“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”
Ó Jẹ́rìí Kúnnákúnná Pẹ̀lú “Ìgboyà”
ÀWỌN jàǹdùkú èèyàn kan tórí wọn ti gbóná ṣùrù bo ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó jẹ́ onígbọràn. Ṣíún báyìí ló kù kí wọ́n pa á táwọn ọmọ ogun Róòmù fi dé tí wọ́n sì já a gbà lọ́wọ́ wọn, àwọn ọmọ ogun náà sì lọ tì í mọ́lé. Ibi tí oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi bí ọdún márùn-ún ṣẹlẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú káwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba Róòmù gbọ́ nípa Jésù Kristi.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹni tí wọ́n ń lù nílù bàrà yẹn. Ní nǹkan bí ọdún 34 Sànmánì Kristẹni, Jésù sọ ọ́ di mímọ̀ pé Pọ́ọ̀lù (Sọ́ọ̀lù) á gbé orúkọ òun dé ọ̀dọ̀ “àwọn ọba.” (Ìṣe 9:15) Títí di ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, ohun tí Jésù sọ yẹn ò tíì ṣẹlẹ̀. Àmọ́, nígbà tó kù díẹ̀ kí àpọ́sítélì yìí parí ìrìn-àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta tó rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, àwọn nǹkan ti fẹ́ máa yí padà.
Wọ́n Dáwọ́ Jọ Lù Ú Síbẹ̀ Kò Jáwọ́
Pọ́ọ̀lù ń bá ìrìn-àjò ẹ̀ nìṣó ní Jerúsálẹ́mù, àwọn Kristẹni kan sì sọ fún un “nípasẹ̀ ẹ̀mí” pé inúnibíni líle koko ń dúró dè é ní ìlú yẹn. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù fìgboyà sọ pé: “Mo ti múra tán, kì í ṣe fún dídè nìkan ni, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa.” (Ìṣe 21:4-14) Gbàrà tí Pọ́ọ̀lù yọjú sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù báyìí, àwọn Júù tó wá láti Éṣíà tí wọ́n ti mọ bí ìwàásù àpọ́sítélì yìí ṣe rinlẹ̀ tó níbẹ̀ dẹ àwọn èèyàn sí i kí wọ́n lè pa á. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọmọ ogun tó tètè wá gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀. (Ìṣe 21:27-32) Gbígbà tí wọ́n gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ yẹn fún un láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó mú kó lè polongo òtítọ́ nípa Kristi fáwọn èrò tí ò fẹ́ gbọ́ àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn.
Ó Wàásù Fáwọn Tó Ṣòro Láti Rí Bá Sọ̀rọ̀
Wọ́n wọ́ Pọ́ọ̀lù lọ síbi tọ́wọ́ ò ti ní tó o, níbi àtẹ̀gùn ilé ààbò kan tó ń jẹ́ Ilé Gogoro Antonia.a Látorí àtẹ̀gùn yìí ni àpọ́sítélì náà ti ṣe ìwàásù tó lágbára fáwọn ẹlẹ́sìn tórí wọn ti gbóná. (Ìṣe 21:33–22:21) Ṣùgbọ́n bó ṣe sọ fún wọn pé iṣẹ́ tó wà níkàáwọ́ òun ni pé kóun wàásù fáwọn Kèfèrí báyìí, ṣe ni gbogbo ibẹ̀ tún dà rú. Ọ̀gágun Lísíà pàṣẹ pé kí wọ́n bó Pọ́ọ̀lù lẹ́gba láti wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹ̀ kí wọ́n fi lè mọ ìdí táwọn Júù fi fẹ̀sùn kàn án. Àmọ́, ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n na Pọ́ọ̀lù ni pé ó sọ fún wọn pé ọmọ orílẹ̀-èdè Róòmù lòun. Lọ́jọ́ kejì, Lísíà mú Pọ́ọ̀lù lọ síwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn kí wọ́n lè wádìí ẹ̀sùn táwọn Júù fi kàn án.—Ìṣe 22:22-30.
Nígbà tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù déwájú ilé ẹjọ́ gíga yìí, ó láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ míì láti wàásù fáwọn Júù bíi tiẹ̀. Ajíhìnrere tẹ́rù ò bà yìí sọ ìgbàgbọ́ tó ní nínú àjíǹde fún wọn. (Ìṣe 23:1-8) Ìkórìíra táwọn Júù ní sí Pọ́ọ̀lù, èyí tó fẹ́ mú kí wọ́n pa á, ṣì ń gbóná lọ́kàn wọn síbẹ̀, làwọn sójà bá mú Pọ́ọ̀lù lọ sí bárékè. Lóru ọjọ́ kejì, Olúwa ki Pọ́ọ̀lù láyà báyìí pé: “Jẹ́ onígboyà gidi gan-an! Nítorí pé bí o ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ tún gbọ́dọ̀ jẹ́rìí ní Róòmù.”—Ìṣe 23:9-11.
Ìmọ̀ tí wọ́n gbà láti pa Pọ́ọ̀lù ò jọ torí báwọn ọmọ ogun Róòmù ṣe tètè mú àpọ́sítélì yìí ní bòókẹ́lẹ́ lọ sí Kesaréà tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba Róòmù ní àgbègbè Jùdíà. (Ìṣe 23:12-24) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Kesaréà, ọ̀pọ̀ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló tún ṣí sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù sì lo àwọn àǹfààní yìí láti wàásù fún “àwọn ọba.” Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, àpọ́sítélì yìí fi han Gómìnà Fẹ́líìsì pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù wá wàásù fún òun àtìyàwó ẹ̀ Dùrùsílà nípa Jésù, ìkóra-ẹni-níjàánu, òdodo àti ìdájọ́ tó ń bọ̀. Síbẹ̀, wọ́n fi Pọ́ọ̀lù pa mọ́ sẹ́wọ̀n fọ́dún méjì, torí pé kò fún Fẹ́líìsì ní ẹ̀gúnjẹ tó ń retí lọ́wọ́ ẹ̀.—Ìṣe 23:33–24:27.
Nígbà tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì rọ́pò Fẹ́líìsì, àwọn Júù tún padà bẹ̀rẹ̀ akitiyan wọn láti rí i pé wọ́n dájọ́ ikú fún Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì gbẹ̀mí ẹ̀. Kesaréà ni wọ́n ti tún ẹjọ́ náà gbọ́, kó má sì lọ di pé wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí Jerúsálẹ́mù, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì . . . Mo ké gbàjarè sí Késárì.” (Ìṣe 25:1-11, 20, 21) Lọ́jọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí àpọ́sítélì náà ti rojọ́ tiẹ̀ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì, ọba yẹn sọ pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” (Ìṣe 26:1-28) Ní nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Kristẹni, wọ́n fi Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Róòmù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́wọ̀n ni àpọ́sítélì tó lè wàásù lọ́nàkọnà yìí níbẹ̀ yẹn, síbẹ̀ fún nǹkan bí ọdún méjì sí i tó lò níbẹ̀, ó wá ọ̀nà táá fi máa wàásù nípa Kristi ni ṣáá. (Ìṣe 28:16-31) Ó dà bíi pé Pọ́ọ̀lù pàpà déwájú Olú Ọba Nérò, wọ́n dá a láre níbẹ̀ ó sì láǹfààní láti máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì ẹ̀ lọ lómìnira. Kò sí àkọsílẹ̀ pé àpọ́sítélì èyíkéyìí míì láǹfààní láti gbé ìhìn rere déwájú àwọn bọ̀rọ̀kìnní èèyàn bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tá a rí lókè yìí ṣe fi hàn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ohun tó tẹ̀ lé ìlànà táwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ kan sọ níwájú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ Júù pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Àbí ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún wa! Pẹ̀lú gbogbo akitiyan àwọn èèyàn láti pa á lẹ́nu mọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àpọ́sítélì yìí ṣègbọràn pátápátá sí àṣẹ náà pé ká wàásù kúnnákúnná. Látàrí ìgbọràn rẹ̀ sí Ọlọ́run tí kò yingin, Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ohun èlò tí a ti yàn” láti gbé orúkọ Jésù “lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Ìṣe 9:15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù November àti December nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ṢÉ TORÍ KÍ PỌ́Ọ̀LÙ BÀA LÈ GBÈJÀ ARA Ẹ̀ NÌKAN LÓ ṢE ṢOHUN TÓ ṢE?
Nígbà tí òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Ben Witherington III ń sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè yìí, ó sọ pé: “Lójú Pọ́ọ̀lù . . . ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bó ṣe máa gbé ìwàásù ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà nípò àṣẹ, ì báà jẹ́ Júù tàbí Kèfèrí, kì í ṣe bó ṣe máa gbèjà ara ẹ̀. . . . Ìhìn rere gan-an ló ń tìtorí ẹ̀ jẹ́jọ́.”