ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SEFANÁYÀ 1–HÁGÁÌ 2
Ẹ Wá Jèhófà Kí Ọjọ́ Ìbínú Rẹ̀ Tó Dé
Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀, ó kọjá pé ká kàn ya ara wa sí mímọ́ fún un, a tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Sefanáyà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Wá Jèhófà: Ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa
Wá òdodo: Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà
Wá ọkàn tútù: Máa fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ìfẹ́ Jèhófà kó o sì gba ìbáwí rẹ̀
Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa wá Jèhófà, òdodo àti ọkàn tútù?