Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Láyọ̀ Lóde Òní
“Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:14.
1, 2. (a) Kí la rí nínú ìjọ Kristẹni tó ń fúnni níṣìírí? (b) Ṣàlàyé bí ìgbéyàwó aláyọ̀ ṣe máa ń rí?
NÍGBÀ tá a bá wo inú ìjọ Kristẹni lónìí, inú wa máa ń dùn gan-an láti rí ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn fún ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún, ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n ti dúró ti ara wọn gbágbáágbá àní lákòókò ìṣòro pàápàá.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.
2 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn lọ́kọláya ló gbà pé àjọgbé àwọn ò ṣàìní ìṣòro rárá. Obìnrin kan ṣe àkíyèsí kan, ó ní: “Ìgbéyàwó aláyọ̀ kì í wà láìsí ìṣòro. Ọjọ́ dídùn àti ọjọ́ kíkan wà . . . Ṣùgbọ́n lọ́nà kan ṣá . . . àwọn èèyàn wọ̀nyí kò fira wọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro pọ̀ lóde oní.” Àwọn tọkọtaya aláyọ̀ mọ bí wọ́n ṣe máa ń kápá ìjì àti àníyàn ayé tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ohun yìí sì máa ń jẹ yọ látinú ìṣòro ìgbésí ayé, pàápàá táwọn tọkọtaya náà bá ní àwọn ọmọ. Ohun tí wọ́n ti là kọjá ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ tòótọ́ “kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
3. Kí ni àyẹ̀wò fi hàn nípa ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀, àwọn ìbéèrè wo lèyí sì mú wá?
3 Àmọ́ tá a bá wá wo gbogbo ayé lápapọ̀, àá rí i pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ìgbéyàwó ló ń tú ká. Ìròyìn kan sọ pé: “Ìdajì gbogbo ìgbéyàwó tí wọ́n bá ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lónìí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìkọ̀sílẹ̀ ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. Ìdajì àwọn [ìkọ̀sílẹ̀] náà yóò sì wáyé kí ọdún kẹjọ ìgbéyàwó wọn tó pé . . . Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó bá sì tún ìgbéyàwó náà ṣe ni yóò tún jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.” Àní, ìkọ̀sílẹ̀ ti ń pọ̀ sí i báyìí láwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìkọ̀sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, ní Japan, ìkọ̀sílẹ̀ ti lọ sókè ní nǹkan bí ìlọ́po méjì láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń fà á, ìyẹn àwọn ìṣòro tó máa ń nípa lórí àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni pàápàá nígbà mìíràn? Kí ló lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ láìka ohun tí Sátánì ń ṣe láti bà á jẹ́ sí?
Àwọn Ewu Tí A Gbọ́dọ̀ Yẹra Fún
4. Àwọn ohun wo ló lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí yẹ̀ wò, ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:1-5.
5. Ọ̀nà wo ni ẹnì kan tó jẹ́ ‘olùfẹ́ ara rẹ̀’ nìkan fi ń ba ìgbéyàwó rẹ̀ jẹ́, ìmọ̀ràn wo sì ni Bíbélì fúnni nípa ọ̀ràn yìí?
5 Tá a bá ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí, àá rí i pé àwọn nǹkan tó tò lẹ́sẹẹsẹ yẹn lè fa ìṣòro sáàárín tọkọtaya. Bí àpẹẹrẹ, tara wọn nìkan làwọn tó jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn” máa ń mọ̀, wọn kì í sì í gba ti ẹlòmíràn rò. Nǹkan tó bá ti wu ọkọ tàbí aya tó jẹ́ olùfẹ́ ara rẹ̀ láti ṣe ló máa ń fẹ́ ṣe dandan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kì í fara da nǹkan fún ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè mú kí tọkọtaya láyọ̀ nínú ìgbéyàwó wọn? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn, títí kan àwọn lọ́kọláya, pé: “[Ẹ má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílípì 2:3, 4.
6. Báwo ni ìfẹ́ owó ṣe lè ba àárín tọkọtaya jẹ́?
6 Ìfẹ́ owó lè da àárín ọkọ àti aya rú. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ó dunni pé ohun tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé kó má ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó lónìí. Níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ti ń wá owó kiri, wọ́n ti pa ẹnì kejì wọn tì, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bìkítà nípa ẹ̀dùn ọkàn ẹnì kejì wọn, títí kan ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin tó yẹ kó wà láàárín wọn.
7. Nínú àwọn ìgbéyàwó kan, irú ìwà wo ló ti yọrí sí panṣágà?
7 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn kan ní ọjọ́ ìkẹyìn yìí yóò jẹ́ “aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan.” Ohun pàtàkì ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, ńṣe ló yẹ kó so tọkọtaya pọ̀ títí ayé, tí wọn ò sì ní ṣe àdàkàdekè sí ara wọn. (Málákì 2:14-16) Àwọn kan máa ń wo obìnrin olóbìnrin tàbí ọkùnrin ọlọ́kùnrin. Aya kan tó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún tí ọkọ rẹ̀ fi sílẹ̀ ṣàlàyé pé, kó tó di pé ó fi òun sílẹ̀ ló ti máa ń ṣe kùrùkẹrẹ lọ́dọ̀ àwọn obìnrin tó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn lọ́nà tó pàpọ̀jù. Kò ronú pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò yẹ ẹni tó ti níyàwó. Ó dun obìnrin náà gan-an bó ṣe ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ó sì fọgbọ́n kìlọ̀ fún ọkọ rẹ̀ pé ọ̀nà tó ń tọ̀ yẹn léwu. Láìka gbogbo ìkìlọ̀ náà sí, ọkùnrin náà lọ dẹ́ṣẹ̀ panṣágà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kìlọ̀ fún ọkùnrin náà, kò gba ìkìlọ̀. Àfìgbà tó tẹsẹ̀ bọ páńpẹ́.—Òwe 6: 27-29.
8. Kí ló lè sún ẹnì kan ṣe panṣágà?
8 Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé panṣágà kò dára! Ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá obìnrin ṣe panṣágà jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún; ẹni tí ó bá ṣe é ń run ọkàn ara rẹ̀.” (Òwe 6:32) Bó ti sábà máa ń rí, èèyàn kì í ṣàdédé ṣe panṣágà. Jákọ́bù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà máa ń wáyé lẹ́yìn tẹ́ni náà bá ti ń ronú nípa rẹ̀ léraléra. (Jákọ́bù 1:14, 15) Díẹ̀díẹ̀ ni ẹni náà ò ní ṣòótọ́ sí aya tàbí ọkọ rẹ̀ mọ́, ìyẹn ẹni tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún pé òun máa jẹ́ olóòótọ́ sí ní gbogbo ọjọ́ ayé òun. Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:27, 28.
9. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ló wà nínú Òwe 5:18-20?
9 Nítorí náà, ìwé Òwe sọ ohun kan tó bọ́gbọ́n mu tó sì máa fi hàn pé tọkọtaya dúró ṣinṣin ti ara wọn, ó ní: “Jẹ́ kí orísun omi rẹ jẹ́ èyí tí ó ní ìbùkún, kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá. Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà. Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo. Nítorí náà, ọmọ mi, èé ṣe tí ìwọ yóò fi máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú àjèjì obìnrin tàbí tí ìwọ yóò fi gbá oókan àyà obìnrin ilẹ̀ òkèèrè mọ́ra?”—Òwe 5:18-20.
Má Ṣe Kánjú Ṣègbéyàwó
10. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn fi àkókò sílẹ̀, kó lè mọ ẹni tó fẹ́ fẹ́ dáadáa?
10 Ìṣòro máa ń jẹ yọ nínú ìgbéyàwó nígbà táwọn kan bá lọ kánjú ṣègbéyàwó. Ọjọ́ orí wọn lè kéré gan-an kí wọ́n má sì lóye tó pọ̀ tó. Tàbí kí wọ́n má fi àkókò sílẹ̀ tó láti mọ ara wọn dáadáa, ìyẹn láti mọ ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tí wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tí wọ́n fẹ́ fi ìgbésí ayé wọn ṣe àti inú ìdílé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti wá. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn ní sùúrù, kó fi àkókò sílẹ̀, kó lè mọ ẹní to fẹ́ fẹ́ náà dáadáa. Gbé ọ̀ràn Jékọ́bù, ọmọ Ísákì yẹ̀ wò. Ọdún méje ló fi ṣiṣẹ́ fún àna rẹ̀ kó tó lè fẹ́ Rákélì. Ohun tó mú un ṣe é ni pé ìfẹ́ gidi ló ní sí Rákélì, kì í ṣe torí ẹwà lásán.—Jẹ́nẹ́sísì 29:20-30.
11. (a) Irú èèyàn méjì wo ló máa ń wà nínú ìgbéyàwó? (b) Kí nìdí tí sísọ̀rọ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání fi ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó?
11 Ìgbéyàwó kò mọ sí òòfà ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrìn àti obìnrìn. Ìdílé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn méjì tí wọ́n fẹ́ra wọn ti máa ń wá, ìwà wọn yàtọ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn yàtọ̀, ọ̀pọ̀ wọn ni kì í sì í kàwé tóra wọn. Nígbà mìíràn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn tiẹ̀ lè máà bára mu tàbí kí èdè àwọn méjèèjì tiẹ̀ yàtọ̀. Bá a bá tiẹ̀ yọwọ́ ìwọ̀nyẹn kúrò, èèyàn méjì tí èrò wọn lè yàtọ̀ pátápátá lórí onírúurú nǹkan ṣì ni wọ́n. Àwọn méjì yìí gan-an ló sì ń para pọ̀ di tọkọtaya. Wọ́n lè jẹ́ ẹni tó le koko tó sì máa ń ṣàròyé tàbí kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ń fúnra wọn níṣìírí tí wọ́n sì ń gbéra wọn ró. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ wa lè pa ọkọ tàbí aya wa lára tàbí kó tù wọ́n lára. Sísọ̀rọ̀ gbàùgbàù lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó.—Òwe12:18; 15:1, 2; 16:24; 21:9; 31:26.
12, 13. Èrò tó tọ́ wo ló yẹ ká ní nípa ìgbéyàwó?
12 Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn fi àkókò sílẹ̀ láti mọ ẹni tèèyàn fẹ́ fẹ́ dáadáa. Arábìnrin kan tó ti nírìírí sọ nígbà kan pé: “Nígbà tó o bá ronú nípa ẹni tó o fẹ́ fẹ́, ronú nípa nǹkan mẹ́wàá pàtàkì tó o fẹ́ láti rí nínú ẹni náà. Bó o bá lè rí méje, wá béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè gbójú fo mẹ́ta tó kù tí ẹni náà kò ní? Ǹjẹ́ mo lè máa fara mọ́ àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wọ̀nyẹn lójoojúmọ́?’ Tó o bá ń ṣiyèméjì, tẹsẹ̀ dúró ná, kó o tún inú ara rẹ rò dáadáa.” Àmọ́ ṣá o, kó yẹ kó o retí ohun tó ga jù. Bó o bá fẹ́ ṣègbéyàwó, ó yẹ kó o mọ̀ pé o ò lè rí ẹni tí ìwà rẹ̀ á bá tìrẹ mu délẹ̀délẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà sì lẹni tó bá fẹ́ ọ á rí i pé ìwà rẹ kò bá tòun mú pátápátá!—Lúùkù 6:41.
13 Ìgbéyàwó ń béèrè pé kéèyàn máa yááfì àwọn nǹkan kan. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ wà láìní àníyàn. Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, ó sì pínyà lọ́kàn. Síwájú sí i, obìnrin tí kò lọ́kọ, àti wúńdíá, ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, pé kí òun lè jẹ́ mímọ́ nínú ara rẹ̀ àti nínú ẹ̀mí rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin tí a gbé níyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:32-34.
Ìdí Táwọn Ìgbéyàwó Kan Fi Ń Tú Ká
14, 15. Kí làwọn ohun tó lè sọ ìdè ìgbéyàwó di aláìlágbára?
14 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, arábìnrin kan àti ọkọ̀ rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀, èyí sì kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá obìnrin náà. Ọkọ rẹ̀ fi í sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjìlá tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin mìíràn gbé. Ǹjẹ́ obìnrin náà tiẹ̀ rí àmì kankan kí ìgbéyàwó náà tó túká? Ó ṣàlàyé pé: “Ọkọ mi kì í gbàdúrà mọ́ nígbà tó yá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwáwí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fún bó ṣe ń pa ìpàdé jẹ́ tí kò sì wàásù mọ́. Ó máa ń sọ pé ọwọ́ òun dí jù tàbí pé ó ti rẹ òun jù láti wà pẹ̀lú mi. Kì í bá mi sọ̀rọ̀ mọ́, kódà kì í bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. Ó mà ṣe o pé ó di irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Ó ti yàtọ̀ sí bó ṣe rí nígbà tí mo fẹ́ ẹ.”
15 Àwọn mìíràn sọ pé àwọn ṣàkíyèsí irú àwọn àmì kan náà lára ọkọ tàbí aya àwọn tó di aláìṣòótọ́. Wọ́n ní wọn kò ka ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà gbígbà sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ wá sáwọn ìpàdé Kristẹni mọ́. Lédè mìíràn, ọ̀pọ̀ àwọn tó fi ọkọ tàbí aya wọn sílẹ̀ níkẹyìn ló ti jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà di ahẹrẹpẹ. Ìgbẹ̀yìn rẹ̀ ni pé, nǹkan tẹ̀mí ò sí lọ́kàn wọn mọ́. Wọn ò rí Jèhófà bí Ọlọ́run alààyè mọ́. Ayé tuntun òdodo tí Bíbélì ṣèlérí rẹ̀ kò jẹ́ ohun gidi lójú wọn mọ́. Nígbà mìíràn, ọkọ tàbí aya tó di aláìṣòótọ́ náà á ti ní àìlera tẹ̀mí yìí kó tiẹ̀ tó di pé ó lọ ní àjọṣe pẹ̀lú ẹlòmíràn níta.—Hébérù 10:38, 39; 11:6; 2 Pétérù 3:13, 14.
16. Kí ló ń mú kí ìgbéyàwó dúró digbí?
16 Wá wo bí ọ̀ràn tọkọtaya kan tó láyọ̀ gan-an ṣe yàtọ̀ sí tàwọn tá a sọ lókè yìí. Wọ́n sọ pé ipò tẹ̀mí àwọn tó lágbára ló jẹ́ kí ìgbéyàwó àwọn láyọ̀. Wọ́n máa ń gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n sì jọ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀. Ọkọ sọ pé: “A jọ máa ń ka Bíbélì. A jọ máa ń lọ wàásù. A sì jọ máa ń ṣe nǹkan pọ̀.” Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ níbẹ̀ ni pé: Mímú kí àjọṣe ẹni pẹ̀lú Jèhófà dán mọ́rán ló ń mú kí ìgbéyàwó ẹni dúró digbídigbí.
Ẹ Má Ṣe Retí Ohun Tó Ga Jù, Ẹ sì Jọ Máa Sọ̀rọ̀
17. (a) Àwọn ohun méjì wo ló ń mú kí ìgbéyàwó láyọ̀? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ìfẹ́ Kristẹni?
17 Àwọn ohun méjì mìíràn tó ń mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ ni: Ìfẹ́ Kristẹni àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Nígbà tí ìfẹ́ bá ti kó sáwọn èèyàn méjì lórí, wọn kì í sábà rí kùdìẹ̀-kudiẹ ara wọn. Àwọn méjèèjì lè fẹ́ra wọn pẹ̀lú èrò pé ìgbádùn rẹpẹtẹ ló wà fáwọn. Wọ́n lè máa rò pé ìgbéyàwó àwọn yóò dà bíi ti àwọn tí wọ́n ń kà nípa wọn nínú ìtàn eré ìfẹ́ tàbí tí wọ́n ń rí nínú sinimá. Àmọ́ ṣá o, níkẹyìn, ojú àwọn méjèèjì á wá mọ́ gbòlà. Ìgbà yẹn làwọn kùdìẹ̀-kudiẹ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí àwọn ìwà tí ń ríni lára yóò wá di ìṣòro ńlá. Bí irú yẹn bá ṣẹlẹ̀, ńṣe ló yẹ kí Kristẹni kan fi èso tẹ̀mí sílò, èyí tí ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀. (Gálátíà 5: 22, 23) Ká sòótọ́, ìfẹ́ lágbára púpọ̀, ìfẹ́ tá a sì ń sọ yìí kì í ṣe ìfẹ́ àárín takọtabo bí kò ṣe ìfẹ́ Kristẹni. Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ní: Ìfẹ́ a máa ní “ìpamọ́ra àti inú rere. . . . Kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) Ní kedere, ojúlówó ìfẹ́ máa ń gbójú fo àìpé ẹ̀dá. Tá ò bá ní tan ara wa, irú ìfẹ́ yìí kì í retí pé kéèyàn pé pátápátá.—Òwe 10:12.
18. Báwo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣe lè fún ìgbéyàwó lókun?
18 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tún ṣe pàtàkì gan-an. Láìka iye ọdún tí tọkọtaya kan ti ṣègbéyàwó sí, wọ́n gbọ́dọ̀ jọ máa sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì máa fetí sí ara wọn dáadáa. Ọkọ kan sọ pé: “A máa ń sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí lára wa àmọ́ a kì í fìjà sọ ọ́.” Bí òye tọkọtaya kan bá ṣe ń pọ̀ sí i, wọ́n á mọ bí wọ́n ṣe lè fetí sí ohun tí ẹnì kejì wọn ń sọ àtohun tí kò tiẹ̀ sọ jáde pàápàá. Lédè mìíràn, bí ọdún ti ń gorí ọdún, àwọn tọkọtaya aláyọ̀ á máa mọ ọ̀rọ̀ tí ẹnì kejì wọn ò tiẹ̀ sọ jáde pàápàá. Àwọn aya kan sọ pé àwọn ọkọ àwọn kì í fetí sílẹ̀ nígbà táwọn bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ọkọ kan náà sì ṣàròyé pé, ó jọ pé àkókò tí kò wọ̀ làwọn ìyàwó àwọn máa ń fẹ́ láti bá àwọn sọ̀rọ̀. Téèyàn ò bá ní òye àti ìyọ́nú, kò ní lè máa bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó múná dóko máa ń ṣe tọkọtaya láǹfààní.—Jákọ́bù 1:19.
19. (a) Kí nìdí tí títọrọ àforíjì kò fi rọrùn? (b) Kí ló máa sún wa láti tọrọ àforíjì?
19 Nígbà mìíràn, títọrọ àforíjì jẹ́ ara ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín tọkọtaya. Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti tọrọ àforíjì nígbà tí a bá ṣẹ ẹnì kejì wa. Ó gba ìwà ìrẹ̀lẹ̀ kí ẹnì kan tó lè gbà pé òun ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, tá a bá ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ó lè fún ìdè ìgbéyàwó lókun gan-an! Títọrọ àforíjì látọkànwá lè mú ohun tó lè fa àríyànjiyàn lọ́jọ́ iwájú kúrò, ó sì lè jẹ́ ká dárí jini látọkànwá kí ìṣòro ọ̀hún sì yanjú. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:13, 14.
20. Báwo ló ṣe yẹ kí Kristẹni kan máa hùwà sí ọkọ tàbí aya rẹ̀ níkọ̀kọ̀ àti ní gbangba?
20 Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tún ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó. Ó yẹ kí ọkọ àti aya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè fọkàn tán ara wọn kí wọ́n sì lè gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹnì kejì wọn. Ó yẹ kí a máa yin ọkọ tàbí aya wa; a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ sí wọn lọ́nà tí kò dára. (Òwe 31:28b) A kò gbọ́dọ̀ máa bẹnu àtẹ́ lù wọ́n, ká máa fi wọ́n ṣàwàdà burúkú. (Kólósè 4:6) Kí tọkọtaya máa fìfẹ́ hàn síra wọn nígbà gbogbo ló máa mú káwọn nǹkan wọ̀nyí ṣeé ṣe. Fífọwọ́ kanni lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tàbí sísọ̀rọ̀ ìfẹ́ lè jẹ́ ọ̀nà láti sọ fún aya tàbí ọkọ ẹni pé: “Mo ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Inú mi dùn pé o dúró tì mí.” Díẹ̀ lára àwọn ohun tó lè mú kí àjọṣe àárín ọkọ àti aya dára nìyẹn, wọ́n sì ń mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ lóde òní. Àwọn ohun mìíràn wà tí a tún lè ṣe. Àpilẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí yóò fún wa láwọn ìlànà tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tí yóò túbọ̀ sọ bí ìgbéyàwó ṣe lè lárinrin.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé sí i, wo ìwé náà Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Àwọn ohun wo ló lè sojú ìgbéyàwó dé?
• Kí nìdí tí kíkánjú ṣègbéyàwó kó fi bọ́gbọ́n mu?
• Ipa wo ni ipò tẹ̀mí tọkọtaya ń kó nínú ìgbéyàwó?
• Àwọn ohun wo ló ń mú kí ìgbéyàwó dúró digbí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìgbéyàwó kò mọ sí òòfà ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrìn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà ló lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti mu kí ìgbéyàwó wọn láyọ̀