Bí Àwọn Kan Ṣe Rí Ìdáhùn Gbà
Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn ló ń gbàdúrà. Ó dá àwọn kan lójú pé àdúrà àwọn ti gbà. Àwọn mìíràn ò tiẹ̀ lè sọ bóyá Ọlọ́run gbọ́ àdúrà àwọn rí. Síbẹ̀ àwọn kan ń wá ìdáhùn àmọ́ wọn ò ronú nípa sísọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún Ọlọ́run nínú àdúrà.
Bíbélì pe Ọlọ́run tòótọ́ náà ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Tó o bá ń gbàdúrà, ṣé ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run tòótọ́ lò ń darí àdúrà rẹ sí? Ṣé irú àwọn àdúrà tó máa ń gbọ́ lò ń gbà?
Ohun tó jẹ́ ìdáhùn ọ̀pọ̀ èèyàn sí ìbéèrè yìí lápá ibi gbogbo lágbàáyé ni bẹ́ẹ̀ ni! Báwo ni wọ́n ṣe rí ìdáhùn gbà? Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n kọ́?
Ta Ni Ọlọ́run?
Tọkàntọkàn ni olùkọ́ kan táwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtàwọn àlùfáà kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ Potogí fi ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀. Nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì náà wá yí padà tó pa àwọn àṣà àtijọ́ tì, èyí tí wọ́n ti fi kọ́ obìnrin yìí pé ó ṣe pàtàkì, ńṣe ni ọkàn rẹ̀ dà rú. Lílọ tó lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn ló jẹ́ kó mọ ọ̀nà táwọn ará Ìlà Oòrùn gbà ń jọ́sìn, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run tòótọ́ kan wà. Báwo ló ṣe yẹ kóun máa jọ́sìn? Nígbà tó béèrè ìbéèrè nípa àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì lọ́wọ́ àlùfáà rẹ̀, ńṣe nìyẹn kọtí ọ̀gbọn-in sí ìbéèrè rẹ̀, ọ̀rọ̀ yẹn sì kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a.
Ìjọ Kátólíìkì ti pín ìwé ìléwọ́ kékeré kan káàkiri ìlú olùkọ́ yìí tí wọ́n fi kìlọ̀ pé àwọn ọmọ ìjọ àwọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Àmọ́ àwọn ìbéèrè obìnrin náà ṣì ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí wá sílé rẹ̀, ó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́, ó sì fìfẹ́ hàn gan-an sí ohun tó gbọ́. Ìgbà àkọ́kọ́ tó máa bá wọn sọ̀rọ̀ nìyẹn.
Kí obìnrin yìí lè rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ní, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti bi wọ́n. Ó fẹ́ mọ orúkọ Ọlọ́run, ó fẹ́ mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, bóyá ó fọwọ́ sí lílo àwọn ère nínú ìjọsìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó rí i pé inú Bíbélì ni wọ́n ti ń mú gbogbo ìdáhùn náà jáde, pé kì í ṣe èrò ara wọn ni wọ́n ń sọ. Èyí yà á lẹ́nu gan-an, inú rẹ̀ sì ń dùn sí ohun tí wọ́n ń kọ́ ọ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbéèrè tó ní. Ó ti ń sin Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́ báyìí, gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe sọ pé àwọn “olùjọ́sìn tòótọ́” yóò ṣe.—Jòhánù 4:23.
Ní Sri Lanka, ìdílé kan wà níbẹ̀ tí wọ́n máa ń ka Bíbélì pa pọ̀ déédéé, àmọ́ wọn ò rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́, síbẹ̀ àlùfáà wọn ò lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wọn, wọ́n sì fún ìdílé náà láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó gbéṣẹ́ gan-an. Nígbà tó yá, ìdílé náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fún wọn lésì tó tẹ́ wọn lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tí wọ́n ń béèrè tó dá lórí Bíbélì. Ohun tí wọ́n kọ́ nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe dùn mọ́ wọn nínú gan-an ni.
Síbẹ̀, ohun tí wọ́n ti fi kọ́ ìyàwó láti kékeré ò jẹ́ kó gbà pé “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà” ni Baba Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe sọ ọ́. (Jòhánù 17:1, 3) Wọ́n ti kọ́ ọ láti kékeré pé ọgbọọgba ni Jésù àti Baba, àti pé “àwámáàrídìí” yìí kì í ṣe ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì nípa rẹ̀. Nítorí pé ó ní ọkàn tòótọ́, tí ò sì mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó pe orúkọ yẹn gan-an, ó sì ní kó ran òun lọ́wọ́ láti mọ ẹni tí Jésù jẹ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fara balẹ̀ yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa kókó yẹn wò lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 14:28; 17:21; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Ńṣe ló dà bíi pé ojú rẹ̀ tó ti fọ́ tẹ́lẹ̀ wá là gbòò, ó wá rí i kedere pé Jèhófà—Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé tó tún jẹ́ Baba Jésù Kristi—ni Ọlọ́run tòótọ́ náà.—Aísáyà 42:8; Jeremáyà 10:10-12.
Kí Ló Fa Ìjìyà?
Ìyà tó jẹ Jóòbù kọjá sísọ. Ìjì pa gbogbo ọmọ tó bí, ó sì di òtòṣì paraku. Àìsàn líle koko tún kọ lù ú, àwọn ọ̀rẹ́ èké ò sì jẹ́ kó rímú mí. Nígbà tí gbogbo èyí ń ṣẹlẹ̀, Jóòbù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tí ò yẹ kó sọ. (Jóòbù 6:3) Àmọ́ Ọlọ́run gba ti ipò tí Jóòbù wà rò. (Jóòbù 35:15) Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn Jóòbù, ó sì pèsè ìmọ̀ràn tí Jóòbù nílò. Ó ń ṣe ohun kan náà fáwọn èèyàn lóde òní pẹ̀lú.
Ní Mòsáńbíìkì, ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni Castro nígbà tí màmá rẹ̀ kú. Èyí dà á lọ́kàn rú gan-an. Ó wá ń béèrè pé: “Kí nìdí tó fi ní láti kú, tó sì fi wá sílẹ̀ lọ?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ló tọ́ ọ dàgbà, síbẹ̀ gbogbo nǹkan ló tojú sú u báyìí. Kí ló lè tù ú nínú táá sì tu ọkàn rẹ̀ lára? Ó rí ìtùnú nínú kíka Bíbélì kékeré kan tó jẹ́ ti èdè Chichewa, ó sì ń jíròrò ohun tó kà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Castro wá lóye pé kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn fẹ́ rẹ́ màmá òun jẹ ló ṣe jẹ́ kó kú, pé àìpé tá a ti jogún ló fà á. (Róòmù 5:12; 6:23) Ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde ló wá fún un ní ìtùnú tó ga jù lọ, nítorí pé ó rí i kà níbẹ̀ pé òun á tún rí màmá òun sójú lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ó bani nínú jẹ́ pé ọdún mẹ́rin péré lẹ́yìn ìyẹn ni bàbá rẹ̀ tún kú. Àmọ́ Castro ti wá ní ọkàn tó lè fi gba ọ̀ràn náà lákòókò yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà báyìí, ó sì ń fi ìṣòtítọ́ lo ìgbésí ayé rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ayọ̀ tó ti ní hàn kedere sí gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́n.
Ọ̀pọ̀ èèyàn táwọn èèyàn wọn ti kú ló rí ìtùnú nínú òtítọ́ Bíbélì kan náà tó tu Castro nínú. Àwọn kan tó ti fojú winá ìṣòro líle koko nítorí ìwà táwọn ẹni ibi hù sí wọn ń béèrè irú ìbéèrè kan náà tí Jóòbù béèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó?” (Jóòbù 21:7) Nígbà táwọn èèyàn bá dìídì fetí sílẹ̀ sí èsì tí Ọlọ́run fúnni nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n máa ń rí i pé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bójú tó àwọn nǹkan ń ṣe àwọn láǹfààní gan-an.—2 Pétérù 3:9.
Barbara, tí wọ́n tọ́ dàgbà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kò fìgbà kan gbé níbi tí ogun ti ń jà rí. Àmọ́ àtìgbà tó ti wà ní kékeré ni ogun ti ń jà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé. Ìròyìn nípa ìwà ìkà bíburú jáì táwọn èèyàn ń hù lójú ogun ló máa ń gbọ́ lójoojúmọ́. Nígbà tó wà nílé ìwé, ó máa ń bà á lọ́kàn jẹ́ láti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ìtàn fi hàn pé ó wáyé lọ́nà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Kí ló fà á? Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀? Ó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, àmọ́ èrò tó ní nípa rẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe sàn án.
Àmọ́, èrò tí Barbara ní nípa ìgbésí ayé wá ń yí padà díẹ̀díẹ̀ bó ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fetí sí wọn, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn. Ó wá sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó tiẹ̀ lọ sí ọkàn lára àwọn àpéjọ ńlá tí wọ́n máa ń ṣe. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún kíyè sí i pé èsì táwọn Ẹlẹ́rìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń fún òun kì í yàtọ̀ síra nígbà tóun bá bi wọ́n láwọn ìbéèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí náà máa ń sọ nítorí pé orí Bíbélì ni wọ́n gbé èrò wọn kà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tọ́ka sáwọn ẹ̀rí inú Bíbélì tó fi hàn pé Sátánì Èṣù tó jẹ́ alákòóso ayé yìí ló ń darí rẹ̀, àti pé ẹ̀mí rẹ̀ sì ni ayé ń fi hàn. (Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4; Éfésù 2:1-3; 1 Jòhánù 5:19) Wọ́n ṣàlàyé pé àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń da Barbara láàmù wà nínú Bíbélì. (Dáníẹ́lì, orí 2, 7, àti 8) Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn nítorí pé ó lágbára láti rí ọjọ́ iwájú nígbà tó bá wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run ló jẹ́ kí àwọn kan lára ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Àwọn mìíràn sì wà lára wọn tó kàn fàyè gbà láti ṣẹlẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún fi han Barbara pé Bíbélì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ rere àti búburú tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tá a wà yìí, ó sì tún sọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí fún wa. (Mátíù 24:3-14) Wọ́n fi àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe hàn án nípa ayé tuntun kan nínú èyí tí òdodo yóò ti borí, tí ìjìyà yóò sì di ohun àtijọ́.—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Barbara wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye pé lóòótọ́ ni kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé, síbẹ̀ kò dá a dúró nípa fífipá mú àwọn èèyàn láti ṣègbọràn sí àṣẹ òun nígbà tí wọ́n bá yàn láti ṣàìgbọràn. (Diutarónómì 30:19, 20) Ọlọ́run ti ṣètò tá a fi lè láyọ̀ títí láé, àmọ́ ó tún ń fún wa láǹfààní nísinsìnyí láti fi hàn bóyá a óò gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo òun. (Ìṣípayá 14:6, 7) Barbara wá pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run àti láti gbé níbàámu pẹ̀lú wọn. Ó tún rí i pé irú ìfẹ́ tí Jésù sọ pé yóò fi àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ hàn wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Jòhánù 13:34, 35.
Ìwọ náà lè jàǹfààní látinú àwọn ohun tó ràn án lọ́wọ́.
Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀
Kódà àwọn èèyàn tó dà bíi pé nǹkan ṣẹnuure fún lè wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń kọ wọ́n lóminú. Bí àpẹẹrẹ, Matthew, ọ̀dọ́mọkùnrin kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ti ń wá bóun ṣe lè mọ Ọlọ́run tòótọ́ àti ìdí téèyàn fi wà láyé. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Matthew nígbà tí bàbá rẹ̀ kú. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Matthew gboyè jáde nínú ìmọ̀ orin ní Yunifásítì. Lẹ́yìn náà ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé asán lórí asán ni kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Bó ṣe filé sílẹ̀ nìyẹn tó lọ ń gbé ní London, ibẹ̀ ló ti dẹni tó ń lo oògùn olóró, tó ń lọ sáwọn ilé ìgbafàájì alaalẹ́, ó ń wo ìràwọ̀, ó ń bẹ́mìí lò, ó sì ń kópa nínú ìmọ̀ Zen ti Ìsìn Búdà àtàwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí mìíràn—ó ṣe gbogbo èyí kó ṣáà lè rí ọ̀nà ìgbésí ayé tí yóò fún un láyọ̀. Níbi tí ọ̀ràn náà ká a lára dé, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti rí òtítọ́.
Ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìyẹn ni Matthew bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kan pàdé, tó sì ṣàlàyé ìṣòro tó ní fún un. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó sì fi ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:1-5 han Matthew, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un pé bí ayé yìí ṣe rí gẹ́lẹ́ ni Bíbélì ṣe sọ ọ́. Nígbà tó ka Ìwàásù Lórí Òkè, ìyẹn fà á lọ́kàn mọ́ra gan-an. (Mátíù, orí 5-7) Ó kọ́kọ́ ń lọ́ tìkọ̀ nítorí pé ó ti ka àwọn ìwé kan tó sọ ohun tí ò dáa nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ níkẹyìn ó pinnu láti máa wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó wà nítòsí rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tí Matthew ń gbọ́ níbẹ̀ múnú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọkàn lára àwọn alàgbà ìjọ náà. Ó wá rí i pé ohun tóun ti ń wá kiri gan-an ni wọ́n fi ń kọ́ òun, ìyẹn sì jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run. Ó jàǹfààní tó pọ̀ gan-an bó ṣe jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Ìbẹ̀rù àtọkànwá tó bẹ̀rẹ̀ sí í ní fún Ọlọ́run wá jẹ́ kó mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn àṣẹ Ọlọ́run mu. Matthew wá rí i pé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ló ní ìtumọ̀.—Oníwàásù 12:13.
A ò yàn án mọ́ Matthew àtàwọn mìíràn tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí pé wọ́n máa rí ọ̀nà ìgbésí ayé aláyọ̀. Ńṣe ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ní ète onífẹ̀ẹ́ kan tó fa gbogbo àwọn tó fi ìdùnnú yàn láti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Rẹ̀ mọ́ra. (Ìṣe 10:34, 35) Ìyè ayérayé nínú ayé tí kò ti ní sí ogun, tí kò ní sí àìsàn àti ebi—kódà tí ikú pàápàá ò ní sí níbẹ̀ wà lára ète yẹn. (Aísáyà 2:4; 25:6-8; 33:24; Jòhánù 3:16) Ṣé nǹkan tó o fẹ́ nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè mọ ọ̀nà tó o máa gbà gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ nípa wíwá sí àwọn ìpàdé tá a gbé karí Bíbélì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A ké sí ọ tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run, kó o lo orúkọ tó ń jẹ́ gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn tó dìídì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ kọ́ni
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Ẹni tó ń rìn ní òkè ńlá: Chad Ehlers/Index Stock Photography