Ogun Iyebíye Làwọn Ọmọ Wa
“Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.”—SÁÀMÙ 127:3.
1. Báwo ni ọmọ jòjòló àkọ́kọ́ ṣe dáyé?
RONÚ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ lọ́nà àgbàyanu tí wọ́n fi lè bímọ. Ohun kan láti ara Ádámù tó jẹ́ bàbá àti ohun kan láti ara Éfà tó jẹ́ ìyá dàpọ̀ mọ́ra. Ohun yìí sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ikùn Éfà títí tó fi wá di odindi ọmọ tuntun kan. Ọmọ yìí ni ọmọ jòjòló tá a kọ́kọ́ bí sáyé. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Títí dòní olónìí ni oyún níní àti ọmọ bíbí ṣì ń yà wá lẹ́nu, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń sọ pé kò sí ohun mìíràn tá a lè pè é ju iṣẹ́ ìyanu lọ.
2. Kí nìdí tó o fi lè sọ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ikùn aboyún jẹ́ iṣẹ́ ìyanu?
2 Láàárín nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án péré, ohun tíntínní kan tí àjọṣepọ̀ bàbá àti ìyá mú jáde á bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà títí tó fi máa di ọmọ kékeré jòjòló kan. Ohun tíntínní náà ní ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ohun tín-tìn-tín nínú. Ìlànà kan wà nínú ohun tíntínní yẹn tó máa mú oríṣi àwọn ohun tín-tìn-tín mìíràn tó lé ní igba jáde. Nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà àgbàyanu wọ̀nyí, tó ta yọ òye ọmọ èèyàn, àwọn ohun tín-tìn-tín wọ̀nyẹn á wá máa dàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ títí tó fi máa di ọmọ tuntun jòjòló kan!
3. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ronú jinlẹ̀ fi gbà pé Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe láti bí ọmọ tuntun kan?
3 Ta ni o lè sọ pé ó dá ọmọ jòjòló yìí? Dájúdájú Ẹni tó ṣẹ̀dá èèyàn ni. Nínú Bíbélì, onísáàmù kan kọ ọ́ lórin pé: “Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.” (Sáàmù 100:3) Láìsí àní-àní, ẹ̀yin òbí mọ̀ dáadáa pé kì í ṣe mímọ̀-ọ́n ṣe yín lẹ fi lè mú ọmọ tuntun làǹtìlanti kan jáde. Àyàfi Ọlọ́run oníbú ọgbọ́n nìkan ló lè ṣẹ̀dá odindi èèyàn kan lọ́nà ìyanu bẹ́ẹ̀. Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn tó ń ronú jinlẹ̀ ti gbà pé Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá ló mú kí ọmọ tuntun kan dàgbà nínú ikùn. Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀?—Sáàmù 139:13-16.
4. Báwo làwọn èèyàn kan ṣe rí àmọ́ tí Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀?
4 Ṣùgbọ́n, ṣé Ẹlẹ́dàá tí kò bìkítà, tó kàn ṣáà ṣètò pé kí ọkùnrin àti obìnrin máa mú èèyàn bíi tiwọn jáde ni Jèhófà jẹ́? Lóòótọ́ làwọn èèyàn kan kì í bìkítà, àmọ́ Jèhófà kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. (Sáàmù 78:38-40) Bíbélì sọ nínú Sáàmù 127:3 pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún látọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.” Ẹ jẹ́ ká wá ronú nípa ohun tí ogún jẹ́ àti ohun tó mú káwọn òbí máa fi ogún sílẹ̀ fáwọn ọmọ.
Ogún àti Èrè
5. Kí nìdí táwọn ọmọ fi jẹ́ ogún?
5 Ogún dà bí ẹ̀bùn. Àwọn òbí sábà máa ń ṣiṣẹ́ kárakára kí wọ́n lè rí ogún fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn. Ó lè jẹ́ owó, dúkìá tàbí àwọn ohun iyebíye mìíràn. Èyí ó wù ó jẹ́, ńṣe ló ń fi hàn pé àwọn òbí ọ̀hún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. Bíbélì sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run fi àwọn ọmọ fáwọn òbí wọn gẹ́gẹ́ bí ogún. Ẹ̀bùn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n. Tó o bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ o lè fọwọ́ sọ̀yà pé ìṣesí rẹ fi hàn pé o ka àwọn ọmọ rẹ sí ẹ̀bùn tí Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé fi síkàáwọ́ rẹ?
6. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti bímọ?
6 Ohun tó mú kí Jèhófà fún àwa èèyàn lẹ́bùn yìí ni pé ó fẹ́ kí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà kún orí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Aísáyà 45:18) Jèhófà ò dá àwa èèyàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan bó ṣe dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Sáàmù 104:4; Ìṣípayá 4:11) Dípò ìyẹn, ńṣe ni Ọlọ́run dá èèyàn lọ́nà tí wọ́n á fi lè bí àwọn ọmọ tí yóò jọ wọ́n. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún ìyá àti bàbá láti mú ọmọ tuntun kan wá sáyé kí wọ́n sì máa ṣìkẹ́ irú ọmọ bẹ́ẹ̀! Ìwọ tó o jẹ́ òbí, ǹjẹ́ o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti ní ogún iyebíye yìí?
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jésù
7. Báwo ni Jésù ṣe fi ìfẹ́ àti ìyọ́nú hàn sí “àwọn ọmọ ènìyàn” tó mú kí ìṣe rẹ̀ yàtọ̀ sí ohun táwọn òbí kan máa ń ṣe?
7 Ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo òbí ló ka àwọn ọmọ wọn sí èrè. Ọ̀pọ̀ òbí ni kì í sábà fi ìyọ́nú bá àwọn ọmọ wọn lò. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Ọmọ rẹ̀. (Sáàmù 27:10; Aísáyà 49:15) Jésù yàtọ̀ sírú àwọn òbí bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tó ní sáwọn ọmọdé. Kódà, kí Jésù tó wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ìyẹn nígbà tó ṣì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá ní ọ̀run, Bíbélì sọ pé “ohun tí inú [rẹ̀] máa ń dùn sí jù lọ ni àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:31, Rotherham) Ìfẹ́ tó ní sí àwa ọmọ èèyàn pọ̀ débi pé tinútinú ló fi fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ká bàa lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 20:28; Jòhánù 10:18.
8. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn òbí?
8 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi àpẹẹrẹ àtàtà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lélẹ̀ fáwọn òbí. Ẹ jẹ́ ká wo bó ti ṣe é. Ó máa ń wáyè fún àwọn ọmọdé kódà nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ dí tí nǹkan ò sì rọrùn fún un pàápàá. Ó máa ń wo bí wọ́n ṣe ń ṣeré nínú ọjà, ó sì lo àpèjúwe ohun tí àwọn ọmọdé ń ṣe yìí nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Mátíù 11:16, 17) Nígbà tí Jésù wà lẹ́nu ìrìn àjò rẹ̀ ìkẹyìn sí Jerúsálẹ́mù, ó mọ̀ pé òun yóò jìyà níbẹ̀, wọ́n á sì pa òun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà táwọn èèyàn ń kó àwọn ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fẹ́ máa lé àwọn ọmọ náà padà, bóyá torí kí wọ́n má bàa yọ Jésù lẹ́nu nítorí gbogbo wàhálà tí ń bẹ níwájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí. Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé inú òun “máa ń dùn sí” àwọn ọmọdé gan-an, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.”—Máàkù 10:13, 14.
9. Kí nìdí tí ohun tá a bá ń ṣe fi ṣe pàtàkì ju ohun tá a bá ń sọ lọ?
9 A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà táwọn ọmọdé bá wá sọ́dọ̀ wa, báwo la ṣe máa ń ṣe sí wọn, pàápàá nígbà tí ọwọ́ wa bá dí? Ṣé bí Jésù ti ṣe ni? Ohun tó yẹ káwọn òbí máa ṣe fáwọn ọmọ wọn gan-an ni Jésù ṣe, ìyẹn ni pé ó wáyè fún àwọn ọmọdé, ó sì gbọ́ tiwọn. Lóòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo fẹ́ràn rẹ” ṣe pàtàkì. Àmọ́ ìṣe àwọn òbí máa ń nípa lórí àwọn ọmọ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lọ. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu ìwọ tó o jẹ́ òbí nìkan kọ́ ni yóò fi hàn pé o fẹ́ràn ọmọ rẹ, ìṣe rẹ gan-an ni yóò fi hàn jù. Yóò sì hàn nínú àkókò tó ò ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, bó o ṣe ń gbọ́ tiwọn tó, àti bó o ṣe ń tọ́jú wọn. Àmọ́ ṣá o, bá a tiẹ̀ ṣe gbogbo èyí, ó lè má yọrí sí ibi tá a fọkàn sí. Nítorí àwọn ọmọ náà lè má tètè ṣe ohun tá a retí pé kí wọ́n ṣe. Ọ̀ràn náà gba sùúrù. A lè kọ́ bá a ṣe lè ní sùúrù tá a bá tẹ̀ lé ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò.
Sùúrù àti Ìyọ́nú Jésù
10. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ náà ṣe ohun tí Jésù retí lójú ẹsẹ̀?
10 Jésù mọ̀ nípa ẹ̀mí ìdíje tó ń jà ràn-ìn láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí wọ́n ń fẹ́ ipò ọlá. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn tí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé Kápánáúmù, ó bi wọ́n pé: “‘Kí ni ẹ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?’ Wọ́n dákẹ́, nítorí lójú ọ̀nà, wọ́n ti jiyàn láàárín ara wọn lórí ẹni tí ó tóbi jù.” Dípò tí Jésù ì bá fi bínú sí wọn kó sì bá wọn wí, ńṣe ló fi sùúrù kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, kí wọ́n lè mọ béèyàn ṣe ń ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Máàkù 9:33-37) Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ yìí ṣe ohun tí Jésù retí? Rárá, kò ṣe é lójú ẹsẹ̀. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn ni Jákọ́bù àti Jòhánù ní kí màmá àwọn wá bá wọn pàrọwà sí Jésù pé kó fi wọ́n sí ipò ọlá nínú Ìjọba ọ̀run. Ńṣe ni Jésù tún fi sùúrù tún èrò wọn ṣe.—Mátíù 20:20-28.
11. (a) Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù, iṣẹ́ wo làwọn àpọ́sítélì Jésù kọ̀ láti ṣe lẹ́yìn tí àwọn àti Jésù dé yàrá òkè? (b) Kí ni Jésù ṣe, ǹjẹ́ ìsapá rẹ̀ kẹ́sẹ járí lákòókò yẹn?
11 Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa dé, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sì pàdé níbì kan láti ṣe Ìrékọjá náà. Nígbà tí wọ́n dé yàrá òkè, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà tó múra tán láti wẹ ẹsẹ̀ àwọn yòókù gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti máa ń ṣe. Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ tàbí àwọn obìnrin ló máa ń ṣe iṣẹ́ yìí nínú ilé. (1 Sámúẹ́lì 25:41; 1 Tímótì 5:10) Ọ̀ràn náà á mà ba Jésù nínú jẹ́ gan-an o, nígbà tó rí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò tíì jáwọ́ nínú wíwá ipò ọlá! Jésù wá wẹ ẹsẹ̀ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun, kí wọ́n máa lo ara wọn fún àwọn ẹlòmíràn. (Jòhánù 13:4-17) Ǹjẹ́ wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé ní alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà “awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.”—Lúùkù 22:24.
12. Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jésù nínú títọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà?
12 Nígbà táwọn ọmọ rẹ ò bá ṣe ohun tó o ní kí wọ́n ṣe, ǹjẹ́ ìwọ tó o jẹ́ òbí máa ń ronú nípa bí ọ̀ràn náà ṣe ní láti rí lára Jésù? Rántí pé Jésù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn àpọ́sítélì òun sú òun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tètè ṣàtúnṣe lórí ohun tó bá wọn sọ. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, sùúrù rẹ̀ so èso rere. (1 Jòhánù 3:14, 18) Ẹ̀yin òbí, ẹ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí ẹ ní ìfẹ́ àti sùúrù bíi tirẹ̀, ẹ má sì jáwọ́ nínú títọ́ àwọn ọmọ yín sọ́nà.
13. Kí nìdí tí òbí kan ò fi gbọ́dọ̀ máa jágbe mọ́ ọmọ tó ń béèrè nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀?
13 Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé ire àwọn jẹ wọ́n lọ́kàn. Jésù fẹ́ mọ ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rò, ìdí nìyẹn tó fi máa ń fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń béèrè ìbéèrè. Ó béèrè èrò wọn nípa àwọn ọ̀ràn kan. (Mátíù 17:25-27) Dájúdájú, ohun tó lè mú kí ẹ̀kọ́ wọni lọ́kàn ṣinṣin ni pé kí ẹni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ fetí sílẹ̀ dáadáa sí ẹni tó ń kọ́, kó sì ní ojúlówó ìfẹ́ sí i. Òbí gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó máa mú kó jágbe mọ́ ọmọ tó ń béèrè nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ máa sọ fún ọmọ náà pé: “Má yọ mí lẹ́nu! Ṣé o ò ri pé ọwọ́ mi dí ni?” Bí ọwọ́ òbí náà bá dí lóòótọ́, ó yẹ kó sọ fún ọmọ náà pé àwọn á jíròrò ọ̀ràn náà nígbà tí òun bá ṣe tán. Àwọn òbí sì gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, ọmọ náà á mọ̀ pé òbí òun fẹ́ràn òun tinútinú, ìyẹn á sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti finú han òbí rẹ̀.
14. Kí làwọn òbí lè kọ́ lọ́dọ̀ Jésù nípa bí wọ́n á ṣe máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn?
14 Ǹjẹ́ àwọn òbí lè fìfẹ́ tí wọ́n ní sáwọn ọmọ wọn hàn nípa fífọwọ́ kọ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n sì máa gbá wọn mọ́ra? Ohun mìíràn táwọn òbí tún ní láti kọ́ lọ́dọ̀ Jésù nìyẹn. Bíbélì sọ pé ó “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:16) Báwo lo ṣe rò pé ohun tó ṣe náà ṣe rí lára àwọn ọmọ wọ̀nyẹn? Áà, inú wọn dùn, wọ́n sì yọ̀ mọ́ Jésù! Tí ìfẹ́ bá wà láàárín ẹ̀yin òbí àtàwọn ọmọ yín, wọ́n á tètè máa gbọ́ràn sí yín lẹ́nu.
Bó Ṣe Yẹ Kí Àkókò Tí Òbí Máa Lò Pẹ̀lú Ọmọ Rẹ̀ Pọ̀ Tó
15, 16. Kí ni èrò ọ̀pọ̀ èèyàn nípa ọmọ títọ́, kí ló sì fa irú èrò bẹ́ẹ̀?
15 Àwọn kan ò gbà pé ó pọn dandan pé kí òbí máa lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ kó sì máa fìfẹ́ gbọ́ tiwọn. Ọ̀nà ìgbàtọ́mọ táwọn ẹlẹ́nu-dùn-juyọ̀ kan ń polongo rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ sì gbà pé ó dára gan-an ni èyí tí wọ́n pè ní lílo àkókò tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ohun táwọn tó ń polongo àṣà yìí ń wí ni pé àwọn òbí ò ní láti lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ní kí ìwọ̀nba àkókò tí àwọn òbí bá máa lò pẹ̀lú wọn sáà ti jẹ́ àkókò tó nítumọ̀, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fara balẹ̀ ṣètò rẹ̀. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìlànà ká sáà ti lo àkókò tó gbámúṣé yìí dára? Ṣé ire àwọn ọmọ ló jẹ àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà yìí lógún tó bẹ́ẹ̀?
16 Òǹkọ̀wé kan tó ti bá ọ̀pọ̀ ọmọdé sọ̀rọ̀ sọ pé ohun tí wọ́n “ń fẹ́ jù lọ lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn ni pé kí wọ́n máa lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú wọn,” kí wọ́n sì tún “máa gbọ́ tiwọn láìsí ìpínyà ọkàn.” Àmọ́ o, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan sọ pé: “Ẹ̀rí ọkàn ló ń yọ àwọn òbí lẹ́nu tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí dá àṣà [lílo àkókò tó gbámúṣé]. Ńṣe làwọn èèyàn ń fìyẹn wá ọ̀nà tí wọ́n á fi lè túbọ̀ dín àkókò tí wọ́n ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kù.” Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò táwọn òbí máa lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn pọ̀ tó?
17. Kí làwọn ọmọ ń fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn?
17 Bíbélì ò sọ bó ṣe yẹ kí àkókò náà pọ̀ tó. Àmọ́, ó rọ àwọn òbí nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ilé wọn, nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí wọ́n bá dìde. (Diutarónómì 6:7) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn lójoojúmọ́.
18. Báwo ni Jésù ṣe lo gbogbo àǹfààní tó ní láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí sì lè rí kọ́ nínú èyí?
18 Jésù rí i dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára òun bí wọ́n ṣe jọ ń jẹun, tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, tí wọ́n sì jọ ń sinmi. Ó tipa bẹ́ẹ̀ lo gbogbo àǹfààní tó ní láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Máàkù 6:31, 32; Lúùkù 8:1; 22:14) Bẹ́ẹ̀ náà làwọn òbí ṣe gbọ́dọ̀ wà lójúfò, kí wọ́n máa lo gbogbo àyè tó bá yọ láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé kí wọ́n sì máa lo àwọn àkókò náà láti kọ́ wọn láwọn ọ̀nà Jèhófà.
Ohun Tó Yẹ Ká Kọ́ Wọn àti Bí A Ó Ṣe Kọ́ Wọn
19. (a) Kí ló tún pọn dandan láti ṣe yàtọ̀ sí ká máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wa? (b) Kí ló yẹ káwọn òbí dìídì kọ́ àwọn ọmọ wọn?
19 Ṣùgbọ́n lílo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ tàbí ká tiẹ̀ máa kọ́ wọn nìkan kọ́ ló máa mú ká lè tọ́ wọn yanjú o. Ohun tá à ń kọ́ wọn gan-an tún ṣe pàtàkì. Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ pé ẹ̀kọ́ yìí gbọ́dọ̀ dá lé lórí. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí . . . , kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.” Kí ni “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí” tó yẹ ká kọ́ àwọn ọmọ? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tó wà ní ẹsẹ tó ṣáájú èyí ni, tó sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5-7) Jésù sọ pé èyí ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo òfin Ọlọ́run. (Máàkù 12:28-30) Nítorí náà, àwọn òbí ní láti dìídì kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà, kí wọ́n sì ṣàlàyé fún wọn pé òun nìkan ṣoṣo ló yẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́, àti pé òun ló yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa sìn.
20. Kí ni Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí àwọn òbí ayé ìgbàanì kọ́ àwọn ọmọ wọn?
20 Ṣùgbọ́n “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,” tá a rọ àwọn òbí láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn kò mọ sí kìkì pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn o. Wàá rí i pé ní orí karùn-ún ìwé Diutarónómì yẹn, Mósè tún padà mẹ́nu kan àwọn òfin tí Ọlọ́run kọ sórí wàláà òkúta, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá. Lára òfin yìí ni, má purọ́, má jalè, má pànìyàn, má ṣe panṣágà. (Diutarónómì 5:11-22) Ohun tí èyí ń tẹ̀ mọ́ àwọn òbí ayé ìgbàanì lọ́kàn ni pé ó pọn dandan kí wọ́n gbin ìwà ọmọlúwàbí sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí lóde òní gbọ́dọ̀ máa fún àwọn ọmọ wọn ní irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ kí ayé wọn lè dára, kí wọ́n sì lè láyọ̀ tí wọ́n bá dàgbà.
21. Kí ni ìtọ́ni tá a fún àwọn òbí pé kí wọ́n “fi ìtẹnumọ́ gbin” ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ wọn túmọ̀ sí?
21 Tún kíyè sí i pé Ọlọ́run fún àwọn òbí nítọ̀ọ́ni nípa bí wọn yóò ṣe fi “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,” tàbí àwọn òfin yẹn, kọ́ àwọn ọmọ wọn. Àṣẹ náà sọ pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ.” Ọ̀rọ̀ náà “fi ìtẹnumọ́ gbìn” níhìn-ín túmọ̀ sí “láti kọ́ni àti láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọni lọ́kàn nípa sísọ nǹkan lásọtúnsọ tàbí nípa gbígbani níyànjú tàbí nípa títẹ ọ̀rọ̀ mọ́ni lọ́kàn dáadáa.” Ohun tí Ọlọ́run wá ń tipa báyìí sọ fáwọn òbí ni pé, kí wọ́n ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa gbin ọ̀rọ̀ tẹ̀mí sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn.
22. Kí la sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ òbí ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, kí sì nìyẹn túmọ̀ sí?
22 Òbí ní láti lo òye kó tó lè gbé irú ètò bẹ́ẹ̀ kalẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí ìwọ sì so wọ́n [ìyẹn, “ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,” tàbí àwọn òfin Ọlọ́run] gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ rẹ, kí wọ́n sì jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú rẹ; kí ìwọ sì kọ wọ́n sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sára àwọn ẹnubodè rẹ.” (Diutarónómì 6:8, 9) Èyí ò túmọ̀ sí pé káwọn òbí dìídì kọ àwọn òfin Ọlọ́run sára àwọn òpó ilẹ̀kùn àti ẹnubodè wọn tàbí kí wọ́n dìídì so ẹ̀dà rẹ̀ mọ́ ọwọ́ àwọn ọmọ wọn, tàbí kí wọ́n dè é mọ́ àárín ojú wọn. Àmọ́, ó dájú pé ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé kí àwọn òbí máa rán àwọn ọmọ wọn létí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ wọn déédéé, kì í ṣe ní ìdákúrekú, nípa bẹ́ẹ̀ yóò dà bíi pé àwọn ẹ̀kọ́ Ọlọ́run yìí ń bẹ níwájú àwọn ọmọ náà nígbà gbogbo.
23. Kí la óò gbé yẹ̀ wò nínú ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀?
23 Kí ni àwọn nǹkan mìíràn tó ṣe pàtàkì gan-an táwọn òbí ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti kọ́ àwọn ọmọ ní ọ̀nà tí wọ́n á gbà dáàbò bo ara wọn lóde òní? Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí fún àwọn òbí láti lè kọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó gbéṣẹ́? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó kan ọ̀pọ̀ òbí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí ka ọmọ sí ogún iyebíye?
• Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí àtàwọn ẹlòmíràn lè kọ́ lára Jésù?
• Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò táwọn òbí á fi máa gbọ́ tàwọn ọmọ wọn pọ̀ tó?
• Kí ló yẹ ká máa kọ́ àwọn ọmọ, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwés 11]
Ìgbà wo ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn, báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n kọ́ wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwés 12]
Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run wà níwájú àwọn ọmọ wọn