ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 21
Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Nípa Ọjọ́ Iwájú
“Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”—ÌFI. 22:20.
ORIN 142 Ká Jẹ́ Kí Ìrètí Wa Lágbára
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ìpinnu pàtàkì wo ló yẹ kí gbogbo èèyàn ṣe?
LÓNÌÍ, ìpinnu pàtàkì kan wà tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Ìpinnu náà ni pé, ṣé Jèhófà Ọlọ́run Alákòóso ayé àtọ̀run ni wọ́n máa tì lẹ́yìn ni àbí Sátánì Èṣù ọ̀tá rẹ̀ tó burú jù lọ? Ìkan nínú méjèèjì lèèyàn gbọ́dọ̀ mú. Ìpinnu tí wọ́n bá ṣe ló máa sọ bóyá wọ́n á wà láàyè títí láé tàbí wọ́n á pa run. (Mát. 25:31-33, 46) Nígbà “ìpọ́njú ńlá,” wọ́n máa sàmì sí wọn kí wọ́n lè la ìpọ́njú náà já tàbí kí wọ́n pa run.—Ìfi. 7:14; 14:9-11; Ìsík. 9:4, 6.
2. (a) Kí ni Hébérù 10:35-39 sọ fún wa pé ká ṣe? (b) Báwo ni ìwé Ìfihàn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?
2 Ka Hébérù 10:35-39. Tó bá jẹ́ pé àkóso Jèhófà lo tì lẹ́yìn, ìpinnu tó dáa lo ṣe yẹn. Torí náà, ó yẹ kó o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè ṣe irú ìpinnu yẹn. Kó o bàa lè ṣe bẹ́ẹ̀, fi ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìwé yẹn jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ta ko Jèhófà, ó sì tún sọ àwọn ohun rere táwọn tó ń ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn máa gbádùn. Kò yẹ ká gbàgbé àwọn òtítọ́ pàtàkì yẹn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, a lè lo ohun tá a kọ́ nínú ìwé náà láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà, kí wọ́n má sì fi í sílẹ̀.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Àwọn ohun rere wo làwọn tó ń ti àkóso Ọlọ́run lẹ́yìn máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ìwé Ìfihàn sọ?
KÍ NI ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́ MÁA GBÁDÙN LỌ́JỌ́ IWÁJÚ?
4. Àwọn wo ni àpọ́sítélì Jòhánù rí lọ́dọ̀ Jésù lọ́run?
4 Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwùjọ méjì tó ń ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn, wọ́n sì rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). (Ìfi. 7:4) Ọlọ́run mú wọn látinú aráyé kí wọ́n lè bá Jésù jọba lọ́run. Àwọn àti Jésù máa ṣàkóso ayé látọ̀run. (Ìfi. 5:9, 10; 14:3, 4) Nínú ìran yẹn, Jòhánù rí i pé wọ́n dúró lọ́dọ̀ Jésù lórí Òkè Síónì.—Ìfi. 14:1.
5. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó wà láyé?
5 Láti ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run ti ń yan ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. (Lúùkù 12:32; Róòmù 8:17) Àmọ́ Jòhánù sọ pé díẹ̀ lára wọn ló máa ṣẹ́ kù láyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. “Àwọn tó ṣẹ́ kù” náà máa gba “èdìdì” ìkẹyìn kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀, ìyẹn lá fi hàn pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n. (Ìfi. 7:2, 3; 12:17) Lẹ́yìn náà, Jèhófà máa kó àwọn tó ṣẹ́ kù náà lọ sọ́run nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tó kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú, tí wọ́n sì ti wà lọ́run. Gbogbo wọn máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run.—Mát. 24:31; Ìfi. 5:9, 10.
6-7. (a) Àwọn wo ni Jòhánù tún rí, kí ni Bíbélì sì sọ nípa wọn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù àti “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà máa retí ìgbà tí ohun tó wà nínú Ìfihàn orí 7 máa ṣẹ?
6 Lẹ́yìn tí Jòhánù rí àwọn tó wà lọ́run, ó tún rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” Wọn ò dà bí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) torí pé Bíbélì ò sọ iye wọn. (Ìfi. 7:9, 10) Kí ni Bíbélì sọ nípa wọn? Jòhánù sọ pé: “Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfi. 7:14) Tí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” náà bá ti la ìpọ́njú ńlá já, wọ́n á máa gbé ayé, wọ́n á sì máa gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí Ọlọ́run pèsè.—Sm. 37:9-11, 27-29; Òwe 2:21, 22; Ìfi. 7:16, 17.
7 Bóyá Ọlọ́run yàn wá pé ká lọ sí ọ̀run tàbí ká máa gbé ayé, ṣé a gbà pé a máa wà níbẹ̀ nígbà táwọn nǹkan tó wà nínú ìwé Ìfihàn orí 7 yẹn bá ṣẹ? Ó yẹ ká wà níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé àkókò aláyọ̀ nìgbà yẹn máa jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó máa gbé ọ̀run àtàwọn tó máa gbé ayé! Inú wa máa dùn gan-an pé a ti àkóso Jèhófà lẹ́yìn. Àmọ́, àwọn nǹkan míì wo ni ìwé Ìfihàn sọ nípa ìpọ́njú ńlá náà?—Mát. 24:21.
KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ SÁWỌN TÓ Ń TA KO ỌLỌ́RUN?
8. Báwo ni ìpọ́njú ńlá ṣe máa bẹ̀rẹ̀, kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa ṣe?
8 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn ìjọba ayé máa tó gbéjà ko Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé yìí. (Ìfi. 17:16, 17) Ìgbésẹ̀ yẹn ló máa fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀. Ṣé ìyẹn á wá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá jọ́sìn Jèhófà? Rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìfihàn orí 6 sọ pé ní àkókò yẹn, gbogbo àwọn tí ò jọ́sìn Jèhófà máa wá ààbò lọ sọ́dọ̀ ètò òṣèlú àti ètò ìṣòwò ayé yìí, àwọn ètò yẹn ni ìwé Ìfihàn pè ní àwọn òkè. Alátakò ni Jèhófà sì máa kà wọ́n sí torí pé wọn ò ti Ìjọba ẹ̀ lẹ́yìn.—Lúùkù 11:23; Ìfi. 6:15-17.
9. Kí ló máa mú káwọn èèyàn Jèhófà dá yàtọ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀?
9 Ó dájú pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa dá yàtọ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá. Ìdí ni pé àwọn nìkan lá máa jọ́sìn Jèhófà láyé, wọn ò sì ní ti “ẹranko náà” lẹ́yìn. (Ìfi. 13:14-17) Nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ìyẹn máa múnú bí àwọn tó ń ta ko Jèhófà. Torí náà, gbogbo orílẹ̀-èdè máa kóra jọ láti gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé. Ìbínú burúkú yìí ni Bíbélì pè ní ìkọlù látọ̀dọ̀ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.—Ìsík. 38:14-16.
10. Bí Ìfihàn 19:19-21 ṣe sọ, kí ni Jèhófà máa ṣe tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀?
10 Kí ni Jèhófà máa ṣe tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀? Ó sọ pé: “Inú á bí mi gidigidi.” (Ìsík. 38:18, 21-23) Ìfihàn orí 19 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Jèhófà máa rán Ọmọ rẹ̀ láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, kó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ ogun ọ̀run,” ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ja ogun náà. (Ìfi. 17:14; 19:11-15) Kí ni ogun náà máa yọrí sí? Gbogbo àwọn tó ń ta ko Jèhófà máa pa run pátápátá!—Ka Ìfihàn 19:19-21.
ÌGBÉYÀWÓ KAN WÁYÉ LẸ́YÌN TÍ OGUN NÁÀ PARÍ
11. Ohun pàtàkì wo ló ṣẹlẹ̀ nínú ìwé Ìfihàn?
11 Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn olóòótọ́ tó máa là á já nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá pa run! Àkókò ayọ̀ nìyẹn máa jẹ́! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ariwo ayọ̀ má sọ lọ́run nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ohun míì máa ṣẹlẹ̀ tó máa mú ayọ̀ tó ju ìyẹn lọ wá. (Ìfi. 19:1-3) Nǹkan náà ni “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ó sì wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nínú ìwé Ìfihàn.—Ìfi. 19:6-9.
12. Ìgbà wo ni Ìfihàn 21:1, 2 sọ pé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣègbéyàwó?
12 Ìgbà wo ni ìgbéyàwó náà máa wáyé? Gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa ti wà lọ́run kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà yẹn ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣègbéyàwó. (Ka Ìfihàn 21:1, 2.) Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa wáyé lẹ́yìn tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá ti parí, tí Ọlọ́run sì ti pa gbogbo àwọn ọ̀tá ẹ̀ run.—Sm. 45:3, 4, 13-17.
13. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?
13 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà? Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ọkùnrin kan àti obìnrin kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ níbi ìgbéyàwó ìṣàpẹẹrẹ yìí. Jèhófà máa so Jésù Kristi Ọba àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì “ìyàwó” rẹ̀ pọ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí ló máa mú kí ìjọba tuntun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún.—Ìfi. 20:6.
ÌLÚ OLÓGO ÀTI ỌJỌ́ Ọ̀LA RẸ
14-15. Kí ni Ìfihàn orí 21 fi àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà wé? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
14 Lẹ́yìn ìyẹn, Ìfihàn orí 21 fi àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì wé ìlú kan tó rẹwà, ó pe ìlú náà ní “Jerúsálẹ́mù Tuntun.” (Ìfi. 21:2, 9) Ìlú náà ní òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá tí wọ́n kọ “orúkọ méjìlá (12) àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” sí. Kí nìdí tí ohun tí Jòhánù rí fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn? Ìdí ni pé ó rí orúkọ rẹ̀ lára ọ̀kan nínú àwọn òkúta náà. Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run dá a lọ́lá gan-an!—Ìfi. 21:10-14; Éfé. 2:20.
15 Kò sí ìlú míì tó dà bí ìlú yìí. Ògidì wúrà ni wọ́n fi ṣe ojú ọ̀nà ẹ̀, ó ní ẹnubodè méjìlá tí wọ́n fi péálì ṣe, oríṣiríṣi òkúta iyebíye ni wọ́n fi ṣe àwọn ìpìlẹ̀ àti ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́, igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìlú náà sì dọ́gba. (Ìfi. 21:15-21) Síbẹ̀, ohun kan wà tí ò sí níbẹ̀! Ẹ gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ lẹ́yìn náà, ó ní: “Mi ò rí tẹ́ńpìlì kankan nínú rẹ̀, torí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìlú náà ò nílò kí oòrùn tàbí òṣùpá tàn sórí rẹ̀, torí ògo Ọlọ́run mú kó mọ́lẹ̀ rekete, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ni fìtílà rẹ̀.” (Ìfi. 21:22, 23) Àwọn tó jẹ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun náà máa láǹfààní láti máa rí Jèhófà. (Héb. 7:27; Ìfi. 22:3, 4) Torí náà, Jèhófà àti Jésù ni tẹ́ńpìlì ìlú náà.
16. Àwọn ohun rere wo ni aráyé máa gbádùn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Ọlọ́run?
16 Inú àwọn ẹni àmì òróró á máa dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń ronú nípa ìlú yìí. Síbẹ̀, ó yẹ kó máa múnú àwọn tó nírètí àtigbé ayé náà dùn. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Ọlọ́run, Jerúsálẹ́mù Tuntun náà máa mú ọ̀pọ̀ ohun rere wá fún aráyé. Jòhánù rí “odò omi ìyè” tó ń ṣàn jáde, èyí tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun rere náà. “Àwọn igi ìyè” wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà, ewé àwọn igi náà sì ń mú “àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.” (Ìfi. 22:1, 2) Gbogbo àwọn tó bá wà láàyè nígbà yẹn ló máa láǹfààní láti gbádùn àwọn ohun rere yìí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà máa di ẹni pípé. Kò ní sí àìsàn, ìrora àti igbe ẹkún mọ́.—Ìfi. 21:3-5.
17. Àwọn wo ni Ìfihàn 20:11-13 sọ pé wọ́n máa jàǹfààní Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?
17 Àwọn wo ló máa jàǹfààní àwọn ohun rere yìí? Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó la Amágẹ́dọ́nì já àtàwọn ọmọ tí wọ́n bá bí nínú ayé tuntun. Lẹ́yìn náà, Ìfihàn orí 20 ṣèlérí pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde. (Ka Ìfihàn 20:11-13.) Torí náà, gbogbo àwọn “olódodo” tí wọ́n ti kú àtàwọn “aláìṣòdodo” tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ló máa jíǹde sí ayé. (Ìṣe 24:15; Jòh. 5:28, 29) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó bá kú ló máa jíǹde sí ayé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà? Rárá o. Àwọn tó bá ṣorí kunkun pé àwọn ò ní sin Jèhófà kí wọ́n tó kú ò ní jíǹde. Wọ́n láǹfààní láti sin Jèhófà, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe fi hàn pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó máa gbé ayé nínú Párádísè.—Mát. 25:46; 2 Tẹs. 1:9; Ìfi. 17:8; 20:15.
ÀDÁNWÒ ÌKẸYÌN
18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láyé níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà?
18 Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà bá máa fi parí, gbogbo àwọn tó ń gbé ayé á ti di ẹni pípé. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ò ní mú kí ẹnikẹ́ni dẹ́ṣẹ̀ mọ́. (Róòmù 5:12) Ègún tó wà lórí aráyé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ò ní sí mọ́. Ìyẹn ló máa mú kí àwọn èèyàn tó ń gbé ayé “pa dà wà láàyè,” kí wọ́n sì di ẹni pípé níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà.—Ìfi. 20:5.
19. Kí nìdí tó fi pọn dandan kí àdánwò ìkẹyìn wà?
19 A mọ̀ pé nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, tó fẹ́ kó di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, Jésù ò gbà fún un torí ó jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́ ṣé gbogbo àwọn ẹni pípé ló máa jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí Jèhófà bá gba Sátánì láyè láti dán wọn wò? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tí wọ́n bá tú Sátánì sílẹ̀ nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níparí ẹgbẹ̀rún ọdún náà. (Ìfi. 20:7) Àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn yìí máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n á sì ní òmìnira tòótọ́ títí láé. (Róòmù 8:21) Jèhófà máa pa gbogbo àwọn tó bá ṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run pátápátá.—Ìfi. 20:8-10.
20. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn tó wà nínú ìwé Ìfihàn ṣe rí lára ẹ?
20 Báwo ló ṣe rí lára ẹ lẹ́yìn tó o kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìfihàn? Ṣé inú ẹ ò máa dùn nígbà tó o rí i pé ìwọ náà wà lára àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ náà ń ṣẹ sí lára? Ṣé àwọn nǹkan tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ yìí ò mú kó túbọ̀ wù ẹ́ láti pe àwọn míì pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run? (Ìfi. 22:17) Bí àwọn nǹkan alárinrin tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú yìí ṣe ń mú ọkàn wa yọ̀, ó dájú pé á wu àwa náà láti sọ ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”—Ìfi. 22:20.
ORIN 27 Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn rèé nínú àwọn àpilẹ̀kọ tá a fi ṣàlàyé ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn. Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà máa gbádùn ohun rere lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, àwọn tó ń ta ko àkóso Ọlọ́run máa pa run.