Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
“Ayé yìí lágbára láti tún ara ẹ̀ ṣe ju bá a ṣe rò lọ.”
Ibi tí àwùjọ kan tó ń ṣèwádìí karí ayé nípa bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà parí èrò wọn sí nìyẹn. Ohun tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ká rí i pé ńṣe ni Ọlọ́run dá ayé yìí lọ́nà tó fi lè máa tún ara ẹ̀ ṣe, ìyẹn sì fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa.
Torí pé àwọn èèyàn ti ba ayé yìí jẹ́ gan-an, kò lè tún ara ẹ̀ ṣe mọ́, àfi kí Ọlọ́run bá wa tún un ṣe. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa tún un ṣe lóòótọ́?
Kíyè sí ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àpótí yìí sọ tó jẹ́ ká gbà pé ayé yìí máa wà títí láé, á sì dùn-ún gbé.
Ọlọ́run ló dá ayé yìí. “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.” —Jẹ́nẹ́sísì 1:1
Ọlọ́run ló ni ayé yìí. “Jèhófàa ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.”—Sáàmù 24:1
Ọlọ́run dá ayé kó lè wà títí láé. “Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò ṣí i nípò títí láé àti láéláé.”—Sáàmù 104:5
Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn ohun alààyè á máa gbé ayé títí láé. “Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá ayé, . . . kò kàn dá a lásán, àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.”—Àìsáyà 45:18
Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé. “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:29
Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ń ṣe àwọn nǹkan tó ń pa ayé yìí lára, àmọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ayé yìí ò lè jẹ́ kí wọ́n bà á jẹ́ kọjá àtúnṣe. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, Jèhófà Ọlọ́run ò ní gbà káwọn èèyàn pa ayé yìí run, ó ti yan àkókò tó máa run gbogbo àwọn tó ń ba ayé yìí jẹ́.—Ìfihàn 11:18
Bíbélì ṣèlérí pé tó bá yá Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè tó rẹwà, ó sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.” —Sáàmù 145:16
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.