Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà Ìwé Mímọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìtọ́jú Ara
“Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ . . . pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.”—MÁÀKÙ 12:30.
1. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé nígbà tó dá wọn?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ò dá àìsàn àti ikú mọ́ àwa èèyàn. Inú ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn Párádísè ló fi Ádámù àti Éfà sí, pé kí wọ́n ‘máa ro ó kí wọ́n sì máa bójú tó o.’ Kì í ṣe pé kí wọ́n kàn wà níbẹ̀ fún àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún lásán, ṣùgbọ́n títí láé ni. (Jẹ́n. 2:8, 15; Sm. 90:10) Ká sọ pé wọ́n dúró bí olóòótọ́ sí Jèhófà ni, tí wọ́n sì ń fìfẹ́ tẹrí ba fún un gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, wọn ì bá tí mọ ohun tó ń jẹ́ àìsàn, ara hẹ́gẹhẹ̀gẹ àti ikú.
2, 3. (a) Báwo ni ìwé Oníwàásù ṣe ṣàpèjúwe ọjọ́ ogbó? (b) Ta ló fa ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, báwo la ó sì ṣe mú ikú àtàwọn ohun tó ń bá a rìn kúrò?
2 Ìwé Oníwàásù orí kejìlá ṣàpèjúwe tó ṣe kedere nípa “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tó máa ń bá ọjọ́ ogbó àwa èèyàn aláìpé rìn. (Ka Oníwàásù 12:1-7.) Ó fi ewú orí wé ìtànná “igi álímọ́ńdì.” Ó fi ẹsẹ̀ wé “àwọn ọkùnrin tí ó ní ìmí” àmọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ tí wọ́n sì ń rìn tàgétàgé. Ó bá a mu wẹ́kú bó ṣe fi ojú tó ti di bàìbàì wé àwọn ọmọge tó lọ wòde lójú fèrèsé ṣùgbọ́n tí wọ́n rí i pé gbogbo ẹ̀ ṣókùnkùn. Nítorí pé àwọn eyín kan ti ká, ó fi àwọn tó kù wé “àwọn obìnrin tí ń lọ nǹkan [tí wọ́n] ti dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí pé wọ́n ti kéré níye.”
3 Ká sòótọ́, kí ẹsẹ̀ máa gbọ̀n rìrì, kójú máa ríran bàìbàì àti kí gbogbo eyín wọ́ tán lẹ́nu kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé nígbà tó dá wọn. Kódà, ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù pàápàá jẹ́ ọ̀kan lára “àwọn iṣẹ́ Èṣù” tí Ọmọ Ọlọ́run máa tó mú kúrò nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà. Ìdí nìyí tí àpọ́sítélì Jòhánù fi sọ pé: “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòh. 3:8.
Kò Burú Láti Ṣàníyàn Níwọ̀nba Nípa Ìlera Ẹni
4. Kí nìdí táwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi máa ń ṣàníyàn níwọ̀nba nípa ìlera wa, àmọ́ kí la ní láti máa fi sọ́kàn?
4 Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àìlera àti ọjọ́ ogbó tó ń dààmú gbogbo èèyàn tó ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ ń bá àwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà fínra. Nítorí náà, kò burú tá a bá ń ṣàníyàn níwọ̀nba nípa ìlera wa, kódà ó ṣàǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣáà wù wá pé ká máa fi “gbogbo okun” wa sin Jèhófà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (Máàkù 12:30) Àmọ́ ṣá o, bá a ṣe ń wá ọ̀nà tí ara wa á fi le dé ìwọ̀n àyè kan, ká máa fi sọ́kàn pé ìwọ̀nba lohun téèyàn lè ṣe kó má tètè darúgbó tàbí kí àìsàn kankan má ṣe é.
5. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbà àtijọ́ tí àìlera ti bá fínra?
5 Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni àìlera ti bá fínra. Ẹpafíródítù jẹ́ ọ̀kan lára wọn. (Fílí. 2:25-27) Bákan náà, inú sábà máa ń yọ Tímótì tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù tímọ́tímọ́ lẹ́nu. Torí ẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ṣe gbà á nímọ̀ràn pé kó máa lo “wáìnì díẹ̀.” (1 Tím. 5:23) Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ní ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara,’ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ojú tó ń dùn ún tàbí àwọn àìlera mìíràn tí kò sí oògùn tó lè wò ó sàn lákòókò yẹn. (2 Kọ́r. 12:7; Gál. 4:15; 6:11) Pọ́ọ̀lù gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà nípa ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara’ rẹ̀ náà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 12:8-10.) Àmọ́, Ọlọ́run kò fi iṣẹ́ ìyanu mú ‘ẹ̀gún inú ẹran ara’ Pọ́ọ̀lù kúrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Ọlọ́run fún un lókun láti lè fara dà á. Àìlera Pọ́ọ̀lù wá fi agbára Jèhófà hàn. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹ̀kọ́ pàtàkì ni ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí kọ́ wa?
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ìlera Gbà Ọ́ Lọ́kàn Jù
6, 7. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ kí ọ̀rọ̀ ìlera wa gbà wá lọ́kàn jù?
6 Bẹ́ ẹ ṣe mọ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, oríṣi àwọn ìtọ́jú mìíràn sì wà tá ò lòdì sí. Ìwé ìròyìn wa tá à ń pè ní Jí! máa ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ìlera jáde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í sọ pé ìtọ́jú kan dára ju òmíràn lọ, síbẹ̀ a mọyì ìrànlọ́wọ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn tó ń tọ́jú aláìsàn. Àmọ́, ó dájú pé àwa ẹ̀dá èèyàn ò tíì lè ní ìlera pípé báyìí. Nítorí náà, àwa Kristẹni mọ̀ pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká má ṣe kó ọ̀ràn ìlera wa lékàn. A ò gbọ́dọ̀ ṣe bíi tàwọn èèyàn tí wọn ò “ní ìrètí kankan,” tí wọ́n rò pé ayé ìsinsìnyí nìkan ni ìrètí àwọn pin sí, tó fi jẹ́ pé kò sí irú ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọn ò lè gbà kára wọn ṣáà ti lè yá. (Éfé. 2:2, 12) Àwa ti pinnu pé a ò ní tìtorí pé a kò fẹ́ kú nísinsìnyí ṣe ohun tó máa mú wa pàdánù ojú rere Jèhófà, nítorí ó dá wa lójú pé bá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, a ó “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—1 Tím. 6:12, 19; 2 Pét. 3:13.
7 Ìdí míì tún wà tí kò fi yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera wa gbà wá lọ́kàn jù. Ìdí náà sì ni pé, kíkó ọ̀rọ̀ ìlera lékàn lè mú kéèyàn dẹni tó ń ro kìkì tara ẹ̀ nìkan. Pọ́ọ̀lù ṣèkìlọ̀ nípa ewu yìí nígbà tó sọ fáwọn ará Fílípì pé kí wọ́n má ṣe máa mójú tó ire ara wọn nìkan, ṣùgbọ́n kí wọ́n máa mójú tó ire àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. (Fílí. 2:4) Lóòótọ́ kò yẹ ká fọ̀rọ̀ ìlera wa ṣeré, ṣùgbọ́n ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní fáwọn ará àtàwọn èèyàn tá à ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run fún, kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera wa jẹ wá lógún jù.—Mát. 24:14.
8. Kí ni kíkó ọ̀rọ̀ ìlera lékàn lè sún wa ṣe?
8 Ewu tó wà ńbẹ̀ ni pé Kristẹni kan lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera jẹ òun lógún ju ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lọ. Bá a bá kó ọ̀rọ̀ ìlera lékàn, ó tún lè jẹ́ ká máa mú àwọn ẹlòmíì ní dandan pé kí wọ́n gba èrò wa nípa ìtọ́jú kan, àkànṣe oúnjẹ kan, tàbí oògùn kan tó ní èròjà oúnjẹ nínú. Ìlànà tó lè ràn wá lọ́wọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí wà nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “[Ẹ] máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù, kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀ títí di ọjọ́ Kristi.”—Fílí. 1:10.
Kí Ló Ṣe Pàtàkì Jù?
9. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ ká máa kópa nínú rẹ̀ déédéé, kí sì nìdí?
9 Tá a bá ń wádìí tá a sì ń mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, a ó máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwòsàn tẹ̀mí, ìyẹn wíwàásù àti kíkọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Iṣẹ́ aláyọ̀ yìí ń ṣe àwa àtàwọn tá à ń kọ́ láǹfààní. (Òwe 17:22; 1 Tím. 4:15, 16) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! máa ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ jáde nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ń ṣàìsàn tó le gan-an. Nígbà míì, àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ń sọ bí wọ́n ṣe fara da ìṣòro wọn tàbí bí wọ́n ṣe mú ọkàn kúrò lára ìṣòro ọ̀hún fúngbà díẹ̀ nípa wíwá ọ̀nà láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ àgbàyanu.a
10. Kí nìdí tí irú ìtọ́jú tá a yàn fi ṣe pàtàkì?
10 Tí ara Kristẹni kan tó ti tójúúbọ́ kò bá yá, òun ló máa gbé “ẹrù ti ara rẹ̀” ní ti pé kó fúnra rẹ̀ yan irú ìtọ́jú tó fẹ́. (Gál. 6:5) Àmọ́, ká máa rántí pé irú ìtọ́jú tá a bá yàn kan Jèhófà. Ṣé ẹ mọ̀ pé ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn ìlànà Bíbélì ló ń mú ká “ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:20) Bákàn náà ló ṣe yẹ kí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká máa yẹra fún ìtọ́jú tó lè mú ká tẹ ìlànà Ọlọ́run lójú tàbí tó lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. Ọ̀nà táwọn kan ń gbà ṣàyẹ̀wò àìsàn àti ọ̀nà táwọn kan ń gbà ṣètọ́jú àìsàn jẹ mọ́ bíbá ẹ̀mí èṣù lò. Jèhófà bínú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà tí wọ́n ń lo “agbára abàmì,” ìyẹn bíbá ẹ̀mí èṣù lò. Jèhófà sọ pé: “Ẹ ṣíwọ́ mímú àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà tí kò ní láárí wá. Tùràrí—ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún mi. Òṣùpá tuntun àti sábáàtì, pípe àpéjọpọ̀—èmi kò lè fara da lílo agbára abàmì pa pọ̀ pẹ̀lú àpéjọ ọ̀wọ̀.” (Aísá. 1:13) A ò gbọ́dọ̀ torí pé a wà nínú àìsàn, ká wá ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí Jèhófà máa gbọ́ àdúrà wa àtohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́.—Ìdárò 3:44.
Ó Ṣe Pàtàkì Ká Jẹ́ Ẹni Tí Èrò Inú Rẹ̀ Yè Kooro
11, 12. Báwo ni èrò inú tó yè kooro ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń yan ọ̀nà tá a máa gbà tọ́jú ara wa?
11 Bí ara wa ò bá yá, a ò lè máa retí pé dandan ni kí Jèhófà ṣiṣẹ́ ìyanu láti wò wá sàn, ṣùgbọ́n a lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n láti lè yan ìtọ́jú tó yẹ. Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ńṣe ni ká jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì máa darí wa ká sì jẹ́ ẹni tó ń ro àròjinlẹ̀. Tó bá jẹ́ àìsàn tó le ni, ó lè jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kí o má ṣe fi ìwádìí rẹ mọ sọ́dọ̀ oníṣègùn kan ṣoṣo, tó bá ṣeé ṣe. Ìyẹn bá ohun tí Òwe 15:22 sọ mu pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn tó jẹ́ Kristẹni bíi tirẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.
12 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti obìnrin aláìsàn kan nígbà ayé Jésù. Nínú Máàkù 5:25, 26, Bíbélì sọ pé: “Obìnrin kan wà tí ó ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá, ọ̀pọ̀ oníṣègùn sì ti mú ọ̀pọ̀ ìrora bá a, ó sì ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀, kò sì ṣe é láǹfààní ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó burú sí i.” Jésù wo obìnrin náà sàn, ó sì fi ìyọ́nú hàn sí i. (Máàkù 5:27-34) Nítorí kára wọn ṣáà ti lè yá, àwọn Kristẹni kan ti yan ọ̀nà ìgbàṣàyẹ̀wò àìsàn tàbí ọ̀nà ìgbàtọ́jú àìsàn tó tẹ ìlànà ìjọsìn mímọ́ lójú.
13, 14. (a) Báwo ni Sátánì ṣe lè lo ìtọ́jú ara wa láti fi ba ìdúróṣinṣin wa jẹ́? (b) Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó bá tiẹ̀ ṣe bí ẹní jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò?
13 Kò sí ohun tí Sátánì ò ní lò tán láti sáà rí i pé òun tàn wá kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Bó ṣe ń lo ìṣekúṣe àti ìfẹ́ ọrọ̀ láti mú àwọn kan kọsẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń gbìyànjú láti ba ìdúróṣinṣin àwọn mìíràn jẹ́ nípa mímú kí wọ́n gba àwọn ìtọ́jú téèyàn lè fura sí, tó jẹ́ pé tá a bá wò ó dáadáa, agbára òkùnkùn àti ìbẹ́mìílò ló wà nídìí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bá a ti ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” kó sì gbà wá lọ́wọ́ “onírúurú ìwà àìlófin,” kò yẹ ká tún wá gbé ara wa lé Sátánì lọ́wọ́ nípa lílọ́wọ́ sí ohunkóhun tó bá jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò àti agbára òkùnkùn.—Mátíù 6:13; Títù 2:14.
14 Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn. (Diu. 18:10-12) Pọ́ọ̀lù ka “bíbá ẹ̀mí lò” mọ́ “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19, 20) Síwájú sí i, “àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò” kò ní ní ìpín kankan nínú ètò àwọn nǹkan tuntun ti Jèhófà. (Ìṣí. 21:8) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jèhófà kórìíra ohunkóhun tó bá tiẹ̀ ṣe bí ẹní jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò.
Ẹ Fi Hàn Pé Ẹ Jẹ́ Olóye
15, 16. Kí nìdí tá a fi nílò ọgbọ́n nígbà tá a bá ń yan irú ìtọ́jú ara tá a fẹ́, ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo sì ni ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní fúnni?
15 Lójú gbogbo ohun tá a ti jíròrò yìí, tá a bá wá ń ṣiyè méjì pé ìbẹ́mìílò ti fẹ́ wọnú ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣàyẹ̀wò àìsàn tàbí ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà tọ́jú àìsàn, ó bọ́gbọ́n mu pé ká kọ irú àyẹ̀wò tàbí ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, pé àwa fúnra wa ò lè ṣàlàyé ọ̀nà táwọn kan ń gbà ṣètọ́jú ara kò fi dandan túmọ̀ sí pé ìtọ́jú náà ní ìbẹ́mìílò nínú. A nílò ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti òye láti lè máa ṣe ohun tí kò lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara. Bíbélì gbà wá níyànjú kan nínú ìwé Òwe orí kẹta, ó ní: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́. . . . Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, wọn yóò sì jẹ́ ìyè fún ọkàn rẹ.”—Òwe 3:5, 6, 21, 22.
16 Nítorí náà, bá a ṣe ń gbìyànjú pé kára wa le bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa pàdánù ojú rere Ọlọ́run níbi tá a ti ń wá ìtọ́jú sí àìsàn wa tàbí ara tó ń dara àgbà. Bó ṣe rí nínú àwọn ọ̀ràn míì náà ló ṣe rí nínú ọ̀ràn ìlera, a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ‘ìfòyebánilò wa di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn’ nípa rírí i dájú pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Fílí. 4:5) Nínú lẹ́tà pàtàkì kan tí ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní kọ sáwọn Kristẹni nígbà yẹn, wọ́n fún àwọn Kristẹni yẹn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n yẹra fún ìbọ̀rìṣà, ẹ̀jẹ̀ àti àgbèrè. Ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí wà nínú lẹ́tà yẹn pé: “Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí.” (Ìṣe 15:28, 29) Lọ́nà wo?
Tọ́jú Ara Rẹ Dé Àyè Tó Yẹ, Ṣùgbọ́n Ìlera Pípé Dọjọ́ Iwájú
17. Báwo ni títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì láìyẹsẹ̀ ti ṣe ṣàǹfààní fún ìlera wa?
17 Ó máa dáa kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mo mọ bí aásìkí mi ṣe pọ̀ tó nítorí pé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì láìyẹsẹ̀ lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ àti àgbèrè?’ Tún ronú lórí àwọn àǹfààní tá a ti rí nítorí pé à ń sapá láti máa “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́r. 7:1) Títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn ìmọ́tótó ara wa ń jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àìsàn. A tún ń láásìkí nítorí pé a ti kọ àwọn àṣà tí ń kó ẹ̀gbin bá ara tó sì lè ba àjọṣe àwa àti Ọlọ́run jẹ́, irú bíi lílá áṣáà, fífín tábà, mímu sìgá àti lílo oògùn olóró. Bákan náà, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú oúnjẹ àti ohun mímu ń ṣe ara wa ní oore tó pọ̀. (Ka Òwe 23:20; Títù 2:2, 3.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tá a bá ń fún ara ní ìsinmi tá a sì ń ṣeré ìdárayá, ara wa lè túbọ̀ le, àmọ́ gbígbà tá à ń gba ìtọ́sọ́nà látinú Bíbélì ló ń ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ jù lọ nípa tara àti nípa tẹ̀mí.
18. Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún, ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa ìlera ló sì yẹ ká máa retí?
18 Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó yẹ ká máa bójú tó ìlera wa nípa tẹ̀mí kí àjọṣe tímọ́tímọ́, tó ṣeyebíye, lè túbọ̀ máa wà láàárín àwa àti Baba wa ọ̀run tó jẹ́ Orísun “ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀” nínú ayé tuntun tó ṣèlérí. (1 Tím. 4:8; Sm. 36:9) Nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, ìwòsàn tara àti tẹ̀mí á wáyé ní kíkún nígbà tí Ọlọ́run bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé jì wọ́n lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. Jésù Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, yóò ṣamọ̀nà wa lọ sí “àwọn ìsun omi ìyè,” Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wa. (Ìṣí. 7:14-17; 22:1, 2) Nígbà yẹn, a óò tún rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó wúni lórí yìí, pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísá. 33:24.
19. Bá a ti ń ṣètọ́jú ara wa lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, kí ló yẹ kó dá wa lójú?
19 Ó dá wa lójú pé ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé, a sì ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ tí Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ń fa àìsàn àti ikú kúrò. Àmọ́, ní báyìí ná, ó dá wa lójú pé Baba wa onífẹ̀ẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fara da gbogbo àìsàn àti àìlera wa, nítorí pé, ‘ó bìkítà fún wa.’ (1 Pét. 5:7) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣètọ́jú ara wa, àmọ́ ká máa rí i pé à ń tẹ̀ lé ìlànà tó ṣe kedere tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tọ́ka sí irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ nínú àpótí tó wà lójú ìwé 17 nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2003.
Àtúnyẹ̀wò
• Ta ló fa àìsàn, ta ni yóò sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ fà?
• Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti ṣàníyàn nípa ìlera wa, kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
• Kí nìdí tí irú ìtọ́jú tá a yàn fi kan Jèhófà?
• Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera wa, báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú títẹ̀lé ìlànà Bíbélì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọlọ́run kò dá àìsàn àti ọjọ́ ogbó mọ́ aráyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Láìka àìlera sí, àwọn èèyàn Jèhófà ń rí ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù