Awọn Ìdílé Kristian Ń fi Àwọn Ohun Tẹ̀mí Sí Ipò Àkọ́kọ́
“Lákòótán, kí gbogbo yin ṣe onínú kan, ẹ máa bá ara yin kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.”—1 PETERU 3:8.
1. Yíyàn wo ni gbogbo wa ní, báwo sì ni yíyàn wa ṣe lè nípa lórí ọjọ́-ọ̀la wa?
ẸWO bí ọ̀rọ̀ ẹsẹ-ìwé tí ó wà lókè yìí ti ṣeé fisílò tó nínú ètò-ìdásílẹ̀ araye tí ó lọ́jọ́ lórí julọ—ìdílé! Ó sì ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn òbí fi ipò-aṣíwájú hàn ni àwọn ọ̀nà wọ̀nyí! Àwọn ànímọ́ agbéniró wọn àti èyí tí ó jẹ́ òdìkejì yóò sábà máa farahan lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwọn ọmọ wọn. Síbẹ̀, àǹfààní láti ṣe yíyàn dọwọ́ mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé. Gẹ́gẹ́ bí Kristian, àwa lè yàn láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí tàbí ẹni ti ara. A lè yàn láti tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn tàbí láti ṣàìtẹ́ ẹ lọ́rùn. Yíyàn yẹn lè yọrísí yálà ìbùkún, ìyè àìnípẹ̀kun àti àlàáfíà—tàbí ègún, ikú ayérayé.—Genesisi 4:1, 2; Romu 8:5-8; Galatia 5:19-23.
2. (a) Báwo ni Peteru ṣe fi ìdàníyàn rẹ̀ fún ìdílé hàn? (b) Kí ni ipò-tẹ̀mí? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀-ìwé.)
2 Àwọn ọ̀rọ̀ aposteli náà ní Peteru Kìn-ín-ní orí kẹta, ẹsẹ kẹjọ, tẹ̀lé e kété lẹ́yìn àwọn ìmọ̀ràn rere kan tí òun ti fifún àwọn aya àti ọkọ. Peteru lọ́kàn-ìfẹ́ nítòótọ́ nínú ire àlàfíà àwọn ìdílé Kristian. Ó mọ̀ pé ipò-tẹ̀mí lílágbára ni kọ́kọ́rọ́ náà sí agbo-ilé sísopọ̀ṣọ̀kan, onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú. Nípa báyìí, òun dọ́gbọ́n ní in lọ́kàn ní ẹsẹ keje pé bí a bá ṣàìnáání ìmọ̀ràn rẹ̀ sí àwọn ọkọ, ìyọrísí náà yóò jẹ́ ìdènà tẹ̀mí kan láàárín ọkọ náà àti Jehofa.a Àdúrà ọkọ lè ní ìdènà bí ó bá pa àwọn àìní aya rẹ̀ tì tàbí bí ó bá fi àìnínúure dá a lágara.
Kristi—Àpẹẹrẹ Pípé kan Níti Ipò-Tẹ̀mí
3. Báwo ni Paulu ṣe tẹnumọ́ àpẹẹrẹ Kristi fún àwọn ọkọ?
3 Ipò-tẹ̀mí ìdílé kan sinmi lórí àpẹẹrẹ rere. Nígbà tí ọkọ bá jẹ́ Kristian nínú ìwà àti ìṣe, ó ń mú ipò iwájú nínú fífi àwọn ànímọ́ tẹ̀mí hàn. Bí kò bá sí ọkọ tí ó gbàgbọ́, ìyá sábà máa ń gbìyànjú láti gbé ẹrù-iṣẹ́ náà. Nínú ọ̀ràn méjèèjì, Jesu Kristi pèsè àwòkọ́ṣe pípé láti tẹ̀lé. Ìwà rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ìrònú rẹ̀ jẹ́ èyí tí ń gbéniró tí ó sì ń tunilára nígbà gbogbo. Léraléra, aposteli Paulu darí òǹkàwé sí àpẹẹrẹ onífẹ̀ẹ́ ti Kristi. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ọkọ níí ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe orí ìjọ ènìyàn rẹ̀: òun sì ni Olùgbàlà ara. Ẹyin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yin, gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.”—Efesu 5:23, 25, 29; Matteu 11:28-30; Kolosse 3:19.
4. Àpẹẹrẹ ipò-tẹ̀mí wo ni Jesu fi lélẹ̀?
4 Jesu jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ nípa ipò-tẹ̀mí àti ipò-orí ti a fihàn pẹ̀lú ìfẹ́, inúrere, àti àánú. Òun jẹ́ olùfara-ẹni-rubọ, kìí ṣe olùtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn. Òun máa ń fògo fún Baba rẹ̀ nígbà gbogbo ó sì bọ̀wọ̀ fún ipò-orí rẹ̀. Ó ń tẹ̀lé ìdarí Baba náà, débi tí òun fi lè sọ pé: “Èmi kò lè ṣe ohun kan fún ara mi: bí mo ti ń gbọ́, mo ń dájọ́: òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi tìkáraàmi, bíkòṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” “Èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi, èmi ń sọ nǹkan wọ̀nyí.”—Johannu 5:30; 8:28; 1 Korinti 11:3.
5. Ní pípèsè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àpẹẹrẹ wo ni Jesu fi lélẹ̀ fún àwọn ọkọ?
5 Kí ni èyí túmọ̀sí fún àwọn ọkọ? Ó túmọ̀sí pé àwòkọ́ṣe tí wọ́n níláti tẹ̀lé nínú ohun gbogbo ni Kristi, ẹni tí ó máa ń tẹrí araarẹ̀ ba fún Baba rẹ̀ nígbà gbogbo. Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti pèsè oúnjẹ fún gbogbo onírúurú ìṣẹ̀dá lórí ilẹ̀-ayé, bẹ́ẹ̀ ni Jesu ṣe pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Òun kò ṣàìnáání àwọn àìní wọn nípa ti ara tí ó jẹ́ kòṣeémánìí. Àwọn iṣẹ́-ìyanu rẹ̀ ti fífoúnjẹ bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin jẹ́ ẹ̀rí ìbìkítà rẹ̀ àti èrò-ìmọ̀lára ìmẹrù-iṣẹ́-níṣẹ́ rẹ̀. (Marku 6:35-44; 8:1-9) Bákan náà lónìí, àwọn olórí ìdílé tí wọ́n mọ ẹrù-iṣẹ́ níṣẹ́ ń bójútó àìní ti ara àwọn agbo-ilé wọn. Ṣùgbọ́n ẹrù-iṣẹ́ wọn ha parí síbẹ̀ bí?—1 Timoteu 5:8.
6. (a) Àwọn àìní pàtàkì ti ìdílé wo ni a gbọ́dọ̀ bójútó? (b) Báwo ni àwọn ọkọ àti baba ṣe lè fi òye hàn?
6 Àwọn ìdílé tún ní àwọn àìní mìíràn, tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe ṣàlàyé. Wọ́n ní àìní tẹ̀mí àti ti èrò-ìmọ̀lára. (Deuteronomi 8:3; Matteu 4:4) A ń ní àjùmọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lu àwọn ẹlòmíràn, nínú ìdílé àti nínú ìjọ. A nílò ìtọ́sọ́nà rere láti sún wa láti jẹ́ agbéniró. Ní ọ̀nà yìí àwọn ọkọ àti baba ní ipa kan tí ó ṣe pàtàkì láti kó—àní jù bẹ́ẹ̀ lọ bí wọ́n bá jẹ́ alàgbà tàbí ìráńṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ nílò àwọn ànímọ́ kan-náà nígbà tí wọ́n bá ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ lóye kìí ṣe ohun tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ń sọ nìkan ṣugbọn ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ láìsọ pẹ̀lú. Ìyẹn ń bèèrè fún ìmòye, àkókò, àti sùúrù. Ó jẹ́ ìdí kan tí Peteru fi nílàti sọ pé àwọn ọkọ níláti jẹ́ agbatẹnirò kí wọ́n sì bá aya wọn gbé pẹ̀lú òye.—1 Timoteu 3:4, 5, 12; 1 Peteru 3:7.
Àwọn Ewu ti A Ó Yẹra Fún
7, 8. (a) Kí ni a nílò bí ìdílé kan bá níláti yẹra fún ọkọ̀-rírì tẹ̀mí? (b) Kí ni a nílò yàtọ̀ sí ìbẹ̀rẹ̀ rere nínú ipa-ọ̀nà Kristian? (Matteu 24:13)
7 Èéṣe tí fífún ipò-tẹ̀mí ìdílé ní àfiyèsí fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀? Láti ṣàkàwé, a lè béèrè pé, Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí atukọ̀ kan fiyèsí àwòrán-ìrìnnà rẹ̀ kínní-kínní nígbà tí ó bá ń darí ọkọ̀-òkun kan gba ojú-omi tí ó léwu tí ó sì ní àwọn ibi tí kò jìn? Ní August 1992 ọkọ̀-òkun Queen Elizabeth 2 (QE2) ti ń rìnrìn-àjò láti èbúté kan sí òmíràn la àgbègbè kan tí ó ní àgbájọ-yanrìn àti àwọn àpáta tí ó léwu kọjá níbi tí a sọ pe àṣìṣe ìtukọ̀-òkun ti wọ́pọ̀. Ẹnìkan tí ń gbé ládùúgbò sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn awakọ̀-òkun ti pàdánù iṣẹ́ wọn nítorí ṣíṣe àwọn àṣìṣe tí ń fa ìjàm̀bá ní agbègbè yẹn.” Ọkọ̀-òkun QE2 forí sọ àpáta títẹ́ pẹrẹsẹ kan ní ìsàlẹ̀ omi. Ó jásí àṣìṣe tí ń náni lówó gan-an. Ìdámẹ́ta ara ọkọ̀ náà ni ó bàjẹ́, ọkọ̀-òkun náà ni a sì níláti mú kúrò lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn ọ̀sẹ̀ mélòókan fún àtúnṣe.
8 Lọ́nà kan-náà, bi “atukọ̀” ìdílé kò bá fi ìṣọ́ra wo àwòrán-ìrìnnà, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ìdílé rẹ̀ lè fi tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn jìyà ìpalára tẹ̀mí. Fún alàgbà tàbí ìráńṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan, àbájáde náà lè jẹ́ ìpàdánù àwọn àǹfààní nínú ìjọ àti bóyá ìpalára wíwúwo fún àwọn mẹ́ḿbà mìíràn nínú ìdílé. Nítorí naa, Kristian kọ̀ọ̀kan níláti ṣọ́ra kí ìtẹ́lọ́rùn àìbìkítà tẹ̀mí má baà lé e bá, ní gbígbẹ́kẹ̀lé kìkì àwọn àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìtara mo-ti-ṣeé-rí. Nínú ipa-ọ̀nà Kristian wa, kò tó láti wulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́nà rere; ìrìn-àjò náà ni a gbọ́dọ̀ parí lọ́nà tí ó yọrí sí rere.—1 Korinti 9:24-27; 1 Timoteu 1:19.
9. (a) Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe pàtàkì tó? (b) Àwọn ìbéèrè tí ó jẹmọ́rọ̀ wo ni a lè béèrè lọ́wọ́ araawa?
9 Kí á baà lè yẹra fún ibi tí kò jinlẹ̀ tó, àwọn àpáta, àti àgbájọ-yanrìn nípa tẹ̀mí, a níláti máa wá ìsọfúnni titun láti inú “àwòrán-ìrìnnà” wa nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé. A kò lè gbáralé kìkì ìkẹ́kọ̀ọ́ ìpìlẹ̀ tí ó mú wa wá sínú òtítọ́. Okun tẹ̀mí wa sinmi lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́-ìsìn déédéé tí ó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Fún àpẹẹrẹ, bí a ti wá fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ti ìjọ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde yìí gan-an lọ́wọ́, a lè béèrè lọ́wọ́ araawa pe, ‘Emi, tàbí àwa gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ha ti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí níti tòótọ́, ní wíwo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ àti ní ríronú jinlẹ̀ lórí ìfisílò wọn bí? Tàbí àwa ha wulẹ̀ ti fàlà sídìí àwọn ìdáhùn bí? Àbí, àwa ha ti ṣàìnáání kíka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà ṣaájú wíwá sí ìpàdé pàápàá bí?’ Àwọn ìdáhùn aláìlábòsí-ọkàn sí àwọn ìbéèrè wọnyi lè sún wa láti ronú jinlẹ̀ nípa àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ wa kí ó sì ru ìfẹ́-ọkàn láti sunwọ̀n síi dìde—bí ìyẹn bá pọndandan.—Heberu 5:12-14.
10. Èéṣe tí ìwádìí-ara-ẹni-wò fi ṣe pàtàkì?
10 Èéṣe tí irú ìwádìí-ara-ẹni-wò bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì? Nítorí pe a ń gbé nínú ayé kan tí ẹ̀mí Satani ń jọba lé lórí, ayé kan tí ó ń gbìyànjú lọ̀nà àrékérekè láti sojú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun àti àwọn ìlérí rẹ̀ dé. Ó jẹ́ ayé kan tí ó ń fẹ́ láti mú kí ọwọ́ wa dí gan-an débi pe a kò ní ní àkókò láti bójútó àwọn àìní tẹ̀mí mọ́. Nítorí náà a lè béèrè lọ́wọ́ araawa pe, ‘Ìdílé mi ha lágbára nípa tẹ̀mí bí? Èmi gẹ́gẹ́ bí òbí kan ha lágbára tó bí ó ti ṣe yẹ kí n ní tó bí? Àwa gẹ́gẹ́ bí ìdílé ha ń mú ipá tẹ̀mí tí ń sún èrò-inú ṣiṣẹ yẹn tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí a gbékarí òdodo àti ìdúróṣinṣin dàgbà bí?’—Efesu 4:23, 24.
11. Èéṣe tí àwọn ipade Kristian fi ṣàǹfààní nípa tẹ̀mí? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.
11 Ipò-tẹ̀mí wa ni a níláti mú lókun nípasẹ̀ gbogbo ìpàdé tí a ń lọ. Àwọn wákàtí ṣíṣeyebíye wọ̀nyẹn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwe Ìjọ ń ṣèrànwọ́ láti tù wá lára lẹ́yìn àwọn wákàtí gígùn tí a níláti lò ní gbígbìyànjú láti máa báa lọ láti wàláàyè nínú ayé akóguntini ti Satani. Ó ti tunilára tó, fún àpẹẹrẹ, láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí! Èyí ti ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè òye tí ó túbọ̀ dára nípa Jesu, ìgbésí-ayé rẹ̀, àti iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀. A ti fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí, ṣe ìwádìíkiri fúnra-ẹni, tí a sì ti tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun pupọ láti inú àpẹẹrẹ tí Jesu fi lélẹ̀.—Heberu 12:1-3; 1 Peteru 2:21.
12. Báwo ni iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá ṣe ń dán ipò-tẹ̀mí wa wò?
12 Ìdánwò tí ó dára nípa ipò-tẹ̀mí wa ni iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Kí á baà lè máa báa lọ nínú ìjẹ́rìí bí-àṣà àti aláìjẹ́-bí-àṣà wa, níye ìgbà ní ojú ìdágunlá tàbí àwọn ará ìta tí ń ṣàtakò, a nílò ìsúnniṣe tí ó tọ̀nà, ìfẹ́ fún Ọlọrun àti aládùúgbò. Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó gbádùn jíjẹ́ ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀, ìyẹn sì lè ṣẹlẹ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa. Ṣùgbọ́n a níláti rántí pé ìhìnrere náà ni wọ́n ń kọ̀, kìí ṣe àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Jesu sọ pe: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. Ìbáṣepé ẹ̀yin í ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ àwọn tirẹ̀; ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin kìí ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n emi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. . . . Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn ó ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.”—Johannu 15:18-21.
Àwọn Ìṣesí Dún Ketekete Ju Àwọn Ọ̀rọ̀ Lásán Lọ
13. Bawo ni ẹnìkan ṣe lè mú ipò-tẹ̀mí ìdílé kan yìnrìn?
13 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kan bí gbogbo wọn àyàfi ẹnìkan bá bọ̀wọ̀ fún wíwà ní mímọ́ tónítóní àti nigín-nigín inú ilé? Ní ọjọ́ olójò kan, gbogbo wọn ni yóò kíyèsára láti máṣe gbé àbàtà wọnú ilé àyàfi ẹnìkan tí ó jẹ́ onígbàgbé náà. Àwọn ojú-ẹsẹ̀ alábàtà níbi gbogbo fúnni ní ẹ̀rí àìbìkítà ẹni yẹn, ní dídá àfikún iṣẹ́ sílẹ̀ fún àwọn yòókù. Ohun kan-náà ṣeé fisílò fún ipò-tẹ̀mí wa. Kìkì ẹnìkan tí ó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan tàbí onídàágunlá lè kó àbàwọ́n bá orúkọ rere ìdílé náà. Gbogbo ẹni tí ó wà nínú agbo-ilé náà, kìí wulẹ̀ ṣe àwọn òbí, níláti làkàkà láti ṣàgbéyọ ìtẹ̀sí èrò-orí ti Kristi. Ó ti tunilára tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun ní iwájú! Ìtẹ̀sí èrò-orí ti ìdílé yẹn jẹ́ tẹ̀mí (ṣùgbọ́n kìí ṣe ti olódodo ara-ẹni). Àwọn àmì ìdágunlá tẹ̀mí ni kìí sábà wà nínú irú agbo-ilé bẹ́ẹ̀.—Oniwasu 7:16; 1 Peteru 4:1, 2.
14. Àwọn àdánwò ti ara wo ni Satani gbé ka iwájú wa?
14 Gbogbo wa ní àwọn àìní nípa ohun ti ara tí ó jẹ́ kòṣeémánìí tí a níláti bójútó láti gbé ìwàláàyè wa ró lójoojúmọ́. (Matteu 6:11, 30-32) Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ohun tí a ń fẹ́ máa ń ṣíji bo àwọn àìní wa. Fún àpẹẹrẹ, ètò-ìgbékalẹ̀ Satani ń fi onírúurú ohun-èèlò oníná gbogbo lọ̀ wá. Bí a bá ń fi ìgbà gbogbo fẹ́ láti ní eyi tí ó dé kẹ́yìn nínú ohun gbogbo, a kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn láé, níwọ̀n bí èyí tí ó dé kẹ́yìn jùlọ yóò ti di èyí tí kò bóde mu mọ́ láìpẹ́, tí èyí tí ó jẹ́ agánrán yóò sì farahàn. Ayé ìṣòwò ti dá àyípoyípo kan tí kìí dáwọ́ dúró láé sílẹ̀. Ó ń fà wá mọ́ra sínú títúbọ̀ wá owó púpọ̀ sii láti tẹ́ àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sii ṣáá lọ́rùn. Èyí lè ṣamọna sí “wèrè ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tíí panilára,” tàbí “àwọn ìlépa òmùgọ̀ àti eléwu.” Ó lè yọrísí ìgbésí-ayé kan tí kò wàdéédéé pẹ̀lú àkókò fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí ó túbọ̀ ń lọ sílẹ̀.—1 Timoteu 6:9, 10; The Jerusalem Bible.
15. Ni ọ̀nà wo ni àpẹẹrẹ olórí ìdílé gbà ṣe pàtàkì?
15 Níhìn-ín pẹ̀lú, ni àpẹẹrẹ tí olórí agbo-ilé Kristian fi lélẹ̀ tún ti ṣe pàtàkì gan-an. Ìṣarasíhùwà rẹ̀ tí ó wàdéédéé síhà àwọn ẹrù-iṣẹ́ nípa ti ara àti tẹ̀mí níláti ru àwọn mẹ́ḿbà yòókù nínú ìdílé soke. Dájúdájú yóò jẹ́ ohun tí ń panilára bí baba bá fúnni ní àwọn ìtọ́ni aláfẹnusọ tí ó dára ṣùgbọ́n tí ó wá kùnà láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó lè má pẹ́ tí àwọn ọmọ yóò fi rí àṣírí àṣà ṣe-bí-mo-ti-sọ-ṣùgbọ́n-kìí-ṣe-bí-mo-ti-ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, alàgbà kan tàbí ìráńṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan tí ń fún àwọn mìíràn ní ìṣírí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé síbẹ̀ tí ó jẹ́ lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni ó ń darapọ̀ mọ́ ìdílé rẹ̀ nínú ìgbòkègbodò yẹn kò ní pẹ́ pàdánù ìṣeégbàgbọ́, nínú ìdílé àti nínú ijọ.—1 Korinti 15:58; fiwé Matteu 23:3.
16. Àwọn ìbéèrè wo ni a lè béèrè lọ́wọ́ araawa?
16 Fún ìdí èyí, a lè ṣàyẹ̀wò ìgbésí-ayé wa ní ọ̀nà tí ó lérè nínú. Ọwọ́ wa ha dí fún lílé àṣeyọrí ti ayé bá kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ dágunlá sí ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí bí? Àwa ha ń gun àkàbà ìtẹ̀síwájú nínú ayé tí á sì ń jórẹyin nínú ijọ bí? Ẹ rántí ìmọ̀ràn Paulu: “Òdodo ni ọ̀rọ̀ náà. Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà sí ipò-iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́.” (1 Timoteu 3:1, NW) Níní ìmọ̀lára ẹrù-iṣẹ́ nínú ìjọ ń fi ipò-tẹ̀mí wa hàn dáradára ju ìgbéga lẹnu iṣẹ lọ. Ìwàdéédéé tí a fìṣọ́ra ṣe ni a níláti pamọ́ kí á má baà fààyè gba àwọn agbanisíṣẹ́ wa láti máa darí wa bí ẹni pe a yà wá sí mímọ́ fún wọn kìí sìí ṣe fún Jehofa.—Matteu 6:24.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí Ó Nítumọ̀ Ń Gbé Ipò-Tẹ̀mí Ga Síwájú
17. Kí ni ó pakún mímú ìjójúlówó ìfẹ́ nínú ìdílé kan dàgbà?
17 Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ilé lónìí ti di ilé-oorun pátápátá. Báwo? Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ń darí wá sílé kìkì láti sùn kí wọ́n sì jẹun, àti lẹ́yìn náà wọ́n a bẹ́ jáde. Ó ṣọ̀wọ́n kí wọn tó jókòó yí tábìlì kan ká láti gbádùn oúnjẹ papọ̀. Ìmọ̀lára wíwà pẹ́kípẹ́kí nínú ìdílé ti wábi gbà. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wà, kò sí ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ kan dàbí alárà. Iyẹn sì lè yọrísí àìní ọkàn-ìfẹ́ nínú àwọn mẹ́ḿbà yòókù, bóyá àìsí ìdàníyàn tòótọ́ kan. Bí a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnìkínní kejì, a ó wáàyè láti bárasọ̀rọ̀ àti láti tẹ́tísíra. A óò fúnra-ẹni níṣìírí, a ó sì ranra-ẹni lọ́wọ́. Apá ìhà ipò-tẹ̀mí yìí wémọ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó ṣe pàtàkì láàárín àwọn tọkọtaya àti láàárín àwọn òbí àti ọmọ.b Ó béèrè fún àkókò àti ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ bi a ti ń fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnìkínní kejì láti ṣàjọpín ayọ̀, ìrírí, àti àwọn ìṣòro wa.—1 Korinti 13:4-8; Jakọbu 1:19.
18. (a) Kí ni ó sábà máa ń jẹ́ olórí ìdènà fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀? (b) Orí kí ni a kọ́ ipò-ìbátan tí ó nítumọ̀ lé?
18 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rere ń béèrè fún àkókò àti ìsapá. Ó túmọ̀sí yíya àkókò sọ́tọ̀ láti sọ̀rọ̀ àti láti fetísílẹ̀ síra-ẹni. Ọ̀kan lára àwọn ìdíwọ́ títóbi jùlọ fún èyí ni ohun-èèlò ti ń jẹ àkókò yẹn tí ó gba ipò ọlá nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé—tẹlifíṣọ̀n. Èyí gbé ìpèníjà kan kalẹ̀—tẹlifíṣọ̀n ha ń ṣàkóso rẹ, tàbí ìwọ ha ń ṣàkóso rẹ̀ bí? Ṣíṣàkóso tẹlifíṣọ̀n béèrè fún ìpinnu fífẹsẹ̀múlẹ̀—títíkan agbára ìfẹ́-inú náà láti yí i pa. Ṣùgbọ́n ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti yíjú sí ẹnìkínní kejì gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà ìdílé àti gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tẹ̀mí. Àwọn ipò-ìbátan tí ó nítumọ̀ béèrè fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, lílóye ẹnìkínní kejì, àwọn àìní àti ayọ̀ wa, sísọ fún ẹnìkínní kejì bí a ti mọrírì gbogbo ohun onínúure tí a ti ṣe fún wa. Ní èdè mìíràn, ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ó nítumọ̀ fihàn pé a kún fún imoore fún àwọn mìíràn a sì mọrírì wọn.—Owe 31:28, 29.
19, 20. Bí a bá bìkítà fún gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ìdílé, ki ni awa yoo ṣe?
19 Nítorí náà, bí a bá bìkítà fún araawa ẹnìkínní kejì nínú ìgbékalẹ̀ ìdílé—ìyẹn sì kan bíbójútó àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́—àwa yóò máa ṣe ohun púpọ̀ síhà gbígbé ipò-tẹ̀mí wa ró àti pípa á mọ́. Nínú ìgbékalẹ̀ ìdílé, àwa yóò máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn Peteru: “Lákòótán, kí gbogbo yín ṣe onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ máṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin kí ó lè jogún ìbùkún.”—1 Peteru 3:8, 9.
20 A lè ní ìbùkún Jehofa nísinsìnyí bí a bá làkàkà láti pa ipò-tẹ̀mí wa mọ́, èyí sì lè ṣiṣẹ́ síhà jíjogún ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la wa nígbà tí a bá gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí paradise ilẹ̀-ayé. Àwọn nǹkan mìíràn wà tí a lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti ran araawa ẹnìkínní kejì lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò jíròrò àwọn àǹfààní ṣíṣe àwọn nǹkan papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé.—Luku 23:43; Ìfihàn 21:1-4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ipò-tẹ̀mí ni a túmọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ànímọ́ níní ìmọ̀lára tàbí ìfọkànsìn fún àwọn ọ̀pá ìdíyelé ti isin: ànímọ́ tàbí ipò jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Ẹni tẹ̀mí jẹ́ òdìkejì ẹni ti ara, oníwà-bí-ẹranko.—1 Korinti 2:13-16; Galatia 5:16, 25; Jakọbu 3:14, 15; Juda 19.
b Fún àwọn ìdámọ̀ràn síwájú síi lórí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ìdílé, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1991, ojú-ìwé 20 sí 22.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ipò-tẹ̀mí?
◻ Báwo ni olórí ìdílé kan ṣe lè ṣàfarawé àpẹẹrẹ Kristi?
◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún àwọn ohun tí ó lè wu ipò-tẹ̀mí wa léwu?
◻ Kí ni ó lè mú ipò-tẹ̀mí ìdílé kan yìnrìn?
◻ Èéṣe tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó nítumọ̀ fi ṣe pàtàkì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pípésẹ̀ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ń fun ìdílé wa lókun nípa tẹ̀mí