Àyà Ò Fò Wá Torí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa
Gẹ́gẹ́ bí Egyptia Petrides Ṣe Sọ Ọ́
Lọ́dún 1972, gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí tó wà jákèjádò orílẹ̀-èdè Kípírọ́sì kóra jọ sílùú Nicosia láti gbọ́ àkànṣe àsọyé látẹnu Arákùnrin Nathan H. Knorr tó ti ń fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe kòkáárí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ojú ẹsẹ̀ ló dá mi mọ̀, kí n sì tó dárúkọ mi fún un, ó bi mí pé: “Ṣó ò ń gbúròó àwọn ará Íjíbítì?” Ogún ọdún rèé tí mo ti pàdé Arákùnrin Knorr ní ìlú mi, ìyẹn Alẹkisáńdíríà lorílẹ̀-èdè Íjíbítì.
WỌ́N bí mi ní January 23, ọdún 1914 nílùú Alẹkisáńdíríà, èmi sì ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́rin táwọn òbí wa bí. Ibi tá a dàgbà sí ò jìnnà sétí òkun. Nígbà yẹn, ìlú Alẹkisáńdíríà jẹ́ ìlú ẹlẹ́wà táwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè ń gbé, ó sì lókìkí nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́lé níbẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ pé ó ti pẹ́ tó ti wà nínú ìtàn. Nítorí pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn Lárúbáwá ti wọnú ara wọn níbẹ̀, ó rọrùn fáwa ọmọ kéékèèké láti gbọ́ èdè Lárúbáwá, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àti èdè Ítálì, a sì tún gbọ́ èdè wa, ìyẹn èdè Gíríìkì.
Lẹ́yìn tí mo jáde nílé ìwé, mo ríṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ aránṣọ ọmọ ilẹ̀ Faransé kan. Mo gbádùn kí n máa faṣọ rírán dárà, mo sì máa ń rán àwọn aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ táwọn sàràkí obìnrin máa ń lò láwọn ayẹyẹ pàtàkì. Mi ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré, mo sì nífẹ̀ẹ́ sí kíka Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ló yé mi nínú ohun tí mò ń kà. Àárín ọdún 1934 sí ọdún 1937 ni gbogbo ohun tí mo sọ yìí ṣẹlẹ̀.
Àárín àkókò yẹn ni mo pàdé arẹwà ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Kípírọ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Theodotos Petrides. Ó jẹ́ ẹnì kan tó mọ ìjàkadì jà dáadáa, àmọ́ ó tún mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe oríṣiríṣi ìpápánu, ó sì ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ìpápánu kan tó lókìkí. Ìfẹ́ mi wá kó sí Theodotos lórí, lémi èèyàn kúkúrú pẹ̀lú irun dúdú lórí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń kọ orin ìfẹ́ àwọn ará Gíríìsì fún mi láti ìsàlẹ̀ tí màá sì máa gbọ́ ohùn rẹ̀ látojú fèrèsé. Nígbà tó sì wá di ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹfà, ọdún 1940, a ṣègbéyàwó. Mo gbádùn àwọn àkókò yẹn gan-an ni. Ibì kan náà làwa àti màmá mi ń gbé, àwọn ń gbé òkè àwa sì ń gbé nísàlẹ̀ wọn gan-an. Nígbà tó di ọdún 1941, a bí John àkọ́bí wa.
Bá A Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Àwọn ìgbà kan wà tí ìsìn wa ò tẹ́ Theodotos ọkọ mi lọ́rùn mọ́, ó sì máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa Bíbélì. Àṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, témi ò sì mọ̀. Lọ́jọ́ kan témi àti ọmọ wa jòjòló wà nílé, obìnrin kan wá kanlẹ̀kùn wa, ó sì fún mi ní káàdì kékeré kan tí wọ́n fi wàásù nípa Bíbélì. Kò má bàa dà bíi pé mi ò kà á sí, mo gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, mo sì kà á. Ó wá fún mi láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Ó yà mí lẹ́nu pé irú àwọn ìwé yẹn gan-an ni ọkọ mi ti mú wálé tẹ́lẹ̀.
Mo sọ fún obìnrin náà pé: “Mo láwọn ìwé yìí kẹ̀ẹ. Jọ̀wọ́ wọlé wá.” Eleni Nicolaou lórúkọ obìnrin Ẹlẹ́rìí yẹn, ojú ẹsẹ̀ ni mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó. Ó sì fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè mi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. Ó dùn mọ́ mi gan-an ni. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, òye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi. Láàárín kan, a dá ìjíròrò wa dúró díẹ̀, Eleni rí ọ̀kan lára àwọn fọ́tò ọkọ mi. Ló bá dédé sọ pé: “Mo mọ arákùnrin yìí!” Mo wá mọ ohun tí ọkọ mi ti ń ṣe látọjọ́ yìí, ó yà mí lẹ́nu gan-an ni. Ìyẹn ni pé ọkọ mi ti ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn mi, láìsì bùn mí gbọ́! Nígbà tó dé lọ́jọ́ yẹn, mo sọ fún un pé: “Ibi tó o lọ lọ́jọ́ Sunday tó kọjá yẹn, màá bá ẹ débẹ̀ lọ́sẹ̀ yìí!”
Nípàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ, mo ráwọn èèyàn bíi mẹ́wàá tó ń jíròrò ìwé Míkà nínú Bíbélì. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ pátá ló wọ̀ mí lọ́kàn! Látìgbà yẹn ni Arákùnrin George Petraki àti ìyàwó rẹ̀ Katerini ti máa ń wá sílé wa ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ Friday láti wá kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bàbá mi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin méjèèjì ta ko ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ wa, ṣùgbọ́n àbúrò mi obìnrin ò janpata ní tiẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pàpà di Ẹlẹ́rìí. Àmọ́, màmá wa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní tiwọn. Lọ́dún 1942, èmi, ọkọ mi àti màmá mi ṣèrìbọmi nínú òkun nílùú Alẹkisáńdíríà láti fi hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà.
Nǹkan Dojú Rú fún Wa
Lọ́dún 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi gbóná janjan. Kété lẹ́yìn ọdún 1940, Ọ̀gágun Erwin Rommel ọmọ ilẹ̀ Jámánì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sí tòsí ìlú El Alamein, àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì kún ìlú Alẹkisáńdíríà. A kó ọ̀pọ̀ oúnjẹ pa mọ́ sílé. Ilé iṣẹ́ tí ọkọ mi ń bá ṣiṣẹ́ wá ní kó lọ máa bójú tó ṣọ́ọ̀bù ìpápánu tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílùú Port Taufiq lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú Suez, bá a ṣe kó lọ síbẹ̀ nìyẹn. Àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n gbọ́ èdè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí í wá wa kiri nílùú Port Taufiq. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ àdírẹ́sì ibi tá à ń gbé, wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé títí wọ́n fi wá wa kàn.
Nígbà tá a wà nílùú Port Taufiq, a kọ́ Stavros Kypraios àti ìyàwó rẹ̀ Giula àtàwọn ọmọ wọn méjì tó ń jẹ́ Totos àti Georgia lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì di ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Stavros máa ń gbádùn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ ọ gan-an débi pé ó máa ń yí ọwọ́ gbogbo aago tó wà nílé rẹ̀ padà sẹ́yìn fún wákàtí kan kí ọkọ̀ tó máa rìn kẹ́yìn lọ́jọ́ náà bàa lè já wa sílẹ̀ ká lè lo àkókò tó pọ̀ sí i lọ́dọ̀ rẹ̀. Bá a ṣe máa bá ìjíròrò wa wọ ọ̀gànjọ́ òru nìyẹn.
Ọdún kan àbọ̀ la lò ní ìlú Port Taufiq ká tó padà sílùú Alẹkisáńdíríà torí ara màmá mi tí kò yá. Màmá mi ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà títí dọjọ́ ikú wọn lọ́dún 1947. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí bí Jèhófà ṣe ń fún wa níṣìírí nípa bá a ṣe ń bá àwọn ará tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́ pọ̀. A tún láǹfààní láti máa gba àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ ibi tí wọ́n yàn wọ́n sí lálejò láwọn ìgbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ bá dúró fúngbà díẹ̀ nílùú Alẹkisáńdíríà.
Àwọn Ohun Tó Dùn Mọ́ Wa Àtàwọn Ohun Tó Dùn Wá
Lọ́dún 1952, mo bí ọmọkùnrin wa kejì, a sọ orúkọ rẹ̀ ní James. Gẹ́gẹ́ bí òbí, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì púpọ̀ láti tọ́ àwọn ọmọ wa nínú ilé tí wọn ò ti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìjọsìn mímọ́. Ìdí nìyẹn tá a fi yọ̀ǹda pé káwọn ará máa ṣèpàdé nílé wa, ọ̀pọ̀ ìgbà la sì máa ń gba àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lálejò. Èyí ló mú kí àkọ́bí wa, ìyẹn John nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, bó sì ṣe lé lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ń lọ sílé ẹ̀kọ́ ìrọ̀lẹ́ kó lè parí ilé ìwé rẹ̀.
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni àyẹ̀wò fi hàn pé ọkọ mi lárùn ọkàn, wọ́n sì ní kó má ṣe irú iṣẹ́ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Ọmọ ọdún mẹ́rin péré ni James ọmọ wa nígbà yẹn. Kí la wá máa ṣe? A mọ̀ pé Jèhófà ṣáà ti ṣèlérí fún wa pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ.” (Aísá. 41:10) Ẹ wo bó ti yà wá lẹ́nu tó, tó sì dùn mọ́ wa nínú tó lọ́dún 1956 tí wọ́n ní ká lọ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà nílùú Ismailia nítòsí Ipadò Suez! Fún ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, nǹkan ò fara rọ lórílẹ̀-èdè Íjíbítì, àwọn ará tó wà níbẹ̀ sì nílò ìṣírí gan-an.
Ó di dandan fún wa láti kúrò lórílẹ̀-èdè Íjíbítì lọ́dún 1960, kódà báàgì aṣọ kan ṣoṣo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gbé. A kó lọ sí orílẹ̀-èdè ọkọ mi ní erékùṣù Kípírọ́sì. Ní gbogbo àkókò yìí, ara ọkọ mi ò yá mọ́ rárá, kò sì lè ṣiṣẹ́ kankan. Àmọ́, arákùnrin onínúure kan àti ìyàwó rẹ̀ fún wa láyè nínú ilé wọn. Ó dùn mí gan-an ni pé ọkọ mi kú lọ́dún méjì lẹ́yìn náà, ìtọ́jú James ọmọ wa kékeré wá dọwọ́ èmi nìkan. John ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ti níyàwó ó sì ní ìdílé tiẹ̀ náà tó ń bójú tó, òun pẹ̀lú sì ti kó wá sí orílẹ̀-èdè Kípírọ́sì.
Bá A Ṣe Rí Ìtọ́jú Nígbà Tí Nǹkan Le
Arákùnrin Stavros Kairis àti Arábìnrin Dora ìyàwó ẹ̀ bá sọ pé ká wá máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Ńṣe ni mo kúnlẹ̀ tí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó tún ṣe pèsè ọ̀nà àbáyọ fún wa lọ́tẹ̀ yìí. (Sm. 145:16) Nígbà tí Stavros àti Dora pinnu láti ta ilé wọn kí wọ́n sì kọ́ tuntun tó máa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nísàlẹ̀, wọ́n kọ́ yàrá kékeré méjì fún èmi àti James náà.
Nígbà tí James náà dàgbà, ó gbéyàwó, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà títí dìgbà tí wọ́n bí àkọ́kọ́ nínú ọmọ mẹ́rin tí wọ́n bí. Lọ́dún 1974, ìyẹn ọdún méjì lẹ́yìn àbẹ̀wò mánigbàgbé Arákùnrin Knorr, ọ̀rọ̀ òṣèlú dá rògbòdìyàn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kípírọ́sì.a Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí, ló filé àtọ̀nà sílẹ̀, wọ́n sì padà sí ẹsẹ àárọ̀ níbi tí wọ́n sá lọ. Ọmọ mi John náà wà lára wọn. Orílẹ̀-èdè Kánádà ló kó ìyàwó àtọmọ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló kó lọ, inú wa dùn láti rí bí iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Kípírọ́sì.
Mo wá láǹfààní láti wàásù dáadáa nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba owó ìfẹ̀yìntì lóṣooṣù. Àmọ́ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, àrùn rọpárọsẹ̀ ṣe bí ẹní kọ lù mí, ni mo bá kó lọ sọ́dọ̀ James ọmọ mi àti ìdílé rẹ̀. Àmọ́, nígbà tí àìsàn náà wá ń burú sí i, mo lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan nílé ìwòsàn, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn wọ́n gbé mi lọ sílé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Láìka bí mo ṣe máa ń ní ìrora ní gbogbo ìgbà sí, mo máa ń wàásù fáwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú wa, àwọn arúgbó míì tí wọ́n gbé wá síbẹ̀ àtàwọn àlejò. Mo tún máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Lọ́lá inúure àwọn ará, ó tún máa ń ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tó wà nítòsí.
Ọjọ́ Alẹ́ Mi Tù Mí Nínú
Ó máa ń tù mí nínú bí mo ṣe ń gbúròó àwọn tí èmi àti ọkọ mi ti láǹfààní láti ràn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ wọn ló wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn kan ń sìn nílẹ̀ Ọsirélíà, Kánádà, Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìsì àti Switzerland. Orílẹ̀-èdè Kánádà ni ọmọ mi John àti ìdílé rẹ̀ ń gbé báyìí. Aṣáájú-ọ̀nà ni àkọ́bí ọmọbìnrin wọn àti ọkọ rẹ̀. Wọ́n sì ti pe àbígbẹ̀yìn wọn obìnrin, tó ń jẹ́ Linda àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Joshua Snape sí kíláàsì ìkẹrìnlélọ́gọ́fà [124] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.
James ọmọ mi àti ìyàwó ẹ̀ náà ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì báyìí. Méjì nínú ọmọ wọn ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ọ̀kan wà ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Áténì lórílẹ̀-èdè Gíríìsì, èkejì sì wà ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Selters lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ọmọ wọn ọkùnrin tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn àti ọmọ wọn obìnrin pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Jámánì.
Ìròyìn tá a máa sọ fún màmá mi àti Theodotos ọkọ mi ọ̀wọ́n nígbà tí wọ́n bá jíǹde á mà pọ̀ gan-an ni o! Inú wọn á dùn gan-an láti rí ogún àtàtà tí wọ́n fi sílẹ̀ fún ìdílé wọn.b
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! October 22, 1974, ojú ìwé 12 sí 15, lédè Gẹ̀ẹ́sì.
b Arábìnrin Petrides sùn nínú ikú lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún, nígbà tá a ṣì ń ṣètò láti tẹ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
Lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí bí Jèhófà ṣe ń fún wa níṣìírí nípa bá a ṣe ń bá àwọn ará tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí kẹ́gbẹ́ pọ̀
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KÍPÍRỌ́SÌ
NICOSIA
ÒKUN MẸDITERÉNÍÀ
ÍJÍBÍTÌ
CAIRO
El Alamein
Alẹkisáńdíríà
Ismailia
Suez
Port Taufiq
Ipadò Suez
[Credit Line]
Látinú àwòrán NASA/Visible Earth imagery
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti Theodotos ọkọ mi rèé lọ́dún 1938
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
James ọmọ mi àti ìyàwó rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
John ọmọ mi àti ìyàwó rẹ̀