Ìtàn Ìgbésí Ayé
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ìdílé Wa Ṣọ̀kan!
GẸ́GẸ́ BÍ SUMIKO HIRANO ṢE SỌ Ọ́
Èmi ti rí ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà gbé ìgbésí ayé, mo sì fẹ́ kí ọkọ mi náà wá gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ọdún méjìlélógójì kọjá kí èyí tó rí bẹ́ẹ̀.
ỌDÚN 1951 lèmi àtọkọ mi ṣègbéyàwó, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sì ni mí nígbà náà. Láàárín ọdún mẹ́rin, a bí ọmọkùnrin méjì, ó sì jọ pé gbogbo ọ̀nà láyé mi fi dára.
Lọ́jọ́ kan lọ́dún 1957, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin sọ fún mi pé míṣọ́nnárì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wá sọ́dọ̀ òun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́sìn Búdà lẹ̀gbọ́n mi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ míṣọ́nnárì yẹn ó sì rọ̀ mí pé kémi náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì gbà. Ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì ni mò ń lọ nígbà yẹn, èrò mi sì ni pé tí n bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ kí n lè fi àwọn ohun tí kò tọ̀nà nínú ẹ̀kọ́ wọn hàn wọ́n.
Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ nǹkan kan nípa Bíbélì. Mo ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa bi míṣọ́nnárì náà pé, “Ta ni wọ́n ń pè ní Jèhófà?” Mi ò gbọ́ kí wọ́n lo orúkọ yẹn rí ní ṣọ́ọ̀ṣì wa. Míṣọ́nnárì yẹn, tó ń jẹ́ Daphne Cooke (tó wá di Pettitt nígbà tó yá) sọ pé kí n ka Aísáyà 42:8, èyí tó sọ ní kedere pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run Olódùmarè. Gbogbo ìbéèrè mi pátá ni Daphne dáhùn, àtinú Bíbélì ló sì ti mú àwọn ìdáhùn náà jáde.
Ni mo bá tún lọ bi àlùfáà mi láwọn ìbéèrè yẹn gan-gan. Èsì tó fún mi ni pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn máa béèrè ìbéèrè. Ohun tí n bá sọ fún ẹ ni kó o gbà gbọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ò gbà pé ó burú láti béèrè ìbéèrè, odindi oṣù mẹ́fà ni mo fi ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì láràárọ̀ ọjọ́ Sunday tí màá sì lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́sàn-án.
Ẹ̀kọ́ Tí Mò Ń Kọ́ Kò Dún Mọ́ Ọkọ Mi Nínú
Ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì ń múnú mi dùn gan-an, mo sì máa ń sọ fún ọkọ mi, Kazuhiko, nípa rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti kẹ́kọ̀ọ́ tán àti lẹ́yìn tí mo bá dé láti ìpàdé ni mo máa ń sọ ohun tí mo kọ́ fún un. Bó ṣe di pé àárín wa ò dán mọ́rán mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Kò fẹ́ kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ mò ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn gan-an débi pé mi ò jáwọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò yéé lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Kí n tó jáde nílé lọ́jọ́ ìpàdé, màá ti se oúnjẹ tí ọkọ mi fẹ́ràn gan-an sílẹ̀ fún un, àmọ́ ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í lọ jẹun níta. Nígbà tí mo bá sì padà délé lẹ́yìn ìpàdé, mi ò kì í rójú ẹ̀ nílẹ̀ rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní bá mi sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta inú rẹ̀ á yọ́ díẹ̀, àmọ́ nígbà yẹn, àkókò ìpàdé mìíràn á tún ti tó.
Láàárín àkókò yìí ni àìsàn ikọ́ ẹ̀gbẹ kọ lù mí, àìsàn yìí sì ti pa àwọn kan nínú ìdílé ọkọ mi. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba Kazuhiko, ó sì sọ fún mi pé tára mi bá ti yá, ohunkóhun tí mo bá fẹ́ ni kí n máa ṣe. Ohun kan ti mo wá tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀ ni pé kó jọ̀ọ́, kó jẹ́ kí n máa lọ sáwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yẹn. Ó sì gbà.
Oṣù mẹ́fà ni mo lò lórí àìsàn yìí kí n tó gbádùn, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an láàárín àkókò yẹn. Mo ń wá ibi tí ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ti tọ̀nà, èrò mi sì ni pé tí n bá tiẹ̀ lè rí ẹyọ kan péré, mi ò ní kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn mọ́. Àmọ́ mi ò rí ọ̀kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ẹ̀kọ́ tí kò tọ̀nà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ń kọ́ni túbọ̀ ń hàn kedere. Mo wá lóye pé Jèhófà jẹ́ ìfẹ́ àti ẹni tí kì í ṣègbè, mo sì rí àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn òfin rẹ̀ ṣèwàhù.
Lẹ́yìn tára mi yá, ọkọ mi mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kò sì sọ pé kí n má lọ sípàdé mọ́. Ìmọ̀ mi nínú Bíbélì ń jinlẹ̀ sí i, nígbà tó di oṣù May ọdún 1958, mo ṣèrìbọmi, mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wù mí gan-an kí èmi àti ìdílé mi jọ máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́.
Bí Mo Ṣe Ran Àwọn Ọmọ Mi Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Ọlọ́run
Gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sípàdé tàbí ti mo bá lọ wàásù ni mo máa ń mú àwọn ọmọ mi lọ, àmọ́ àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kí n rí i pé ìmọ̀ wọn nínú Bíbélì ń pọ̀ sí i. Lọ́jọ́ kan, Masahiko, ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà ń ṣeré níwájú ìta ilé wa. Bẹ́ẹ̀ ni mo gbọ́ ariwo ńlá kan tí mo sì gbọ́ tẹ́nì kan figbe ta. Aládùúgbò wa kan sáré wọnú ilé wa, ó sì ń pariwo pé mọ́tò ti gbá ọmọ mi. Mo ní ṣé ó ti kú ni? Bí mo ti ń sáré jáde, mo gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà mí jù. Jìnnìjìnnì bò mí nígbà tí mo rí i bí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ṣe bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò pẹ́ ni mo rí i tó ń rìn bọ̀ níwájú mi, ó kàn fara pa díẹ̀ ni. Bó ti dì mọ́ mi ló sọ pé, “Mọ́mì, Jèhófà ló yọ mí, àbí òun kọ́?” Rírí tí mo rí i pé kò kú àti ọ̀rọ̀ dáadáa tí mo gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ yìí mú kí omi bọ́ lójú mi.
Ó tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé, nígbà tá a wà lóde ìwàásù, a bá bàbá àgbàlagbà kan pàdé tó pariwo mọ́ wa pé: “Ṣé ohun tó ò ń ṣe yìí dáa báyìí, tó ò ń fa ọmọ kékeré yìí kiri? Àánú ọmọ yìí ló kàn ṣe mí.” Kí n tó dá bàbá náà lóhun ni Tomoyoshi ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ ti dáhùn pé: “Bàbá, màmá mi ò fipá mú mi wàásù rára. Torí pé ó wù mí láti sin Jèhófà ni mo ṣe ń wàásù.” Ni bàbá náà bá ń wò láìlè sọ nǹkan kan mọ́.
Ní ti ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ọmọ aláìníbaba làwọn ọmọ mi. Ó sì ti di ojúṣe mi láti kọ́ wọn lohun tó wà nínú Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan lèmi alára ò tíì mọ̀. Mo sapá láti rí i pé mo jẹ́ ẹni tó ní ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti ìtara, mo sì gbìyànjú láti jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń fọpẹ́ fún Jèhófà níwájú àwọn ọmọ mi. Mo máa ń sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù tó dùn mọ́ mi nínú fún wọn. Èyí sì fún wọn níṣìírí gan-an. Nígbà kan tí wọ́n bi wọ́n pé kí ló mú kí wọ́n di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù, wọ́n dáhùn pé: “A rí i pé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tí màmá wa ń ṣe ń fún un láyọ̀ gan-an, àwa náà sì fẹ́ láyọ̀ bíi tirẹ̀.”
Mo máa ń ṣọ́ra gan-an láti má ṣe sọ̀rọ̀ bàbá wọn tàbí ẹlòmíràn nínú ìjọ lọ́nà tí kò dára. Mo mọ̀ pé ṣíṣe àríwísí àwọn èèyàn lè ṣàkóbá fáwọn ọmọ mi. Kì í ṣe pé wọ́n lè má bọ̀wọ̀ fẹ́ni náà mọ́ nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún lè má bọ̀wọ̀ fún èmi alára pẹ̀lú.
Bí Mo Ṣe Borí Àwọn Ìṣòro Tó Fẹ́ Ṣèdíwọ́ Fún Mi
Nítorí iṣẹ́ ọkọ mi, ìdílé wa ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Taiwan lọ́dún 1963. Lọkọ mi bá sọ fún mi pé tí mo bá lọ ń wàásù fáwọn ará Japan tó wà níbẹ̀, màá dá ìṣòro sílẹ̀ o. Ó ní ńṣe ni wọ́n máa dá wa padà sílẹ̀ Japan, wàhálà nìyẹn sì máa dá sílẹ̀ fún iléeṣẹ́ tóun ń bá ṣiṣẹ́. Kò fẹ́ ká ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Nílẹ̀ Taiwan, èdè Ṣáìnà ni wọ́n fi ń ṣe gbogbo ìpàdé wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Mo pinnu pé màá kọ́ èdè Ṣáìnà kí n lè máa wàásù fáwọn ará Taiwan dípò àwọn ará Japan. Nípa bẹ́ẹ̀, màá lè yẹra fáwọn ìṣòro tí ọkọ mi sọ pé mo lè dá sílẹ̀.
Àjọṣe àwa àtàwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Taiwan fún wa lókun gan-an. Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Orúkọ wọn ni Harvey àti Kathy Logan. Arákùnrin Logan wá di bàbá àwọn ọmọ mi nípa tẹ̀mí. Ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé téèyàn bá ń sin Jèhófà, kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní gbádùn ayé ẹ̀ mọ́ tàbí pé òfin léèyàn á kàn máa tẹ̀ lé ṣáá. Ó dá mi lójú pé ìgbà tá a wà ní Taiwan làwọn ọmọ mi pinnu nínú ọkàn wọn pé àwọn máa sin Jèhófà.
Iléèwé kan táwọn ará Amẹ́ríkà dá sílẹ̀ ni Tomoyoshi àti Masahiko lọ, wọ́n sì kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Ṣáìnà níbẹ̀. Nígbà tó yá, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kí wọ́n di òjíṣẹ́ tó túbọ̀ wúlò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà. Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó yí ohun tí ì bá jẹ́ àkókò líle koko padà fún wa, ó mú kó jẹ́ àkókò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbùkún, èyí tá a ṣì ń gbádùn títí dòní. Lẹ́yìn tá a lo ọdún mẹ́tà àtààbọ̀ tá ò lè gbàgbé nílẹ̀ Taiwan, ìdílé wa padà sórílẹ̀-èdè Japan.
Lákòókò yìí, àwọn ọmọ mi ti ń bàlágà, àwọn náà sì fẹ́ dòmìnira. Àìmọye wákàtí ni mo máa ń lò pẹ̀lú wọn tí mo fi ń ṣàlàyé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ fún wọn, Jèhófà sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ó jẹ́ kí wọ́n la àkókò tó nira yẹn já. Bí Tomoyoshi ṣe jáde ilé ẹ̀kọ́ girama ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Láàárín ọdún díẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀, ó ran èèyàn mẹ́rin lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Masahiko náà ṣe bíi ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà bó ṣe parí ilé ẹ̀kọ́ girama. Láàárín ọdún mẹ́rin tóun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ó ran àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí.
Nígbà tó yá, Jèhófà tún bù kún àwọn ọmọ náà síwájú sí i. Tomoyoshi kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́, ọkùnrin yìí sì jẹ́ ọkọ obìnrin kan tí mo ràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn ọmọ wọn obìnrin méjèèjì náà di Ẹlẹ́rìí. Nígbà tó yá, Tomoyoshi fẹ́ èyí ẹ̀gbọ́n tó ń jẹ́ Nobuko, Masahiko sì fẹ́ àbúrò, tó ń jẹ́ Masako. Oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Tomoyoshi àti Nobuko ti ń sìn báyìí. Masahiko àti Masako sì jẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Paraguay.
Ọkọ Mi Ń Yí Padà Díẹ̀díẹ̀
Ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyẹn, ńṣe ló dà bíi pé ọkọ mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn wa, àmọ́ a rí àwọn àmì tó fi hàn pé ó ń yí padà. Nígbà táwọn èèyàn bá ta kò mí, ó máa ń sọ fún wọn pé ohun tí mo gbà gbọ́ yẹn ló tọ̀nà, ó sì ń tipa báyìí ti ẹ̀kọ́ Bíbélì lẹ́yìn láìmọ̀. Ó máa ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́. Nínú ọ̀rọ̀ kúkúrú tó sọ níbi ìgbéyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa, ó ní: “Kíkọ́ àwọn èèyàn nípa ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé ni iṣẹ́ tó dára jù lọ láyé yìí, òun náà sì tún ni iṣẹ́ tó nira jù lọ. Ọ̀nà tó nira jù lọ yìí làwọn ọmọ mi àtàwọn aya wọn wá yàn láti fi ṣiṣẹ́ ṣe nígbèésí ayé wọn. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá mi ràn wọ́n lọ́wọ́.” Gbogbo nǹkan báyìí máa ń jẹ́ kí n ronú pé dájúdájú, yóò dára pọ̀ mọ́ wa nínú sísin Jèhófà lọ́jọ́ kan.
Nínú ilé wa, mo máa ń ṣe àwọn ètò tó máa jẹ́ kí ọkọ mi lè ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Mo máa ń ní kó wá sáwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn àpéjọ, títí kan Ìrántí ikú Kristi. Nígbà tí iṣẹ́ rẹ̀ kò bá dí i lọ́wọ́, ó máa ń wá, àmọ́ kì í tinú rẹ̀ wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń rò pé ó lè gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, màá sì pe àwọn alàgbà wá sílé wa. Àmọ́ ó kọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́. Mo wá ń wò ó pé kí ló lè fà á?
Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù ló wá sí mi lọ́kàn, ó ní: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:1, 2) Mo rí i pé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni mò ń fi ìmọ̀ràn yẹn sílò. Kí n lè túbọ̀ máa ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí dáadáa, mo ní láti túbọ̀ fi ohun tí mò ń kọ́ sílò.
Lọ́dún 1970, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kí èyí lè ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ọdún mẹ́wàá kọjá, ogún ọdún kọjá. Síbẹ̀ ọkọ mi ò yí èrò rẹ̀ padà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà kan, ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Kò lè rọrùn láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ nìyẹn o, nígbà tó ò lè ran ọkọ tiẹ̀ gan-an lọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ yẹn bà mí nínú jẹ́, àmọ́ mi ò juwọ́ sílẹ̀.
Nígbà tó di ìparí àwọn ọdún 1980, àwọn òbí wa ti ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé wọn. Kò rọrùn fún mi rárá bí mo ṣe ń ṣètọ́jú wọn tí mo sì tún ń bójú tó àwọn nǹkan mìíràn tó yẹ ní ṣíṣe, agbára mi sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má gbé e. Ọ̀pọ̀ ọdún ni gbogbo wọn fi ta kò mí nítorí pé mò ń sin Jèhófà, àmọ́ mo gbìyànjú láti fìfẹ́ hàn sì wọn débi tágbára mi gbé e dé. Nígbà tó kù díẹ̀ kí màmá mi kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún, ó sọ fún mi pé: “Sumiko, bí Ọlọ́run bá jí mi dìde, màá ṣe ìsìn rẹ yìí.” Mo wá rí i pé ìsapá mi ò já sánsán.
Gbogbo ohun tí mo ṣe fáwọn òbí wa lọkọ mi kíyè sí. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé déédéé láti fi ìmọrírì rẹ̀ hàn. Ó wá sípàdé fún ọ̀pọ̀ ọdún àmọ́ kò tẹ̀ síwájú. Mo ṣáà ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn. Mo máa ń pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, títí kan àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n wà lókè òkun wá sílé wa, màá sì ṣe wọ́n lálejò. A jọ máa ń lọ fún eré ìnàjú. Nígbà tí wọ́n sì dín iye wákátì táwọn aṣáájú ọ̀nà fi ń wàásù kù, ìyẹn fún mi láyè láti máa wà pẹ̀lú rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Nǹkan Yí Padà Nígbà Tí Ọkọ Mi Fẹ̀yìn Tì Lẹ́nu Iṣẹ́
Ọkọ mi fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dún 1993. Mo sì ronú pé, á tiẹ̀ ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Àmọ́ ohun tó sọ fún mi ni pé ìwà àìlọ́wọ̀ ló máa jẹ́ tóun bá ń jọ́sìn Ọlọ́run nítorí pé ọwọ́ òun dilẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní nígbà tọ́kàn òun bá sọ pé kóun jọ́sìn Ọlọ́run lóun máa ṣe bẹ́ẹ̀, kí n má fipá mú òun.
Lọ́jọ́ kan, ọkọ mi bi mí bóyá màá wá fi ìyókù ayé mi gbọ́ tòun báyìí. Ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí gan-an, nítorí pé àtìgbà tí mo ti fẹ́ ẹ ni mo ti ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nítorí tiẹ̀. Mo ti sa gbogbo ipá mi kínú rẹ̀ lè máa dùn, àmọ́ èrò rẹ̀ ni pé èyí tí mo ti lò fún Jèhófà nínú ìgbésí ayé mi ju èyí tí mo lò fún òun lọ. Lẹ́yìn tí mo ronú díẹ̀ nípa ohun tó sọ yẹn, mo sọ fún un pé mi ò lè ṣe ju ohun tí mò ń ṣe yẹn lọ. Àmọ́ tó bá lè jẹ́ ká jọ máa sin Jèhófà, a tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ayé wa pa pọ̀ lákọ̀tun, èyí ò sì ní jẹ́ fún ọdún díẹ̀ péré, àmọ́ títí ayé ló máa jẹ́. Fún ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà lọkọ mi ò fi fèsì sóhun tí mo sọ yẹn. Nígbà tó yá, ló wá bi mí pé, “Ṣé wàá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Nígbàkigbà tí mo bá rántí ohun tó sọ yẹn, ńṣe lorí mi máa ń wú.
Mo kọ́kọ́ ṣètò pé kí alàgbà kan wá máa kọ́ ọkọ mi lẹ́kọ̀ọ́ àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Mi ò ní gbà kí ẹnikẹ́ni kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ àyàfi ìwọ.” Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́ nìyẹn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ìjọ tó ń sọ èdè Ṣáínà ni mo wà tí ọkọ mi náà sì gbọ́ èdè yẹn dáadáa, èdè Ṣáìnà la fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. A tún jọ ka Bíbélì tán látìbẹ̀rẹ̀ dópin kí ọdún kan tó parí.
Láàárín àkókò yẹn, alàgbà kan àti ìyàwó rẹ̀ nínú ìjọ tó ń sọ èdè Ṣáìnà yẹn máa ń rìn mọ́ àwa méjèèjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tó àwọn ọmọ wa lọ́jọ́ orí, síbẹ̀ wọ́n di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn náà tún fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí ọkọ mi. Wọ́n máa ń ṣọ̀yàyà sí wa gan-an wọ́n sì máa ń bá Kazuhiko sọ̀rọ̀ bíi pé bàbá wọn ni. Èyí múnú rẹ̀ dùn gan-an.
Lọ́jọ́ kan, a rí ìwé ìkésíni kan nílé wa tí wọ́n fi pè wá síbi ìgbéyàwó kan tí wọ́n fẹ́ ṣe ní ìjọ wa, orúkọ ọkọ mi ni wọ́n sì kọ sẹ́yìn rẹ̀. Bí wọ́n ṣe pọ́n ọn lé gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé jọ ọ́ lójú gan-an, ó sì sọ pé òun á lọ síbi ìgbéyàwó náà. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í túra ká sáwọn Ẹlẹ́rìí, alàgbà kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sípàdé, àti ìfẹ́ tí ìjọ fi hàn sí i mú kó tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
Ìdílé Wa Ṣọ̀kan Nígbẹ̀yìn-Gbẹ́yín
Ní December ọdún 2000, ọkọ mi ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà. Àwọn ọmọ mi àtàwọn aya wọn wá láti ọ̀nà jíjìn kí wọ́n lè rí “iṣẹ́ ìyanu òde òní” yìí. Èyí gba ọdún méjìlélógójì kó tó ṣẹlẹ̀, àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìdílé wa ṣọ̀kan.
Ní báyìí láràárọ̀, àwa méjèèjì jọ máa ń jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ a sì jọ máa ń ka Bíbélì pa pọ̀. Ojoojúmọ́ la máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa tá a sì jọ máa ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọkọ mi báyìí nínú ìjọ, ó sì fi èdè Ṣáínà sọ àsọyé Bíbélì kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú wa ṣọ̀kan nínú ìjọsìn rẹ̀. Pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mò ń fojú sọ́nà láti gbé orúkọ rẹ̀ ga títí ayé kí n sì fara mọ́ jíjẹ́ tó jẹ́ ọba aláṣẹ.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ṢÁÍNÀ
ORÍLẸ̀-ÈDÈ KÒRÍÀ ONÍJỌBA TIWA-N-TIWA
ORÍLẸ̀-ÈDÈ KÒRÍÀ
Òkun Japan
JAPAN
Tokyo
Òkun Ìlà Oòrùn Ṣáínà
TAIWAN
Taipei
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èmi àti ìdílé mi lọ́dún 1958, ọdún tí mo ṣèrìbọmi
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà tá a ṣí lọ sí Taipei láti Tokyo, àwọn ọ̀rẹ́ bíi Harvey àti Kathy Logan fún wa lókun nípa tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lónìí, èmi àti ìdílé mi ti jọ ń ṣe ìjọsìn tòótọ́