Ẹ̀bùn Tó Máa Wà Títí Láé Tí Ẹlẹ́dàá Fún Wa
ǸJẸ́ kò yà ọ́ lẹ́nu pé orí àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ó gbọ́dọ̀ wà nínú pílánẹ́ẹ̀tì kan kóhun ẹlẹ́mìí tó lè wà níbẹ̀? Kí làwọn ohun náà?
Kí ohun ẹlẹ́mìí tó lè wà nínú pílánẹ́ẹ̀tì kan, omi tó pọ̀ gan-an gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀, irú èyí tí Jẹ́nẹ́sísì 1:2 sọ. Bákan náà, pílánẹ́ẹ̀tì náà ò gbọ́dọ̀ tutù jù kò sì gbọ́dọ̀ gbóná jù débi tí omi á fi di yìnyín tàbí táá fi gbẹ. Kéyìí sì tó lè rí bẹ́ẹ̀, pílánẹ́ẹ̀tì náà ò gbọ́dọ̀ jìnnà sí oòrùn jù, kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ ọn jù. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, léraléra ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ̀rọ̀ nípa oòrùn àti àǹfààní tó ń ṣe fún ilẹ̀ ayé.
Kí pílánẹ́ẹ̀tì kan tó lè jẹ́ èyí tó ṣeé gbé fún èèyàn, ìwọ̀n onírúurú afẹ́fẹ́ tó yẹ gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀. Jẹ́nẹ́sísì 1:6-8 sì mẹ́nu kan ohun pàtàkì yìí. Àwọn ewéko tí Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 12 sọ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà ló mú kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó wà pọ̀ gan-an. Láfikún, kí onírúurú àwọn ẹranko tó lè wà nínú pílánẹ́ẹ̀tì kan, pílánẹ́ẹ̀tì náà gbọ́dọ̀ ní ìyàngbẹ ilẹ̀ tó lọ́ràá, irú èyí tí Jẹ́nẹ́sísì 1:9-12 mẹ́nu kàn. Yàtọ̀ síyẹn, kí ojú ọjọ́ tó lè máa rí bó ṣe yẹ kó rí ní pílánẹ́ẹ̀tì kan, pílánẹ́ẹ̀tì náà gbọ́dọ̀ dagun ní ìwọ̀n tó yẹ kó má sì yẹ̀ kúrò níbẹ̀. Ní ti ayé, agbára òòfà òṣùpá wà lára ohun tó jẹ́ kó dagun tí ò sì jẹ́ kó yẹ̀ kúrò lápá ibi tó dagun sí. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1:14, 16 sọ bí òṣùpá yìí ṣe dèyí tó wà àtàwọn àǹfààní tó ń ṣe.
Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún Mósè tó gbé láyé ìgbà tí kò tíì sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tá a sọ yìí? Àbí ńṣe ló kàn ní òye àrà ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ ò ní, tó jẹ́ kó mọ bí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣe ṣe pàtàkì tó? Ṣó o rí i, ohun tó mú kí Mósè mọ àwọn ohun náà ni pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ló mí sí i. Òdodo ọ̀rọ̀ sì nìyẹn, nítorí pé àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì bá ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mu.
Bíbélì sọ pé ó dájú pé ìdí kan wà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo àwọn ohun ìyanu tó wà nínú ayé òun òfuurufú tó lọ salalu. Sáàmù 115:16 sọ pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” Sáàmù mìíràn sọ pé: “Ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá ló dá ilé ayé wa tó jẹ́ ẹlẹ́wà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ó lè mú kó wà títí láé. Èyí fi hàn pé ó yẹ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé dájúdájú, á mú ìlérí tó ṣe ṣẹ, pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run “kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán,” kàkà bẹ́ẹ̀, “ó ṣẹ̀dá rẹ̀” káwọn èèyàn tí wọ́n gbà pé òun ló dá àwọn nǹkan, tí wọ́n sì mọyì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, “lè máa gbé inú rẹ̀” títí láé.—Aísáyà 45:18.
Ìwé Mímọ́ sọ pé Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé kó lè kọ́ wa nípa Ọlọ́run àti nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ìyẹn láti fún àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Bíbélì mú un dá wa lójú pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé,” yóò sì dá àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ohun tó ṣe láti gbani là sí ní gbogbo orílẹ̀-èdè. (Ìṣípayá 7:9, 14; 11:18) Ńṣe layé á máa dùn yùngbà títí láé báwọn èèyàn bá ṣe ń ṣàwárí àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run dá tí wọ́n sì ń gbádùn rẹ̀!—Oníwàásù 3:11; Róòmù 8:21.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Fọ́tò NASA