Fi Ọkàn Àti Èrò Inú Rẹ Wá Ọlọ́run
Ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ń fún wa níṣìírí pé ká lo ọkàn àti èrò inú wa láti ní ìgbàgbọ́ tó wu Ọlọ́run.
JÉSÙ KRISTI, tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀, tilẹ̀ kọ́ wa pé ká fi “gbogbo èrò inú” wa, ìyẹn làákàyè wa, àti “gbogbo ọkàn-àyà” àti “gbogbo ọkàn” wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 22:37) Àní sẹ́, iṣẹ́ tí làákàyè wa ń ṣe nínú ìjọsìn wa kò kéré.
Nígbà tí Jésù bá ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n gba ẹ̀kọ́ òun rò, ó sábà máa ń sọ pé: “Kí ni ìwọ [tàbí ẹ̀yin] rò?” (Mátíù 17:25; 18:12; 21:28; 22:42) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti lè ‘ru agbára ìrònú wọn ṣíṣe kedere sókè.’ (2 Pétérù 3:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí í ṣe míṣọ́nnárì tó rìnrìn àjò jù lọ lára àwọn míṣọ́nnárì ìjímìjí, rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa lo “agbára ìmọnúúrò” wọn, kí wọ́n sì “ṣàwárí fúnra [wọn] ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:1, 2) Àfi bí àwọn Kristẹni bá fara balẹ̀ gbé ẹ̀kọ́ wọn yẹ̀ wò kínníkínní ni wọ́n tó lè ní irú ìgbàgbọ́ tó wu Ọlọ́run, tó sì lè kojú àwọn àdánwò inú ìgbésí ayé.—Hébérù 11:1, 6.
Láti lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ yẹn, àwọn Kristẹni ajíhìnrere ìjímìjí ‘bá wọn fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́, wọ́n ń ṣàlàyé, wọ́n sì ń fi ẹ̀rí ti ohun tí wọ́n ń kọ́ni nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka.’ (Ìṣe 17:1-3) Ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe é yẹn ló jẹ́ káwọn olóòótọ́ ọkàn tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn kan nílùú Bèróà tó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Makedóníà “gba ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run] pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí [tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣàlàyé] rí.” (Ìṣe 17:11) Nǹkan méjì gba àfiyèsí nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Èyí àkọ́kọ́, àwọn ará Bèróà ń hára gàgà láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; èkejì, wọn ò kàn gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ láìṣèwádìí. Ṣùgbọ́n wọ́n yẹ inú Ìwé Mímọ́ wò láti mọ̀ bóyá òótọ́ ni. Kristẹni míṣọ́nnárì náà Lúùkù fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbóríyìn fáwọn ará Bèróà nítorí èyí, wọ́n sọ pé wọ́n ní “ọkàn-rere.” Ṣé irú ọkàn rere bẹ́ẹ̀ lo fi ń wo nǹkan tẹ̀mí?
Èrò Inú àti Ọkàn Jọ Ń Ṣiṣẹ́ Pọ̀ Ni
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, ìjọsìn tòótọ́ wé mọ́ èrò inú àti ọkàn. (Máàkù 12:30) Ronú lọ sórí àpèjúwe tá a lò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, nípa ọmọ tí ìyá rẹ̀ ní kó lọ ra òróró wá, tó lọ ra epo pupa. Ká ní ó tẹ́tí sóhun tí ìyá rẹ̀ ní kó rà ni, ohun náà gan-an ni ì bá rà. Ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀ pé inú ìyá òun á dùn sóun. Bọ́ràn ìjọsìn wa ṣe rí náà nìyẹn.
Jésù sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23) Ìyẹn ló jẹ́ kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìdí tún nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé . . . àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” (Kólósè 1:9, 10) Irú “ìmọ̀ pípéye” bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fáwọn olóòótọ́ ọkàn láti máa fi tọkàntọkàn ṣe ìjọsìn wọn, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún pé wọ́n “ń jọ́sìn ohun tí [wọ́n] mọ̀.”—Jòhánù 4:22.
Ìdí wọ̀nyí ló fà á tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í batisí ìkókó tàbí olùfìfẹ́hàn, tí kò tíì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ẹ̀yìn ìgbà tí ẹni tó ń fi òótọ́ inú kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ní ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ Ọlọ́run ló tó lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa ọ̀ràn ìjọsìn. Ǹjẹ́ ò ń sapá láti jèrè ìmọ̀ pípéye yẹn?
Lílóye Àdúrà Olúwa
Láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín níní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì àti níní ìmọ̀ oréfèé nípa ohun tó sọ, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àdúrà táwọn èèyàn ń pè ní Àdúrà Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run, tàbí Àdúrà Olúwa, tó wà ní Mátíù 6:9-13.
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa ń gba àdúrà àwòṣe tí Jésù fi kọ́ wa yìí nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn mélòó ló mọ ìtumọ̀ rẹ̀, àgàgà apá àkọ́kọ́ àdúrà náà tó sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀? Àwọn kókó wọ̀nyí ṣe pàtàkì débi pé àwọn ni Jésù kọ́kọ́ mẹ́nu kàn nínú àdúrà náà.
Bí àdúrà náà ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Ṣàkíyèsí pé Jésù ní ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́. Èyí á gbé ó kéré tán ìbéèrè méjì dìde lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn: Èkíní, kí ni orúkọ Ọlọ́run? Èkejì sì ni, kí nìdí tó fi pọn dandan láti sọ ọ́ di mímọ́?
A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ yẹn ní iye ìgbà tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje nínú Bíbélì, nínú àwọn èdè tá a fi kọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀kan lára ibi wọ̀nyí ni Sáàmù 83:18 tó kà pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Nínú Ẹ́kísódù 3:15 ohun tí Jèhófà sọ rèé nípa orúkọ rẹ̀: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.”a Àmọ́ kí nìdí tó fi ń béèrè pé kí orúkọ Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ látòkèdélẹ̀ tún di èyí tí a ó sọ di mímọ́? Ìdí ni pé a ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ náà, a sì ti ṣáátá rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn aráyé.
Nínú ọgbà Édẹ́nì, Ọlọ́run sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọn yóò kú bí wọ́n bá jẹ èso tá a kà léèwọ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Sátánì gbójúgbóyà, ó tako Ọlọ́run, ó sọ fún Éfà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀sùn irọ́ pípa kan Ọlọ́run. Àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Ó tún pẹ̀gàn orúkọ Ọlọ́run síwájú sí i, ó sọ fún Éfà pé Ọlọ́run fi ohun pàtàkì kan tó yẹ kó mọ̀ dù ú. “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Ìbanilórúkọjẹ́ gbáà lèyí!—Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5.
Ádámù àti Éfà fi hàn pé ìhà Sátánì làwọn wà nípa jíjẹ èso tá a kà léèwọ̀ náà. Yálà àwọn èèyàn mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ló ti pa kún ẹ̀gàn náà látìgbà yẹn nípa títàpá sí àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run. (1 Jòhánù 5:19) Àwọn èèyàn ṣì ń ṣáátá Ọlọ́run nípa dídẹ́bi fún un nítorí ìyà tó ń jẹ wọ́n—bó tilẹ̀ jẹ́ pé àfọwọ́fà wọn ni. Òwe 19:3 sọ pé: “Ìwà òmùgọ̀ èèyàn ló bayé ẹ̀ jẹ́, tó wá ń fìkanra mọ́ Olúwa.” (The New English Bible) Ṣé o wá rí ìdí tí Jésù, tó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ tọkàntọkàn, fi gbàdúrà pé ká sọ orúkọ Rẹ̀ di mímọ́?
“Kí Ìjọba Rẹ Dé”
Lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà nípa sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ ló wá sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ìbéèrè tá a lè béèrè nípa àyọkà yẹn ni pé: ‘Kí ni Ìjọba Ọlọ́run jẹ́? Báwo sì ni dídé rẹ̀ yóò ṣe kan ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé?’
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìjọba” ní pàtàkì túmọ̀ sí “ìṣàkóso látọwọ́ ọba.” Fún ìdí yìí, ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí ni ìṣàkóso, tàbí ìjọba látọwọ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ ọba tí òun yàn. Ta ni ọba ọ̀hún ì bá tún jẹ́, bí kì í bá ṣe Jésù Kristi tá a jí dìde—tí í ṣe “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” (Ìṣípayá 19:16; Dáníẹ́lì 7:13, 14) Wòlíì Dáníẹ́lì kọ̀wé nípa Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ àkóso Jésù Kristi Mèsáyà náà, pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn àwọn ìjọba ènìyàn tó ń ṣàkóso báyìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin,” ìyẹn títí láé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìjọba Ọlọ́run yóò gba àkóso lórí ilẹ̀ ayé yìí, yóò sì mú gbogbo àwọn olubi àtàwọn ìjọba kúrò “fún àkókò tí ó lọ kánrin,” ìyẹn, títí láé. Nípa báyìí, Ìjọba Ọlọ́run ni Jèhófà yóò lò láti sọ orúkọ ara rẹ̀ di mímọ́. Ìjọba yìí ni yóò lò láti rí sí i pé gbogbo ẹ̀gàn burúkú tí Sátánì àtàwọn olubi ti mú wá sórí rẹ̀ ni a mú kúrò.—Ìsíkíẹ́lì 36:23.
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìjọba yòókù, Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọmọ abẹ́. Àwọn wo ni? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” Dájúdájú, àwọn wọ̀nyí ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, èyí tá a gbọ́dọ̀ ní ká tó lè ní ìyè.—Mátíù 5:5; Jòhánù 17:3.
Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo gbogbo ilẹ̀ ayé tó kún fún àwọn ọlọ́kàn tútù tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, tó sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì? (1 Jòhánù 4:7, 8) Ohun tí Jésù gbàdúrà fún nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà lọ́nà yẹn? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ǹjẹ́ o mọ bí ìmúṣẹ àdúrà yẹn ṣe lè kan ìwọ alára?
Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ló Ń Fèròwérò Látinú Ìwé Mímọ́ Báyìí
Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí tí a óò ṣe kárí ayé, èyí tí yóò dá lórí kíkéde Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ yìí. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin [ayé tàbí ètò ìsinsìnyí] yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ló ń polongo ìhìn rere yẹn báyìí fún àwọn aládùúgbò wọn. Wọ́n ké sí ọ láti wá mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, kí o “fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́,” nípa lílo agbára ìrònú rẹ. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, á sì jẹ́ kí inú rẹ máa dùn bó o ti ń ronú nípa ìrètí ìwàláàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tí “yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:6-9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan yàn láti lo “Yáwè” dípò “Jèhófà.” Ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn olùtumọ̀ Bíbélì lóde òní ló ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì tí wọ́n túmọ̀, wọ́n sì ti fi àwọn orúkọ oyè náà “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀. Láti lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí orúkọ Ọlọ́run, jọ̀wọ́ lọ wo ìwé pẹlẹbẹ náà Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
MÁA FARA WÉ OLÙKỌ́ ŃLÁ NÁÀ
Nígbà tí Jésù bá ń kọ́ni, ó máa ń gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka ẹṣin ọ̀rọ̀ pàtó látinú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ó ṣàlàyé ipa tí òun kó nínú ète Ọlọ́run fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì tí ọ̀ràn ikú rẹ̀ kó ìdààmú bá. Lúùkù 24:27 sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.”
Ṣàkíyèsí pé Jésù gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka kókó ọ̀rọ̀ kan pàtó—ìyẹn “ara rẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà—ó sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú “gbogbo Ìwé Mímọ́” nínú àlàyé rẹ̀. Ìyẹn ni pé Jésù tọ́ka sí oríṣiríṣi ẹsẹ Bíbélì, tó jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lóye òtítọ́ tẹ̀mí kedere. (2 Tímótì 1:13) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé yàtọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ yìí là wọ́n lóye, ó gbún wọn ní kẹ́sẹ́ pẹ̀lú. Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Wọ́n sì wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: ‘Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?’”—Lúùkù 24:32.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jésù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ jù lọ ni ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? àti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwọn ìwé wọ̀nyí sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ tó fani lọ́kàn mọ́ra látinú Bíbélì, bíi: “Ta Ni Ọlọrun?,” “Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègba Ìjìyà?,” “Báwo Ni O Ṣe Lè Rí Ìsìn Tòótọ́?,” “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìwọ̀nyí!,” àti “Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá fún Ọlọrun Ró.” Ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú.
A fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ̀ ọ́ láti kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ ládùúgbò rẹ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó wà lójú ewé kejì ìwé ìròyìn yìí, kí o sọ pé kí wọ́n wá bá ọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé rẹ lórí kókó wọ̀nyí àtàwọn kókó mìíràn.
[Àwòrán]
Rí i dájú pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ka àwọn kókó pàtó látinú Bíbélì, kí ọ̀rọ̀ rẹ lè wọ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́kàn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ o mọ ìtumọ̀ àdúrà tí Jésù kọ́ wa?
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́ . . . ”
Kí ìjọba rẹ [ìyẹn ti Mèsáyà] dé . . . ”
“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú”