Mú Agbára Ìmòye Rẹ Dàgbà
1 Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn oníwàhálà tá a bá ara wa nínú rẹ̀ báyìí ti kó pákáǹleke àti onírúurú àdánwò púpọ̀ sí i bá àwọn èèyàn Ọlọ́run níbi gbogbo. (2 Tím. 3:1-5) Gbogbo wa ló nílò ìṣírí láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (1 Kọ́r. 16:13) Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí a ti ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé, tí a ń gbára lé ẹ̀mí rẹ̀, tí a kò sì jẹ́ kí ètò àjọ rẹ̀ yà wá sílẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan.—Sm. 37:28; Róòmù 8:38, 39; Ìṣí. 2:10.
2 Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé, ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Dàgbà Di Géńdé Nínú Agbára Òye” la sọ̀rọ̀ lé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tó kọjá. A gbé e karí 1 Kọ́ríńtì 14:20 níbi tí a ti ka ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe di ọmọ kéékèèké nínú agbára òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú; síbẹ̀, ẹ dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” Kí lèrò rẹ nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn?
3 “Ó mà fúnni níṣìírí o!” “Ohun tá a ń fẹ́ gan-an nìyí!” Méjì péré nìyẹn lára ohun táwọn ará sọ. Àní ẹni kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, tó wá sí àpéjọ àkànṣe ọ̀hún láti wo ìrìbọmi ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá sọ pé, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀hún wú òun lórí àti pé òun rí i pé yóò ṣe ìdílé òun láǹfààní. Ṣé bó ṣe rí lára ìwọ pẹ̀lú nìyẹn? Ẹ jẹ́ ka rántí díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
4 Ìmọ̀ Pípéye Pọn Dandan Láti Mú Agbára Ìmòye Ẹni Dàgbà: Nínú ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Mú Agbára Òye Rẹ Dàgbà Nísinsìnyí,” kí ni olùbánisọ̀rọ̀ tẹnu mọ́ pé a nílò láti kojú àwọn ìpèníjà òde òní? Ohun tí a nílò ju níní agbára èrò orí nìkan. A gbọ́dọ̀ mú kí agbára òye Bíbélì tí a ní pọ̀ sí i kí ó sì jinlẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ìwà búburú tó yí wa ká yóò borí wa. Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ló sì lè mú ká ní irú òye bẹ́ẹ̀. Bíi ti onísáàmù náà, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí a lóye àwọn òfin àti ìránnilétí rẹ̀ kí a lè máa fi gbogbo ọkàn wa sìn ín.—Sm. 119:1, 2, 34.
5 Nínú apá tó tẹ̀ lé e, alábòójútó àyíká fi hàn pé Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ fún wa ní “Àwọn Ìrànwọ́ fún Dídi Géńdé Nínú Òye Bíbélì.” Wọ́n túmọ̀ òye pé ó jẹ́ “agbára àtiyẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn wò, kí a sì fòye mọ bó ṣe rí nípa wíwo gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọn, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ lóye rẹ̀.” Ta ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní irú agbára yìí? Jèhófà ti pèsè àwọn ẹ̀bùn tó jẹ́ ènìyàn láti ràn wá lọ́wọ́ kí á lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:11, 12) Ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ń rọ̀ wá pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ká sì máa lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ déédéé. (Sm. 1:2) A kọ́ wa bí a ṣe lè lo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni wa nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti bí a tún ṣe lè lò ó nínú mímúra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìsìn pápá. Ǹjẹ́ o ń tẹ̀ lé gbogbo àwọn ètò wọ̀nyí dáadáa? Ǹjẹ́ o ń tẹ̀ lé ètò tó ṣe déédéé fún dídá ka Bíbélì? Ìyẹn pọn dandan bí a óò bá di ẹni tí a pa mọ́ kí a má bàa di ẹni tó ń tẹ̀ lé ìṣe, àṣà, ọgbọ́n èrò orí, àti ìdarí atannijẹ ti ayé.—Kól. 2:6-8.
6 A Gbọ́dọ̀ Kọ́ Agbára Ìmòye Wa: Nínú ọ̀rọ̀ tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá kọ́kọ́ sọ, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Dáàbò Bo Ipò Tẹ̀mí Rẹ Nípa Kíkọ́ Agbára Ìmòye Rẹ,” ó ṣàlàyé pé ayé yìí kò lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Aísá. 5:20, 21) Ohun tó fà á ni pé wọ́n kọ̀ láti gba àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e. Ní ìyàtọ̀ gédégbé, àwa tí a ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí nínú ètò àjọ Jèhófà mọ ìlànà Ọlọ́run, èyí tó ń tọ́ wa sọ́nà nínú àwọn ìgbòkègbodò wa àti ìwà wa. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ohun tó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà àti àwọn ohun tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ pípé.—Róòmù 12:2.
7 Láti yẹra fún ìrònú ayé yìí tó ti pòrúurùu àti àbájáde búburú tó ń mú wá, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kọ́ agbára ìmòye wa. Báwo la ó ṣe ṣe ìyẹn? Nínú ìwé Hébérù 5:12-14, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti má ṣe fi kìkì “wàrà” ọ̀rọ̀ náà bọ́ ara wa. A nílò oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí, irú èyí tí a ń rí gbà bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Lẹ́yìn náà, a gbọ́dọ̀ fi àwọn ohun tí a ń kọ́ sílò dáadáa ní ìgbésí ayé wa. Nígbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ó dá wa lójú pé àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà tọ̀nà. Ìyẹn ló máa ń kọ́ agbára ìmòye wa láti fi ìyàtọ̀ kedere sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.
8 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ti ṣubú nípa tẹ̀mí. Kí ló fà á? Wọn kò pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó dára tí ó sì tọ́ ní ojú Jèhófà. Nítorí ìyẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ orí tẹlifíṣọ̀n tàbí ọ̀rọ̀ orí rédíò tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ lòdì sí Ìwé Mímọ́, wọ́n ń gbọ́ orin oníwà ìbàjẹ́ wọ́n sì tún ń kẹ́gbẹ́ búburú níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí kọ̀ǹpútà. Nípa híhùwà ọgbọ́n, a ó yẹra fún àwọn èèyàn oníwà pálapàla, àwọn òmùgọ̀ tàbí àwọn ẹni burúkú.—Òwe 13:20; Gál. 5:7; 1 Tím. 6:20, 21.
9 Àwọn Ọ̀dọ́ Gbọ́dọ̀ “Jẹ́ Ìkókó Ní Ti Ìwà Búburú”: Apá méjì ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pín sí tó fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí ní pàtó pé kí wọ́n mú agbára ìmòye wọn dàgbà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi hàn pé jíjẹ́ “ìkókó ní ti ìwà búburú” túmọ̀ sí wíwà láìní ìrírí, ìyẹn ni pé, kí a jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ bíi ti ìkókó, tó bá di ti àwọn ohun tí kò mọ́ ní ojú Jèhófà. (1 Kọ́r. 14:20) A fún gbogbo wa níṣìírí pé ká máa ṣọ́ra lójú méjèèjì nípa bí a ṣe ń lo àkókò wa, ká lè dènà dídi ẹni tó ń rí onírúurú ohun búburú gbogbo ká má sì jẹ́ kí wọ́n kó bá wa. (Éfé. 5:15-17) A fún wa níṣìírí pé ká ṣírò iye àkókò tí a fi ń ka àwọn ìwé tí kò lè mú kí òye tá a ní nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ o ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìṣirò tí o ṣe fi hàn? Láfikún sí kíka Bíbélì lójoojúmọ́, pinnu láti máa ka àwọn ìwé tí ètò àjọ náà ń pèsè. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ran gbogbo wa àtàwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti “ní òye.”—Òwe 4:7-9.
10 “Jàǹfààní Nínú Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Tòyetòye”: Ìyẹn ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé tó kẹ́yìn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe ọ̀hún. Olùbánisọ̀rọ̀ tá a gbà lálejò ṣàlàyé pé Jèhófà ni Orísun òye tó ń fúnni ní ìyè tí ó sì níye lórí gidigidi ju ti ènìyàn lọ. Ìwọ sáà fojú inú wo àǹfààní rírí gbà lára òye Jèhófà! Lọ́pọ̀ yanturu ló ń fi í fún àwọn tó bá fi tọkàntọkàn wá a, tí wọ́n sì fi ìgbàgbọ́ béèrè fún un. (Òwe 2:3-5, 9; 28:5) Ǹjẹ́ o ń lo àǹfààní ohun tó ń nawọ́ rẹ̀ sí ọ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
11 A fún wa níṣìírí pé ká kọ́ bí a ṣe lè máa dá àwọn ìlànà mọ̀ bí a ti ń ka Bíbélì. (2 Tím. 3:16, 17) Fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn kí o lè ní òye pípé nípa ohun tí Jèhófà ń sọ. Wá àyè láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìlànà wọ̀nyí kí o sì fi wọ́n sí inú àti ọkàn rẹ. Ìyẹn yóò kọ́ agbára ìmòye rẹ kí o lè ṣàṣeyọrí nígbà tí o bá ń ṣe àwọn ìpinnu ní ìgbésí ayé. (Jóṣ. 1:8) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ipò kan tí ọ̀pọ̀ dojú kọ àti bí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.
12 ‘Ǹjẹ́ ó yẹ kí n tẹ̀ lé irú àṣà ìwọṣọ àti ìmúra kan báyìí?’ Ọ̀nà ìgbàlódé tí ayé ń gbà múra tí wọ́n sì ń gbà wọṣọ sábà máa ń fi ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ hàn. Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ló ń mú káwọn èèyàn máa múra wúruwùru lọ́nà tí kò fani mọ́ra tàbí lọ́nà tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè. Àwọn ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ọn wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dènà irú àṣà bẹ́ẹ̀? Bí a bá ti kọ́ agbára ìmòye wa, a óò ronú nípa ìlànà tó wà ní 1 Tímótì 2:9, 10, tó sọ pé ká fi ‘ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú wọṣọ, lọ́nà tí ó yẹ àwọn èèyàn tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.’ Àwọn ìlànà mìíràn tí ó tún ṣeé fi sílò wà ní 2 Kọ́ríńtì 6:3 àti Kólósè 3:18, 20.
13 ‘Kí ni mo lè ṣe láti mú kí ìdílé mi túbọ̀ wà ní ìrẹ́pọ̀?’ Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn tó wà nínú ìdílé máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀ dáadáa. Jákọ́bù 1:19 sọ fún wa pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” Ó yẹ kí àwọn tó wà nínú ìdílé máa fetí sílẹ̀ sí ara wọn kí wọ́n sì máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ nítorí pé bù fún mi kí n bù fún ọ lọ̀rọ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nínú ìdílé. Àní bó bá jẹ́ òótọ́ lohun tá a sọ, bí a bá fi ohùn líle sọ ọ́, tí a sọ ọ́ lọ́nà ìgbéraga tàbí lọ́nà tí kò fi ìgbatẹnirò hàn, ìpalára tá a ṣe yóò ju ìrànwọ́ tá a ṣe lọ. Nítorí náà, yálà a jẹ́ ọkọ tàbí aya, òbí tàbí ọmọ, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa “fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.”—Kól. 4:6.
14 ‘Ǹjẹ́ ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kì í dààmú mi báyìí?’ Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jẹ́ ara ohun tí ayé yìí máa ń tini sí tó sì ń mú kí ìgbésí ayé ẹni bà jẹ́. Kì í ṣe òun ló ń jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́. (Oníw. 5:10; Lúùkù 12:15; 1 Tím. 6:9, 10) Láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè yẹra fún ìdẹkùn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, Jésù kọ́ wa ní ìlànà pàtàkì yìí pé: Jẹ́ kí ojú rẹ mú ọ̀nà kan. Gbígbé ìgbé ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí kò lọ́jú pọ̀ kan pé ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ire Ìjọba náà, kí a sì fi gbogbo àwọn nǹkan yòókù sí ipò kejì.—Mát. 6:22, 23, 33.
15 Ohun Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ìpinnu Wa: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni orísun àwọn ìlànà òdodo tó ṣeé gbára lé, èyí tó lè tọ́ wa sọ́nà, nígbà tí a bá ń ṣe àwọn ìpinnu. Ó yẹ ká kọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, ká ṣàṣàrò nípa wọn, ká sì mọ bí a ṣe lè fi wọ́n sílò ní ìgbésí ayé wa. Bá a bá ń tipa bẹ́ẹ̀ ‘kọ́ agbára ìwòye wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́,’ a ó ṣe ara wa láǹfààní, a ó sì bọlá fún Jèhófà.—Héb. 5:14.