Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí Bíbélì mẹ́nu kan nínú ìwé Ìṣípayá jẹ́ iye gidi kan, pé kì í ṣe ìṣàpẹẹrẹ?
Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì dì, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.” (Ìṣípayá 7:4) Àwọn tí gbólóhùn náà “àwọn tí a fi èdìdì dì,” ń tọ́ka sí nínú Bíbélì ni àwọn tá a yàn lára aráyé kí wọ́n lè bá Kristi ṣàkóso ní ọ̀run lé Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ lórí. (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22; Ìṣípayá 5:9, 10; 20:6) Àwọn ìdí bíi mélòó kan ló mú ká gbà pé iye gidi ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí jẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ìdí náà wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé Ìṣípayá 7:4.
Lẹ́yìn tá a sọ nípa àwọn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí fún àpọ́sítélì Jòhánù nínú ìràn, ó tún rí àwùjọ mìíràn. Jòhánù sọ pé àwùjọ kejì yìí jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ń tọ́ka sí àwọn tó máa la “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já, èyí tí yóò pa ayé búburú yìí run.—Ìṣípayá 7:9, 14.
Wá kíyè sí ìyàtọ̀ tí Jòhánù fi hàn pé ó wà nínú ẹsẹ kẹrin àti ìkẹsàn-án ìwé Ìṣípayá orí keje yìí. Ó sọ pé àwùjọ àkọ́kọ́, ìyẹn “àwọn tí a fi èdìdì dì,” ní iye pàtó kan. Àmọ́, àwùjọ kejì, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” kò ní iye pàtó kan. Nítorí ìdí yìí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé iye gidi ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́. Tí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bá jẹ́ iye ìṣàpẹẹrẹ tó ń tọ́ka sí àwùjọ kan tí iye wọn ò lóǹkà, á jẹ́ pé kò ní sí ìyàtọ̀ kankan láàárín ẹsẹ méjèèjì náà nìyẹn. Nítorí náà, àyíká ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn gbangba pé iye gidi ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́.
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ bíi mélòó kan tó ti kú àtàwọn tó ṣì wà láyé báyìí gbà pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí nìyẹn, pé iye gidi ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Ọ̀mọ̀wé Ethelbert W. Bullinger, ń ṣàlàyé Ìṣípayá 7:4, 9, ó sọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn pé: “Òtítọ́ tó lè tètè yéni lèyí jẹ́: pé iye kan tó ṣe pàtó la fi wé iye kan tí kò ṣe pàtó nínú orí kan náà yìí.” (Ìwé The Apocalypse or “The Day of the Lord,” ojú ìwé 282) Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Robert L. Thomas, Kékeré, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú Májẹ̀mú Tuntun ní Ilé Ẹ̀kọ́ The Master’s Seminary ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kọ̀wé pé: “Gbígbà pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́ iye ìṣàpẹẹrẹ kan kì í ṣe ohun tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.” Ó tún sọ pé: “Iye pàtó kan tó wà [nínú orí keje ẹsẹ kẹrin] yàtọ̀ sí iye tí kò ṣe pàtó nínú orí keje ẹsẹ ìkẹsàn-án. Tá a bá sọ pé ìṣàpẹẹrẹ ni iye yìí jẹ́, a jẹ́ pé kò sí iye kankan tá a máa gbà pé ó jẹ́ gidi nínú ìwé Ìṣípayá nìyẹn.”—Ìwé Revelation: An Exegetical Commentary, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 474.
Àwọn kan sọ pé níwọ̀n bí ìwé Ìṣípayá ti kún fún àwọn èdè tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ gan-an, gbogbo iye tó wà nínú ìwé yìí, títí kan ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ. (Ìṣípayá 1:1, 4; 2:10) Àmọ́, ó ṣe kedere pé irú èrò yẹn kò tọ̀nà. Lóòótọ́, Ìṣípayá kún fún ọ̀pọ̀ iye tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ, àmọ́ àwọn iye tó jẹ́ gidi tún wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa “orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 21:14) Láìsí àní-àní, iye gidi ni méjìlá tá a mẹ́nu kàn nínú ẹsẹ yìí, kì í ṣe ìṣàpẹẹrẹ. Síwájú sí i, àpọ́sítélì Jòhánù tún kọ̀wé nípa “ẹgbẹ̀rún ọdún” ìṣàkóso Kristi. Iye gidi ni ìyẹn náà tún jẹ́, gẹ́gẹ́ bí àyẹ̀wò kínníkínní tá a ṣe nínú Bíbélì ṣe fi hàn.a (Ìṣípayá 20:3, 5-7) Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àtèyí tó yí iye kan ká nínú ìwé Ìṣípayá lá ó fi mọ̀ bóyá iye náà jẹ́ iye gidi tàbí bóyá ó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ.
Bá a ṣe sọ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́ iye gidi kan tó tọ́ka sí iye àwọn èèyàn tí kò pọ̀, tí wọ́n jẹ́ àwùjọ kékeré tá a bá fi wọ́n wé “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tún bá ohun tí Bíbélì sọ níbòmíràn mu. Bí àpẹẹrẹ, ní apá ìparí ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí yẹn, a ṣàpèjúwe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì níbẹ̀ pé àwọn ni “a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so.” (Ìṣípayá 14:1, 4) Ọ̀rọ̀ náà “àkọ́so,” ń tọ́ka sí àwọn kéréje tá a yàn. Bákan náà, nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ nípa àwọn tí yóò bá òun ṣàkóso nínú Ìjọba òun lọ́run, ó sì pè wọ́n ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32; 22:29) Dájúdájú, àwọn tó máa ṣàkóso ní ọ̀run tá a mú látara aráyé kéré níye tá a bá fi wọ́n wé iye àwọn tó máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 7:4 àtàwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó fara pẹ́ ẹ tá a rí láwọn apá ibòmíràn nínú Bíbélì fi hàn kedere pé iye gidi ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́. Ó tọ́ka sí àwọn tí yóò wà pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run tí wọn yóò si jùmọ̀ ṣàkóso lé Párádísè ilẹ̀ ayé lórí, ìyẹn Párádísè tí yóò kún fún àwọn èèyàn púpọ̀ rẹpẹtẹ, tí iye wọn ò lóǹkà, tí wọ́n jẹ́ èèyàn aláyọ̀ tó ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run.—Sáàmù 37:29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí ìsọfúnni síwájú sí i lórí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, wo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ìwé 289 àti 290. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]
A fi iye àwọn tó ń lọ sí ọ̀run mọ sí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Iye àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kò lóǹkà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn ìràwọ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, fọ́tò látọwọ́ David Malin