Bí A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọdé Nípa Ọlọ́run—Àwọn Ọ̀nà Wo Ló Dára Jù Lọ Láti Gbà Kọ́ Wọn?
“Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” —DIUTARÓNÓMÌ 6:6, 7.
NÍGBÀ míì, gbogbo nǹkan lè tojú sú àwọn òbí nítorí bí iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ wọn ti pọ̀ tó. Àmọ́, nígbà tí wọ́n bá wá àmọ̀ràn, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àmọ̀ràn táwọn èèyàn bá fún wọn lè mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ dojú rú. Àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tètè máa ń fún wọn ní àwọn àbá. Àwọn ìwé, àwọn àpilẹ̀kọ nínú ìwé ìròyìn àti àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń fún àwọn òbí ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àmọ̀ràn tó ta kora nígbà míì.
Àmọ́ Bíbélì máa ń fún àwọn òbí ní ìmọ̀ràn lórí ohun tí wọ́n máa fi kọ́ àwọn ọmọ wọn, yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó wúlò nípa bí wọ́n ṣe máa kọ́ wọn. Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a lò níbẹ̀rẹ̀ ti sọ, àwọn òbí ní láti wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run lójoojúmọ́. A máa jíròrò àwọn àbá mẹ́rin tá a gbé ka Bíbélì, èyí tó ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run.
1. Fi àwọn ìṣẹ̀dá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Àwọn òbí lè ṣe ohun tó pọ̀ láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run nípa jíjẹ́ káwọn ọmọ náà lóye àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí àwọn ìṣẹ̀dá ń fi hàn.
Jésù lo ọ̀nà yìí nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” (Mátíù 6:26) Ìfẹ́ àti àánú tó jẹ́ ànímọ́ Jèhófà ni Jésù ń sọ nípa wọn níbi yìí. Àmọ́, ó tún ṣe ohun míì. Ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe ń fi àwọn ànímọ́ yẹn hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀.
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn èèrà, ó sì fi wọ́n kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Ó ní: “Tọ eèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; wo àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì di ọlọ́gbọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso, ó ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ àní ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ó ti kó àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè.” (Òwe 6:6-8) Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó dára nìyẹn láti gbà kọ́ni nípa béèyàn ṣe lè múra sílẹ̀ fún ohun kan téèyàn fẹ́ ṣe, kí èèyàn sì lo okun tí Ọlọ́run ń fúnni láti ṣe àwọn nǹkan náà!
Àwọn òbí lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí Jésù àti Sólómọ́nì gbà kọ́ni tí wọ́n bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí: (1) Ní káwọn ọmọ rẹ sọ, irú àwọn ẹranko, àwọn ewéko àtàwọn igi tí wọ́n fẹ́ràn. (2) Kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn ẹranko, àwọn ewéko àtàwọn igi náà. (3) Mọ ohun táwọn ìṣẹ̀dá náà kọ́ni nípa Ọlọ́run.
2. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa bó ṣe ṣe sí àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé ayé rí, Jésù nìkan ló ní àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó lè sọ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìbéèrè ló máa ń béèrè. Ó fẹ́ mọ èrò àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ àti bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn. (Mátíù 17:24, 25; Máàkù 8:27-29) Bákan náà, àwọn òbí ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ kí wọ́n lè kọ́ wọn lọ́nà tó múná dóko, wọ́n ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn sọ èrò wọn ní fàlàlà.
Bí àwọn ọmọ náà bá ní ìwà burúkú kan tàbí tí wọn kò bá tètè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ńkọ́? Wo ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Nígbà míì, wọ́n máa ń jiyàn láàárín ara wọn, wọn kò sì tètè rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀ Jésù mú sùúrù, léraléra ló sì ń sọ ìdí tí wọ́n fi ní láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Máàkù 9:33, 34; Lúùkù 9:46-48; 22:24, 25) Àwọn òbí tí wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù á máa fi sùúrù tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà, tó bá sì pọn dandan, wọ́n á ní láti sọ ohun kan léraléra títí àwọn ọmọ náà á fi lóye rẹ̀.a
3. Fi àpẹẹrẹ rẹ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó máa dára gan-an tí àwọn òbí bá fetí sí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù. Ó sọ fún wọn pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí?”—Róòmù 2:21.
Ìmọ̀ràn yẹn wúlò gan-an nítorí ohun tí àwọn òbí bá ń ṣe ni àwọn ọmọ máa ń tẹ̀ lé ju ohun táwọn òbí bá ń sọ lọ. Àwọn òbí tó bá ń ṣe ohun tí wọ́n ń sọ làwọn ọmọ wọn sábà máa ń fetí sí ohun táwọn náà bá sọ.
4. Bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn láti kékeré. Àwọn èèyàn ń sọ ohun tó dáa nípa Tímótì ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó yàn án láti máa bá òun rin ìrìn àjò lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. (Ìṣe 16:1, 2) Ìdí kan tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni wọ́n ti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́.” Yàtọ̀ sí pé ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ń ka Ìwé Mímọ́ fún un, wọ́n tún ràn án lọ́wọ́ kó lè ronú lórí àwọn òtítọ́ tó wà nínú àwọn ìwé náà.—2 Tímótì 1:5; 3:14, 15.
Ibi Tó O Ti Lè Rí Ìrànwọ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé tí àwọn òbí lè lò láti fi kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Wọ́n dìídì ṣe àwọn kan nítorí àwọn ọmọdé. Wọ́n ṣe àwọn ìwé míì láti ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa bá àwọn ọmọ wọn tí kò tíì pé ogún ọdún sọ̀rọ̀ ní fàlàlà.b
Àmọ́ ṣá o, kí àwọn òbí tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run, ó yẹ kí wọ́n mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè kan tó ta kókó tí àwọn ọmọ wọn lè béèrè. Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé? Ibo ni àwọn òkú wà? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì kí ìwọ àti ìdílé rẹ lè sún mọ́ Ọlọ́run.—Jákọ́bù 4:8.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “fi ìtẹnumọ́ gbìn” ní Diutarónómì 6:7 ní ìtumọ̀ kéèyàn má sọ ohun kan léraléra.
b Àwọn òbí lè lo ìwé náà, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà fún àwọn ọmọdé. Ìwé yìí sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi kọ́ni. Tàbí kí wọ́n lo Ìwé Ìtàn Bíbélì, èdè tó rọrùn la fi kọ ìwé yìí, ó sì kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì. Wọ́n tún lè lo ìwé kan tó ń jẹ́, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Apá Kejì fún àwọn ọ̀dọ́.