Onírúurú Èrò Nípa Béèyàn Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run
NÍNÚ ìwàásù Jésù lórí òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ pé ó yẹ káwọn sún mọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì gbà pé táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọ́n á máa láyọ̀. Àmọ́, kí ni “jíjẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run” túmọ̀ sí?
Ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ sísúnmọ́ Ọlọ́run sí ni, “kéèyàn jẹ́ ẹni tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré” tàbí “kéèyàn jẹ́ ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run.” Nípa bẹ́ẹ̀, ohun kan náà làwọn èèyàn gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí. Kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí lè túbọ̀ ṣe kedere, wo àfiwé yìí: Ẹni tó bá jára mọ́ṣẹ́ ni wọ́n máa ń sọ pé kò fiṣẹ́ ṣeré. Bọ́rọ̀ ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn ṣe rí náà nìyẹn, wọ́n máa ń sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré.
Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, báwo wá lẹnì kan ṣe lè jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ló máa ń sọ pé àwọn mọ ọ̀nà téèyàn lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run, bí ẹ̀sìn ṣe pọ̀ tó náà làwọn ọ̀nà tí wọ́n là kalẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì máa ń sọ pé àwọn rí ìgbàlà níbi ìsọjí. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sì máa ń lọ sí Máàsì kó bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà ní tiwọn máa ń wá ìlàlóye nípa ṣíṣe àṣàrò. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù sì máa ń ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́ nítorí kí wọ́n máa bàa máa tún ayé wá ṣáá. Ṣé gbogbo àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí ló ń múni sún mọ́ Ọlọ́run lóòótọ́? Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí lè múni sún mọ́ Ọlọ́run?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò dáhùn pé rárá. Wọ́n ní “èèyàn lè nígbàgbọ́ láìṣe ẹ̀sìn kankan,” ìyẹn ni pé, kéèyàn nígbàgbọ́ nínú nǹkan kan láìjẹ́ pé èèyàn ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn mìíràn sì gbà pé kì í ṣe ṣíṣe ẹ̀sìn ló ń fi hàn pé èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run, àmọ́ ohun tó túmọ̀ sí ni kéèyàn fẹ́ láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti pé kéèyàn fẹ́ káyé òun nítumọ̀. Wọ́n ní kò pọn dandan rárá káwọn tó fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run máa ṣe ẹ̀sìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kàn máa ṣe ni pé kí wọ́n máa kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wọn, ìyẹn ohun tí wọ́n máa ń rò nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ọkàn ẹni nígbàgbọ́ ẹni. Ọ̀nà téèyàn ń gbà nífẹ̀ẹ́ ohun tó ń lọ láyìíká rẹ̀ àtàwọn èèyàn tó yí i ká, bó ṣe fara mọ́ wọn sí, àti bó ṣe ń ṣe sí wọn, ló máa fi hàn pé ó sún mọ́ Ọlọ́run. Kì í ṣe nípa lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tàbí gbígba àwọn nǹkan kan gbọ́.”
Láìsí àní-àní, èrò àwọn èèyàn nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run yàtọ̀ síra gan-an. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé làwọn èèyàn ń ṣe jáde, tí wọ́n ń fi sọ pé àwọn lè fi ọ̀nà téèyàn lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run hanni. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn tó ń ka àwọn ìwé wọ̀nyí kì í rí ohun tí wọ́n ń wá, ńṣe ni gbogbo rẹ̀ sì máa ń tojú sú wọn. Àmọ́ ìwé kan wà tó lè tọ́ni sọ́nà nípa béèyàn ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ìwé téèyàn lè gbára lé. Ó jẹ́ ìwé tó ní àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run mí sí i. (2 Tímótì 3:16) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí ìwé náà, ìyẹn Bíbélì, sọ nípa ohun tí sísúnmọ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Background: © Mark Hamblin/age fotostock