruwùru lè dá wàhálà sílẹ̀. Nínú 1 Kọ́ríńtì 10:7, 8, a kà nípa bí kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ ṣe yọrí sí àgbèrè, tó sì yọrí sí ikú fún “ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́] ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” A tún rí ìkìlọ̀ mìíràn tó múni ronú jinlẹ̀ nínú Róòmù 13:13 pé: “Gẹ́gẹ́ bí ní ìgbà ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá, kì í ṣe nínú ìbádàpọ̀ tí ó tàpá sófin àti ìwà àìníjàánu, kì í ṣe nínú gbọ́nmi-si omi-ò-to àti owú.” (Fi wé 1 Pétérù 4:3.) Lóòótọ́, a kò lè sọ pé iye èèyàn báyìí ló gbọ́dọ̀ wà ní àpèjẹ kan. Ṣùgbọ́n ìrírí fi hàn pé bí èrò bá ṣe pọ̀ tó níbi àpèjẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe ṣòro tó láti darí rẹ̀. Àwọn àpèjẹ tí èrò ò pọ̀ jù, táa sì ṣètò dáadáa, kì í sábà di “àríyá oníwà ẹhànnà.”—Gálátíà 5:21, Byington.
10 Kò sí àní-àní pé ìwádìí rẹ yóò tún ru ìbéèrè mìíràn sókè, irú bíi: Ǹjẹ́ àwọn àgbà Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú yóò wà ní àpèjẹ náà? Àní, ta ló tiẹ̀ ń ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ gan-an? Ṣé ète àpèjẹ náà ni láti gbé ìfararora gbígbámúṣé lárugẹ tàbí láti pawó sápò ẹnì kan? Ǹjẹ́ àwọn kan wà tí a kò yọ̀ǹda fún láti wá síbẹ̀? Bó bá jẹ́ òpin ọ̀sẹ̀ ni àpèjẹ náà, ǹjẹ́ wọ́n á parí ẹ̀ lásìkò, kí àwọn tó bá wá, lè jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́jọ́ kejì? Bí orin bá máa wà níbẹ̀, táwọn èèyàn á sì jó, ǹjẹ́ ìwọ̀nyí máa bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Kristẹni mu? (2 Kọ́ríńtì 6:3) Bíbéèrè irú ìbéèrè báwọ̀nyí lè má rọrùn. Ṣùgbọ́n Òwe 22:3 kìlọ̀ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, bóo bá lo agbára ìwòye rẹ, o lè yẹra fún àwọn ipò eléwu.
Lo Ìfòyemọ̀ Láti Wéwèé Ètò Ẹ̀kọ́ Rẹ
11. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo agbára ìwòye wọn láti ṣètò ọjọ́ ọ̀la wọn?
11 Bíbélì sọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la. (Òwe 21:5) Ṣé ìwọ àti àwọn òbí rẹ̀ ti fikùn lukùn nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ? Bóyá o fẹ́ wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Ká sòótọ́, kò síṣẹ́ mìíràn tóo lè yàn, tó lè fún ọ ní ìtẹ́lọ́rùn ju ìyẹn lọ. Bóo bá ń mú àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ tó mọ́yán lórí àti òye dàgbà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, o ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ aláyọ̀ yẹn nìyẹn. Ǹjẹ́ o ti ronú lórí bóo ṣe lè gbọ́ bùkátà ara rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Lẹ́yìnwá ọ̀la, bóo bá pinnu pé o fẹ́ ní ìdílé, ǹjẹ́ wàá lè bójú tó àfikún ẹrù iṣẹ́ yẹn? Ṣíṣe ìpinnu gúnmọ́, tó sì jẹ́ èyí tó fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń béèrè pé kí o lo agbára ìwòye rẹ.
12. (a) Báwo ni àwọn ìdílé kan ti ṣe mú ara wọn bá ipò ọrọ̀ ajé tí kò dúró sójú kan mu? (b) Ǹjẹ́ kíkàwé sí i dí fífi aṣáájú ọ̀nà ṣe góńgó lọ́wọ́? Ṣàlàyé.
12 Ní àwọn ibì kan, ó ṣì ṣeé ṣe láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ níbi tí a ti ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Àwọn ọ̀dọ́ kan wà tí wọ́n kọ́ iṣẹ́ tí baba tàbí ìyá wọ́n ń ṣe, àwọn mìíràn sì kọ́ṣẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wọn kan tó dàgbà jù wọ́n lọ, tó sì ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn mìíràn kọ́ àwọn iṣẹ́ kan nílé ẹ̀kọ́ tí yóò wúlò fún wọn láti fi gbọ́ bùkátà ara wọn lẹ́yìnwá ọ̀la. Níbi tí irú èyí ò bá ti sí, lẹ́yìn ríronú jinlẹ̀, àwọn òbí lè ṣètò pé kí àwọn ọmọ wọn kàwé sí i lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìwé mẹ́wàá. Ṣíṣètò fún ọjọ́ ọ̀la lọ́nà yìí láti lè bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ tí yóò dé téèyàn bá dàgbà tán, pàápàá jù lọ láti lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà fún ìgbà pípẹ́, kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà fífi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́. (Mátíù 6:33) Kíkàwé sí i kò sì ní kéèyàn má ṣe aṣáájú ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, ó ti pẹ́ ti ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà. Lẹ́yìn tí ọmọbìnrin yìí parí ìwé mẹ́wàá, àwọn òbí rẹ̀—táwọn fúnra wọn jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé—ṣètò pé kó lọ kàwé sí i. Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣe aṣáájú ọ̀nà nígbà tó ń kàwé rẹ̀, ní báyìí, bó ti ń bá aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ní iṣẹ́ lọ́wọ́ tó fi lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀.
13. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn ìdílé ronú lórí kíkàwé sí i?
13 Tọ́ràn bá di ti kíkàwé sí i, ìdílé kọ̀ọ̀kan ló láṣẹ láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́, àwọn ni yóò sì dáhùn fún un. Nígbà táa bá fara balẹ̀ yan irú ètò ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an. Ṣùgbọ́n o, ó tún lè jẹ́ ẹ̀bìtì. Bóo bá ń wéwèé àtikàwé sí i, kí ni góńgó rẹ? Ṣóo fẹ́ múra ara rẹ sílẹ̀ lọ́nà tó lọ́lá, kí o bàa lè bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ tí yóò dé tóo bá dàgbà tán ni? Àbí ṣe lò ń “wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ”? (Jeremáyà 45:5; 2 Tẹsalóníkà 3:10; 1 Tímótì 5:8; 6:9) Lílọ kàwé sí i níbi tó jìnnà sílé ńkọ́, bóyá gbígbé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn yóò jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu táa bá fi wọ́n wé ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù nígbà tó sọ pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́”? (1 Kọ́ríńtì 15:33; 2 Tímótì 2:22) Pẹ̀lúpẹ̀lù, rántí pé, “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́ríńtì 7:29) Báwo ni àkókò tóo fẹ́ lò fún irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ti pọ̀ tó? Ǹjẹ́ kò ní gba ọdún tó pọ̀ jù lọ nínú ọdún ìgbà ọ̀dọ́ rẹ? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni wàá ṣe fi ìṣírí Bíbélì yìí sílò, èyí tó wí pé “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin”? (Oníwàásù 12:1) Ní àfikún sí i, ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tóo yàn láti ṣe yóò fàyè sílẹ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni pàtàkì bí lílọ sí ìpàdé, iṣẹ́ ìsìn pápá, àti dídákẹ́kọ̀ọ́? (Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25) Bí agbára ìwòye rẹ bá múná, o kò ní fojú kéré àwọn góńgó tẹ̀mí àti ètò tí àwọn òbí rẹ ní fún ọ nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ.
Mímú Kí Ìfẹ́sọ́nà Níyì
14. (a) Ìlànà wo ló yẹ kó darí àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà bí wọ́n ti ń fi ìfẹ́ hàn síra wọn? (b) Báwo làwọn kan tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà ti ṣe fi àìlóye hàn nínú ọ̀ràn yìí?
14 Àgbègbè mìíràn tí ó tún ti nílò agbára ìwòye rẹ ni ìfẹ́sọ́nà. Ó jẹ́ àdámọ́ ẹ̀dá pé ká fi ìfẹ́ hàn sí ẹnì kan táa bìkítà fún. Ó hàn gbangba pé àwọn àfẹ́sọ́nà méjì oníwà mímọ́ táa sọ̀rọ̀ wọn nínú Orin Sólómọ́nì fi ìfẹ́ díẹ̀ hàn sí ara wọn kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. (Orin Sólómọ́nì 1:2; 2:6; 8:5) Lóde òní, àwọn àfẹ́sọ́nà kan lè rò pé dídi ara wọn lọ́wọ́ mú, fífẹnu kora wọn lẹ́nu, àti dídì mọ́ra wọn, pàápàá jù lọ nígbà tí ìgbéyàwó bá kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ jẹ́ ohun tó yẹ. Ṣùgbọ́n rántí pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” (Òwe 28:26) Ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà ni kò lo ìfòyemọ̀ nípa pé wọ́n fira wọn sí ipò tó dán wọn wò láti ré ìlànà Kristẹni kọjá. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń fi ìfẹ́ hàn síra wọn wá gbóná tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè ṣàkóso rẹ̀ mọ́; ó yọrí sí ìwà àìmọ́, tó sì wá jálẹ̀ sí àgbèrè pàápàá.
15, 16. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló yẹ káwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà gbé kí ìfẹ́sọ́nà wọn lè níyì?
15 Bóo bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, ó dáa tóo bá lè yẹra fún dídá wà pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà rẹ ní àwọn ipò tí kò yẹ. Nítorí náà, ó dáa jù, tí ẹ̀yin méjèèjì bá wà láàárín àwọn ẹlòmíràn tàbí ibi tí ojú ti lè tóo yín. Àwọn àfẹ́sọ́nà kan tilẹ̀ máa ń ṣètò ẹnì kan tí yóò wà pẹ̀lú wọn. Bákan náà, ronú nípa ọ̀rọ̀ Hóséà 4:11 pé: “Wáìnì àti wáìnì dídùn ni ohun tí ń gba ète rere kúrò.” Ọtí lè rani níyè, ó sì lè mú kí àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà hùwà tí yóò mú kí wọ́n jẹ̀ka àbámọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
16 Òwe 13:10 sọ pé: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ‘ẹ fikùn lukùn,’ kí ẹ sì jọ jíròrò bí ẹ óò ṣe máa ṣe. Níwọ̀n-níwọ̀n ni kí ẹ máa fi ìfẹ́ hàn síra yín, kí olúkúlùkù máa bọ̀wọ̀ fún ìmọ̀lára àti ẹ̀rí-ọkàn ẹnì kejì. (1 Kọ́ríńtì 13:5; 1 Tẹsalóníkà 4:3-7; 1 Pétérù 3:16) Sísọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ yìí lè ṣòro lákọ̀ọ́kọ́ o, ṣùgbọ́n ó lè dènà àwọn ìṣòro ńlá tó lè dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Kíkọ́ni ‘Láti Ìgbà Èwe’
17. Báwo ni Dáfídì ṣe fi Jèhófà ṣe ‘ìgbọ́kànlé rẹ̀ láti ìgbà èwe,’ ẹ̀kọ́ wo làwọn èwe ìwòyí rí kọ́ níbẹ̀?
17 Yíyẹra fún ìdẹkùn Sátánì yóò béèrè pé kóo máa kíyè sára nígbà gbogbo—nígbà mìíràn, yóò béèrè pé kóo jẹ́ onígboyà. Họ́wù, nígbà mìíràn pàápàá o lè rí i pé kì í ṣe ohun tí àwọn ojúgbà rẹ ń ṣe nìkan ni o kò fara mọ́, àní o lè má fara mọ́ ohun tí ayé lápapọ̀ ń ṣe. Dáfídì, onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá. Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sáàmù 71:5, 17)c Kò sẹ́ni tí kò mọ Dáfídì pé ó jẹ́ onígboyà. Ṣùgbọ́n ìgbà wo ló mú ìwà náà dàgbà? Nígbà tó wà léwe ni! Kódà kó tó di pé Dáfídì lọ kojú Góláyátì nínú ìjà wọn tí òkìkí rẹ̀ kàn káyé, ó ti fi ìgboyà àrà ọ̀tọ̀ hàn nínú dídáàbò bo agbo ẹran baba rẹ̀—nípa pípa kìnnìún kan àti béárì kan. (1 Sámúẹ́lì 17:34-37) Ṣùgbọ́n, gbogbo ìgboyà tí Dáfídì fi hàn, Jèhófà ló fi ògo rẹ̀ fún, ó pè é ní “ìgbọ́kànlé [òun] láti ìgbà èwe [òun] wá.” Agbára tí Dáfídì ní láti gbára lé Jèhófà ló jẹ́ kí ó lè kojú àdánwò èyíkéyìí tó dé bá a. Ìwọ pẹ̀lú lè rí i pé bóo bá gbára lé Jèhófà, òun yóò fún ọ ní ìgboyà àti okun tí o nílò láti “ṣẹ́gun ayé.”—1 Jòhánù 5:4.
18. Ọ̀rọ̀ ìṣítí wo la fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run lónìí?
18 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ ti dúró gẹ́gẹ́ bí onígboyà, wọ́n sì ń sìn bí akéde ìhìn rere náà tó ti ṣe batisí báyìí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó fún irú ẹ̀yin èwe wọ̀nyí! Ẹ má ṣe yẹsẹ̀ lórí ìpinnu yín pé ẹ óò bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé yìí. (2 Pétérù 1:4) Ẹ máa bá a nìṣó láti máa lo agbára ìwòye yín táa ti fi Bíbélì kọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò dáàbò bò yín lọ́wọ́ àjálù nísinsìnyí, lékè gbogbo rẹ̀, yóò jẹ́ kí ìgbàlà yín dájú. Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ wa tó kẹ́yìn yóò ti fi hàn, ẹ ó kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé yín.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Òtítọ́ Di Tèmi?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! October 22, 1998.
b Àpilẹ̀kọ náà, “Eré-Ìnàjú Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà—Gbádùn Àwọn Àǹfààní Rẹ̀, Yẹra fún Àwọn Ìdẹkùn Rẹ̀,” èyí tó fara hàn nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1992 ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni lórí kókó yìí.
c Ó jọ pé Sáàmù ìkọkànléláàádọ́rin jẹ́ apá kan Sáàmù àádọ́rin, èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní sáàmù ti Dáfídì.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè kọ́ agbára ìwòye rẹ̀?
◻ Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè lo agbára ìwòye rẹ̀ nígbà tó bá kan lílọ sí àwọn àpèjẹ Kristẹni?
◻ Àwọn kókó wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò bí a bá ń ṣètò ẹ̀kọ́ ẹni?
◻ Báwo ni àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà ṣe lè yẹra fún ìdẹkùn ìṣekúṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kíkọ́ báa ṣe ń ṣèwádìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ agbára ìwòye rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó máa ń rọrùn láti darí àpèjẹ tí kò lérò púpọ̀, kì í sì í tètè di àríyá aláriwo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn òbí ní láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣètò fún ẹ̀kọ́ wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jíjáde pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà ẹni láwùjọ àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ààbò