Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.”—MÁTÍÙ 22:37.
1. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí Kristẹni máa ń mú dàgbà? (b) Ànímọ́ wo ló ṣe pàtàkì jù lọ fún Kristẹni, èé sì ti ṣe?
Ọ̀PỌ̀ ànímọ́ ni Kristẹni máa ń mú dàgbà kí ó bàa lè di òjíṣẹ́ tó gbéṣẹ́. Ìwé Òwe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀, òye, àti ọgbọ́n. (Òwe 2:1-10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ tó dúró sán-ún àti ìrètí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣe pàtàkì. (Róòmù 1:16, 17; Kólósè 1:5; Hébérù 10:39) A ò sì gbọ́dọ̀ kóyán ìfaradà òun ìkóra-ẹni-níjàánu kéré. (Ìṣe 24:25; Hébérù 10:36) Àmọ́, ó ṣì ku ànímọ́ kan, tó jẹ́ pé téèyàn ò bá ní in, gbogbo ànímọ́ yòókù kò ní níyì, kódà wọ́n tiẹ̀ lè máà wúlò. Ìfẹ́ ni ànímọ́ náà.—1 Kọ́ríńtì 13:1-3, 13.
2. Báwo ni Jésù ṣe fi bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó hàn, àwọn ìbéèrè wo sì ni èyí gbé dìde?
2 Jésù fi bí ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó hàn nígbà tó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìfẹ́ ni àmì tí a fi ń dá Kristẹni tòótọ́ mọ̀, ó yẹ ká béèrè àwọn ìbéèrè bíi, Kí ni ìfẹ́ jẹ́? Èé ṣe tó fi ṣe kókó tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí Jésù fi sọ pé ìfẹ́, lékè gbogbo ànímọ́ yòókù, ni a ó fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀? Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ dàgbà? Àwọn wo ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Kí Ni Ìfẹ́ Jẹ́?
3. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe ìfẹ́, èé sì ti ṣe tó fi wé mọ́ èrò inú àti ọkàn-àyà?
3 Ọ̀kan lára ọ̀nà táa lè gbà ṣàpèjúwe ìfẹ́ ni pé ó jẹ́ ‘ìfàsí ọkàn tàbí ìfẹ́ni àtọkànwá, ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ téèyàn ní fún ẹlòmíì.’ Ó jẹ́ ànímọ́ tí ń sún àwọn èèyàn láti ṣiṣẹ́ fún ire àwọn ẹlòmíì, àní kéèyàn tiẹ̀ fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara ẹ̀ nígbà míì. Ìfẹ́ tí Bíbélì ṣàpèjúwe wé mọ́ èrò inú àti ọkàn-àyà. Ó wé mọ́ èrò inú, tàbí lédè mìíràn làákàyè, nítorí pé ẹni tó nífẹ̀ẹ́ kì í ṣe aláìmọ̀kan, ó mọ̀ pé bí òun àtàwọn ẹlòmíì tí òun fẹ́ràn ṣe ní àwọn ànímọ́ tó dáa, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tún ní àléébù. Àní ó gba làákàyè, nítorí pé àwọn kan wà tí kò ní yá Kristẹni kan lára láti nífẹ̀ẹ́ wọn. Àmọ́ nígbà tó bá rò ó lọ, tó rò ó bọ̀, á wá nífẹ̀ẹ́ wọn, nítorí ó mọ̀ pé ohun tí òun kà nínú Bíbélì ni pé Ọlọ́run fẹ́ kóun nífẹ̀ẹ́ wọn. (Mátíù 5:44; 1 Kọ́ríńtì 16:14) Ṣùgbọ́n o, inú ọkàn gan-an ni ìfẹ́ ti ń wá. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi hàn, ojúlówó ìfẹ́ kì í ṣe ọ̀ràn làákàyè nìkan. Ó wé mọ́ òtítọ́ inú àti fífẹ́ni dénú.—1 Pétérù 1:22.
4. Báwo ni ìfẹ́ ṣe jẹ́ ìdè tó lágbára?
4 Àwọn tó bá ní ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan kì í sábàá fi ọkàn fẹ́ni, nítorí pé ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fi ire àwọn ẹlòmíì ṣíwájú tirẹ̀. (Fílípì 2:2-4) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ,” pàápàá tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ló jẹ́ kéèyàn fúnni ní nǹkan. (Ìṣe 20:35) Ìdè ìfẹ́ lágbára púpọ̀. (Kólósè 3:14) Ó sábà máa ń wé mọ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n ìdè ìfẹ́ tún lágbára ju ti ọ̀rẹ́ lọ. Nígbà míì, a máa ń pe ìbáṣepọ̀ àárín tọkọtaya ní ìfẹ́; àmọ́ ìfẹ́ tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní tún ré kọjá ti òòfà ẹwà. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni tọkọtaya kan nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọn ò ní já ara wọn jù sílẹ̀, kódà bí ìfararora kò bá ṣeé ṣe mọ́ nítorí hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó tàbí nítorí pé ọ̀kan lára wọn ti di aláìlera.
Ànímọ́ Pàtàkì Ni Ìfẹ́
5. Èé ṣe tí ìfẹ́ fi jẹ́ ànímọ́ tó ṣe kókó fún Kristẹni?
5 Èé ṣe tí ìfẹ́ fi jẹ́ kòṣeémánìí fún Kristẹni? Èkíní, nítorí pé Jésù pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ó sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín. Nǹkan wọ̀nyí ni mo pa láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 15:14, 17) Èkejì, níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ afi-gbogbo-ara-ṣe-ìfẹ́, ó yẹ kí àwa náà táa ń sìn ín máa fara wé e. (Éfésù 5:1; 1 Jòhánù 4:16) Bíbélì sọ pé gbígba ìmọ̀ Jèhófà àti ti Jésù sínú ni yóò túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Báwo la ṣe lè sọ pé a mọ Ọlọ́run bí a kò bá gbìyànjú láti dà bíi rẹ̀? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.
6. Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè mú kí onírúurú ìhà ìgbésí ayé wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì?
6 Ìdí kẹta rèé tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì: Ó ń jẹ́ kí àwọn apá yòókù nínú ìgbésí ayé wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì ń jẹ́ ká ní ète tí ó tọ́ fún ohun tí à ń ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ó pọndandan láti máa bá a nìṣó ní gbígba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. Lójú Kristẹni, irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kò yàtọ̀ sí oúnjẹ jíjẹ. Ó ń jẹ́ kó dàgbà di géńdé, kí ó sì máa gbégbèésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:105; Mátíù 4:4; 2 Tímótì 3:15, 16) Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:1) Ká má ṣì í gbọ́ o, kò sọ pé ohunkóhun burú nínú ìmọ̀ pípéye. Àwa la níṣòro, èyíinì ni ìtẹ̀sí fún ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Bí ìfẹ́, tí ń mú kí nǹkan wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kò bá sí, ìmọ̀ lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wú fùkẹ̀, kí ó máa rò pé òun sàn ju àwọn yòókù lọ. Ìyẹn ò ní ṣẹlẹ̀ bó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ló ń sún un hùwà. “Ìfẹ́ . . . kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Kristẹni tí ìfẹ́ ń sún hùwà kì í gbéra ga, bó tiẹ̀ ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀. Ìfẹ́ yóò jẹ́ kó níwà ìrẹ̀lẹ̀, kí ó sì yẹra fún fífẹ́ láti ṣe orúkọ fún ara rẹ̀.—Sáàmù 138:6; Jákọ́bù 4:6.
7, 8. Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ?
7 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún; pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:9, 10) Ìfẹ́ Kristẹni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí lò, láti máa wádìí dájú nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì yẹ̀ wò, pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tímótì 3:1) Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, iye àwọn ìjọ tó wà yí ká ayé fi 1,502 lé sí i, àròpọ̀ gbogbo rẹ̀ báyìí sì jẹ́ 91,487. Fún ìdí yìí, a ń fẹ́ àwọn alàgbà púpọ̀ sí i, ó sì yẹ ká gbóríyìn fáwọn tó ń nàgà fún àǹfààní yìí.
8 Àmọ́ o, àwọn tó ń nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ àbójútó yóò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì kí wọ́n má bàa gbàgbé ète irú àǹfààní bẹ́ẹ̀. Kí ọwọ́ tẹ ọ̀pá àṣẹ, tàbí ká yọrí ọlá kọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì. Ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún àwọn ará ló gba ọkàn àwọn alàgbà tí ń múnú Jèhófà dùn. Òkìkí tàbí agbára kọ́ ni wọ́n ń dù. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn alàgbà nínú ìjọ ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n máa hùwà rere, ó wá tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” Ó gba gbogbo àwọn ará nínú ìjọ nímọ̀ràn pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:1-6) Á dára kí ẹnikẹ́ni tó bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ yìí máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àìmọye àwọn alàgbà yí ká ayé, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n níwà ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì tipa báyìí jẹ́ orísun ìbùkún fún ìjọ wọn.—Hébérù 13:7.
Ète Rere Ń Jẹ́ Ká Ní Ìfaradà
9. Èé ṣe táwọn Kristẹni ń fi àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí sọ́kàn?
9 Ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ kí ìfẹ́ sún wa ṣiṣẹ́ tún hàn kedere ní ọ̀nà mìíràn. Bíbélì ṣèlérí ìbùkún jìngbìnnì nísinsìnyí àti àgbàyanu ìbùkún yabuga-yabuga lọ́jọ́ iwájú fún àwọn tó ń fi ìfẹ́ lépa ìfọkànsin Ọlọ́run. (1 Tímótì 4:8) Kristẹni tó bá fi tọkàntọkàn gba ìlérí wọ̀nyí gbọ́, tó sì dá a lójú gbangba pé Jèhófà ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a” ni a ń ràn lọ́wọ́ láti dúró láìyẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. (Hébérù 11:6) Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ló ń yán hànhàn fún ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run, a sì ń tìtorí èyí sọ irú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ, pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” (Ìṣípayá 22:20) Dájúdájú, báa bá jẹ́ olóòótọ́, ríronú lórí àwọn ìbùkún tí ń bẹ níwájú ń fún wa lókun láti fara dà á, gan-an gẹ́gẹ́ bí fífi tí Jésù fi “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀” sọ́kàn ṣe ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á.—Hébérù 12:1, 2.
10, 11. Bí ìfẹ́ bá ń sún wa ṣiṣẹ́, báwo ni èyí yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á?
10 Ṣùgbọ́n, tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ láti gbé nínú ayé tuntun nìkan ni ète táa fi ń sin Jèhófà ńkọ́? Tóò, á jẹ́ pé kò ní pẹ́ tí a ó di aláìnísùúrù tàbí aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nígbà tí nǹkan bá ń lọ́ tín-ín-rín tàbí nígbà tí ọ̀nà ò bá gba ibi táa fojú sí. Á jẹ́ pé ewu ńlá dé nìyẹn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí sú lọ láìmọ̀. (Hébérù 2:1; 3:12) Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀gbẹ́ni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Démà. Wọ́n jọ ń rìn tẹ́lẹ̀ ni o, àmọ́ ó pa Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó yá. Kí ló dé? Nítorí pé “ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (2 Tímótì 4:10) Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ pé torí tara ẹ̀ nìkan ló ṣe ń sìn kò lè ṣe kó máà gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn. Ojú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè wọ àwọn àǹfààní ojú ẹsẹ̀ táyé ń nawọ́ rẹ̀ síni, kí wọ́n má sì fẹ́ fi nǹkan kan du ara wọn nísinsìnyí kí wọ́n bàa lè gbádùn àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú.
11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò burú tó sì bá ìwà ẹ̀dá mu láti máa wọ̀nà fún àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú ká sì máa retí ìtura táa máa rí kúrò lọ́wọ́ àwọn àdánwò, síbẹ̀síbẹ̀, ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ohun tó yẹ kó gbawájú nínú ìgbésí ayé wa. Ohun tí àwa fẹ́ kọ́ ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Lúùkù 22:41, 42) Dájúdájú, ìfẹ́ máa ń gbé wa ró. Ó ń jẹ́ ká fi sùúrù dúró de Ọlọ́run wa láìjanpata, kí ìbùkún yòówù tó bá fún wa tẹ́ wa lọ́rùn, kí ọkàn wa sì balẹ̀ pé nígbà tó bá tọ́ lójú rẹ̀, ọwọ́ wa yóò tẹ gbogbo ohun tó ti ṣèlérí—àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. (Sáàmù 145:16; 2 Kọ́ríńtì 12:8, 9) Ní báyìí ná, ìfẹ́ yóò jẹ́ ká máa fi àìmọtara-ẹni-nìkan sìn nìṣó, nítorí pé “ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
Àwọn Wo Ló Yẹ Káwọn Kristẹni Nífẹ̀ẹ́?
12. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ, àwọn wo ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́?
12 Ìlànà tó gbòòrò ni Jésù fi lélẹ̀ nípa àwọn tó yẹ ká nífẹ̀ẹ́, nígbà tó fa gbólóhùn méjì yọ látinú Òfin Mósè. Ó wí pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ,” èkejì sì ni pé, “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:37-39.
13. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí Jèhófà, báwo la ṣe lè kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
13 Látinú ọ̀rọ̀ Jésù, ó ṣe kedere pé, lékè gbogbo rẹ̀, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́ kò sẹ́ni tí wọ́n bí pẹ̀lú ògidì ìfẹ́ fún Jèhófà nínú wa. A gbọ́dọ̀ kọ́ ọ ni. Nígbà táa kọ́kọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ohun táa gbọ́ ló mú wa fà sún mọ́ ọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe ṣètò ilẹ̀ ayé sílẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:5-23) A kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí aráyé, bí kò ti ta wá nù nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ kọ́kọ́ kó àìrójú-ráyè bá ọmọ aráyé, ṣùgbọ́n tó ṣètò bí a ó ṣe rà wá padà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 15) Ó fi inú rere bá àwọn tó ṣolóòótọ́ lò, níkẹyìn ó sì pèsè Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 3:16, 36) Bí a ti ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ ni a túbọ̀ ń mọyì Jèhófà. (Aísáyà 25:1) Dáfídì Ọba sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. (Sáàmù 116:1-9) Lóde òní, Jèhófà ń tọ́jú wa, ó ń ṣamọ̀nà wa, ó ń fún wa lókun, ó sì ń fún wa níṣìírí. Bí a bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ wa yóò túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i.—Sáàmù 31:23; Sefanáyà 3:17; Róòmù 8:28.
Báwo La Ṣe Lè Fi Ìfẹ́ Wa Hàn?
14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkànwá?
14 Gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti mọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn yí ká ayé lónìí ló ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìṣesí wọn yàtọ̀ pátápátá sóhun tí wọ́n ń sọ lẹ́nu. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? A lè bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà kí a sì sọ ohun tó ń ṣe wá fún un. A sì lè gbégbèésẹ̀ lọ́nà tó fi han pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń pa ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run] mọ́, lótìítọ́ nínú ẹni yìí ni a ti sọ ìfẹ́ fún Ọlọ́run di pípé. Nípasẹ̀ èyí ni a ní ìmọ̀ pé a wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:5; 5:3) Ara ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká ṣe ni pé ká máa pàdé pọ̀, ká sì máa gbé ìgbésí ayé tí ó mọ́, tí kò lẹ́gbin. A máa ń yàgò fún ìwà àgàbàgebè, a ń sọ òtítọ́, a sì ń rí sí i pé ìrònú wa wà ní mímọ́. (2 Kọ́ríńtì 7:1; Éfésù 4:15; 1 Tímótì 1:5; Hébérù 10:23-25) Ríran àwọn aláìní lọ́wọ́ nípa tara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táa gbà ń fìfẹ́ hàn. (1 Jòhánù 3:17, 18) Bákan náà, a kì í yé sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn. Èyí wé mọ́ nínípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé. (Mátíù 24:14; Róòmù 10:10) Ṣíṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú irú nǹkan báwọ̀nyí ló fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkànwá.
15, 16. Báwo ni ìfẹ́ fún Jèhófà ṣe nípa lórí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́dún tó kọjá?
15 Ìfẹ́ fún Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa. Lọ́dún tó kọjá, irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sún 288,907 èèyàn láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún un, wọ́n sì fi hàn pé àwọn ti ṣe ìpinnu yẹn nípa ṣíṣe batisí. (Mátíù 28:19, 20) Ìyàsímímọ́ tí wọ́n ṣe ní ìtumọ̀. Ó sàmì sí ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn. Fún àpẹẹrẹ, Gazmend jẹ́ òléwájú lára àwọn ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Albania. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdènà pọ̀ lọ́tùn-ún lósì, òun àtìyàwó rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún mélòó kan, wọ́n sì di akéde Ìjọba náà níkẹyìn. Lọ́dún tó kọjá ni Gazmend ṣe batisí. Ó jẹ́ ọ̀kan lára 366 èèyàn tó ṣe batisí ní Albania ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000. Ìwé ìròyìn kan tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde nípa rẹ̀, pé: “Ìgbésí ayé rẹ̀ ní ète, fún ìdí yìí, ìsinsìnyí lòun àti ìdílé rẹ̀ láyọ̀ jù lọ láyé wọn. Ní tirẹ̀, kì í ṣe eré bó ṣe lè jèrè gbogbo ayé ló ń sá kiri mọ́ báyìí, bí kò ṣe bó ṣe lè sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.”
16 Bákan náà, arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tó ń ṣiṣẹ́ fún iléeṣẹ́ elépo rọ̀bì kan ní Guam, rí àǹfààní kan tó ṣòroó kọ̀. Lẹ́yìn tó ti dọ̀gá níbi iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n wá láwọn fẹ́ sọ ọ́ di obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fi jẹ igbá kejì ààrẹ látìgbà tí wọ́n ti dá iléeṣẹ́ náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, òun rèé tó ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà báyìí. Nítorí náà, lẹ́yìn tóun àti ọkọ rẹ̀ jíròrò ọ̀ràn náà, arábìnrin tuntun yìí kò tẹ́wọ́ gba ipò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ṣètò fún iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kí ó bàa lè tẹ̀ síwájú láti di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ìfẹ́ fún Jèhófà sún un láti fẹ́ sìn ín gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, kàkà tí ì bá fi máa lé owó kiri nínú ayé yìí. Àní, irú ìfẹ́ yìí ló sún 805,205 èèyàn kárí ayé láti nípìn-ín nínú onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000. Àwọn aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyí mà ní ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ o!
Nínífẹ̀ẹ́ Jésù Látọkànwá
17. Kí ni àpẹẹrẹ rere tí Jésù fi lélẹ̀ nípa ìfẹ́?
17 Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ wíwúnilórí nípa ẹnì kan tí ìfẹ́ sún ṣiṣẹ́. Kó tó di pé ó wá sílé ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ó nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ aráyé. Gẹ́gẹ́ bí ẹni táa pè ní ọgbọ́n, ó sọ pé: “Mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ilẹ̀ eléso ilẹ̀ ayé rẹ̀, àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:30, 31) Ìfẹ́ tí Jésù ní sún un láti fi ibùgbé rẹ̀ ní ọ̀run sílẹ̀, a sì bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré jòjòló. Ó mú sùúrù, ó sì káàánú àwọn onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀, àwọn ọ̀tá Jèhófà tún fìyà jẹ ẹ́. Níkẹyìn, ó kú fún gbogbo aráyé lórí òpó igi oró. (Jòhánù 3:35; 14:30, 31; 15:12, 13; Fílípì 2:5-11) Àpẹẹrẹ ìfẹ́ àtinúwá yìí mà ga o!
18. (a) Báwo la ṣe ń mú ìfẹ́ fún Jésù dàgbà? (b) Ọ̀nà wo la gbà ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù?
18 Nígbà táwọn tó ní ọkàn rere bá ka àwọn ìròyìn nípa ìgbésí ayé Jésù nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, tí wọ́n sì ṣàṣàrò lórí ọ̀pọ̀ ìbùkún tí ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ rẹ̀ ti mú bá wọn, èyí yóò mú kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún un ta gbòǹgbò nínú ọkàn wọn. Àwa lónìí dà bí àwọn tí Pétérù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí [Jésù] rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Pétérù 1:8) A ó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí a sì ń fara wé ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:1; 1 Tẹsalóníkà 1:6; 1 Pétérù 2:21-25) Ní April 19, 2000, àròpọ̀ 14,872,086 ni a rán létí nípa àwọn ìdí tó fi yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jésù, nígbà tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ táa máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ẹ ò rí i pé èrò tó wá pọ̀ gan-an! Ẹ sì wo bó ṣe fúnni lókun tó láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ ìgbàlà nípasẹ̀ ẹbọ Jésù! Ní tòótọ́, ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní fún wa àti èyí táwa náà ní fún wọn ń gbé wa ró.
19. Kí làwọn ìbéèrè tí a óò jíròrò nípa ìfẹ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Jésù sọ pé kí a fi gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò inú, àti okun wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ṣùgbọ́n ó tún sọ pé kí a nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Máàkù 12:29-31) Àwọn wo ni ìyẹn ní nínú? Báwo sì ni ìfẹ́ fún aládùúgbò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí a sì ní ète rere? A óò jíròrò ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Èé ṣe tí ìfẹ́ fi jẹ́ ànímọ́ tó ṣe kókó?
• Báwo la ṣe lè kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
• Báwo ni ìwà wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
• Báwo la ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Ìfẹ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi sùúrù dúró de ìtura
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ẹbọ ńlá tí Jésù rú ń sún wa láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀