Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀
Gẹ́gẹ́ Bí Henryk Dornik Ṣe Sọ Ọ́
ỌDÚN 1926 ni wọ́n bí mi. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré làwọn òbí mi. Ìlú Ruda Slaska ni wọ́n ń gbé nígbà yẹn. Ó jẹ́ ìlú kan tí wọ́n ti máa ń wa kùsà nítòsí ìlú Katowice, ní gúùsù ilẹ̀ Poland. Wọ́n kọ́ àwa ọmọ wọn, ìyẹn èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Bernard, àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì, tórúkọ wọn ń jẹ́ Róża àti Edyta, pé ká máa gbàdúrà, ká máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ká sì máa ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Ìdílé Wa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Nínú oṣù January ọdún 1937, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, bàbá mi dé láti ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ kan tayọ̀tayọ̀. Ó mú ìwé kan tó tóbi dání, èyí tó gbà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá sọ pé, “Ẹyin ọmọ, ẹ wá wo ohun tó wà lọ́wọ́ mi yìí, Ìwé Mímọ́ ni!” Mi ò rí Bíbélì rí ṣáájú ìgbà yẹn.
Ọjọ́ pẹ́ tí Ìjọ Kátólíìkì ti ń jẹgàba lórí àwọn èèyàn ìlú Ruda Slaska àti àgbègbè rẹ̀. Àwọn àlùfáà máa ń bá àwọn tó ni ibi ìwakùsà náà ṣọ̀rẹ́ gan-an wọ́n sì fẹ́ káwọn awakùsà náà àtàwọn ìyàwó wọn máa ṣe gbogbo ohun táwọn bá ti sọ fún wọn. Bí awakùsà kan kò bá wá sí Máàsì ní ṣọ́ọ̀ṣì tàbí tó kọ̀ láti lọ ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, aláìgbàgbọ́ ni wọ́n máa kà á sí, wọ́n á sì sọ pé lílé làwọ́n máa lé e kúrò níbi ìwakùsà náà. Kò pẹ́ tí bàbá mi fi bá ara rẹ̀ nínú irú ipò yìí nítorí pé ó lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí àlùfáà kan wá sílé wa, ojú gbogbo wa báyìí ni bàbá mi ṣe sọ fún un pé alágàbàgebè ni. Ojú ti àlùfáà yìí gan-an, àmọ́ nítorí pé kò fẹ́ wàhálà mọ́, wọn ò lé bàbá mi kúrò níbi ìwakùsà náà.
Níwọ̀n bó ti ṣojú mi nígbà tí bàbá mi ko àlùfáà yẹn lójú, èyí mú kí n túbọ̀ dúró lórí ìpinnu mi pé mo fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Díẹ̀díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, mo sì wá sún mọ́ ọn gan-an. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá mi bá àlùfáà yẹn sọ̀rọ̀ la lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe Ìrántí ikú Kristi. Igbà yẹn ni wọ́n fi bàbá mi han àwọn èèyàn tó tó ọgbọ̀n, tí wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Jónádábù kan nìyí.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo wá mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń pè ní “Jónádábù” làwọn tó nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, àti pé ńṣe ni iye wọn yóò máa pọ̀ sí i.a—2 Àwọn Ọba 10:15-17.
“Ọ̀dọ́mọkùnrin, Ǹjẹ́ O Mọ Ìtúmọ̀ Ìrìbọmi?”
Lẹ́yìn tí bàbá mi di olùjọ́sìn Jèhófà, kò mutí mọ́, ó sì di ọkọ rere àti bàbá dáadáa. Síbẹ̀, màmá mi kò fara mọ́ ẹ̀sìn tó ń ṣe yìí, yóò sì máa sọ nígbà yẹn pé ó tẹ́ òun lọ́rùn kí bàbá mi ṣì jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kò sì máa hu ìwà tó ń hù tẹ́lẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, ó ṣàkíyèsí pé àwọn àlùfáà kan náà tó ń gbàdúrà pé kí ilẹ̀ Poland ṣẹ́gun àwọn ará Jámánì tó gbógun wá náà ló tún ń gbàdúrà ìdúpẹ́ nígbà tí Hitler bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun! Nígbà tó di ọdún 1941, màmá wa dara pọ̀ mọ́ àwa tó kù nínú ìjọsìn Jèhófà.
Ṣáájú ìgbà yẹn ni mo ti sọ pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run àmọ́ àwọn alàgbà ìjọ wa rò pé mo ṣì kéré. Wọ́n ní kí n ní sùúrù díẹ̀ sí i. Àmọ́ nígbà tó di ọjọ́ kẹwàá oṣù December ọdún 1940, arákùnrin Konrad Grabowy, (tó ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú nínu àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́) fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò nínú ilé kékeré kan láìjẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Ó béèrè ìbéèrè márùn-ún lọ́wọ́ mi, nígbà tó sì rí i pé àwọn ìdáhùn náà tẹ́ òun lọ́rùn, ló bá ṣèrìbọmi fún mi. Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó bi mí ni, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, ǹjẹ́ o mọ ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí?” Ìbéèrè mìíràn ni, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ní báyìí tí ogun ń lọ lọ́wọ́, láìpẹ́ láìjìnnà, wàá pinnu bóyá Hitler lo máa tì lẹ́yìn àbí Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe kí ìpinnu rẹ mú kó o pàdánù ẹ̀mí rẹ.” Kíá ni mo dáhùn pé, “bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀.”
Inúnibíni Bẹ̀rẹ̀
Kí nìdí tí arákùnrin Konrad Grabowy fi béèrè àwọn ìbéèrè tó ṣe tààràtà yìí? Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì ti gbógun wọ ilẹ̀ Poland lọ́dún 1939, a sì rí àdánwò tó le gan-an lẹ́yìn náà nítorí ìgbàgbọ́ wa àti nítorí pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ojoojúmọ́ ni ẹ̀rù túbọ̀ ń bà wá bá a ti ń gbọ́ pé wọ́n ń mú àwọn arákùnrin wa àtàwọn arábìnrin wa, pé wọ́n ń lé wọn jáde nílùú, pé wọ́n sì ń sọ wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí sáwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. A mọ̀ pé kò ní pẹ́ táwa náà á fi rí irú àwọn àdánwò yìí.
Gbogbo ọ̀dọ́ ni Ìjọba Násì fẹ sọ di alátìlẹyìn Ìjọba Hitler, títí kan èmi àtàwọn ọmọ ìyá mi. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá mi àti màmá mi ti kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Volkslist (ìwé tí orúkọ gbogbo àwọn tó ti gbà láti di ọmọ ilẹ̀ Jámánì tàbí tó fẹ́ di ọmọ ilẹ̀ Jámánì wà nínú rẹ̀), wọ́n gba àwa ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn. Wọ́n sọ bàbá mi sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Auschwitz. Lóṣù February ọdún 1944, wọ́n mú èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ aláìgbọràn tó wà nílùú Grodków, (Grottkau), nítòsí Odò Nysa, wọ́n sì kó àwọn àbúrò mi obìnrin lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó jẹ́ tàwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, èyí tó wà ní Czarnowąsy (Klosterbrück) nítòsí ìlú Opole. Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè jáwọ́ nínú ohun táwọn aláṣẹ pè ní “èrò tó ń ṣini lọ́nà táwọn òbí wa ní.” Ó wá ku màmá wa nìkan sílé.
Láràárọ̀, nínú àgbàlá ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ aláìgbọràn yẹn, wọ́n á ta àsíá, wọ́n á sì pàṣẹ pé ká gbé ọwọ́ ọ̀tún wa sókè ká sì kí àsíá, ká sì máa sọ pé “Ti Hitler Ni Ìgbàlà.” Èyí dán ìgbàgbọ́ wa wò gan-an, àmọ́ èmi àti Bernard kọ̀ láti ṣe ohun tó ta ko ìgbàgbọ́ wa. Nípa báyìí, wọ́n nà wá bí ẹní máa kú, wọ́n ní aláfojúdi ni wá. Gbogbo ohun tí wọ́n tún ṣe lẹ́yìn ìgbà yẹn láti mu wa ṣe ohun tí a kò fẹ́ ṣe, ló já sí pàbó. Èyí ló mú káwọn ọmọ ogun Násì sọ fún wa pé ká mú ọ̀kan nínú ohun méjì táwọn á là sílẹ̀ fún wa. Wọ́n ní: “Yálà kẹ́ ẹ fọwọ́ síwèé pé alátìlẹyìn Ìjọba Ilẹ̀ Jámánì ni yín kẹ́ ẹ sì dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì, ìyẹn Wehrmacht, tàbí ká kó o yín lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.”
Lóṣù August ọdún 1944, nígbà táwọn aláṣẹ wá sọ pé kí wọ́n máa kó wa lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n ní: “Kò sọ́gbọ́n tá a lè fi yí wọn lọ́kàn padà láti ṣe ohunkóhun. Ńṣe ni inú wọn máa ń dùn láti kú nítorí ẹ̀sìn wọn. Ìwà ọ̀tẹ̀ wọn lè ran gbogbo àwọn tó wà nílé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ aláìgbọràn yìí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù mí láti kú nítorí ẹ̀sìn, mo láyọ̀ láti fara da ìyà láìbẹ̀rù, ojú kò sì tì mí, nítorí pé mo jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Ìṣe 5:41) Tá a bá fi dá agbára tèmi nìkan, kò ṣeé ṣe rárá láti fara da ohun tójú mi rí lẹ́yìn ìgbà náà. Àmọ́ gbígbàdúrà látọkànwá jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì fi hàn pé Olùrànlọ́wọ́ tó ṣeé gbára lé lòun.—Hébérù 13:6.
Ohun Tójú Mi Rí Nínú Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
Kò pẹ́ tí wọ́n fi mú mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Gross-Rosen, èyí tó wà lágbègbè Silesia. Wọ́n fún mi ní nọ́ńbà ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì tún rán àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò mọ́ aṣọ mi, láti fi hàn pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Àwọn ọmọ ogun náà wá fi ohun kan lọ̀ mí. Wọ́n ní àwọn á dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, kódà mo lè di ọ̀gá nínú ẹgbẹ́ ológun Ìjọba Násì tí mo bá ti lè ṣe ohun kan. Wọ́n ní: “O gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tó ta ko Ìjọba Hitler.” Wọn ò firú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù o. Kìkì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fún láǹfààní láti jáde kúrò nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Síbẹ̀, bíi ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kù, mo kọ̀ jálẹ̀ láti gba ohun tí wọ́n pè ní àǹfààní yìí. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà wá fèsì, wọ́n ní: “Wo ihò èéfín ibi tí wọ́n ti ń sun òkú àwọn èèyàn yẹn dáadáa. Ronú lórí ohun tá a fi lọ̀ ẹ́ dáadáa, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú ihò èéfín yẹn ni wàá ti rí òmìnira rẹ gbà padà.” Mo tún kọ̀ jálẹ̀, mo sì rí i pé lákòókò yẹn, mo ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6, 7.
Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè rí àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi nínú àgọ́ náà, ó sì jẹ́ kí n rí wọn. Lára àwọn Kristẹni tí mo rí ni arákùnrin kan tó jẹ́ adúróṣinṣin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gustaw Baumert, ó tọ́jú mi dáadáa ó sì fìfẹ́ hàn sí mi gan-an. Ó dá mi lójú gbangba pé, Jèhófà fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó sún mọ́ tòsí mú káwọn ọmọ ogun Násì sá kúrò nínú àgọ́ náà ní tipátipá. Bá a ti ń múra láti jáde kúrò nínú àgọ́ náà, àwa arákùnrin fi ẹ̀mí ara wa wewu, a pinnu láti lọ sí bárékè tí wọ́n kó àwọn obìnrin sí, ká sì lọ wo báwọn arábìnrin wa, tí iye wọn ń lọ sí bí ogún, ṣe ń ṣe sí níbẹ̀. Lára àwọn arábìnrin wọ̀nyí ni Elsa Abt àti Gertrud Ott wà.b Bí wọ́n ti rí wa, kíá ni wọ́n sáré wá bá wa, lẹ́yìn tá a sì ti jọ fún ara wa níṣìírí, wọ́n kọ orin Ìjọba Ọlọ́run. Lára àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà ni: “Ẹni bá ṣòótọ́, tó duro ṣinṣin, ki yoo fọkàn rẹ̀ fẹ́rù.”c Kò sẹ́ni tómi kò bọ́ lójú rẹ̀ nínú gbogbo wa!
A Bá Ara Wa Ní Àgọ́ Mìíràn
Àwọn ọmọ ogun Násì kó àwa ẹlẹ́wọ̀n tá a tó ọgọ́rùn-ún sí àádọ́jọ sínú ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n fi ń kó èédú, kò sí oúnjẹ kò sí omi, a sì rìnrìn àjò nínú yìnyín àti òjò tó ń mú otútù gan-an. Òùngbẹ gbẹ kísà sí wa lára bẹ́ẹ̀ ni àrùn ibà fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa. Báwọn ẹlẹ́wọ̀n tára wọn ò yá àtàwọn tí kò ní ìmí nínú mọ́ ti ń dìgbò lulẹ̀ tí wọ́n sì ń kú, ní wọ́n ń kó wọn jáde tí ọkọ̀ ojú irin náà sì túbọ̀ ń láyè sí i. Ẹsẹ̀ mi méjèèjì àtàwọn oríkèé ara mi wú débi pé mi ò lè dìde dúró. Lẹ́yìn tá a ti wà lẹ́nu ìrìn àjò náà fún ọjọ́ mẹ́wàá, ìwọ̀nba àwa ẹlẹ́wọ̀n tá a ṣẹ́ kù dé sí àgọ́ ìfìyàjẹni ti Mittelbau-Dora, tó wà nílùú Nordhausen, nítòsí ìlú Thuringia. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé kò sí ọ̀kankan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kú nínú ìrìn àjò burúkú yẹn.
Bí ara mi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀ sípò látinú wàhálà ìrìn àjò yẹn ni àìsàn ìgbẹ́ ọ̀rìn tún bẹ́ sílẹ̀ nínú àgọ́ náà, àwọn arákùnrin kan àtèmi náà sì kó àìsàn yìí. Wọ́n sọ fún wa pé ká má ṣe jẹ ọbẹ̀ tí wọ́n ń fún wa nínú ọgbà náà mọ́, pé búrẹ́dì tí wọ́n yan gbẹ nìkan ni ká máa jẹ. Mo ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì pẹ́ tára mi fi yá. Lóṣù March ọdún 1945, a gbọ́ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ọdún náà ni Mátíù 28:19, tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Èyí fi hàn wá gbangba pé géètì àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kò ní pẹ́ ṣí sílẹ̀, a ó sì máa wàásù ìhìn rere náà nìṣó! Èyí fún wa láyọ̀ gan-an ó sì tún jẹ́ ká nírètí, nítorí èrò wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni pé Amágẹ́dọ́nì ló máa kádìí Ogun Àgbáyé Kejì. Ọ̀nà àgbàyanu gbáà ni Jèhófà fi fún wa lókun lákòókò tí nǹkan nira gan-an yẹn!
Wọ́n Dá Wa Sílẹ̀ Láwọn Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
Lọ́jọ́ kìíní oṣù April, ọdún 1945, àwọn ọmọ ogun Olùgbèjà ju bọ́ǹbù sí bárékè àwọn ọmọ ogun Násì àti ọgbà ẹ̀wọ̀n tiwa tí kò jìnnà síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kú táwọn mìíràn sì fara pa gan-an. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò bọ́ǹbù lù wá, bí èyí sì ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ni bọ́ǹbù kan tó bú lọ́nà tó lágbára sọ mí sókè.
Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Fritz Ulrich ló wá ràn mí lọ́wọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá inú àwọn òkìtì pàǹtírí, pẹ̀lú ìrètí pé mi ò tíì kú. Níkẹyìn, ó rí mi ó sì wọ́ mi jáde lábẹ́ àwọn àwókù náà. Nígbà tí mo ta jí, mo rí i pé mo fi gbogbo ojú àti gbogbo ara ṣèṣe gan-an, etí mi ò sì gbọ́ràn mọ́. Ariwo ńlá tó wá látinú bọ́ǹbù yẹn ti ṣe jàǹbá fún etí mi. Ọ̀pọ̀ ọdún ni etí mi méjèèjì fi yọ mí lẹ́nu gan-an kó tó dì pé wọ́n san.
Láàárín ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹlẹ́wọ̀n, àwa díẹ̀ péré la ṣẹ́ kù tí bọ́ǹbù kò pa. Díẹ̀ lára àwọn arákùnrin wa kú, arákùnrin Gustaw Baumert tí mo fẹ́ràn gan-an yẹn sì wà lára wọn. Kòkòrò wọ egbò mi, àrùn ibà tó lágbára sì tún kọ lù mí. Àmọ́ kò pẹ́ táwọn ọmọ ogun Olùgbèjà fi rí wa tí wọ́n sì dá wa sílẹ̀. Ṣùgbọ́n òkú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹrà mú kí àrùn ibà jẹ̀funjẹ̀fun bẹ́ sílẹ̀, ó sì kọ lu èmi náà. Wọ́n kó èmi àtàwọn mìíràn tára wa ò yá lọ sílé ìwòsàn kan. Pẹ̀lú gbogbo báwọn dókítà ṣe sapá gidigidi tó, àwa mẹ́ta péré ni kò kú. Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi lókun láti lè jẹ́ olóòótọ́ láwọn àkókò tó burú jáì yẹn. Mo tún dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà yọ mí nínú “ibú òjìji” ikú.—Sáàmù 23:4.
Mo Padà Sílé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
Lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Jámánì ti juwọ́ sílẹ̀, èrò mi ni pé màá tètè padà sílé kíákíá, àmọ́ èyí ṣòro ju bí mo ṣe rò lọ. Àwọn kan tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n rí, tí wọ́n sì jẹ́ ara ẹgbẹ́ kan nínú ìjọ Kátólíìkì rí mi, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Ẹ pà á!” Wọ́n tì mí lulẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn kọjá lórí mi. Ọkùnrin kan ló sáré wá tó sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà burúkú tí wọ́n fi ń jẹ mí, ṣùgbọ́n ó pẹ́ kí n tó gbádùn padà, torí pé wọ́n ṣe mí léṣe gan-an, mi ò sì tíì gbádùn tán látinú àìsàn ibà jẹ̀funjẹ̀fun tó kọ lù mí tẹ́lẹ̀. Àmọ́ níkẹyìn, ó ṣeé ṣe fún mi láti padà sílé. Inú mi dùn gan-an pé mo tún lè wà pẹ̀lú ìdílé mi padà! Gbogbo wọn ni inú wọn dùn gidigidi nígbà tí wọ́n rí mi, nítorí èrò wọn ni pé mo ti kú.
Kò pẹ́ tá a fi tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù padà, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ mọ òtítọ́ fara mọ́ ohun tí à ń kọ́ wọn. Wọ́n fún mi ní iṣẹ́ kíkó àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ sáwọn ìjọ. Èmi àtàwọn arákùnrin mìíràn sì láǹfààní láti bá àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ilẹ̀ Jámánì ṣèpàdé nílùú Weimar, àtibẹ̀ la sì ti kó àwọn Ilé Ìṣọ́ tó kọ́kọ́ jáde pàá lẹ́yìn ogun wá sórílẹ̀-èdè Poland. Kíákíá la túmọ̀ wọn, tá a ṣe ohun ìtẹ̀wé tí wọ́n ń pè ní stencil, tá a sì tẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀dà. Nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Lodz wá ń bójú tó gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ní gbogbo ilẹ̀ Poland, àwọn ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìwé tá a fi ń ṣàlàyé Bíbélì gbà déédéé. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, tàbí ajíhìnrere tó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò wàásù, mo sì ń wàásù ní gbogbo ìpínlẹ̀ Silesia tó gbòòrò gan-an, tí ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ jẹ́ apá kan ilẹ̀ Poland nígbà yẹn lọ́hùn-ún.
Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, ìjọba Kọ́múníìsì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nílẹ̀ Poland ló ń ṣenúnibíni náà. Nítorí pé mo kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ìṣèlú, wọ́n ní kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì lọ́dún 1948. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo ran ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn lọ́wọ́ láti dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run. Ọ̀kan lára wọn tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi.
Lọ́dún 1952, wọ́n tún sọ mí sẹ́wọ̀n, ẹ̀sùn pé mò ń ṣamí fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n sì fi kàn mí lọ́tẹ̀ yìí! Nígbà ti mò ń dúró de ìgbẹ́jọ́ mi, wọ́n jù mí sínú àhámọ́ aládàáwà, tọ̀sántòru ni wọ́n sì máa ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò. Àmọ́, Jèhófà tún yọ mí lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣenúnibíni sí mi, mi ò sì jẹ irú ìyà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́ láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e.
Ohun Tó Jẹ́ Kí N Lè Ní Ìfaradà
Tí mo bá ronú nípa gbogbo ọdún tí mo fi rí ọ̀pọ̀ àdánwò àti gbogbo ìnira yẹn, mo lè sọ àwọn ohun pàtàkì kan to fún mi níṣìírí. Àkọ́kọ́, àtọ̀dọ̀ Jèhófà, àti láti inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ni mo ti rí okun tó jẹ́ kí n lè ní ìfaradà. Gbígbàdúrà lóòrèkóòrè látọkànwá sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́ ran èmi àtàwọn mìíràn lọ́wọ́, kò jẹ́ ká sẹ́ ìgbàgbọ́ wa. Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n fọwọ́ dà kọ tún jẹ́ ká rí oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò gan-an. Nígbà tí mo wà láwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn, àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi tí wọ́n bìkítà nípa mi fún mi níṣìírí gan-an, wọ́n sì ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́.
Ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà tún gbà bù kún mi ni ìyàwó tí mo fẹ́, ìyẹn Maria. Oṣù October ọdún 1950 la ṣègbéyàwó, a sì bí ọmọbìnrin kan lẹ́yìn náà. Halina lorúkọ tá a sọ ọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an bó ti ń dàgbà, ó sì ń sìn ín. Ọdún márùndínlógójì lèmi àti Maria fi jọ ṣe tọkọtaya kó tó dì pé ó kú lẹ́yìn tó ti ṣàìsàn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ikú rẹ̀ bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dà bíi pé “a gbé [mi] ṣánlẹ̀” fúngbà díẹ̀, “a kò pa [mí] run.” (2 Kọ́ríńtì 4:9) Láwọn àkókò tó le gan-an yẹn, ọmọ mi, ọkọ rẹ̀, àtàwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ ọmọ mi, tí gbogbo wọn ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, jẹ́ ìtùnú fún mi.
Láti ọdún 1990 ni mo ti ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Poland. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún mi pé lójoojúmọ́ ni mò ń wà pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn àtàtà. Nígbà míì, ara mi tó ti ń dara àgbà máa ń mú kí n dà bí ẹyẹ idì tí kò lè fò dáadáa mọ́. Síbẹ̀, ọkàn mi balẹ̀ bí mo ti ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, mo sì ń “kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti bá mi lò lọ́nà tí ń mú èrè wá” títí di oní olónìí. (Sáàmù 13:6) Mò ń dúró de ìgbà tí Jèhófà, Olùrànlọ́wọ́ mi, yóò mú gbogbo aburú tó ti ṣẹlẹ̀ kúrò, ìyẹn aburú tó wá látinú ìṣàkóso Sátánì tó kún fún ìnira.
[Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Wo ìtàn ìgbésí ayé arábìnrin Elsa Abt nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 1980, ojú ìwé 12 sí 15.
c Orin 101 ni orin yìí nínú ìwé orin ọdún 1928 tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Àwọn Orin Ìyìn Sí Jèhófà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Orin 56 ló jẹ́ nínú ìwé orin tí à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nọ́ńbà àti àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò tí wọ́n fún mi nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nìyí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èmi àti Maria aya mi lọ́dún 1980