ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 46
Mọ́kàn Le—Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Rẹ
“Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.”—HÉB. 13:5.
ORIN 55 Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló lè tù wá nínú tó bá ń ṣe wá bíi pé a dá wà tàbí táwọn ìṣòro wa mu wá lómi? (Sáàmù 118:5-7)
ǸJẸ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé o dá wà tàbí pé o ò rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o níṣòro? Ó ti ṣe ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀ rí títí kan àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. (1 Ọba 19:14) Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn, rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè fìgboyà sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.” (Héb. 13:5, 6) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni. Ohun tó sọ yìí rán wa létí ohun tó wà nínú Sáàmù 118:5-7.—Kà á.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí?
2 Bíi ti onísáàmù, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù jẹ́ kóun náà gbà pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ òun. Bí àpẹẹrẹ, lóhun tó lé lọ́dún méjì ṣáájú ìgbà tó kọ̀wé sáwọn Hébérù, díẹ̀ ló kù kí ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù bọ́ nígbà tó rìnrìn àjò tí ìjì líle kan sì bì lu ọkọ̀ ojú omi tó wà nínú ẹ̀. (Ìṣe 27:4, 15, 20) Jèhófà ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà ìrìn àjò yẹn àti nínú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìrìn àjò náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà gbà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, Jèhófà lo Jésù àtàwọn áńgẹ́lì láti ràn án lọ́wọ́. Ìkejì, ó lo àwọn tó wà nípò àṣẹ. Ìkẹta, ó lo àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù, á túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun á ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ké pe òun nígbà ìṣòro.
BÍ JÉSÙ ÀTÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ ṢE RÀN ÁN LỌ́WỌ́
3. Kí ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa rò, kí sì nìdí?
3 Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. Àwọn èèyàn gbá a mú, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè pa á. Lọ́jọ́ kejì tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn, díẹ̀ ló kù káwọn ọ̀tá yìí fa Pọ́ọ̀lù ya. (Ìṣe 21:30-32; 22:30; 23:6-10) Lásìkò yẹn, ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ronú pé ‘Ṣé ẹ̀mí mi ò ní bọ́ báyìí?’
4. Báwo ni Jèhófà ṣe lo Jésù láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
4 Bí wọ́n ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ní òru ọjọ́ tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù, Jésù “Olúwa” dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Nítorí pé bí o ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ lo ṣe máa jẹ́rìí ní Róòmù.” (Ìṣe 23:11) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn bọ́ sásìkò gan-an ni! Jésù gbóríyìn fún Pọ́ọ̀lù torí bó ṣe jẹ́rìí nípa òun ní Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣèlérí fún un pé á dé Róòmù, á sì túbọ̀ jẹ́rìí nípa òun níbẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí, ó dájú pé ọkàn Pọ́ọ̀lù máa balẹ̀ bí ọmọ jòjòló kan tí bàbá ẹ̀ gbé mọ́ra.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe lo áńgẹ́lì kan láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
5 Àwọn ìṣòro míì wo ni Pọ́ọ̀lù tún kojú? Ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, Pọ́ọ̀lù wọ ọkọ̀ òkun kan tó ń lọ sí Ítálì. Àmọ́ ìjì líle kan bì lu ọkọ̀ náà débi pé gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀ ló rò pé àwọn máa kú. Síbẹ̀, ẹ̀rù ò ba Pọ́ọ̀lù. Kí nìdí? Ó sọ fáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ náà pé: “Ní òru yìí, áńgẹ́lì Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sọ pé: ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Wàá dúró níwájú Késárì, sì wò ó! Ọlọ́run ti fún ọ ní gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ̀.’ ” Jèhófà ló rán áńgẹ́lì yẹn láti fi Pọ́ọ̀lù lọ́kàn balẹ̀ bí Jésù náà ti ṣe. Bí Jèhófà ti ṣèlérí náà ló rí, Pọ́ọ̀lù dé Róòmù láyọ̀.—Ìṣe 27:20-25; 28:16.
6. Ìlérí wo ni Jésù ṣe tó máa fún wa lókun, kí sì nìdí?
6 Bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Jésù máa ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ṣèlérí fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí máa ń fún wa lókun. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ọjọ́ kan máa ń wà tí nǹkan kì í dẹrùn. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn wa bá kú, ọgbẹ́ ọkàn tá a máa ń ní kì í lọ láàárín ọjọ́ mélòó kan, nígbà míì, ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn míì ń fara da ìṣòro tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ làwọn míì sì fi máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn. Èyí ó wù kó jẹ́, àá lè fara dà á torí a mọ̀ pé Jésù wà pẹ̀lú wa ní “gbogbo ọjọ́” títí kan àwọn ọjọ́ tí nǹkan nira fún wa gan-an.—Mát. 11:28-30.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí bó ṣe wà nínú Ìfihàn 14:6?
7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. (Héb. 1:7, 14) Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn, wọ́n sì ń tọ́ wá sọ́nà bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.”—Mát. 24:13, 14; ka Ìfihàn 14:6.
BÍ ÀWỌN TÓ WÀ NÍPÒ ÀṢẸ ṢE RÀN ÁN LỌ́WỌ́
8. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ọ̀gágun kan láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
8 Bí wọ́n ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ní 56 Sànmánì Kristẹni, Jésù fi Pọ́ọ̀lù lọ́kàn balẹ̀ pé ó máa dé Róòmù. Àmọ́, àwọn Júù kan tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbìmọ̀ pọ̀ láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á. Nígbà tí ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kíláúdíù Lísíà gbọ́ nípa ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, ó dáàbò bo Pọ́ọ̀lù. Láìjáfara, Kíláúdíù yan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun, ó sì ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaríà, tó jìnnà gan-an sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Gómìnà Fẹ́líìsì pàṣẹ pé “kí wọ́n máa ṣọ́ [Pọ́ọ̀lù] ní ààfin Hẹ́rọ́dù.” Ó dájú pé ọwọ́ àwọn apààyàn yẹn ò ní lè tẹ Pọ́ọ̀lù níbẹ̀.—Ìṣe 23:12-35.
9. Báwo ni Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
9 Lẹ́yìn ọdún méjì, Pọ́ọ̀lù ṣì wà ní àtìmọ́lé ní Kesaríà. Ní báyìí, Fẹ́sítọ́ọ̀sì ló rọ́pò Fẹ́líìsì bíi gómìnà. Àwọn Júù bẹ Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé kó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù kó lè wá jẹ́jọ́, àmọ́ Fẹ́sítọ́ọ̀sì ò gbà. Ó ṣeé ṣe kí gómìnà náà mọ̀ pé àwọn Júù “ń gbèrò láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á lójú ọ̀nà.”—Ìṣe 24:27–25:5.
10. Kí ni Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun máa fẹ́ kí Késárì gbọ́ ẹjọ́ òun?
10 Nígbà tó yá, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù ní Kesaríà. Torí pé Fẹ́sítọ́ọ̀sì “ń wá ojú rere àwọn Júù,” ó bi Pọ́ọ̀lù pé: “Ṣé o fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a lè dá ẹjọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi?” Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa òun tóun bá lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì mọ ohun tóun lè ṣe tọ́wọ́ àwọn apààyàn yẹn ò fi ní tẹ òun. Nípa bẹ́ẹ̀, òun á lè lọ sí Róòmù, òun á sì máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lọ. Torí náà, ó sọ pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ti bá àwọn agbaninímọ̀ràn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.” Ìpinnu tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣe yìí ló gba ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù là. Láìpẹ́, Pọ́ọ̀lù máa lọ sí Róòmù, ọwọ́ àwọn Júù tó ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á ò sì ní lè tẹ̀ ẹ́.—Ìṣe 25:6-12.
11. Ọ̀rọ̀ Àìsáyà wo ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ronú lé?
11 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń múra àtilọ sí Ítálì, ó ṣeé ṣe kó ronú lórí ìkìlọ̀ tí wòlíì Àìsáyà ṣe fáwọn ọ̀tá Jèhófà. Jèhófà gbẹnu Àìsáyà sọ pé: “Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, àmọ́ a máa dà á rú! Ẹ sọ ohun tó wù yín, àmọ́ kò ní yọrí sí rere, torí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!” (Àìsá. 8:10) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́, ó sì dájú pé ìyẹn máa fún un lókun láti fara da àwọn ìṣòro tó máa tó kojú.
12. Ọwọ́ wo ni Júlíọ́sì fi mú Pọ́ọ̀lù, kí ló sì ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù gbà nínú ọkàn rẹ̀?
12 Lọ́dún 58 Sànmánì Kristẹni, Pọ́ọ̀lù mú ìrìn àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí Ítálì. Torí pé ẹlẹ́wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù, abẹ́ àbójútó ọ̀gá àwọn ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Júlíọ́sì ni wọ́n fi í sí. Torí náà, Júlíọ́sì lágbára láti mú kí nǹkan dẹrùn fún Pọ́ọ̀lù, tó bá sì fẹ́ ó lè fayé ni ín lára. Àmọ́ kí ni Júlíọ́sì ṣe? Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀ sílùú kan lọ́jọ́ kejì, “Júlíọ́sì ṣojú rere sí Pọ́ọ̀lù, ó sì gbà á láyè láti lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Kódà, nígbà tó yá, Júlíọ́sì dá ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù sí. Lọ́nà wo? Àwọn ọmọ ogun tó kù fẹ́ pa gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú ọkọ̀ náà, àmọ́ Júlíọ́sì ò jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Júlíọ́sì ti “pinnu láti mú Pọ́ọ̀lù gúnlẹ̀ láìséwu.” Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù gbà lọ́kàn rẹ̀ pé Jèhófà ló lo ọ̀gá àwọn ọmọ ogun yẹn láti dáàbò bo òun.—Ìṣe 27:1-3, 42-44.
13. Báwo ni Jèhófà ṣe lè lo àwọn tó wà nípò àṣẹ?
13 Bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mú kí àwọn tó wà nípò àṣẹ ṣe ohun tó fẹ́ tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Ọkàn ọba dà bí odò ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi tí Ó bá fẹ́ ló ń darí rẹ̀ sí.” (Òwe 21:1) Kí ni òwe yìí túmọ̀ sí? Àwọn èèyàn lè gbẹ́lẹ̀ láti mú kí odò kan ṣàn gba ibi tí wọ́n bá fẹ́. Lọ́nà kan náà, Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti darí ọkàn àwọn alákòóso lọ́nà tó fi jẹ́ pé wọ́n á ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Tí Jèhófà bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó máa ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní.—Fi wé Ẹ́sírà 7:21, 25, 26.
14. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 12:5, àwọn wo la lè gbàdúrà fún?
14 Ohun tá a lè ṣe. A lè gbàdúrà fún “àwọn ọba àti gbogbo àwọn tó wà ní ipò àṣẹ” tó bá di pé kí wọ́n ṣe ìpinnu tó máa kan ìgbésí ayé wa àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (1 Tím. 2:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀; Neh. 1:11) Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà máa ń gbàdúrà kíkankíkan fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà lẹ́wọ̀n. (Ka Ìṣe 12:5; Héb. 13:3) Yàtọ̀ síyẹn, a tún lè gbàdúrà fún àwọn ẹ̀ṣọ́ tàbí àwọn wọ́dà tó ń bójú tó àwọn ará wa náà. A lè bẹ Jèhófà pé kó fọwọ́ tọ́ ọkàn wọn kí àwọn náà lè ṣe bíi Júlíọ́sì, kí wọ́n sì “ṣojú rere” sáwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n.—Ìṣe 27:3.
BÍ ÀWỌN KRISTẸNI BÍI TIẸ̀ ṢE RÀN ÁN LỌ́WỌ́
15-16. Báwo ni Jèhófà ṣe lo Àrísítákọ́sì àti Lúùkù láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
15 Bí wọ́n ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rìnrìn àjò lọ sí Róòmù, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà lo àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò.
16 Àrísítákọ́sì àti Lúùkù tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù pinnu láti bá a rìnrìn àjò náà lọ sí Róòmù.b Kò sí ibì kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé Jésù fara han Àrísítákọ́sì àti Lúùkù tó sì sọ fún wọn pé wọ́n máa dé Róòmù láyọ̀. Síbẹ̀, wọ́n gbà láti fi ẹ̀mí ara wọn wewu, kí wọ́n sì bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò yẹn. Ìgbà tí ìjì ń jà lójú omi tó sì ń bì lu ọkọ̀ wọn ni wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà máa dá ẹ̀mí àwọn sí. Torí náà, nígbà tí Àrísítákọ́sì àti Lúùkù wọnú ọkọ̀ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù ní Kesaríà, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù máa gbàdúrà sí Jèhófà, á sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó fún òun láwọn arákùnrin onígboyà méjì yìí láti ran òun lọ́wọ́.—Ìṣe 27:1, 2, 20-25.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn Kristẹni míì láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
17 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Kristẹni míì ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nígbà tó rìnrìn àjò lọ sí Róòmù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀ sí Sídónì, Júlíọ́sì gbà kí Pọ́ọ̀lù “lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀.” Nígbà tí wọ́n dé Pútéólì, Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ‘rí àwọn ará níbẹ̀, wọ́n sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn.’ Bí àwọn Kristẹni tó wà láwọn ìlú yẹn ṣe ń ṣe Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ lálejò, ó dájú pé Pọ́ọ̀lù á máa fi àwọn ìrírí tó ní gbé àwọn ará náà ró. (Fi wé Ìṣe 15:2, 3.) Lẹ́yìn ìbẹ̀wò tó ń fúnni níṣìírí yẹn, Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ń bá ìrìn àjò wọn lọ.—Ìṣe 27:3; 28:13, 14.
18. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run kó sì mọ́kàn le?
18 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sún mọ́ ìlú Róòmù, ó ṣeé ṣe kó máa rántí ohun tó kọ sí ìjọ tó wà ní ìlú yẹn lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún ló . . . ti ń wù mí kí n wá sọ́dọ̀ yín.” (Róòmù 15:23) Àmọ́, kò ronú pé ẹlẹ́wọ̀n lòun máa jẹ́ nígbà tóun bá wá. Ẹ wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó rí àwọn ará láti Róòmù tí wọ́n ń dúró dè é lójú ọ̀nà láti kí i káàbọ̀! Bíbélì ròyìn pé: “Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kàn le.” (Ìṣe 28:15) Ẹ kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tó rí àwọn ará yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jèhófà ló lo àwọn ará yẹn láti fún òun lókun.
19. Kí ni 1 Pétérù 4:10 sọ tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe lè lò wá láti ran àwọn míì lọ́wọ́?
19 Ohun tá a lè ṣe. Ǹjẹ́ o mọ arákùnrin tàbí arábìnrin èyíkéyìí nínú ìjọ yín tó ń ṣàìsàn tàbí tó ní àwọn ìṣòro míì tàbí téèyàn ẹ̀ kú? Tó o bá mọ irú ẹni bẹ́ẹ̀, o ò ṣe bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sọ ọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó máa tù ú nínú. Ó lè jẹ́ ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe yẹn ló máa fún ẹni náà lókun lásìkò yẹn. (Ka 1 Pétérù 4:10.)c Tá a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, á jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé ìlérí tí Jèhófà ṣe fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ kan àwọn náà, pé “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” Ó dájú pé inú ẹ máa dùn pé o ràn wọ́n lọ́wọ́. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
20. Kí nìdí tá a fi lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi”?
20 Bíi ti Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, àwa náà máa ń kojú ìṣòro bá a ṣe ń rìn lọ́nà tó lọ sí ìyè. Bákan náà, ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa. Jèhófà máa ń lo Jésù àtàwọn áńgẹ́lì láti ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tó bá sì bá ìfẹ́ ẹ̀ mu, ó lè lo àwọn tó wà nípò àṣẹ láti ràn wá lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wa la ti rí bí Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí ẹ̀ láti mú kí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Torí náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà lè fi gbogbo ẹnu sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”—Héb. 13:6.
ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà gbà ran àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó ní. Tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láyé àtijọ́, èyí á mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ bá a ṣe ń kojú ìṣòro.
b Àrísítákọ́sì àti Lúùkù ti fìgbà kan rí bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Àwọn arákùnrin méjèèjì yìí dúró ti Pọ́ọ̀lù ní gbogbo àsìkò tó fi wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù.—Ìṣe 16:10-12; 20:4; Kól. 4:10, 14.