Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Mo Fẹ́ Sin Ọlọ́run”
“Ẹ JÁDE kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.” Ìpè tí àpọ́sítélì Jòhánù gbọ́ lẹ́nu áńgẹ́lì kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa nìyẹn. Ní àkókò tá a wà yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọlọ́kàntútù ló ti ṣègbọràn, tí wọ́n sì ti sá kúrò nínú “Bábílónì Ńlá,” tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 18:1-4) Lára wọn ni ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wilner, ará Haiti, tó sọ ìrírí ara rẹ̀.
“Ọdún 1956 ni wọ́n bí mi sínú ìdílé Kátólíìkì tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá, nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ St. Marc, ní orílẹ̀-èdè Haiti. Ẹ fojú inú wo bí inú ìdílé mi ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n yan èmi àtàwọn méjì mìíràn nílùú wa pé ká lọ sílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà tó wà ní St. Michel de l’Atalaye, Haiti. Nígbà tó tún di ọdún 1980, wọ́n rán wa lọ sílùú Stavelot, ní orílẹ̀-èdè Belgium, pé ká lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ sí i. Ibẹ̀ lá tún ti lọ sí yunifásítì ìjọ Kátólíìkì.
“Lákọ̀ọ́kọ́, ó wù mí gan-an láti di àlùfáà. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, nínú yàrá tá a ti ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán, àlùfáà tó jẹ́ ọ̀gá ní kíláàsì tiwa sọ pé kí n dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀ nítorí pé nǹkan kan wà tí òun fẹ́ sọ fún mi. Tẹ́ ẹ bá rí i bí ara mi ṣe gbọ̀n rìrì nígbà tó là á mọ́lẹ̀ pé òun ń ní òòfà ìbálòpọ̀ sí mi! Mo kọ ìlọ̀kulọ̀ tó fi lọ̀ mí o, àmọ́ ìjákulẹ̀ gidi ló jẹ́ fún mi. Mo kọ̀wé sí ìdílé mi nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, mo sì fi ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà náà sílẹ̀ ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wọn ò dùn sí i. Mo wá ń gbé ibì kan lábúlé, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ mìíràn.
“Nígbà tí mo padà sí St. Marc, mi ò ní ìgbẹ́kẹ̀lé kankan nínú Ìjọ Kátólíìkì mọ́. Síbẹ̀, mo fẹ́ sin Ọlọ́run, àmọ́ mi ò mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Adventist, mo tún lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Ebenezer, àti ṣọ́ọ̀ṣì Mormon. Gbogbo nǹkan wá tojú sú mi nípa tẹ̀mí.
“Ìgbà yẹn ni mo wá rántí pé mo máa ń ka Bíbélì Crampon nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà ní Belgium. Inú rẹ̀ ni mo ti rí i pé Ọlọ́run ní orúkọ kan. Mo wá fi tìtaratìtara gbàdúrà lórúkọ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti rí ẹ̀sìn tòótọ́.
“Àìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó wá sí àdúgbò mi. Èèyàn jẹ́jẹ́ ni wọ́n, wọ́n ní ìtẹríba, wọ́n sì gbayì láwùjọ. Ọ̀nà ìgbésí ayé wọn wú mi lórí gan-an ni. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà pè mí pé kí n wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Mo gbádùn ìpàdé náà gan-an, mo sì sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí náà wá máa bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà, ó dá mi lójú pé mo ti rí ọ̀nà tí ó tọ́ láti sin Ọlọ́run. Mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe batisí ní November 20, 1988.”
Nígbà tó yá, Wilner tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ báyìí. Òun àti aya rẹ̀, àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì ń fi tayọ̀tayọ̀ sìn nínú ìjọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bíbélì kíkà mú kí Wilner rí i pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run