Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ náà, “bóyá” tí wọ́n lò nínú Sefanáyà 2:3 túmọ̀ sí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò ní ìdánilójú pé àwọn á rí ìyè àìnípẹ̀kun?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà kà pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” Kí nìdí tí ẹsẹ yìí fi sọ pé “bóyá”?
Ká lè lóye ohun tí Jèhófà yóò ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní Amágẹ́dọ́nì, á dára ká rántí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe fún àwọn tó kú kí ìdájọ́ náà tó dé. Àwọn kan yóò jíǹde sí ọ̀run, wọ́n á sì di ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́. Àwọn yòókù yóò sì jíǹde sórí ilẹ̀ ayé láti máa gbé nínú Párádísè títí láé. (Jòhánù 5:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 15:53, 54) Bí Jèhófà bá rántí àwọn adúróṣinṣin rẹ̀ tí wọ́n kú ṣáájú Amágẹ́dọ́nì tó sì san èrè fún wọn, ó dájú pé yóò ṣe ohun kan náà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà láàyè ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù tó ní ìmísí tún fúnni níṣìírí gan-an. Ó kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run; àti nípa sísọ àwọn ìlú ńlá náà Sódómù àti Gòmórà di eérú, ó dá wọn lẹ́bi, . . . ó sì dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè . . . Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (2 Pétérù 2:5-9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà pa àwọn èèyàn búburú run nígbà àtijọ́, ó dá Nóà àti Lọ́ọ̀tì sí, nítorí pé wọ́n fi ìṣòtítọ́ sìn ín. Jèhófà yóò tún dá àwọn tó ń fọkàn sìn ín nídè bákan náà nígbà tó bá pa àwọn èèyàn búburú run ní Amágẹ́dọ́nì. Àwọn olódodo èèyàn tí wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yóò la ìparun náà já.—Ìṣípayá 7:9, 14.
Nítorí náà, lílò tá a lo ọ̀rọ̀ náà “bóyá” ní Sefanáyà 2:3 jọ pé kì í ṣe ọ̀ràn bóyá Ọlọ́run lágbára tàbí kò lágbára láti pa àwọn tó bá rí ojú rere rẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá òdodo àti ọkàn tútù ni ọ̀rọ̀ irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ bóyá a óò pa á mọ́ tàbí a kò ní pa á mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà. Nítorí pé kìkì téèyàn bá ń bá a nìṣó láti máa wá ọkàn tútù àti òdodo láìjáwọ́ la ó pà á mọ́.—Sefanáyà 2:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò”