Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ni Atóbilọ́lá Olùkọ́ni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Kì í kàn ṣe pé ó ń kọ́ wọn nípa ara rẹ̀ nìkan, àní, ó tún ń kọ́ wọn nípa bí wọn ó ṣe máa gbé ìgbésí ayé. (Aísáyà 30:20; 54:13; Sáàmù 27:11) Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àwọn wòlíì, àwọn ọmọ Léfì—pàápàá àwọn àlùfáà—àti àwọn ọkùnrin ọlọgbọ́n mìíràn, kí wọ́n lè máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (2 Kíróníkà 35:3; Jeremáyà 18:18) Àwọn wòlíì wọ̀nyí kọ́ àwọn èèyàn ní ète Ọlọ́run àti ànímọ́ rẹ̀, wọ́n sì tún kọ́ wọn ní ọ̀nà tó dára láti tọ̀. Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ló lẹrù iṣẹ́ kíkọ́ni ní Òfin Jèhófà. Ní àfikún sí i, àwọn ọkùnrin ọlọgbọ́n, tàbí àwọn àgbààgbà wà tí ń gbani nímọ̀ràn tó yè kooro nípa ìgbésí ayé ojoojúmọ́.
Sólómónì, ọmọ Dáfídì, tayọ pátápátá nínú àwọn amòye Ísírẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 4:30, 31) Nígbà tí ayaba Ṣébà, ọkàn lára àwọn àlejò rẹ̀ pàtàkì, rí ògo àti ọlá rẹ̀, ó jẹ́wọ́ pé: “A kò sọ ìdajì wọn fún mi. Ìwọ ta yọ ní ọgbọ́n àti aásìkí ré kọjá àwọn ohun tí a gbọ́ èyí tí mo fetí sí.” (1 Àwọn Ọba 10:7) Kí ni àṣírí ọgbọ́n Sólómọ́nì? Nígbà tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì lọ́dún 1037 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó gbàdúrà fún “ọgbọ́n àti ìmọ̀.” Inú Jèhófà dùn sí nǹkan tó tọrọ, ló bá fi ìmọ̀, ọgbọ́n, àti ọkàn-àyà ìmòye jíǹkí rẹ̀. (2 Kíróníkà 1:10-12; 1 Àwọn Ọba 3:12) Abájọ́ tí Sólómọ́nì fi “pa ẹgbẹ̀ẹ́dógún òwe”! (1 Àwọn Ọba 4:32) Díẹ̀ lára ìwọ̀nyí, àti “àwọn ọ̀rọ̀ Ágúrì” àti ti “Lémúẹ́lì Ọba” wà nínú ìwé Òwe, nínú Bíbélì. (Òwe 30:1; 31:1) Àwọn òtítọ́ òwe wọ̀nyí fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn, wọ́n sì wúló títí lọ gbére. (1 Àwọn Ọba 10:23, 24) Lónìí, bíi ti ìgbà tí a kọ́kọ́ pa àwọn òwe wọ̀nyí, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀, tó sì fẹ́ ṣàṣeyọrí láyé, kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ rọ́ wọn sẹ́yìn.
Àṣeyọrí àti Ìgbésí Ayé Mímọ́—Báwo Ló Ṣe Lè Ṣeé Ṣe?
A ṣàlàyé ète táa fi kọ ìwé Òwe nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Òwe Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí, láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye, láti gba ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye, òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, láti fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà, láti fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.”—Òwe 1:1-4.
“Òwe Sólómọ́nì” yóò mà ṣiṣẹ́ fún ète tó ga o! Wọ́n wà “fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí.” Ọgbọ́n wé mọ́ lílóye nǹkan bí wọ́n ṣe rí gan-an àti lílo ìmọ̀ yẹn láti yanjú ìṣòro, láti lé góńgó bá, láti yẹra fún ewu tàbí láti fò ó dá, tàbí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Nínú ìwé Òwe, ‘ọgbọ́n’ dúró fún gbígbé ìgbésí ayé ọ̀jáfáfá—ìyẹn wé mọ́ níní agbára láti lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, kí a sì gbé ìgbésí ayé tó yọrí sí réré.” Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ọgbọ́n!—Òwe 4:7.
Òwe Sólómọ́nì tún báni wí. Ǹjẹ́ a nílò ìbáwí yìí? Nínú Ìwé Mímọ́, ìbáwí wé mọ́ sísọ ohun tó yẹ kí ẹnì kan ṣe fún un, títọ́ni sọ́nà, tàbí fífìyà jẹni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan ti sọ, ó “jẹ́ kíkọ́ni ní ìwà rere, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú yíyí ìrònú tó lè súnni hùwà òmùgọ̀ padà.” Ìbáwí, yálà èyí táa fúnra wa tàbí tí àwọn ẹlòmíràn fún wa, ń ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún ìwà àìtọ́, kì í ṣe ìyẹn nìkan, ó tún ń sún wa láti yí padà sí rere. Bẹ́ẹ̀ ni, a nílò ìbáwí báa bá fẹ́ máa bá ìwà mímọ́ wa nìṣó.
Nígbà náà, ète òwe wọ̀nyí pín sí apá méjì—láti gbin ọgbọ́n síni lọ́kàn àti láti báni wí. Ìwà rere àti agbára ìrònú pín sí onírúurú ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, òdodo àti ìdájọ́ òdodo jẹ́ ànímọ́ tó fi hàn pé ẹnì kan ní ìwà rere, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti Jèhófà.
Onírúurú ànímọ́ ló para pọ̀ jẹ́ ọgbọ́n, lára rẹ̀ ni òye, àròjinlẹ̀, lílo làákàyè, àti agbára láti ronú. Òye ni agbára àtiyẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn wò, kí a sì mọ bó ṣe rí nípa wíwo gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọn, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ lóye rẹ̀. Àròjinlẹ̀ ń béèrè pé ká ní agbára àtironú lórí nǹkan, ká sì mọ ìdí tí ọ̀nà kan fi tọ́ tàbí tó fi burú. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó lóye lè mọ ìgbà tí ẹnì kan bá ń forí lé ọ̀nà tí kò tọ́, ó sì lè tètè kìlọ̀ fún onítọ̀hún pé ewú wà níbẹ̀. Àmọ́, ó gbọ́dọ̀ ní àròjinlẹ̀ kó tó lè mọ ìdí tí onítọ̀hún fi forí lé ọ̀nà yẹn, kí ó sì wá ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tó fi lé gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Àwọn onílàákàyè máa ń fọgbọ́n hùwà—kò rọrùn láti tètè tàn wọ́n jẹ. (Òwe 14:15) Kí wàhálà tó dé, wọ́n á ti rí i, wọ́n á sì ti gbára dì. Ọgbọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìrònú tó gbámúṣé kalẹ̀, èyí tó lè fúnni ní ìdarí tó nítumọ̀ nínú ìgbésí ayé. Kíkọ́ nípa àwọn òwe inú Bíbélì ṣàǹfààní púpọ̀, nítorí pé, a kọ ọ́ sílẹ̀ kí a bàa lè mọ ọgbọ́n àti ìbáwí. Kódà “àwọn aláìní ìrírí” tó bá fiyè sí òwe wọ̀nyí yóò ní ọgbọ́n tí wọ́n lè fi hùwà, “ọ̀dọ́kùnrin” tó bá sì lò ó yóò ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.
Òwe Tó Wà fún Àwọn Ọlọ́gbọ́n
Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe àwọn tí kò tí ì nírìírí ayé àti àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni òwe inú Bíbélì wà fún. Ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́n ló yẹ kó tẹ́tí sí i. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá, láti lóye òwe àti ọ̀rọ̀ àdììtú, ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àlọ́ wọn.” (Òwe 1:5, 6) Ẹnì kan tó ti ní ọgbọ́n tẹ́lẹ̀ yóò fi kún ìmọ̀ rẹ̀ nípa fífiyèsí àwọn òwe wọ̀nyí, ẹni òye yóò sì túbọ̀ mú kí agbára òun jáfáfá sí i láti lè tukọ̀ ìgbésí ayé òun lọ́nà tí yóò yọrí sí rere.
Òwe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ ṣókí láti sọ òótọ́ pọ́ńbélé. Nígbà mìíràn a lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tó takókó láti gbé òwe Bíbélì kalẹ̀. (Òwe 1:17-19) Àwọn òwe kan wà tó jẹ́ àlọ́ àpamọ̀—àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tètè súni, tó sì lọ́jú, tó ń béèrè pé ká ṣàlàyé wọn. Òwe tún lè jẹ́ àfiwé lásán, àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́, àti àwọn àkànlò èdè mìíràn. Ó ń gba àkókò àti àṣàrò láti lè lóye ìwọ̀nyí. Kò sí àní-àní pé, Sólómọ́nì, ẹni tó kọ òwe rẹpẹtẹ, mọ̀ pé lílóye òwe, ń béèrè pé kéèyàn lè ṣe ọ̀rínkinniwín ọ̀rọ̀. Nínú ìwé Òwe, ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ gbíngbin agbára yẹn sínú àwọn òǹkàwé rẹ̀, ohun kan tí ọlọgbọ́n ènìyàn yóò fẹ́ láti fún ní àfiyèsí.
Ìbẹ̀rẹ̀ Tó Ń Sìnni Lọ sí Góńgó Náà
Níbo lẹ́nì kan ti lè bẹ̀rẹ̀ sí lépa ọgbọ́n àti ìbáwí? Sólómọ́nì dáhùn pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀. Ọgbọ́n àti ìbáwí ni àwọn òmùgọ̀ lásán-làsàn ti tẹ́ńbẹ́lú.” (Òwe 1:7) Ìmọ̀ ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá ní ìbẹ̀rù Jèhófà lọ́kàn. Tí ẹnì kan kò bá ní ìmọ̀, kò sí bó ṣe lè ní ọgbọ́n tàbí kó gba ìbáwí. Nítorí náà, ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n àti ìbáwí.—Òwe 9:10; 15:33.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kì í wá ṣe pé ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí fífún un ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀, ká sì máa wárìrì fún un. A kò lè ní ìmọ̀ tòótọ́, bí a kò bá ní irú ìbẹ̀rù yìí. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwàláàyè ti wá, ó sì dájú pé, ìwàláàyè ṣe pàtàkì báa bá fẹ́ ní ìmọ̀ èyíkéyìí. (Sáàmù 36:9; Ìṣe 17:25, 28) Síwájú sí i, Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan; nítorí náà gbogbo ìmọ̀ tí ẹ̀dá ní jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. (Sáàmù 19:1, 2; Ìṣípayá 4:11) Ọlọ́run tún mí sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, èyí tó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Nípa báyìí, Jèhófà ni igi lẹ́yìn ọgbà fún gbogbo ìmọ̀ tòótọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì ń wá ìmọ̀ yìí gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún un.
Kí làǹfààní ìmọ̀ orí ènìyàn àti ọgbọ́n ayé tí kò bá sì ìbẹ̀rù Ọlọ́run níbẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ibo ni ọlọ́gbọ́n ènìyàn náà wà? Ibo ni akọ̀wé òfin náà wà? Ibo ni olùjiyàn ọ̀rọ̀ ètò àwọn nǹkan yìí wà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀?” (1 Kọ́ríńtì 1:20) Nítorí tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ẹnì kan tó jẹ́ pé ọgbọ́n ayé ló wà lórí ẹ̀ kò jẹ́ rí òtítọ́ tó wà nínú àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ tí gbogbo èèyàn mọ̀, ṣe ni yóò máa fẹnu tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, yóò wá di ‘òmùgọ̀ lásán.’
“Ìlẹ̀kẹ̀ Ọrùn fún Ọrùn Rẹ”
Àwọn ọ̀dọ́ ni ọlọgbọ́n ọba náà tún bá sọ̀rọ̀, ó ní: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì. Nítorí ọ̀ṣọ́ òdòdó fífanimọ́ra ni wọ́n jẹ́ fún orí rẹ àti àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún ọrùn rẹ.”—Òwe 1:8, 9.
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn òbí ni Ọlọ́run fún lẹ́rù iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọ wọn. Mósè gba àwọn baba níyànjú pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Àwọn màmá pẹ̀lú ní ipa tiwọn. Lábẹ́ ọlá àṣẹ ọkọ, obìnrin Hébérù kan lè mú òfin ìdílé fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Lóòótọ́, jálẹ̀ inú Bíbélì, ìdílé jẹ́ ẹ̀ka pàtàkì táa ti ń fi ẹ̀kọ́ kọ́ni. (Éfésù 6:1-3) Bí àwọn ọmọ bá ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn onígbàgbọ́ ṣe ni yóò dà bíi pé a gbé òdodo tó fani mọ́ra kọ́ wọn lọ́rùn, tí a sì tún wá fi ìlẹ̀kẹ̀ ọlá sí i.
“Ó Máa Ń Gba Ọkàn Àwọn Tí Ó Ni Ín Pàápàá Lọ”
Kó tó di pé baba kan tó jẹ́ ará Éṣíà rán ọmọ rẹ̀ lọ́ sílé ẹ̀kọ́ gíga ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó rọ ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún pé, kó jọ̀wọ́ o, kó má báwọn èèyànkéèyàn rìn. Ìmọ̀ràn yìí jẹ́ àtúnsọ ìkìlọ̀ tí Sólómọ́nì fúnni pé: “Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá gbìyànjú láti sún ọ dẹ́ṣẹ̀, má gbà.” (Òwe 1:10) Ṣùgbọ́n, Sólómọ́nì ṣàlàyé ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tírú àwọn ẹni ibi bẹ́ẹ̀ máa ń ta, ó sọ pé: “Wọ́n . . . ń wí pé: ‘Bá wa lọ. Jẹ́ kí a ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀. Jẹ́ kí a ba sí ibi tí ó lùmọ́ de àwọn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ láìnídìí. Jẹ́ kí a gbé wọn mì láàyè bí Ṣìọ́ọ̀lù ti ń ṣe, àní lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò. Jẹ́ kí a wá onírúurú ohun iyebíye tí ó níye lórí kàn. Jẹ́ kí a fi ohun ìfiṣèjẹ kún ilé wa. Ó yẹ kí o da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ tiwa. Jẹ́ kí gbogbo wa jọ ní ẹyọ àpò kan ṣoṣo.’”—Òwe 1:11-14.
Ó ṣe kedere pé, ọrọ̀ ni ẹ̀tàn náà. Nítorí àtirí èrè ojú ẹsẹ̀, “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” máa ń tan àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n lè bá wọn lọ́wọ́ sí ìwà ipá tí wọ́n fẹ́ hù tàbí ètekéte tí wọ́n gùn lé. Bó bá dọ̀ràn àtijèrè nǹkan àlùmọ́nì, àwọn olubi wọ̀nyí ò kọ̀ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n ‘á gbé àwọn tó bá kó sí pańpẹ́ wọn mì láàyè bí Ṣìọ́ọ̀lù ti ń ṣe, àní lódindi,’ wọ́n a gba gbogbo ohun tí wọ́n ní pátá, bí ìgbà tí sàréè bá gba gbogbo ara. Ohun tí wọ́n ń peni sí kò ju ìwà ọ̀daràn lọ—wọ́n fẹ́ fi ‘ohun ìfiṣèjẹ kún ilé wọn,’ wọ́n sì fẹ́ kí ẹni tí kò nírìírí ‘da ìpín rẹ̀ pọ̀ mọ́ tiwọn.’ Ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò gan-an mà lèyí jẹ́ fún wa o! Ṣé kì í ṣe ọgbọ́n kan náà làwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ tó jẹ́ jàǹdùkú àtàwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró ń lò? Ṣe bí ìlérí pé a ó tètè dọlọ́rọ̀ ni ìdánwò tí ọ̀pọ̀ okòwò tó ń kọni lóminú ń gbé síwájú ẹni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ọlọgbọ́n ọba náà rọni pé: “Ọmọ mi, má ṣe bá wọn rìn pọ̀ ní ọ̀nà. Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò ní òpópónà wọn. Nítorí ẹsẹ̀ wọn jẹ́ èyí tí ń sáré sí kìkì ìwà búburú, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” Nígbà tó ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa jàǹbá tí yóò gbẹ̀yìn wọn, ó fi kún un pé: “Nítorí lásán ni a tẹ́ àwọ̀n sílẹ̀ lójú ohunkóhun tí ó ní ìyẹ́ apá. Nítorí náà, àwọn fúnra wọn ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ àwọn wọ̀nyí gan-an; wọ́n ba sí ibi tí ó lùmọ́ de ọkàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo ẹni tí ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu rí. Ó máa ń gba ọkàn àwọn tí ó ni ín pàápàá lọ.”—Òwe 1:15-19.
“Gbogbo ẹni tí ń jẹ èrè tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu” yóò ṣègbé nínú ìwà rẹ̀. Bíba tí àwọn ẹni ibi ń ba dé àwọn ẹlòmíràn yóò di ẹ̀bìtì fún àwọn alára. Ǹjẹ́ àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà burúkú yóò yí ọ̀nà wọn padà? Rárá o. Àwọ̀n kan lè wà gbangba gbàǹgbà níbi táa ta á sí, ṣùgbọ́n ẹyẹ—ìyẹn àwọn ẹ̀dá “tí ó ní ìyẹ́ apá”—lè mọ̀ọ́mọ̀ lọ ki ọrùn bọ̀ ọ́. Lọ́nà kan náà, àwọn ènìyàn búburú, tí ìwọra ti fọ́ lójú, kò jẹ́ dẹ̀yìn nínú ìwà ọ̀daràn, àmọ́ o, bó pẹ́ bó yá, ọwọ́ pálábá wọn yóò ségi.
Ta Ni Yóò Fetí Sí Ohùn Ọgbọ́n?
Ǹjẹ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ lóòótọ́ pé jàǹbá ni ipa ọ̀nà wọn yóò yọrí sí? Ǹjẹ́ a tiẹ̀ ti kìlọ̀ fún wọn nípa ibi tí ọ̀nà yìí forí lé? Kò sí àwíjàre kankan tí wọ́n lè rí wí, nítorí pé níta gbangba la ti kéde iṣẹ́ náà, tí a kò fi bọpobọyọ̀.
Sólómọ́nì là á mọ́lẹ̀ pé: “Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó gan-an. Àwọn ojúde ìlú ni ó ti ń fọ ohùn rẹ̀ jáde. Ìpẹ̀kun òkè àwọn ojú pópó aláriwo ni ó ti ń ké jáde. Ibi àtiwọ àwọn ẹnubodè tí ó wọ ìlú ńlá ni ó ti ń sọ àwọn àsọjáde tirẹ̀.” (Òwe 1:20, 21) Pẹ̀lú ohùn rara, tó ń dún ketekete ni ọgbọ́n fi ń kígbe ní ìta gbangba, kí gbogbo ènìyàn baà lè gbọ́. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn àgbà ọkùnrin ló ń fúnni nímọ̀ràn, àwọn ni wọ́n sì ń dájọ́ lẹ́nu ọ̀nà àbáwọ̀lú. Ní tiwa, Jèhófà ti mú kí ọgbọ́n tòótọ́ di èyí tí a kọ sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, èyí tó wà níbi gbogbo. Lóde ìwòyí, ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dí fún pípolongo iṣẹ́ yìí níbi gbogbo. Lóòótọ́, Ọlọ́run ti mú kí a polongo ọgbọ́n fún tọmọdé tàgbà.
Kí ni ọgbọ́n tòótọ́ wá sọ o? Ohun tó wí rèé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìní ìrírí yóò fi máa nífẹ̀ẹ́ àìní ìrírí, yóò sì ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin olùyọṣùtì yóò fi máa fẹ́ ìyọṣùtì gbáà fún ara yín . . . ? Mo ti ké jáde, ṣùgbọ́n ẹ ń bá a nìṣó ní kíkọ̀, mo ti na ọwọ́ mi jáde, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ń fetí sílẹ̀.” Àwọn òmùgọ̀ kò kọbi ara sí ohùn ọgbọ́n. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, “wọn yóò jẹ nínú èso ọ̀nà wọn.” ‘Ìwà ọ̀dàlẹ̀ àti ìdẹra dẹngbẹrẹ’ tiwọn fúnra wọn ‘yóò sì pa wọ́n.’—Òwe 1:22-32.
Ẹni tó ti wá fetí sí ohùn ọgbọ́n ńkọ́? “Yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.” (Òwe 1:33) Ǹjẹ́ kíwọ náà wà lára àwọn tó ní ọgbọ́n, tí wọ́n sì gba ìbáwí, nípa fífiyèsí àwọn òwe inú Bíbélì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọgbọ́n tòótọ́ wà níbi gbogbo