Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ?
OLÙDÁMỌ̀RÀN fún ààrẹ, Bernard Baruch, ẹni tó ti dolóògbé báyìí, wí pé: “Ẹni tí ò bá ṣèlérí púpọ̀ ni kóo dìbò fún; òun ni kò ní tètè já ọ kulẹ̀.” Láyé òde òní, ó dà bíi pé nítorí káwọn èèyàn má bàa mú ìlérí wọn ṣẹ gan-an ni wọ́n ṣe ń ṣèlérí. Ìlérí yìí lè jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, àdéhùn okòwò, tàbí jíjẹ́jẹ̀ẹ́ láti lo àkókò tó pọ̀ sí i pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ìtumọ̀ àṣàyàn ọ̀rọ̀ náà, pé: “Bí ènìyàn bá ṣe ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tó, ló fi hàn bó ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé tó,” ti di ohun tí a kò kà sí mọ́.
Ó dájú pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò fẹ́ máa mú ìlérí wọn ṣẹ. Àwọn mìíràn kàn ń ṣèlérí lásán ni, wọn ò ní mú un ṣẹ, ìdí sì ni pé, ìyẹn ni ọ̀nà tó rọrùn jù lọ tí wọ́n lè gbà.
Lóòótọ́, ó lè ṣòro láti mú ìlérí ṣẹ bí àwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣé lóòótọ́ ni ìlérí tí a kò mú ṣẹ máa ń ba nǹkan jẹ́? Ǹjẹ́ ó yẹ kóo fọwọ́ dan-in dan-in mú ìlérí rẹ? Gbígbé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run yẹ̀ wò ní ṣókí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn yìí.
Jèhófà Máa Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
A ń jọ́sìn Ọlọ́run tí orúkọ rẹ̀ gan-an wé mọ́ mímú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, orúkọ ẹnì kan sábà máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tí onítọ̀hún jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni orúkọ Jèhófà, tó túmọ̀ sí “Ó Mú Kí Ó Di.” Nípa báyìí, orúkọ Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú èrò náà pé, yóò mú ìlérí àti ète rẹ̀ ṣẹ.
Nítorí tí orúkọ Jèhófà rò ó, ó mú gbogbo ìlérí tó ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣẹ. Sólómọ́nì Ọba sọ nípa àwọn ìlérí wọ̀nyí pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, tí ó ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì ní ibi ìsinmi gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó ṣèlérí. Ọ̀rọ̀ kan kò kùnà nínú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 8:56.
Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lè sọ pé: “Nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù, níwọ̀n bí kò ti lè fi ẹnì kankan tí ó tóbi jù ú búra, ó fi ara rẹ̀ búra.” (Hébérù 6:13) Bẹ́ẹ̀ ni, orúkọ Jèhófà àti irú ẹni tó jẹ́ mú kó dá wa lójú pé òun kò ní ṣàìmú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ná an ní ọ̀pọ̀ nǹkan. (Róòmù 8:32) Òtítọ́ náà pé Jèhófà yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ fún wa ní ìrètí tó jẹ́ ìdákọ̀ró fún ọkàn wa, tàbí ẹ̀mí wa.—Hébérù 6:19.
Ìlérí Jèhófà àti Ọjọ́ Ọ̀la Wa
Ìrètí wa, ìgbàgbọ́ wa, àti ìwàláàyè wa pàápàá, gbogbo rẹ̀ sinmi lórí mímú tí Jèhófà bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìrètí wo la ní? “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká gbà gbọ́ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ó sì tún yẹ kó dá wa lójú pé ohun mìíràn ń bẹ tó ṣe pàtàkì ju ìwàláàyè ìsinsìnyí. Ní tòótọ́, ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù pè ní “ohun ìlérí” ni “ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Jòhánù 2:25) Ṣùgbọ́n ìlérí Jèhófà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò mọ sí ọjọ́ ọ̀la nìkan. Wọ́n ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ nítumọ̀ nísinsìnyí pàápàá.
Onísáàmù náà kọrin pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, . . . igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́.” (Sáàmù 145:18, 19) Ọlọ́run tún mú un dá wa lójú pé òun “ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.” (Aísáyà 40:29) Ẹ sì wo bó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé ‘Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí a dẹ wá wò ré kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde’! (1 Kọ́ríńtì 10:13) Bó bá jẹ́ pé àwa fúnra wa ti rí bí Ọlọ́run ṣe mú èyíkéyìí nínú àwọn ìlérí wọ̀nyí ṣẹ, a ó mọ̀ pé atóógbẹ́kẹ̀lé pátápátá ni Jèhófà. Pẹ̀lú àwọn àǹfààní táa ti rí jẹ nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe, tó sì ti mú ṣẹ, ojú wo lo yẹ ká fi wo àwọn ìlérí táa bá A ṣe?
Mímú Ìlérí Táa Bá Ọlọ́run Ṣe Ṣẹ
Kò sí àní-àní pé yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ táa ṣe. Nípa gbígbé ìgbésẹ̀ yìí, a fi hàn pé a fẹ́ sin Jèhófà títí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin Ọlọ́run ò nira, ó lè má rọrùn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo, báa ti ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. (2 Tímótì 3:12; 1 Jòhánù 5:3) Ṣùgbọ́n, gbàrà tí a ‘bá ti fi ọwọ́ wa lé ohun ìtúlẹ̀,’ tí a ti di ìránṣẹ́ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, tí a sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ tún máa wo àwọn nǹkan ti ayé tí a ti fi sílẹ̀.—Lúùkù 9:62.
Nígbà táa bá gbàdúrà sí Jèhófà, ohun kan lè sún wa láti ṣèlérí fún un pé a ó jìjàkadì láti borí ìkùdíẹ̀-káàtó kan, pé a ó mú ànímọ́ Kristẹni kan dàgbà, tàbí pé a ó mú apá kan nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìlérí wọ̀nyí ṣẹ?—Fi wé Oníwàásù 5:2-5.
Látinú ọkàn-àyà ẹni àti èrò ẹni ni ojúlówó ìlérí ti ń wá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a mú kí àwọn ìlérí táa bá Jèhófà ṣe fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nípa ṣíṣí ọkàn-àyà wa payá fún un nínú àdúrà, nípa sísọ ohun tó ń bà wá lẹ́rù jáde láìfòyà, ká sọ ohun táa fẹ́, àti àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa, láìfi ohunkóhun pa mọ́. Gbígbàdúrà nípa ìlérí táa ṣe yóò fún wa lókun láti mú un ṣẹ. A lè ka ìlérí táa bá Ọlọ́run ṣe sí gbèsè. Tí gbèsè bá pọ̀, ó yẹ ká máa san án díẹ̀díẹ̀. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìlérí táa ṣe fún Jèhófà ni yóò gba àkókò ká tó lè mú un ṣẹ tán. Ṣùgbọ́n nípa fífún un ní ohun tí a bá lè fún un déédéé, a ń fi hàn pé a ṣe tán láti mú ìlérí wa ṣẹ, òun yóò sì bù kún wa bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
A lè fi hàn pé a kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlérí wa nípa gbígbàdúrà nípa rẹ̀ léraléra, bóyá lójoojúmọ́ pàápàá. Èyí yóò jẹ́ kí Baba wa ọ̀run mọ̀ pé ó jẹ wá lọ́kàn. Yóò tún jẹ́ ìránnilétí ìgbà gbogbo. Dáfídì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa èyí. Nínú orin, ó bẹ Jèhófà pé: “Gbọ́ igbe ìpàrọwà mi, Ọlọ́run. Fetí sí àdúrà mi. . . . Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ títí láé, kí n lè san àwọn ẹ̀jẹ́ mi ní ọjọ́ dé ọjọ́.”—Sáàmù 61:1, 8.
Mímú Ìlérí Wa Ṣẹ Ń Jẹ́ Ká Di Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé
Bó bá jẹ́ pé kò yẹ ká fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlérí táa bá Ọlọ́run ṣe, kò yẹ ká fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlérí táa ṣe fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa pẹ̀lú. Kò yẹ ká lo ìlànà kan fún bíbá Jèhófà lò, kí a sì wá lo òmíràn fún bíbá àwọn ará wa lò. (Fi wé 1 Jòhánù 4:20.) Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù wí pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Rírí i dájú pé ọ̀rọ̀ wa ṣeé gbára lé jẹ́ ọ̀nà kan láti ‘ṣe ohun rere sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.’ (Gálátíà 6:10) Gbogbo ìlérí tí a bá mú ṣẹ ló ń jẹ́ ká túbọ̀ di ẹni tó ṣeé gbára lé.
Ìgbà tó bá kan ọ̀ràn owó la máa ń rí i pé aburú tó wà nínú kí ènìyàn má máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ kò kéré. Ó yẹ kí Kristẹni sọ̀rọ̀ ká sì bá a bẹ́ẹ̀, ì báà jẹ́ ní ti sísan owó tó yá padà, bíbáni ṣiṣẹ́, tàbí mímú ìlérí okòwò ṣẹ. Èyí ń mú inú Ọlọ́run dùn, ó sì ń fi kún ìgbẹ́kẹ̀lé tó ṣe pàtàkì bí àwọn ará yóò bá máa “gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.”—Sáàmù 133:1.
Ṣùgbọ́n, yíyẹ àdéhùn lè pa ìjọ àti ẹni tí ọ̀ràn náà kàn lára. Alábòójútó arìnrìn àjò kan ṣàkíyèsí pé: “Èdè àìyedè lórí okòwò—tí yíyẹ̀ tí ẹnì kan yẹ àdéhùn ń fà—sábà máa ń di ohun tó hàn sí gbogbo ayé. Ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, àwọn ará á bẹ̀rẹ̀ sí gbè sẹ́yìn ara wọn, ni gbúngbùngbún á wá dé sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó láti gbé àdéhùn èyíkéyìí tí a bá fẹ́ ṣe yẹ̀ wò fínnífínní, kí a sì rí i pé ó wà ní àkọsílẹ̀!a
A tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra báa bá ń ta àwọn ọjà tó gbówó lórí tàbí tí a ń fi okòwò lọni, pàápàá tó bá jẹ́ pé èrè yóò tibẹ̀ bọ́ sápò wa. Bákan náà, ó ṣe pàtàkì láti kíyè sára gidigidi kí a má ṣe pọ́n àǹfààní tó wà nínú ọjà kan tàbí oògùn kan ju bó ṣe yẹ lọ tàbí ká máa ṣèlérí èrè tí kò lè ṣeé ṣe lórí okòwò kan. Ìfẹ́ yẹ kó sún àwọn Kristẹni láti ṣàlàyé ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ewu èyíkéyìí tó wà nínú okòwò náà. (Róòmù 12:10) Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará kò ti ní ìrírí tó bẹ́ẹ̀ nínú okòwò, wọ́n lè gbára lé ìmọ̀ràn wa kìkì nítorí pé a jẹ́ ìbátan wọn nínú ìgbàgbọ́. Ẹ wo bí yóò ṣe bà wọ́n nínú jẹ́ tó tí a bá lọ fojú kéré ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní nínú wa!
Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò lè kó wọnú òwò tó kún fún màgòmágó tàbí tí kò gba ti ire àwọn ẹlòmíràn rò. (Éfésù 2:2, 3; Hébérù 13:18) Láti rí ojú rere Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ‘àlejò nínú àgọ́ rẹ̀,’ a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé. ‘Àní tí a bá búra ohun tí ó burú fún ara wa, síbẹ̀síbẹ̀ a kò ní yí padà.’—Sáàmù 15:1-4.
Jẹ́fútà, onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, bí Ọlọ́run bá jẹ́ kí òun ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé òun nígbà tí òun bá ń ti ojú ogun náà bọ̀, ni òun yóò fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun. Ọmọ kan ṣoṣo tí Jẹ́fútà bí ló kọ́kọ́ wá pàdé rẹ̀ nígbà tó ń darí bọ̀ wálé láti ojú ogun, ṣùgbọ́n kò tìtorí rẹ̀ yẹ àdéhùn tó ti ṣe. Lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ ti fi tọkàntọkàn gbà pẹ̀lú rẹ̀, ó yọ̀ǹda ọmọ náà láti lọ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn títí ayé nínú ibi mímọ́ Ọlọ́run—ìrúbọ kan tó ni ín lára, tó sì ná an ní ohun púpọ̀ lọ́pọ̀ ọ̀nà.—Onídàájọ́ 11:30-40.
Pàápàá jù lọ, àwọn alábòójútó nínú ìjọ ní ẹrù iṣẹ́ láti mú àdéhùn wọn ṣẹ. Ní ìbámu pẹ̀lú 1 Tímótì 3:2, alábòójútó ní láti jẹ́ “aláìlẹ́gàn.” Èyí jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “kí ó má ṣe jẹ́ ẹni tí a rí nídìí àìdáa, ẹni tí a lè fojú ẹ̀gàn wò, kí ó má sì jẹ́ ẹni àbùkù.” Ó “túmọ̀ sí pé, kó ní jẹ́ pé ọkùnrin náà ní ìròyìn rere nìkan, ṣùgbọ́n pé ó tún jẹ́ ẹni tó yẹ ká fojú rere wò.” (Gẹ́gẹ́ bí àlàyé A Linguistic Key to the Greek New Testament) Níwọ̀n bí alábòójútó ti gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlẹ́gàn, àwọn ìlérí rẹ̀ yẹ kó ṣeé gbára lé.
Àwọn Ọ̀nà Mìíràn Láti Mú Ìlérí Wa Ṣẹ
Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìlérí táa bá àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa ṣe? Jésù wí pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Nípa fífi hàn pé a máa ń ka ìlérí tí a bá ṣe sí, a óò jẹ́ kí ìhìn iṣẹ́ Kristẹni wa fa àwọn ẹlòmíràn mọ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jákèjádò ayé ni àwọn èèyàn kò ti fọwọ́ pàtàkì mú jíjẹ́ olóòótọ́ mọ́, ọ̀pọ̀ ló ṣì jẹ́ pé wọ́n gbà pé ó dáa púpọ̀ ká wí bẹ́ẹ̀, ká sì bá á bẹ́ẹ̀. Mímú ìlérí wa ṣẹ jẹ́ ọ̀nà kan láti fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wa, ká sì di ẹni tí àwọn olùfẹ́ òdodo fẹ́ràn.—Mátíù 22:36-39; Róòmù 15:2.
Nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 1998, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo wákàtí tó lé ní bílíọ̀nù kan láti polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbangba. (Mátíù 24:14) Ká sọ pé àwọn èèyàn ti mọ̀ wá sí ẹni tí kì í mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ ni, bóyá nínú ọ̀ràn ìṣòwò tàbí ọ̀ràn mìíràn, àwọn kan ì bá má tẹ́tí sí wa rárá. Níwọ̀n bí a ti ń ṣojú fún Ọlọ́run òtítọ́, àwọn ènìyàn máa ń retí pé kí a jẹ́ olóòótọ́. Nípa jíjẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé, tó sì jẹ́ olóòótọ́, a ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a láǹfààní láti mú àdéhùn wa ṣẹ nígbà tí a bá padà lọ bẹ àwọn tó fi ìfẹ́ hàn sí iṣẹ́ Ìjọba náà wò. Táa bá sọ pé a ó padà wá, a gbọ́dọ̀ rí i pé a padà lọ. Pípadà lọ gẹ́gẹ́ báa ti ṣèlérí jẹ́ ọ̀nà kan ‘láti má ṣe fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó yẹ kí a ṣe é fún.’ (Òwe 3:27) Bí arábìnrin kan ṣe ṣàlàyé ọ̀ràn yìí rèé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo ti bá ọ̀pọ̀ àwọn tó fi ìfẹ́ hàn pàdé, tí wọ́n sọ pé, Ẹlẹ́rìí kan ti sọ pé òun máa padà wá, tí àwọn ò sì gbúròó rẹ̀ mọ́. Àmọ́ ṣáá o, mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí onílé náà máà sí nílé nígbà tí onítọ̀hún padà lọ tàbí kí ipò nǹkan máà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún onítọ̀hún láti lọ. Ṣùgbọ́n n kò ní fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ bẹ́ẹ̀ nípa mi o, nítorí náà, mo máa ń sa gbogbo ipá mí láti rí i pé mo padà bá ẹni náà nílé. Mo gbà pé bí mo bá já ẹnì kan kulẹ̀, èrò onítọ̀hún nípa Jèhófà àti àwọn ará mi gbogbo kò ní dáa rárá.”
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a lè máà fẹ́ padà lọ nítorí a ti gbà pé ẹni náà kò nífẹ̀ẹ́ gidi. Arábìnrin kan náà ṣàlàyé pé: “N kì í fẹ́ ṣèdájọ́ nípa bí ìfẹ́ ti ẹnì kan fi hàn ti pọ̀ tó. Ìrírí tèmi alára ti kọ́ mi pé, ìfẹ́ àkọ́kọ́ kì í sábà rí bí a ṣe rò pé ó rí. Nítorí náà, mo sábà máa ń fẹ́ láti ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára, mo máa ń fẹ ka olúkúlùkù sí ẹni tó lè di arákùnrin tàbí arábìnrin lọ́la.”
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni àti láwọn ọ̀nà mìíràn, ó yẹ ká máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa ṣeé gbára lé. Lóòótọ́, ọ̀tọ̀ ní kà sọ̀rọ̀, ọ̀tọ̀ sì ni ká mú un ṣẹ. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà fi èyí hàn nígbà tó sọ pé: “Olúkúlùkù nínú ògìdìgbó ènìyàn yóò máa pòkìkí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tirẹ̀, ṣùgbọ́n olùṣòtítọ́ ènìyàn, ta ní lè rí i?” (Owe 20:6) Ṣùgbọ́n, táa bá ti pinnu pé a máa mú ìlérí wa ṣẹ, a lè jẹ́ ẹni to ṣeé gbíyè lé, a kò sì ní yẹ àdéhùn.
Ìbùkún Yàbùgà-Yabuga Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Mímọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìlérí òfo jẹ́ ìwà màgòmágó, a sì lè fi wé ẹnì kan tó kọ ìwé sọ̀wédowó fúnni, ṣùgbọ́n tí kò ní kọ́bọ̀ ní báńkì. Àmọ́, ẹ wo bí àǹfààní àti ìbùkún tí a ń rí gbà ti pọ̀ tó nígbà táa bá mú ìlérí wa ṣẹ! Ìbùkún kan tí jíjẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé ní, ni pé, yóò jẹ́ kí a ní ẹ̀rí-ọkàn rere. (Fi wé Ìṣe 24:16.) Dípò tí ọkàn wa yóò fi máa dá wa lẹ́bi, ṣe ni ọkàn wa yóò balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, tí a ó sì lálàáfíà. Síwájú sí i, nípa mímú ìlérí wa ṣẹ, a ń fi kún ìṣọ̀kan ìjọ, èyí tó sinmi lórí ìgbẹ́kẹ̀lé tí ẹnì kan ní nínú ẹnì kejì. “Ọ̀rọ̀ òtítọ́” wa tún lè jẹ́ káwọn èèyàn rí wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run òtítọ́.—2 Kọ́ríńtì 6:3, 4, 7.
Jèhófà máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó sì kórìíra “ahọ́n èké.” (Òwe 6:16, 17) Báa bá ń fara wé Baba wa ọ̀run, ó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Dájúdájú nígbà náà, ìdí tó múná dóko wà táa fi ní láti máa mú ìlérí wa ṣẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Kọ Ọ Silẹ Sori Iwe!” nínú Jí! ti July 8, 1984, ojú ìwé 13 sí 15.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jẹ́fútà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ni ín lára
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Bóo bá ṣèlérí pé wàá padà wá, yáa múra láti padà lọ