Má Ṣe Sọ Ìwà Kristẹni Nù
“‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà.”—AÍSÁYÀ 43:10.
1. Irú àwọn èèyàn wo ní Jèhófà ń fà sún mọ́ ara rẹ̀?
NÍGBÀ tó o bá dénú Gbọ̀ngàn Ìjọba, fara balẹ̀ wo gbogbo àwọn tó péjú pésẹ̀ síbẹ̀. Àwọn wo lo máa rí níbi ìjọsìn yìí? Ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọgbọ́n tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Sáàmù 148:12, 13) Ó sì ṣeé ṣe kó o rí àwọn olórí ìdílé tí wọ́n ń sapá gidigidi láti múnú Ọlọ́run dùn nínú ayé tí ọ̀rọ̀ ìdílé ò ti jọ àwọn èèyàn lójú yìí. Ó ṣeé ṣe kó o tún rí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà láìfi àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó pè. (Òwe 16:31) Gbogbo wọn ló nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jinlẹ̀jinlẹ̀. Jèhófà náà sì fà wọ́n sún mọ́ ara rẹ̀ kóun lè ní àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú wọn. Ọmọ Ọlọ́run sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—Jòhánù 6:37, 44, 65.
2, 3. Kí nìdí tó fi lè má rọrùn láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́?
2 Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé a wà lára àwọn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà tó sì tún ń bùn kún? Àmọ́ kò rọrùn láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá à ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1) Àwọn ọ̀dọ́ tá a tọ́ dàgbà nínú ìdílé tí wọ́n ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì máa ń ṣòro fún jù. Ọ̀dọ́ kan tó wà nírú ipò yẹn sọ pé: “Mo máa ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, àmọ́ mi ò ní ohunkóhun tí mò ń lé nípa tẹ̀mí. Kí n sòótọ́, kò fìgbà kan tọkàn mi wá láti sin Jèhófà.”
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń gbìyànjú láti sin Jèhófà, síbẹ̀ ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, àtàwọn nǹkan tó wà nínú ayé àti àwọn ohun mìíràn tó lè súnni dẹ́ṣẹ̀ lè máà jẹ́ kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Ọlọ́run. Tí ìdààmú yìí bá sì ti wá pọ̀ jù, èyí lè mú kí wọ́n gbàgbé pé Kristẹni làwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan nínú ayé lónìí ń sọ pé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ò bóde mu, wọ́n ní àwọn ìlànà náà kò gbésẹ̀ láyé ọ̀làjú tá à wà yìí. (1 Pétérù 4:4) Àwọn kan gbà pé kò pọn dandan kéèyàn máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ là kalẹ̀. (Jòhánù 4:24) Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́ sáwọn ará Éfésù, ó sọ pé ayé yìí ní “ẹ̀mí,” tàbí ìwà kan tó gbilẹ̀. (Éfésù 2:2) Ẹ̀mí yìí ló ń darí àwọn èèyàn tí wọ́n fi ń ṣe nǹkan lọ́nà ti ayé tí kò mọ Jèhófà.
4. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa hùwà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́ nígbà gbogbo?
4 Àmọ́ ṣá o, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe ìyàsímímọ́ mọ̀ pé àgbákò ńlá ló máa jẹ́ tí ẹnikẹ́ni nínú wa bá lọ ba ìwà Kristẹni rẹ̀ jẹ́, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà. Ìlànà tí Jèhófà là kalẹ̀ fún wa láti máa tẹ̀ lé àti ohun tó fẹ́ ká máa ṣe ló máa pinnu ìwà tó yẹ ká máa hù gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Ó ṣe tán, àwòrán Ọlọ́run ni a dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Míkà 6:8) Bíbélì fi ìwà tó fi àwa Kristẹni hàn yàtọ̀ wé ẹ̀wù àwọ̀lékè tí gbogbo èèyàn á rí nígbà tá a bá wọ̀ ọ́. Jésù ṣe ìkìlọ̀ kan nípa àkókò tá à ń gbé yìí, ó ní: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò, tí ó sì pa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́, kí ó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn ènìyàn sì wo ipò ìtìjú rẹ̀.”a (Ìṣípayá 16:15) A ò ní fẹ́ sọ ìwà Kristẹni wa nù, bẹ́ẹ̀ la ò sì ní fẹ́ fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà ìwà híhù wa tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kí ayé Sátánì má bàa sọ wá di bó ṣe dà. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá lọ ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, a ò ní “ẹ̀wù àwọ̀lékè” mọ̀ nìyẹn. Àbámọ̀ àti ìtìjú tó máa kẹ́yìn rẹ̀ kò sì ní kéré.
5, 6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí?
5 Tá a bá ń fi àwọn ohun tó fi wá hàn yàtọ̀ pé á jẹ́ Kristẹni sọ́kàn nígbà gbogbo, èyí á nípa lórí bí a óò ṣe máa gbé ìgbésí ayé wa. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Bí olùjọsìn Jèhófà kan ò bá mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín òun àtàwọn èèyàn ayé mọ́, èyí lè mú kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Ọlọ́run, kó má sì ní ohun kan pàtó tó ń lé. Léraléra sì ni Bíbélì kìlọ̀ nípa irú nǹkan yẹn. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri. Ní ti tòótọ́, kí ẹni yẹn má rò pé òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà; ó jẹ́ aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:6-8; Éfésù 4:14; Hébérù 13:9.
6 Kí la lè ṣe tá ò fi ní sọ ìwà Kristẹni wa nù? Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ tá a ó fi túbọ̀ mọyì àǹfààní tá a ní láti jẹ́ olùjọsìn Ọ̀gá Ògo Jù Lọ? Jọ̀wọ́, gbé àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Má Ṣe Ṣiyèméjì Nípa Jíjẹ́ Tó O Jẹ́ Kristẹni
7. Kí nìdí tó fi dára láti bẹ Jèhófà pé kó yẹ̀ wá wò?
7 Máa mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i nígbà gbogbo. Ohun ṣíṣeyebíye jù lọ táwa Kristẹni ní ni àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Sáàmù 25:14; Òwe 3:32) Tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni, á dára ká yẹ ara wa wò láti mọ bí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe lágbára tó àti bó ṣe jinlẹ̀ tó. Abájọ tí onísáàmù náà fi bẹ Ọlọ́run pé: “Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò; yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.” (Sáàmù 26:2) Kí nìdí tí irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì? Ó ṣe pàtàkì nítorí pé àwa fúnra wa ò lè dá ṣe àyẹ̀wò ara wa ká sì mọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ èrò ọkàn wa àtohun tó wà nísàlẹ̀ ikùn wa. Jèhófà nìkan ló lè mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an.—Jeremáyà 17:9, 10.
8. (a) Àǹfààní wo ni àyẹ̀wò tí Jèhófà bá ṣe nípa wa yóò ṣe fún wa? (b) Ọ̀nà wo lèyí ti gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni?
8 Tá a bá ní kí Jèhófà yẹ̀ wá wò, ńṣe là ń sọ fún un pé kó dán wa wò. Ó lè gba àwọn nǹkan kan láyè láti ṣẹlẹ̀ sí wa kí àwọn ohun tó wà lọ́kàn wa lè di mímọ̀. (Hébérù 4:12, 13; Jákọ́bù 1:22-25) Ó yẹ kínú wa dùn sí irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ nítorí pé yóò fún wa láǹfààní láti fi bá a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tó hàn. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ ni yóò fi hàn bóyá á “pé pérépéré,” tàbí bóyá a “yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:2-4) Àyẹ̀wò tí Jèhófà bá sì ṣe yìí yóò mú ká lè dàgbà nípa tẹ̀mí.—Éfésù 4:22-24.
9. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kó dá wa lójú pé òtítọ́ làwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì?
9 Jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì dá ọ lójú. Ìgbàgbọ́ wa gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà lè di èyí tí kò lágbára mọ́ tá ò bá kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́. (Fílípì 1:9, 10) Ìdí rèé tó fi ṣe pàtàkì pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan, àtọmọdé àtàgbà, máa kẹ́kọ̀ọ́ kó lè dá wa lójú pé àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ jẹ́ òtítọ́ látinú Bíbélì. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ pé kí wọ́n “máa wádìí ohun gbogbo dájú; [kí wọ́n sì] di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Kí àwọn ọ̀dọ́ tá a tọ́ dàgbà ní ìdílé Kristẹni mọ̀ dájú pé ìgbàgbọ́ òbí wọn kọ́ ló máa sọ wọn di Kristẹni tòótọ́ o. Dáfídì gba Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ níyànjú pé kó “mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré . . . sìn ín.” (1 Kíróníkà 28:9) Kí Sólómọ́nì má ṣe ronú pé nígbà tí bàbá òun ti nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, òun náà ti nígbàgbọ́ nìyẹn. Sólómọ́nì gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ Jèhófà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Wàyí o, fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí n lè máa jáde lọ níwájú àwọn ènìyàn yìí, kí n sì lè máa wọlé.”—2 Kíróníkà 1:10.
10. Kí nìdí tí kò fi burú láti béèrè ìbéèrè tó ti ọkàn wa wá lórí ohun tá a fẹ́ mọ́ gan-an?
10 Kẹ́nì kan tó lè nígbàgbọ́ tó lágbára, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Kí lohun tó ní lọ́kàn tó fi sọ ọ̀rọ̀ yẹn? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára, ìgbọ́kànlé tá a ní nínú Jèhófà, nínú àwọn ìlérí rẹ̀ àti nínú ètò àjọ rẹ̀ yóò sì túbọ̀ lágbára sí i. Tá a bá béèrè ìbéèrè tó ti ọkàn wa wá lórí ohun tá a fẹ́ mọ́ gan-an nípa Bíbélì, tí kì í ṣe pé a kàn fẹ́ ṣe lámèyítọ́, a óò rí ìdáhùn tó mọ́yán lórí. Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú nínú Róòmù 12:2 pé: “Ẹ ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣèyẹn? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa níní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (Títù 1:1) Ẹ̀mí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣòro lóye pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 2:11, 12) Nítorí náà, tá ò bá lóye àwọn nǹkan kan, ó yẹ ká gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye wọn. (Sáàmù 119:10, 11, 27) Jèhófà fẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fẹ́ ká gbà á gbọ́, ó sì fẹ́ ká ṣègbọràn sí i. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ọkàn wa wá, tí kì í ṣe èyí tá a béèrè láti ṣe lámèyítọ́.
Pinnu Láti Múnú Ọlọ́run Dùn
11. (a) Kí ni ohun táwa èèyàn máa ń fẹ́ àmọ́ tó lè di ìdẹkùn fún wa? (b) Báwo la ṣe lè dẹni tó nígboyà láti dènà ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?
11 Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní kó o máa ṣe kì í ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n fojú pa òun rẹ́. Gbogbo wa la fẹ́ ká ní ọ̀rẹ́, inú wa sì máa ń dùn táwọn èèyàn bá kà wá sí. Ìfẹ́ láti ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ ẹni ń ṣe máa ń lágbára gan-an nígbà téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, àti nígbà téèyàn bá dàgbà pàápàá. Èyí ló máa ń mú kéèyàn fẹ́ máa fara wé àwọn ẹlòmíì tàbí kó fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà gbogbo ni ire wa máa ń jẹ àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúgbà wa lógún. Ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ń fẹ́ ẹni tó máa dara pọ̀ mọ́ wọn láti hùwà burúkú. (Òwe 1:11-19) Nígbà táwọn ojúgbà Kristẹni kan bá sún un ṣe ohun kan tí kò bójú mu, Kristẹni bẹ́ẹ̀ á fẹ́ máa fojú pa mọ́ káwọn èèyàn má bàa mọ irú ẹni tóun jẹ́. (Sáàmù 26:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé “Má ṣe mú ara rẹ bá àṣà ayé tí ó yí ọ ká mu.” (Róòmù 12:2, The Jerusalem Bible) Jèhófà ń fún wa lágbára tá a fi lè dènà ohunkóhun tó lè mú ká hùwà bíi táwọn èèyàn ayé.—Hébérù 13:6.
12. Tó bá kan ọ̀ràn pé ká ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run, ìlànà àti àpẹẹrẹ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tí ìgbàgbọ́ wa ò fi ní yẹ̀?
12 Nígbà táwọn èèyàn bá fẹ́ mú wa ṣe ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run, ó yẹ ká rántí pé jíjẹ́ onígbọràn sí Jèhófà ṣe pàtàkì ju èrò táwọn èèyàn ní lọ. Ìlànà kan tá a lè máa tẹ̀ lé ni èyí tó wà nínú Ẹ́kísódù 23:2 tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Kálébù ò fara mọ́ àwọn èèyàn náà rárá àti rárá. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Ọlọ́run sì bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí èyí. (Númérì 13:30; Jóṣúà 14:6-11) Ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ láti dènà ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́?
13. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mú láti jẹ́ káwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé Kristẹni ni wá?
13 Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Kristẹni ni ọ́. Àwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ kan pé, igi ganganran máà gún mi lójú òkèèrè la ti í wò ó. Ọ̀rọ̀ yìí bá a mu wẹ́kú bá a ṣe ń gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba ìwà Kristẹni wa jẹ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nígbà ayé Ẹ́sírà ń fojú winá àtakò, táwọn èèyàn ò sì fẹ́ kí wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà, wọ́n sọ pé: “Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Ẹ́sírà 5:11) Tá a bá jẹ́ kí ìwà táwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ wa ń hù sí wa àti àtakò tí wọ́n ń ṣe sí wa nípa lórí wa, èyí lè mú ká má lè ṣe nǹkan kan nítorí ìbẹ̀rù. Tá a bá sì sọ pé á fẹ́ tẹ́ gbogbo èèyàn lọ́rùn, a ò ní lè ṣe ohunkóhun láṣeyanjú. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dẹ́rù bà ọ́. Ohun tó ti dára ni pé kó o jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́. O lè ṣàlàyé àwọn ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé fún àwọn ẹlòmíràn, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó o gbà gbọ́, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Kristẹni ni ọ́. Àmọ́, ṣe èyí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kó o má sì bẹ̀rù. Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Jèhófà gbé kalẹ̀ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò lè tìtorí ohunkóhun bá ìwà Kristẹni rẹ jẹ́ láé. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú rẹ ń dùn láti máa hùwà tó dára. (Sáàmù 64:10) Tí gbogbo èèyàn bá mọ̀ ọ́ sí Kristẹni kan tó níwà rere, èyí lé fún ọ lókun, ó lè dáàbò bò ọ́, ó sì lè mú káwọn mìíràn fẹ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.
14. Ǹjẹ́ ó yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì nítorí àtakò tàbí yẹ̀yẹ́ táwọn èèyàn lé máa fi wá ṣe? Ṣàlàyé.
14 Òótọ́ kan ni pé àwọn kan lè máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n máa ta kò ọ́. (Júúdà 18) Táwọn kan ò bá gba àwọn àlàyé tó o ṣe fún wọn nípa àwọn ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé, má ṣe jẹ́ kí èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. (Ìsíkíẹ́lì 3:7, 8) Bó ti wù kó o ṣàlàyé tó, àwọn tí ò ní gbà kò ní gbà. Rántí Fáráò. Pẹ̀lú gbogbo wàhálà tó dé bá Fáráò àti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tó rí, síbẹ̀ kó gbà pé ńṣe ni Mósè ń gbẹnu sọ fún Jèhófà. Àkọ́bí ọmọ rẹ̀ tilẹ̀ kú pàápàá, síbẹ̀ kò gbà. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú ọ nígbèkùn. Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run tá a sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù.—Òwe 3:5, 6; 29:25.
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ Sẹ́yìn, Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ọ̀la
15, 16. (a) Kí ni ogún tẹ̀mí wa? (b) Ọ̀nà wo la lè gbà jàǹfààní tá a bá ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ronú lórí ogún tẹ̀mí tá a ní?
15 Mọyì ogún tẹ̀mí tó o ní. Táwọn Kristẹni bá lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ronú lórí ogún tẹ̀mí tí wọ́n ní, èyí yóò ṣe wọ́n láǹfààní. Lára ogún tẹ̀mí yìí ni òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun àti àǹfààní tá a ní láti máa ṣojú fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ oníwàásù ìhìn rere. Ǹjẹ́ ò ń rí ipa tó ò ń kó láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ìyẹn láàárín àwọn tí Ọlọ́run gbé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ti wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run lé lọ́wọ́? Rántí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.”—Aísáyà 43:10.
16 Ó lè bi ara rẹ làwọn ìbéèrè bíi: ‘Báwo ni ogún tẹ̀mí yìí ṣe ṣeyebíye sí mi tó? Ǹjẹ́ mo kà á sí pàtàkì gan-an débi pé mo tìtorí rẹ̀ fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé mi? Ǹjẹ́ mo mọyì rẹ̀ gan-an débi pé ó máa jẹ́ kí n lè dènà ìdẹwò èyíkéyìí tó lè mú kí n pàdánù ogún náà?’ Ogún tẹ̀mí tá a ní yìí lè mú ká ní ìfọkànbalẹ̀ nípa tẹ̀mí èyí tó jẹ́ pé inú ètò Jèhófà nìkan léèyàn ti lè ní in. (Sáàmù 91:1, 2) Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn nínú ìtàn ètò Jèhófà ti òde òní, èyí lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé kò sẹ́nì kankan tàbí ohunkóhun tó lè pa àwọn èèyàn Jèhófà rẹ́ láyé yìí.—Aísáyà 54:17; Jeremáyà 1:19.
17. Yàtọ̀ sí pé ká gbójú lè ogún tẹ̀mí wa, kí ni ohun mìíràn tá a tún gbọ́dọ̀ ṣe?
17 Lóòótọ́, a ò lè gbójú lé ogún tẹ̀mí wa nìkan. Olúkúlùkù wa gbọ́dọ̀ ní àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti ṣiṣẹ́ kára láti gbé ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì ró, ó wá kọ̀wé sí wọn pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, lọ́nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí pẹ̀lú ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (Fílípì 2:12) A ò lè retí pé ohun tí ẹlòmíràn bá ṣe ló máa fún wa nígbàlà.
18. Báwo ní àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe lè túbọ̀ fi wà hàn yàtọ̀ pé á jẹ́ Kristẹni?
18 Máa kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò Kristẹni. Àwọn kan sọ pé “iṣẹ́ ẹni máa ń hàn níwà ẹni.” Àwọn Kristẹni lónìí ti gba àṣẹ láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì ti wíwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níwọ̀n bí èmi, ní ti gidi, ti jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè, mo ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lógo.” (Róòmù 11:13) Iṣẹ́ ìwàásù wa mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé, ṣíṣe tá a sì ń ṣe iṣẹ́ ọ̀hún ń fi wa hàn yàtọ̀ pé á jẹ́ Kristẹni. Tá a bá wá ń kópa nínú ìgbòkègbodò mìíràn tó jẹ́ ti Ìjọba Ọlọ́run, bíi lílọ sí ìpàdé ìjọ, kíkópa nínú kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn, ríran àwọn aláìní lọ́wọ́ àti ṣíṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò túbọ̀ fi wa hàn yàtọ̀ pé á jẹ́ Kristẹni.—Gálátíà 6:9, 10; Hébérù 10:23, 24.
Àǹfààní Wà Nínú Jíjẹ́ Kristẹni
19, 20. (a) Àǹfààní wo lò ń gbádùn nítorí pé ó jẹ́ Kristẹni? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an?
19 Jókòó kó o ronú ná lórí ọ̀pọ̀ àǹfààní tá à ń gbádùn nítorí pé a jẹ́ Kristẹni tòótọ́. A ní àǹfààní láti jẹ́ ẹnì kan tí Jèhófà mọ̀. Wòlíì Málákì sọ pé: “Àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Ọlọ́run lè kà wá sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jákọ́bù 2:23) Ìgbésí ayé wa jẹ́ èyí tó nítumọ̀ nítorí pé a ní ohun tó ṣe gúnmọ́ tá à ń lé. Ọlọ́run tún ní ká máa retí ìyè àìnípẹ̀kun.—Sáàmù 37:9.
20 Rántí pé Ọlọ́run lẹni tó lè sọ bó o ṣe jẹ́ gan-an àti bó o ṣe ṣe pàtàkì tó, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn ń rò nípa rẹ. Àwọn kan lè máa sọ bá a ṣe ṣeyebíye tó gẹ́gẹ́ bí òye wọn ṣe mọ. Àmọ́ ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló jẹ́ ká mọ bá a ṣe ṣeyebíye tó, tirẹ̀ ni wá. (Mátíù 10:29-31) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló máa jẹ́ ká ṣọ́ra tá ò fi ní ba ìwà Kristẹni wa jẹ́, ó sì lè mú ká túbọ̀ mọ ọ̀nà tó yẹ ká tọ̀ nígbèésí ayé wa. “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni ó mọ̀.”—1 Kọ́ríńtì 8:3.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn ọ̀gá tẹ́ńpìlì tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù máa ń ṣe làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tọ́ka sí. Nígbà ìṣọ́ òru, ọ̀gá yìí á máa rìn káàkiri inú àgbàlá tẹ́ńpìlì láti lọ wò bóyá àwọn ọmọ Léfì tó ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò tàbí wọ́n ń sùn lẹ́nu iṣẹ́. Tó bá rí ẹ̀ṣọ́ kan tó ń sún, ńṣe ló máa da igi bò ó, ó sì lè dáná sun ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ láti kó ìtìjú bá a.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì káwọn Kristẹni má ṣe sọ ìwà wọn nípa tẹ̀mí nù?
• Kí ló yẹ ká ṣe láti mú kí jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni dá wa lójú?
• Nígbà tó bá kan ọ̀ràn ẹni tó yẹ ká máa múnú rẹ̀ dùn, kí làwọn ohun tó máa mú ká ṣe ìpinnu tó tọ̀nà?
• Báwo ni jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni ṣe máa jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa rí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kíkópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò Kristẹni lè túbọ̀ fi wá hàn yàtọ̀ pé a jẹ́ Kristẹni