Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Mẹ́ta nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ló ṣe àkọsílẹ̀ àròyé tó wáyé lórí òróró olówó gọbọi tẹ́nì kan dà sí Jésù lórí. Ṣé ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì ló ṣàròyé náà ni, àbí Júdásì nìkan?
Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà nínú Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, àti Jòhánù. Ó dà bí ẹni pé Júdásì gan-an ni abẹnugan nínú àròyé náà, ó sì wá jọ pé àwọn àpọ́sítélì kan fara mọ́ ohun tó ń sọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí ìdí táa fi ní láti dúpẹ́ pé a ní àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tí òǹkọ̀wé kọ̀ọ̀kan kọ péye, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ló fún wa ní kúlẹ̀kúlẹ̀ kan náà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Táa bá fi àkọsílẹ̀ wọ̀nyí wéra wọn, ọ̀rọ̀ wọn yóò túbọ̀ yé wa, a ó sì wá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀.
Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Mátíù 26:6-13 sọ ibi tó ti ṣẹlẹ̀—ilé Símónì adẹ́tẹ̀, ní Bétánì—ṣùgbọ́n kò sọ orúkọ obìnrin tó bẹ̀rẹ̀ sí da òróró onílọ́fínńdà sí Jésù lórí. Mátíù sọ pé: “Nígbà tí wọ́n rí èyí, ìkannú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ru,” wọ́n sì ṣàròyé pé wọn ì bá ti ta òróró náà, kí wọ́n sì kó owó rẹ̀ fún àwọn tálákà.
Àkọsílẹ̀ ti Máàkù ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n ó fi kún un pé, obìnrin náà já orùba náà. Òróró onílọ́fínńdà tó jẹ́ “ojúlówó náádì,” irú èyí tí wọ́n máa ń kó wá láti Íńdíà, ló wà nínú rẹ̀. Nípa àròyé náà, Máàkù ròyìn pé “àwọn kan wà tí wọ́n ń fi ìkannú hàn,” àti pé “wọ́n . . . ní ìbìnújẹ́ ńláǹlà sí i.” (Máàkù 14:3-9) Nítorí náà, àkọsílẹ̀ méjèèjì fi hàn pé kì í ṣe àpọ́sítélì kan péré ló ṣàròyé. Báwo ló ṣe bẹ̀rẹ̀ ná?
Jòhánù, ẹni tí ọ̀ràn náà ṣojú rẹ̀, fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe pàtàkì wọ̀nyí kún un. Ó dárúkọ obìnrin náà—Màríà ni, arábìnrin Màtá àti Lásárù. Jòhánù tún pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí, èyí táa lè pè ní àṣekún dípò tí a ó fi rò pé ṣe ló ta kora: “Ó sì fi pa ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ.” Táa bá pa àkọsílẹ̀ wọ̀nyí pọ̀, a lè rí i pé Màríà ti ní láti da òróró náà, tí Jòhánù jẹ́rìí sí i pé ó jẹ́ “ojúlówó náádì,” sí orí àti ẹsẹ̀ Jésù. Jòhánù fẹ́ràn Jésù gan-an, inú á sì bí i tó bá rí i pé ẹnì kan fẹ́ rí I fín. A kà pé: “Júdásì Ísíkáríótù, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tí ó máa tó dà á, wí pé: ‘Èé ṣe tí a kò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì, kí a sì fi fún àwọn òtòṣì?’”—Jòhánù 12:2-8.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Júdásì jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀,” ṣùgbọ́n o le rí i pé inú bí Jòhánù pé ẹnì kan tó wà nírú ipò ỵẹn ló fẹ́ da Jésù. Atúmọ̀ èdè nì, Ọ̀mọ̀wé C. Howard Matheny sọ nípa Jòhánù 12:4 pé: “Ọ̀rọ̀ tó ń júwe ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ìyẹn ni ‘máa tó’ àti ọ̀rọ̀ tó ń tọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ “máa tó dà á” fi hàn pé nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀ bọ̀. Èyí fi hàn pé dídà tí Júdásì da Jésù kì í ṣe ohun kan tó kàn ṣẹlẹ̀ lójijì, nítorí pé ó ti ronú lé e lórí, ó ti wéwèé rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.” Jòhánù wá fi ìdí abájọ kún un pé, Júdásì ń ṣàròyé “kì í ṣe nítorí pé ó ń ṣàníyàn nípa àwọn òtòṣì, bí kò ṣe nítorí pé olè ni, àti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, a sì máa kó àwọn owó tí a fi sínú rẹ̀ lọ.”
Ó wá jọ ohun tó bọ́gbọ́n mu táa bá sọ pé olè náà, Júdásì, ló dá àròyé náà sílẹ̀ nítorí pé yóò túbọ̀ rí owó jí bí wọ́n bá ta òróró olówó gọbọi náà, tí wọ́n sì wá kó owó náà sínú àpótí tí ó máa ń wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbàrà tí Júdásì ṣàròyé yìí, ó ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítélì kan máa sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ pé àwọn gbà pé òótọ́ ló sọ. Àmọ́ ṣá o, Júdásì gan-an leku ẹdá tó dá àròyé yìí sílẹ̀.