Ohun Kan Tó Níye Lórí Ju Àwọn Ìṣúra Íjíbítì Lọ
MÓSÈ wà lára àwọn tó tóbi lọ́lá jù lọ nínú ìtàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò lábẹ́ ìdarí Mósè ni odindi ìwé mẹ́rin nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ lé lórí, bẹ̀rẹ̀ láti Ẹ́kísódù títí dé Diutarónómì. Mósè ló kó wọn jáde kúrò ni Íjíbítì, òun ni alárinà májẹ̀mú Òfin, òun ló sì ṣamọ̀nà Ísírẹ́lì dé bèbè Ilẹ̀ Ìlérí. Agboolé Fáráò ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà, àmọ́ ó di olùdarí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó tún jẹ́ wòlíì àti onídàájọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló tún jẹ́ òǹkọ̀wé tí Ọlọ́run mí sí. Síbẹ̀ ó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.”—Númérì 12:3.
Ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ogójì ọdún tó lò kẹ́yìn nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn láti àkókò tí Mósè kó àwọn Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú títí dìgbà ikú rẹ̀ lẹ́ni ọgọ́fà ọdún. Iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló ń ṣe ní Mídíánì láti ẹni ogójì ọdún sí ẹni ọgọ́rin ọdún. Ìwé kan sọ pé, “ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá tó fani mọ́ra jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, àmọ́ tá ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohunkóhun nípa rẹ̀,” ni ogójì ọdún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn láti ìgbà tí wọ́n ti bí i títí di ìgbà tó fi sá kúrò ní Íjíbítì. Kí tiẹ̀ lohun tá a lè fòye mọ̀ nípa àkókò yìí? Báwo ni àyíká ibi tí wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà ṣe lè ti nípa lórí irú ẹni tó wá jẹ́ níkẹyìn? Irú àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe kí wọ́n fi kọ́ ọ? Àwọn ìṣòro wo ló ti ní láti dojú kọ? Kí la lè rí kọ́ nínú gbogbo èyí?
Oko Ẹrú ní Íjíbítì
Ìwé Ẹ́kísódù ròyìn pé Fáráò kan bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó tẹ̀dó sí Íjíbítì nítorí pípọ̀ tí wọ́n ń pọ̀ ní iye. Ó lérò pé òun lè “ta ọgbọ́n,” láti fi dín iye wọn kù nípa kíkó wọn ṣe iṣẹ́ àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lábẹ́ àwọn akóniṣiṣẹ́ tó ń kó ẹgba bò wọ́n—wọ́n ń ru ẹrù ìnira, wọ́n ń ṣe àpòrọ́ tí a fi amọ̀ ṣe, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe iye bíríkì tí a yàn fún wọn láti ṣe lójúmọ́.—Ẹ́kísódù 1:8-14; 5:6-18.
Bí a ṣe ṣàpèjúwe ilẹ̀ Íjíbítì tí a bí Mósè sí yìí bá ohun tí àwọn òpìtàn sọ mu wẹ́kú. Àwọn ìwé ìgbàanì tá a fi òrépèté ṣe àti ó kéré tán àwòrán kan tó wà lára ibojì kan ṣàpèjúwe àwọn ẹrú tí ń fi amọ̀ ṣe bíríkì ní ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa tàbí ṣáájú àkókò yẹn. Àwọn aláṣẹ tó ń bojú tó mímọ bíríkì ṣètò ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹrú, wọ́n pín wọn sí ìsọ̀rí bíi mẹ́fà sí méjìdínlógún lábẹ́ akóniṣiṣẹ́ kan. Wọ́n ní láti wa amọ̀ tí wọ́n fi ń mọ bíríkì náà nílẹ̀, kí wọ́n sì ru òun àti pòròpórò lọ síbi tí wọ́n ti ń yọ bíríkì. Àwọn òṣìṣẹ́ láti onírúurú orílẹ̀-èdè máa ń pọnmi, wọ́n sì ń fi ọkọ́ pò ó mọ́ amọ̀ àti pòròpórò. Wọ́n sì máa ń fi àpótí ìyọ-bíríkì yọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ bíríkì. Àwọn òṣìṣẹ́ yóò wá fi àjàgà ru bíríkì tí wọ́n ti sá gbẹ lọ síbi iṣẹ́ ìkọ́lé náà, nígbà mìíràn ọ̀nà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ni wọ́n máa gbà débẹ̀. Àwọn ará Íjíbítì tó ń bójú tó iṣẹ́ náà máa ń mú ọ̀pá lọ́wọ́, wọ́n á jókòó tàbí kí wọ́n máa rìn káàkiri láti wo bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́.
Àkọsílẹ̀ ìgbàanì kan tọ́ka sí bíríkì ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógójì ó lé ẹyọ méjìdínlọ́gọ́fà [39,118] tí àwọn òṣìṣẹ́ méjìlélẹ́gbẹ̀ta [602] ṣe, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ṣe bíríkì márùnlélọ́gọ́ta [65] níwọ̀nba wákàtí tó bá fi ṣiṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìwé kan tó ti wà láti ọ̀rúndún kẹtàlá ṣááju Sànmánì Tiwa sọ pé: “Àwọn ọkùnrin náà . . . ń ṣe iye bíríkì tí a yàn fún wọn lójúmọ́.” Gbogbo èyí ló fara jọ iṣẹ́ àṣekúdórógbó táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìwé Ẹ́kísódù.
Àmọ́, ìnilára kò dín iye àwọn Hébérù náà kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, “bí [àwọn ará Íjíbítì] ti ń ni wọ́n lára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń di púpọ̀ sí i . . . , tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn mú wọn nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ẹ́kísódù 1:10, 12) Ìdí nìyẹn tí Fáráò fi kọ́kọ́ sọ fún àwọn agbẹ̀bí, tó tún sọ fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ níkẹyìn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọkùnrin táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bí. Abẹ́ ipò líle koko yìí ni Jókébédì àti Ámúrámù ti bí ọmọkùnrin rírẹwà kan, ìyẹn Mósè.—Ẹ́kísódù 1:15-22; 6:20; Ìṣe 7:20.
Wọ́n Gbé E Pa Mọ́, Wọ́n Rí I He, Wọ́n sì Gbà Á Ṣọmọ
Àwọn òbí Mósè kò bẹ̀rù àṣẹ ìpànìyàn tí Fáráò gbé kalẹ̀, wọ́n sì gbé ọmọkùnrin wọn jòjòló pa mọ́. Ṣé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ láìbìkítà nípa àwọn amí àtàwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí wọ́n ń wá àwọn ọmọ kéékèèké kiri ni? A ò lè sọ ní pàtó. Ohun yòówù kí ó jẹ́, lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, àwọn òbí Mósè kò lè gbé e pa mọ́ mọ́. Nítorí náà, ìyá rẹ̀ tí kò mọ ohun tí òun lè ṣe mọ́, fi òrépèté hun agbọ́n kan, ó fi ọ̀dà kùn ún kí omi má bàa wọnú rẹ̀, ó sì gbé ọmọ rẹ̀ jòjòló sínú rẹ̀. Títí dé àyè kan, Jókébédì pa àṣẹ Fáráò mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe ohun tó ní kí wọ́n ṣe gan-an pé kí wọ́n máa ju gbogbo ọmọkùnrin jòjòló táwọn Hébérù bá bí sínú Odò Náílì. Míríámù, ẹ̀gbọ́n Mósè wá lúgọ nítòsí kí ó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀.—Ẹ́kísódù 1:22–2:4.
Bóyá ńṣe ni Jókébédì fẹ́ kí ọmọbìnrin Fáráò rí Mósè nígbà tó bá wá wẹ̀ lódò náà ni o, a ò lè sọ, àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ọmọbìnrin ọba náà mọ̀ pé ọkàn lára ọmọ àwọn Hébérù ni. Kí ló máa wá ṣe báyìí? Ṣé kó wá sọ pé kí wọ́n pa á nítorí àtiṣègbọràn sí bàbá rẹ̀ ni? Rárá o, ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ obìnrin máa ṣe gẹ́ẹ́ ló ṣe. Àánú ṣe é.
Kò pẹ́ tí Míríámù fi sá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, tó sì sọ pé: ‘Ṣé kí n lọ bá ọ wá obìnrin Hébérù kan wá kí ó lè máa bá ọ tọ́jú ọmọ náà?’ Àwọn kan sọ pé kàyéfì gbáà ni ìtàn yìí jẹ́. Ẹ̀gbọ́n Mósè yàtọ̀ pátápátá sí Fáráò tí òun àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ jùmọ̀ “ta ọgbọ́n” láti ba ti àwọn Hébérù jẹ́. Àmọ́ o, ìgbà tí ọmọbìnrin ọba náà fara mọ́ ohun tí ẹ̀gbọ́n Mósè wí ni ìdánilójú tó wà pé Mósè ti bọ́ lọ́wọ́ ikú. Ọmọbìnrin Fáráò dáhùn pé: “Lọ!” Ojú ẹsẹ̀ ni Míríámù lọ pe ìyá rẹ̀ wá. Lẹ́yìn tí wọ́n dúnàádúrà, ó wá háyà Jókébédì láti tọ́jú ọmọ ara rẹ̀ lábẹ́ ààbò ọba.—Ẹ́kísódù 2:5-9.
Ẹ̀mí ìyọ́nú tí ọmọbìnrin ọba náà ní yàtọ̀ pátápátá sí ìwà òǹrorò bàbá rẹ̀. Kì í ṣe pé kò mọ bí ọmọ náà ṣe jẹ́. Àánú àtọkànwá ló sún un láti gbà á ṣọmọ. Bó sì ṣe gbà pé kí Hébérù kan tó jẹ́ olùṣètọ́jú bá òun tọ́jú rẹ̀ fi hàn pé kò fara mọ́ ẹ̀tanú bàbá rẹ̀.
Bá A Ṣe Tọ́ Ọ Dàgbà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Tó Gbà
Jókébédì “gbé ọmọ náà, ó sì ṣètọ́jú rẹ̀. Ọmọ náà sì dàgbà. Lẹ́yìn náà, ó mú un wá fún ọmọbìnrin Fáráò, ó sì tipa báyìí di ọmọkùnrin rẹ̀.” (Ẹ́kísódù 2:9, 10) Bíbélì kò sọ bí àkókò tí Mósè lò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ ṣe gùn tó. Àwọn kan sọ pé ó ní láti wà níbẹ̀ ó kéré tán títí di ìgbà tí wọ́n fi já a lẹ́nu ọmú—ìyẹn ọdún méjì sí mẹ́ta—àmọ́ ó ṣeé ṣe kó gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ́kísódù kò sọ ju pé ó “dàgbà” lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, èyí ò sì tọ́ka sí iye ọdún kan pàtó. Bó ti wù kó rí, ó dájú pé Ámúrámù àti Jókébédì ti ní láti lo àkókò yẹn láti jẹ́ kí ọmọ wọn mọ̀ pé Hébérù lòun, wọ́n á sì kọ́ ọ nípa Jèhófà pẹ̀lú. Ó dìgbẹ̀yìn ká tó mọ bí wọ́n ṣe kẹ́sẹ̀ járí tó nínú gbígbin ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ fún òdodo sọ́kàn Mósè.
Nígbà tí wọ́n dá a padà sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò, wọ́n kọ́ Mósè “nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n fún Mósè ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kó tóótun fún iṣẹ́ ìjọba. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ní Íjíbítì ni ẹ̀kọ́ ìṣirò, ìyàwòrán ilé, ìmọ̀ ìkọ́lé, àti àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kí ìdílé ọba fẹ́ kó gba ìtọ́ni nínú ìsìn àwọn ará Íjíbítì.
Ó lè jẹ́ Mósè àtàwọn ọmọ mìíràn láàfin ni wọ́n jọ gba ẹ̀kọ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí. Lára àwọn tí wọ́n máa ń gba irú ẹ̀kọ́ ńláńlá bẹ́ẹ̀ ni “ọmọ àwọn alákòóso láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n rán wá tàbí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn sí Íjíbítì kí ‘ojú wọn lè là,’ lẹ́yìn náà tí wọ́n á dá wọn padà láti lọ máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba dọ̀bọ̀sìyẹsà” fún Fáráò. (The Reign of Thutmose IV, látọwọ́ Betsy M. Bryan) Àwọn iléèwé àwọn ọmọdé tó wà láàfin jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń múra àwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀ láti sìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ láàfin.a Àwọn àkọsílẹ̀ kan tó ti wà láti sáà Agbedeméjì àti sáà Ìjọba Tuntun ti Íjíbítì fi hàn pé àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àtàwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba nígbà yẹn ṣì ń fi àpèlé náà “Ọmọ Iléèwé Àwọn Ọmọdé” yangàn, kódà nígbà tí wọ́n di àgbàlagbà.
Ìgbésí ayé láàfin yóò jẹ́ àdánwò fún Mósè. Ọrọ̀ á wà, afẹ́ á wà, agbára á sì wà. Àmọ́ ó lè ba ìwà rere rẹ̀ jẹ́. Báwo ni Mósè ṣe máa hùwà? Ta ni yóò jẹ́ olóòótọ́ sí? Nínú ọkàn rẹ̀ lọ́hùn-ún, ṣé olùjọsìn Jèhófà ni, àti arákùnrin àwọn Hébérù tí wọ́n ń ni lára, tàbí ńṣe ló tiẹ̀ wù ú láti máa gbádùn gbogbo afẹ́ tí ń bẹ ní Íjíbítì ilẹ̀ kèfèrí?
Ìpinnu Tó Ṣe Pàtàkì
Nígbà tí Mósè pé ẹni ogójì ọdún, lákòókò tó yẹ kó ti di ará Íjíbítì tán pátápátá, ó ‘jáde lọ láti lọ wo ẹrù ìnira táwọn arákùnrin rẹ̀ ń rù.’ Ohun tó ṣe lẹ́yìn ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe pé ó wulẹ̀ fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn; ó dìídì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ ni. Nígbà tó rí ará Íjíbítì kan tó ń lu Hébérù kan, ó dá sí i, ó sì pa aninilára náà. Ohun tó ṣe yẹn fi hàn pé ọkàn Mósè wà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ẹni tó kú yẹn jẹ́ onípò àṣẹ, tó pa níbi tó ti ń ṣe ojúṣe rẹ̀. Lójú àwọn ará Íjíbítì, kò sídìí kankan tí kò fi yẹ kí Mósè jẹ́ olóòótọ́ sí Fáráò. Síbẹ̀, ohun tó sún Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ fún ìdájọ́ òdodo, ànímọ́ tó wá hàn kedere nígbà tó bá Hébérù kan wí ní ọjọ́ kejì, níbi tíyẹn ti ń lu ẹnì kejì rẹ̀ láìnídìí. Mósè fẹ́ gba àwọn Hébérù sílẹ̀ nínú oko ẹrú bíbanilọ́kànjẹ́ tí wọ́n wà ni, àmọ́ nígbà tí Fáráò gbọ́ pé ó ti kẹ̀yìn sóun, tó sì fẹ́ pa á ni Mósè bá fẹsẹ̀ fẹ, ló bá lọ sí Mídíánì.—Ẹ́kísódù 2:11-15; Ìṣe 7:23-29.b
Àkókò tí Mósè fẹ́ gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ kò bá àkókò ti Jèhófà mu rárá. Síbẹ̀, àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Hébérù 11:24-26 sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè, nígbà tí ó dàgbà, fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Kí nìdí? “Nítorí pé ó ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì; nítorí tí ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” Lílo gbólóhùn pàtàkì náà “Kristi” tó túmọ̀ sí “ẹni àmì òróró,” bá Mósè mu wẹ́kú ní ti pé ó wá gba àkànṣe iṣẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà lẹ́yìn náà.
Ìwọ rò ó wò ná! Wọ́n tọ́ Mósè dàgbà lọ́nà tó jẹ́ pé kìkì ọ̀tọ̀kùlú ará Íjíbítì nìkan ni wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tọ́. Ipò tó wà fún un láǹfààní láti di èèyàn jàǹkàn, kó sì máa gbádùn bó ṣe fẹ́, síbẹ̀ ó kọ gbogbo ìyẹn sílẹ̀. Kò rí ohun tí ìgbésí ayé tí òun ń gbé nínú ààfin Fáráò aninilára fi bá ìfẹ́ tí òun ní fún Jèhófà àti fún ìdájọ́ òdodo mu. Ìmọ̀ tí Mósè ní àti bó ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá rẹ̀ Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ló jẹ́ kí ojú rere Ọlọ́run wù ú ju ohunkóhun mìíràn lọ. Nítorí ìdí èyí, Jèhófà lo Mósè fún iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì gan-an láti mú àwọn ète Rẹ̀ ṣẹ.
Gbogbo wa la dojú kọ yíyan ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú wa. Bíi ti Mósè, bóyá ìwọ náà fẹ́ ṣe ìpinnu kan tó ṣòro láti ṣe. Ǹjẹ́ o lè pa àwọn àṣà kan tì, tàbí kí o kọ àwọn àǹfààní kan sílẹ̀, láìka ohun tó lè ná ọ sí? Tó bá jẹ́ pé yíyàn tó dojú kọ ẹ́ nìyẹn, rántí pé Mósè ka jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà sí ohun tó ṣeyebíye ju gbogbo ìṣúra ilẹ̀ Íjíbítì, kò sì kábàámọ̀ rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ̀kọ́ yìí lè dà bí irú èyí tí Dáníẹ́lì àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbà kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìjọba ní Bábílónì. (Dáníẹ́lì 1:3-7) Fi wé ìwé Fiyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, orí kẹta, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
b Pé Mósè nítara fún ìdájọ́ òdodo tún hàn kedere nípa bó ṣe gbèjà àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí wọn ò rẹ́ni ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà táwọn kan ń fìyà jẹ wọ́n ní Mídíánì, níbi tó ti jẹ́ ìsáǹsá.—Ẹ́kísódù 2:16, 17.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Iṣẹ́ Abánitọ́mọ
Àwọn ìyá ló máa ń fún àwọn ọmọ wọn lọ́yàn mu. Àmọ́, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Brevard Childs, sọ nínú ìwé Journal of Biblical Literature pé, “nígbà mìíràn, àwọn ìdílé ọ̀tọ̀kùlú [ìhà Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn] máa ń háyà abánitọ́mọ. Àṣà yìí tún wọ́pọ̀ níbi tí ìyá náà ò bá ti lè tọ́jú ọmọ rẹ̀ tàbí níbi tí wọn ò bá ti mọ ìyá tó bí ọmọ náà. Ẹrù iṣẹ́ abánitọ́mọ náà ni pé kó tọ́jú ọmọ náà, kó sì máa fún un lọ́yàn mu láàárín àkókò tí wọ́n jọ fọwọ́ sí náà.” Àwọn ìwé kan tá a fi òrépèté ṣe láti ìhà Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ṣì wà títí di báyìí, tó sọ̀rọ̀ nípa àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn abánitọ́mọ. Àkọsílẹ̀ wọ̀nyí jẹ́rìí sí àṣà tó gbòde láti sáà àwọn ẹ̀yà Sumer títí di sáà àwọn Hélénì ní Íjíbítì. Àwọn apá tó wọ́pọ̀ jù nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ni ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ọ̀ràn kàn sọ, irú bí àkókò àdéhùn náà ti máa gùn tó, bí iṣẹ́ náà ṣe máa rí, ọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ, owó ìtanràn tí ẹnì kan kò bá mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ, owó iṣẹ́, àti bí wọ́n á ṣe máa san owó náà. Ọ̀gbẹ́ni Childs ṣàlàyé pé, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé “iṣẹ́ ìtọ́jú yìí máa ń gbà tó ọdún méjì sí mẹ́ta. Inú ilé abánitọ́mọ ló ti máa tọ́jú ọmọ náà, àmọ́ yóò máa mú ọmọ ọ̀hún lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ní in lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún àyẹ̀wò.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bí wọ́n ṣe ń yọ bíríkì ní Íjíbítì kò tíì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti ìgbà ayé Mósè, gẹ́gẹ́ bí àwòrán ìgbàanì ṣe fi hàn
[Àwọn Credit Line]
Lókè: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.; nísàlẹ̀: Erich Lessing/Art Resource, NY