Ìtàn Ìgbésí Ayé
Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
GẸ́GẸ́ BÍ JOYCELYN VALENTINE ṢE SỌ Ọ́
Ní ọdún 1989, ọkọ mi lọ ṣiṣẹ́ lókè òkun. Ó ṣèlérí pé òun á máa fi owó ránṣẹ́ kí n lè máa fi tọ́jú àwọn ọmọ mi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ. Àmọ́ ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kọjá, mi ò gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ oṣù kọjá, síbẹ̀ mi ò gbúròó ọkọ mi. Mo ṣáà ń sọ fún ara mi pé, ‘Tí nǹkan bá ti ṣẹnuure fún un, yóò padà wálé.’
NÍGBÀ tó yá ara mi ò gbà á mọ́, nítorí pé kò sówó tí mo fi máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Ọ̀pọ̀ òru ni mi ò fi rí oorun sùn, tí mò ń bi ara mi tìyanutìyanu pé, ‘Kí nìdí tó fi lè ṣe irú nǹkan yìí sí ìdílé rẹ̀?’ Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo gbà pé láìsí àní-àní, ọkọ mi ti pa wá tì nìyẹn, èyí sì bà mi nínú jẹ́ gan-an. Ó ti tó ọdún mẹ́rìndínlógún tó ti fi wá sílẹ̀ báyìí, síbẹ̀ kò tíì padà wálé. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í nìkan tọ́ àwọn ọmọ mi nìyẹn láìsí ọkọ tó máa ràn mí lọ́wọ́. Èyí ò rọrùn rárá, àmọ́ rírí tí mò ń rí àwọn ọmọ mi tí wọ́n ń rìn ni ọ̀nà Jèhófà ń fún mi láyọ̀ gan-an. Àmọ́, kí n tó sọ bí ìdílé mi ṣe borí ìṣòro náà, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ nípa ara mi.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wá Ìtọ́sọ́nà Bíbélì
Ọdún 1938 ni wọ́n bí mi ni erékùṣù Caribbean, lórílẹ̀-èdè Jàmáíkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò ṣe ìsìn kankan rí, síbẹ̀ ó ka ara rẹ̀ sẹ́nì kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Ó sábà máa ń sọ fún mi lálaalẹ́ pé kí n ka ìwé Sáàmù inú Bíbélì sóun létí. Láìpẹ́, mo mọ ọ̀pọ̀ sáàmù sórí. Ṣọ́ọ̀ṣì kan tó wà ní erékùṣù náà ni màmá mi máa ń lọ, ó sì máa ń mú mi lọ sáwọn ìpàdé ìsìn tí wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Ohun tí wọ́n máa ń sọ fún wa láwọn ìpàdé wọ̀nyẹn ni pé Ọlọ́run máa ń mú àwọn èèyàn rere lọ sọ́run, ó sì máa ń sun àwọn ẹni ibi títí ayé nínú ìná ọ̀run àpáàdì. Wọ́n tún sọ fún wa pé Jésù ni Ọlọ́run àti pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé. Ọ̀rọ̀ náà ò yé mi, ẹ̀rù Ọlọ́run wá ń bà mí. Mo wá ń bi ara mi pé, ‘Báwo ni Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa yóò ṣé máa dá èèyàn lóró nínú iná?’
Ìrònú ọ̀run àpáàdì di ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ sí mi lọ́kàn. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nípasẹ̀ ìkọ̀wé-ránṣẹ́, èyí tí Ìjọ Seventh-Day Adventist ń ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀. Wọ́n sọ pé Ọlọ́run kò ní dá àwọn ẹni ibi lóró títí láé, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa jó wọn di eérú nínú iná. Èyí mọ́gbọ́n dání létí mi ju ohun tí mo gbọ́ tẹ́lẹ̀. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé ìsìn wọn nìyẹn. Àmọ́ mo rí i pé ohun tí wọ́n ń fi kọ́ni kò lórí kò nídìí, ohun tí mo sì ń gbọ́ níbẹ̀ kò yí èrò mi nípa ìwà tí kò dáa padà.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, gbogbo èèyàn ló gbà pé àgbèrè ò dáa. Síbẹ̀, èmi àti ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn míì gbà pé kìkì àwọn tí kò bá fi ìbálòpọ̀ mọ sọ́dọ̀ ẹnì kan ni alágbèrè. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ka ẹni méjì tó jọ ń ní ìbálòpọ̀ láìṣe ìgbéyàwó sí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí wọ́n ò bá ṣáà ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Hébérù 13:4) Ohun tá a gbà pé ó tọ́ yìí ló sọ mi dẹni tó bí ọmọ mẹ́fà láìṣe ìgbéyàwó.
Mo Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí
Lọ́dún 1965, Vaslyn Goodison àti Ethel Chambers wá ń gbé ní ibì kan tó ń jẹ́ Bath nítòsí ọ̀dọ̀ wa. Aṣáájú-ọ̀nà ni wọ́n, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ló wá bá bàbá mi sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kan. Ó fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n sọ pé àwọn á wá máa kọ́ ọ nílé. Tí mo bá wà nílé nígbà tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n máa ń bá èmi náà sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì í fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá, síbẹ̀ mo pinnu pé máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn kí n lè já irọ́ wọn.
Mo da àìmọye ìbéèrè bò wọ́n lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí yìí fi Bíbélì dáhùn gbogbo wọn pátá. Àwọn ló jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn òkú ò mọ ohunkóhun, pé wọn ò sì jìyà nínú ọ̀run àpáàdì. (Oníwàásù 9:5, 10) Wọ́n tún jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn èèyàn máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà mọ́ nígbà tó yá, síbẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wa. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn létòlétò tó sì máa ń tòrò minimini jẹ́ kí n túbọ̀ mọ ohun púpọ̀ sí i nípa Jèhófà. Mo tún bá wọn lọ sáwọn ìpàdé àyíká àtàwọn ìpàdé àgbègbè, ìyẹn àwọn àpéjọ ńlá táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe. Bí mo ṣe dẹni tó ń ka Bíbélì yìí wá jẹ́ kó wù mi gan-an láti jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tínú rẹ̀ dùn sí. Àmọ́, ohun kan wà tó ń dí mi lọ́wọ́.
Lákòókò yẹn, èmi àti ọkùnrin tí mo bí mẹ́ta lára àwọn ọmọ mi mẹ́fà fún la jọ ń gbé láìṣègbéyàwó. Mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé inú Ọlọ́run ò dùn sí kéèyàn máa ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó, ẹ̀rí ọkàn mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. (Òwe 5:15-20; Gálátíà 5:19) Bí ìfẹ́ tí mo ní sí òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń wù mí láti mú ìgbésí ayé mi bá òfin Ọlọ́run mu. Níkẹyìn mo ṣe ìpinnu kan. Mo sọ fún ọkùnrin tá a jọ ń gbé pọ̀ pé kó jẹ́ ká ṣègbéyàwó tàbí ká pínyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fara mọ́ ohun tí mo gbà gbọ́, síbẹ̀ a ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu ní August 15, 1970, ìyẹn ọdún márùn-ún lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí kọ́kọ́ bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tó di oṣù December ọdún 1970, mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.
Ní ti iṣẹ́ ìwàásù, mi ò lè gbàgbé ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sóde ìwàásù. Ẹ̀rù ń bà mi, mi ò sì mọ bí mo ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Kí n sòótọ́, inú mi dùn nígbà tí ẹni tá a bá sọ̀rọ̀ nílé tá a kọ́kọ́ wọ̀ kò jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ lọ títí. Àmọ́, nígbà tó yá ẹ̀rù ò bà mí mọ́. Nígbà tá a ṣe tán lọ́jọ́ yẹn, inú mi dùn gan-an nítorí pé mo ti bá àwọn èèyàn bíi mélòó kan sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, wọ́n sì gba díẹ̀ lára àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì.
Ohun Tí Mo Ṣe Tí Ìdílé Mi Fi Lágbára Nípa Tẹ̀mí
Nígbà tó fi máa di ọdún 1977, àwọn ọmọ mi ti di mẹ́jọ. Mo pinnu láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe kí n lè ran agbo ilé mi lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. (Jóṣúà 24:15) Nípa bẹ́ẹ̀, mo sa gbogbo agbára mi láti rí i pé mò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa déédéé. Nígbà míì, tó bá rẹ̀ mí, mo máa ń tòògbé nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ bá ń ka ìpínrọ̀ kan lọ́wọ́, àwọn ọmọ á sì jí mi. Àmọ́, kò sígbà kan tí àárẹ̀ mú wa débi tá ò ní ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa.
Mo tún máa ń gbàdúrà déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. Bí mo bá tí rí i pé wọ́n ti dàgbà tó, máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fúnra wọn gbàdúrà sí Jèhófà. Mo sì máa ń rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gbàdúrà kó tó sùn lálẹ́. Mó tún máa ń gbàdúrà pẹ̀lú ọmọ kọ̀ọ̀kan tí kò bá tíì dàgbà tó láti dá gbàdúrà.
Ọkọ mi ò kọ́kọ́ gbà pé kí n máa kó àwọn ọmọ lọ sípàdé ìjọ. Àmọ́, nígbà tó rí i pé kò ní rọrùn fóun láti máa bójú tó wọn nígbà tí mo bá wà nípàdé, kò wá fi bẹ́ẹ̀ ṣàtakò mọ́. Tí alẹ́ bá ti lẹ́, ó máa ń fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti lọ bá wọn ṣeré fúngbà díẹ̀, àmọ́ ó mọ̀ pé àwọn ọmọ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló máa tẹ̀ lé òun lẹ́yìn nígbà tóun bá ń lọ, kò sì fẹ́ bẹ́ẹ̀! Nígbà tó yá, ó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi múra fáwọn ọmọ náà pàápàá tá a bá ti fẹ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Kò pẹ́ rárá tí lílọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ àti jíjáde òde ẹ̀rí déédéé fi mọ́ àwọn ọmọ mi lára. Nígbà tí wọ́n bá wà ní ọlidé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn, wọ́n sábà máa ń bá àwọn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nínú ìjọ jáde òde ẹ̀rí. Èyí ran àwọn ọmọ mi lọwọ́ gan-an láti ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìjọ àti fún ìṣẹ́ ìwàásù.—Mátíù 24:14.
Àwọn Àkókò Ìdánwò
Kí nǹkan lè túbọ̀ ṣẹnuure fún ìdílé wa, ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ ṣiṣẹ́ lókè òkun. Ó lè fi wá sílẹ̀ fúngbà pípẹ́ o, ṣùgbọ́n tó bá yá á padà wá. Àmọ́, nígbà tó di ọdún 1989, ó lọ kò sì padà wá mọ́. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ ṣáájú, ọ̀ràn ọkọ mi tí mi ò rí mọ́ yìí dà mí lọ́kàn rú gan-an. Ọ̀pọ̀ òru ni mo fi sunkún tí mo sì gbàdúrà sí Jèhófà kíkankíkan pé kó tù mí nínú kò jẹ́ kí n lè fara da ìṣòro náà. Mo sì rí i pé ó dáhùn àdúrà mi. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Aísáyà 54:4 àti 1 Kọ́ríńtì 7:15 fi mí lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì fún mi lókun láti máa gbé ìgbésí ayé mi lọ. Bákan náà làwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ tún ràn mí lọ́wọ́ nípa tara, wọ́n sì tún ń fún mi níṣìírí. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe fún mi.
A tún kojú àwọn àdánwò mìíràn. Ìgbà kan wà tí wọ́n yọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ mi obìnrin nínú ìjọ nítorí pé ó ṣe ohun tó lòdì sí Ìwé Mímọ́. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ mi gan-an, àmọ́ ìṣòtítọ́ mi sí Jèhófà ló ṣáájú ohun gbogbo. Nítorí bẹ́ẹ̀, lákòókò yẹn, ohun tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn ṣe sẹ́ni tí wọ́n bá yọ lẹ́gbẹ́ lèmi àtàwọn ọmọ mi tó kù ṣe. (1 Kọ́ríńtì 5:11, 13) Oríṣiríṣi kòbákùngbé ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn tí kò lóye ọwọ́ tá a fi mú ọ̀ràn náà sọ sí wa. Àmọ́ nígbà tí wọ́n gba ọmọ mi padà sínú ìjọ, ọkọ rẹ̀ sọ fún mi pé bá a ṣe tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yẹn wú òun lórí gan-an. Òun náà ti ń sin Jèhófà pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ báyìí.
Bá A Ṣe Borí Ìṣòro Ìṣúná Owó
Nígbà tí ọkọ mi fi wá sílẹ̀ yẹn, mi ò níṣẹ́ gidi kan lọ́wọ́ tó ń mówó wọlé, a ò sì rówó gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ipò tá a bára wa yìí kọ́ wa láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tá a bá ní, ká sì gbà pé ọrọ̀ tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì ju kéèyàn máa lé nǹkan tára lọ. Báwọn ọmọ ṣe ń mọ̀ pé ó yẹ kí gbogbo wọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́ ni ìdè àárín wọn túbọ̀ ń lágbára sí i. Báwọn tó dàgbà bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, tinútinú ni wọ́n fi máa ń ran àwọn àbúrò wọn lọ́wọ́. Èyí tó dàgbà jù lára àwọn ọmọbìnrin mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Marseree ran Nicole àbúrò rẹ̀ obìnrin tó kéré jù lọ́wọ́ láti kàwé jáde nílé ẹ̀kọ́ girama. Yàtọ̀ síyẹn, èmi náà tún ṣí ṣọ́ọ̀bù kékeré kan tí mo ti ń ta àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ìwọ̀nba èrè díẹ̀ tí mò ń rí níbẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ díẹ̀ lára bùkátà wa.
Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ rí. Nígbà kan, mo sọ fún arábìnrin kan pé bí ipò nǹkan ṣe rí kò lè jẹ́ ká lọ sípàdé àgbègbè. Ó fèsì pé: “Arábìnrin Val, tó o bá ti gbọ́ pé àsìkò ìpàdé àgbègbè ti tó, bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́! Jèhófà á pèsè.” Mo tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ yìí. Jèhófà sì pèsè, bó sì ṣe ń pèsè fún wa látìgbà náà nìyẹn. Ìdílé wa ò tìtorí owó pa ìpàdé àyíká tàbí ìpàdé àgbègbè kankan jẹ rí.
Lọ́dún 1988, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Gilbert ba orílẹ̀-èdè Jàmáíkà jẹ́ gan-an, a ní láti fi ilé wa sílẹ̀, a sì sá lọ síbi tó láàbò. Nígbà tí ìjì náà dáwọ́ dúró díẹ̀, èmi àti ọmọ mi ọkùnrin kúrò níbi tí wọ́n kó wa sí a sì sáré lọ wo ilé wà tó ti wó lulẹ̀. Bá a ṣe ń wo inú àwókù ilé náà kiri, mo rí ohun kan tí mo fẹ́ gbé. Lójijì ni ẹ̀fúùfù tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ tí ariwo rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ di èèyàn létí, àmọ́ ńṣe ni mo wa ohun tí mo rí gbé náà máyà. Lọmọ mi bá sọ pé: “Mọ́mì, ẹ gbé tẹlifíṣọ̀n ọwọ́ yín sílẹ̀. Àbí aya Lọ́ọ̀tì ni yín ni?” (Lúùkù 17:31, 32) Ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu ọmọ mi jáde yẹn pe orí mi wálé. Kíá ni mo gbé tẹlifíṣọ̀n tí òjò ti rin gbingbin náà jù sílẹ̀ táwa méjèèjì sì sá kúrò níbi eléwu náà.
Ńṣe lara mi máa ń gbọ̀n tí mo bá ti rántí bí mo ṣe fi ẹ̀mí ara mi wewu nítorí tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́ inú mi máa ń dùn gan-an bí mo bá ti ronú kan ọ̀rọ̀ tí ọmọ mi sọ lákòókò yẹn, tó fi hàn pé ó wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Mo dúpẹ́ fún ẹ̀kọ́ Bíbélì tó gbà nínú ìjọ Kristẹni, òun ló jẹ́ kó lè ràn mí lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ jàǹbá tí ì bá ṣẹlẹ̀ sí mi nípa tara àti bóyá nípa tẹ̀mí pàápàá.
Ìjì líle náà run gbogbo ilé àti ohun ìní wa pátá, ó sì tún kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Báwọn ará tún ṣe dé nìyẹn. Wọ́n fún wa níṣìírí, wọ́n sì ní ká mọ́kàn kúrò lára àwọn ohun tá a pàdánù, ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ láìbojú wẹ̀yìn. Wọ́n sì bá wa tún ilé wa kọ́. Iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn láti Jàmáíkà àtàwọn ibòmíràn fi ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìyọ̀ǹda-ara-ẹni ṣe yẹn mórí wa wú gan-an.
Ti Jèhófà La Fi Ṣáájú
Lẹ́yìn tí ọmọ mi kejì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Melaine jáde nílé ìwé, ó di aṣáájú-ọ̀nà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n pè é pé kó wá lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìjọ mìíràn, ó sì gbà láti lọ. Ìyẹn túmọ̀ sí pé yóò fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ yẹn ti mú kó ṣeé ṣe fún un láti ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti gbọ́ bùkátà ìdílé wa, síbẹ̀ ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà yóò bójú tó wa bí gbogbo wa bá ti fi ire Ìjọba rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́. (Mátíù 6:33) Nígbà tó yá, wọ́n tún pe ọmọ mi ọkùnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ewan pé kóun náà wá ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Òun náà ń fowó ṣèrànwọ́ fún ìdílé wa, àmọ́ a fún un níṣìírí láti lọ, a sì sọ fún un pé Jèhófà á bù kún un. Kò sígbà kan tí mi ò fún àwọn ọmọ mi níṣìírí láti túbọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣe máa gbòòrò sí i. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò sígbà kan táwa tá a wà nílé ṣe aláìní ohun tó yẹ ká ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ayọ̀ wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i, kódà àwọn ìgbà míì wà táwa náà ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí nǹkan ò rọgbọ fún.
Lónìí, ńṣe ni inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe ń rí àwọn ọmọ mi tí wọ́n ‘ń rìn nínú òtítọ́.’ (3 Jòhánù 4) Ọ̀kan lára àwọn ọmọ mi obìnrin, ìyẹn Melaine, ń bá ọkọ rẹ̀ lọ sáwọn ìjọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká báyìí. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni ọmọ mi Andrea àti ọkọ rẹ̀ báyìí, ó sì máa ń tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ nígbà tó bá lọ bẹ ìjọ wò gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe náà ni Ewan ọmọ mi ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀, alàgbà sì ni nínú ìjọ tó wà. Ọmọ mi obìnrin mìíràn tó ń jẹ́ Ava-Gay àti ọkọ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jàmáíkà. Jennifer, Genieve, àti Nicole pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn àtàwọn ọmọ wọn náà ń ṣe déédéé nínú ìjọ tí wọ́n wà. Marseree ń gbé lọ́dọ̀ mi, àwa méjèèjì sì ń dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Port Morant báyìí. Àwọn ìbùkún tí mo ní pọ̀ gan-an, nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ mi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló ń jọ́sìn Jèhófà nìṣó.
Ara tó ń dara àgbà ti jẹ́ káwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan máa ṣe mí. Làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wù ló ń yọ mí lẹ́nu báyìí, àmọ́ mo ṣì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi lọ. Àmọ́, nígbà kan, àtirìn ni àgbègbè tí òkè pọ̀ sí tí mò ń gbé ò rọrùn fún mi rárá. Àtilọ sóde ẹ̀rí wá nira gan-an. Mo gbìyànjú láti gun kẹ̀kẹ́, mo sì rí i pé ìyẹn rọrùn fún mi ju ìrìn rírìn lọ. Mo wá ra àlòkù kẹ̀kẹ́ kan, mo sì ń gùn ún. Inú àwọn ọmọ mi ò kọ́kọ́ dùn bí wọ́n ṣe ń rí ìyá wọn tí làkúrègbé ń yọ lẹ́nu tó ń gun kẹ̀kẹ́. Síbẹ̀, inú wọn dùn pé mo ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù mi lọ bí ọkàn mí ti fẹ́.
Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ti ń rí àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń di olùjọ́sìn Jèhófà. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ran gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé mi lọ́wọ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí i nìṣó ní gbogbo àkókò òpin yìí àti títí ayérayé. Mo ń fi ọpẹ́ àti ìyìn fún Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” fún mímú tó mú kó ṣeé ṣe fún mi láti tọ́ àwọn ọmọ mi mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ dàgbà ní ọ̀nà rẹ̀.—Sáàmù 65:2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èmi àtàwọn ọmọ mi, àwọn ọkọ àti aya wọn, àtàwọn ọmọ ọmọ mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kẹ̀kẹ́ ni mò ń lò báyìí tí mo fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi