Ẹ Jẹ́ Kí Inú Yín Máa Dùn Pé Kristẹni Ni Yín!
“Ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Jèhófà.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 1:31.
1. Irú ẹ̀mí wo ló hàn gbangba pé àwọn èèyàn ní sí ìsìn?
LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan tó máa ń sọ ohun tó ń lọ nípa ìsìn sọ pé, láwọn ibì kan láyé, ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́sìn ní sí ẹ̀sìn wọn ti di tútù. Nínú àlàyé tó ṣe, ó sọ pé: “Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìsìn òde òní, tó sì hàn kedere sáwọn èèyàn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìtẹ̀síwájú nípa ìjọsìn rárá bí kò ṣe ẹ̀mí ìdágunlá táwọn èèyàn ní sí ẹ̀sìn.” Ó ṣàlàyé pé ẹ̀mí ìdágunlá yìí ò jẹ́ káwọn èèyàn fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn mọ́. Ọkùnrin náà sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló “gbà pé Ọlọ́run wà . . . àmọ́ wọn ò bìkítà nípa rẹ̀.”
2. (a) Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé àwọn èèyàn ní ẹ̀mí ìdágunlá sí nǹkan tẹ̀mí? (b) Ewu wo ló wà níbẹ̀ tí ìfẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ bá lọ di tútù?
2 Kò ya àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu pé àwọn èèyàn ní ẹ̀mí ìdágunlá sí ìsìn. (Lúùkù 18:8) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ ìsìn, èèyàn ò lè fẹ́ irú ẹ̀mí yìí kú. Ọjọ́ pẹ́ tí ìsìn èké ti ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà tí wọ́n sì ti ń ṣe àwọn ohun téèyàn ò retí pé ó lè máa ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀sìn. (Ìṣípayá 17:15, 16) Àmọ́, ewu ńlá ló máa yọrí sí tí ìfẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ bá lọ di tútù tàbí tí wọn ò nítara bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kò ní dára rárá tá ò bá fọwọ́ pàtàkì mú ìgbàgbọ́ wa tàbí tí ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti fún òtítọ́ Bíbélì bá lọ dín kù. Jésù fi hàn pé irú ìwà yẹn kò dára nígbà tó kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó ń gbé nílùú Laodíkíà pé: ‘O kò tutù bẹ́ẹ̀ ni o kò gbóná. Èmi ì bá fẹ́ kí o tutù tàbí kẹ̀ kí o gbóná, àmọ́ o lọ́wọ́ọ́wọ́.’—Ìṣípayá 3:15-18.
Mímọ Irú Ẹni Tá A Jẹ́
3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó fi wá hàn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó sì yẹ kó máa múnú wa dùn?
3 Káwọn Kristẹni tó lè borí ẹ̀mí ìdágunlá, wọ́n ní láti mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́, kí inú wọn sì máa dùn nítorí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Tá a bá sì wo inú Bíbélì, a óò rí irú ẹni tí Bíbélì sọ pé àwa tí í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà tá a sì tún jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi jẹ́. “Ẹlẹ́rìí” Jèhófà ni wá, a sì tún jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere” fáwọn èèyàn. (Aísáyà 43:10; 1 Kọ́ríńtì 3:9; Mátíù 24:14) A ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòhánù 13:34) Kristẹni tòótọ́ ni àwọn tó “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) “Atànmọ́lẹ̀ nínú ayé” ni wá. (Fílípì 2:15) A sì ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ‘ìwà wa dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’—1 Pétérù 2:12; 2 Pétérù 3:11, 14.
4. Báwo ni ẹnì kan tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tóun kì í ṣe?
4 Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn tún mọ irú èèyàn tí wọn kì í ṣe. “Wọn kì í ṣe apá kan ayé,” bí Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá wọn kì í ti í ṣe apá kan ayé. (Jòhánù 17:16) Wọn kì í ṣe ara “àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n wà “nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.” (Éfésù 4:17, 18) Èyí ló mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé . . . láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.
5. Kí lohun tí ọ̀rọ̀ ìṣítí tó ní ká máa “ṣògo nínú Jèhófà” túmọ̀ sí?
5 Mímọ̀ tá a mọ irú ẹni tá a jẹ́ àti àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọba Aláṣẹ àgbáyé ń mú ká máa “ṣògo nínú Jèhófà.” (1 Kọ́ríńtì 1:31) Àmọ́, ọ̀nà wo la gbà ń ṣògo? Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, inú wa ń dùn pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa. À ń tẹ́ lè ọ̀rọ̀ ìṣítí náà pé: “Kí ẹni tí ń fọ́nnu nípa ara rẹ̀ fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ohun yìí gan-an, níní tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye àti níní tí ó ní ìmọ̀ mi, pé èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 9:24) Mímọ̀ tá a mọ Ọlọ́run àti bó ṣe ń lò wá láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ló mú ká máa “ṣògo.”
Ìṣòro Tó Wà Níbẹ̀
6. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn Kristẹni kan láti fi hàn pé àwọn yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé?
6 Ká sòótọ́, ìgbà mìíràn wà tí kì í rọrùn fún àwa Kristẹni láti fi hàn pé a yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn ayé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé Kristẹni rántí ìgbà kan tóun ò ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí. Ó ní: “Ìgbà míì wá ti màá kàn ronú lọ títí láìní mọ ohun tó mú kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àtikékeré ni mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì. Àmọ́, nígbà míì, ńṣe ni mo máa ń wo ìsìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára àwọn ìsìn ńláńlá tó wà nínú ayé.” Àwọn eré ìnàjú inú ayé, àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ìwàkiwà ti mú káwọn kan sọ ìwà Kristẹni wọn nù. (Éfésù 2:2, 3) Àwọn Kristẹni kan lè máa ṣiyèméjì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí kí wọ́n máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì máa ronú àtiyí ohun tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀ padà.
7. (a) Irú àyẹ̀wò wo ló yẹ kí olúkúlùkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe nípa ara rẹ̀? (b) Ibo sì níṣòro wà?
7 Ǹjẹ́ ó burú téèyàn bá ń yẹ ara rẹ̀ wò látìgbàdégbà? Rárá o. Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa yẹ ara wọn wò. Ó ní: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ohun tí àpọ́sítélì yìí ń sọ nínú ẹsẹ yẹn ni pé káwọn Kristẹni máa yẹ ara wọn wò látòkèdélẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n ní kùdìẹ̀-kudiẹ èyíkéyìí nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Nígbà tí Kristẹni kan bá ń dán ara rẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá òun wà nínú ìgbàgbọ́, ó yẹ kó rí i dájú pé ọ̀rọ̀ ẹnu òun àti ìṣe òun bá àwọn nǹkan tóun gbà gbọ́ mu. Àmọ́, tá ò bá ṣe àyẹ̀wò ọ̀hún bí ẹni tẹ̀mí, tó jẹ́ pé irú èèyàn tá a jẹ́ láwùjọ là ń ronú nípa rẹ̀ tàbí tá a lọ ń wá ojútùú sí ìṣòro wa lọ́nà tí kò bá òfin Jèhófà àti ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nínú ìjọ Kristẹni mu, èyí lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí.a Ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ kí “ọkọ̀ ìgbàgbọ́” wa rì!—1 Tímótì 1:19.
Àwa Kristẹni Náà Máa Ń Ṣiyèméjì
8, 9. (a) Kí ni Mósè sọ tó fi hàn pé kò dá ara rẹ̀ lójú? (b) Kí ni Jèhófà sọ fún Mósè nígbà tí Mósè ò dá ara rẹ̀ lójú? (d) Báwo ni àwọn ìlérí Jèhófà ṣe rí lára rẹ?
8 Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn Kristẹni tó máa ń ronú nígbà míì pé àwọn ò tóótun rò pé àwọn ò wúlò fún ohunkóhun? Rárá o! Ọ̀rọ̀ ìtùnú ló jẹ́ fún wọn láti mọ̀ pé kì í ṣe àwọn nìkan ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Ó ṣẹlẹ̀ sáwọn olóòótọ́ ẹlẹ́rìí Ọlọ́run láyé àtijọ́ pẹ̀lú. Àpẹẹrẹ kan ni ti Mósè. Mósè jẹ́ ẹnì kan tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ó jẹ́ adúróṣinṣin àti olùfọkànsìn. Àmọ́ nígbà tí Mósè gba iṣẹ́ kan tó dà bíi pé ó kà á láyà, ó fìtìjú béèrè pé: “Ta ni èmi?” (Ẹ́kísódù 3:11) Ó dájú pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé, ‘Èmi tí kò já mọ́ nǹkan kan!’ tàbí ‘Mi ò tó ẹni tó lè ṣe iṣẹ́ yìí!’ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú ẹni tí Mósè jẹ́ látilẹ̀wá ló mú kó máa ronú lọ́nà yẹn. Ọmọ orílẹ̀ èdè kan tí wọ́n jẹ́ ẹrú ni. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti pa á tì. Kì í tún ṣe sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́. (Ẹ́kísódù 1:13, 14; 2:11-14; 4:10) Iṣẹ́ darandaran ló ń ṣe. Èèyàn rádaràda sì làwọn ará Íjíbítì ka ẹni tó bá ń ṣe irú iṣẹ́ yìí sí. (Jẹ́nẹ́sísì 46:34) Abájọ tó fi rò pé òun ò tóótun láti gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ lóko ẹrú!
9 Jèhófà fọkàn Mósè balẹ̀ nípa ṣíṣe ìlérí méjì tó lágbára fún un pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, èyí sì ni àmì fún ọ pé èmi ni ó rán ọ: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní Íjíbítì, ẹ ó sin Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè ńlá yìí.” (Ẹ́kísódù 3:12) Ọlọ́run ń sọ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń lọ́ tìkọ̀ yìí pé òun ò ní fi í sílẹ̀ nígbà kankan. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà jẹ́ kó mọ̀ pé òun yóò dá àwọn èèyàn òun nídè. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni Ọlọ́run ti máa ń ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè sọ fún orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.” (Diutarónómì 31:6) Jèhófà fí Jóṣúà náà lọ́kàn balẹ̀, ó sọ fún un pé: ‘Ẹnikẹ́ni kì yóò mú ìdúró gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. . . . Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Èmi kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.’ (Jóṣúà 1:5) Ó tún ṣèlérí fáwọn Kristẹni pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Ńṣe ló yẹ kí wíwà tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa yìí máa múnú wa dùn pé a jẹ́ Kristẹni!
10, 11. Báwo ni ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Ásáfù ṣe rí ìrànlọ́wọ́ gbà tó fi wá ní èrò tó yẹ nípa àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà?
10 Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn ikú Mósè, ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Ásáfù sọ bọ́rọ̀ ara rẹ̀ ṣe rí gan-an. Ó sọ pé òun máa ń ṣiyèméjì nípa àǹfààní tó wà nínú gbígbé ìgbésí ayé tó múnú Ọlọ́run dùn. Bí Ásáfù ṣe ń sapá lójú méjèèjì láti sin Ọlọ́run láìfi àdánwò àti ìdẹkùn pè, bẹ́ẹ̀ ló ń rí àwọn tó ń fi Ọlọ́run ṣẹ̀sín tí wọ́n ń gbèrú sí i, tí nǹkan sì túbọ̀ ń ṣẹnuure fún wọn. Báwo lèyí ṣe rí lára Ásáfù? Ó jẹ́wọ́ bó ṣe rí, ó ní: “Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà, díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́. Nítorí ti èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá làǹfààní kankan tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa jọ́sìn Jèhófà. Ásáfù ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀. Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 73:2, 3, 13, 14.
11 Kí ni Ásáfù wá ṣe nípa ọ̀ràn tó ń dà á lọ́kàn rú yìí? Ǹjẹ́ ó bò ó mọ́ra síbẹ̀? Rárá o. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí ọ̀ràn náà gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú Sáàmù Kẹtàléláàádọ́rin. Ásáfù ṣe àtúnṣe sí ìrònú rẹ̀ nígbà tó lọ sí tẹ́ńpìlì. Ibẹ̀ ló ti wá mọ̀ dájú pé kò sóhun tá a lè fi wé kéèyàn máa sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. Ní báyìí tó ti túbọ̀ mọyì nǹkan tẹ̀mí, ó wá rí i pé Jèhófà kórìíra ìwà tí kò dára àti pé yóò fìyà jẹ àwọn ẹni ibi nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. (Sáàmù 73:17-19) Nípa báyìí, inú Ásáfù túbọ̀ dùn jọjọ nítorí àǹfààní tó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.” (Sáàmù 73:23, 24) Inú Ásáfù wá dùn gan-an pé òun ń sin Ọlọ́run.—Sáàmù 34:2.
Wọ́n Ò Ṣiyèméjì Rárá Nípa Irú Ẹni Tí Wọ́n Jẹ́
12, 13. Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ àwọn èèyàn inú Bíbélì tí inú wọn dùn nítorí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run.
12 Ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa hùwà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́ nígbà gbogbo ni pé ká máa ronú nípa ìgbésí ayé àwọn olùjọ́sìn tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì máa fara wé wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùjọ́sìn tá a ní ká máa fára wé yìí níṣòro tó lékenkà, síbẹ̀ inú wọn ń dùn nítorí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Wo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, ọmọ Jákọ́bù. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n tà á sóko ẹrú, ó sì lọ bára ẹ̀ nílùú Íjíbítì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà ni Íjíbítì wà sí ilé bàbá rẹ̀ tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ ló ti lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Lákòókò tí Jósẹ́fù fi wà ní Íjíbítì, kò séèyàn kankan tó lè fún Jósẹ́fù nímọ̀ràn rere, ọ̀pọ̀ ìṣòro ló sì dojú kọ ọ́ tó dán ìwà rẹ̀ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Ọlọ́run wò. Àmọ́, ó sapá gidigidi láti fi hàn pé lóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lòun, kò sì yéé ṣe ohun tó mọ̀ pé ó tọ̀nà. Inú rẹ̀ dùn pé òun jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà kódà láàárín àwọn èèyàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, kò sì lọ́ tìkọ̀ láti sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-10.
13 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn àkókò ti Jósẹ́fù, wọ́n mú ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan lọ sígbèkùn, ó sì di ẹrú fún Náámánì tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà. Ọmọbìnrin yìí ò gbàgbé pé olùjọ́sìn Jèhófà lòun. Nígbà tó láǹfààní láti wàásù, ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà nígbà tó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wòlíì Ọlọ́run tòótọ́ ni Èlíṣà jẹ́. (2 Àwọn Ọba 5:1-19) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jòsáyà Ọba ṣe àtúntò ìjọsìn, ó tún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ṣe, ó sì ran àwọn tó wà lórílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́ láti padà máa jọ́sìn Jèhófà. Gbogbo ohun tó ṣe yìí sì jẹ́ láàárín àwọn èèyàn tó bà jẹ́ bàlùmọ̀. Inú rẹ̀ dùn sí ìgbàgbọ́ tó ní àti ìjọsìn tó ń ṣe. (2 Kíróníkà, orí 34, 35) Dáníẹ́lì àtàwọn Hébérù mẹ́tà tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ò gbàgbé pè ìránṣẹ́ Jèhófà làwọn. Kódà nígbà táwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wọn láti ṣe ohun tí kò tọ́ pàápàá, wọ́n pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Ó dájú pé inú wọn dùn sí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.—Dáníẹ́lì 1:8-20.
Jẹ́ Kí Inú Rẹ Dùn Nítorí Pé O Jẹ́ Kristẹni
14, 15. Kí lohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé inú wa dùn sí jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni?
14 Ohun tó mú káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí ṣe àṣeyọrí ni pé wọ́n jẹ́ kí inú wọn dùn pé àwọn ń sin Ọlọ́run. Àwa náà ńkọ́ lónìí? Kí lohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé inú wa dùn sí jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni?
15 Olórí ohun tá a lè ṣe ni pé ká mọyì jíjẹ́ tá a jẹ́ ọkàn lára àwọn èèyàn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà tó sì ń bù kún. Kò sí àní-àní pé Ọlọ́run mọ gbogbo àwọn tó jẹ́ tirẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó gbé ayé lákòókò tí ọ̀rọ̀ ìsìn ò lójútùú rárá kọ̀wé pé: “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (2 Tímótì 2:19; Númérì 16:5) Inú Jèhófà dùn sáwọn “tí í ṣe tirẹ̀.” Jèhófà sọ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Kò sí àní-àní pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Nítorí náà ó yẹ kó jẹ́ pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní sí Jèhófà ló mú ká máa sìn ín. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.”—1 Kọ́ríńtì 8:3.
16, 17. Kí nìdí tó fi yẹ kínú àwọn Kristẹni, àtọmọdé àtàgbà, máa dùn nítorí ogún tẹ̀mí tí wọ́n ní?
16 Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tá a tọ́ dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe àyẹ̀wò ara wọn láti mọ̀ bóyá ìwà wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ń dára sí i níbàámu pẹ̀lú àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ àwọn òbí wọn kọ́ ló máa gbà wọ́n. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa olúkúlùkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé: “Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:4, 12) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí àwọn ọmọ bá jẹ́ kò-gbóná-kò-tutú nínú ìjọsìn wọn sí Jèhófà, á ṣòro fún wọn láti ní àjọṣe tó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.
17 Láti ọjọ́ tó ti pẹ́ ni àwọn ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà. Ó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ébẹ́lì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún sẹ́yìn, títí dé ọ̀dọ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lóde òní, yóò sì máa bá a lọ títí dé ọ̀dọ́ àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tí yóò wà láàyè títí láé. (Ìṣípayá 7:9; Hébérù 11:4) Àwa la dé kẹ́yìn lára àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ tó pọ̀ rẹpẹtẹ yìí. Ẹ ò rí i pé àgbàyanu ogún tẹ̀mí lèyí jẹ́!
18. Báwo ni àwọn ìlànà tá à ń tẹ̀ lé ṣe mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé?
18 Irú ẹni tá a jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tún kan àwọn ìlànà, àwọn ànímọ́, àtàwọn ìwà tó fi wá hàn pé a jẹ́ Kristẹni. Èyí ni “Ọ̀nà Náà,” ìyẹn ọ̀nà kan ṣoṣo tó dára jù lọ, tó sì jẹ́ ọ̀nà téèyàn lè gbà múnú Ọlọ́run dùn. (Ìṣe 9:2; Éfésù 4:22-24) Ẹ ò rí i pé ó yẹ́ káwa Kristẹni “wádìí ohun gbogbo dájú” ká sì “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin!” (1 Tẹsalóníkà 5:21) A mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀sìn Kristẹni àti ayé tó ti dàjèjì sí Ọlọ́run. Jèhófà mú kí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké ṣe kedere. Jèhófà tipa wòlíì Málákì sọ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18.
19. Kí lohun tí kò ní ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tòótọ́ láé?
19 Níwọ̀n bó ti ṣe pàtàkì pé ká máa ṣògo nínú Jèhófà nínú ayé tó ti dojú rú yìí, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tínú wa yóò fi máa dùn pé à ń sin Ọlọ́run tá ò fi ní sọ ìwà Kristẹni wa nù? Àpilẹ̀kọ́ tó kàn yóò sọ àwọn ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́. Tó o bá ń gbé àwọn kókó náà yẹ̀ wò, ohun kan rèé tó yẹ kó dá ọ lójú: Ìyẹn ni pé ìfẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ ní sí ìjọsìn Ọlọ́run kò ní di tútù láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ àyẹ̀wò ara ẹni nípa tẹ̀mí là ń sọ níbí yìí. Àmọ́, àwọn tó bá ní àìlera ara lè lọ gbàtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè máa “ṣògo nínú Jèhófà”?
• Kí lohun tó o ti rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Mósè àti Ásáfù?
• Àwọn èèyàn inú Bíbélì wo ni inú wọn dùn sí iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run?
• Kí lohun tá a lè ṣe láti fi hàn pé inú wa dùn sí jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìgbà kan wà tí Mósè ò dá ara rẹ̀ lójú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ ní inú wọn dùn nítorí pé wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà